Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù Kó O Lè Tẹ̀ Síwájú Nínú Òtítọ́

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù Kó O Lè Tẹ̀ Síwájú Nínú Òtítọ́

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù Kó O Lè Tẹ̀ Síwájú Nínú Òtítọ́

“Mo ti ja ìjà àtàtà náà, mo ti sáré ní ipa ọ̀nà eré ìje náà dé ìparí, mo ti pa ìgbàgbọ́ mọ́.”—2 TÍM. 4:7.

1, 2. Àyípadà wo ni Sọ́ọ̀lù ará Tásù ṣe nígbèésí ayé rẹ̀, iṣẹ́ pàtàkì wo ló sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe?

 SỌ́Ọ̀LÙ ará Tásù jẹ́ olóye èèyàn tí kì í fọ̀rọ̀ falẹ̀. Àmọ́ ńṣe ló ń hùwà ‘ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ara rẹ̀.’ (Éfé. 2:3) Nígbà tó ń sọ irú èèyàn tóun jẹ́ lásìkò náà, ó ní: “Mo jẹ́ asọ̀rọ̀ òdì àti onínúnibíni àti aláfojúdi.”—1 Tím. 1:13.

2 Ṣùgbọ́n nígbà tó yá, Sọ́ọ̀lù ṣe àyípadà gidi nígbèésí ayé rẹ̀. Ó fi gbogbo ìwà tó ti ń hù tẹ́lẹ̀ sílẹ̀ pátápátá, ó sì sapá gidigidi láti lè dẹni tí kì í ‘wá àǹfààní ti ara rẹ̀ bí kò ṣe ti ọ̀pọ̀ ènìyàn.’ (1 Kọ́r. 10:33) Ó wá dèèyàn jẹ́jẹ́ tó ń ṣaájò àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó ti ń gbógun tì nígbà kan rí. (Ka 1 Tẹsalóníkà 2:7, 8.) Sọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo di òjíṣẹ́ . . . Èmi, ẹni tí ó kéré ju kékeré jù lọ nínú gbogbo ẹni mímọ́, ni a fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí yìí fún, pé kí n polongo ìhìn rere nípa àwọn ọrọ̀ tí kò ṣeé díwọ̀n ti Kristi.”—Éfé. 3:7, 8.

3. Báwo ni gbígbé àwọn lẹ́tà Pọ́ọ̀lù àti ìtàn iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ yẹ̀ wò yóò ṣe ràn wá lọ́wọ́?

3 Sọ́ọ̀lù yìí, tá a tún mọ̀ sí Pọ́ọ̀lù, wá dẹni tó tẹ̀ síwájú gan-an nínú òtítọ́. (Ìṣe 13:9) Tá a bá gbé àwọn lẹ́tà Pọ́ọ̀lù àti ìtàn iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ yẹ̀ wò, tá a sì wá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ rẹ̀, ó dájú pé ìtẹ̀síwájú wa nínú òtítọ́ á lè yára kánkán. (Ka 1 Kọ́ríńtì 11:1; Hébérù 13:7.) Ẹ jẹ́ ká wo bí àyẹ̀wò yẹn yóò ṣe jẹ́ ká túbọ̀ rí i pé ó ṣe pàtàkì pé ká ní ìṣètò ìdákẹ́kọ̀ọ́ tó ṣe gúnmọ́ tá a ó máa tẹ̀ lé, ká nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn jinlẹ̀-jinlẹ̀, ká má sì jọ ara wa lójú jù.

Ọ̀nà Tí Pọ́ọ̀lù Gbà Ń Ṣe Ìdákẹ́kọ̀ọ́

4, 5. Báwo ni ìdákẹ́kọ̀ọ́ ṣe ṣe Pọ́ọ̀lù láǹfààní?

