Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ Rántí Ẹlẹ́dàá Yín Atóbilọ́lá Nísinsìnyí

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ Rántí Ẹlẹ́dàá Yín Atóbilọ́lá Nísinsìnyí

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ Rántí Ẹlẹ́dàá Yín Atóbilọ́lá Nísinsìnyí

“Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nísinsìnyí, ní àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́kùnrin.”—ONÍW. 12:1.

1. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun fọkàn tán àwọn ọ̀dọ́ tó ń sin òun?

 ÀWỌN ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni ṣeyebíye, wọ́n sì dà bí ìrì atunilára lójú Jèhófà. Ó tiẹ̀ sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ọ̀dọ́ lọ́kùnrin lóbìnrin yóò “fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn” fún iṣẹ́ “ní ọjọ́ ẹgbẹ́ ológun” Kristi Ọmọ rẹ̀. (Sm. 110:3) Bẹ́ẹ̀, ó mọ̀ pé àsìkò wa yìí tí ọ̀pọ̀ èèyàn kò ka Ọlọ́run sí, tó jẹ́ pé ìfẹ́ tara wọn àti ìfẹ́ owó ló gbà wọ́n lọ́kàn, tí wọ́n sì jẹ́ aláìgbọràn, ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí máa ṣẹ. Èyí fi hàn pé Jèhófà mọ̀ pé ìwà àwọn ọ̀dọ́ tó ń sin òun lásìkò táwọn èèyàn ò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run yìí yóò yàtọ̀. Ẹ ò rí i pé Jèhófà fọkàn tán ẹ̀yin ọ̀dọ́ lọ́kùnrin lóbìnrin gan-an!

2. Kí lẹni tó bá ń rántí Jèhófà yóò máa ṣe?

2 Ẹ wo bínú Ọlọ́run á ṣe máa dùn tó bó ṣe ń rí ẹ̀yin ọ̀dọ́ tẹ́ ẹ̀ ń rántí òun tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá yín Atóbilọ́lá! (Oníw. 12:1) Àmọ́ o, rírántí Jèhófà ju pé ká kàn máa rántí pé Ẹlẹ́dàá wà. A gbọ́dọ̀ ṣe nǹkan kan, ìyẹn ni pé ká máa ṣe ohun tínú Ọlọ́run dùn sí, ká sì jẹ́ kí òfin àti ìlànà rẹ̀ máa darí wa nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe. A sì tún ní láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, nítorí a mọ̀ pé ó ń wá ire wa. (Sm. 37:3; Aísá. 48:17, 18) Ṣé bí ọ̀rọ̀ Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá ṣe rí lára rẹ náà nìyẹn?

“Fi Gbogbo Ọkàn-Àyà Rẹ Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà”

3, 4. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwa náà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà lónìí?

3 Jésù Kristi ni àpẹẹrẹ tó dára jù lọ tó bá dọ̀rọ̀ ká gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run. Ó gbé ìgbé ayé rẹ̀ lọ́nà tó bá ọ̀rọ̀ inú ìwé Òwe 3:5, 6 mu. Èyí tó sọ pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Jésù ṣèrìbọmi ni Sátánì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, tó ń gbìyànjú láti fi agbára àti ògo ayé tàn án jẹ. (Lúùkù 4:3-13) Àmọ́ kò rí Jésù tàn jẹ. Jésù mọ̀ pé ẹni tó bá ní “ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Jèhófà” yóò ní ojúlówó “ọrọ̀ àti ògo àti ìyè.”—Òwe 22:4.

4 Ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan àti ojúkòkòrò gbayé kan lóde òní. Nígbà tó sì ti jẹ́ pé inú ayé yìí là ń gbé, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Má gbàgbé pé Sátánì ń sa gbogbo ipá rẹ̀ kó lè rí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tàn kúrò lójú ọ̀nà híhá tó jẹ́ ọ̀nà ìyè. Ọ̀nà gbòòrò tó jẹ́ ọ̀nà ìparun ló ń fẹ́ kí gbogbo èèyàn máa rìn. Má ṣe jẹ́ kó rí ẹ tàn jẹ o! Kàkà bẹ́ẹ̀, pinnu pé wàá máa rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá. Fi gbogbo ọkàn rẹ gbẹ́kẹ̀ lé e kó o sì di “ìyè tòótọ́,” tó dájú pé kò ní pẹ́ dé yìí, mú gírígírí.—1 Tím. 6:19.

