Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ta Ni Nínú Yín Tí ó Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n Àti Olóye?”

“Ta Ni Nínú Yín Tí ó Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n Àti Olóye?”

“Ta Ni Nínú Yín Tí ó Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n Àti Olóye?”

“Ta ni nínú yín tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti olóye? Kí ó fi àwọn iṣẹ́ rẹ̀ hàn láti inú ìwà rẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ pẹ̀lú ìwà tútù tí ó jẹ́ ti ọgbọ́n.”—JÁK. 3:13.

1, 2. Kí lo lè sọ nípa ọ̀pọ̀ àwọn táráyé ń kà sí ọlọ́gbọ́n?

 TA NI ìwọ kà sí ọlọ́gbọ́n? Ṣé àwọn òbí rẹ ni, àbí bàbá àgbàlagbà kan, àbí ọ̀jọ̀gbọ́n kan nílé ẹ̀kọ́ yunifásítì? Ó lè jẹ́ pé bí wọ́n ṣe tọ́ ẹ dàgbà, ibi tó ò ń gbé àti ipò tó o wà ló máa sọ irú ẹni tí wàá kà sí ọlọ́gbọ́n. Àmọ́, ohun tó ṣe pàtàkì lójú àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni ohun tí Ọlọ́run sọ pé ó ń sọ èèyàn di ọlọ́gbọ́n.

2 Gbogbo àwọn tí aráyé kà sí ọlọ́gbọ́n kọ́ ló gbọ́n lójú Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, Jóòbù sọ̀rọ̀ sí àwọn ọkùnrin tí wọ́n rò pé àwọn ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n, ó ní: “Èmi kò . . . rí ọlọ́gbọ́n kankan nínú yín.” (Jóòbù 17:10) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa àwọn kan tó kọ ìmọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀, ó ní: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń tẹnu mọ́ ọn pé àwọn jẹ́ ọlọ́gbọ́n, wọ́n ya òmùgọ̀.” (Róòmù 1:22) Jèhófà la ọ̀rọ̀ náà mọ́lẹ̀ nígbà tó tipasẹ̀ wòlíì Aísáyà sọ̀rọ̀, ó ní: “Ègbé ni fún àwọn tí ó gbọ́n ní ojú ara wọn.”— Aísá. 5:21.

3, 4. Kí ló máa fi hàn pé ẹnì kan jẹ́ ọlọ́gbọ́n lóòótọ́?

3 Ó ṣe kedere pé, ó yẹ ká mọ ohun tó lè sọni di ọlọ́gbọ́n kéèyàn sì tipa bẹ́ẹ̀ rí ojú rere Ọlọ́run. Òwe 9:10 sọ ọ̀rọ̀ kan tó lè jẹ́ ká mọ̀ ọ́n, ó ní: “Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n, ìmọ̀ Ẹni Mímọ́ Jù Lọ sì ni ohun tí òye jẹ́.” Ọlọ́gbọ́n gbọ́dọ̀ ní ìbẹ̀rù tó tọ́ fún Ọlọ́run, ó sì gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú àwọn ìlànà rẹ̀. Àmọ́, ó tún gbọ́dọ̀ ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ, kì í ṣe pé kó kàn sáà gbà pé Ọlọ́run wà, pé ó sì ní àwọn ìlànà. Ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó ń jẹ́ Jákọ́bù ràn wá lọ́wọ́ láti ronú nípa èyí. (Ka Jákọ́bù 3:13.) Kíyè sí gbólóhùn kan nínú ọ̀rọ̀ tó sọ yẹn, ó ní: “Kí ó fi àwọn iṣẹ́ rẹ̀ hàn láti inú ìwà rẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀.” Ó yẹ kí ìwà rẹ àti ọ̀rọ̀ rẹ máa fi ọgbọ́n tòótọ́ hàn.

