Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Ń gbọ́ Igbe Wa Fún Ìrànlọ́wọ́

Jèhófà Ń gbọ́ Igbe Wa Fún Ìrànlọ́wọ́

Jèhófà Ń gbọ́ Igbe Wa Fún Ìrànlọ́wọ́

“Ojú Jèhófà ń bẹ lọ́dọ̀ àwọn olódodo, Etí rẹ̀ sì ṣí sí igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́.”—SM. 34:15.

1, 2. (a) Báwo ni nǹkan ṣe rí lára ọ̀pọ̀ èèyàn lóde òní? (b) Kí nìdí tí èyí kò fi yà wá lẹ́nu?

 ǸJẸ́ o wà nínú ìpọ́njú? Má bọkàn jẹ́, àwọn míì náà wà nínú ìpọ́njú bíi tiẹ̀. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ni kòókòó jàn-ánjàn-án nítorí àtijẹ-àtimu nínú ayé burúkú yìí ń kó ìnira bá. Gbogbo èyí tiẹ̀ ti sú àwọn míì. Ṣe ni ọ̀rọ̀ wọn dà bíi ti Dáfídì, ẹni tó sọ pé: “Ara mi ti kú tipiri, mo sì ti di ẹni ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ní ìwọ̀n tí ó dé góńgó; mo ti ké ramúramù nítorí ìkérora ọkàn-àyà mi. Ọkàn-àyà mi lù kì-kì-kì, agbára mi ti fi mí sílẹ̀, pẹ̀lúpẹ̀lù, ìmọ́lẹ̀ ojú mi kò sí lọ́dọ̀ mi.”—Sm. 38:8, 10.

2 Kò ya àwa Kristẹni lẹ́nu pé ìpọ́njú ń bá aráyé fínra lóde òní. Nítorí a mọ̀ pé “ìroragógó wàhálà” jẹ́ ara àwọn àmì tí Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò fi hàn pé Jésù ti wà níhìn-ín. (Máàkù 13:8; Mát. 24:3) Ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì tá a tú sí “ìroragógó wàhálà” nínú ẹsẹ Bíbélì yìí ń tọ́ka sí ìrora tí aláboyún máa ń ní nígbà tó bá ń rọbí. Ẹ ò rí i bí ọ̀rọ̀ tí Bíbélì fi ṣàpèjúwe ìyà tó ń jẹ ọmọ aráyé ní “àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” tá à ń gbé yìí ti bá a mu tó!—2 Tím. 3:1.

Jèhófà Mọ Gbogbo Ìpọ́njú Wa

3. Kí làwọn èèyàn Ọlọ́run mọ̀ dáadáa?

3 Àwa èèyàn Jèhófà mọ̀ dáadáa pé àwọn ò bọ́ nínú ìpọ́njú ayé yìí àti pé ipò àwọn nǹkan tiẹ̀ tún lè burú jù báyìí lọ pàápàá. Yàtọ̀ sí ìṣòro tó ń bá gbogbo aráyé fínra, àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run tún ní “Elénìní” kan, ìyẹn Èṣù, tó ń gbógun lójú méjèèjì láti lè jẹ́ kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa rì. (1 Pét. 5:8) Gbogbo èyí lè jẹ́ kó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwa náà bó ṣe ṣe Dáfídì nígbà tó sọ pé: “Àní ẹ̀gàn ti ba ọkàn-àyà mi jẹ́, ọgbẹ́ náà sì jẹ́ aláìṣeéwòsàn. Mo sì ń retí ṣáá láti rí ẹnì kan tí yóò fi ìbánikẹ́dùn hàn, ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kankan; àti láti rí àwọn olùtùnú, ṣùgbọ́n n kò rí ẹnì kankan.”—Sm. 69:20.