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n!

5. Kí lẹ rò pé ó máa ṣẹlẹ̀ sáyé yìí lọ́jọ́ iwájú?

5 Àwọn ọ̀dọ́ tó rántí Ẹlẹ́dàá wọn máa ń gbọ́n ju àwọn ojúgbà wọn lọ. (Ka Sáàmù 119:99, 100.) Torí ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ayé yìí làwọn náà fi ń wò ó, wọ́n mọ̀ dájú pé ayé yìí máa tó kọjá lọ. Lóòótọ́ kò tíì pẹ́ tẹ́yin ọ̀dọ́ dáyé, síbẹ̀ níwọ̀nba ìgbà tẹ́ ẹ dáyé yìí, ẹ ó ti rí i pé ńṣe ni ìbẹ̀rù àti àníyàn nípa ọjọ́ ọ̀la túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Èyí tó bá ṣì wà nílé ìwé lára yín, yóò ti gbọ́ nípa bíba àyíká jẹ́, bí ayé ṣe túbọ̀ ń gbóná sí i, pípa igbó run àtàwọn ìṣòro míì. Ọkàn àwọn èèyàn ò balẹ̀ nítorí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan la mọ̀ dájú pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí jẹ́ àmì pé ayé Sátánì ò ní pẹ́ pa run.—Ìṣí. 11:18.

6. Kí ni Sátánì fi mú àwọn ọ̀dọ́ kan dẹ́sẹ̀ ńlá?

6 Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run kò wà lójúfò mọ́, wọn ò fi sọ́kàn mọ̀ pé ìgbà kúkúrú ló kù fún ayé yìí. (2 Pét. 3:3, 4) Sátánì ti lo ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ àti wíwo àwòrán ìṣekúṣe láti fi mú àwọn kan dẹ́ṣẹ̀ ńlá. (Òwe 13:20) Ẹ ò rí i pé ìbànújẹ́ ńlá ló máa jẹ́ téèyàn bá lọ pàdánù ojú rere Ọlọ́run lákòókò tó kù díẹ̀ kí òpin dé yìí! Dípò ìyẹn, ẹ jẹ́ ká kọ́gbọ́n látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́dún 1473 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Nígbà yẹn wọ́n pàgọ́ sí Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù, ó sì kù díẹ̀ kí wọ́n wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Kí ló ṣẹlẹ̀ níbẹ̀?

Wọ́n Di Aláìṣòótọ́ Nígbà Tó Kù Díẹ̀ Kí Wọ́n Wọ Ilẹ̀ Ìlérí

7, 8. (a) Ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ wo ni Sátánì lò ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù? (b) Ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ wo ni Sátánì ń lò lóde òní?

7 Sátánì fẹ́ rí i dájú pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò wọ ilẹ̀ tí Ọlọ́run ṣèlérí fún wọn. Bó ṣe rí i pé kò ṣeé ṣe fún wòlíì Báláámù láti gégùn-ún fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ míì; ó gbìyànjú láti mú kí wọ́n pàdánù ojú rere Jèhófà. Lọ́tẹ̀ yìí, àwọn obìnrin Móábù ẹlẹ̀tàn ni Èṣù lò láti fi tàn wọ́n jẹ, ọwọ́ rẹ̀ sì tẹ àwọn kan. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọmọbìnrin Móábù ṣèṣekúṣe, wọ́n sì tún ń tẹrí ba fún òrìṣà Báálì ti Péórù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé díẹ̀ ló kù kí wọ́n wọ Ilẹ̀ Ìlérí tó jẹ́ ogún wọn, àwọn tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún [24,000] ló pàdánù ẹ̀mí wọn. Àjálù ńlá gbáà nìyẹn!—Núm. 25:1-3, 9.

8 Lónìí, àwa náà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ wọ ilẹ̀ ìlérí kan tó ju tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ fíìfíì, ìyẹn ètò tuntun Ọlọ́run. Ìṣekúṣe yìí kan náà ni Sátánì ń lò láti fi mú àwọn èèyàn Ọlọ́run dẹ́ṣẹ̀. Ayé ti bà jẹ́ gan-an débi pé àwọn èèyàn ò ka ìṣekúṣe sóhun tó burú mọ́, wọ́n sì ka ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ sí ọ̀rọ̀ èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́. Arábìnrin kan sọ pé: “Kò síbòmíì mọ́ táwọn ọmọ mi ti ń kẹ́kọ̀ọ́ pé ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ àti ìṣekúṣe burú lójú Ọlọ́run àyàfi nílé àti Gbọ̀ngàn Ìjọba.”

9. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ nígbà “ìtànná òdòdó èwe,” báwo sì làwọn ọ̀dọ́ ṣe lè borí rẹ̀?

9 Àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n rántí Ẹlẹ́dàá wọn Atóbilọ́lá mọ̀ pé ẹ̀bùn tó yẹ kéèyàn bọ̀wọ̀ fún ni ìbálòpọ̀ jẹ́, èyí tó so pọ̀ mọ́ ìwàláàyè àti ọmọ bíbí. Nítorí náà, wọ́n mọ̀ pé àwọn tọkọtaya nìkan ni Ọlọ́run fọwọ́ sí pé kó máa jọ ní ìbálòpọ̀. (Héb. 13:4) Àmọ́ ní “ìgbà ìtànná òdòdó èwe,” ó lè nira gan-an fún ọ̀dọ́ láti yẹra fún ìwà pálapàla, nítorí ó máa ń jẹ́ ìgbà tí ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ máa ń lágbára gan-an lára àwọn ọ̀dọ́, èyí tó lè má jẹ́ kí wọ́n ṣèpinnu tó tọ́. (1 Kọ́r. 7:36) Kí lo lè ṣe tí èròkerò bá wá sí ọ lọ́kàn? Fi taratara gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè mú un kúrò lọ́kàn kó o sì máa ronú nípa àwọn ohun tó mọ́. Jèhófà máa ń gbọ́ àdúrà àwọn tó bá fi tọkàntọkàn ké pè é. (Ka Lúùkù 11:9-13.) Tó o bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó ń gbéni ró, ìyẹn náà tún lè jẹ́ kó o borí irú èròkerò bẹ́ẹ̀.

Fọgbọ́n Yan Ohun Tí Wàá Fi Ṣe Àfojúsùn Rẹ!

10. Irú èrò wo ló yẹ ká yẹra fún, àwọn ìbéèrè wo ló sì yẹ ká bi ara wa?

10 Ìdí tí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ nínú ayé fi máa ń yàyàkuyà tí wọ́n sì ń lépa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara ni pé kò sí “ìran” kankan fún wọn, ìyẹn ni pé, wọn ò mọ ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run, wọn ò sì tún ní ìrètí tó dájú pé ayé yìí ń bọ̀ wá dáa. (Òwe 29:18) Wọ́n dà bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbà ayé Aísáyà tí wọ́n ò ṣèfẹ́ Ọlọ́run, tí wọ́n kàn ń fi gbogbo ìgbésí ayé wọn lépa “ayọ̀ ńláǹlà àti ayọ̀ yíyọ̀, . . . jíjẹ ẹran àti mímu wáìnì.” (Aísá. 22:13) Dípò tí wàá fi máa jowú irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o máa ronú nípa àwọn ìlérí àgbàyanu tí Jèhófà ṣe fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́. Ẹ̀yin ọ̀dọ́ tẹ́ ẹ jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run, ṣe ẹ̀ ń fi ìháragàgà retí ayé tuntun? Ǹjẹ́ ẹ̀ ń sapá gan-an láti máa “gbé pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú . . . bí [ẹ] ti ń dúró de ìrètí aláyọ̀” tí Jèhófà ṣèlérí fún yín? (Títù 2:12, 13) Ìdáhùn yín ló máa jẹ́ kẹ́ ẹ mọ ohun tó yẹ kẹ́ ẹ fi ṣe àfojúsùn yín àtohun tó máa gbapò iwájú ní ìgbésí ayé yín.

11. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn ọ̀dọ́ Kristẹni tó ṣì wà nílé ìwé fojú sí ẹ̀kọ́ wọn dáadáa?

11 Ohun tí ayé yìí ń fẹ́ kẹ́yin ọ̀dọ́ máa lépa lójú méjèèjì ni bí ẹ ṣe máa dèèyàn pàtàkì nínú ayé. Lóòótọ́, ó yẹ kẹ́yin tẹ́ ẹ ṣì wà nílé ìwé fojú sí ẹ̀kọ́ yín dáadáa kẹ́ ẹ lè ní ìwọ̀n ẹ̀kọ́ ìwé tó yẹ. Ó ṣe tán, ìdí tẹ́ ẹ fi ń kàwé kì í ṣe torí kẹ́ ẹ kàn lè ríṣẹ́ tó jọjú ṣe, ṣùgbọ́n kẹ́ ẹ tún lè wúlò fún ìjọ, kẹ́ ẹ sì tún jẹ́ akéde tó já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Kí ẹ tó lè ṣe èyí, ẹ ní láti mọ bá a ṣe ń báni sọ́rọ̀ lọ́nà tó yéni yékéyéké, bá a ṣe ń ronú lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu àti bá a ṣe ń fi sùúrù báni sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Àmọ́ ṣá o, àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n sì ń sapá gan-an láti máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò ń gba ẹ̀kọ́ tó dára jù lọ láyé yìí, èyí tó máa múra wọn sílẹ̀ de ìyè ayérayé lọ́jọ́ ọ̀la.—Ka Sáàmù 1:1-3. a

12. Àpẹẹrẹ wo ló yẹ káwọn ìdílé tó jẹ́ Kristẹni máa tẹ̀ lé?

12 Ní Ísírẹ́lì, ohun àìgbọ́dọ̀máṣe ló jẹ́ fún òbí láti kọ́ ọmọ rẹ̀. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé òbí ló máa ń kọ́ ọmọ ní gbogbo nǹkan láyé ìgbà yẹn, pàápàá àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn àti pípa òfin Ọlọ́run mọ́. (Diu. 6:6, 7) Nítorí náà, tí ọ̀dọ́ ọmọ Ísírẹ́lì kan bá ń fetí sí ẹ̀kọ́ àwọn òbí rẹ̀ àtàwọn àgbàlagbà míì tó bẹ̀rù Ọlọ́run, yàtọ̀ sí pé á ní ìmọ̀, yóò tún ní ọgbọ́n àti ìjìnlẹ̀ òye, á sì tún jẹ́ olórí pípé. Ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run àtàwọn òfin rẹ̀ ló sì máa ń jẹ́ kéèyàn lè ní àwọn ànímọ́ àtàtà yìí. (Òwe 1:2-4; 2:1-5, 11-15) Ẹ ò rí i pé ó yẹ káwọn ìdílé tó jẹ́ Kristẹni máa kọ́ àwọn ọmọ wọn nírú ẹ̀kọ́ yìí.

Fetí sí Jèhófà Àtàwọn Tó Nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀

13. Irú ìmọ̀ràn wo làwọn ọ̀dọ́ máa ń rí gbà, kí sì nìdí tó fi yẹ kí wọ́n kíyè sára?

13 Onírúurú èèyàn ló máa ń fún àwọn ọ̀dọ́ nímọ̀ràn, títí kan àwọn agbaninímọ̀ràn ní ilé ìwé, tí ìmọ̀ràn wọn sábà máa ń dá lórí báwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe máa dèèyàn pàtàkì nínú ayé. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ máa gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó tọ́ yín sọ́nà lórí irú àwọn ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀, kẹ́ ẹ sì wá fi ohun tẹ́ ẹ ti kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ìtẹ̀jáde ẹrú olóòótọ́ àti olóye gbé e yẹ̀ wò. Ẹ ó ti mọ̀ látinú ẹ̀kọ́ Bíbélì tẹ́ ẹ kọ́ pé àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn tí kò tíì nírìírí ni Sátánì máa ń dójú sọ. Bí àpẹẹrẹ, ní ọgbà Édẹ́nì, Éfà tí ò nírìírí fetí sí Sátánì, tó jẹ́ àjèjì tí ò mọ̀ rí tí kò sì tíì ṣe nǹkan kan fún un rí láti fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Éfà ì bá má dá wàhálà sílẹ̀ ká ní Jèhófà tó fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ló gbọ́rọ̀ sí lẹ́nu.—Jẹ́n. 3:1-6.

