Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìgbéyàwó Àti Ọmọ Bíbí Lákòókò Òpin Yìí

Ìgbéyàwó Àti Ọmọ Bíbí Lákòókò Òpin Yìí

Ìgbéyàwó Àti Ọmọ Bíbí Lákòókò Òpin Yìí

“Àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti dín kù.”—1 KỌ́R. 7:29.

1. (a) Àwọn àyípadà tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí wo ló wà lára àwọn ohun tó mú kí àkókò yìí “nira láti bá lò”? (b) Kí nìdí táwọn àyípadà tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé kò fi fi wá lọ́kàn balẹ̀?

 Ọ̀RỌ̀ Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé ogun, ìsẹ̀lẹ̀, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn tó lékenkà yóò jẹ́ ká mọ̀ pé a ti wà ní “àkókò òpin.” (Dán. 8:17, 19; Lúùkù 21:10, 11) Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé àkókò wa yìí yóò jẹ́ àkókò kan táwọn àyípadà ńlá yóò máa wáyé nínú àjọṣe àwọn èèyàn. Gbọ́nmi-sí-i omi-ò-to nínú ìdílé wà lára àwọn nǹkan tó mú kí àwọn “ọjọ́ ìkẹyìn” tí ó le koko yìí “nira láti bá lò.” (2 Tím. 3:1-4) Kí nìdí táwọn àyípadà yìí kò fi fi wá lọ́kàn balẹ̀? Ìdí ni pé, wọ́n gbilẹ̀ wọ́n sì lágbára débi pé wọ́n lè nípa lórí ojú táwa Kristẹni á máa fi wo ìgbéyàwó àti ọmọ bíbí. Lọ́nà wo?

2. Irú ojú wo ni aráyé fi ń wo ìgbéyàwó àti ìkọ̀sílẹ̀?

2 Lóde òní, ìkọ̀sílẹ̀ ti dohun tó rọrùn tó sì wọ́pọ̀ gan-an, iye àwọn tí wọ́n ń kọ ara wọn sílẹ̀ lọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè sì túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Àmọ́, kò yẹ ká gbàgbé pé ojú tí Jèhófà Ọlọ́run fi ń wo ètò ìgbéyàwó àti ìkọ̀sílẹ̀ yàtọ̀ pátápátá sí ojú táráyé fi ń wò ó. Irú ojú wo ni Jèhófà fi ń wò ó?

3. Ojú wo ni Jèhófà àti Jésù Kristi fi ń wo ìgbéyàwó?

3 Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ káwọn tọkọtaya pa ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó wọn mọ́. Nígbà tó so ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya, ó sọ pé: “Ọkùnrin . . . yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.” Jésù Kristi náà tún gbólóhùn yìí sọ nígbà tó yá, ó wá fi kún un pé: “Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” Ó tún sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, bí kò ṣe lórí ìpìlẹ̀ àgbèrè, tí ó sì gbé òmíràn níyàwó, ṣe panṣágà.” (Jẹ́n. 2:24; Mát. 19:3-6, 9) Nítorí náà, lójú Jèhófà àti Jésù, ìdè ìgbéyàwó jẹ́ ohun tó wà títí lọ, tó jẹ́ pé ikú nìkan ló lè fòpin sí i. (1 Kọ́r. 7:39) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run ló dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀, kò yẹ kéèyàn fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀rọ̀ ìkọ̀sílẹ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pàápàá sọ pé Jèhófà kórìíra ìkọ̀sílẹ̀ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. aKa Málákì 2:13-16; 3:6.

Fọwọ́ Pàtàkì Mú Ìdílé Rẹ

4. Kí nìdí táwọn ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ Kristẹni fi máa ń kábàámọ̀ pé àwọn ti tètè ṣègbéyàwó jù?

4 Ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ gba àwọn èèyàn inú ayé aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run yìí lọ́kàn. Ojoojúmọ́ ni wọ́n sì ń gbé ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwòrán oníṣekúṣe jáde. A ò kàn lè gbójú fo ọṣẹ́ tí wọ́n lè ṣe fún wa, pàápàá ipa tó ń ní lórí àwọn ọ̀dọ́ wa nínú ìjọ. Kí ló yẹ kó jẹ́ ìṣarasíhùwà àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ Kristẹni nípa irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, tó lè mú kí ọkàn wọn máa fà sí ìbálòpọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò fẹ́ bẹ́ẹ̀? Àwọn kan máa ń torí ìyẹn lọ fẹ́yàwó tàbí kí wọ́n lọ́kọ nígbà tí wọ́n ṣì kéré lọ́jọ́ orí. Wọ́n rò pé ìyẹn ni kò ní jẹ́ káwọn ṣèṣekúṣe. Àmọ́, kì í pẹ́ táwọn kan fi máa ń kábàámọ̀ ìgbésẹ̀ tí wọ́n gbé yìí. Kí nìdí? Nígbà tí wọ́n bá di tọkọtaya tójú wọn sì ti wá wálẹ̀, wọ́n á wá rí i pé ìwà àwọn méjèèjì kò bára mu rárá. Ìyẹn ni kì í fi í pẹ́ tí ìṣòro ńlá fi máa ń yọjú láàárín wọn.

5. Kí ni tọkọtaya ní láti mọ̀ tí yóò jẹ́ kí wọ́n lè pa ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó wọn mọ́? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

5 Tí ìwà ẹni tẹ́nì kan fẹ́ bá lọ yàtọ̀ sóhun tó rò pé ó jẹ́ kí wọ́n tó di tọkọtaya, ìṣòro ńlá ló máa ń dá sílẹ̀, kódà báwọn méjèèjì jẹ́ Kristẹni. (1 Kọ́r. 7:28) Àmọ́, bí ìṣòro àárín tọkọtaya bá tiẹ̀ pọ̀ gan-an, àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ pé ìkọ̀sílẹ̀ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu kọ́ ni yóò yanjú ìṣòro wọn. Nítorí náà, àwọn tí wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí ìdílé wọn lè wà níṣọ̀kan láti lè pa ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó wọn mọ́, yẹ lẹ́ni táwọn ará ń yìn tí wọ́n sì ń fi tìfẹ́tìfẹ́ ràn lọ́wọ́. b

6. Kí lohun tó yẹ káwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni fi sọ́kàn nípa ìgbà tó yẹ kí wọ́n ṣègbéyàwó?

6 Ṣé ọ̀dọ́ tí ò tíì ṣègbéyàwó ni ọ́? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kí lohun tó yẹ kó o fi sọ́kàn nípa ìgbà tó yẹ kó o ṣègbéyàwó? Wàá bọ́ lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ ìbànújẹ́ tó o bá dúró dìgbà tó o dàgbà tó, tó o lóye tó, tí òtítọ́ sì jinlẹ̀ dáadáa nínú rẹ kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ ẹnì kan nínú ìjọ Kristẹni. Lóòótọ́, Ìwé Mímọ́ kò sọ ọjọ́ orí kan pàtó tó yẹ kéèyàn lọ́kọ tàbí láya. c Ṣùgbọ́n, Bíbélì fi hàn pé á dára kó o dúró dìgbà tó o bá kọjá ìgbà ìtànná òdòdó èwe tó jẹ́ àsìkò tí ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ máa ń lágbára gan-an. (1 Kọ́r. 7:36) Kí nìdí tó fi dára kó o dúró dìgbà yẹn? Nítorí pé ìháragàgà láti ní ìbálòpọ̀ lè má jẹ́ kó o lè ronú dáadáa, kó o wá lọ ṣèpinnu tá jẹ́ kó o jẹ̀ka àbámọ̀ lọ́jọ́ ọ̀la. Máa rántí pé ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tí Jèhófà pèsè lórí ìgbéyàwó wà nínú Bíbélì fún àǹfààní àti ayọ̀ rẹ.—Ka Aísáyà 48:17, 18.

Òbí Tó Mọṣẹ́ Rẹ̀ Níṣẹ́

7. Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tọkọtaya tí wọ́n ṣì kéré lọ́jọ́ orí, kí sì nìdí tí èyí fi lè fa ìṣòro láàárín wọn?

7 Àwọn ọ̀dọ́ tó tètè ṣègbéyàwó lè bímọ nígbà tó yẹ káwọn fúnra wọn ṣì wà lábẹ́ òbí wọn. Wọ́n lè má tíì mọwọ́ ara wọn dáadáa tọ́mọ fi dé, bẹ́ẹ̀, ọmọ máa ń fẹ́ àbójútó ní gbogbo ìgbà. Tó bá wá di pé ìyàwó ń fi gbogbo àkókò rẹ̀ tọ́jú ọmọ, ọkọ rẹ̀ tó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́ lè bẹ̀rẹ̀ sí í jowú pé ó pa òun tì. Bákan náà, àìsùn nítorí ọmọ lè fa ìdààmú tó lè mú káwọn méjèèjì máa kanra mọ́ ara wọn. Wọ́n lè wá rí i pé àwọn ò lómìnira láti ṣe ohun tó wù wọ́n tàbí kí wọ́n má lè lọ síbi tó wù wọ́n bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Ojú wo ló yẹ kí wọ́n máa fi wo àyípadà tó dé bá wọn yìí?

8. Irú ọwọ́ wo ló yẹ káwọn òbí máa fi mú ojúṣe wọn, kí sì nìdí?

8 Bó ṣe yẹ kí tọkọtaya fọwọ́ pàtàkì mú ìdè ìgbéyàwó wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ṣe gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bí òbí torí Ọlọ́run ló gbé iṣẹ́ yẹn lé wọn lọ́wọ́. Nítorí náà, ìyípadà yòówù kí ọmọ tí wọ́n bí mú bá tọkọtaya kan tó jẹ́ Kristẹni, ó yẹ kí wọ́n sa gbogbo ipá wọn láti ṣe àyípadà yìí lọ́nà tó máa fi hàn pé wọ́n mọṣẹ́ wọn níṣẹ́. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jèhófà ló dá àwa èèyàn pé ká máa bímọ, àwọn òbí gbọ́dọ̀ gbà pé ọmọ tuntun yìí jẹ́ “ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.” (Sm. 127:3) Kí bàbá àti ìyá tó jẹ́ Kristẹni rí i dájú pé àwọn ṣe ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bí ‘òbí ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Olúwa.’—Éfé. 6:1.

9. (a) Iṣẹ́ wo ló wà nínú ọmọ títọ́? (b) Kí lọkọ lè ṣe láti ran ìyàwó rẹ̀ lọ́wọ́ kí ìgbòkègbodò ìjọsìn rẹ̀ má bàa jó rẹ̀yìn?

9 Àwọn òbí máa ń jìyà gan-an lórí ọmọ kó tó dàgbà. Ó máa ń gba ọ̀pọ̀ àkókò àti ìsapá. Ọkọ tó jẹ́ Kristẹni ní láti mọ̀ pé fọ́dún mélòó kan lẹ́yìn tí wọ́n bá bímọ, ó ṣeé ṣe kí ìyàwó òun má lè pọkàn pọ̀ nípàdé lọ́pọ̀ ìgbà, kó má sì fi bẹ́ẹ̀ ráyè fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti ṣíṣe àṣàrò. Èyí sì lè jẹ́ kí ìgbòkègbodò ìjọsìn rẹ̀ jó rẹ̀yìn dé ìwọ̀n àyè kan. Ọkọ tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́ yóò ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe láti bójú tó ọmọ náà láìdá gbogbo rẹ̀ dá ìyàwó rẹ̀. Ó lè máa sọ àwọn ohun tó ṣeé ṣe kí ìyàwó rẹ̀ pàdánù nínú ìpàdé fún un nílé. Ó sì tún lè máa bá ìyàwó rẹ̀ tọ́jú ọmọ kó lè ṣeé ṣe fún ìyàwó láti máa kópa tó jọjú nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run.—Ka Fílípì 2:3, 4.

10, 11. (a) Báwo làwọn òbí ṣe lè kọ́ ọmọ wọn ní “ìlànà èrò orí Jèhófà”? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbóríyìn fún ọ̀pọ̀ òbí tó jẹ́ Kristẹni?

10 Ojúṣe òbí tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́ ju pé kó kàn pèsè oúnjẹ, aṣọ àti ibùgbé fún ọmọ, kó sì máa bójú tó ọ̀rọ̀ ìlera rẹ̀. Ní pàtàkì, lákòókò òpin tó jẹ́ ìgbà ewu yìí, àtikékeré ló yẹ káwọn òbí ti máa kọ́ ọmọ wọn ní ìlànà ìwà rere tó yẹ kí wọ́n máa tẹ̀ lé. Kí wọ́n fi “ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà” tọ́ wọn dàgbà. (Éfé. 6:4) Ohun tí kíkọ́ ọmọ ní “ìlànà èrò orí” yìí túmọ̀ sí ni pé kí òbí ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbin èrò Jèhófà sọ́kàn ọmọ láti kékeré jòjòló títí dìgbà táá fi dẹni tó bàlágà, ìyẹn ìgbà tó máa ń ṣòro fún ọmọ láti gba ìbáwí.—2 Tím. 3:14, 15.

11 Ó dájú pé, nígbà tí Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n “máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn,” ó fẹ́ káwọn òbí mọ̀ pé ọmọ wọn náà wà lára àwọn tí wọ́n ní láti ràn lọ́wọ́ kí wọ́n di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:19, 20) Èyí ò sì rọrùn nítorí aráyé máa ń fẹ́ sọ àwọn ọmọ dà bí wọ́n ṣe dà. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ kí gbogbo wa máa gbóríyìn fáwọn òbí tó bá ṣeé ṣe fún láti tọ́ ọmọ wọn tó fi di Kristẹni tó ṣèrìbọmi. Nítorí pé wọ́n ti tipa ìgbàgbọ́ àti ìṣòtítọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí òbí tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́ “ṣẹ́gun” ipa búburú tí ayé máa ń ní lórí àwọn ọmọ.—1 Jòh. 5:4.

Wíwà Láìlọ́kọ, Láìláya Tàbí Láìbímọ fún Ìdí Rere

12. Kí nìdí táwọn Kristẹni kan fi pinnu láti wà láìlọ́kọ tàbí láìláya fún àkókò kan?

12 Nítorí pé “àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti dín kù” àti pé “ìrísí ìran ayé yìí ń yí padà,” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá níyànjú pé ká wò ó bóyá yóò ṣeé ṣe fún wa láti wà láìlọ́kọ tàbí láìláya nítorí iṣẹ́ Ọlọ́run. (1 Kọ́r. 7:29-31) Ìdí nìyí táwọn Kristẹni kan fi máa ń pinnu láti wà láìlọ́kọ tàbí láìláya títí ọjọ́ ayé wọn tàbí fún àkókò kan kí wọ́n tó fẹ́ ẹnì kan. Inú wa dùn pé, wọ́n ò lo àkókò tí wọ́n fi wá láìṣègbéyàwó láti máa fi wá bí wọ́n á ṣe kó ọrọ̀ jọ. Ọ̀pọ̀ ló pinnu láti wà láìṣègbéyàwó kí wọ́n báa lè máa sin Jèhófà “láìsí ìpínyà-ọkàn.” (Ka 1 Kọ́ríńtì 7:32-35.) Àwọn Kristẹni kan tí wọn kò lọ́kọ tàbí láya ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà àwọn míì sì ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Àwọn míì sapá láti dójú ìlà ohun tí wọ́n á fi lè lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ kí wọ́n lè túbọ̀ wúlò fún ètò Jèhófà. Ká sòótọ́, àwọn tó ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún fún àkókò kan kí wọ́n tó fẹ́ ẹnì kan sábà máa ń rí i pé ìdílé wọn ń jàǹfààní látinú ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti kọ́ ní gbogbo àkókò náà.

13. Kí nìdí táwọn tọkọtaya kan tó jẹ́ Kristẹni fi pinnu pé àwọn kò ní bímọ?

13 Àyípadà míì tún wà tó ń bá ìdílé láwọn apá ibi kan láyé, ìyẹn ni bí ọ̀pọ̀ tọkọtaya ṣe ń pinnu láti wà láìbímọ. Àwọn kan máa ń ṣe irú ìpinnu yìí torí àtilè gbọ́ bùkátà, àwọn míì sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ torí kí wọ́n lè ráyè wá iṣẹ́ tá máa mówó gọbọi wọlé. Àwọn tọkọtaya míì tó jẹ́ Kristẹni náà máa ń pinnu pé àwọn ò ní bímọ. Ìdí tí wọ́n fi sábà máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọn ò fẹ́ kí ohunkóhun dí wọn lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Àmọ́, èyí ò túmọ̀ sí pé ìgbésí ayé ìdílé wọn yàtọ̀ sí tàwọn tọkọtaya yòókù o. Ńṣe ni wọ́n fẹ́ fi ire Ìjọba Ọlọ́run ṣáájú àwọn ìbùkún kan tí wọ́n lè rí nínú ìgbéyàwó. (1 Kọ́r. 7:3-5) Díẹ̀ lára àwọn tọkọtaya yìí jẹ́ alábòójútó àyíká, àwọn míì jẹ́ alábòójútó àgbègbè, àwọn kan ń sin ní Bẹ́tẹ́lì, àwọn kan ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà àwọn kan sì jẹ́ míṣọ́nnárì. Gbogbo wọn ń tipa báyìí sin Jèhófà àtàwọn arákùnrin wọn. Jèhófà ò sì ní gbàgbé iṣẹ́ wọn àti ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn fún orúkọ rẹ̀.—Héb. 6:10.

“Ìpọ́njú Nínú Ẹran Ara”

14, 15. “Ìpọ́njú nínú ẹran ara” wo làwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni lè ní?

14 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn tọkọtaya tó jẹ́ Kristẹni pé wọ́n yóò ní “ìpọ́njú nínú ẹran ara wọn.” (1 Kọ́r. 7:28) Ó lè jẹ́ àìlera tiwọn tàbí tàwọn ọmọ wọn tàbí tàwọn òbí ló máa fa ìpọ́njú yìí. Ó tún lè jẹ́ ìṣòro àti ìdààmú tó wà nínú ọmọ títọ́. Bá a ṣe sọ ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé “ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà.” Lára àwọn ohun tó sì máa nira láti bá lò ni báwọn ọmọ kan á ṣe jẹ́ “aṣàìgbọràn sí òbí.”—2 Tím. 3:1-3.

15 Kì í ṣe nǹkan tó rọrùn fáwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni láti tọ́ ọmọ dàgbà. Àwọn ìṣòro tí “àkókò lílekoko” yìí ń fà kò yọ àwa náà sílẹ̀. Torí náà àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni kò gbọ́dọ̀ dẹwọ́ nínú bí wọ́n ṣe ń sapá kí “ètò àwọn nǹkan ti ayé yìí” má bàa ní ipa búburú lórí àwọn ọmọ wọn. (Éfé. 2:2, 3) Àmọ́ kì í ṣe gbogbo ìgbà làwọn òbí máa ń borí. “Ìpọ́njú” gidi ló jẹ́ fún òbí tí ọmọ kan tí wọ́n tọ́ dàgbà nínú ìdílé Kristẹni bá lóun ò sin Jèhófà mọ́, lẹ́yìn táwọn òbí rẹ̀ tí sapá gan-an láti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.—Òwe 17:25.

“Ìpọ́njú Ńlá Yóò Wà”

16. “Ìpọ́njú” wo ni Jésù sọ tẹ́lẹ̀?

16 Kékeré ni “ìpọ́njú” yòówù kéèyàn ní nínú ìdílé àti lórí ọmọ títọ́ máa jẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀ lọ́nà. Nígbà tí Jésù ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wíwàníhìn-ín rẹ̀ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan, ó ní: “Ìpọ́njú ńlá yóò wà, irúfẹ́ èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí, rárá o, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò tún ṣẹlẹ̀ mọ́.” (Mát. 24:3, 21) Jésù wá jẹ́ ká mọ̀ pé ogunlọ́gọ̀ ńlá máa la “ìpọ́njú ńlá” yìí já. Àmọ́ kì í ṣe lójú bọ̀rọ̀, torí pé ńṣe ni ètò Sátánì yóò máa bá ìjà lílekoko tó ń bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n jẹ́ èèyàn àlàáfíà jà nìṣó títí ètò Sátánì fi máa pa rẹ́. Dájúdájú, àkókò tó lè koko ló máa jẹ́ fún tọmọdé tàgbà.

17. (a) Kí nìdí tí ọkàn wa fi lè balẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la? (b) Kí ló yẹ kó máa darí èrò wa tó bá dọ̀rọ̀ ìgbéyàwó àti ọmọ bíbí?

17 Àmọ́ ṣá, kò yẹ ká wá máa gbọ̀n jìnnìjìnnì torí ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la. Ọkàn àwọn òbí tó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà balẹ̀ pé Jèhófà yóò dáàbò bo àwọn àtàwọn ọmọ wọn. (Ka Aísáyà 26:20, 21; Sef. 2:2, 3; 1 Kọ́r. 7:14) Ṣùgbọ́n ní báyìí, ẹ jẹ́ kí ohun tá a mọ̀ nípa àkókò lílekoko tá à ń gbé yìí máa darí èrò wa tó bá dọ̀rọ̀ ìgbéyàwó àti ọmọ bíbí lákòókò òpin yìí. (2 Pét. 3:10-13) Nípa bẹ́ẹ̀, yálà a ṣègbéyàwó tàbí a wà láìlọ́kọ tàbí láìláya, bóyá á bímọ tàbí a ò bímọ, ìgbé ayé wa yóò máa gbé Jèhófà àti ìjọ Kristẹni ga.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àkòrí tó sọ pé “Òun Kórìíra Ìkọ̀sílẹ̀,” nínú ìwé Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn, ojú ìwé 125.

b Tí tọkọtaya tó ní ìṣòro bá ka àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí ìgbéyàwó tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ September 15, 2003 àti   àti   àti   àti Jí! January 8, 2001 yóò ràn wọ́n lọ́wọ́.

c Wo àkòrí 30 nínú ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́. Àkòrí náà sọ pé, “Mo Ha Ti Ṣetan fun Igbeyawo Bi?”

Àtúnyẹ̀wò

• Kí nìdí tí kò fi yẹ káwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni kánjú láti lọ́kọ tàbí láya?

• Iṣẹ́ wo ló wà nínú ọmọ títọ́?

• Kí nìdí táwọn Kristẹni kan fi pinnu láti wà láìlọ́kọ tàbí láìláya tàbí táwọn tọkọtaya kan fi pinnu láti má ṣe bímọ?

• “Ìpọ́njú” wo làwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni lè ní?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé káwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni dàgbà tó kí wọ́n tó ṣègbéyàwó?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ó yẹ kí ọkọ máa ran aya rẹ̀ lọ́wọ́ kó lè máa kópa tó jọjú nínú ìgbòkègbodò ìjọsìn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Kí nìdí táwọn tọkọtaya tó jẹ́ Kristẹni kan fi máa ń pinnu pé àwọn ò ní bímọ?