Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ o gbádùn kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí:

• Ìgbà wo làwọn awòràwọ̀ lọ sọ́dọ̀ Jésù?

Bíbélì New International Version Study Bible sọ pé: “Àwọn amòye ò lọ sọ́dọ̀ Jésù ní ibùjẹ ẹran lóru ọjọ́ tí wọ́n bí i, àwọn olùṣọ́ àgùntàn ló lọ. Ó tó oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà káwọn amòye náà tó lọ.” Nígbà yẹn, Jésù ti kúrò lọ́mọ jòjòló, ó ti di “ọmọ kékeré,” inú ilé ló sì wà. (Mát. 2:7-11) Tó bá jẹ́ pé àwọn awòràwọ̀ yìí ti fún Jésù ní wúrà àtàwọn ẹ̀bùn iyebíye míì lóru ọjọ́ tí wọ́n bí i, ǹjẹ́ kìkì ẹyẹ méjì ni Màríà á fi rúbọ nígbà tó gbé Jésù wá sí tẹ́ńpìlì ní ogójì ọjọ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn?—1/1, ojú ìwé 31.

• Báwo làwọn èèyàn ṣe lè yan ohun tó sàn jù nígbèésí ayé?

A lè bi ara wa pé, ‘Ǹjẹ́ mo lè tún ọ̀ràn ara mi gbé yẹ̀ wò, kí n wá jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ mi lọ́rùn?’ Ohun tí Amy ṣe nìyẹn. Ó rí towó ṣe àmọ́ kò láyọ̀. Ó rí i pé ipò ọlá tóun ń lé nínú ayé ti fẹ́rẹ̀ẹ́ mú kóun ṣáko lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́. Nítorí náà, ó pinnu láti fàwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́, ó sì ṣe aṣáájú-ọ̀nà fún ọdún mélòó kan. Amy sọ pé òun ti wá ní irú ìfọ̀kànbalẹ̀ tóun ò ní nígbà tóun ń lépa ipò ọlá nínú ayé.—1/15, ojú ìwé 19.

• Iṣẹ́ wo làwọn abiyamọ kan lè ṣe tó máa fún wọn nítẹ̀ẹ́lọ́rùn jù lọ?

Ọ̀pọ̀ abiyamọ ló ń ṣiṣẹ́ oṣù. Ìdí táwọn kan fi ń ṣe é ni láti fi gbọ́ bùkátà ìdílé, àwọn míì ń ṣe é torí kí wọ́n má bàa máa wojú ọkọ kí wọ́n tó lè náwó, àwọn kan sì ń wá owó tí wọ́n á fi máa jẹ̀gbádùn. Àmọ́ ní tàwọn míì, torí pé wọ́n ń gbádùn iṣẹ́ wọn ni wọ́n ṣe ń ṣe é. Ohun tí Bíbélì fi kọ́ni ni pé ìyá ní ipa pàtàkì kan láti kó, pàápàá nígbà tọ́mọ bá ṣì wà lọ́mọ ọwọ́. Àwọn kan dín àkókò tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ níta kù, àwọn míì sì kúkú fiṣẹ́ sílẹ̀ kí wọ́n lè ráyè gbọ́ ti ìdílé wọn. Èyí sì fún wọn nítẹ̀ẹ́lọ́rùn gan-an.—2/1, ojú ìwé 28 sí 31.

• “Ìran” wo ni Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú Mátíù 24:34?

Jésù sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “ìran,” nígbà tó bá ń bá àwọn èèyàn burúkú wí tàbí tó bá ń sọ̀rọ̀ nípa wọn. Àmọ́ nínú ẹsẹ Bíbélì yìí, ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn burúkú kọ́ ni Jésù ń sọ, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, tí Ọlọ́run máa tó fẹ̀mí mímọ̀ yàn ló ń tọ́ka sí. Àwọn ló máa tètè lòye ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́nà tí Jésù gbà sọ ọ́ nínú Mátíù 24:32, 33. Nítorí náà, ó ní láti jẹ́ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí Ọlọ́run fẹ̀mí mímọ̀ yàn ni Jésù ń tọ́ka sí, ìyẹn àwọn ti ọ̀rúndún kìíní àti àwọn tòde òní.—2/15, ojú ìwé 23 àti 24.

• Báwo ni Òfin ṣe jẹ́ akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ gẹ́gẹ́ bí Gálátíà 3:24 ṣe sọ?

Akọ́nilẹ́kọ̀ọ́, ìyẹn ẹnì kan tó dà bí alágbàtọ́, sábà máa ń jẹ́ àgbàlagbà ẹrú tó ṣeé fọkàn tán. Ó máa ń dáàbò bo ọmọ, ó sì máa ń rí i dájú pé ohun tí bàbá ọmọ fẹ́ ni wọ́n ń ṣe fún ọmọ náà. Lọ́nà kan náà, Òfin Mósè dáàbò bo àwọn Júù kúrò lọ́wọ́ àwọn ìwà tó lè ṣàkóbá fún wọn, irú bíi bíbá àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà dána. Ṣùgbọ́n bó ṣe jẹ́ pé akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kì í láṣẹ lórí ọmọ títí lọ bẹ́ẹ̀ náà ni Òfin náà ṣe parí iṣẹ́ rẹ̀ nígbà tí Kristi dé.—3/1, ojú ìwé 18 sí 21.

• Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó wà nínú Jákọ́bù 3:17, àwọn ànímọ́ wo ló yẹ ká ní?

Nítorí pé a jẹ́ oníwà mímọ́, a ní láti máa yẹra fún ohun búburú lójú ẹsẹ̀. (Jẹ́n. 39:7-9) A sì tún ní láti jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà, ká máa yẹra fún ìwà jàgídíjàgan tàbí àwọn ohun tó máa ń ba àlàáfíà jẹ́. Nítorí náà, á dáa kí kálukú wa bi ara rẹ̀ pé: ‘Ǹjẹ́ wọ́n mọ̀ mí sí ẹni tí ń wá àlàáfíà tàbí ẹni tó ń ba àlàáfíà jẹ́? Ṣé lemọ́lemọ́ lèmi àtàwọn èèyàn jọ máa ń ní èdèkòyédè? Ṣé mo máa ń tètè ṣẹ àwọn èèyàn tàbí wọ́n máa ń tètè ṣẹ̀ mí? Ǹjẹ́ mo máa ń tètè darí jini? Ṣé n kì í sọ pé ọ̀rọ̀ tèmi làwọn èèyàn gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé dandan?’—3/15, ojú ìwé 24 àti 25.

• Kí nìdí tó fi jẹ́ pé díẹ̀díẹ̀ ni Jésù la ojú afọ́jú kan? (Máàkù 8:22-26)

Bíbélì ò sọ ìdí kan pàtó tí Jésù fi ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé, bó ṣe ń la ojú ọkùnrin náà díẹ̀díẹ̀, ìyẹn á jẹ́ kí ọpọlọ rẹ̀ lè gbé gbogbo ohun tójú rẹ̀ ń rí bó ṣe ń là bọ̀. Èyí jẹ́ ká rí bí ìfẹ́ àti àánú tí Jésù ní sí ọ̀gbẹ́ni yẹn ṣe tó.—4/1, ojú ìwé 30.