4. Kí ló máa ń tù wá nínú tá a bá wà nínú ìpọ́njú?

4 Ṣé ohun tí Dáfídì ń sọ ni pé kò sí ìrètí kankan fóun mọ́? Ó tì o. Wo ohun tó sọ lẹ́yìn èyí, ó ní: “Jèhófà ń fetí sí àwọn òtòṣì, ní tòótọ́, kì yóò sì tẹ́ńbẹ́lú àwọn ẹlẹ́wọ̀n tirẹ̀,” ìyẹn àwọn èèyàn rẹ̀ tí ìpọ́njú dè mọ́lẹ̀. (Sm. 69:33) Nígbà míì, ó lè máa ṣe wá bíi pé ìpọ́njú gbé wa dè bí ìgbà téèyàn wà lẹ́wọ̀n. Ó tiẹ̀ lè dà bíi pé àwọn èèyàn ò mọ bí ìṣòro wa ṣe le tó. Wọ́n sì lè má mọ̀ ọ́n lóòótọ́. Àmọ́ a lè rí ìtùnú gbà látinú mímọ̀ pé Jèhófà mọ gbogbo ìpọ́njú tó ń bá wa ní àmọ̀dunjú, àní bí ìyẹn náà ṣe tu Dáfídì nínú.—Sm. 34:15.

5. Kí lohun tó dá Sólómọ́nì Ọba lójú?

5 Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì sọ̀rọ̀ nípa kókó yìí nígbà ìyàsímímọ́ tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù. (Ka 2 Kíróníkà 6:29-31.) Ó bẹ Jèhófà pé kó gbọ́ àdúrà olúkúlùkù olóòótọ́ ọkàn tó bá ké pè é nítorí “ìyọnu àjàkálẹ̀ tirẹ̀ àti ìrora tirẹ̀.” Ojú wo ni Ọlọ́run yóò fi wo àdúrà àwọn tó wà nínú ìpọ́njú yìí? Sólómọ́nì fi hàn dájú pé Ọlọ́run máa gbọ́ àdúrà wọn, á sì wá nǹkan ṣe sí ìṣòro wọn. Nítorí pé Jèhófà mọ ohun tó wà nínú “ọkàn-àyà ọmọ aráyé ní àmọ̀dunjú.”

6. Báwo la ò ṣe ní jẹ́ kí àníyàn borí wa, kí sì nìdí rẹ̀?

6 Àwa náà lè gbàdúrà sí Jèhófà nípa gbogbo ‘ìyọnu àti ìrora wa.’ Ó yẹ kí mímọ̀ tá a mọ̀ pé Jèhófà mọ gbogbo ìpọ́njú wa àti pé ó bìkítà nípa wa máa tù wá nínú. Ohun tí àpọ́sítélì Pétérù sọ sì fi hàn pé Jèhófà bìkítà lóòótọ́, ó ní: “[Ẹ] kó gbogbo àníyàn yín lé e, nítorí ó bìkítà fún yín.” (1 Pét. 5:7) Jèhófà kì í fọwọ́ kékeré mú àwọn ìṣòro wa. Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sọ pé: “Kì í ha ṣe ológoṣẹ́ méjì ni a ń tà ní ẹyọ owó kan tí ìníyelórí rẹ̀ kéré? Síbẹ̀, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò jábọ́ lulẹ̀ láìjẹ́ pé Baba yín mọ̀. Ṣùgbọ́n gbogbo irun orí yín gan-an ni a ti kà. Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù: ẹ níye lórí púpọ̀ ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.”—Mát. 10:29-31.

Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà

7. Ìrànlọ́wọ́ wo ni Bíbélì mú kó dá wa lójú pé a máa rí nígbà ìṣòro?

7 Ó dá wa lójú pé Jèhófà lágbára láti ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá wà nínú ìpọ́njú àti pé ó fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ibi ìsádi àti okun fún wa, ìrànlọ́wọ́ tí a lè rí tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn nígbà wàhálà.” (Sm. 34:15-18; 46:1) Ọ̀nà wo ni Ọlọ́run ń gbà ràn wá lọ́wọ́? Wo ohun tí 1 Kọ́ríńtì 10:13 sọ, ó ní: “Ọlọ́run jẹ́ olùṣòtítọ́, kì yóò sì jẹ́ kí a dẹ yín wò ré kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra, ṣùgbọ́n pa pọ̀ pẹ̀lú ìdẹwò náà, òun yóò tún ṣe ọ̀nà àbájáde kí ẹ lè fara dà á.” Jèhófà lè jẹ́ káwọn nǹkan kan ṣẹlẹ̀ tó máa jẹ́ ká bọ́ nínú ìṣòro wa, tàbí kó fún wa lókun tá a ó fi fara dà á. Èyí ó wù kó jẹ́, ìrànlọ́wọ́ Jèhófà ni.

