Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wíwàníhìn-ín Kristi—Báwo Ló Ṣe Yé ọ sí?

Wíwàníhìn-ín Kristi—Báwo Ló Ṣe Yé ọ sí?

Wíwàníhìn-ín Kristi—Báwo Ló Ṣe Yé ọ sí?

“Kí ni yóò sì jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?”— MÁT. 24:3.

1. Ìbéèrè tó gbàfiyèsí wo làwọn àpọ́sítélì Jésù bi í?

 NÍ NǸKAN bí ẹgbàá ọdún sẹ́yìn, mẹ́rin lára àwọn àpọ́sítélì Jésù béèrè ìbéèrè kan lọ́wọ́ Jésù Ọ̀gá wọn nígbà tí wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀ ní ìdákọ́ńkọ́ lórí Òkè Ólífì. Wọ́n bi í pé: “Nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀, kí ni yóò sì jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?” (Mát. 24:3) Àwọn àpọ́sítélì yìí lo ọ̀rọ̀ méjì tó gbàfiyèsí gan-an nínú ìbéèrè tí wọ́n bi Jésù yìí. Àwọn ọ̀rọ̀ náà ni, “wíwàníhìn-ín rẹ” àti “ìparí ètò àwọn nǹkan.” Kí làwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí túmọ̀ sí?

2. Báwo la ṣe lè ṣàlàyé ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ náà, “ìparí”?

2 Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀rọ̀ náà “ìparí.” Ọ̀rọ̀ yìí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà syn·teʹlei·a. Jálẹ̀ inú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, la ti túmọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí sí “ìparí.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì míì tó jọ syn·teʹlei·a ni te’los. A túmọ̀ èyí sí “òpin.” Ká bàa lè rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn ọ̀rọ̀ méjì yìí, ẹ jẹ́ ká fi àsọyé tẹ́nì kan sọ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣàpèjúwe. Apá ìgbẹ̀yìn àsọyé náà ni ìparí, ìyẹn ìgbà tí olùbánisọ̀rọ̀ náà bá ń ṣàkópọ̀ àwọn kókó pàtàkì tó ti bá àwùjọ sọ nínú àsọyé náà àti bí ọ̀rọ̀ náà ṣe kàn wọ́n. Àmọ́ òpin àsọyé náà ni ìgbà tí olùbánisọ̀rọ̀ bá kúrò lórí pèpéle. Lọ́nà kan náà, tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa “ìparí ètò àwọn nǹkan,” gẹ́gẹ́ bá a ṣe lò ó nínú Bíbélì, ó tọ́ka sí àkókò tó máa ṣáájú òpin ètò àwọn nǹkan àti òpin ọ̀hún fúnra rẹ̀.

3. Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó máa wáyé láàárín ìgbà wíwàníhìn-ín Jésù?

3 Ọ̀rọ̀ kejì táwọn àpọ́sítélì náà lò nínú ìbéèrè tí wọ́n bi Jésù ni, “wíwàníhìn-ín.” Kí ni ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí? Látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, pa·rou·siʹa la ti túmọ̀ ọ̀rọ̀ yìí. a Látọdún 1914 tí Jèhófà ti fi Jésù jẹ Ọba ní ọ̀run ni wíwàníhìn-ín, ìyẹn pa·rou·siʹa Jésù ti bẹ̀rẹ̀, yóò sí máa bá a nìṣó títí dìgbà “ìpọ́njú ńlá,” tí Jésù máa wá pa àwọn èèyàn burúkú run. (Mát. 24:21) Oríṣiríṣi nǹkan ló máa wáyé láàárín ìgbà wíwàníhìn-ín Jésù yìí. Lára àwọn nǹkan ọ̀hún ni “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ti ètò àwọn nǹkan búburú yìí, kíkó àwọn àyànfẹ́ jọ àti àjíǹde wọn sí ìyè ti ọ̀run. (2 Tím. 3:1; 1 Kọ́r. 15:23; 1 Tẹs. 4:15-17; 2 Tẹs. 2:1) A lè sọ pé àkókò tó jẹ́ “ìparí ètò àwọn nǹkan” (syn·teʹlei·a) bá àkókò tí Bíbélì pè ní ìgbà wíwàníhìn-ín (pa·rou·siʹa) Kristi mu.

