Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Lúùkù

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Lúùkù

Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Lúùkù

ÀWỌN èèyàn gbà pé àwọn Júù ni Mátíù dìídì kọ Ìhìn Rere rẹ̀ fún, nígbà tó jẹ́ pé Ìhìn Rere Máàkù wà fún àwọn tí kì í ṣe Júù. Àmọ́, gbogbo orílẹ̀-èdè ni Ìhìn Rere Lúùkù wà fún. Nǹkan bí ọdún 56 sí 58 Sànmánì Kristẹni ni Lúùkù kọ ìwé rẹ̀ yìí. Ìhìn Rere Lúùkù ṣàlàyé ní kíkún nípa ìgbésí ayé Jésù àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí oníṣègùn kan tara ẹ̀ balẹ̀ tó sì mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́, Lúùkù “tọpasẹ̀ ohun gbogbo láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpéye.” Ó sọ ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín ọdún márùndínlógójì, ìyẹn ọdún 3 ṣáájú Sànmánì Kristẹni sí ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. (Lúùkù 1:3) Nǹkan bí ìdá mẹ́fà nínú mẹ́wàá àwọn ìtàn tó wà nínú ìwé Ìhìn Rere Lúùkù ni kò sí nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere yòókù.

ÌBẸ̀RẸ̀ IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ RẸ̀

(Lúùkù 1:1–9:62)

Lẹ́yìn tí Lúùkù ti ṣàlàyé lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ nípa bí wọ́n ṣe bí Jòhánù Olùbatisí àti Jésù, ó sọ fún wa pé Jòhánù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún ìgbà ìjọba Tìbéríù Késárì, ìyẹn ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 29 Sànmánì Kristẹni. (Lúùkù 3:1, 2) Apá ìparí ọdún 29 Sànmánì Kristẹni ni Jòhánù ṣèrìbọmi fún Jésù. (Lúùkù 3:21, 22) Nígbà tó fi máa di ọdún 30 Sànmánì Kristẹni, ‘Jésù padà sí Gálílì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn nínú sínágọ́gù wọn.’—Lúùkù 4:14, 15.

Bí Jésù ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ àkọ́kọ́ ní ilẹ̀ Gálílì nìyẹn. Ó sọ fáwọn ogunlọ́gọ̀ náà pé: “Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú ńlá mìíràn pẹ̀lú.” (Lúùkù 4:43) Ó mú Símónì tó jẹ́ apẹja àtàwọn míì dání. Ó wá sọ pé: “Láti ìsinsìnyí lọ, ìwọ yóò máa mú àwọn ènìyàn láàyè.” (Lúùkù 5:1-11; Mát. 4:18, 19) Nígbà tí Jésù lọ wàásù ní Gálílì lẹ́ẹ̀kejì, àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá wà pẹ̀lú rẹ̀. (Lúùkù 8:1) Nígbà tó lọ síbẹ̀ lẹ́ẹ̀kẹta, ó rán àwọn àpọ́sítélì náà jáde láti “wàásù Ìjọba Ọlọ́run àti láti ṣe ìmúláradá.”—Lúùkù 9:1, 2.

Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:

1:35—Ǹjẹ́ ẹyin tó wà nínú Màríà ló di oyún Jésù? Gẹ́gẹ́ bí ìlérí Ọlọ́run, kí ọmọ tí Màríà máa bí tó lè jẹ́ àtọmọdọ́mọ àwọn baba ńlá Màríà lóòótọ́, ìyẹn Ábúráhámù, Júdà, àti Dáfídì, ẹyin tó wà nínú Màríà ló ní láti di oyún ọmọ tó máa bí náà. (Jẹ́n. 22:15, 18; 49:10; 2 Sám. 7:8, 16) Àmọ́, ńṣe ni Jèhófà lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti ta àtaré ìwàláàyè pípé Ọmọ Rẹ̀ sínú ilé ọlẹ̀ Màríà, ó sì lóyún. Ó jọ pé ẹ̀mí mímọ́ yìí ló mú àìpé èyíkéyìí tó lè wà nínú ẹyin Màríà kúrò, látìgbà tí ọlẹ̀ náà sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà ni ẹ̀mí mímọ́ ti ń dáàbò bo ọlẹ̀ náà lọ́wọ́ ìpalára èyíkéyìí tí àìpé Màríà lè ṣe fún ọlẹ̀ náà.

1:62—Ṣé lóòótọ́ ni Sekaráyà ò lè sọ̀rọ̀ tí etí rẹ̀ sì di? Rárá o. Ọ̀rọ̀ nìkan ni kò lè sọ. Lóòótọ́, àwọn èèyàn “fi àmì” béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ láti mọ orúkọ tó fẹ́ kí wọ́n sọ ọmọ náà, àmọ́ kì í ṣé nítorí pé etí Sekaráyà di. Ó jọ pé ó gbọ́ orúkọ tí ìyàwó rẹ̀ sọ pé ọmọ náà á máa jẹ́. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn tó kù tó wà níbẹ̀ ló ń fi àmì béèrè orúkọ tí Sekaráyà fẹ́ kí ọmọ rẹ̀ máa jẹ́. Bó ṣe jẹ́ pé ẹnu rẹ̀ tó là àti ahọ́n rẹ̀ tó tú nìkan ni Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ fi hàn pé etí Sekaráyà kò di.—Lúùkù 1:13, 18-20, 60-64.

2:1, 2—Báwo ni títọ́ka tí ẹsẹ Bíbélì yìí tọ́ka sí “ìforúkọsílẹ̀ àkọ́kọ́ yìí” ṣe jẹ́ ká mọ ìgbà tí wọ́n bí Jésù? Nígbà tí Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì wà lórí àlééfà, ó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ tó pàṣẹ pé káwọn èèyàn lọ forúkọ sílẹ̀. Ìgbà àkọ́kọ́ ni ọdún 2 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, èyí sì jẹ́ ìmúṣẹ ohun tó wà nínú Dáníẹ́lì 11:20. Èkejì sì wáyé lọ́dún 6 tàbí 7 Sànmánì Kristẹni. (Ìṣe 5:37) Kúírínọ́sì ni gómìnà Síríà láàárín ìgbà táwọn ìforúkọsílẹ̀ méjèèjì yìí wáyé. Nítorí náà, ó lè jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Kúírínọ́sì jẹ gómìnà Síríà. Bó ṣe jẹ́ pé ìforúkọsílẹ̀ àkọ́kọ́ ni Lúùkù tọ́ka sí jẹ́ ká mọ̀ pé ọdún 2 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n bí Jésù.

2:35—Kí ló túmọ̀ sí pé a ó fi “idà gígùn kan” gún ọkàn Màríà? Ohun tí èyí ń tọ́ka sí ni ìbànújẹ́ tó máa dorí Màríà kodò nígbà tó bá rí i pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn kò gba Jésù gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà náà. Ó sì tún ń tọ́ka sí ẹ̀dùn ọkàn ńlá tó máa bá Màríà nítorí ikú oró tí Jésù máa kú.—Jòh. 19:25.

9:27, 28—Kí nìdí tí Lúùkù fi sọ pé ìyípadà ológo náà ṣẹlẹ̀ ní “ọjọ́ mẹ́jọ” lẹ́yìn tí Jésù ṣèlérí fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé àwọn kan lára wọn “kì yóò tọ́ ikú wò rárá” títí wọn yóò fi rí Jésù tó ń bọ̀ nínú Ìjọba rẹ̀, nígbà tó jẹ́ pé Mátíù àti Máàkù sọ pé “ọjọ́ mẹ́fà lẹ́yìn náà” ni? (Mát. 17:1; Máàkù 9:2) Ó jọ pé, ńṣe ni Lúùkù ka ọjọ́ méjì míì mọ́ ọn, ìyẹn ọjọ́ tí Jésù ṣèlérí yẹn àti ọjọ́ tí ìlérí yẹn nímùúṣẹ.

9:49, 50—Kí nìdí tí Jésù kò fi ṣèdíwọ́ fún ọkùnrin kan tó ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkùnrin náà kì í tẹ̀ lé Jésù? Ìdí tí Jésù kò fi ṣèdíwọ́ fún ọkùnrin náà ni pé wọn ò tíì dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀ nígbà yẹn. Fún ìdí yìí, kì í ṣe dandan pé kí ọkùnrin yẹn máa tẹ̀ lé Jésù kó tó lè nígbàgbọ́ nínú orúkọ Jésù kó sì lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.—Máàkù 9:38-40.

Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:

1:32, 33; 2:19, 51. Màríà fi àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àtàwọn ọ̀rọ̀ tó mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ sọ́kàn. Ṣé àwa náà máa ń fàwọn àsọtẹ́lẹ̀ Jésù nípa “ìparí ètò àwọn nǹkan” sọ́kàn? Ṣé a sì máa ń fàwọn nǹkan tó sọ wéra pẹ̀lú àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí?—Mát. 24:3.

2:37. Ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Ánà ni pé, ká máa bá a nìṣó ní sísin Jèhófà láìyẹsẹ̀, ká máa ní “ìforítì nínú àdúrà,” ká má sì máa kọ “ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀,” ìyẹn àwọn ìpàdé Kristẹni.—Róòmù 12:12; Héb. 10:24, 25.

2:41-50. Ìjọsìn Jèhófà ni Jósẹ́fù fi ṣohun àkọ́kọ́ nígbèésí ayé rẹ̀, ó bìkítà fún ìdílé rẹ̀ nípa tara àti nípa tẹ̀mí, ó sì tipa báyìí fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ fáwọn olórí ìdílé.

4:4. A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọjọ́ kan lọ láìjẹ́ pé a ṣàyẹ̀wò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

6:40. Olùkọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Òun náà gbọ́dọ̀ máa ṣohun tó ń kọ́ àwọn ẹlòmíì pé kí wọ́n ṣe.

8:15. Ká bàa lè ‘di Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú ṣinṣin, ká sì so èso pẹ̀lú ìfaradà,’ a gbọ́dọ̀ lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ká mọyì rẹ̀, ká sì fi ara wa fún un pátápátá. Bá a bá ń ka Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde tó dá lórí Bíbélì, ó yẹ ká máa ṣàṣàrò lórí àwọn nǹkan tá à ń kà, ká sì máa gbàdúrà.

IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ TÍ JÉSÙ ṢE KẸ́YÌN

(Lúùkù 10:1–24:53)

Jésù rán àwọn àádọ́rin mìíràn ṣáájú rẹ̀ lọ sáwọn ìlú ńlá àtàwọn ibì kan ní Jùdíà. (Lúùkù 10:1) Ó rin ìrìn àjò “láti ìlú ńlá dé ìlú ńlá àti láti abúlé dé abúlé, ó ń kọ́ni.”—Lúùkù 13:22.

Nígbà tí àjọyọ̀ Ìrékọjá ti ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ku ọjọ́ márùn-ún, Jésù gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ Jerúsálẹ́mù. Ṣáájú ìgbà yẹn, ó ti sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ọmọ ènìyàn gbọ́dọ̀ fara gba ọ̀pọ̀ ìjìyà, kí àwọn àgbà ọkùnrin àti àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin sì kọ̀ ọ́ tì, kí a sì pa á, kí a sì gbé e dìde ní ọjọ́ kẹta.” (Lúùkù 9:22, 44) Àkókò ti tó báyìí fún ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ tó sọ yẹn.

Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:

10:18—Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ fáwọn àádọ́rin ọmọ ẹ̀yìn náà pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí rí Sátánì tí ó ti já bọ́ ná bí mànàmáná láti ọ̀run? Kì í ṣohun tí Jésù ń sọ ni pé wọ́n ti lé Sátánì kúrò lọ́run nígbà yẹn o. Kété lẹ́yìn tí Ọlọ́run fi Kristi jẹ Ọba ní ọ̀run lọ́dún 1914 ni wọ́n tó ṣẹ̀ṣẹ̀ lé e kúrò lọ́run. (Ìṣí. 12:1-10) Lóòótọ́, tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, àwa ò lè fi gbogbo ẹnu sọ ọ́ bí ìgbà tó jẹ́ pé ó ti ṣẹlẹ̀, àmọ́ ó jọ pé ńṣe ni Jésù sọ̀rọ̀ lọ́nà yìí láti fi hàn pé ohun tó sọ yẹn kò ní ṣàìṣẹ.

14:26—Lọ́nà wo ni àwọn Kristẹni fi gbọ́dọ̀ “kórìíra” àwọn ìbátan wọn? Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà, “ìkórìíra” lè túmọ̀ sí pé kéèyàn fẹ́ràn ẹnì kan tàbí ohun kan ju òmíràn lọ. (Jẹ́n. 29:30, 31) Ohun tó túmọ̀ sí pé káwọn Kristẹni “kórìíra” àwọn ìbátan wọn ni pé, kí wọ́n fẹ́ràn Jésù ju àwọn ìbátan wọn lọ.—Mát. 10:37.

