Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wọn Ò Sí Láàárín Wa Àmọ́ A Kò Gbàgbé Wọn

Wọn Ò Sí Láàárín Wa Àmọ́ A Kò Gbàgbé Wọn

Wọn Ò Sí Láàárín Wa Àmọ́ A Kò Gbàgbé Wọn

ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ níyànjú pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gál. 6:10) Títí dòní yìí, a ṣì ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Ọlọ́run mí sí yìí, à ń wá ọ̀nà láti ṣe rere fún àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́. Lára àwọn tó yẹ ká fi ìfẹ́ bójú tó nínú ìjọ Kristẹni ni àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa àtàtà tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà tí wọ́n wà nílé ìtọ́jú àwọn arúgbó.

Òótọ́ ni pé láwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn ọmọ ló máa ń tọ́jú àwọn òbí wọn tó ti darúgbó nínú ilé. Ṣùgbọ́n, láwọn orílẹ̀-èdè míì, ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó ni wọ́n ti sábà máa ń tọ́jú ọ̀pọ̀ arúgbó. Àmọ́, àwọn àgbàlagbà Kristẹni tí wọ́n ń gbé nílé ìtọ́jú àwọn arúgbó ńkọ́? Àwọn ìṣòro wo ló ń dojú kọ wọ́n níbẹ̀? Báwo ni wọ́n ṣe lè borí àwọn ìṣòro náà bí wọn ò bá ní ẹbí tò lè ràn wọ́n lọ́wọ́? Báwo làwọn ará ìjọ ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́? Àǹfààní wo la lè rí tá a bá ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn déédéé?

Ìṣòro Táwọn Àgbàlagbà Ń Dojú Kọ Nílé Ìtọ́jú Àwọn Arúgbó

Nígbà táwọn Kristẹni tó jẹ́ àgbàlagbà bá kó lọ sílé ìtọ́jú àwọn arúgbó, ó lè jẹ́ pé ìpínlẹ̀ ìjọ tí wọn ò ti mọ̀ wọ́n ni ilé ìtọ́jú ọ̀hún á wà. Èyí sì lè mú kí ọkàn àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ládùúgbò náà má lọ síbi pé ó yẹ káwọn máa lọ wo àlàáfíà wọn déédéé. Ohun mìíràn ni pé, ó lè jẹ́ àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn yàtọ̀ sí tiwọn ni wọ́n jọ wà ní ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó tí wọ́n ń gbé. Èyí lè mú káwọn ará wa tó ti darúgbó dojú kọ ìṣòro.

Bí àpẹẹrẹ, láwọn àgbègbè kan, wọ́n máa ń ṣe ìsìn fáwọn àgbàlagbà tó wà nílé ìtọ́jú àwọn arúgbó. Ọkùnrin kan tó máa ń tọ́jú àwọn arúgbó sọ pé: “Wọ́n ti fi àga onítáyà gbé àwọn àgbàlagbà Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tí wọn ò lè sọ̀rọ̀ dáadáa lọ síbi táwọn ṣọ́ọ̀ṣì kan ti ń ṣe ìsìn láì béèrè lọ́wọ́ wọn bóyá wọ́n fẹ́ lọ tàbí wọn ò fẹ́.” Ìyẹn nìkan kọ́, àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó sábà máa ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí, Ọdún Kérésìmesì tàbí Ọdún Àjíǹde láti ṣe kóríyá fáwọn àgbàlagbà kí ibẹ̀ má bàa sú wọn. Wọ́n ti fún àwọn Ẹlẹ́rìí kan tó wà nílé ìtọ́jú àwọn arúgbó láwọn oúnjẹ kan tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà wọ́n láyè láti jẹ. (Ìṣe 15:29) Tá a bá ń bẹ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó jẹ́ àgbàlagbà wò déédéé, á ṣeé ṣe fún wa láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè kápá irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀.

Bí Ìjọ Ṣe Lè Ràn Wọ́n Lọ́wọ́

Àwọn tó wà nínú ìjọ nígbà tí ẹ̀sìn Kristẹni ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ mọ iṣẹ́ wọn níṣẹ́ tó bá dọ̀ràn ṣíṣèrànwọ́ fáwọn àgbàlagbà tí wọn ò ní ẹbí táá máa tọ́jú wọn. (1 Tím. 5:9) Lọ́nà kan náà, àwọn alábòójútó òde òní ní láti rí i pé àwọn ò pa àwọn àgbàlagbà tó wà nílé ìtọ́jú àwọn arúgbó tó wà ládùúgbò wọn tì. a Alàgbà kan tó ń jẹ́ Robert sọ pé: “Ó máa dára gan-an tí olúkúlùkù alábòójútó nínú ìjọ bá ń lọ wo àlàáfíà àwọn àgbàlagbà, kí wọ́n sì gbàdúrà pẹ̀lú wọn. Ọ̀pọ̀ nǹkan tí wọ́n nílò ni ìjọ lè ṣe fún wọn.” Tá a bá ń wá àyè lọ sọ́dọ̀ àwọn àgbàlagbà, ńṣe là ń fi hàn pé a mọ bó ṣe ṣe pàtàkì tó lójú Jèhófà pé ká máa bójú tó àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́.—Ják. 1:27.

Nígbà tó bá pọn dandan, àwọn alàgbà yóò fìfẹ́ ṣètò bí wọ́n á ṣe máa ṣèrànwọ́ fáwọn arákùnrin àti arábìnrin tó ń gbé ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó tó wà ládùúgbò wọn. Arákùnrin Robert ṣàkíyèsí ohun kan tó yẹ ká máa ṣe, ó ní: “A ní láti ran àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tó jẹ́ àgbàlagbà lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa wá sípàdé ìjọ tó bá ṣeé ṣe fún wọn.” Àmọ́, àwọn alàgbà lè ṣe ètò míì fáwọn tí kò lè wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba mọ́. Àìsàn làkúrègbé tó ń sọ eegun di hẹ́gẹhẹ̀gẹ ló ń ṣe Arábìnrin Jacqueline, tọ́jọ́ orí ẹ̀ tó nǹkan bí ọdún márùn-dín-láàádọ́rùn-ún [85], ẹ̀rọ tẹlifóònù ló fi máa ń gbọ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé ìjọ. Ó sọ pé: “Ó ń ṣe mí láǹfààní gan-an bí mo ṣe ń gbọ́ ohun tó ń lọ lọ́wọ́ nínú ìpàdé. Kò sóhun tó lè mú kí n má gbọ́ ọ!”

Bó bá ṣẹlẹ̀ pé Kristẹni kan tó ti darúgbó kò lè gbọ́ ohun tó ń lọ nípàdé lórí tẹlifóònù, àwọn alàgbà ìjọ rẹ̀ lè ṣètò pé kẹ́nì kan máa gba àwọn ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀. Ẹni tó lọ mú nǹkan tí wọ́n fi gbá ohùn náà sílẹ̀ fún arákùnrin tàbí arábìnrin tó ń gbé ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó lè lo àǹfààní yẹn láti sọ̀rọ̀ ìṣírí fún un. Alábòójútó inú ìjọ kan sọ pé: “Ríròyìn bí nǹkan ṣe ń lọ láàárín àwọn ará nínú ìjọ fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n ti darúgbó máa ń mú kí wọ́n rí i pé àwọn ṣì jẹ́ ara ìjọ.”

Bó O Ṣe Lè Máa Bá Wọn Sọ̀rọ̀ Nìṣó

A mọ̀ pé kíkó lọ sí ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó máa ń ni ọ̀pọ̀ àgbàlagbà lára, ó sì máa ń mú kí ọkàn wọn pòrúurùu. Ìdí rèé táwọn kan lára wọn kì í fi fẹ́ dá sí ẹnikẹ́ni mọ́ nígbà tí wọ́n bá ti débẹ̀. Àmọ́, tá a bá tètè ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tó jẹ́ àgbàlagbà ní gbàrà tí wọ́n bá ti kó dé ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó, tá a sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a óò máa tì wọ́n lẹ́yìn nìṣó, èyí á fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ gan-an wọ́n á sì láyọ̀.—Òwe 17:22.

