Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Máa Wà Ní Mímọ́ Nínú Ìbẹ̀rù Ọlọ́run

Ẹ Máa Wà Ní Mímọ́ Nínú Ìbẹ̀rù Ọlọ́run

Ẹ Máa Wà Ní Mímọ́ Nínú Ìbẹ̀rù Ọlọ́run

NÍGBÀ tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà Ọlọ́run ṣe jẹ́ ẹni mímọ́ jù lọ, ó ní: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà.” (Aísá. 6:3; Ìṣí. 4:8) Àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù àti ti Gíríìkì tó túmọ̀ sí ìjẹ́mímọ́ la fi máa ń ṣàlàyé ohun tó mọ́ tónítóní, ìsìn tí kò lábààwọ́n, tàbí ohun tí kò ní ẹ̀gbin kankan. Ohun tí ìjẹ́mímọ́ Ọlọ́run túmọ̀ sí ni pé Ọlọ́run ò lábààwọ́n kankan, ó sì fọwọ́ pàtàkì mú ìwà tó mọ́ látòkèdélẹ̀.

Ǹjẹ́ Jèhófà, Ọlọ́run mímọ́ kò ní retí pé káwọn tó ń jọ́sìn òun jẹ́ mímọ́ ní ti ara, ní ti ìwà àti nípa tẹ̀mí? Bíbélì là á mọ́lẹ̀ pé Jèhófà ń fẹ́ káwọn èèyàn òun jẹ́ mímọ́. Nínú 1 Pétérù 1:16, Jèhófà sọ pé: “Ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́, nítorí pé èmi jẹ́ mímọ́.” Ǹjẹ́ èèyàn aláìpé lè jẹ́ mímọ́ bíi ti Jèhófà? Bẹ́ẹ̀ ni, àmọ́ a ò lè pé pátápátá bíi tirẹ̀. A lè sọ pé a jẹ́ mímọ́ lójú Ọlọ́run tá a bá ń jọ́sìn rẹ̀ lọ́nà mímọ́, tí àjọṣe àárín àwa àti Ọlọ́run sì gún régé.

Àmọ́ o, báwo la ṣe lè wà ní mímọ́ nínú ayé aláìmọ́ yìí? Àwọn ìwà wo ló yẹ ká yẹra fún? Àwọn ìyípadà wo ló lè pọn dandan pé ká ṣe nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè rí kọ́ lórí kókó yìí látinú ohun tí Ọlọ́run ní káwọn Júù tó kúrò ní Bábílónì ṣe nígbà tí wọ́n ń padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn lọ́dún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni.

‘Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́ Yóò Wà Níbẹ̀’

Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn òun tó wà nígbèkùn ní Bábílónì yóò padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn. Àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe máa padà sí ìlú wọn yẹn fún wọn ní ìdánilójú kan, ó sọ pé: “Dájúdájú, òpópó kan yóò sì wá wà níbẹ̀, àní ọ̀nà kan; Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́ sì ni a ó máa pè é.” (Aísá. 35:8a) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí fi hàn pé yàtọ̀ sí pé Jèhófà máa ṣe ọ̀nà àbáyọ fún àwọn Júù láti padà wálé, ó tún mú un dá wọn lójú pé òun yóò dáàbò bò wọ́n lójú ọ̀nà.

Jèhófà ṣí “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” sílẹ̀ fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ òde òní, ọ̀nà tó ṣí sílẹ̀ yìí ni wọ́n gbà jáde kúrò nínú Bábílónì Ńlá, ìyẹn ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé. Lọ́dún 1919 Jèhófà dá àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró sílẹ̀ kúrò nínú ìgbèkùn tẹ̀mí tí ìsìn èké ti kó wọn sí. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í mú gbogbo ẹ̀kọ́ èké kúrò nínú ìjọsìn wọn. Lóde òní, ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ tónítóní ó sì ń tuni lára, èyí ló mú kó ṣeé ṣe fún wa láti máa jọ́sìn Jèhófà tó sì jẹ́ ká lè ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú rẹ̀ àtàwọn ará wa.

Àwọn tó jẹ́ “agbo kékeré,” ìyẹn àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àtàwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti àwọn àgùntàn mìíràn ti pinnu láti máa rìn ní ọ̀nà mímọ́ yẹn, wọ́n sì ń pe àwọn èèyàn láti wá dara pọ̀ mọ́ wọn. (Lúùkù 12:32; Ìṣí. 7:9; Jòh. 10:16) “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” ti ṣí sílẹ̀ fún àwọn tó bá fẹ́ láti “fi ara [wọn] fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà.”—Róòmù 12:1.

