Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àdéhùn Pàtàkì Kan

Àdéhùn Pàtàkì Kan

Àdéhùn Pàtàkì Kan

MO ṢE àdéhùn pàtàkì kan. Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé ohun tó mú èmi ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ adélébọ̀ tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Sípéènì ṣe àdéhùn yẹn.

Kò sí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan rárá nílé àwọn òbí mi. Ìbànújẹ́ dorí ìdílé wa kodò nígbà tí àbúrò mi ọkùnrin tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rin kú nínú jàǹbá kan. Ìyẹn nìkan kọ́, ìwàkiwà tó kún ọwọ́ bàbá mi kò jẹ́ kí ìyá mi fi bẹ́ẹ̀ láyọ̀ lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ. Pẹ̀lú gbogbo ìṣòro tí ìyá mi dojú kọ yìí, síbẹ̀ ó kọ́ èmi àti ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin ní ìwà ọmọlúwàbí.

Nígbà tó yá, ẹ̀gbọ́n mi gbéyàwó, kò sì pẹ́ témi náà fi relé ọkọ. Láìpẹ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn, àyẹ̀wò táwọn dókítà ṣe fi hàn pé ìyá mi ní àrùn jẹjẹrẹ, àrùn jẹjẹrẹ yìí ló sì wá gbẹ̀mí ẹ̀ nígbà tó yá. Àmọ́ kó tó kú ó fi ogún iyebíye kan sílẹ̀ fún wa.

Obìnrin kan tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ojúlùmọ̀ ìyá mi ti sọ fún un nípa ìrètí tó wà nínú Ìwé Mímọ́ nípa àjíǹde, ìyá mi sì gbà pé kí obìnrin náà máa wá kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tó kù díẹ̀ kí ìyá mi kú, ọ̀rọ̀ tó ń fúnni nírètí tó wà nínú Bíbélì mú kí ìgbésí ayé rẹ̀ nítumọ̀ èyí sì fún un láyọ̀.

Nígbà témi àti ẹ̀gbọ́n mi rí ipa rere tí ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ní lórí ìyá mi, làwa náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nígbà tó ku oṣù kan kí n bí ọmọ mi kejì, mo ṣèrìbọmi láti fi hàn pé mo ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lucía lorúkọ tá a sì sọ arẹwà ọmọbìnrin náà.

Ọjọ́ pàtàkì lọjọ́ tí mo ṣèrìbọmi jẹ́ fún mi. Ọ̀kan lára ìdí tí mo fi sọ bẹ́ẹ̀ ni pé mo ti di ti Jèhófà báyìí. Mo ti ya ara mi sí mímọ́ fún un pé òun ni màá máa sìn títí ayé. Ìdí kejì ni pé yóò ṣeé ṣe fún mi láti sọ ohun tí mo gbà gbọ́ fún ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mi ọ̀wọ́n.

Àmọ́, kò pẹ́ rárá tí ohun kejì tí mo sọ pé ó ń fún mi láyọ̀ yẹn fi mú ọkàn mi pòrúurùu. Nígbà tí Lucía pé ọmọ ọdún mẹ́rin, inú bẹ̀rẹ̀ sí í kan án burúkú burúkú. Lẹ́yìn oríṣiríṣi àyẹ̀wò, dókítà kan tó ń yàwòrán inú ara sọ pé kinní kan wà tó so mọ́ ẹ̀dọ̀ Lucía, kinní ọ̀hún sì tóbi tó ọsàn. Dókítà yẹn ṣàlàyé pé Lucía ní oríṣi àrùn jẹjẹrẹ kan tó ń mú káwọn ibì kan lára iṣan tó ń bá ọpọlọ ṣiṣẹ́ wú, àìsàn gbẹ̀mígbẹ̀mí sì ni àìsàn ọ̀hún. Bí Lucía ṣe bẹ̀rẹ̀ àìsàn tó bá a fínra fún ọdún méje gbáko nìyẹn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ ló sì lò nílé ìwòsàn.

Ó Lẹ́mìí Àtiran Àwọn Ẹlòmíì Lọ́wọ́

Láàárín àwọn ọdún tí nǹkan le koko yìí, bí Lucía ṣe máa ń dì mọ́ mi tó sì máa ń fẹnu kò mí lẹ́nu máa ń mú kí ń túra ká. Bákan náà, ọ̀nà tó gbà fara da àìsàn tó ń ṣe é yìí wú àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn yẹn lórí gan-an ni. Gbogbo ìgbà ló máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn nọ́ọ̀sì. Ó máa ń bá wọn kó yúgọ́ọ̀tì, omi èso àtàwọn nǹkan míì lọ fún àwọn ọmọdé tó wà ní wọ́ọ̀dù tó wà nítòsí tirẹ̀. Kódà, àwọn nọ́ọ̀sì yẹn fún un ní ẹ̀wù funfun kan táwọn nọ́ọ̀sì máa ń wọ̀ sórí aṣọ wọn, wọ́n sì tún fún un ní báàjì àyà kan tí wọ́n kọ “nọ́ọ̀sì kékeré” sí lára.

Obìnrin kan tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn yẹn sọ pé: “Àwọn nǹkan tí Lucía ṣe wú mi lórí gan-an ni. Ọmọ tó jáfáfá ni, ó lójú ọnà, ó fẹ́ràn kó máa ya àwòrán kó sì máa kùn ún. Ó jẹ́ ọmọ kan tí ọ̀rọ̀ dá ṣáká lẹ́nu rẹ̀, ó sì máa ń hùwà àgbà gan-an ni.”

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló fún Lucía lókun tí kò fi banú jẹ́. (Héb. 4:12) Ó dá a lójú pé gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣèlérí nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, nínú ayé tuntun, “ikú kì yóò . . . sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.” (Ìṣí. 21:4) Ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ ẹ́ lógún gan-an ni, gbogbo ìgbà ló máa ń sọ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì fáwọn èèyàn. Ìrètí tó lágbára tí Lucía ní nínú àjíǹde ló tù ú nínú, tó sì mú kó túra ká, láìwo ti pé kò sí ìrètí pé ó máa ye àìsàn náà. (Isa. 25:8) Bó sì ṣe ń ṣe nìyẹn títí di ọjọ́ tí àrùn jẹjẹrẹ yẹn fi gbẹ̀mí ẹ̀.

Ọjọ́ yẹn gan-an ni mo ṣe àdéhùn pàtàkì yẹn. Lucía ò lè la ojú rẹ̀ rárá. Bàbá rẹ̀ di ọwọ́ rẹ̀ kan mú, èmi náà sì di èkejì mú. Mo rọra sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sí i létí pé: “Fọkàn balẹ̀, mi ò ní fi ẹ́ sílẹ̀. Ṣáà máa mí díẹ̀díẹ̀, tó o bá jíǹde ara rẹ á yá. O ò ní jẹ̀rora mọ́, èmi náà á sì wà pẹ̀lú ẹ.”

Nísinsìnyí, mo gbọ́dọ̀ rí i pé mo mú àdéhùn yẹn ṣẹ. Mo mọ̀ pé kò ní rọrùn rárá fún mi láti dúró dìgbà tó máa jíǹde. Ṣùgbọ́n, tí mo bá ní sùúrù, tí mo gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, tí mo sì ń bá a nìṣó láti jẹ́ adúróṣinṣin sí i, màá wà níbẹ̀ tí Lucía bá jíǹde.

Àwọn Nǹkan Rere Tá A Fi Ń Rántí Lucía

Àpẹẹrẹ ìgboyà tí Lucía fi sílẹ̀ àti àtìlẹ́yìn tó kọjá àfẹnusọ tí ìjọ ṣe fún wa wọ ọkọ mi tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọkàn gan-an ni. Lọ́jọ́ tí Lucía kú, ọkọ mi sọ fún mi pé òun ní láti tún èrò òun pa. Ní ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan lẹ́yìn náà, ó sọ fún ọ̀kan lára àwọn alàgbà ìjọ wa pé òun fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí ọkọ mi fi bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí gbogbo ìpàdé. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ọkọ mi jáwọ́ sìgá mímu, èyí sì jẹ́ ohun tó ṣòro fún un tẹ́lẹ̀ láti ṣe.

Ọgbẹ́ ọkàn tí mo ní nítorí ikú Lucía ò tíì lọ tán pátápátá, síbẹ̀, mo dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Jèhófà fún àwọn nǹkan rere tá a fi ń rántí Lucía. Ìrètí àgbàyanu pé àjíǹde ń bọ̀ lèmi àti ọkọ mi fi ń tu ara wa nínú. A tiẹ̀ máa ń fojú inú wo ìgbà tá a máa rí Lucía padà, pẹ̀lú ojú rẹ̀ tó gún régé tó sì fani mọ́ra, àti tọ́rọ́ tó máa ń yọ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ tó bá rẹ́rìn-ín músẹ́.

Ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú tó ṣẹlẹ̀ sí ọmọbìnrin mi yìí tún nípa lórí aládùúgbò wa kan. Lọ́jọ́ Sátidé kan tí òjò ń rọ̀, obìnrin kan tí ọmọ rẹ̀ ń lọ síléèwé kan náà pẹ̀lú Lucía wá sílé wa. Irú àìsàn tó pa Lucía ló pa ọmọkùnrin rẹ̀ kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlá. Nígbà tí obìnrin yẹn gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Lucía, ó béèrè ibi tá à ń gbé lọ́wọ́ àwọn èèyàn, ó sì wá sílé wa. Obìnrin yẹn wá kí mi kú àmúmọ́rá ti ikú Lucía, ó sì dábàá pé ká dá ẹgbẹ́ kan sílẹ̀ tí yóò máa tu àwọn abiyamọ tírú nǹkan báyìí ṣẹlẹ̀ sí nínú.

Mo sọ fún un pé ọ̀kan lára àwọn ìlérí tí Bíbélì ṣe ló ń tù mí nínú, èyí sì ju ìtùnú èyíkéyìí téèyàn lé fúnni lọ fíìfíì. Bí mo ṣe ka ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Jòhánù 5:28, 29 fún un, inú ẹ̀ dùn gan-an. Ó gbà pé kí n máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kò sì pẹ́ rárá tóun náà fi bẹ̀rẹ̀ sí í ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.” (Fílí. 4:7) Lọ́pọ̀ ìgbà, tá a bá jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì a máa ń dúró díẹ̀ tá a sì máa ń fojú inú wò ó pé a wà nínú ayé tuntun, táwọn èèyàn wa tí wọ́n ti kú sì ń jíǹde, tá a wá ń kí wọn káàbọ̀.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ikú dá ẹ̀mí Lucía légbodò, a ò lè gbàgbé àwọn nǹkan rere tó fi sílẹ̀ láé. Ìgbàgbọ́ rẹ̀ ti mú kí ìdílé wa máa sin Ọlọ́run níṣọ̀kan, ó sì ti mú kí ìpinnu mi láti dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́ túbọ̀ lágbára sí i. Láìsí àní-àní, gbogbo àwa táwọn èèyàn wa kan ti kú, tá a sì ń retí pé wọ́n á jíǹde la ní àdéhùn pàtàkì kan.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Àwòrán Párádísè tí Lucía yà