Àkókò Gígùn Kan

4. Ọ̀nà wo ni wíwàníhìn-ín Jésù gbà jọra pẹ̀lú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé nígbà ayé Nóà?

4 Bó ṣe jẹ́ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ fún àkókò gígùn là ń lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà pa·rou·siʹa fún, ó bá ohun tí Jésù sọ nípa wíwàníhìn-ín rẹ̀ mu. (Ka Mátíù 24:37-39.) Kíyè sí i pé Jésù kò fi wíwàníhìn-ín rẹ̀ wé àkókò kúkúrú tí Ìkún-omi fi wáyé ní ọjọ́ Nóà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló fi wíwàníhìn-ín rẹ̀ wé àkókò gígùn tó ṣáájú Ìkún-omi, èyí sì kan àkókò tí Nóà fi kan ọkọ̀ àti àkókò tó fi wàásù títí dìgbà tí Ìkún-omi fi dé. Àwọn ohun wọ̀nyẹn sì gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Lọ́nà kan náà, àkókò tí oríṣiríṣi ìṣẹ̀lẹ̀ yóò máa wáyé títí dìgbà ìpọ́njú ńlá, àti ìpọ́njú ńlá ọ̀hún fúnra rẹ̀ wà nínú àkókò wíwàníhìn-ín Kristi.—2 Tẹs. 1:6-9.

5. Báwo ni àkọsílẹ̀ tó wà nínú Ìṣípayá orí kẹfà ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé àkókò gígùn ni wíwàníhìn-ín Jésù ń tọ́ka sí?

5 Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì mìíràn tún wà tó fi hàn gbangba pé àkókò gígùn ni wíwàníhìn-ín Kristi ń tọ́ka sí, kì í wulẹ̀ ṣe ìgbà tó máa wá pa àwọn èèyàn búburú run nìkan. Ìwé Ìṣípayá ṣàpèjúwe pé Jésù ń gun ẹṣin funfun, a sì fún un ní adé. (Ka Ìṣípayá 6:1-8.) Ó sì fi hàn pé lẹ́yìn tí Jèhófà ti fi Jésù jẹ Ọba lọ́dún 1914, Jésù “jáde lọ ní ṣíṣẹ́gun àti láti parí ìṣẹ́gun rẹ̀.” Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn tún sọ pé àwọn kan tí wọ́n gẹṣin tí àwọ̀ wọn yàtọ̀ síra ń tẹ̀ lé e. Ńṣe ni àkọsílẹ̀ yìí ń fi àwọn tó gẹṣin wọ̀nyí sàsọtẹ́lẹ̀ nípa ogun, àìtó oúnjẹ àti àjàkálẹ̀ àrùn, àwọn nǹkan wọ̀nyí sì ti ń ṣẹlẹ̀ fún àkókò gígùn tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” À ń rí i tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń nímùúṣẹ lọ́jọ́ tiwa yìí.

6. Kí ni Ìṣípayá orí kejìlá jẹ́ ká mọ̀ nípa wíwàníhìn-ín Kristi?

6 Ìṣípayá orí kejìlá tún ṣàlàyé síwájú sí i nípa bí Ìjọba Ọlọ́run ṣe bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀run. A kà níbẹ̀ pé ogun kan ṣẹlẹ̀ ní ọ̀run. Máíkẹ́lì, ìyẹn Jésù Kristi tó ti wà ní ipò rẹ̀ lọ́run àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀ bá Èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù jagun. Ohun tí èyí sì yọrí sí ni pé wọ́n lé Sátánì Èṣù àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀ kúrò lọ́run wá sórí ilẹ̀ ayé. Àkọsílẹ̀ yẹn sọ pé àkókò yẹn ni Èṣù ní ìbínú ńlá, torí “ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.” (Ka Ìṣípayá 12:7-12.) Nígbà náà, ó ṣe kedere pé ìgbà tí Ìjọba Kristi ti bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀run ni “ègbé” tó dé bá ayé àtàwọn tó ń gbé inú rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i.

