Pinnu Láti Sin Jèhófà Látìgbà Èwe Rẹ
Pinnu Láti Sin Jèhófà Látìgbà Èwe Rẹ
“Máa bá a lọ nínú àwọn ohun tí o ti kọ́, tí a sì ti yí ọ lérò padà láti gbà gbọ́.”—2 TÍM. 3:14.
1. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo iṣẹ́ ìsìn àwọn èwe tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí rẹ̀?
IṢẸ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ táwọn èwe ń ṣe ṣe pàtàkì lójú Jèhófà gan-an, débi tó fi mí sí ọkàn lára àwọn tó kọ ìwé Sáàmù láti sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn èwe pé: “Àwọn ènìyàn rẹ yóò fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn ní ọjọ́ ẹgbẹ́ ológun rẹ. Nínú ọlá ńlá ìjẹ́mímọ́, láti inú ilé ọlẹ̀ ọ̀yẹ̀, ìwọ ní àwùjọ rẹ ti àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n rí bí ìrì tí ń sẹ̀.” (Sm. 110:3) Jèhófà ka àwọn èwe tí wọ́n ń fẹ́ láti máa sìn ín sí ẹni ọ̀wọ́n.
2. Irú ìmọ̀ràn wo làwọn èèyàn máa ń fáwọn èwe tó bá dọ̀rọ̀ ohun tí wọ́n máa fi ìgbésí ayé wọn ṣe?
2 Ẹ̀yin èwe tẹ́ ẹ wà nínú ìjọ Kristẹni, ǹjẹ́ ẹ ti ya ara yín sí mímọ́ fún Jèhófà? Ọ̀pọ̀ èwe ló máa ń nira fún láti pinnu bóyá kí wọ́n sin Ọlọ́run tòótọ́ tàbí kí wọ́n má sìn ín. Àwọn oníṣòwò, àwọn agbaninímọ̀ràn nílé ìwé, àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ sábà máa ń gba àwọn èwe nímọ̀ràn pé kí wọ́n máa lépa bí wọ́n á ṣe dẹni ńlá nínú ayé. Àwọn èèyàn sábà máa ń fi àwọn èwe tó ń lépa ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Jèhófà ṣe yẹ̀yẹ́. Àmọ́ ká sòótọ́, kéèyàn fi ìgbésí ayé rẹ̀ sin Ọlọ́run tòótọ́ ló dára jù lọ. (Sm. 27:4) Nítorí náà, ẹ gbé ìbéèrè mẹ́ta yìí yẹ̀ wò: Kí nìdí tó fi yẹ kó o sin Ọlọ́run? Báwo lo ṣe lè máa gbé ìgbé ayé ẹni tó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà láìka ohun táwọn èèyàn lè máa sọ tàbí ohun tí wọ́n lè máa ṣe sí? Irú àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn wo lo lè ní?
Kéèyàn Sin Jèhófà Ló Dára Jù
3. Kí ló yẹ ká ṣe bá a ṣe ń rí àwọn ohun àrà tí Jèhófà dá?
3 Kí nìdí tó fi yẹ kó o sin Ọlọ́run tòótọ́ tí ń bẹ láàyè? Ìwé Ìṣípayá 4:11 jẹ́ ká mọ ìdí náà, ó ní: “Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.” Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá Atóbilọ́lá tó dá gbogbo nǹkan. Ẹ ò rí bí ilẹ̀ ayé wa ṣe lẹ́wà tó! Jèhófà ló dá àwọn igi, òdòdó, ẹranko, agbami òkun, òkè ńlá àtàwọn omi tó ń ya wálẹ̀ látorí òkè. Ìwé Sáàmù 104:24 sọ pé: “Ilẹ̀ ayé kún fún àmújáde [Ọlọ́run].” A dúpẹ́ gan-an ni pé Jèhófà fi ìfẹ́ dá wa lọ́nà tó máa jẹ́ ká gbádùn ayé àti gbogbo ohun rere tó wà nínú rẹ̀! Ǹjẹ́ kò yẹ ká jẹ́ kí ìmọrírì àtọkànwá fún àwọn ohun àrà tí Ọlọ́run dá mú ká máa sìn ín?
4, 5. Kí làwọn ohun tí Jèhófà ṣe tó mú kí Jóṣúà sún mọ́ ọn?