“Aláìmọ́ Kì Yóò Gbà Á Kọjá”

Lọ́dún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ohun pàtàkì kan wà tá à ń retí látọ̀dọ̀ àwọn Júù tó ń padà lọ sí ìlú wọn. Aísáyà 35:8b sọ nípa àwọn tí wọ́n yẹ láti máa rin “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” yẹn pé: “Aláìmọ́ kì yóò gbà á kọjá. Yóò sì wà fún ẹni tí ń rìn lójú ọ̀nà, òmùgọ̀ kankan kì yóò sì rìn káàkiri lórí rẹ̀.” Nígbà tó jẹ́ pé torí káwọn Júù lè mú ìjọsìn tòótọ́ padà bọ̀ sípò ni wọ́n fi padà sí Jerúsálẹ́mù, kò ní sáyè fáwọn onímọtara ẹni nìkan, àwọn tí kò bọ̀wọ̀ fún ohun mímọ́ tàbí àwọn tó ń ṣohun ẹlẹ́gbin. Wọ́n ní láti máa pa ìlànà Jèhófà nípa ìwà rere mọ́. Lónìí, àwọn tó bá fẹ́ rí ojú rere Ọlọ́run ní láti ṣe ohun kan náà. Wọ́n ní láti máa wà ní ‘mímọ́ nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.’ (2 Kọ́r. 7:1) Àwọn ohun àìmọ́ wo ló wá yẹ ká yẹra fún?

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àwọn iṣẹ́ ti ara fara hàn kedere, àwọn sì ni àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìwà àìníjàánu.” (Gál. 5:19) Àgbèrè ni gbogbo ìbálòpọ̀ tó jẹ mọ́ lílo ẹ̀ya ìbímọ ẹni pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe aya tàbí ọkọ ẹni. Ìwà àìníjàánu jẹ́ “ìṣekúṣe; ìṣekúṣe tí kò ní ìjánu; ìwà àìnítìjú; ìwà ìbàjẹ́.” Àgbèrè àti ìwà àìníjàánu lòdì sí ìjẹ́mímọ́ Jèhófà pátápátá. Nítorí náà, a kò gba àwọn tó ń bá a nìṣó láti máa ṣe irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ láyè láti jẹ́ ara ìjọ Kristẹni. Ńṣe la máa ń yọ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lẹ́gbẹ́. Ohun kan náà la máa ń ṣe fáwọn tó ń hu ìwà àìmọ́ tó burú jáì, ìyẹn fifi “ìwọra hu onírúurú ìwà àìmọ́ gbogbo.”—Éfé. 4:19.

Onírúurú ẹ̀ṣẹ̀ la lè pè ní “ìwà àìmọ́.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí ìwà àìmọ́ máa ń tọ́ka sí ìdọ̀tí tàbí ẹ̀gbin èyíkéyìí, èyí tí ìwà wa, ọ̀rọ̀ ẹnu wa, tàbí àwọn tá à ń bá kẹ́gbẹ́ lè kó bá wa. Ó kan irú àwọn ìwà àìmọ́ kan tó lè má pọn dandan kó déwájú ìgbìmọ̀ ìdájọ́. a Àmọ́, ṣé a lè sọ pé àwọn tó ń hu irú ìwà àìmọ́ bẹ́ẹ̀ fẹ́ láti máa wà ní mímọ́?

Ká sọ pé Kristẹni kan bẹ̀rẹ̀ sí í wo àwòrán tó ń mú ọkàn ẹni fà sí ìṣekúṣe ní bòókẹ́lẹ́. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, bí ìfẹ́ ìṣekúṣe bá ṣe ń lágbára sí i lọ́kàn rẹ̀, ìpinnu tó ti ṣe láti wà ní mímọ́ lójú Jèhófà á máa mẹ́hẹ. Lóòótọ́ ìwà rẹ̀ lè má tíì di ìwà àìmọ́ tó burú jáì, àmọ́ ó ti kúrò lẹ́ni tá a lè sọ pé ó ń ronú lórí ‘ohun yòówù tí ó jẹ́ mímọ́, ohun yòówù tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ìwà funfun àti ohun yòówù tí ó yẹ fún ìyìn.’ (Fílí. 4:8) Wíwo àwòrán tó ń mú ọkàn ẹni fà sí ìṣekúṣe jẹ́ ìwà àìmọ́, ó sì dájú pé ó máa ń ba àjọṣe ẹni pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Kò tiẹ̀ yẹ ká gbọ́ pé ẹnì kan ń hu ìwà àìmọ́ èyíkéyìí láàárín wa.—Éfé. 5:3.

Gbé àpẹẹrẹ mìíràn yẹ̀ wò. Ká ní Kristẹni kan ti sọ ọ́ dàṣà láti máa fi ọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ara rẹ̀ láti lè mú kí ara rẹ̀ gbóná. Ó tiẹ̀ lè máa wo àwòrán tó ń mú kí ọkàn ẹni fà sí ìṣekúṣe nígbà tó bá ń ṣe é, ó sì lè má wò ó. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò sọ̀rọ̀ nípa fífi ọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ara ẹni, ǹjẹ́ irú ìwà bẹ́ẹ̀ kò lè sọ ọpọlọ àti èrò ẹni di ẹlẹ́gbin? Tẹ́nì kan bá ń hu irú ìwà ẹlẹ́gbin yìí tí kò sì jáwọ́, ṣé kò ní ba àjọṣe onítọ̀hún pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ kó sì sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin lójú rẹ̀? Ẹ jẹ́ ká fi ọ̀rọ̀ ìyànjú tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ sọ́kàn pé ká “wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí,” ó tún sọ pé, “ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò.”—2 Kọ́r. 7:1; Kól. 3:5.

Ayé tí Sátánì ń ṣàkóso yìí fàyè gba ìwà àìmọ́, ó tún ń gbé e lárugẹ pàápàá. Ó lè ṣòro gan-an kéèyàn tó lè dènà ìdẹwò tó lè fẹ́ múni hùwà àìmọ́. Àmọ́ àwa Kristẹni tòótọ́ kò gbọ́dọ̀ “máa bá a lọ mọ́ ní rírìn gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú ti ń rìn nínú àìlérè èrò inú wọn.” (Éfé. 4:17) Ó dìgbà tá a bá yẹra fún ìwà àìmọ́, bóyá ní kọ̀rọ̀ tàbí ní gbangba, kí Jèhófà tó lè jẹ́ ká máa rìn nìṣó ní “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́.”

“Kìnnìún Kankan Kì Yóò Sí Níbẹ̀”

Ó lè gba pé káwọn kan ṣe ìyípadà tó lágbára nínú ìwà àti ọ̀rọ̀ wọn tí wọ́n bá fẹ́ rí ojú rere Jèhófà Ọlọ́run mímọ́. Aísáyà 35:9 sọ pé: “Kìnnìún kankan kì yóò sí níbẹ̀, irú apẹranjẹ ẹranko ẹhànnà kankan kì yóò sì wá sórí rẹ̀,” ìyẹn “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́.” A sábàá máa ń fi àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ oníwà ipá àti oníjàgídíjàgan nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wé ẹranko ẹhànnà. Ó dájú pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò ní sí nínú ayé tuntun òdodo ti Ọlọ́run. (Aísá. 11:6; 65:25) Ó ṣe pàtàkì gan-an fáwọn tó bá fẹ́ rí ojú rere Ọlọ́run pé kí wọ́n fi irú àwọn ìwà ẹhànnà bẹ́ẹ̀ sílẹ̀, kí wọ́n sì máa wà ní mímọ́.

Ìwé Mímọ́ gbà wá níyànjú pé: “Kí ẹ mú gbogbo ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ìwà búburú.” (Éfé. 4:31) Kólósè 3:8 kà pé: “Ẹ mú gbogbo wọn kúrò lọ́dọ̀ yín, ìrunú, ìbínú, ìwà búburú, ọ̀rọ̀ èébú, àti ọ̀rọ̀ rírùn kúrò lẹ́nu yín.” Gbólóhùn náà, “ọ̀rọ̀ èébú,” tá a lò nínú ẹsẹ méjèèjì yìí jẹ́ ọ̀rọ̀ tó ń kanni lábùkù tàbí ọ̀rọ̀ òdì.

Lónìí, àwọn ọ̀rọ̀ aṣa, tó ń pani lára pọ̀ lẹ́nu àwọn èèyàn, kódà wọ́n wà nínú agboolé pàápàá. Àwọn lọ́kọláya máa ń sọ òkò ọ̀rọ̀ àti ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ara wọn tàbí sí àwọn ọmọ wọn. Irú àwọn ọ̀rọ̀ kòbákùngbé wọ̀nyí kò gbọ́dọ̀ máa wáyé nílé àwọn Kristẹni.—1 Kọ́r. 5:11.

Wíwà ní ‘Mímọ́ Nínú Ìbẹ̀rù Ọlọ́run’ Máa Ń Yọrí sí Ìbùkún!

Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńláǹlà ló jẹ́ láti máa sin Jèhófà Ọlọ́run mímọ́! (Jóṣ. 24:19) Párádísè tẹ̀mí tí Jèhófà mú ká wá sínú rẹ̀ ṣeyebíye gan-an ni. Jíjẹ́ kí ìwà wa máa wà ní mímọ́ lójú Jèhófà ni ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà gbé ìgbésí ayé wa.

Láìpẹ́ Párádísè orí ilẹ̀ ayé tí Ọlọ́run ṣèlérí yóò dé. (Aísá. 35:1, 2, 5-7) Àwọn tí wọ́n ń fojú sọ́nà fún un, tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run ni yóò wà níbẹ̀. (Aísá. 65:17, 21) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa bá a nìṣó láti máa sin Ọlọ́run lọ́nà mímọ́, ká sì jẹ́ kí àjọṣe àárín àwa pẹ̀lú rẹ̀ dán mọ́rán.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó o bá fẹ́ mọ̀ nípa ìyàtọ̀ tó wà láàárín ‘ìwà àìmọ́ téèyàn fi ìwà ìwọra hù’ àti “ìwà àìmọ́,” wo Ilé Ìṣọ́, July 15, 2006, ojú ìwé 29 sí 31.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Kí ni Ọlọ́run ń retí látọ̀dọ̀ àwọn Júù kí wọ́n lè máa rìn ní “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́”?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Àwòrán tó ń mú ọkàn ẹni fà sí ìṣekúṣe máa ń ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

“Ẹ mú gbogbo . . . ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín”