Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bá a Ṣe Mú Ìhìn Rere Dé Orí Àwọn Òkè Ńlá Nílẹ̀ Bòlífíà

Bá a Ṣe Mú Ìhìn Rere Dé Orí Àwọn Òkè Ńlá Nílẹ̀ Bòlífíà

Bá a Ṣe Mú Ìhìn Rere Dé Orí Àwọn Òkè Ńlá Nílẹ̀ Bòlífíà

ÀWA méjìdínlógún la sùn sórí ilẹ̀ eléruku, tá à ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ nínú àpò tá a wọ̀ sùn. À ń gbọ́ bí ọ̀yamùúmùú òjò ṣe ń rọ̀ sórí páànù òrùlé ibi tá a wà. Ńṣe ni inú ibi tá a wà yìí rí wúruwùru, ó sì jọ pé àwọn èèyàn ò gbé ibẹ̀ rí.

Kí lohun táwa méjìdínlógún lọ ṣe ní ìlú yìí? Ohun tó gbé wa débẹ̀ ni pé a fẹ́ ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù pé, ká wàásù ìhìn rere “dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8; Mát. 24:14) Ìpínlẹ̀ kan tó jẹ́ àdádó lórí àwọn òkè ńlá ilẹ̀ Bòlífíà la ti lọ wàásù.

Ìṣòro Tá a Dojú Kọ Ká Tó Débẹ̀

Ìṣòro àkọ́kọ́ tó dojú kọ wa ni bá a ṣe máa débi tá à ń lọ. Ohun tá a gbọ́ ni pé kò sẹ́ni tó lè sọ ìgbà táwọn ọkọ̀ tó ń ná ibẹ̀ máa wá. Nígbà tí ọkọ̀ tó máa gbé wa dé, a rí i pé ó kéré, kò sì lè gba gbogbo wa. Bó ṣe jẹ́ pé orí ìdúró làwọn kan wà nìyẹn, títí tá a fi débi tá à ń lọ.

Ìpinnu wa ni pé a fẹ́ lọ wàásù ní àwọn abúlé tó wà lórí àwọn òkè ńlá nílẹ̀ Bòlífíà. Nígbà tá a bọ́ sílẹ̀ nínú ọkọ̀, a gbé àwọn ẹrù wa, a sì rọra ń rìn lọ́wọ̀ọ̀wọ́ gba ọ̀nà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ kan lórí àwọn òkè ńlá náà.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn abúlé náà kò fi bẹ́ẹ̀ tóbi, gátagàta tí wọ́n kọ́ àwọn ilé tó wà níbẹ̀ mú kó gba ọ̀pọ̀ wákàtí ká tó lè kárí abúlé kọ̀ọ̀kan. Ibi yòówù ká rìn dé, ńṣe ló tún máa dà bíi pé ilé kan ṣì wà ní òkèèrè. Nígbà míì, a máa ń ṣìnà nítorí ọ̀nà ojúgbó tó rí kọ́lọkọ̀lọ.

“Kí Ló Dé Tẹ́ Ò Fi Wá Ṣáájú Àkókò Yìí?”

Ìrìn ọ̀nà jíjìn tá a rìn wú obìnrin kan lórí débi pé ó gbà wá láyè láti lo ilé ìdáná rẹ̀ àti igi ìdáná rẹ̀ láti se oúnjẹ ọ̀sán wa. Lẹ́yìn tá a ṣàlàyé fún ọkùnrin kan nípa ipò táwọn òkú wà, ó ní, “Kí ló dé tẹ́ ò fi wá ṣáájú àkókò yìí?” Ọ̀rọ̀ tá a sọ fún un wọ̀ ọ́ lọ́kàn débi pé nígbà tá a kúrò ní abúlé tó ń gbé, ńṣe ló tẹ̀ lé wa tó sì ń béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè sí i. A tún pàdé ọkùnrin kan tó jẹ́ pé kò gbọ́ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí láyé ẹ̀. Ó nífẹ̀ẹ́ sáwọn ìwé wa gan-an ni. Ó dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ wa fún wíwá tá a wá, ó sì fún wa ní kọ́kọ́rọ́ abà kan tá a lè sùn mọ́jú.