4 Ọ̀rọ̀ tí Jóṣúà tó jẹ́ aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ jẹ́ ká mọ ìdí míì tó fi yẹ ká sin Jèhófà. Nígbà tó kù díẹ̀ kí Jóṣúà kú, ó sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ̀yin sì mọ̀ dáadáa ní gbogbo ọkàn-àyà yín àti ní gbogbo ọkàn yín pé kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín. Gbogbo wọn ti ṣẹ fún yín.” Kí nìdí tí Jóṣúà fi sọ̀rọ̀ yìí?—Jóṣ. 23:14.
5 Ilẹ̀ Íjíbítì ni Jóṣúà dàgbà sí, ó sì ti mọ ìlérí tí Jèhófà ṣe pé òun máa fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ilẹ̀ tiwọn. (Jẹ́n. 12:7; 50:24, 25; Ẹ́kís. 3:8) Jóṣúà sì ti fojú ara rẹ̀ rí bí Jèhófà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, tó mú Ìyọnu Mẹ́wàá bá àwọn ará Íjíbítì, tí Fáráò olóríkunkun fi jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ. Jóṣúà wà lára àwọn tó la Òkun Pupa já, ojú ẹ̀ lòkun sì ṣe bo Fáráò àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ mọ́lẹ̀. Jóṣúà rí bí Jèhófà ṣe ń fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní gbogbo ohun tí wọ́n nílò nígbà ìrìn-àjò ológójì ọdún tí wọ́n rìn la Aṣálẹ̀ Sínáì tó jẹ́ “aginjù ńlá àti amúnikún-fún-ẹ̀rù” kọjá. Kò sì sí èyíkéyìí nínú wọn tí òùngbẹ tàbí ebi pa kú. (Diu. 8:3-5, 14-16; Jóṣ. 24:5-7) Jóṣúà rí bí Ọlọ́run tí òun àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń sìn ṣe tì wọ́n lẹ́yìn nígbà tí wọ́n bá àwọn orílẹ̀-èdè alágbára tó wà ní ilẹ̀ Kénáánì jagun, tí wọ́n sì gba Ilẹ̀ Ìlérí.—Jóṣ. 10:14, 42.
6. Kí ló lè jẹ́ kó wù ọ́ láti máa sin Ọlọ́run?
6 Jóṣúà ti rí i pé Jèhófà mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Ìdí nìyẹn tó fi sọ pé: “Ní tèmi àti agbo ilé mi, Jèhófà ni àwa yóò máa sìn.” (Jóṣ. 24:15) Ìwọ ńkọ́? Tó o bá ronú nípa àwọn ìlérí tí Ọlọ́run tòótọ́ ti mú ṣẹ àtàwọn tó ṣì máa ṣẹ, ǹjẹ́ kò yẹ kó wu ìwọ náà láti máa sin Jèhófà bíi ti Jóṣúà?
7. Kí nìdí tí ìrìbọmi fi jẹ́ ìgbésẹ̀ pàtàkì tó yẹ ká gbé?
7 Ríronú lórí àwọn ohun tí Jèhófà dá àti ṣíṣàṣàrò lórí àwọn ìlérí rẹ̀ àgbàyanu tó ṣeé fọkàn tán yẹ kó mú ọ ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, kó o sì ṣe ìrìbọmi. Ìgbésẹ̀ pàtàkì tó yẹ láti gbé ni ìrìbọmi jẹ́ fáwọn tó bá fẹ́ sin Ọlọ́run. Jésù tó jẹ́ Àwòfiṣàpẹẹrẹ wa sì fi hàn pé ó ṣe pàtàkì lóòótọ́. Jésù lọ sọ́dọ̀ Jòhánù Olùbatisí láti ṣe ìrìbọmi kó tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà. Kí nìdí tí Jésù fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ó sọ ọ́ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà tó yá pé: “Èmi sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run, kì í ṣe láti ṣe ìfẹ́ mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi.” (Jòh. 6:38) Jésù ṣèrìbọmi láti fi hàn pé òun ṣe tán láti ṣe ìfẹ́ inú Baba òun.—Mát. 3:13-17.
8. Kí nìdí tí Tímótì fi pinnu láti sin Ọlọ́run, kí sì lohun tó yẹ kí ìwọ náà ṣe?
8 Wo àpẹẹrẹ Tímótì, ọ̀dọ́ kan tí Jèhófà fún ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ pàtàkì láti ṣe nígbà tó yá. Kí nìdí tí Tímótì fi pinnu láti sin Ọlọ́run tòótọ́? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé, ‘ó ti kẹ́kọ̀ọ́, a sì ti yí i lérò padà láti gbà wọ́n gbọ́.’ (2 Tím. 3:14) Tíwọ náà bá ti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tó o sì gbà gbọ́ pé òótọ́ lohun tó o kọ́, ọ̀rọ̀ rẹ dà bíi ti Tímótì nìyẹn. Ó yẹ kó o wá ṣèpinnu lórí ọ̀rọ̀ ṣíṣe ìrìbọmi wàyí. Ńṣe ni kó o kúkú sọ ohun tó o fẹ́ ṣe fáwọn òbí rẹ. Àwọn òbí rẹ àtàwọn alàgbà nínú ìjọ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti jẹ́ kó o mọ àwọn ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ pé èèyàn gbọ́dọ̀ ṣe kó tó lè ṣe ìrìbọmi.—Ka Ìṣe 8:12.
9. Báwo ni ìpinnu rẹ láti ṣèrìbọmi ṣe máa rí lára àwọn ẹlòmíràn?
9 Ó dára gan-an pé kẹ́ni tó bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í sin Ọlọ́run tòótọ́ ṣèrìbọmi. Tó o bá ti ṣèrìbọmi, o bẹ̀rẹ̀ eré ìje kan nìyẹn, tó dà bí eré ìje ẹlẹ́mìí ẹṣin, tó máa ń pẹ́ kí wọ́n tó sá a dé ìparí. Àmọ́ èrè wà níbẹ̀, torí nísinsìnyí, wàá máa ní ayọ̀ bó o ṣe ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, wàá sì tún ní ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú. (Héb. 12:2, 3) Wàá tún máa mú àwọn ará ilé rẹ, ọ̀rẹ́ rẹ àtàwọn ará ìjọ tí wọ́n ti wà lẹ́nu eré ìje náà láyọ̀. Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé wàá mú ọ̀kan àyà Jèhófà yọ̀. (Ka Òwe 23:15.) Ó dájú pé àwọn kan ò ní mọ ìdí tó o fi pinnu láti sin Jèhófà, inú wọn sì lè má dùn sí ìpinnu tó o ṣe yìí. Wọ́n tiẹ̀ lè ṣàtakò sí ọ pàápàá. Àmọ́ ó dájú pé o lè borí àtakò wọ̀nyẹn.
Táwọn Èèyàn Bá Bi Ọ́ Ní Ìbéèrè Tàbí Tí Wọ́n Ta Kò Ọ́
10, 11. (a) Ìbéèrè wo làwọn èèyàn lè bi ọ́ lórí ìpinnu rẹ láti sin Ọlọ́run? (b) Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ látinú ọ̀nà tí Jésù gbà dáhùn ìbéèrè nípa ìjọsìn tòótọ́?
10 Ó lè ya àwọn ọmọ iléèwé rẹ, ará àdúgbò àtàwọn mọ̀lẹ́bí rẹ lẹ́nu pé o pinnu láti sin Jèhófà. Wọ́n lè fẹ́ mọ ìdí tó o fi ṣerú ìpinnu bẹ́ẹ̀, kí wọ́n sì máa bi ọ́ ní ìbéèrè nípa ohun tó o gbà gbọ́. Báwo ló ṣe yẹ kó o fèsì? Láìsí àní-àní, ó yẹ kí ìwọ fúnra rẹ mọ ìdí tó o fi ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀, kó o bàa lè ṣàlàyé ìdí tó o fi ṣe é fáwọn èèyàn. Tó o bá sì fẹ́ dáhùn ìbéèrè lórí ohun tó o gbà gbọ́, àpẹẹrẹ Jésù ló dáa jù lọ láti tẹ̀ lé.
