Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìdáǹdè Nípasẹ̀ Ìjọba Ọlọ́run Kù sí Dẹ̀dẹ̀!

Ìdáǹdè Nípasẹ̀ Ìjọba Ọlọ́run Kù sí Dẹ̀dẹ̀!

Ìdáǹdè Nípasẹ̀ Ìjọba Ọlọ́run Kù sí Dẹ̀dẹ̀!

“Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”—MÁT. 6:10.

1. Kí ni ẹ̀kọ́ pàtàkì tí Jésù fi kọ́ni?

 NÍGBÀ tí Jésù Kristi ń wàásù lórí òkè, ó fi àdúrà àwòṣe kan kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó jẹ́ àkópọ̀ ẹ̀kọ́ pàtàkì tó fi kọ́ni. Ó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mát. 6:9-13) Jésù “ń rin ìrìn àjò lọ láti ìlú ńlá dé ìlú ńlá àti láti abúlé dé abúlé, ó ń wàásù, ó sì ń polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 8:1) Kristi tún rọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: ‘Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́.’ (Mát. 6:33) Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ àpilẹ̀kọ́ yìí, máa wo àwọn ọ̀nà tó o lè gbà lò ó lóde ẹ̀rí. Bí àpẹẹrẹ, ronú lórí bó o ṣe máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí: Báwo ni ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ti ṣe pàtàkì tó? Inú kí ni aráyé ti nílò ìdáǹdè? Àti, báwo ni Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa dá aráyé nídè?

2. Báwo ni ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ti ṣe pàtàkì tó?

2 Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mát. 24:14) Ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lohun tó ṣe pàtàkì jù lọ. Dájúdájú, kò sí ìhìn míì tó tún ṣe pàtàkì ju ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lọ nínú ayé. Nínú ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún [100,000] kárí ayé, nǹkan bíi àádọ́ta dín nírínwó ọ̀kẹ́ [7,000,000] àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ló ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù tí kò lẹ́gbẹ́ yìí, wọ́n ń sọ fáwọn èèyàn pé Ọlọ́run ti gbé Ìjọba kan kalẹ̀. Ìhìn rere sì nìyẹn lóòótọ́, torí ohun tó túmọ̀ sí ni pé Ọlọ́run ti gbé Ìjọba kan kalẹ̀ lọ́run tí yóò fi máa ṣàkóso ayé. Nígbà ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run, àwọn tó wà láyé yóò máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà bí wọ́n ti ń ṣe ní ọ̀run.

3, 4. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí ìfẹ́ Ọlọ́run bá di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé?

3 Kí ló máa ṣẹlẹ̀ nígbà táráyé bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé? Jèhófà yóò “nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.” (Ìṣí. 21:4) Kò ní sí pé ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti jogún àti àìpé ń fa àìsàn àti ikú fáráyé mọ́. Ọlọ́run yóò jí àwọn òkú tó wà nínú ìrántí rẹ̀ dìde, wọn yóò sì wà láàyè títí láé, torí Bíbélì ti sọ pé: “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Ìṣe 24:15) Kò ní sí ogun, àìlera tàbí ebi mọ́, ilẹ̀ ayé yóò sì di Párádísè. Kódà, àwọn ẹranko ẹhànnà kò ní ṣèpalára fún èèyàn àtàwọn ẹranko míì mọ́.—Sm. 46:9; 72:16; Aísá. 11:6-9; 33:24; Lúùkù 23:43.

4 Nítorí àwọn ìbùkún àgbàyanu tá a máa gbádùn nínú Ìjọba Ọlọ́run, àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa bí ìgbésí ayé ṣe máa rí nígbà yẹn kò yà wá lẹ́nu. Ó ní: “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” Àmọ́, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ẹni burúkú? Ìwé Mímọ́ sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́.” Ṣùgbọ́n, “àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà ni yóò ni ilẹ̀ ayé.”—Sm. 37:9-11.

5. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí?

5 Kí gbogbo èyí tó lè ṣẹ, ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí títí kan ìjọba, ìsìn rẹ̀ àti ètò ọrọ̀ ajé rẹ̀ gbọ́dọ̀ pa run. Ohun tí Ìjọba Ọlọ́run sì máa ṣe gan-an nìyẹn. Ọlọ́run mí sí wòlíì Dáníẹ́lì láti sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn [ìyẹn àwọn tó ń ṣàkóso nísinsìnyí], Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ [lọ́run] èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Dán. 2:44) Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn ìjọba tuntun tó wà lókè ọ̀run, yóò wá máa ṣàkóso lórí àwọn ẹ̀dá tuntun tí yóò wà lórí ilẹ̀ ayé. Bíbélì sọ pé, “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” yóò wà “nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.”—2 Pét. 3:13.

Àkókò Yìí Gan-an La Nílò Ìdáǹdè Jù

6. Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe ìwà ibi tó wà nínú ayé burúkú yìí?

6 Látìgbà tí Sátánì, Ádámù àti Éfà ti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, tí wọ́n fẹ́ máa fúnra wọn pinnu ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, ni ìran èèyàn ti kàgbákò. Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀jọ [1,600] ọdún lẹ́yìn ìṣọ̀tẹ̀ yẹn, ìyẹn ṣáájú Ìkún-omi ọjọ́ Nóà, “Jèhófà rí i pé ìwà búburú ènìyàn pọ̀ yanturu ní ilẹ̀ ayé, gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú ọkàn-àyà rẹ̀ sì jẹ́ kìkì búburú ní gbogbo ìgbà.” (Jẹ́n. 6:5) Ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dégbèje ọdún lẹ́yìn Ìkún-omi, Sólómọ́nì rí i pé ipò nǹkan ti wá burú gan-an débi tó fi sọ pé: “Mo . . . yọ̀ fún àwọn òkú tí ó ti kú jù fún àwọn alààyè tí ó ṣì wà láàyè. Nítorí náà, ẹni tí kò tíì sí, tí kò tíì rí iṣẹ́ oníyọnu àjálù tí a ń ṣe lábẹ́ oòrùn, sàn ju àwọn méjèèjì.” (Oníw. 4:2, 3) Láti ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọdún sẹ́yìn tí Sólómọ́nì sì ti sọ ọ̀rọ̀ yìí, ńṣe ni ìwà ibi túbọ̀ ń pọ̀ sí i títí di báyìí.

7. Kí nìdí tá a fi túbọ̀ nílò ìdáǹdè látọ̀dọ̀ Ọlọ́run báyìí?

7 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ pẹ́ tí ìwà ibi ti gbilẹ̀ nínú ayé, a nílò ìdáǹdè nípasẹ̀ Ìjọba Ọlọ́run lákòókò wa yìí gan-an ju tìgbàkigbà rí lọ. Láti nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn báyìí, ńṣe ni nǹkan túbọ̀ ń burú sí i nínú ayé ju tàtẹ̀yìnwá lọ. Bí àpẹẹrẹ, Àjọ Worldwatch Institute, ìyẹn àjọ kan tó ń rí sí bí àwọn nǹkan ṣe ń lọ lágbàáyé sọ pé: “Àwọn tí ogun pa ní ọ̀rúndún ogun nìkan jẹ́ ìlọ́po mẹ́ta iye àwọn tí ogun ń pa láti ọ̀rúndún kìíní Ọdún Olúwa Wa títí di ọdún 1899.” Ẹgbẹ̀rún márùn-ún ọ̀kẹ́ [100,000,000] èèyàn ni ogun ti pa láti ọdún 1914 wá! Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan fojú bù ú pé ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọ̀kẹ́ [60,000,000] èèyàn tó bá Ogun Àgbáyé Kejì lọ. Ní báyìí táwọn orílẹ̀-èdè kan sì ti wá kó àwọn ohun ìjà arunlé-rùnnà jọ, ẹ̀dá èèyàn lágbára láti run apá tó pọ̀ gan-an nínú ayé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àti ìṣègùn túbọ̀ ń gòkè àgbà, síbẹ̀ ebi àti àìsàn ṣì ń gbà ẹ̀mí àwọn ọmọdé tó tó àádọ́ta lé ní igba ọ̀kẹ́ [5,000,000] lọ́dọọdún.—Wo orí Kẹsàn-án nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?

8. Kí ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún táwọn èèyàn ti fi ṣàkóso ti jẹ́ ká rí dájú?

8 Gbogbo ìsapá àwọn èèyàn kò fòpin sí ìwà ibi. Ètò ìṣèlú, ọrọ̀ ajé àti ìsìn ayé kò tíì fìgbà kankan rí pèsè olórí ohun táráyé nílò, ìyẹn àlàáfíà, aásìkí àti ìlera. Dípò kí wọ́n yanjú ìṣòro aráyé, ńṣe ni wọ́n ń dá kún un. Láìsíyèméjì, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún táwọn èèyàn ti fi ṣàkóso ti jẹ́ ká rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí wòlíì Jeremáyà sọ pé: “Ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jer. 10:23) Àní, “ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” (Oníw. 8:9) Kò tán síbẹ̀ o, “gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀ títí di ìsinsìnyí.”—Róòmù 8:22.