Lálẹ́ ọjọ́ kan, níbi tí òkùnkùn ṣú dé, a ò mọ̀ pé ilé àwọn kòkòrò dúdú ńlá kan báyìí la pàgọ́ sí. Kò pẹ́ rárá táwọn kòkòrò yìí fi bẹ̀rẹ̀ sí í ta wá, ó sì ti rẹ̀ wá tẹnutẹnu, a ò lè ṣí àgọ́ wa kúrò níbẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ yẹn. Àmọ́ a dúpẹ́ pé nígbà tó ṣe díẹ̀, àwọn kòkòrò yìí ò tiẹ̀ dá sí wa mọ́.

Nígbà tá a kọ́kọ́ sùn sílẹ̀, kò rọrùn rárá torí ńṣe ni gbogbo ara ń ro wá, àmọ́ nígbà tí ilẹ̀ máa fi mọ́, ó ti mọ́ wa lára. Láàárọ̀ ọjọ́ kejì, ńṣe ni gbogbo ara tó ń ro wá dàwátì nígbà tá a wo ọ̀ọ́kán tá a sì rí àwọn àfonífojì kan tẹ́ni kẹ́ni ò tíì dé rí, tí kùrukùru rọra ń wọ́ lọ lójú sánmà lápá ibi táwọn àfonífojì náà wà. A tún rí àwọn òkè ńlá kan lọ́ọ̀ọ́kán tí yìnyín bo orí wọn, èyí sì mú kí wọ́n lẹ́wà gan-an. Ìró odò tó ń ṣàn àti orin àwọn ẹyẹ la kàn ń gbọ́.

Lẹ́yìn tá a wẹ̀ nínú odò náà tán, gbogbo wa ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan pa pọ̀, a sì jẹun àárọ̀. Lẹ́yìn náà, a rọra rìn gba ibi òkè kan, títí tá a fi já sáwọn abúlé míì tó jìnnà gan-an. Ìsapá tá a ṣe láti gun àwọn òkè yẹn tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ìyá àgbàlagbà kan tá a wàásù fún bú sẹ́kún nígbà tó gbọ́ pé orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà wà nínú Bíbélì. Ó yà á lẹ́nu gan-an ni. Ó ti wá ṣeé ṣe fún ìyá náà láti máa lo orúkọ Ọlọ́run nínú àdúrà rẹ̀ báyìí!

Bàbá àgbàlagbà kan sọ pé ó ní láti jẹ́ pé Ọlọ́run ti rántí òun, bó ṣe mórin bẹnu nìyẹn, tó ń kọrin pé àwọn áńgẹ́lì ló rán wa wá. Ọkùnrin kan tí àìsàn ò jẹ́ kó lè jáde nílé sọ fún wa pé kò sẹ́nì kankan lára àwọn ará abúlé yẹn tó tiẹ̀ wá wo òun. Ó yà á lẹ́nu gan-an nígbà tó gbọ́ pé iyànníyàn ìlú La Paz la ti wá. Bákan náà, orí ọkùnrin kan wú gan-an pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń lọ bá àwọn èèyàn nínú ilé wọn láti wàásù fún wọn, nígbà tó jẹ́ pé ńṣe làwọn ìsìn tó kù máa ń lu aago láti fi pe àwọn èèyàn wá sí ṣọ́ọ̀ṣì wọn.

Kò sí ilé kankan ní àgbègbè yẹn tó ní iná mànàmáná, nítorí èyí, tó bá ti di pé ọjọ́ ti ń pofírí làwọn èèyàn ti máa ń lọ sùn, ìgbà tí oòrùn àárọ̀ bá sì yọ ni wọ́n á tó jí. Nítorí náà, aago mẹ́fà àárọ̀ la ti gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ka lè bá àwọn èèyàn nílé. Tá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, èyí tó pọ̀ jù lára wọn á ti lọ sóko. Nígbà tó yá tá a lọ wàásù fáwọn tó ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ lóko, ọ̀pọ̀ lára wọn ló dá màlúù tí wọ́n fi ń túlẹ̀ dúró tí wọ́n sì gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a sọ fún wọn. Bákan náà, ọ̀pọ̀ lára àwọn tá a bá nílé ni wọn tẹ́ awọ àgùntàn sílẹ̀ fún wa láti jókòó lé, tí wọ́n sì pe àwọn ìdílé wọn jọ pé kí wọ́n wá gbọ́ ohun tá a fẹ́ sọ. Àwọn kan tí wọ́n jẹ́ àgbẹ̀ fún wa ní àwọn àpò àgbàdo ńlá láti fi ìmoore wọn hàn fún àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a fún wọn.