11 Nígbà táwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù da ìbéèrè bo Jésù nípa àjíǹde, ńṣe ló tọ́ka wọn sí Ìwé Mímọ́ kan tí wọn ò tíì fìgbà kan rí ronú lé lórí. (Ẹ́kís. 3:6; Mát. 22:23, 31-33) Nígbà tí akọ̀wé kan béèrè lọ́wọ́ Jésù pé èwo ló tóbi jù lọ nínú òfin, ńṣe ni Jésù ka ẹsẹ Bíbélì tó dáhùn ìbéèrè náà gan-an. Inú ọkùnrin náà sì dùn sí ìdáhùn tí Jésù fún un. (Léf. 19:18; Diu. 6:5; Máàkù 12:28-34) Ọ̀nà tí Jésù gbà lo Ìwé Mímọ́ àti bó ṣe ń sọ̀rọ̀ mú kí “ìpínyà dìde nípa rẹ̀ láàárín ogunlọ́gọ̀ náà,” àwọn alátakò rẹ̀ kò sì lè ṣe é ní jàǹbá kankan. (Jòh. 7:32-46) Nígbà tí ìwọ náà bá ń dáhùn ìbéèrè nípa ohun tó o gbà gbọ́, Bíbélì ni kó o máa lò, kó o sì máa fèsì “pẹ̀lú inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” (1 Pét. 3:15) Tí o kò bá mọ ìdáhùn ìbéèrè kan, sọ fún wọn pé o kò mọ̀ ọ́n, kó o sì sọ pé wàá lọ ṣèwádìí nípa rẹ̀. Lẹ́yìn náà, o lè lọ ṣèwádìí nínú Atọ́ka Àwọn Àkòrí tó máa ń wà nínú Ilé Ìṣọ́ December 15 lọ́dọọdún tàbí kó o lo ìwé atọ́ka Watch Tower Publications Index, tàbí àkójọ ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a ṣe sórí àwo CD [Watchtower Library on CD-ROM] tó bá wà ní èdè tó o gbọ́. Tó o bá múra sílẹ̀ dáadáa, wàá lè ‘mọ bí ó ti yẹ kí o dáhùn.’—Kól. 4:6.
12. Kí nìdí tí kò fi yẹ kó o jẹ́ kí inúnibíni kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ?
12 Yàtọ̀ sí pé kí wọ́n bi ọ́ ní ìbéèrè nípa ìpinnu rẹ àti ohun tó o gbà gbọ́, wọ́n tún lè ṣàtakò sí ọ. Ó ṣe tán, Sátánì Èṣù, ọ̀tá Ọlọ́run ló ń darí ayé yìí. (Ka 1 Jòhánù 5:19.) Àlá tí ò lè ṣẹ ni tó o bá lọ ń retí pé gbogbo èèyàn lá máa yìn ọ́, tínú wọn á sì máa dùn sí ìpinnu tó o ṣe. Ìgbà míì wà tí wọ́n máa ṣàtakò. Àwọn kan lè máa ‘sọ̀rọ̀ rẹ tèébútèébú,’ bóyá kí wọ́n kàn máa bú ẹ ṣáá. (1 Pét. 4:4) Àmọ́, máa rántí pé ìwọ nìkan kọ́ nirú èyí ń ṣẹlẹ̀ sí. Wọ́n ṣenúnibíni sí Jésù Kristi náà. Bí wọ́n ṣe ṣe sí àpọ́sítélì Pétérù náà nìyẹn, ó sì sọ pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe jẹ́ kí iná tí ń jó láàárín yín [ìyẹn, ìyà tó n jẹ yín] rú yín lójú, èyí tí ń ṣẹlẹ̀ sí yín fún àdánwò, bí ẹni pé ohun àjèjì ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa bá a lọ ní yíyọ̀ níwọ̀n bí ẹ ti jẹ́ alájọpín nínú àwọn ìjìyà Kristi.”—1 Pét. 4:12, 13.
13. Kí nìdí tínú àwọn Kristẹni fi lè máa dùn tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí wọn?
13 Tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni tàbí àtakò sí wa torí pé a jẹ́ Kristẹni ó yẹ kí inú wa máa dùn. Kí nìdí? Tó bá jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló ń fara mọ́ ohun tó ò ń ṣe, a jẹ́ pé ohun tó wu Sátánì lò ń ṣe nìyẹn, kì í ṣe ohun tó wu Ọlọ́run. Jésù kìlọ̀ pé: “Ègbé, nígbàkigbà tí gbogbo ènìyàn bá ń sọ̀rọ̀ yín ní dáadáa, nítorí nǹkan báwọ̀nyí ni àwọn baba ńlá wọn ṣe sí àwọn wòlíì èké.” (Lúùkù 6:26) Tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí ẹ, ńṣe ló ń fi hàn pé inú Sátánì àti ayé rẹ̀ kò dùn sí ọ torí pé ò ń sin Jèhófà. (Ka Mátíù 5:11, 12.) Ohun ìdùnnú sì ni tí wọ́n bá ‘ń gàn ọ́ nítorí orúkọ Kristi.’—1 Pét. 4:14.