8. Kí la lè ṣe ká lè rí ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run gbà?

8 Kí la lè ṣe ká bàa lè jàǹfààní ìrànlọ́wọ́ Jèhófà yìí? Rántí ohun tí Pétérù ní ká ṣe, ó ní: “[Ẹ] kó gbogbo àníyàn yín lé e.” Èyí tó túmọ̀ sí pé ńṣe ni ká fa gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìṣòro àti àníyàn wa lé Jèhófà lọ́wọ́. A óò ní máa dààmú nípa ìṣòro wa, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe la óò gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé yóò bá wa yanjú ìṣòro wa. (Mát. 6:25-32) Kéèyàn tó lè nírú ìgbẹ́kẹ̀lé yẹn, onítọ̀hún gbọ́dọ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, kó má sì gbára lé ọgbọ́n àti òye tirẹ̀. Tá a bá rẹ ara wa sílẹ̀ “lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọ́run,” ńṣe là ń fi hàn pé a ò lè dá ohunkóhun ṣe fúnra wa. (Ka 1 Pétérù 5:6.) Èyí á sì jẹ́ ká lè fara da ohunkóhun tí Ọlọ́run bá gbà pé kó ṣẹlẹ̀ sí wa. Ó lè máa wù wá pé ká bọ́ nínú ìṣòro wa lójú ẹsẹ̀, àmọ́ ó dá wa lójú pé Jèhófà mọ ìgbà tó yẹ kó yanjú ìṣòro wa àti bó ṣe máa yanjú rẹ̀.—Sm. 54:7; Aísá. 41:10.

9. Irú ẹrù ìnira wo ni Dáfídì jù sọ́dọ̀ Jèhófà?

9 Rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ nínú ìwé Sáàmù 55:22, pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró. Kì yóò jẹ́ kí olódodo ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.” Inú ìpọ́njú tó ga gan-an ni Dáfídì wà nígbà tó sọ ọ̀rọ̀ yìí. (Sm. 55:4) Ó ní láti jẹ́ pé ìgbà tí Ábúsálómù dìtẹ̀ láti gbàjọba lọ́wọ́ Dáfídì bàbá rẹ̀ ni Dáfídì kọ sáàmù yìí. Áhítófẹ́lì tó jẹ́ agbani-nímọ̀ràn tí Dáfídì fọkàn tán jù bá wọn lọ́wọ́ sí ọ̀tẹ̀ náà. Ńṣe ni Dáfídì ní láti sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù fún ẹ̀mí rẹ̀. (2 Sám. 15:12-14) Àmọ́ bí ìpọ́njú Dáfídì ṣe ga tó yìí, Ọlọ́run ló gbẹ́kẹ̀ lé, Ọlọ́run ò sì já a kulẹ̀.

10. Kí la ní láti ṣe tá a bá wà nínú ìpọ́njú?

10 Ó ṣe pàtàkì pé káwa náà máa gbàdúrà sí Jèhófà nípa ìpọ́njú èyíkéyìí tá a bá ní, bí Dáfídì náà ti ṣe. Ẹ jẹ́ ká wo ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún wa nípa àdúrà gbígbà nígbà tá a bá wà nínú ìpọ́njú. (Ka Fílípì 4:6, 7.) Kí ló máa jẹ́ àbájáde irú àdúrà àtọkànwá bẹ́ẹ̀? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà [wa] àti agbára èrò orí [wa] nípasẹ̀ Kristi Jésù.”