14. Kí nìdí tó fi yẹ ká gbọ́ràn sí Jèhófà àtàwọn òbí wa tó ń sìn ín lẹ́nu?

14 Jèhófà Ẹlẹ́dàá yín náà ti fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ yín tọkàntọkàn. Kì í ṣe pé ó kàn fẹ́ kẹ́ ẹ láyọ̀ nísinsìnyí nìkan, ńṣe ló fẹ́ kẹ́ ẹ máa láyọ̀ títí láé! Bí òbí onífẹ̀ẹ́ ṣe ń bá ọmọ sọ̀rọ̀ lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ ni Jèhófà ṣe ń sọ fún ẹ̀yin àti gbogbo àwọn tó ń sìn ín pé: “Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀.” (Aísá. 30:21) Tẹ́ ẹ bá tún wá ní àwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tí wọ́n sì ń sìn ín tọkàntọkàn, ohun iyebíye lẹ ní yẹn. Ẹ fara balẹ̀ gbọ́ ìmọ̀ràn wọn nígbà tẹ́ ẹ bá ń ronú nípa ohun tẹ́ ẹ máa fi ṣe àfojúsùn yín àtohun tó máa gbawájú nígbèésí ayé yín. (Òwe 1:8, 9) Ẹ ṣáà mọ̀ pé ńṣe ni wọ́n ń fẹ́ kẹ́ ẹ ní ìyè, èyí tó ṣeyebíye gan-an ju ọrọ̀ tàbí òkìkí ayé yìí.—Mát. 16:26.

15, 16. (a) Kí ló dá wa lójú pé Jèhófà kò ní ṣe? (b) Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la rí kọ́ lára Bárúkù?

15 Àwọn tí wọ́n rántí Ẹlẹ́dàá wọn máa ń jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ wọn lọ́rùn, nítorí ó dá wọn lójú pé Jèhófà kì yóò fi wọ́n sílẹ̀ “lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ [wọ́n] sílẹ̀ lọ́nàkọnà.” (Ka Hébérù 13:5.) Irú ẹ̀mí yìí yàtọ̀ pátápátá sí ohun táyé ń fẹ́ ká ṣe, nítorí náà, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí ẹ̀mí ayé má lọ nípa lórí wa. (Éfé. 2:2) Lórí kókó yìí, ẹ wo àpẹẹrẹ Bárúkù, akọ̀wé Jeremáyà tó gbé ayé nígbà tó kù díẹ̀ kí Jerúsálẹ́mù pa run lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ní àsìkò tí nǹkan le koko.

16 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Bárúkù fẹ́ wá bó ṣe máa di ọlọ́rọ̀. Jèhófà kíyè sí èyí, ó sì fi inúure kìlọ̀ fún Bárúkù pé kó yéé wá “ohun ńláńlá” fún ara rẹ̀. Bárúkù lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ó sì jẹ́ ẹni tó gbọ́n, nítorí pé ó fetí sí Jèhófà ó sì tipa bẹ́ẹ̀ la ìparun Jerúsálẹ́mù já. (Jer. 45:2-5) Àmọ́ ní tàwọn èèyàn yòókù tó kó “ohun ńláńlá” jọ, ìyẹn ọrọ̀, tí wọ́n sì pa Jèhófà tì, wọ́n pàdánù gbogbo ọrọ̀ wọn nígbà táwọn ará Bábílónì pa ìlú náà run. Ọ̀pọ̀ sì pàdánù ẹ̀mí wọn pàápàá. (2 Kíró. 36:15-18) Ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ lára Bárúkù ni pé, níní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run ṣe pàtàkì ju ọrọ̀ àti òkìkí ayé yìí lọ.

Àpẹẹrẹ Rere Ni Kẹ́ Ẹ Máa Tẹ̀ Lé

17. Kí nìdí tí Jésù, Pọ́ọ̀lù àti Tímótì fi jẹ́ àwòkọ́ṣe àtàtà fáwa ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní?