14. Àǹfààní wo lèèyàn lè ní tó bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà láìfi inúnibíni pè?
14 Tó o bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà láìka àtakò sí, ó kéré tán àǹfààní mẹ́rin lo lè ní. Á ṣeé ṣe fún ẹ láti jẹ́rìí nípa Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀. Bó o ṣe ń fi ìṣòtítọ́ fara da inúnibíni yóò jẹ́ ìṣírí fáwọn ará. Àwọn tí kò mọ Jèhófà lè tipasẹ̀ ìwà rẹ tí wọ́n rí dẹni tó mọ Jèhófà. (Ka Fílípì 1:12-14.) Bó o ṣe ń rí i pé Jèhófà ń fún ọ lókun láti fara da àdánwò yóò jẹ́ kó o túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà sí i.
“Ilẹ̀kùn Ńlá” Ṣí Sílẹ̀ fún Ọ
15. “Ilẹ̀kùn ńlá” wo ló ṣí sílẹ̀ fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù?
15 Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ nílùú Éfésù, ó ní: “Ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò ni a ti ṣí sílẹ̀ fún mi.” (1 Kọ́r. 16:8, 9) Ilẹ̀kùn ńlá tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni àǹfààní tó ṣí sílẹ̀ fún un láti wàásù ìhìn rere lọ́nà àkànṣe, kó sì sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn ní ìlú yẹn. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe tẹ́wọ́ gba àǹfààní yìí, ó ṣeé ṣe fún un láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà, kí wọ́n sì máa sìn ín.
16. Báwo ni àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró ṣe gba ẹnu “ilẹ̀kùn ṣíṣísílẹ̀” wọlé lọ́dún 1919?
16 Lọ́dún 1919, Jésù Kristi tí Ọlọ́run ti ṣe lógo mú kí ‘ilẹ̀kùn ṣí sílẹ̀’ níwájú àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró, ìyẹn ni pé ó jẹ́ kí àǹfààní láti wàásù ṣí sílẹ̀ fún wọn. (Ìṣí. 3:8) Àwọn ẹni àmì òróró tẹ́wọ́ gba àǹfààní yìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ìhìn rere, wọ́n sì ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ìtara tó ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Kí ló wá jẹ́ àbájáde iṣẹ́ ìwàásù wọn? Wọ́n ti wàásù ìhìn rere náà jákèjádò ayé, táwọn èèyàn tó tó àádọ́ta dín nírínwó ọ̀kẹ́ [7,000,000] sì ti ń retí láti jèrè ìyè ayérayé nínú ayé tuntun Ọlọ́run.
17. Báwo lo ṣe lè gba ẹnu “ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò” yìí wọlé?
17 “Ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò” yẹn ṣì wà ní ṣíṣísílẹ̀ fún gbogbo àwọn tó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà. Àwọn tó ń tẹ́wọ́ gba àǹfààní yìí ń rí ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn bí wọ́n ṣe ń kópa tó jọjú nínú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere. Ẹ̀yin èwe tẹ́ ẹ jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà, báwo ni àǹfààní tí kò lẹ́gbẹ́ yìí ṣe ṣe pàtàkì tó lójú yín, ìyẹn àǹfààní láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè “ní ìgbàgbọ́ nínú ìhìn rere”? (Máàkù 1:14, 15) Ǹjẹ́ o ti ronú lórí ṣíṣe olùrànlọ́wọ́ aṣáájú-ọ̀nà tàbí aṣáájú-ọ̀nà déédéé? Ọ̀pọ̀ nínú yín tún lè láǹfààní láti kópa nínú iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, iṣẹ́ ìsìn ní Bẹ́tẹ́lì, aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe àti iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Bá a ṣe ń rí i lójoojúmọ́ pé ayé Sátánì ti ń kógbá sílé, ó túbọ̀ ń di kánjúkánjú fún wa pé ká tẹ́wọ́ gba àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn yìí. Ṣé wàá gba ẹnu “ilẹ̀kùn ńlá” yìí wọlé nísinsìnyí tákòókò ṣì wà?