11. Báwo ni “àlàáfíà Ọlọ́run” ṣe máa ń ṣọ́ ọkàn-àyà wa àti agbára èrò orí wa?

11 Ṣé tá a bá ṣáà ti gbàdúrà, ìṣòro wa máa tán? Ó ṣeé ṣe kó tán. Àmọ́, ó yẹ ká mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń dáhùn àdúrà wa lọ́nà tá à ń retí pé kó gbà dáhùn rẹ̀. Síbẹ̀, àdúrà máa ń jẹ́ ká lè ronú lọ́nà tó tọ́, tí ìṣòro wa ò fi ní pin wá lẹ́mìí. “Àlàáfíà Ọlọ́run” á máa pẹ̀tù sí wa lọ́kàn nígbà tí ìṣòro bá kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa. Bí ìgbà tí wọ́n kó àwùjọ àwọn ọmọ ogun sí ẹnu bodè ìlú láti dàábò bo ìlú náà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá, bẹ́ẹ̀ náà ni “àlàáfíà Ọlọ́run” ṣe máa ń ṣọ́ ọkàn-àyà wa àti agbára èrò orí wa. Yóò sì tún jẹ́ ká lè borí iyèméjì, ìbẹ̀rù àti èròkérò tó lè máa sọ sí wa lọ́kàn, ká má bàa ṣìwà hù.—Sm. 145:18.

12. Ṣàpèjúwe bí ẹnì kan ṣe lè ní àlàáfíà ọkàn.

12 Báwo la ṣe lè ní àlàáfíà ọkàn nígbà tá a bá wà nínú ìpọ́njú? Wo àpèjúwe kan tó ṣeé ṣe kó bá ipò wa mu. Òṣìṣẹ́ kan lè máa ṣiṣẹ́ lábẹ́ ọ̀gá ilé iṣẹ́ kan tó máa ń kanra mọ́ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ rẹ̀. Àmọ́ òṣìṣẹ́ yìí wá láǹfààní láti sọ ohun tójú rẹ̀ ń rí fún ẹni tó ni ilé iṣẹ́ náà, tó jẹ́ èèyàn dáadáa, tó sì máa ń gba tàwọn èèyàn rò. Ẹni tó ni ilé iṣẹ́ náà sì wá fi yé òṣìṣẹ́ yìí pé òun mọ gbogbo ohun tójú ẹ̀ ń rí àti pé òun máa tó yọ ọ̀gá náà kúrò. Báwo lọ̀rọ̀ náà ṣe máa rí lára òṣìṣẹ́ yìí? Tó bá gba ìlérí tí ẹni tó ni ilé iṣẹ́ náà ṣe gbọ́, tó sì mọ ohun tó máa tó ṣẹlẹ̀, á lè máa rọ́jú bá iṣẹ́ náà lọ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ṣì máa wà lábẹ́ ọ̀gá oníkanra yìí fúngbà díẹ̀ sí i. Bákan náà, a mọ̀ pé Jèhófà náà mọ ohun tójú wa ń rí nínú ayé yìí, ó jẹ́ kó dá wa lójú pé láìpẹ́, “olùṣàkóso ayé yìí ni a óò lé jáde.” (Jòh. 12:31) Èyí mà tù wá nínú gan-an o!

13. Yàtọ̀ sí pé ká gbàdúrà, kí ló tún yẹ ká ṣe?

13 Ṣé ohun tí ibí yìí ń sọ ni pé ká ṣáà ti máa gbàdúrà sí Jèhófà nípa ìṣòro wa láìṣe ohunkóhun mìíràn? Rárá o. A ní láti ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. A ní láti ṣiṣẹ́ lórí àdúrà tá a gbà. Nígbà tí Sọ́ọ̀lù Ọba rán àwọn kan kí wọ́n lọ pa Dáfídì nílé, Dáfídì gbàdúrà pé: “Dá mi nídè lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, ìwọ Ọlọ́run mi; kí o dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn tí ń dìde sí mi. Dá mi nídè lọ́wọ́ àwọn aṣenilọ́ṣẹ́, kí o sì gbà mí là lọ́wọ́ àwọn ajẹ̀bi ẹ̀jẹ̀.” (Sm. 59:1, 2) Yàtọ̀ sí pé Dáfídì gbàdúrà, ó tún tẹ̀ lé ìmọ̀ràn aya rẹ̀, ó wá ọ̀nà àbáyọ ó sì sá lọ. (1 Sám. 19:11, 12) Lọ́nà kan náà, ó yẹ kí àwa náà gbàdúrà pé kí Jèhófà fún wa lọ́gbọ́n tá a máa fi yanjú àwọn ìṣòro wa tàbí èyí táá jẹ́ kí ìṣòro yẹn lè rọjú.—Ják. 1:5.