“Ẹ Ò Gbàgbé Mi”

Ó dájú pé tá a bá fẹ́ káwọn èèyàn tẹ̀ síwájú nínú ìmọ̀ Bíbélì, ohun tá a máa ṣe ju pé ká kàn ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn lẹ́ẹ̀kan lọ. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ará abúlé yẹn ló bẹ̀ wá pé ká padà wá kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí i. Nítorí èyí, ó tó ìgbà mélòó kan tá a padà lọ sí àgbègbè yìí nílẹ̀ Bòlífíà.

Nígbà tá a padà bẹ obìnrin àgbàlagbà kan wò, inú ẹ̀ dùn gan-an pé a padà wá. Ó ní: “Bí ọmọ ni gbogbo yín ṣe jẹ́ fún mi. Ẹ ò gbàgbé mi.” Ọkùnrin kan dúpẹ́ lọ́wọ́ wa fún iṣẹ́ tá à ń ṣe, ó sì sọ pé ilé òun ni ká dé sí tá a bá tún padà wá ní ọjọ́ mìíràn. Ohun tó dà bí èrè tó tóbi jù lọ tá a rí nínú gbogbo ìsapá wa ni gbígbọ́ tá a gbọ́ pé obìnrin kan tá a bá sọ̀rọ̀ nígbà kan tá a lọ wàásù ní abúlé yẹn ti ṣí lọ sáàárín ìlú, ó sì ti ń wàásù ìhìn rere níbẹ̀.

Nígbà ìrìn-àjò wa àkọ́kọ́, ọjọ́ tá a fẹ́ padà sílé ni epo kẹrosíìnì tá a fi máa ń tan sítóòfù wa tán, oúnjẹ wa pàápàá sì ti fẹ́ẹ̀ tán. A wá kó igi jọ, a dáná, a sì se gbogbo oúnjẹ wa tó kù. Lẹ́yìn náà, a wá bẹ̀rẹ̀ sí í fẹsẹ̀ rìn lọ. Ọ̀pọ̀ kìlómítà ni ibi tá a wà sí ibi tá a tí máa lọ wọ ọkọ̀. Nígbà tá a fi máa débi tá a ti máa wọ ọkọ̀, ilẹ̀ ti ṣú.

A Padà Sílé

Ìṣòro tó dojú kọ wá nígbà tá à ń lọ sílé ni ọkọ̀ wa tó dẹnu kọlẹ̀ lójú ọ̀nà. Àmọ́ kò pẹ́ tá a fi rí ọkọ̀ ńlá kan wọ̀, ńṣe làwọn èèyàn há ara wọn mọ́ ẹ̀yìn ọkọ̀ náà gádígádí. A sì lo àǹfààní yìí láti wàásù fún àwọn tá a jọ wà nínú ọkọ̀ tí wọ́n fẹ́ mọ ìdí tá a fi wá sí àgbègbè yẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé onítìjú èèyàn ni wọ́n, wọ́n kóni mọ́ra wọ́n sì lọ́yàyà.

Lẹ́yìn wákàtí mẹ́sàn-án tá a ti wà lẹ́yìn ọkọ̀ yẹn, a délé. Ara wa ti rin gbingbin, bẹ́ẹ̀ ni òtútù ń mú wa burúkú-burúkú. Àmọ́, ìrìn-àjò wa yìí ò já sásán. Bá a ṣe ń bọ̀ lọ́nà nínú ọkọ̀ yẹn, a lo àǹfààní yẹn láti bá obìnrin kan tó ń gbé àárín ìlú sọ̀rọ̀, a sì ṣètò láti lọ máa kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Àǹfààní ńlá gbáà ló jẹ́ pé a lọ wàásù fáwọn èèyàn tó ń gbé láwọn ibi àdádó yẹn. A ti wàásù ní abúlé mẹ́rin àti ọ̀pọ̀ eréko. Ńṣe lèyí ń mú ká rántí ohun tí Bíbélì sọ pé: “Ẹsẹ̀ ẹni tí ń mú ìhìn rere wá mà dára rèǹtè-rente lórí àwọn òkè ńlá o, ẹni tí ń kéde àlàáfíà fáyé gbọ́, ẹni tí ń mú ìhìn rere ohun tí ó dára jù wá, ẹni tí ń kéde ìgbàlà fáyé gbọ́.”—Aísá. 52:7; Róòmù 10:15.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Wọ́n múra tán láti wàásù Ìhìn rere