17 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ká rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí a lè fi ṣe àwòkọ́ṣe àtàtà, kí ìyẹn lè ràn wá lọ́wọ́ bá a ṣe ń tọ ọ̀nà ìyè. Àpẹẹrẹ kan ni ti Jésù tó jẹ́ ẹni tó lẹ́bùn àbínibí jù lọ láyé yìí, síbẹ̀ ohun tó máa ṣe àwọn èèyàn láǹfààní títí láé ló gbájú mọ́, ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù “ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 4:43) Nítorí pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fẹ́ ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ó pa iṣẹ́ tí ì bá sọ ọ́ dèèyàn ńlá nínú ayé tì, ó wá ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù lójú méjèèjì. Tímótì tó jẹ́ “ojúlówó ọmọ nínú ìgbàgbọ́,” tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere Pọ́ọ̀lù. (1 Tím. 1:2) Ǹjẹ́ Jésù, Pọ́ọ̀lù àti Tímótì kábàámọ̀ ohun tí wọ́n ṣe yìí? Ó tì o! Kódà, Pọ́ọ̀lù sọ pé òun ka gbogbo mo-fẹ́-dogún mo-fẹ́-dọgbọ̀n inú ayé yìí sí “ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ pàǹtírí” lẹ́gbẹ̀ẹ́ àǹfààní tóun ní láti máa sin Ọlọ́run.—Fílí. 3:8-11.

18. Àyípadà wo ni arákùnrin kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ ṣe, kí sì nìdí tí kò fi kábàámọ̀?

18 Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni lóde òní ló ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Jésù, Pọ́ọ̀lù àti Tímótì. Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ tó ń ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń sanwó gọbọi fún un nígbà kan sọ pé: “Torí pé mò ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì, kò pẹ́ tí mo fi ń rí ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́ mi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé owó ńlá ló ń wọlé fún mi, ńṣe ló dà bíi pé ẹ̀fúùfù ni mò ń lépa. Nígbà tí mo wá sọ fún àwọn ọ̀gá ilé iṣẹ́ wa pé mo fẹ́ lọ máa ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkùn, kíá ni wọ́n láwọn máa fowó kún owó oṣù mi, ní ìrètí pé màá yí èrò mi padà. Àmọ́ mi ò yí ìpinnu mi padà. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò rídìí tí mo fi ní láti fi iṣẹ́ olówó ńlá yẹn sílẹ̀ nítorí iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Ohun tí mo máa ń sọ fún wọn ni pé mo fẹ́ ṣe ohun tí mo jẹ́jẹ̀ẹ́ nígbà tí mo ya ara mi sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Nísinsìnyí tó jẹ́ pé iṣẹ́ Ọlọ́run ni mo gbájú mọ́, mo láyọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn tó jẹ́ pé owó àti òkìkí ò lè fún mi.”

19. Ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání wo la rọ àwọn ọ̀dọ́ pé kí wọ́n ṣe?

19 Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀dọ́ káàkiri ayé ló ti ṣe irú ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání yẹn. Nítorí náà, ẹ̀yin ọ̀dọ́, tẹ́ ẹ bá ń ronú nípa ohun tẹ́ ẹ máa fayé yín ṣe, ẹ máa fi ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí. (2 Pét. 3:11, 12) Ẹ má ṣe jowú àwọn tó ń rí towó ṣe nínú ayé yìí. Jèhófà àtàwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ni kẹ́ ẹ máa fetí sí. Ńṣe ni kẹ́ ẹ “to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín ní ọ̀run,” nítorí ìyẹn ni ìṣúra tó dára jù lọ, òun nìkan ló sì máa ṣe yín láǹfààní títí láé. (Mát. 6:19, 20; ka 1 Jòhánù 2:15-17.) Ẹ má gbàgbé o, ẹ rántí Ẹlẹ́dàá yín Atóbilọ́lá. Tẹ́ ẹ bá ń rántí Jèhófà, yóò máa bù kún yín.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọ̀rọ̀ nípa lílọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga àti iṣẹ́ wà nínú Ilé Ìṣọ́, October 1, 2005, ojú ìwé 26 sí 31.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Báwo la ṣe ń fi hàn pé Ọlọ́run la gbẹ́kẹ̀ lé?

• Ẹ̀kọ́ wo ló ṣàǹfààní jù lọ?

• Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ lára Bárúkù?

• Àwọn wo ló jẹ́ àwòkọ́ṣe àtàtà fún wa, kí sì nìdí?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Jèhófà ló ń kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ tó ṣàǹfààní jù lọ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Bárúkù gbọ́rọ̀ sí Jèhófà lẹ́nu ó sì la ìparun Jerúsálẹ́mù já. Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ lára rẹ̀?