Bá A Ṣe Lè Lágbára Láti Fara Dà Á

14. Kí ló máa jẹ́ ká lè fara da ìṣòro?

14 Ìṣòro wa lè má kúrò lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ó tiẹ̀ lè máa bá a lọ fúngbà díẹ̀. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló máa jẹ́ ká lè fara dà á? Àkọ́kọ́, ńṣe ni ká rántí pé tá a bá ń bá a lọ láti sin Jèhófà tọkàntọkàn láìfi ìṣòro wa pè, ńṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Ìṣe 14:22) Rántí ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan Jóòbù. Ó ní: “Lásán ha ni Jóòbù ń bẹ̀rù Ọlọ́run bí? Ìwọ fúnra rẹ kò ha ti ṣe ọgbà ààbò yí i ká, àti yí ilé rẹ̀ ká, àti yí ohun gbogbo tí ó ní ká? Ìwọ ti bù kún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, àní ohun ọ̀sìn rẹ̀ ti tàn káàkiri ilẹ̀. Ṣùgbọ́n, fún ìyípadà, jọ̀wọ́, na ọwọ́ rẹ, kí o sì fọwọ́ kan ohun gbogbo tí ó ní, kí o sì rí i bóyá kì yóò bú ọ ní ojú rẹ gan-an.” (Jóòbù 1:9-11) Bí Jóòbù ṣe pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́, ńṣe ló fi hàn pé irọ́ gbuu ni Sátánì ń pa. Bí àwa náà bá fara da ìpọ́njú tá ò sì sẹ́ Jèhófà, ńṣe là ń fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì. Ìfaradà wa á sì tún jẹ́ kí ìrètí àti ìgbẹ́kẹ̀lé tá a ní nínú Jèhófà túbọ̀ lágbára.—Ják. 1:4.

15. Àpẹẹrẹ àwọn wo ló lè fún wa lókun?

15 Ìkejì, rántí pé “àwọn ohun kan náà ní ti ìyà jíjẹ ní ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará yín nínú ayé.” (1 Pét. 5:9) Bẹ́ẹ̀ ni o, “kò sí ìdẹwò kankan tí ó ti bá yín bí kò ṣe ohun tí ó wọ́pọ̀ fún àwọn ènìyàn.” (1 Kọ́r. 10:13) Nípa bẹ́ẹ̀, tó o bá ń ṣàṣàrò lórí àpẹẹrẹ àwọn ará míì dípò tí wàá máa kó ìṣòro rẹ lé ọkàn, ìyẹn yóò fún ọ lágbára àti ìṣírí tí wàá fi lè fara dà á. (1 Tẹs. 1:5-7; Héb. 12:1) Fara balẹ̀ ronú lórí àpẹẹrẹ àwọn ará tó o mọ̀ pé wọ́n ti fara da ìpọ́njú tó ga láìsẹ́ ìgbàgbọ́ wọn. Ǹjẹ́ o ti wo ìrírí àwọn ará nínú àwọn ìwé wa bóyá wàá rí àwọn tí wọ́n fara da irú ìṣòro tó o ní? Àwọn ìrírí wọ̀nyẹn lè fún ẹ lókun gan-an.

16. Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń fún wa lókun nígbà tí ìdánwò bá dé bá wa?

16 Ìkẹta, má gbàgbé pé Jèhófà ni “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, ẹni tí ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa, kí àwa lè tu àwọn tí ó wà nínú ìpọ́njú èyíkéyìí nínú nípasẹ̀ ìtùnú tí Ọlọ́run fi ń tu àwa tìkára wa nínú.” (2 Kọ́r. 1:3, 4) Ńṣe ló máa ń dà bíi pé Ọlọ́run dúró tì wá tó ń fún wa níṣìírí, tó sì ń fún wa lókun “nínú gbogbo ìpọ́njú wa” pátápátá. Èyí ló ń jẹ́ káwa náà lè tu àwọn tó bá “wà nínú ìpọ́njú èyíkéyìí” nínú. Pọ́ọ̀lù alára ní ìrírí àwọn nǹkan tó sọ yìí.—2 Kọ́r. 4:8, 9; 11:23-27.