17:34-37—Àwọn wo ni “idì,” kí sì ni “òkú” táwọn idì kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ̀? Àwọn tí a ‘mú lọ,’ tàbí tí a dá nídè la fi wé àwọn ẹyẹ idì tí wọ́n máa ń ríran jìnnà. “Òkú” tí wọ́n kóra jọ pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀ ni Kristi tòótọ́ náà nígbà wíwàníhìn-ín rẹ̀ tí a ò lè fojú rí, àti oúnjẹ tẹ̀mí tí Jèhófà ń pèsè fún wọn.—Mát. 24:28.

22:44—Kí nìdí tí Jésù fi ní ìrora ọkàn tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Ó tó ìdí bíi mélòó kan tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀. Jésù ń ronú ipa tí ikú ọ̀daràn tó máa kú máa ní lórí Jèhófà Ọlọ́run àti orúkọ Jèhófà. Ìyẹn nìkan kọ́ o, Jésù mọ̀ dájú pé ìyè ayérayé òun àti ọjọ́ ọ̀la gbogbo ìran èèyàn sinmi lórí jíjẹ́ tóun bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà.

23:44—Ǹjẹ́ òṣùpá ló ṣíji bo oòrùn tó sì mú kí òkùnkùn ṣú fún wákàtí mẹ́ta? Rárá o. Àkókò tí oṣù bá lé sójú ọ̀run nìkan ni òṣùpá máa ń ṣíji bo oòrùn. Kì í ṣe àkókò tí òṣùpá bá ti yọ tán gẹ́gẹ́ bó ṣe máa ń rí nígbà àjọyọ̀ Ìrékọjá. Òkùnkùn tó ṣú lọ́jọ́ tí Jésù kú jẹ́ iṣẹ́ ìyanu látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.

Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:

11:1-4. Tá a bá fi ìtọ́ni yìí wéra pẹ̀lú èyí tó wà nínú àdúrà àwòkọ́ṣe tí Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nínú Ìwàásù Lórí Òkè ní nǹkan bí ọdún kan àbọ̀ sẹ́yìn, a óò rí i pé ó yàtọ̀ díẹ̀. Ohun tí èyí ń fi hàn ni pé, kò yẹ ká kàn máa ṣe àtúnwí àwọn ọ̀rọ̀ kan náà ṣáá tá a bá ń gbàdúrà.—Mát. 6:9-13.

11:5, 13. Lóòótọ́, Jèhófà ti múra tán láti gbọ́ àdúrà wa, àmọ́ àwa náà gbọ́dọ̀ máa tẹra mọ́ àdúrà gbígbà.—1 Jòh. 5:14.

11:27, 28. Jíjẹ́ olóòótọ́ àti ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ló lè fún èèyàn ní ayọ̀ tòótọ́, kì í ṣe àjọṣe pẹ̀lú ìdílé ẹni tàbí kíkó ọ̀rọ̀ jọ.

11:41. Tá a bá fẹ́ fúnni ní ẹ̀bùn àánú, ìfẹ́ ló yẹ kó sún wa ṣe é, ó sì yẹ kó wá láti ọkàn wa.

12:47, 48. Béèyàn bá ní ojúṣe tó pọ̀ àmọ́ tó kọ̀ tí kò bójú tó o, irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóò gba ìdálẹ́bi ju ẹni tí kò mọ ojúṣe rẹ̀ dáadáa tàbí tí kò tiẹ̀ mọ̀ ọ́n rárá lọ.

14:28, 29. Kò yẹ ká máa ṣe ju agbára wa lọ tó bá dọ̀rọ̀ ìnáwó.

22:36-38. Kì í ṣe pé Jésù ń sọ fáwọn ọmọ ẹyìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa lo àwọn ohun ìjà láti dáàbò bo ara wọn tàbí kí wọ́n máa fi gbèjà ara wọn o. Kàkà bẹ́ẹ̀, mímú tí wọ́n mú idà lọ́wọ́ lálẹ́ ọjọ́ tí Júdásì da Jésù mú kó ṣeé ṣe fún Jésù láti kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan. Ẹ̀kọ́ náà ni pé: “gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.”—Mát. 26:52.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Jósẹ́fù fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

Lúùkù ló ṣàkọsílẹ̀ tó kún rẹ́rẹ́ jù lọ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti ìgbésí ayé Jésù