‘Tọ́ Ọ Wò, Kí O sì Rí I Pé Jèhófà Jẹ́ Ẹni Rere’
18, 19. (a) Kí ló jẹ́ kó wu Dáfídì gan-an láti sin Jèhófà? (b) Kí ló fi hàn pé Dáfídì ò kábàámọ̀ pé òun sin Ọlọ́run?
18 Ọlọ́run mí sí Dáfídì Ọba tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Sáàmù láti ké sí àwọn èèyàn pé kí wọ́n ‘tọ́ ọ wò, kí wọ́n sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere.’ (Sm. 34:8) Nígbà tí Dáfídì ọba Ísírẹ́lì jẹ́ ọ̀dọ́mọdé olùṣọ́ àgùntàn, Jèhófà gbà á lọ́wọ́ àwọn ẹranko búburú. Ọlọ́run tì í lẹ́yìn nígbà tó bá Gòláyátì jà, ó sì tún gbà á lọ́wọ́ àwọn àjálù míì. (1 Sám. 17:32-51; Sm. 18, àkọlé) Inú rere onífẹ̀ẹ́ tí Ọlọ́run fi hàn sí Dáfídì ló jẹ́ kó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ìwọ fúnra rẹ ti ṣe, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, àní àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ àti ìrònú rẹ sí wa; kò sí ẹnì kankan tí a lè fi ọ́ wé.”—Sm. 40:5.
19 Dáfídì wá dẹni tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an, ó sì fẹ́ máa fi gbogbo ọkàn-àyà yìn ín. (Ka Sáàmù 40:8-10.) Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, Dáfídì ò fìgbà kankan kábàámọ̀ pé òun fayé òun sin Ọlọ́run tòótọ́. Gbígbé ìgbésí ayé rẹ̀ lọ́nà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu lohun tó jẹ ẹ́ lógún jù lọ, ìyẹn sì lohun tó ń fún un láyọ̀ tí kò lẹ́gbẹ́. Nígbà tí Dáfídì darúgbó, ó sọ pé: “Ìwọ ni ìrètí mi, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ìgbọ́kànlé mi láti ìgbà èwe mi wá. Àní títí di ọjọ́ ogbó àti orí ewú, Ọlọ́run, má fi mí sílẹ̀.” (Sm. 71:5, 18) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì ti darúgbó, síbẹ̀ ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ọ̀rẹ́ wọn sì túbọ̀ jinlẹ̀ sí i.
20. Kí nìdí tí sísin Ọlọ́run fi jẹ́ ọ̀nà tó dára jù lọ tó o lè gba lo ìgbésí ayé rẹ?
20 Ìtàn ìgbésí ayé Jóṣúà, Dáfídì àti Tímótì jẹ́ àfikún ẹ̀rí pé ọ̀nà tó dára jù lọ tó o lè gbà lo ìgbésí ayé rẹ ni pé kó o sin Jèhófà. Àǹfààní tó wà nínú dídi èèyàn ńlá nínú ayé yìí kò tó nǹkan lẹ́gbẹ̀ẹ́ àǹfààní ayérayé tó o máa ní látinú ‘sísìn Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ.’ (Jóṣ. 22:5) Tí o kò bá tíì ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà nínú àdúrà, bi ara rẹ pé, ‘Kí ló ń dá mi dúró láti di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?’ Bó o bá jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti ṣèrìbọmi, ṣé wàá fẹ́ kí ayọ̀ rẹ túbọ̀ pọ̀ sí i? Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o fi kún iṣẹ́ ìsìn rẹ, kó o sí máa tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò jẹ́ kó o rí bó o ṣe lè tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ nípa títẹ̀lé àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Sọ ìdí méjì tó fi yẹ ká sin Ọlọ́run.
• Kí ló jẹ́ kí Tímótì pinnu láti sin Ọlọ́run?
• Kí nìdí tó fi yẹ kó o dúró gbọn-in táwọn èèyàn bá ṣenúnibíni sí ọ?
• Àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn wo lo lè ní?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Kéèyàn fi ìgbésí ayé rẹ̀ sin Jèhófà lohun tó dáa jù lọ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Táwọn èèyàn bá bi ọ́ ní ìbéèrè nípa ìgbàgbọ́ rẹ, ṣé o lè dáhùn?