17. Báwo ni Bíbélì ṣe ń jẹ́ ká mọ ohun tá a lè ṣe kí ìpọ́njú má lè borí wa?

17 Ìkẹrin, a ní Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó “ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo, kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.” (2 Tím. 3:16, 17) Kì í ṣe pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kàn ń mú ká “pegedé,” ká sì “gbára dì” fún iṣẹ́ rere gbogbo nìkan ni. Ó tún ń jẹ́ ká mọ ohun tá a lè ṣe kí ìpọ́njú má lè borí wa. Ó ń sọ wa dẹni tó pegedé ní kíkún” àtẹni tó gbára dì pátápátá.” Ní olówuuru, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “mú gbára dì pátápátá” túmọ̀ sí “ohun tá a ti mú kó wà ní sẹpẹ́.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé wọ́n ń lo ọ̀rọ̀ yìí láyé àtijọ́ láti fi ṣàpèjúwe ọkọ ojú omi tó ti wà ní sẹpẹ́ fún ìrìn àjò lójú òkun tàbí ẹ̀rọ kan tó lè ṣe gbogbo ohun tó yẹ kó ṣe. Bákan náà, Jèhófà máa ń lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti fi pèsè gbogbo ohun tá a lè fi yanjú àwọn ìṣòro tá a bá ní. Ìyẹn ló máa ń jẹ́ ká lè sọ pé, “Bí Ọlọ́run bá gbà kí ìṣòro kan dé bá mi, màá fara dà á, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ rẹ̀.”

Jèhófà Ń Dá Wa Nídè Nínú Gbogbo Ìpọ́njú Wa

18. Kí ni kókó tá a tún lè máa rántí tí yóò jẹ́ ká lè fara da ìpọ́njú láìsẹ́ ìgbàgbọ́ wa?

18 Ìkarùn-ún, máa rántí kókó pàtàkì yìí nígbà gbogbo pé, láìpẹ́ Jèhófà yóò dá aráyé nídè kúrò nínú gbogbo ìpọ́njú wọn. (Sm. 34:19; 37:9-11; 2 Pét. 2:9) Àmọ́, yàtọ̀ sí pé Ọlọ́run máa dá wa nídè kúrò nínú gbogbo ìpọ́njú tá a ní báyìí, yóò tún fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú, ì báà jẹ́ pẹ̀lú Jésù lọ́run tàbí nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.

19. Báwo la ṣe lè fara da ìpọ́njú láìsẹ́ Jèhófà?

19 Kó tó dìgbà tí Ọlọ́run yóò mú gbogbo ìpọ́njú kúrò, ẹ jẹ́ ká máa forí ti àwọn ìnira tó ń bá wa fínra nínú ayé burúkú yìí nìṣó. Ọjọ́ lọjọ́ náà máa jẹ́ nígbà tí gbogbo ìpọ́njú yóò kásẹ̀ nílẹ̀! (Sm. 55:6-8) Ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé pé bí a bá fara da ìpọ́njú, tá ò sẹ́ Jèhófà, ńṣe là ń fi hàn pé òpùrọ́ ni Èṣù. Ǹjẹ́ kí àdúrà àti àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ará máa fún wa lókun, ká sì máa rántí pé àwọn ará wa náà ń ní irú ìdánwò tá à ń ní. Máa lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà tó múná dóko, èyí táá jẹ́ kó o dẹni tó pegedé ní kíkún àtẹni tá a mú gbára dì pátápátá. Má ṣe jẹ́ kí mìmì kan mi ìgbẹ́kẹ̀lé tó o ní pé “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo” yóò fi tìfẹ́tìfẹ́ bójú tó ọ. Rántí pé “ojú Jèhófà ń bẹ lọ́dọ̀ àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́.”—Sm. 34:15.

Ǹjẹ́ O Lè Dáhùn?

• Báwo làwọn ìpọ́njú tí Dáfídì ní ṣe rí lára rẹ̀?

• Kí lohun tó dá Sólómọ́nì Ọba lójú?

• Kí ni yóò jẹ́ ká lè fara da ìpọ́njú tí Jèhófà bá gbà láyè?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ó dá Sólómọ́nì lójú pé Jèhófà máa wá nǹkan ṣe sí ìṣòro àwọn èèyàn Rẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Dáfídì ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà nípa gbígbàdúrà sí i, ó sì ṣiṣẹ́ lórí àdúrà tó gbà