4 Ọgbọ́n tòótọ́ máa ń mú kéèyàn ronú jinlẹ̀ kó tó ṣèpinnu, ó sì máa ń mú kéèyàn fi ìmọ̀ àti òye ṣe nǹkan lọ́nà táá fi yọrí sí rere. Àwọn ìwà wo ló máa fi hàn pé a ní irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀? Jákọ́bù to àwọn ohun kan lẹ́sẹẹsẹ tó máa hàn nínú ìwà àwọn tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n. a Kí lohun tó sọ tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní àjọṣe rere pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ àtàwọn tí kì í ṣe onígbàgbọ́ bíi tiwa?

Ìṣe Ẹni Ló Ń Fi Hàn Pé Èèyàn Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n

5. Báwo lẹ́ni tó bá gbọ́n lóòótọ́ ṣe máa ń hùwà?

5 Gẹ́gẹ́ bá a ti ṣe rí i, ọ̀rọ̀ Jákọ́bù fi hàn pé ọgbọ́n àti ìwà rere jọ ń rìn pọ̀ ni. Nítorí pé ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n, ọlọ́gbọ́n èèyàn máa ń hùwà tó bá ọ̀nà àti ìlànà Ọlọ́run mu. Wọn ò bí ọgbọ́n Ọlọ́run mọ́ wa. Síbẹ̀, a lè ní ọgbọ́n Ọlọ́run nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé àti ṣíṣe àṣàrò. Àwọn nǹkan yìí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ohun tí Éfésù 5:1 sọ fún wa, pé: “Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run.” Bá a bá ṣe ń fìwà jọ Jèhófà tó, bẹ́ẹ̀ ni ìṣesí wa yóò ṣe máa fi ọgbọ́n hàn tó. Ọ̀nà Jèhófà ga ju ọ̀nà èèyàn lọ fíìfíì. (Aísá. 55:8, 9) Nítorí náà, bá a ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ṣe nǹkan, àwọn tí kì í ṣe Kristẹni yóò rí i pé ohun kan wà tó mú ká yàtọ̀.

6. Kí nìdí tí ìwà tútù fi jẹ́ ẹ̀rí pé ẹnì kan fìwà jọ Ọlọ́run, báwo lẹnì kan sì ṣe lè fi hàn pé òun jẹ́ oníwà tútù?

6 Jákọ́bù sọ pé ọ̀nà kan tá a lè gbà jọ Jèhófà ni pé ká ní “ìwà tútù tí ó jẹ́ ti ọgbọ́n.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé jíjẹ́ oníwà tútù túmọ̀ sí pé kéèyàn jẹ́ ẹni jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, ìyẹn ò sọ pé kẹ́ni tó jẹ́ Kristẹni máa fàyè gba ìgbàkugbà, èyí yóò sì ràn án lọ́wọ́ láti hùwà bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé agbára Ọlọ́run kò lópin, síbẹ̀ ó jẹ́ oníwà tútù, ẹ̀rù kì í sì í bà wá láti sún mọ́ ọn. Ọmọ Ọlọ́run fi ìwà tútù jọ Bàbá rẹ̀ gan-an débi tó fi lè sọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín.”— Mát. 11:28, 29; Fílí. 2:5-8.

7. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Mósè jẹ́ àpẹẹrẹ rere nípa ìwà tútù?

7 Bíbélì sọ nípa àwọn tí wọ́n jẹ́ oníwà tútù tàbí ọlọ́kàn tútù lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Mósè jẹ́ ọkàn lára wọn. Ó ní iṣẹ́ ńlá kan tó ń bójú tó, síbẹ̀ Bíbélì pè é ní ẹni tó fi “gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ jẹ́ ọlọ́kàn tútù jù lọ nínú gbogbo ènìyàn tí ó wà ní orí ilẹ̀.” (Núm. 11:29; 12:3) Wo bí ìgboyà tí Jèhófà fún Mósè láti fi mú ìfẹ́ Rẹ̀ ṣẹ ti pọ̀ tó. Inú Jèhófà máa ń dùn láti lo àwọn oníwà tútù èèyàn láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ.