9. Kí làwọn Kristẹni ti mọ̀ pé ó máa ṣẹlẹ̀ ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí?

9 Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa àkókò wa pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín.” Lẹ́yìn tí Bíbélì ti sọ bí nǹkan ṣe máa rí lábẹ́ ìṣàkóso àwọn èèyàn láwọn ọjọ́ ìkẹyìn, ó tún sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà yóò máa tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù.” (Ka 2 Tímótì 3:1-5, 13.) Ohun táwọn Kristẹni ti mọ̀ pé ó máa ṣẹlẹ̀ nìyẹn, torí “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà,” Sátánì. (1 Jòh. 5:19) Àmọ́, ohun tó dùn mọ́ wa ni pé, láìpẹ́, Ọlọ́run yóò dá àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ nídè nínú ayé tó túbọ̀ ń bà jẹ́ sí i yìí.

Ẹnì Kan Ṣoṣo Tá A Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé fún Ìdáǹdè

10. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jèhófà nìkan la lè gbẹ́kẹ̀ lé fún ìdáǹdè?

10 Bó o ṣe ń wàásù ìhìn rere, máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Jèhófà lẹnì kan ṣoṣo téèyàn lè gbẹ́kẹ̀ lé fún ìdáǹdè. Òun nìkan ṣoṣo ló lágbára tó sì tún fẹ́ láti gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nínú ìṣòro èyíkéyìí. (Ìṣe 4:24, 31; Ìṣí. 4:11) A mọ̀ dájú pé Jèhófà kò ní yéé gba àwọn èèyàn nínú ìṣòro, yóò sì máa mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, torí ó ti búra pé: “Dájúdájú, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti gbèrò, bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣẹlẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni o, ọ̀rọ̀ Jèhófà “kì yóò padà sọ́dọ̀ [rẹ̀] láìní ìyọrísí.”—Ka Aísáyà 14:24, 25; 55:10, 11.

11, 12. Kí ni Ọlọ́run jẹ́ kó dá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lójú?

11 Jèhófà jẹ́ kó dá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lójú pé òun máa dá wọn nídè nígbà tóun bá ń dá àwọn ẹni ibi lẹ́jọ́. Nígbà tí Ọlọ́run rán wòlíì Jeremáyà níṣẹ́ tó gba ìgboyà, pé kó lọ kìlọ̀ fáwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ paraku, ó sọ fún un pé: “Má fòyà.” Kí nìdí tó fi ní kó má fòyà? Ó ní: “Mo wà pẹ̀lú rẹ láti dá ọ nídè.” (Jer. 1:8) Bákan náà, nígbà tí Jèhófà fẹ́ pa ìlú Sódómù àti Gòmórà run, ó rán áńgẹ́lì méjì láti mú Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ jáde kúrò láwọn ìlú burúkú yẹn kí wọ́n máa bàa pa run pa pọ̀ mọ́ wọn. Lẹ́yìn náà, “Jèhófà mú kí òjò imí ọjọ́ àti iná rọ̀ . . . sórí Sódómù àti sórí Gòmórà.”—Jẹ́n. 19:15, 24, 25.

12 Àní, Jèhófà lè dá àwọn èèyàn rẹ̀ jákèjádò ayé nídè nínú ìparun tó kárí ayé pàápàá. Bí àpẹẹrẹ, nígbà kan tí Ọlọ́run fi Ìkún-omi pa àwọn èèyàn burúkú inú ayé run, ó “pa Nóà, oníwàásù òdodo mọ́ láìséwu pẹ̀lú àwọn méje mìíràn.” (2 Pét. 2:5) Bákan náà, Jèhófà tún máa dá àwọn olódodo nídè nígbà tó bá pa ayé búburú ìsinsìnyí run. Ìdí nìyẹn tí Ọ̀rọ̀ rẹ fi sọ pé: “Ẹ wá Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́kàn tútù ilẹ̀ ayé . . . Ẹ wá òdodo, ẹ wá ọkàn-tútù. Bóyá a lè pa yín mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Jèhófà.” (Sef. 2:3) Ohun tí ìparun tó karí ayé yẹn sì máa yọrí sí ni pé ‘àwọn adúróṣánṣán yóò máa gbé ilẹ̀ ayé àmọ́ àwọn ẹni burúkú, ni a óò ké kúrò lórí rẹ̀.’—Òwe 2:21, 22.

13. Báwo ni Jèhófà ṣe máa dá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ti kú nídè?

13 Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni àìsàn, inúnibíni àtàwọn nǹkan míì ti ṣekú pa. (Mát. 24:9) Báwo wá ni Ọlọ́run ṣe máa dá àwọn yẹn nídè? Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ ṣáájú, “àjíǹde àwọn olódodo . . . yóò wà.” (Ìṣe 24:15) Ohun ìtùnú gbáà ló jẹ́ láti mọ̀ pé ohunkóhun ò lè dí Jèhófà lọ́wọ́ kó má dá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nídè!

Ìjọba Òdodo

14. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé ìjọba òdodo ni Ìjọba Ọlọ́run?

14 Tó o bá ń wàásù, máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ìjọba òdodo ni Ìjọba tí Jèhófà gbé kalẹ̀ lọ́run. Nítorí pé Ìjọba yìí yóò gbé àwọn ànímọ́ àgbàyanu tí Ọlọ́run ní yọ, irú bí ìdájọ́ òdodo àti ìfẹ́. (Diu. 32:4; 1 Jòh. 4:8) Jésù Kristi ẹni tó tóótun jù lọ láti ṣàkóso ayé ni Ọlọ́run gbé Ìjọba yìí lé lọ́wọ́. Jèhófà tún ti ṣètò pé òun máa mú àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì lọ sí ọ̀run kí wọ́n lè jẹ́ ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi, tí wọ́n yóò sì jọ máa ṣàkóso ayé.—Ìṣí. 14:1-5.

15. Sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín Ìjọba Ọlọ́run àti ìjọba èèyàn.

15 Ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ ni yóò wà nínú ìṣàkóso tí Jésù àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì yóò ṣe àtèyí tàwọn èèyàn aláìpé ń ṣe. Àwọn alákòóso ayé yìí sábà máa ń ya òǹrorò ẹ̀dá, wọ́n sì máa ń ti àwọn ọmọ abẹ́ wọn sójú ogun, èyí tó ti jẹ́ kí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn bógun lọ. Abájọ tí Ìwé Mímọ́ fi gbà wá nímọ̀ràn pé ká má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé èèyàn, “ẹni tí ìgbàlà kò sí lọ́wọ́ rẹ̀.” (Sm. 146:3) Àmọ́ ìfẹ́ ni Kristi máa fi ṣe ìjọba tirẹ̀. Jésù ní: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín. Nítorí àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́.”—Mát. 11:28-30.

Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn Máa Tó Dópin!

16. Báwo làwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí ṣe máa dópin?

16 Látọdún 1914 layé yìí ti wà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tàbí “ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 24:3) Láìpẹ́, “ìpọ́njú ńlá” tí Jésù sọ máa bẹ́ sílẹ̀. (Ka Mátíù 24:21.) Ìpọ́njú tá ò rí irú ẹ̀ rí yìí ni yóò mú ayé Sátánì wá sópin. Àmọ́, báwo ni ìpọ́njú ńlá yẹn ṣe máa bẹ̀rẹ̀? Báwo ló sì ṣe máa dópin?

17. Kí ni Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ ṣáájú ìpọ́njú ńlá?

17 Òjijì ni ìpọ́njú ńlá yóò bẹ̀rẹ̀. Àní sẹ́, àìròtẹ́lẹ̀ ni “ọjọ́ Jèhófà” yóò dé bá wọn ní “ìgbà yòówù . . . tí wọ́n bá ń sọ pé: ‘Àlàáfíà àti ààbò!’” (Ka 1 Tẹsalóníkà 5:2, 3.) Ìgbà táwọn orílẹ̀-èdè bá rò pé àwọn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ yanjú àwọn kan lára àwọn ìṣòro ńlá táráyé ní, ni ìpọ́njú ńlá tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ máa bẹ̀rẹ̀. Ìparun òjijì tó máa bá “Bábílónì Ńlá,” ìyẹn ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, máa jẹ́ ìyàlẹ́nu fáráyé. Ẹnu yóò ya àwọn ọba ayé àtàwọn míì nígbà tí Ọlọ́run bá dá Bábílónì Ńlá lẹ́jọ́.—Ìṣí. 17:1-6, 18; 18:9, 10, 15, 16, 19.

18. Kí ni Jèhófà yóò ṣe nípa ìjà tí Sátánì gbé ko àwọn èèyàn Ọlọ́run?

18 Tọ́rọ̀ bá wá dójú ẹ̀ tán nígbà ìpọ́njú ńlá, “àwọn àmì yóò wà nínú oòrùn àti òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀,” bákan náà, “àmì Ọmọ ènìyàn yóò fara hàn ní ọ̀run.” Nígbà náà, a óò wá ‘gbé orí wa sókè, nítorí pé ìdáǹdè wa ń sún mọ́lé.’ (Lúùkù 21:25-28; Mát. 24:29, 30) Sátánì, tá a tún mọ̀ sí Gọ́ọ̀gù máa dojú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kọ àwọn èèyàn Ọlọ́run. Àmọ́, ohun tí Jèhófà sọ fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ nípa èyí ni pé: “Ẹni tí ó bá fọwọ́ kàn yín ń fọwọ́ kan ẹyinjú mi.” (Sek. 2:8) Nítorí náà, asán ni ìsapá Sátánì láti run àwọn èèyàn Ọlọ́run máa já sí. Kí nìdí? Torí pé Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò gbégbèésẹ̀ ní kíá láti dá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nídè.—Ìsík. 38:9, 18.

19. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé ẹgbẹ́ ogún Ọlọ́run yóò pa ayé Sátánì run?

19 Nígbà tí Ọlọ́run bá bẹ̀rẹ̀ sí í dá àwọn orílẹ̀-èdè lẹ́jọ́, wọn yóò ‘mọ̀ pé òun ni Jèhófà.’ (Ìsík. 36:23) Yóò rán Kristi Jésù kí ó kó ọ̀kẹ́ àìmọye ẹ̀dá ẹ̀mí tó jẹ́ ẹgbẹ́ ogun Ọlọ́run láti wá pa ìyókù ètò Sátánì lórí ilẹ̀ ayé run. (Ìṣí. 19:11-19) Tá a bá rántí pé nígbà kan rí, òru ọjọ́ kan ṣoṣo ni áńgẹ́lì kan péré pa “ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n” lára àwọn ọ̀tá Ọlọ́run, yóò dá wa lójú pé bí ẹní fẹran jẹ̀kọ làwọn ẹgbẹ́ ogun ọ̀run ṣe máa pa gbogbo ìyókù ètò Sátánì lórí ilẹ̀ ayé rẹ́ ráúráú nígbà Amágẹ́dọ́nì tó máa fòpin sí ìpọ́njú ńlá. (2 Ọba 19:35; Ìṣí. 16:14, 16) Ọlọ́run yóò wá sọ Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sí ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún ọdún. Yóò sì wá pa wọ́n run níkẹyìn.—Ìṣí. 20:1-3.

20. Kí ni Jèhófà yóò lo Ìjọba rẹ̀ láti ṣe?

20 Bí Jèhófà yóò ṣe mú ìwà ibi kúrò láyé nìyẹn táwọn olódodo yóò sì máa gbé ilé ayé títí láé. Yóò wá hàn gbangba pé Jèhófà ni Ọlọ́run tí ń dání nídè. (Sm. 145:20) Jèhófà yóò lo Ìjọba rẹ̀ láti fi jẹ́ kó hàn pé òun ni Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run, láti fi sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́ àti láti fi mu ìpinnu rẹ̀ nípa ayé ṣẹ. Àdúrà wa ni pé kó o túbọ̀ máa láyọ̀ bó o ṣe ń wàásù ìhìn rere tó o sì ń jẹ́ kí “àwọn tí wọ́n . . . ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun” mọ̀ pé ìdáǹdè nípasẹ̀ Ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀!—Ìṣe 13:48.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run ṣe pàtàkì?

• Kí nìdí tá a fi nílò ìdáǹdè nísinsìnyí ju tìgbàkigbà rí lọ?

• Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni ká máa retí nígbà ìpọ́njú ńlá?

• Báwo ni yóò ṣe wá hàn gbangba pé Jèhófà ni Ọlọ́run tí ń dáni nídè?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12, 13]

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé a ó ṣe iṣẹ́ ìwàásù tí kò lẹ́gbẹ́ kárí ayé lákòókò wa yìí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Jèhófà lè dá wa nídè bó ṣe dá Nóà àti ìdílé rẹ̀ nídè

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Jèhófà “yóò . . . nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́.”—Ìṣí. 21:4