7. Kí ni Sáàmù Kejì sàsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀, àǹfààní wo sì ló ṣí sílẹ̀?

7 Bákan náà, Sáàmù Kejì sàsọtẹ́lẹ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe máa fi Jésù jẹ Ọba lórí Òkè Síónì ti ọ̀run. (Ka Sáàmù 2:5-9; 110:1, 2.) Àmọ́, sáàmù yìí tún jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbà kan wà tí Jèhófà máa fún àwọn alákòóso ayé àtàwọn tó wà lábẹ́ wọn láǹfààní láti fara mọ́ ìṣàkóso Kristi. Sáàmù yìí rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n lo “ìjìnlẹ̀ òye” kí wọ́n sì gba “ìtọ́sọ́nà.” Ó dájú pé, lákòókò yẹn, “aláyọ̀ ni gbogbo àwọn tí ń sá di [Ọlọ́run],” ìyẹn àwọn tí yóò fara mọ́ ìṣàkóso Jèhófà àti Ọba tí Jèhófà ti yàn. Nítorí náà, láàárín ìgbà wíwàníhìn-ín Jésù nínú agbára Ìjọba, àǹfààní ṣì máa wà fún àwọn alákòóso àtàwọn tó wà lábẹ́ wọn láti ṣe àwọn àyípadà tó bá yẹ.—Sm 2:10-12.

Dídá Àmì Náà Mọ̀

8, 9. Àwọn wo ló máa rí àmì wíwàníhìn-ín Kristi tí wọ́n sì máa lóye rẹ̀?

8 Nígbà táwọn Farisí béèrè ìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run máa dé lọ́wọ́ Jésù, ó sọ pé Ìjọba Ọlọ́run kì yóò wá pẹ̀lú “ṣíṣeérí tí ń pàfiyèsí,” ìyẹn lójú àwọn Farisí náà. (Lúùkù 17:20, 21) Àmì wíwàníhìn-ín Kristi kò lè yé àwọn aláìgbàgbọ́ rárá. Báwo ló ṣe fẹ́ yé wọn? Nígbà tó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò gba Jésù gẹ́gẹ́ bí Ọba tó máa ṣàkóso wọn lọ́jọ́ iwájú. Nítorí náà, àwọn wo ló máa rí àmì tí yóò fi hàn pé Kristi ti wà níhìn-ín, tí wọ́n sì máa lóye bí wíwàníhìn-ín rẹ̀ ṣe ṣe pàtàkì tó?

9 Jésù sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ni yóò rí àmì náà kedere, “gẹ́gẹ́ bí mànàmáná, nípa ìkọmànà rẹ̀, ṣe ń tàn láti apá kan lábẹ́ ọ̀run lọ sí apá ibòmíràn lábẹ́ ọ̀run.” (Ka Lúùkù 17:24-29.) Ó dùn mọ́ni pé Mátíù 24:23-27 mú kó ṣe kedere pé àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀ ni Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

Ìran Tó Máa Rí Àmì Náà

10, 11. (a) Àlàyé wo ni ìwé ìròyìn yìí ṣe nígbà kan rí nípa “ìran” tí Jésù sọ ní Mátíù 24:34? (b) Láìsí àní-àní, àwọn wo làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù á mọ̀ pé wọ́n wà lára “ìran” náà?

10 Nígbà kan, ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé pé ní ọ̀rúndún kìíní, “ìran yìí” tí Jésù sọ nínú Mátíù 24:34 túmọ̀ sí “ìran àwọn alájọgbáyé ti àwọn Júù aláìgbàgbọ́.” b Ó jọ pé àlàyé ìgbà yẹn bọ́gbọ́n mu, nítorí pé láwọn apá ibi tó kù tí Jésù ti lo ọ̀rọ̀ náà, “ìran” nínú Ìwé Mímọ́, kì í ṣàwọn èèyàn dáadáa ló lò ó fún. Lọ́pọ̀ ìgbà pàápàá, Jésù lo àwọn ọ̀rọ̀ bíi “burúkú,” “aláìnígbàgbọ́” àti “panṣágà” láti fi ṣàpèjúwe ìran náà. (Mát. 12:39; 17:17; Máàkù 8:38) Èyí ló mú kí ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé pé tá a bá ní ká wo bí ọ̀rọ̀ yìí ṣe nímùúṣẹ lóde òní, ńṣe ni ọ̀rọ̀ Jésù yìí ń tọ́ka sí “ìran” àwọn aláìgbàgbọ́ tó máa rí àwọn àmì tá a máa fi mọ “ìparí ètò àwọn nǹkan” (syn·teʹlei·a) àti òpin ètò àwọn nǹkan (teʹlos).

