Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wọ́n Rọ Àwọn Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege Nílé Ẹ̀kọ́ Gílíádì Pé Kí Wọ́n “Máa Walẹ̀ Jìn”

Wọ́n Rọ Àwọn Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege Nílé Ẹ̀kọ́ Gílíádì Pé Kí Wọ́n “Máa Walẹ̀ Jìn”

Ayẹyẹ Ìkẹ́kọ̀ọ́yege Kíláàsì Kẹtàlélọ́gọ́fà Nílé Ẹ̀kọ́ Gílíádì

Wọ́n Rọ Àwọn Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege Nílé Ẹ̀kọ́ Gílíádì Pé Kí Wọ́n “Máa Walẹ̀ Jìn”

NÍ Sátidé, ọjọ́ kẹjọ, oṣù September, ọdún 2007, àwọn èrò tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́fà, àádọ́ta-dín-nírínwó ó lé méjì [6,352] láti ilẹ̀ mọ́kànlélógójì pé jọ síbi ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege kíláàsì kẹtàlélọ́gọ́fà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Ní dédé aago mẹ́wàá òwúrọ̀, alága ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege náà, Anthony Morris, tó wà lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí, kí àwọn èrò tó pé jọ káàbọ̀. Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ tó fi ṣí ayẹyẹ náà, ó pe olùbánisọ̀rọ̀ àkọ́kọ́, ìyẹn Gary Breaux tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà láti wá sọ̀rọ̀.

Arákùnrin Breaux mú un dá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lójú pé bó ṣe wù kí ìrísí àwọn tó bá ń ṣèfẹ́ Jèhófà rí, wọ́n lẹ́wà lójú rẹ̀. (Jer. 13:11) Ó wá rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí ẹwà tí wọ́n ní lójú Jèhófà ṣá. Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni Gerrit Lösch tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ̀rọ̀. Ó ní kò sóhun tó burú nínú ká máa retí èrè lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (Héb. 11:6) Àmọ́ ìfẹ́ ló yẹ kó mú wa máa sin Jèhófà.

Arákùnrin William Samuelson tó jẹ́ alábòójútó Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Ẹ̀kọ́ Ètò Ọlọ́run ló sọ̀rọ̀ tẹ̀ lé e. Ó rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé kí wọ́n má ṣe wẹ̀yìn lẹ́nu iṣẹ́ tó gbayì, ìyẹn iṣẹ́ pípolongo Ọba wa tó ń ṣàkóso. Ó sì tún ní kí wọ́n jẹ́ kí ìwà wọn fi hàn pé ẹni iyì ni wọ́n. a Arákùnrin Sam Roberson tó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ alábòójútó Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Ẹ̀kọ́ Ètò Ọlọ́run gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà níyànjú pé ànímọ́ rere táwọn èèyàn ní ni kí wọ́n máa wò. Ó ní èyí yóò jẹ́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lè “ní ìfẹ́ fún gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará.”—1 Pét. 2:17.

Lẹ́yìn àwọn ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró yẹn, Arákùnrin Mark Noumair tó jẹ́ olùkọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu díẹ̀ lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà. Wọ́n sì sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ní lóde ẹ̀rí láàárín àkókò tí wọ́n fi wà nílé ẹ̀kọ́ náà. Gbogbo àwọn tí wọ́n pé jọ ló rí i kedere pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ ìsìn àti pé wọ́n fẹ́ láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà ni Arákùnrin Kent Fischer tó wá láti Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ìdílé Bẹ́tẹ́lì nílùú Patterson fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn kan tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ní ilẹ̀ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ táwọn míṣọ́nnárì wà. Ohun táwọn Arákùnrin yìí sọ jẹ́ kó dá àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ àtàwọn òbí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lójú pé wọ́n máa ń tọ́jú àwọn míṣọ́nnárì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rán jáde dáadáa níbi tí wọ́n bá rán wọn lọ. Arákùnrin Izak Marais, tó wá láti Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Ìtumọ̀, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn tó ti ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì látọjọ́ tó ti pẹ́. Ìrírí wọn sì jẹ́ káwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà mọ irú ayọ̀ tí wọ́n máa ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn.

