Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí A Ṣe Ṣètò Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Bí A Ṣe Ṣètò Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Bí A Ṣe Ṣètò Ìgbìmọ̀ Olùdarí

ÀWỌN ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ tí wọ́n sì jẹ́ ẹni àmì òróró ló wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n ń ṣojú fún ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye tó ń fún wa lóúnjẹ tẹ̀mí, tó sì ń tọ́ wa sọ́nà, tó sì ń rí i dájú pé iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run ń tẹ̀ síwájú kárí ayé.—Mát. 24:14, 45-47.

Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ń ṣèpàdé, èyí sì sábà máa ń jẹ́ lọ́jọ́ Wednesday. Ìpàdé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ yìí máa ń mú káwọn arákùnrin yìí lè ṣiṣẹ́ pa pọ̀ níṣọ̀kan. (Sm. 133:1) A pín àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí yìí sí oríṣiríṣi ìgbìmọ̀ kéékèèké. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ìgbìmọ̀ wọ̀nyí ní àwọn iṣẹ́ àtàwọn ọ̀ràn pàtó tí wọ́n ń bójú tó kí ìtẹ̀síwájú lè máa bá gbogbo ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn ìgbìmọ̀ náà àti iṣẹ́ tí wọ́n ń bójú tó la ṣàlàyé ṣókí nípa rẹ̀ nísàlẹ̀ yìí.

◼ ÌGBÌMỌ̀ OLÙṢEKÒKÁÁRÍ: Àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ olùṣekòkáárí ni àwọn tó ń ṣe kòkáárí ìgbìmọ̀ kọ̀ọ̀kan tá a pín àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí sí, wọ́n sì máa ń ní akọ̀wé kan tóun náà jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Ìgbìmọ̀ yìí máa ń rí sí i pé iṣẹ́ gbogbo ìgbìmọ̀ yòókù ń lọ déédéé láìsí ìdílọ́wọ́ kankan. Òun ló tún máa ń bójú tó àwọn ọ̀ràn pàjáwìrì tó lágbára, inúnibíni, ìjábá, àtàwọn ọ̀ràn míì tó jẹ́ kánjúkánjú tó sì kan àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé.

◼ ÌGBÌMỌ̀ TÓ Ń BÓJÚ TÓ Ọ̀RÀN ÒṢÌṢẸ́: Àwọn arákùnrin tó wà nínú ìgbìmọ̀ yìí ló ń bójú tó gbogbo ètò tó wà fún ìtọ́jú àwọn ìdílé Bẹ́tẹ́lì kárí ayé, àwọn ló ń pèsè ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n nílò, wọ́n sì ń bójú tó àwọn ètò táá máa jẹ́ kí wọ́n lágbára nípa tẹ̀mí. Ìgbìmọ̀ yìí ló ń bójú tó bí wọ́n ṣe ń pe àwọn tó fẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì, àwọn ló sì ń bójú tó gbogbo ọ̀ràn tó bá jẹ yọ lórí iṣẹ́ ìsìn wọn ní Bẹ́tẹ́lì.

◼ ÌGBÌMỌ̀ ÌṢÈWÉJÁDE: Ìgbìmọ̀ yìí ló ń bójú tó bá a ṣe ń tẹ̀ àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì àti bá a ṣe ń mú wọn jáde tá a sì ń kó wọn lọ sápá ibi gbogbo láyé. Ìgbìmọ̀ yìí ló ń bójú tó àwọn ilé ìtẹ̀wé títí kan ilé, ilẹ̀ àti dúkìá míì tó jẹ ti onírúurú àjọ tàwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò lábẹ́ òfin. Ìgbìmọ̀ yìí ló máa ń ṣètò ọ̀nà tó dára jù lọ tá a lè gbà lo owó táwọn èèyàn fi ń ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tá à ń ṣe kárí ayé.

◼ ÌGBÌMỌ̀ IṢẸ́ ÌSÌN: Àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ yìí ló ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù, àwọn ló sì ń bójú tó ọ̀ràn tó kan àwọn ìjọ, àwọn aṣáájú ọ̀nà, àwọn alàgbà àtàwọn alábòójútó arìnrìn-àjò. Ìgbìmọ̀ yìí ló ń bójú tó ohun tó ń jáde nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, òun ló sì ń pe àwọn tó máa wá sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, àti Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, òun ló máa sọ ibi táwọn tó bá jáde láwọn ilé ẹ̀kọ́ yìí á ti lọ sìn.

◼ ÌGBÌMỌ̀ ÌKỌ́NILẸ́KỌ̀Ọ́: Ìgbìmọ̀ yìí ló ń bójú tó àwọn ìtọ́ni tó ń jáde láwọn àpéjọ àti ìpàdé ìjọ. Òun ló ń ṣètò oúnjẹ tẹ̀mí fáwọn tó wà nínú ìdílé Bẹ́tẹ́lì, òun ló sì ń bójú tó oríṣiríṣi ilé ẹ̀kọ́, irú bí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì àti Ilé Ẹ̀kọ́ Aṣáájú Ọ̀nà. Ìgbìmọ̀ yìí ló tún ń bójú tó bí wọ́n ṣe ń gbé àwọn ìsọfúnni jáde sórí fídíò pẹ̀lú kásẹ́ẹ̀tì àti àwo CD àtẹ́tísí.

◼ ÌGBÌMỌ̀ ÌKỌ̀WÉ: Ojúṣe ìgbìmọ̀ yìí ni láti bójú tó bí oúnjẹ tẹ̀mí á ṣe wà lákọọ́lẹ̀ àti bó ṣe máa dé ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa títí kan àwọn tí kì í ṣe ará wa pẹ̀lú. Ìgbìmọ̀ yìí ló máa ń dáhùn àwọn ìbéèrè tó bá jáde lórí Bíbélì, òun ló sì máa ń fọwọ́ sí àwọn ìwé àwòkẹ́kọ̀ọ́ tó fi mọ́ àwọn ìwé àsọyé àtàwọn ìsọfúnni míì. Ó tún máa ń bójú tó iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè tá à ń ṣe kárí ayé.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ìjọ àwọn ẹni àmì òróró wé ẹ̀yà ara èèyàn ó sì jẹ́ ká rí ipa pàtàkì tí olúkúlùkù ń kó àti bí wọ́n ṣe wúlò fún ara wọn tó. Ó tún jẹ́ ká rí bí ìfẹ́ àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ti ṣe pàtàkì tó bí wọ́n ṣe ń ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́. (Róòmù 12:4, 5;1 Kọ́r. 12:12-31) Jésù Kristi, tó jẹ́ Orí ìjọ ń pèsè gbogbo ohun tí ìjọ nílò fún wọn kí wọ́n bàa lè wà ní ìṣọ̀kan àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ kí wọ́n sì lè jọ máa gba ìtọ́ni kan náà láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Éfé. 4:15, 16; Kól. 2:19) Bá a ṣe ṣètò Ìgbìmọ̀ Olùdarí nìyí, kí wọ́n lè máa darí wa bí Jèhófà ṣe ń fi ẹ̀mí mímọ́ darí wọn.