Bí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tó jẹ́ àgbàlagbà bá ti ń ṣarán tàbí tí wọn ò bá gbọ́ràn dáadáa mọ́ tàbí tí wọ́n bá ní ìṣòro míì tó jẹ́ kó nira láti máa bá wọn sọ̀rọ̀ dáadáa, àwọn kan lè rò pé lílọ sọ́dọ̀ wọn kò ṣàǹfààní kankan. Àmọ́ ṣá, tá a bá ń sapá láti máa bẹ̀ wọ́n wò láìwo ti bó ṣe ṣòro láti máa bá wọn sọ̀rọ̀, ó fi hàn pé ńṣe là ń ‘mú ipò iwájú nínú bíbu ọlá’ fún àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́. (Róòmù 12:10) Bí arákùnrin àgbàlagbà kan ò bá lè rántí àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, a lè ní kó máa sọ àwọn ìrírí ìgbà àtijọ́, àní kó sọ ti ìgbà ọmọdé rẹ̀ pàápàá, tàbí kó sọ fún wa bó ṣe dẹni tó wá sínú òtítọ́. Kí la lè ṣe tí kò bá tètè rántí ọ̀rọ̀ tó yẹ kó fi ṣàlàyé ohun tó ń sọ? Tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́, tó bá sì yẹ, o lè sọ ọ̀rọ̀ méjì tàbí mẹ́ta láti rán an létí ọ̀rọ̀ tó fẹ́ sọ, tàbí kó o bá a sọ ohun tó fẹ́ sọ ní ṣókí kó o sì ní kó máa bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ọ̀rọ̀ náà dàrú mọ́ ọn lójú tàbí pé kò lè sọ̀rọ̀ kó já gaara, tá ò sì lè lóye ohun tó ń sọ, a lè gbìyànjú láti mọ ohun tó ní lọ́kàn nípa fífarabalẹ̀ kíyè sí ìró ohùn rẹ̀.

Tí kò bá ṣeé ṣe láti fi ọ̀rọ̀ ẹnu bá ẹni yẹn sọ̀rọ̀ mọ́, a lè wá ọ̀nà míì láti bá a sọ̀rọ̀. Arábìnrin Laurence tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà máa ń lọ sọ́dọ̀ Madeleine, arábìnrin kan tó jẹ́ ẹni ọgọ́rin [80] ọdún tí kò lè sọ̀rọ̀ mọ́. Laurence ṣàlàyé bóun ṣe máa ń bá a sọ̀rọ̀, ó ní: “Mo máa ń di ọwọ́ Madeleine mú tá a bá ti jọ ń gbàdúrà, òun náà á sì rọra fún ọwọ́ mi pọ̀ díẹ̀ táá sì ṣẹ́jú láti fi hàn pé ó mọrírì ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn.” Dídi ọwọ́ àwọn bàbá wa àti ìyà wa ọ̀wọ́n wọ̀nyí mú tàbí gbígbá wọn mọ́ra látọkànwá lè mú kí wọ́n mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ wọn.

Lílọ Sọ́dọ̀ Wọn Ṣe Pàtàkì

Tó o bá ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn àgbàlagbà déédéé, èyí lè mú káwọn tó ń tọ́jú wọn túbọ̀ máa tọ́jú wọn dáadáa. Arábìnrin Danièle, tó ti fi bí ogún ọdún ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ará tó wà nílé ìtọ́jú àwọn arúgbó, ṣàlàyé pé: “Nígbà táwọn tó ń tọ́jú àwọn arúgbó bá ṣàkíyèsí pé àwọn èèyàn ń wá sọ́dọ̀ arúgbó kan déédéé, wọ́n máa ń tọ́jú ẹ̀ dáadáa.” Arákùnrin Robert, tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Ó jọ pé àwọn tó ń tọ́jú àwọn arúgbó máa ń fetí sí ẹni tó bá ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn arúgbó déédéé. Wọ́n lè má fi bẹ́ẹ̀ ka ẹni tí kì í wá síbẹ̀ déédéé sí.” Níwọ̀n bí àwọn kan ti máa ń ṣàríwísí nípa bí wọ́n ṣe ń tọ́jú arúgbó wọn, báwọn tó ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn arúgbó bá ń yin àwọn tó ń tọ́jú wọn, wọ́n máa ń mọrírì rẹ̀. Ìyẹn nìkan kọ́, tá a bá jẹ́ káwọn tó ń tọ́jú arúgbó mojú wa, wọ́n á túbọ̀ fẹ́ láti ṣohun tí arúgbó wa tó wà lọ́dọ̀ wọn fẹ́, wọn ò sì ní ta ko ohun tó gbà gbọ́.

Àárín àwa àtàwọn tó ń tọ́jú àwọn arúgbó tún lè dán mọ́rán tá a bá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a lè bá wọn ṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ kan. Láwọn àgbègbè kan, àwọn tó mọ bá a ti í tọ́jú àwọn arúgbó dáadáa kò pọ̀ tó, èyí sì mú káwọn arúgbó má máa rí ìtọ́jú tó yẹ. Rébecca tó ń ṣiṣẹ́ ìtọ́jú àwọn arúgbó sọ pé: “Àkókò oúnjẹ kì í rọrùn rárá fáwọn arúgbó. Nítorí náà, àsìkò yẹn ló dára láti máa wá wo èèyàn ẹni tó jẹ́ àgbàlagbà, ká lè rí sí i pé wọn jẹun dáadáa.” A lè ní káwọn tó ń tọ́jú àwọn àgbàlagbà sọ ohun tá a lè ṣe láti fi ṣèrànwọ́.

Nígbà tá a bá ń ṣèbẹ̀wò déédéé sí ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó kan, á ṣeé ṣe fún wa láti mọ ohun táwọn arákùnrin àti arábìnrin wa àgbàlagbà nílò, a sì lè gba àṣẹ lọ́wọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ibẹ̀ láti ṣe ohun táwọn arúgbó wa nílò fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, a lè mú kí yàrá àgbàlagbà kan lẹ́wà sí i nípa títo fọ́tò àwọn èèyàn wọn tàbí àwòrán táwọn ọmọ kan yà síbẹ̀. A lè bá wọn mú aṣọ òtútù tó nípọn wá tàbí ká ra àwọn ohun ìlò bí ọṣẹ ìwẹ̀, nǹkan ìpara àti irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ wá fún wọn. Bí ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó náà bá ní ọgbà, a lè mú bàbá tàbí màmá náà bọ́ síta láti gba afẹ́fẹ́ tó dáa sára. Arábìnrin Laurence tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Arábìnrin Madeleine máa ń retí mi lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Nígbà tí mo bá kó àwọn ọmọ lọ síbẹ̀, ńṣe ló máa rẹ́rìn-ín músẹ́ tí ayọ̀ á sì hàn lójú rẹ̀!” Tá a bá ń ṣe irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, ó lè túbọ̀ mú kára tu àwọn àgbàlagbà tó wà nílé ìtọ́jú àwọn arúgbó.—Òwe 3:27.

Gbogbo Wa La Máa Jàǹfààní Tá A Bá Ń Bẹ̀ Wọ́n Wò

Tá a bá ń ṣèbẹ̀wò déédéé sọ́dọ̀ àgbàlagbà kan, èyí á fi hàn pé òótọ́ la ní “ojúlówó ìfẹ́” sí i. (2 Kọ́r. 8:8) Lọ́nà wo? Ó máa ń dùn wá gan-an nígbà tá a bá rí èèyàn wa kan tó jẹ́ arúgbó tí àìlera ẹ̀ túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Arábìnrin Laurence sọ pé: “Lákọ̀ọ́kọ́, ipò tí Arábìnrin Madeleine wà ká mi lára gan-an débi pé ní gbogbo ìgbà tí mo bá lọ bẹ̀ ẹ́ wò, ńṣe ni mo máa ń sunkún lẹ́yìn tí mo bá kúrò níbẹ̀. Àmọ́, mo ti wá rí i pé àdúrà àtọkànwá lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí ìbẹ̀rù wa, ìyẹn á sì lè jẹ́ ká máa fún àwọn arúgbó níṣìírí.” Ọ̀pọ̀ ọdún ni Arákùnrin Robert ti ń lọ sọ́dọ̀ arákùnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Larry, tí àìsàn kan tí wọ́n ń pè ní Parkinson ń ṣe, èyí tó máa ń mú kí ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ máa gbọ̀n. Arákùnrin Robert sọ pé: “Àìsàn yìí dààmú Arákùnrin Larry débi pé ọ̀rọ̀ tó ń sọ ò yé èèyàn mọ́. Àmọ́ nígbà tá a bá jọ ń gbàdúrà, mo máa ń rí pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣì lágbára.”

Nígbà tá a bá lọ sọ́dọ̀ àwọn àgbàlagbà tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́, kì í ṣe pé à ń ràn wọ́n lọ́wọ́ nìkan ni, àmọ́ àwa náà ń jàǹfààní. Ìpinnu wọn láti sún mọ́ Jèhófà bí wọ́n ṣe ń gbé láàárín àwọn èèyàn tí ìgbàgbọ́ wọn yàtọ̀ sí tiwọn jẹ́ àpẹẹrẹ ìgboyà àti ìgbàgbọ́ tó lágbára. Bí wọ́n ṣe ń fi gbogbo ọkàn retí àtijẹ oúnjẹ tẹ̀mí, láìwo ti àìlègbọ́rọ̀ dáadáa àti àìlèríran dáadáa, jẹ́ ká túbọ̀ rí i kedere pé “ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.” (Mát. 4:4) Bákan náà, inú àwọn àgbàlagbà máa ń dùn sí àwọn ohun pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, irú bí ẹ̀rín músẹ́ lẹ́nu ọmọdé, tàbí oúnjẹ tá a jọ jẹ, èyí sì ń rán wa létí pé ó yẹ kóhun tá a ní tẹ́ wa lọ́rùn. Ìfẹ́ tí wọ́n ní fún ìjọsìn Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ohun tó yẹ ká fi sípò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wa.

Ní tòótọ́, gbogbo ará ìjọ ló ń jàǹfààní látinú ìrànwọ́ tá a ń ṣe fáwọn àgbàlagbà. Lọ́nà wo? Nítorí pé àwọn tara wọn ò le nílò ìfẹ́ àwọn ará ju àwọn mìíràn lọ, ìyẹn ń mú kí ìjọ túbọ̀ máa tẹ̀ síwájú nínú fífi ìyọ́nú hàn. Nítorí náà, ojú tó yẹ kí gbogbo wa máa fi wo títọ́jú àwọn àgbàlagbà ni pé, ṣíṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ ara ṣíṣe ìránṣẹ́ fún ara wa, àní bó tilẹ̀ gba àkókò gígùn pàápàá. (1 Pét. 4:10, 11) Báwọn alàgbà bá ń mú ipò iwájú nínú ríran àwọn arúgbó wa lọ́wọ́, ńṣe ni wọ́n ń jẹ́ káwọn ará ìjọ rí i pé a ò gbọ́dọ̀ pa iṣẹ́ yìí tì, nítorí pé ara iṣẹ́ Kristẹni ni. (Ìsík. 34:15, 16) Bá a ti ń fìfẹ́ àtọkànwá ran àwọn arúgbó tá a jọ jẹ́ Kristẹni lọ́wọ́, à ń mú un dá wọn lójú pé a kò gbàgbé wọn!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Gbàrà tí akọ̀wé ìjọ kan bá ti mọ̀ pé arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan ti kó lọ sí ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó ní àgbègbè mìíràn, ńṣe ló yẹ kó fi tó àwọn alàgbà ìjọ àgbègbè tó kó lọ létí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Èyí á ran àgbàlagbà náà lọ́wọ́ á sì fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 28]

“Nígbà táwọn tó ń tọ́jú àwọn arúgbó bá ṣàkíyèsí pé àwọn èèyàn ń wá sọ́dọ̀ arúgbó kan déédéé, wọ́n máa ń tọ́jú ẹ̀ dáadáa”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Àdúrà tá a gbà tọkàntọkàn lè mú kí ọkàn àgbàlagbà kan tá a jọ Ẹlẹ́rìí balẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Fífi ìyọ́nú hàn sáwọn àgbàlagbà tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ yóò fún wọn lókun