Arákùnrin Geoffrey Jackson tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló sọ lájorí àsọyé níbi ayẹyẹ náà. Àkòrí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni, “Pẹ̀lú Gbogbo Ohun Tẹ́ Ẹ Ti Gbọ́ Yìí, Kí Lẹ Máa Ṣe”? Arákùnrin Jackson yìí tó ti ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì fọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nílẹ̀ Gúúsù Pàsífíìkì sọ̀rọ̀ nípa apá tó parí Ìwàásù Lórí Òkè. Nínú ìwàásù yẹn Jésù sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin méjì tó kọ́ ilé. Ọ̀kan jẹ́ olóye, ìkejì sì jẹ́ òmùgọ̀. Arákùnrin Jackson sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àgbègbè kan náà ni wọ́n kọ́ ilé méjèèjì sí. Àmọ́ orí iyanrìn ni èyí òmùgọ̀ kọ́lé tirẹ̀ sí, nígbà tí èyí olóye walẹ̀ jìn títí tó fi kan àpáta kó tó fi ìpìlẹ̀ ilé rẹ̀ lélẹ̀. Nígbà tí ẹ̀fúùfù líle fẹ́ lu ilé wọn, èyí tó wà lórí àpáta dúró gbọn-in, àmọ́ ńṣe lèyí tó wà lórí iyanrìn ya lulẹ̀.—Mát. 7:24-27; Lúùkù 6:48.

Jésù ṣàlàyé pé àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ òun tí wọn ò sì ṣe ohun tóun sọ dà bí òmùgọ̀ ọkùnrin náà tó kọ́lé rẹ̀ sórí iyanrìn. Àmọ́ àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù tí wọ́n sì ṣe ohun tó sọ dà bí ọkùnrin olóye náà. Arákùnrin Jackson sọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé: “Tẹ́ ẹ bá fi ohun tẹ́ ẹ ń kọ́ nínú Bíbélì sílò lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nárì yín, ẹ óò dà bí ọkùnrin olóye náà.” Lọ́rọ̀ kan ṣá, ó rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé kí wọ́n “máa walẹ̀ jìn” lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nárì wọn.

Lópin ayẹyẹ náà, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gba ìwé ẹ̀rí wọn àti ibi tí wọ́n rán wọn lọ. Arákùnrin Morris sì wá sọ ọ̀rọ̀ ìyànjú tí wọ́n fi kádìí ayẹyẹ náà. Ó gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà níyànjú pé kí wọ́n máa bá a nìṣó ní títọ Jésù lẹ́yìn, kí wọ́n sì rí i dájú pé àwọn gbára lé Jèhófà. Bí ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege náà ṣe parí nìyẹn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Abẹ́ àbójútó Ìgbìmọ̀ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ni Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Ẹ̀kọ́ Ètò Ọlọ́run wà. Òun ló ń bójú tó Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, Ilé Ẹ̀kọ́ fún Àwọn Tó Wà Nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka, àti Ilé Ẹ̀kọ́ fún Àwọn Alábòójútó Arìnrìn-Àjò.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 31]

ÌSỌFÚNNI NÍPA KÍLÁÁSÌ

Iye orílẹ̀-èdè táwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti wá: 10

Iye orílẹ̀-èdè tá a yàn wọ́n sí: 24

Iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́: 56

Ìpíndọ́gba ọjọ́ orí wọn: 33.5

Ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti lò nínú òtítọ́: 17.9

Ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti lò nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún: 13.8

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

Kíláàsì Kẹtàlélọ́gọ́fà Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege Ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì

Nínú ìlà àwọn orúkọ tí ń bẹ nísàlẹ̀ yìí, ńṣe la to nọ́ńbà ìlà kọ̀ọ̀kan láti iwájú lọ sẹ́yìn, a sì to orúkọ láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún lórí ìlà kọ̀ọ̀kan.

(1) Esparza, E. Papaya, S.; Bilal, A.; Suárez, M.; Evers, E.; Dimichino, K. (2) Rosa, M.; Fujii, R.; Ratey, O.; Leveton, J.; Van Leemputten, M. (3) Boscaino, A.; Beck, K.; Budanov, H.; Braz, C.; Peltz, K.; Siaw, A. (4) Leveton, S.; Santikko, H.; Conte, S.; Wilson, J.; Rylatt, J.; Pierce, S.; Fujii, K. (5) Rosa, D.; Boscaino, M.; Austin, V.; Rodiel, P.; Bilal, P.; Dimichino, P. (6) Ratey, B.; Czyzyk, D.; Clarke, C.; Riedel, A.; Esparza, F.; Siaw, P.; Van Leemputten, T. (7) Rodiel, J.; Evers, J.; Green, J.; Czyzyk, J.; Santikko, M.; Rylatt, M. (8) Peltz, L.; Austin, D.; Riedel, T.; Beck, M.; Pierce, W.; Conte, S.; Green, S. (9) Suárez, J.; Clarke, J.; Papaya, S.; Budanov, M.; Wilson, R.; Braz, R.