8. Báwo ni àwọn èèyàn aláìpé ṣe lè fi “ìwà tútù tí ó jẹ́ ti ọgbọ́n” hàn?

8 A ti wá rí i kedere báyìí pé, ó ṣeé ṣe fáwọn èèyàn aláìpé láti fi “ìwà tútù tí ó jẹ́ ti ọgbọ́n” hàn. Àwa ńkọ́? Báwo la ṣe lè túbọ̀ máa fi hàn dáadáa pé a jẹ́ oníwà tútù? Ìwà tútù wà nínú èso ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà. (Gál. 5:22, 23) A lè gbàdúrà pé kí Jèhófà fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, ká sapá gidigidi láti máa fi èso rẹ̀ hàn, ká sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Ọlọ́run yóò ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ máa fi hàn pé a ní ìwà tútù. Onísáàmù kan sọ ọ̀rọ̀ kan tó máa mú ká sapá láti jẹ́ oníwà tútù, ó mú un dá wa lójú pé: “[Ọlọ́run] yóò sì kọ́ àwọn ọlọ́kàn tútù ní ọ̀nà rẹ̀.”—Sm. 25:9.

9, 10. Ìsapá wo la gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè máa fi ìwà tútù bíi ti Ọlọ́run hàn, kí sì nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀?

9 Àmọ́, ó lè gba pé ká sapá gidigidi ká tó lè jẹ́ oníwà tútù. Àwọn kan nínú wa lè má jẹ́ oníwà tútù nítorí bí wọ́n ṣe tọ́ wọn dàgbà. Yàtọ̀ síyẹn, ìwà táwọn èèyàn tó wà láyìíká wa máa ń hù lè jẹ́ kó ṣòro fún wa láti jẹ́ oníwà tútù, wọ́n lè máa sọ pé “wèrè la fi ń wo wèrè.” Àmọ́, ṣé ìyẹn mọ́gbọ́n dání? Tẹ́nì kan bá sọ pé òun á “ṣe wèrè” fún wa, ṣó yẹ káwa náà “ṣe wèrè” fún un padà? Tá a bá dà á sí agídí, ńṣe ló máa bọ̀rọ̀ jẹ́, àmọ́ tá a bá ṣe sùúrù, ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ náà lójú. Bákan náà, Bíbélì gbà wá níyànjú pé: “Ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí ń fa ìrora máa ń ru ìbínú sókè.” (Òwe 15:1, 18) Torí náà, nígbà tẹ́nì kan bá múnú bí wa, bóyá nínú ìjọ ni tàbí níbòmíì, ǹjẹ́ a lè wá ọ̀nà tá a máa gbà fi hàn pé a jẹ́ ọlọ́gbọ́n nípa dídáhùn padà pẹ̀lú ìwà tútù?—2 Tím. 2:24.

10 Gẹ́gẹ́ bá a ti sọ lókè yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn tí ẹ̀mí ayé ń darí kì í ṣe èèyàn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, wọn kì í wá àlàáfíà, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kì í ṣe sùúrù. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn òǹrorò àtàwọn agbéraga èèyàn ló pọ̀ jù. Jákọ́bù mọ̀ bẹ́ẹ̀, ó sì ṣèkìlọ̀ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa nínú ìjọ lè ṣọ́ra kí irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ má bàa ràn wá. Kí la tún lè rí kọ́ látinú ìmọ̀ràn Jákọ́bù?

Àwọn Ìwà Tá A Fi Ń Dá Àwọn Tí Kò Gbọ́n Mọ̀

11. Àwọn ìwà wo ni kò bá ọgbọ́n Ọlọ́run mu?