11 Òótọ́ ni pé tí Jésù bá fi ọ̀rọ̀ tí kò dáa ṣàpèjúwe “ìran,” àwọn èèyàn burúkú tó wà nígbà ayé rẹ̀ ló ń bá wí. Àmọ́, ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé àwọn èèyàn burúkú tó wà nígbà ayé rẹ̀ ni ó lo ọ̀rọ̀ náà “ìran” fún nínú Mátíù 24:34 ni? Rántí pé mẹ́rin lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ti wá bá a ní “ìdákọ́ńkọ́.” (Mát. 24:3) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jésù kò fi ọ̀rọ̀ tí kò dáa ṣàpèjúwe “ìran yìí” nígbà tó ń bá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ yìí sọ̀rọ̀, kò sí àní-àní pé wọ́n á mọ̀ pé àwọn àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù pẹ̀lú yóò wà lára “ìran” tí kò ní kọjá lọ “títí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹlẹ̀.”

12. Báwo ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ ṣáájú ṣe jẹ́ ká mọ àwọn tó ń bá wí nígbà tó lo ọ̀rọ̀ náà “ìran”?

12 Kí nìdí tá a fi lè sọ bẹ́ẹ̀? A lè rí ìdí náà tá a bá fara balẹ̀ ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ ṣáájú. Nínú Mátíù 24:32, 33, Jésù sọ pé: “Wàyí o, ẹ kẹ́kọ̀ọ́ kókó yìí lára igi ọ̀pọ̀tọ́ gẹ́gẹ́ bí àpèjúwe kan pé: Gbàrà tí ẹ̀ka rẹ̀ tuntun bá yọ ọ̀jẹ̀lẹ́, tí ó sì mú ewé jáde, ẹ mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn sún mọ́lé. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀yin pẹ̀lú, nígbà tí bá rí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, kí ẹ mọ̀ pé ó ti sún mọ́ tòsí lẹ́nu ilẹ̀kùn.” (Fi wé Máàkù 13:28-30; Lúùkù 21:30-32.) Lẹ́yìn náà, ó wá sọ nínú Mátíù 24:34 pé: “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé ìran yìí kì yóò kọjá lọ lọ́nàkọnà títí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹlẹ̀.”

13, 14. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ó ní láti jẹ́ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ni “ìran” tí Jésù ń sọ?

13 Jésù sọ pé àwọn àpọ́sítélì òun tí Ọlọ́run máa tó fi ẹ̀mí mímọ́ yàn lohun tó ń ṣẹlẹ̀ máa yé nígbà tí wọ́n bá rí i tí “gbogbo nǹkan wọ̀nyí” bá ń ṣẹlẹ̀. Nítorí náà, ó ní láti jẹ́ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ló ń bá wí nígbà tó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ìran yìí kì yóò kọjá lọ lọ́nàkọnà títí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹlẹ̀.”

14 Tàwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù yàtọ̀ pátápátá sí tàwọn aláìgbàgbọ́ ní ti pé kì í ṣe pé wọ́n á kàn rí àmì náà nìkan ni, àmọ́ wọ́n á tún lóye bó ṣe ṣe pàtàkì tó. Wọn yóò “kẹ́kọ̀ọ́” látinú àmì náà wọ́n á sì “mọ” ohun tó túmọ̀ sí ní ti gidi. Wọn yóò mọ̀ lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ pé “ó ti sún mọ́ tòsí lẹ́nu ilẹ̀kùn.” Òótọ́ ni pé àtàwọn Júù aláìgbàgbọ́ àtàwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ló rí ìmúṣẹ àkọ́kọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Jésù yẹn ní ọ̀rúndún kìíní, àmọ́ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ nìkan ló kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀, èyí sì mú kí wọ́n lóye ohun táwọn nǹkan tí wọ́n rí túmọ̀ sí ní ti gidi.

15. (a) Àwọn wo ló para pọ̀ jẹ́ “ìran” tòde òní tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? (b) Kí nìdí tí a kò fi lè ṣírò bí “ìran yìí” ṣe máa gùn tó? (Wo àpótí tó wà lójú ìwé 25.)

15 Lóde òní, ńṣe làwọn tí kò lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run ń rò pé kò sí “ṣíṣeérí tí ń pàfiyèsí” nípa àmì wíwàníhìn-ín Jésù. Ohun tí wọ́n ń rò ni pé ohun gbogbo ń bá a lọ gẹ́gẹ́ bó ṣe wà látọjọ́ táláyé ti dáyé. (2 Pét. 3:4) Àmọ́, àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Kristi tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, ìyẹn ẹgbẹ́ Jòhánù ti òde òní ti rí àmì yìí kedere bí ìgbà tí mànàmáná bá kọ, wọ́n sì ti lóye ohun tó túmọ̀ sí gan-an. Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan, àwọn ẹni àmì òróró yìí ló para pọ̀ jẹ́ “ìran” tòde òní tí kì yóò kọjá lọ “títí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹlẹ̀.” c Èyí fi hàn pé àwọn kan lára àwọn arákùnrin Kristi tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró ṣì máa wà lórí ilẹ̀ ayé nígbà tí ìpọ́njú ńlá tí Jésù sàsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀.

‘Ẹ Máa Ṣọ́nà’

16. Kí ni gbogbo àwa ọmọ ẹ̀yìn Kristi gbọ́dọ̀ máa ṣe?

16 Àmọ́, pé ẹgbẹ́ Jòhánù rí àmì yẹn nìkan kò tó, wọ́n tún ní iṣẹ́ láti ṣe. Jésù sọ pé: “Ohun tí mo sọ fún yín ni mo sọ fún gbogbo ènìyàn, Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.” (Máàkù 13:37) Ọ̀rọ̀ yìí ṣe pàtàkì gan-an fún gbogbo wa lóde òní, yálà a wà lára àwọn ẹni àmì òróró tàbí ogunlọ́gọ̀ ńlá. Ó ti lé ní àádọ́rùn-ún ọdún báyìí tí Ọlọ́run ti fi Jésù jẹ Ọba ní ọ̀run, ìyẹn lọ́dún 1914. Òótọ́ ni pé ó lè má rọrùn rárá fún wa láti wà ní ìmúratán ká sì máa ṣọ́nà, àmọ́ ohun tá a gbọ́dọ̀ máa ṣe nìyẹn. Tá a bá gbà lóòótọ́ pé Kristi ti wà níhìn láti máa ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba tá a kò lè fojú rí, á mú ká wà ní ìmúratán ká sì máa ṣọ́nà. Yóò tún jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù máa wá pa gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ run láìpẹ́ “ní wákàtí tí [a] kò ronú pé ó lè jẹ́.”— Lúùkù 12:40.

17. Ipa wo ló yẹ kí òye tá a ní nípa wíwàníhìn-ín Kristi ní lórí wa, kí ló sì yẹ ká pinnu láti ṣe?

17 Òye tá a ní nípa wíwàníhìn-ín Kristi jẹ́ ká mọ̀ pé ìsinsìnyí kọ́ ló yẹ ká máa fàkókò ṣòfò. A mọ̀ pé Jésù ti wà níhìn-ín báyìí ó sì ti ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba lọ́run láti ọdún 1914. Láìpẹ́, ó máa wá pa àwọn èèyàn burúkú run yóò sì mú àyípadà tó ga lọ́lá bá gbogbo ayé pátá. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu láìyẹsẹ̀ láti máa fi ìtara kópa nínú iṣẹ́ tí Jésù sàsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀. Ó ní: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin [teʹlos] yóò sì dé.”—Mát. 24:14.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nínú 2 Kọ́ríńtì 10:10, 11 àti Fílípì 2:12 jẹ́ ká mọ ìyàtọ̀ tó wà nínú ìgbà tó wà lọ́dọ̀ àwọn ará Kọ́ríńtì àti Fílípì àti ìgbà tí kò sí lọ́dọ̀ wọn. Ọ̀rọ̀ náà pa·rou·siʹa, ìyẹn “wíwàníhìn-ín” ló lò láti ṣàlàyé ìgbà tó wà lọ́dọ̀ wọn, èyí sì jẹ́ ká rí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà. Fún àlàyé kíkún, wo ìwé Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ Kejì, ojú ewé 676 sí 679.

b Wo Ilé-ìṣọ́nà November 1, 1995, ojú ìwé 11 sí 15, 19, 30, 31.

c Ó jọ pé “ìran” tá à ń sọ yìí bá ìmúṣẹ ohun tí Ọlọ́run kọ́kọ́ fi han Jòhánù nínú ìwé Ìṣípayá mu. (Ìṣí. 1:10–3:22) Látọdún 1914 ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí í nímùúṣẹ ní ọjọ́ Olúwa títí dìgbà tí ẹni tó kẹ́yìn lára àwọn ẹni àmì òróró bá kú tó sì jíǹde.—Wo ìwé Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀! ojú ewé 24, ìpínrọ̀ 4.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Báwo la ṣe mọ̀ pé àkókò gígùn ni wíwàníhìn-ín Jésù jẹ́?

• Àwọn wo ló rí àmì wíwàníhìn-ín Jésù tí wọ́n sì lóye rẹ̀?

• Àwọn wo ló para pọ̀ jẹ́ ìran tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa wọn nínú Mátíù 24:34 lòde òní?

• Kí nìdí tá ò fi lè ṣírò bí “ìran yìí” ṣe máa gùn tó?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 25]

Ǹjẹ́ A Lè Ṣírò bí “Ìran Yìí” Ṣe Máa Gùn Tó?

Ọ̀rọ̀ náà “ìran” sábà máa ń tọ́ka sí àwọn èèyàn onírúurú ọjọ́ orí tí wọ́n gbé ayé ní àkókò kan pàtó tàbí nígbà ìṣẹ̀lẹ̀ kan. Bí àpẹẹrẹ, Ẹ́kísódù 1:6 sọ pé: “Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Jósẹ́fù kú, àti gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìran yẹn pẹ̀lú.” Ọjọ́ orí Jósẹ́fù àtàwọn arákùnrin rẹ̀ yàtọ̀ síra, àmọ́ ìrírí kan náà ni wọ́n ní láàárín àkókò kan náà tí wọ́n gbé ayé. Àwọn tó tún wà lára “ìran yẹn” ni díẹ̀ lára àwọn arákùnrin Jósẹ́fù tí wọ́n ti bí ṣáájú rẹ̀. Jósẹ́fù kú ṣáájú díẹ̀ lára àwọn wọ̀nyí. (Jẹ́n. 50:24) Bẹ́ńjámínì àtàwọn mìíràn lára àwọn “ìran yẹn” ni wọ́n bí lẹ́yìn tí wọ́n bí Jósẹ́fù, ó sì ṣeé ṣe kí wọn ṣì wà láàyè lẹ́yìn tí Jósẹ́fù kú.

Nítorí náà, tí ọ̀rọ̀ náà “ìran” bá tọ́ka sí àwọn èèyàn tí wọ́n gbé ayé ní àkókò kan pàtó, a ò lè sọ bí irú àkókò bẹ́ẹ̀ ṣe gùn tó, ṣùgbọ́n a mọ̀ pé irú àkókò bẹ́ẹ̀ máa ní òpin, kò sì ní gùn jù bó ṣe yẹ lọ. Nítorí náà, nígbà tí Jésù lo ọ̀rọ̀ náà “ìran yìí” gẹ́gẹ́ bó ṣe wà ní Mátíù 24:34, kì í ṣe pé ó ń kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe lè ṣírò ìgbà tí “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” máa dópin. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù tẹnu mọ́ ọn pé wọn kò lè mọ “ọjọ́ àti wákàtí.”—2 Tím. 3:1; Mát. 24:36.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22, 23]

Lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti fi Jésù jẹ Ọba lọ́dún 1914, Bíbélì sọ pé Jésù jáde lọ ní “ṣíṣẹ́gun”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

“Ìran yìí kì yóò kọjá lọ lọ́nàkọnà títí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹlẹ̀”