4 Níwọ̀n bí Pọ́ọ̀lù ti jẹ́ Farisí tó gba ẹ̀kọ́ “lẹ́bàá ẹsẹ̀ Gàmálíẹ́lì, [àtẹni] tí a fún ní ìtọ́ni ní ìbámu pẹ̀lú àìgbagbẹ̀rẹ́ Òfin àwọn baba ńlá ìgbàanì,” ó ti mọ Ìwé Mímọ́ dé ìwọ̀n àyè kan. (Ìṣe 22:1-3; Fílí. 3:4-6) Nítorí náà, lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi, ó “lọ sí Arébíà,” èyí tó ṣeé ṣe kó jẹ́ Aṣálẹ̀ Síríà tàbí ibi tí kò fi bẹ́ẹ̀ sáriwo lágbègbè Arébíà tó ti máa lè ráyè ṣàṣàrò. (Gál. 1:17) Ó jọ pé ńṣe ni Pọ́ọ̀lù fẹ́ ṣàṣàrò lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó fi hàn pé Jésù gan-an ni Mèsáyà. Yàtọ̀ síyẹn, Pọ́ọ̀lù tún fẹ́ múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ ńlá tí ńbẹ níwájú rẹ̀. (Ka Ìṣe 9:15, 16, 20, 22.) Pọ́ọ̀lù rí i dájú pé òun wáyè láti ṣàṣàrò lórí àwọn nǹkan tẹ̀mí.

5 Ìmọ̀ Bíbélì àti ìjìnlẹ̀ òye tí Pọ́ọ̀lù ní látinú ìdákẹ́kọ̀ọ́ mú kó lè kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lọ́nà tó múná dóko. Bí àpẹẹrẹ, nínú sínágọ́gù ní Áńtíókù ti Písídíà, ó kéré tán Pọ́ọ̀lù fa ọ̀rọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ márùn-ún yọ látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù láti fi jẹ́rìí pé Jésù gan-an ni Mèsáyà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ló sì tún tọ́ka sí ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Ọ̀nà tó gbà ṣàlàyé ọ̀rọ̀ Bíbélì wọ àwọn èèyàn lọ́kàn débi pé “ọ̀pọ̀ àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe tí wọ́n ń jọ́sìn Ọlọ́run tẹ̀ lé Pọ́ọ̀lù àti Bánábà” lọ kí wọ́n lè gbọ́ àlàyé sí i. (Ìṣe 13:14-44) Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, nígbà táwọn Júù tó wà ní ìlú Róòmù wá bá Pọ́ọ̀lù ní ilé tó wọ̀ sí nílùú Róòmù, ó ṣàlàyé fún wọn “nípa jíjẹ́rìí kúnnákúnná nípa ìjọba Ọlọ́run àti nípa lílo ìyíniléròpadà pẹ̀lú wọn nípa Jésù láti inú òfin Mósè àti àwọn Wòlíì.”—Ìṣe 28:17, 22, 23.

6. Kí ló jẹ́ kí Pọ́ọ̀lù lè dúró gbọn-in nínú ìjọsìn Ọlọ́run nígbà àdánwò?

6 Nígbà tí àdánwò bá Pọ́ọ̀lù, ńṣe ló ń bá a nìṣó láti ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́, tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà níbẹ̀ sì ń fún un lókun. (Héb. 4:12) Nígbà tí wọ́n fi Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n nílùú Róòmù kí wọ́n tó pa á, ó ní kí Tímótì bá òun kó “àwọn àkájọ ìwé” àti “àwọn ìwé awọ” kan wá. (2 Tím. 4:13) Ó ṣeé ṣe káwọn ìwé yẹn jẹ́ àwọn apá kan nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí Pọ́ọ̀lù lò láti fi ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ tó jinlẹ̀. Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé kóun máa ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé láti lè ní ìmọ̀ Bíbélì tó máa jẹ́ kóun lè dúró gbọn-in.

7. Mẹ́nu kan àwọn àǹfààní tó wà nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé.

7 Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, tá a sì ń ṣàṣàrò jinlẹ̀ lé e lórí, a ó tẹ̀ síwájú dáadáa nínú ìjọsìn Ọlọ́run. (Héb. 5:12-14) Ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Sáàmù sọ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe wúlò tó, ó ní: “Òfin ẹnu rẹ dára fún mi, pàápàá ju ẹgbẹẹgbẹ̀rún wúrà àti fàdákà lọ. Àṣẹ rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi, nítorí pé tèmi ni ó jẹ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin. Èmi ti kó ẹsẹ̀ mi ní ìjánu kúrò nínú gbogbo ipa ọ̀nà búburú, kí èmi kí ó lè máa pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.” (Sm. 119:72, 98, 101) Ǹjẹ́ o ní ìṣètò ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ṣe gúnmọ́ tó ò ń tẹ̀ lé? Ǹjẹ́ ò ń ka Bíbélì lójoojúmọ́ tó o sì ń ṣàṣàrò lórí ohun tó ò ń kà gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan láti gbà múra sílẹ̀ fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó bá yọjú nínú ètò Ọlọ́run?

Sọ́ọ̀lù Dẹni Tó Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn

8. Irú ìwà wo ni Sọ́ọ̀lù ń hù sáwọn tí kì í ṣe ìsìn àwọn Júù?

8 Kí Sọ́ọ̀lù tó di Kristẹni, ó ní ìtara ìsìn gan-an, àmọ́ ẹni tí kì í bá ṣe ìsìn àwọn Júù kò já mọ́ nǹkan kan lójú rẹ̀. (Ìṣe 26:4, 5) Nígbà táwọn Júù ń sọ Sítéfánù lókùúta inú Sọ́ọ̀lù dùn sóhun tí wọ́n ń ṣe, bóyá nítorí ó gbà pé irú ikú yẹn ló tọ́ sí Sítéfánù. Ó lè jẹ́ pé ìyẹn gan-an ló wá ki í láyà. (Ìṣe 6:8-14; 7:54–8:1) Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Sọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí hùwà sí ìjọ lọ́nà bíburú jáì. Ó ń gbógun ti ilé kan tẹ̀ lé òmíràn àti pé, ní wíwọ́ àti ọkùnrin àti obìnrin jáde, òun a fi wọ́n sẹ́wọ̀n.” (Ìṣe 8:3) Àní, ó “lọ jìnnà dé ṣíṣe inúnibíni sí wọn, kódà ní àwọn ìlú ńlá tí ń bẹ lẹ́yìn òde.”—Ìṣe 26:11.

9. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Sọ́ọ̀lù tó fi wá yí ọ̀nà tó ń gbà bá àwọn èèyàn lò padà?

9 Ńṣe ni Sọ́ọ̀lù ń lọ sílùú Damásíkù láti lọ gbógun ti àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi nígbà tí Jésù Olúwa fara hàn án. Ìkọmànà ìmọ́lẹ̀ ara Ọmọ Ọlọ́run sì wá fọ́ Sọ́ọ̀lù lójú tó sì di pé wọ́n ní láti fà á lọ́wọ́ dé ìlú Damásíkù. Nígbà tó fi máa di pé Jèhófà lo Ananíà láti la Sọ́ọ̀lù lójú, ìwà Sọ́ọ̀lù sáwọn èèyàn ti yí padà pátápátá. (Ìṣe 9:1-30) Nígbà tó sì wá di ọmọlẹ́yìn Kristi, ó sapá gidigidi láti lè dẹni tó ń báwọn èèyàn lò bíi ti Jésù. Ìyẹn ni pé ó dẹni tó kọ ìwà ipá sílẹ̀, tó sì wá di “ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.”—Ka Róòmù 12:17-21.

10, 11. Ọ̀nà wo ni Pọ́ọ̀lù gbà fi ìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn sáwọn èèyàn?

10 Pọ́ọ̀lù ò kàn dúró lórí pé kí àlàáfíà ṣáà ti wà láàárín òun àtàwọn èèyàn. Ó fẹ́ rí i pé òun fi ìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn sí wọn, iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni tó ń ṣe sì jẹ́ kó lè ṣe é. Nígbà tó rin ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ àkọ́kọ́, ó wàásù ìhìn rere ní Éṣíà Kékeré. Pọ́ọ̀lù àtàwọn tó jọ rin ìrìn àjò yìí bá àtakò tó le kókó pàdé, síbẹ̀ ńṣe ni wọ́n gbájú mọ́ ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n ń ṣe fáwọn ọlọ́kàn tútù kí wọ́n lè di Kristẹni. Àní bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alátakò gbìyànjú láti pa Pọ́ọ̀lù nílùú Lísírà àti Íkóníónì, wọ́n ṣì tún padà lọ sílùú méjèèjì láti ṣèrànwọ́ fáwọn ará.—Ìṣe 13:1-3; 14:1-7; 19-23.

11 Nígbà tó yá, Pọ́ọ̀lù àtàwọn ará tó jọ rìnrìn àjò náà tún lọ wá àwọn tó fẹ́ mọ Ọlọ́run ní ìlú Fílípì tó wà nílẹ̀ Makedóníà. Aláwọ̀ṣe Júù kan tó ń jẹ́ Lìdíà fetí sí ìhìn rere ó sì di Kristẹni. Ó wá ṣẹlẹ̀ pé àwọn aláṣẹ ìlú yẹn fi ọ̀pá na Pọ́ọ̀lù àti Sílà wọ́n sì jù wọ́n sẹ́wọ̀n. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù wàásù fún onítúbú yẹn, bí òun àti ìdílé rẹ̀ ṣe ṣèrìbọmi tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sin Jèhófà nìyẹn.—Ìṣe 16:11-34.

12. Kí ló wá mú kí Sọ́ọ̀lù, aláfojúdi ẹ̀dá tẹ́lẹ̀, di àpọ́sítélì Jésù Kristi to nífẹ̀ẹ́ èèyàn?

12 Kí ló wá mú kí Sọ́ọ̀lù tó ti ń ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni tẹ́lẹ̀ rí wá padà di Kristẹni? Kí ló wá sọ aláfojúdi ẹ̀dá tẹ́lẹ̀ yìí, di àpọ́sítélì tó jẹ́ onínúure àti onífẹ̀ẹ́ èèyàn, tí kò kọ̀ láti fẹ̀mí ara rẹ̀ wewu nítorí káwọn èèyàn lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run àti Kristi? Àlàyé tí Pọ́ọ̀lù alára ṣe ni pé: “Ọlọ́run, ẹni tí ó . . . pè mí nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀, ronú pé ó dára láti ṣí Ọmọ rẹ̀ payá fún mi.” (Gál. 1:15, 16) Pọ́ọ̀lù sì kọ̀wé sí Tímótì pé: “Ìdí tí a fi fi àánú hàn sí mi ni pé nípasẹ̀ mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀ràn àkọ́kọ́, kí Kristi Jésù lè fi gbogbo ìpamọ́ra rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ kan lára àwọn tí yóò gbé ìgbàgbọ́ wọn lé e fún ìyè àìnípẹ̀kun.” (1 Tím. 1:16) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà dárí ji Pọ́ọ̀lù, bóun náà sì ṣe rí i pé Ọlọ́run fi irú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àánú ńlá bẹ́ẹ̀ hàn sóun, òun náà wá pinnu láti dẹni tó ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn nípa wíwàásù ìhìn rere fún wọn.

13. Kí ló yẹ kó mú wa máa fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, ọ̀nà wo la sì lè gbà máa ṣe é?

13 Bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe ń dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti àṣìṣe wa jì wá. (Sm. 103:8-14) Ọ̀kan lára àwọn tó kọ Sáàmù náà béèrè pé: “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ìṣìnà ni ìwọ ń ṣọ́, Jáà, Jèhófà, ta ni ì bá dúró?” (Sm. 130:3) Bí kò bá jẹ́ ti ọlá àánú Ọlọ́run ni, kò sí èyíkéyìí nínú wa tí ì bá láǹfààní àtirí ayọ̀ iṣẹ́ ìsìn mímọ́ gbà, à bá má sì ní ìrètí ìyè ayérayé rárá. Gbogbo wa pátá là ń jọlá inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tó pọ̀ gan-an. Nítorí náà, gbogbo wa ló yẹ kó ṣe bíi ti Pọ́ọ̀lù, ìyẹn ni pé ká rí i pé à ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn nípa wíwàásù ìhìn rere fún wọn, ká máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ká sì tún rí i pé à ń gbé àwọn ará wa ró.—Ka Ìṣe 14:21-23.

14. Báwo la ṣe lè túbọ̀ fi kun ipa tá à ń kó nínú iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run?

14 Pọ́ọ̀lù fẹ́ dẹni tó túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere, ó sì wù ú gan-an láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀. Lára ọ̀nà tí Ọmọ Ọlọ́run sì gbà fi ìfẹ́ títayọ hàn sáwọn èèyàn ni bó ṣe ń wàásù fún wọn. Jésù sọ pé: “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́. Nítorí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè láti rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.” (Mát. 9:35-38) Yàtọ̀ sí pé Pọ́ọ̀lù náà gbàdúrà pé káwọn òṣìṣẹ́ púpọ̀ sí i jáde wá, ó tún ṣiṣẹ́ lórí àdúrà tó gbà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í fìtara wàásù. Ìwọ ńkọ́? Ǹjẹ́ o lè sapá láti dẹni tó túbọ̀ já fáfá sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? Tàbí, ǹjẹ́ o lè túbọ̀ fi kún àkókò tó ò ń lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, bóyá kò ó ṣètò bí ìwọ náà á ṣe di aṣáájú-ọ̀nà? Ẹ jẹ́ ká máa fi ìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn sáwọn èèyàn nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè dẹni tó “di ọ̀rọ̀ ìyè mú ṣinṣin.”—Fílí. 2:16.

Èrò Tí Pọ́ọ̀lù Ní Nípa Ara Rẹ̀

15. Èrò wo ni Pọ́ọ̀lù ní nípa ara rẹ̀ láàárín àwọn Kristẹni bíi tirẹ̀?

15 Pọ́ọ̀lù tún fi àpẹẹrẹ títayọ lélẹ̀ fún wa nípa èrò tó ní nípa ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni kan tó jẹ́ òjíṣẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ní ọ̀pọ̀ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ Kristẹni, ó mọ̀ dájú pé irú òun kọ́ ló yẹ kó nírú àǹfààní wọ̀nyẹn, àti pé kì í ṣe mímọ̀-ọ́n ṣe òun lòun fi lè ní wọn. Ó dá a lójú pé nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ni Ọlọ́run kàn fi jẹ́ kóun láwọn àǹfààní yẹn. Ó tún mọ̀ dáadáa pé àwọn Kristẹni míì náà já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere. Nítorí náà, kò torí gbogbo àǹfààní tó ní láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run gbéra ga, ńṣe ló jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.—Ka 1 Kọ́ríńtì 15:9-11.

16. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe lo ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni nínú ọ̀ràn ìdádọ̀dọ́?

16 Wo ọ̀nà tí Pọ́ọ̀lù gbà bójú tó ìṣòro kan tó yọjú nílùú Áńtíókù ti Síríà. Ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn ará ìjọ Kristẹni tó wà níbẹ̀ ń bára wọn jiyàn lórí ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́. (Ìṣe 14:26–15:2) Nígbà tó sì ti jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ni Ọlọ́run yàn kó múpò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù láàárín àwọn Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́, ó lè ti máa wò ó pé òun mọwọ́ àwọn tí kì í ṣe Júù dáadáa, torí náà òun á lè yanjú ìṣòro yẹn. (Ka Gálátíà 2:8, 9.) Àmọ́ nígbà tí ọ̀ràn náà ò yanjú lẹ́yìn gbogbo ìsapá rẹ̀, ó fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni fara mọ́ ètò tí wọ́n ṣe pé kí wọ́n gbé ọ̀rọ̀ náà lọ bá ìgbìmọ̀ olùdarí ní Jerúsálẹ́mù. Ó fara balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ bí ìgbìmọ̀ yẹn ṣe ń tẹ́tí gbọ́ gbogbo ọ̀ràn náà, tí wọ́n ṣe ìpinnu lórí rẹ̀, tí wọ́n sì tún fi í ṣe ọ̀kan lára àwọn tó máa lọ báwọn jíṣẹ́ náà fáwọn ìjọ káàkiri. (Ìṣe 15:22-31) Èyí fi hàn pé Pọ́ọ̀lù ‘mú ipò iwájú nínú bíbu ọlá’ fáwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ará.—Róòmù 12:10b.

17, 18. (a) Irú ẹ̀mí wo ni Pọ́ọ̀lù ní sáwọn ará ìjọ? (b) Kí ni ìṣesí àwọn alàgbà láti ìlú Éfésù nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń lọ jẹ́ ká mọ̀ nípa irú ẹni tó jẹ́?

17 Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ kó gbogbo àwọn ará ìjọ lọ́kùnrin lóbìnrin mọ́ra gan-an ni, kò dá ara rẹ̀ yà sọ́tọ̀ láàárín wọn. Ńṣe ló dọ̀rