Jẹ́ Kí Ọlọ́run Máa Ṣamọ̀nà Rẹ Nínú Ohun Gbogbo
Jẹ́ Kí Ọlọ́run Máa Ṣamọ̀nà Rẹ Nínú Ohun Gbogbo
“Ọlọ́run yìí, Ọlọ́run wa ni fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé. Òun fúnra rẹ̀ yóò máa ṣamọ̀nà wa títí a ó fi kú.”—SM. 48:14.
1, 2. Kí nìdí tá a fi ní láti tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà dípò ká gbẹ́kẹ̀ lé ọgbọ́n orí ara wa, àwọn ìbéèrè wo ló sì yọjú?
TÁ A bá ń sọ nípa àwọn ohun tí kò ní láárí tàbí àwọn ohun tó léwu, ó rọrùn fún wa láti máa tan ara wa jẹ pé àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ò burú. (Òwe 12:11) Tá a bá dìídì fẹ́ ṣe nǹkan tí kò yẹ Kristẹni, ọkàn wa lè máa wá oríṣiríṣi àwáwí tá mú ká rò pé ohun tá a fẹ́ ṣe yẹn kò burú. (Jer. 17:5, 9) Ìdí nìyẹn tí àdúrà onísáàmù náà fi mọ́gbọ́n dání nígbà tó bẹ Jèhófà pé: “Rán ìmọ́lẹ̀ rẹ àti òtítọ́ rẹ jáde. Kí ìwọ̀nyí máa ṣamọ̀nà mi.” (Sm. 43:3) Ọgbọ́n Jèhófà ló gbẹ́kẹ̀ lé, kì í ṣe ọgbọ́n ara rẹ̀ tí ò tó nǹkan. Kò sì sẹ́lòmíì tó fi ṣe amọ̀nà rẹ̀ ju Jèhófà lọ. Gẹ́gẹ́ bíi ti onísáàmù yẹn, ó yẹ ká jẹ́ kí Ọlọ́run máa tọ́ wa sọ́nà.
2 Àmọ́, kí nìdí tó fi yẹ ká gbà pé ìtọ́sọ́nà Jèhófà ló dára jù lọ? Ìgbà wo ló yẹ ká wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà? Irú ẹ̀mí wo ló yẹ ká ní ká bàa lè jàǹfààní ìtọ́sọ́nà Jèhófà, báwo ló sì ṣe ń ṣamọ̀nà wa lónìí? Àwọn ìbéèrè pàtàkì yìí la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí.
Kí Nìdí Tá A Fi Ní Láti Gbà Kí Jèhófà Máa Ṣamọ̀nà Wa?
3-5. Nítorí àwọn ìdí wo ló fi yẹ ká gbà pátápátá pé kí Jèhófà máa ṣamọ̀nà wa?
3 Jèhófà ni Bàbá wa tí ń bẹ lọ́run. (1 Kọ́r. 8:6) Òun ló mọ wá, tó mọ̀ wá, tó sì mọ ohun tó wà nínú ọkàn wa. (1 Sám. 16:7; Òwe 21:2) Dáfídì Ọba sọ fún Ọlọ́run pé: “Ìwọ alára ti wá mọ jíjókòó mi àti dídìde mi. Ìwọ ti gbé ìrònú mi yẹ̀ wò láti ibi jíjìnnàréré. Nítorí tí kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi, ṣùgbọ́n, wò ó! Jèhófà, ìwọ ti mọ gbogbo rẹ̀ tẹ́lẹ̀.” (Sm. 139:2, 4) Níwọ̀n bí Jèhófà ti mọ̀ wá tinú tòde, ṣó wá yẹ ká ṣiyè méjì pé ó mọ ohun tó dáa jù lọ fún wa? Yàtọ̀ síyẹn, ọgbọ́n Jèhófà kò láàlà. Ó rí ohun gbogbo, ó sì ń wo kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun téèyàn kankan ò lè rí, ó lè mọ ìparí ọ̀ràn kan látìbẹ̀rẹ̀ ọ̀ràn náà. (Aísá. 46:9-11; Róòmù 11:33) Òun ni “Ọlọ́run, ẹnì kan ṣoṣo tí ó gbọ́n.”—Róòmù 16:27.
4 Síwájú sí i, Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa ó sì ń fẹ́re fún wa. (Jòh. 3:16; 1 Jòh. 4:8) Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ ni, ó sì ń pèsè àwọn ohun tá a nílò fún wa lọ́pọ̀ yanturu. Ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó ń jẹ́ Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé jẹ́ láti òkè, nítorí a máa sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Baba àwọn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá.” (Ják. 1:17) Tá a bá ń jẹ́ kí Ọlọ́run máa ṣamọ̀nà wa, a ó jàǹfààní tí kò láfiwé látinú ìwà ọ̀làwọ́ rẹ̀.
5 Lákòótán, alágbára ńlá ni Jèhófà. Onísáàmù kan sọ nípa èyí, pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń gbé ibi ìkọ̀kọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ yóò rí ibùwọ̀ fún ara rẹ̀ lábẹ́ òjìji Olódùmarè. Ṣe ni èmi yóò wí fún Jèhófà pé: ‘Ìwọ ni ibi ìsádi mi àti ibi odi agbára mi, Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi yóò gbẹ́kẹ̀ lé dájúdájú.’” (Sm. 91:1, 2) Tá a bá ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà, ibi tó dára jù lọ la wá ààbò lọ yẹn, torí pé ààbò Ọlọ́run dájú lórí wa. Kódà táwọn èèyàn bá ń ṣenúnibíni sí wa, Jèhófà yóò tì wá lẹ́yìn. Kò ní já wa kulẹ̀. (Sm. 71:4, 5; Ka Òwe 3:19-26.) Bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn, Jèhófà ló mọ ohun tó yẹ wá jù lọ, ohun tó yẹ wá jù lọ ló ń fẹ́ fún wa, ó sì lágbára láti ṣe ohun tó yẹ wá jù lọ fún wa. Ẹ ò rí i pé ìwà òmùgọ̀ ló jẹ́ tá ò bá gbà kó ṣamọ̀nà wa! Àmọ́ ṣá, ìgbà wo gan-an la nílò ìtọ́sọ́nà yẹn?
Ìgbà Wo La Nílò Ìtọ́sọ́nà Jèhófà?
6, 7. Àwọn ìgbà wo la nílò ìtọ́sọ́nà Jèhófà?
6 Ká sòótọ́, a nílò ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run látìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ ayé wa títí dọjọ́ alẹ́. Onísáàmù kan sọ pé: “Ọlọ́run yìí, Ọlọ́run wa ni fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé. Òun fúnra rẹ̀ yóò máa ṣamọ̀nà wa títí a ó fi kú.” (Sm. 48:14) Bíi ti onísáàmù yẹn, àwọn Kristẹni tó gbọ́n kì í yéé wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run títí ayé wọn.
7 Àmọ́ ṣá, àwọn ìgbà míì wà tó máa ń ṣe wá bíi pé ká rí ìrànlọ́wọ́ ojú ẹsẹ̀. Nígbà míì, a lè wà nínú “hílàhílo,” bóyá inúnibíni ló dojú kọ wá tàbí a wà nínú àìsàn tó le koko, ó sì lè jẹ́ pé iṣẹ́ ló dédé bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́. (Sm. 69:16, 17) Nírú àkókò báyìí, tá a bá fọ̀rọ̀ náà lọ Jèhófà a óò rí ìtùnú, ọkàn wa á balẹ̀ pé ó máa fún wa lókun láti fara dà á, yóò sì ṣamọ̀nà wa ká lè ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. (Ka Sáàmù 102:17.) Àmọ́ a tún nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ láwọn ìgbà míì. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn, a nílò ìtọ́sọ́nà Jèhófà tá a bá fẹ́ kí ìwàásù náà sèso rere. Nígbàkigbà tá a bá sì fẹ́ ṣèpinnu, bóyá lórí ọ̀ràn eré ìtura, ìwọṣọ àti ìmúra, àwọn tá a fẹ́ máa bá rìn tàbí lórí ọ̀ràn èyíkéyìí míì, ohun tó mọ́gbọ́n dání ni pé ká tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà. Ní tòdodo, a nílò ìtọ́sọ́nà lórí gbogbo ohun tá a bá dáwọ́ lé nígbèésí ayé wa.
Ó Léwu Tá Ò Bá Jẹ́ Kí Ọlọ́run Máa Ṣamọ̀nà Wa
8. Kí ni jíjẹ tí Éfà jẹ èso tí Ọlọ́run kà léèwọ̀ yẹn túmọ̀ sí?
8 Àmọ́ ṣá o, rántí pé ńṣe ló yẹ kí títẹ̀lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà ti ọkàn wa wá. Ọlọ́run ò ní fipá ṣamọ̀nà wa. Èèyàn àkọ́kọ́ tó kọ̀ láti jẹ́ kí Jèhófà ṣamọ̀nà òun ni Éfà, àbájáde rẹ̀ sì jẹ́ ká rí bí irú ìpinnu yẹn ṣe burú tó. Tún wo ohun tí ìgbésẹ̀ tó gbé yẹn túmọ̀ sí. Éfà jẹ èso tí Jèhófà kà léèwọ̀ torí pé ó fẹ́ “dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.” (Jẹ́n. 3:5) Ohun tó ṣe yẹn fi hàn pé ó fẹ́ fi ara rẹ̀ sípò Ọlọ́run, ó fẹ́ máa fúnra rẹ̀ pinnu ohun tó dáa àtohun tó burú, dípò kó máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà. Bó ṣe kẹ̀yìn sí Jèhófà tó jẹ́ aláṣẹ láyé àti lọ́run nìyẹn. Kò fẹ́ kẹ́nì kankan máa darí òun. Ádámù ọkọ rẹ̀ náà bá a lọ́wọ́ nínú ọ̀tẹ̀ yẹn.—Róòmù 5:12.
9. Tá a bá ń kọ ìtọ́sọ́nà Jèhófà sílẹ̀, kí là ń fìyẹn sọ, kí sì nìdí tó fi jẹ́ ìwà òmùgọ̀ pátápátá?
9 Lónìí, táwa náà ò bá gbà kí Jèhófà máa ṣamọ̀nà wa, ńṣe là ń ṣe bíi ti Éfà tí kò gbà pé Ọlọ́run ni aláṣẹ láyé àtọ̀run. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ẹnì kan tó ti mọ́ lára láti máa wo àwòrán arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè. Tó bá jẹ́ pé Kristẹni lonítọ̀hún, á ti mọ ìlànà Jèhófà lórí ọ̀ràn yìí. Ọlọ́run sọ pé ká má tiẹ̀ mẹ́nu kan àwọn ohun àìmọ̀ láàárín wa, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé ẹnì kan ń wo ohun àìmọ́ fún ìgbádùn. (Éfé. 5:3) Tẹ́nì kan bá ń kọ ìtọ́sọ́nà Jèhófà sílẹ̀, ohun tónítọ̀hún ń sọ ni pé Jèhófà kọ́ ni aláṣẹ, pé òun kọ́ ni olórí. (1 Kọ́r. 11:3) Ìwà òmùgọ̀ pátápátá gbáà nìyẹn, torí Jeremáyà sọ pé: “Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Jer. 10:23.
10. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa lo òmìnira tí Ọlọ́run fún wa láti ṣe ohun tó wù wá lọ́nà tó fi hàn pé a máa jíhìn?
10 Àwọn kan lè má gba ohun tí Jeremáyà sọ yẹn, wọ́n lè sọ pé tó bá jẹ́ pé Jèhófà máa bínú sí wa tá a bá lo òmìnira wa bó ṣe wù wá, kò yẹ kó fún wa lómìnira ọ̀hún rárá. Ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé pé òmìnira tá a ní láti ṣe ohun tó wù wá jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, èyí ló sì máa jẹ́ ká jíhìn ohun tá a bá ṣe. A máa jíhìn fún Ọlọ́run lórí ohun tá a yàn láti ṣe àtohun tá a fẹnu wa sọ. (Róòmù 14:10) Jésù sọ pé: “Lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu ń sọ.” Ó tún sọ pé: “Láti inú ọkàn-àyà ni àwọn èrò burúkú ti ń wá, ìṣìkàpànìyàn, panṣágà, àgbèrè, olè jíjà, àwọn èké gbólóhùn ẹ̀rí, àwọn ọ̀rọ̀ òdì.” (Mát. 12:34; 15:19) Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ tó ń jáde lẹ́nu wa àti ìwà tá à ń hù fi bí ọkàn wa ṣe rí hàn. Wọ́n jẹ́ ká mọ irú ẹni tá a jẹ́ gan-an. Ìdí rèé tí Kristẹni kan tó gbọ́n fi gbọ́dọ̀ máa jẹ́ kí Jèhófà ṣamọ̀nà òun nínú ohun gbogbo. Ìyẹn ló máa jẹ́ kí Jèhófà kà á sí “adúróṣánṣán nínú ọkàn-àyà,” Jèhófà sì máa “ṣe rere” fún un.—Sm. 125:4.
11. Kí la rí kọ́ látinú ìtàn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì?
11 Rántí ìtàn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Ní gbogbo ìgbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá yàn láti ṣe ohun tó dáa, tí wọ́n ṣègbọràn sí Jèhófà, ó máa ń dáàbò bò wọ́n. (Jóṣ. 24:15, 21, 31) Àmọ́ ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń ṣi òmìnira wọn lò. Nígbà ayé Jeremáyà, Jèhófà sọ nípa wọn pé: “Wọn kò fetí sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò dẹ etí wọn sílẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí rìn nínú ìmọ̀ràn, nínú agídí ọkàn-àyà búburú wọn, tí wọ́n fi padà sí ìhà ẹ̀yìn, kì í ṣe iwájú.” (Jer. 7:24-26) Ó mà ṣe fún wọn o! Ẹ má ṣe jẹ́ ká di alágídí bíi tiwọn ká má sì gba ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara láyè, kó má bàa di pé a kọ ìtọ́sọ́nà Jèhófà sílẹ̀. Ká má sì tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ara wa, kó má bàa di pé ọlá wa tó ti ń rewájú, á wá bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ̀yìn!
Kí Ló Máa Jẹ́ Ká Lè Máa Tẹ̀ Lé Ìmọ̀ràn Ọlọ́run?
12, 13. (a) Àwọn ànímọ́ wo lá mú ká máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà? (b) Kí nìdí tí ìgbàgbọ́ fi ṣe pàtàkì?
12 Tìtorí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà la ṣe ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀. (1 Jòh. 5:3) Àmọ́ Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan nǹkan míì tá a nílò nígbà tó sọ pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni àwa ń rìn, kì í ṣe nípa ohun tí a rí.” (2 Kọ́r. 5:6, 7) Kí nìdí tí ìgbàgbọ́ fi ṣe pàtàkì? Ó dáa, ṣebí “àwọn òpó ọ̀nà òdodo,” ni Jèhófà ń ṣamọ̀nà wa gbà, àmọ́ gbígba irú àwọn ọ̀nà yẹn kì í gbéni dépò ọlá nínú ayé yìí. (Sm. 23:3) Ìdí rèé tí ìgbàgbọ́ fi ṣe pàtàkì tá a bá fẹ́ rí ìbùkún tẹ̀mí tí kò láfiwé téèyàn máa ń rí nínú sísin Jèhófà. (Ka 2 Kọ́ríńtì 4:17, 18.) Ìgbàgbọ́ ló sì máa ń jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun tá a ní tẹ́ wa lọ́rùn.—1 Tím. 6:8.
13 Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé ìjọsìn tòótọ́ máa ń béèrè pé kéèyàn yááfì ohun pàtàkì kan, béèyàn ò bá sì nígbàgbọ́, kò lè ṣe bẹ́ẹ̀. (Lúùkù 9:23, 24) Àwọn kan tó ń fi òtítọ́ sin Jèhófà ti fara da ohun tó pọ̀, bí ipò òṣì, ìnilára, ẹ̀tanú, àti inúnibíni tó gbóná janjan pàápàá. (2 Kọ́r. 11:23-27; Ìṣí. 3:8-10) Tí ìgbàgbọ́ wọn ò bá lágbára ni, wọn ò ní lè fara dà á pẹ̀lú ìdùnnú. (Ják. 1:2, 3) Ìgbàgbọ́ wa tó lágbára ló mú kó dá wa lójú pé títẹ̀lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà ló máa ń fìgbà gbogbo dáa jù. Gbogbo ìgbà tá a bá tẹ̀ lé e ló máa ń ṣe wá láǹfààní. Ó dá wa lójú ṣáká pé èrè tó wà fáwọn tó ti fara dà á pẹ̀lú ìdúróṣinṣin ju ìyà yòówù kí wọ́n jẹ nísinsìnyí lọ.—Héb. 11:6.
14. Kí nìdí tí Hágárì fi ní láti lo ìrẹ̀lẹ̀?
14 Tún wo bí ìrẹ̀lẹ̀ ṣe máa ń jẹ́ kéèyàn lè tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà. Àpẹẹrẹ Hágárì ìránṣẹ́bìnrin Sárà kọ́ wa ní nǹkan kan nípa èyí. Ó ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Sárà rí i pé òun ò rọ́mọ bí, ó fi Hágárì fún Ábúráhámù. Hágárì sì lóyún fún Ábúráhámù. Hágárì wá bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọ̀gá rẹ̀ Sárà ṣakọ. Bí Sárà ṣe “bẹ̀rẹ̀ sí tẹ́ ẹ lógo” nìyẹn, tí Hágárì sì fẹsẹ̀ fẹ. Nígbà tó yá tí áńgẹ́lì Jèhófà rí Hágárì lójú ọ̀nà, ó sọ fún un pé: “Padà sọ́dọ̀ olúwa rẹ obìnrin kí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ rẹ̀.” (Jẹ́n. 16:2, 6, 8, 9) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé irú ìtọ́sọ́nà yẹn kọ́ ni Hágárì ń fẹ́. Kó tó lè ṣe ohun tí áńgẹ́lì yẹn ní kó ṣe, ó ní láti pa akọ tó ń ṣe tì. Síbẹ̀, Hágárì lo ìrẹ̀lẹ̀, ó ṣe ohun tí áńgẹ́lì yẹn ní kó ṣe, bó ṣe láǹfààní àtibí Íṣímáẹ́lì ọmọ rẹ̀ sínú àgọ́ bàbá rẹ̀ níbi tí bàbá rẹ̀ á ti lè máa bójú tó o nìyẹn.
15. Ṣàlàyé àwọn ipò tó ti lè gba pé ká ní ìrẹ̀lẹ̀ ká tó lè tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà lóde òní.
15 Ó lè gba pé ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ káwa náà tó lè máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ó lè di dandan fáwọn kan láti gbà pé inú Jèhófà ò dùn sí eré ìtura táwọn máa ń gbádùn. Kristẹni kan lè ti ṣẹ ẹnì kan kó sì ní láti tọrọ àforíjì. Ó sì lè jẹ́ pé ó ti ṣàṣìṣe kan tó sì yẹ kó gbà pé òun ṣàṣìṣe náà. Téèyàn bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó wúwo ńkọ́? Ó yẹ kó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ kó sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fáwọn alàgbà. Ó lè jẹ́ pé wọ́n tiẹ̀ ti yọ ẹnì kan lẹ́gbẹ́. Tó bá fẹ́ kí wọ́n gba òun padà sínú ìjọ, àfi kó ronú pìwà dà kó sì yí padà, ìyẹn sì gba ìrẹ̀lẹ̀. Nínú irú àwọn ipò yìí àtàwọn ipò míì tó jọ wọ́n, ọ̀rọ̀ tó wà nínú Òwe 29:23 á tuni nínú. Ó kà pé: “Àní ìrera ará ayé ni yóò rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó ní ìrẹ̀lẹ̀ ní ẹ̀mí yóò di ògo mú.”
Báwo Ni Jèhófà Ṣe Ń Ṣamọ̀nà Wa?
16, 17. Báwo la ṣe lè jàǹfààní lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ nínú Bíbélì tó jẹ́ ohun tí Ọlọ́run fi ń ṣamọ̀nà wa?
16 Ohun pàtàkì jù lọ tí Ọlọ́run fi ń ṣamọ̀nà wa ni Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó mí sí. (Ka 2 Tímótì 3:16, 17.) Láti lè jàǹfààní nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa, kò yẹ ká dúró dìgbà tíṣòro bá dé ká tó bẹ̀rẹ̀ sí í wá àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó lè ràn wá lọ́wọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká jẹ́ kí Bíbélì kíkà ojoojúmọ́ ti mọ́ wa lára. (Sm. 1:1-3) Ìyẹn ló máa jẹ́ ká mọ ohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dunjú. Á wá ṣeé ṣe fún wa láti máa ronú bí Ọlọ́run ṣe ń ronú, tíṣòro àìròtẹ́lẹ̀ bá tiẹ̀ wá yọjú, digbí ló máa bá wa.
17 Yàtọ̀ síyẹn, ó ṣe pàtàkì pé ká máa ṣàṣàrò lórí ohun tá à ń kà nínú Ìwé Mímọ́, ká sì máa fàdúrà tì í. Tá a bá ń ronú lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a kà, a ó máa ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ipò tá a ti lè lò wọ́n. (1 Tím. 4:15) Tí ìṣòro tó lágbára bá dé, a ó gbàdúrà sí Jèhófà, ká bẹ̀ ẹ́ pé kó ṣamọ̀nà wa. Ẹ̀mí Jèhófà á sì ràn wá lọ́wọ́ láti rántí àwọn ìlànà Bíbélì tó wúlò, tá a ti kà nínú Bíbélì fúnra rẹ̀ tàbí látinú àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì.—Ka Sáàmù 25:4, 5.
18. Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń lo àwọn Kristẹni lọ́kùnrin lóbìnrin tá a jọ jẹ́ ẹgbẹ́ ará láti ṣamọ̀nà wa?
18 Ibòmíì tá a tún ti lè rí ìtọ́sọ́nà Jèhófà ni àárín àwa Kristẹni tá a jọ jẹ́ ará. “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń ṣojú fún ṣe pàtàkì púpọ̀ nítorí òun ni okùn tó so àwa arákùnrin àti arábìnrin pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ ará kan. Ẹrú yìí ló ń fún wa lóúnjẹ tẹ̀mí nípasẹ̀ àwọn ìwé tó ń tẹ̀ àti ètò tó ṣe fún ìpàdé àti àpéjọ. (Mát. 24:45-47; fi wé Ìṣe 15:6, 22-31.) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn tó dàgbà nípa tẹ̀mí, irú bí àwọn alàgbà, wà láàárín ẹgbẹ́ ará yìí. Àwọn alàgbà yìí sì mọ bá a ṣe ń ran ẹni tó bá níṣòro lọ́wọ́, wọ́n mọ bá a ṣe ń lo àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì. (Aísá. 32:1) Àwọn ọ̀dọ́ tó wá látinú agboolé Kristẹni tún láǹfààní míì. Àwọn òbí wọn tó jẹ́ onígbàgbọ́ ni Ọlọ́run ti fún láṣẹ láti máa ṣamọ̀nà wọn, ó sì yẹ káwọn ọ̀dọ́ máa gba ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ wọn.—Éfé. 6:1-3.
19. Àwọn ìbùkún wo là ń rí bá a ṣe ń jẹ́ kí Jèhófà máa ṣamọ̀nà wa nìṣó?
19 Kò sí àní-àní, ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni Jèhófà gbà ń ṣamọ̀nà wa, ó sì yẹ ká máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀ lójú méjèèjì. Dáfídì Ọba ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbà kan tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ń fòtítọ́ sin Ọlọ́run, ó sọ pé: “Ìwọ ni àwọn baba wa gbẹ́kẹ̀ lé; wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ìwọ sì ń bá a nìṣó ní pípèsè àsálà fún wọn. Ìwọ ni wọ́n kígbe pè, wọ́n sì yèbọ́; ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé, ìtìjú kò sì bá wọn.” (Sm. 22:3-5) Táwa náà bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, tá à ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀, ‘ojú kò ní tì wá.’ Ìrètí wa ò ní ṣákìí. Tá a bá ‘yí ọ̀nà wa lọ sọ́dọ̀ Jèhófà,’ dípò tá a fi máa gbára lé ọgbọ́n tara wa, ìbùkún jìngbìnnì ló máa jẹ́ fún wa, nísinsìnyí. (Sm. 37:5) Tá a bá sì ń fi ìdúróṣinṣin ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyẹn nìṣó, títí láé la ó máa rí àwọn ìbùkún wọ̀nyẹn. Dáfídì Ọba kọ̀wé pé: “Olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà, òun kì yóò sì fi àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀. Fún àkókò tí ó lọ kánrin ni a óò máa ṣọ́ wọn dájúdájú . . . Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sm. 37:28, 29.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Kí nìdí tó fi yẹ ká gbà pé Jèhófà nìkan lẹni tó yẹ kó máa ṣamọ̀nà wa?
• Tá ò bá tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà, kí nìyẹn máa túmọ̀ sí?
• Kí ni díẹ̀ lára àwọn ipò tó lè mú kí Kristẹni kan nílò ìrẹ̀lẹ̀?
• Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń ṣamọ̀nà wa lónìí?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Ṣé ò ń jẹ́ kí Jèhófà máa ṣamọ̀nà rẹ nígbà gbogbo nínú ìgbésí ayé rẹ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Éfà kò gba Jèhófà lọ́ba aláṣẹ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ànímọ́ wo ni Hágárì nílò tó bá fẹ́ tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà áńgẹ́lì yẹn?