11 Jákọ́bù sojú abẹ níkòó nígbà tó kọ̀wé nípa àwọn ìwà tí kò bá ọgbọ́n Ọlọ́run mu. (Ka Jákọ́bù 3:14.) Ìwà ẹlẹ́ran ara ni owú jíjẹ àti asọ̀, ńṣe ló máa ń fi hàn pé ẹnì kan ò ní ẹ̀mí Ọlọ́run. Wo àpẹẹrẹ ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ níbì tí ẹran ara bá ti ń darí wọn. Ṣọ́ọ̀ṣì kan wà ní Jerúsálẹ́mù tó ń jẹ́ Church of the Holy Sepulchre. Ibi táwọn kan gbà pé wọ́n sin Jésù sí ni wọ́n kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì náà sí. Ẹgbẹ́ mẹ́fà tí wọ́n pe ara wọn ní Kristẹni ló ń darí ṣọ́ọ̀ṣì náà. Gbọ́nmi-si omi-ò-to sì ti wà láàárín wọn tipẹ́tipẹ́. Lọ́dún 2006, ìwé ìròyìn Time sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ nígbà kan táwọn àlùfáà ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé “ń ṣawuyewuye níbẹ̀ fún ọ̀pọ̀ wákàtí, . . . tí wọ́n sì ń fi ọ̀pá irin ńláńlá tí wọ́n ń gbé àbẹ́là sí lu ara wọn.” Wọn ò fọkàn tán ara wọn rárá, débi pé ọwọ́ ẹnì kan tó jẹ́ Mùsùlùmí ni wọ́n fi kọ́kọ́rọ́ ṣọ́ọ̀ṣì náà sí.

12. Níbi tí kò bá ti sí ọgbọ́n Ọlọ́run, kí ló lè ṣẹlẹ̀?

12 Ó dájú pé kò yẹ kí irú gbọ́nmi-si omi-ò-to bẹ́ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni tòótọ́. Àmọ́, àìpé ti mú káwọn kan máa lo agídí torí wọ́n gbà pé èrò tàwọn ló tọ̀nà. Ìyẹn sì lè ṣebí ẹní fa aáwọ̀ àti gbọ́nmi-si omi-ò-to. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kíyè sí èyí nínú ìjọ Kọ́ríńtì, ìdí nìyẹn tó fi kọ̀wé pé: “Nítorí nígbà tí ó jẹ́ pé owú àti gbọ́nmi-si omi-ò-to wà láàárín yín, ẹ kò ha jẹ́ ẹlẹ́ran ara, ẹ kò ha sì ń rìn bí ènìyàn?” (1 Kọ́r. 3:3) Ó pẹ́ díẹ̀ tí ìjọ yẹn fi wà nínú ipò tó ń bani nínú jẹ́ yẹn ní ọ̀rúndún kìíní. Nítorí náà, ó yẹ ká máa ṣọ́ra kírú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ má bàa wọnú ìjọ lónìí.

13, 14. Sọ àwọn àpẹẹrẹ bí ẹran ara ṣe lè lo ẹnì kan láti hùwà tí kò bọ́gbọ́n mu.

13 Báwo nirú ìwà yìí ṣe lè yọ́ wọnú ìjọ? Ó lè bẹ̀rẹ̀ bí eré bí eré. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tá a bá ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan, oríṣiríṣi àbá lè wáyé nípa bó ṣe yẹ ká ṣe àwọn nǹkan kan. Arákùnrin kan lè dá àbá kan tí wọn ò gbà wọlé. Ó sì lè tìtorí bẹ́ẹ̀ dá asọ̀ sílẹ̀ kó wá bẹ̀rẹ̀ sí í bẹnu àtẹ́ lu àwọn ìpinnu tí wọ́n ti ṣe. Kódà, ó lè sọ pé òun ò ní dá sí iṣẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n ń kọ́ náà mọ́! Irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè ti gbàgbé pé ẹ̀mí àlàáfíà tó wà nínú ìjọ ni olórí ohun tó máa ń jẹ́ kí iṣẹ́ ìjọ yọrí sí rere, kì í ṣe ọ̀nà tá a gbà ṣe iṣẹ́ náà. Ohun tá a bá ṣe pẹ̀lú ẹ̀mí ìwà tútù ni inú Jèhófà máa dùn sí, kì í ṣe ohun tá a ṣe pẹ̀lú ẹ̀mí asọ̀.—1 Tím. 6:4, 5.

14 Àpẹẹrẹ míì rèé: Àwọn alàgbà nínú ìjọ kíyè sí i pé alàgbà kan kò kúnjú ìwọ̀n ohun tí Ìwé Mímọ́ béèrè lọ́wọ́ alàgbà mọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti pẹ́ tó ti ń sìn. Wọ́n sì mọ̀ pé àwọn ti fún arákùnrin náà nímọ̀ràn kan pàtó nígbà kan rí àmọ́ kò ṣàtúnṣe. Nígbà tí alábòójútó àyíká wá bẹ̀ wọ́n wò, wọ́n dábàá pé kí wọ́n mú arákùnrin náà kúrò nípò alàgbà, alábòójútó àyíká sì gbà pẹ̀lú wọn. Ojú wo ló yẹ kí arákùnrin náà fi wo ọ̀rọ̀ ọ̀hún? Ṣé yóò fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìwà tútù tẹ́wọ́ gba ìpinnu táwọn alàgbà ti panu pọ̀ ṣe, kó sì tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ tí wọ́n fún un, kó sì wá pinnu láti ṣiṣẹ́ kára kó lè padà kúnjú ìwọ̀n ohun tí Ìwé Mímọ́ béèrè lọ́wọ́ àwọn alàgbà, kó lè tún láǹfààní yìí lọ́jọ́ iwájú? Àbí ńṣe ló máa di àwọn alàgbà sínú, táá sì máa jowú nítorí pé kò láǹfààní láti máa sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà mọ́? Ṣé ó yẹ kí arákùnrin kan máa ṣe bíi pé òun kúnjú ìwọ̀n gẹ́gẹ́ bí àgbà ọkùnrin nígbà tó jẹ́ pé ní tòdodo kò kúnjú ìwọ̀n mọ́? Ẹ ò rí i pé ohun tó bọ́gbọ́n mu jù lọ ni kó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ kó sì jẹ́ olóye!

15. Kí nìdí tó o fi rò pé ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run mí sí tó wà ní Jákọ́bù 3:15, 16 ṣe pàtàkì gan-an?

15 Òótọ́ ni pé àwọn ohun míì wà tó lè mú kẹ́nì kan nírú ìwà bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ohun yòówù tí ì bá dé, a gbọ́dọ̀ máa gbìyànjú láti yẹra fún irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀. (Ka Jákọ́bù 3:15, 16.) Ọmọ ẹ̀yìn Jésù náà Jákọ́bù pe irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ ní “ti ilẹ̀ ayé” nítorí wọ́n jẹ́ ìwà ẹran ara, tí kì í ṣe ìwà ọgbọ́n tí ó wá láti òkè. Wọ́n jẹ́ “ti ẹranko” ní ti pé wọ́n jẹ́ ti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, tó jọ ìwà ẹranko tí kì í ronú. Irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ jẹ́ “ti ẹ̀mí èṣù,” nítorí wọ́n ń fi ìṣe àwọn ẹ̀mí èṣù tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run hàn. Ẹ ò rí i pé kò dáa rárá kí ẹnì kan tó jẹ́ Kristẹni máa hu irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀!

16. Àtúnṣe wo la lè ní láti ṣe, báwo la sì ṣe lè ṣe é?

16 Á dára kí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ yẹ ara rẹ̀ wò kó sì ṣíṣẹ́ láti mú irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ kúrò lọ́kàn ara rẹ̀. Ó yẹ kí àwọn alábòójútó, tí wọ́n tún jẹ́ olùkọ́ nínú ìjọ, máa ṣọ́ra láti má ṣe fàyè gba ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àtàwọn ìwà tó jẹ́ ti ẹ̀mí èṣù lọ́kàn wọn. Ó lè má rọrùn rárá láti mú irú ìwà bẹ́ẹ̀ kúrò lọ́kàn wa nítorí àìpé tó ń bá wa fínra àti ipa tí ayé yìí lè ní lórí wa. A lè fi wé ẹni tó ń gun òkè kan tó ń yọ̀. Bí ò bá rí nǹkan dì mú, ńṣe ló máa yọ̀ padà sísàlẹ̀. Àmọ́, tá a bá di ìmọ̀ràn inú Bíbélì mú ṣinṣin, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ láti inú ìjọ Ọlọ́run kárí ayé, a lè tẹ̀ síwájú ká sì mókè.—Sm. 73:23, 24.

Àwọn Ànímọ́ Tó Máa Ń Hàn Lára Àwọn Ọlọ́gbọ́n

17. Báwo làwọn ọlọ́gbọ́n ṣe máa ń ṣe nígbà tí àdánwò láti ṣe ohun búburú bá dojú kọ wọ́n?

17 Ka Jákọ́bù 3:17. A lè jàǹfààní nínú ṣíṣàgbéyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ànímọ́ tó máa ń wá látinú “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè.” Jíjẹ́ oníwà mímọ́ túmọ̀ sí pé kí ìwà wa àti èrò wa mọ́ kó má sì lẹ́gbin. Ojú ẹsẹ̀ la gbọ́dọ̀ kọ ohun tó bá jẹ́ ibi. Kíá mọ́sá ló yẹ ká kọ̀ ọ́, kò sọ̀rọ̀ pé à ń rò ó níbẹ̀. Bóyá ẹnì kan ti fẹ́ ṣèèṣì ki ìka bọ̀ ẹ́ lójú rí, ó dájú pé kíá ni wàá gbé ojú rẹ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. O ò ní ṣẹ̀ṣẹ̀ máa rò ó, ojú ẹsẹ̀ ni wàá gbé ojú ẹ sá. Bákàn náà ló ṣe yẹ kó rí nígbà tí àdánwò láti hùwà burúkú bá dojú kọ wá. Ìwà mímọ́ wa àti ẹ̀rí ọkàn wa tá a ti fi Bíbélì kọ́ ní láti mú ká yẹra fún ohun búburú lójú ẹsẹ̀. (Róòmù 12:9) Bíbélì fún wa ní àpẹẹrẹ àwọn tó kọ ohun búburú lójú ẹsẹ̀, ó sọ ti Jósẹ́fù àti Jésù.—Jẹ́n. 39:7-9; Mát. 4:8-10.

18. Kí ló túmọ̀ sí láti (a) lẹ́mìí àlàáfíà? (b) láti máa wá àlàáfíà?

18 Ọgbọ́n tí ó wá láti òkè tún máa mú ká lẹ́mìí àlàáfíà. Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé ká yẹra pátápátá fún ìwà jàgídíjàgan, ìwà aríjàgbá tàbí àwọn ohun tó máa ń ba àlàáfíà jẹ́. Jákọ́bù ṣàlàyé sí i lórí kókó yìí nígbà tó sọ pé: “Èso òdodo ni a ń fún irúgbìn rẹ̀ lábẹ́ àwọn ipò tí ó kún fún àlàáfíà fún àwọn tí ń wá àlàáfíà.” (Ják. 3:18) Kíyè sí ọ̀rọ̀ yìí, “ń wá àlàáfíà.” Nínú ìjọ, ǹjẹ́ wọ́n mọ̀ wá sí ẹni tí ń wá àlàáfíà tàbí ẹni tó ń ba àlàáfíà ìjọ jẹ́? Ṣé lemọ́lemọ́ làwa àtàwọn èèyàn jọ máa ń ní aáwọ̀ tàbí èdèkòyédè, tá a sì máa ń tètè ṣẹ àwọn èèyàn tàbí káwọn èèyàn tètè ṣẹ̀ wá? Ṣé a máa ń sọ pé bá a ṣe mọ ìwà tiwa hù nìyẹn, pé káwọn èèyàn gbà wá bẹ́ẹ̀, àbí a máa ń fi ìrẹ̀lẹ̀ sapá láti ṣàtúnṣe àwọn ìwà tó máa ń bí àwọn ẹlòmíì nínú? Ǹjẹ́ àwọn èèyàn mọ̀ wá sẹ́ni tó máa ń sapá láti máa wá àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn, ẹni tó tètè máa ń darí jini tó sì máa ń gbójú fo àṣìṣe àwọn ẹlòmíì? Yíyẹ ara ẹni wò tinútinú yóò lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ̀ bóyá ó yẹ ká túbọ̀ máa fi ọgbọ́n Ọlọ́run hàn nínú ọ̀ràn yìí.

19. Báwo la ṣe lè mọ ẹni tó jẹ́ afòyebánilò?

19 Jákọ́bù fi ìfòyebánilò kún àpèjúwe tó ṣe nípa ọgbọ́n tí ó wá láti òkè. Ǹjẹ́ àwọn èèyàn mọ̀ wá sẹ́ni tó máa ń fara mọ́ èrò àwọn ẹlòmíì nígbà tí èrò náà kò bá ta ko ìlànà Ìwé Mímọ́ kankan? Ṣé a kì í sọ pé ọ̀rọ̀ tiwa làwọn èèyàn gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé dandan? Ṣáwọn èèyàn mọ̀ wá sí ẹni jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ tó dùn bá sọ̀rọ̀? Àwọn nǹkan wọ̀nyí ló ń fi hàn pé ẹnì kan jẹ́ afòyebánilò.

20. Kí ni yóò jẹ́ àbájáde rẹ̀ tá a bá ń fi àwọn ànímọ́ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ jíròrò yìí ṣèwà hù?

20 Ẹ wo bí ìdùnnú ṣe máa kúnnú ìjọ tó táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin bá túbọ̀ ń fi àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tí Jákọ́bù sọ̀rọ̀ nípa wọn ṣèwà hù! (Sm. 133:1-3) Jíjẹ́ oníwà tútù, ẹlẹ́mìí àlàáfíà, àti ẹni tó ń fòye báni lò yóò mú kí àjọṣe àwa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì dára sí i yóò sì jẹ́ ẹ̀rí pé a ní “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè.” Ohun tí a óò gbé yẹ̀ wò tẹ̀ lé èyí ni bí wíwo àwọn èèyàn pẹ̀lú ojú tí Jèhófà fi ń wò wọ́n yóò ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ oníwà tútù, ẹlẹ́mìí àlàáfíà àti afòyebánilò.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ohun tí Jákọ́bù ń jíròrò fi hàn pé àwọn alàgbà tí wọ́n tún jẹ́ “olùkọ́” nínú ìjọ ló dìídì ń bá wí. (Ják. 3:1) Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ló yẹ kí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ nínú fífi ọgbọ́n Ọlọ́run hàn, síbẹ̀ gbogbo wa lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìmọ̀ràn Jákọ́bù.

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

• Kí ló ń sọ Kristẹni kan di ọlọ́gbọ́n?

• Báwo lá ṣe lè túbọ̀ máa fi ọgbọ́n tí ó wá láti òkè hàn dáadáa?

• Àwọn ìwà wo là ń rí lára àwọn tí wọn kì í fi “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè” ṣèwà hù?

• Àwọn ànímọ́ wo lo ti pinnu pé wàá túbọ̀ máa ní?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Báwo ni gbọ́nmi-si omi-ò-to ṣe lè yọ́ wọnú ìjọ lóde òní?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Ṣé ojú ẹsẹ̀ lo máa ń kọ ohun búburú?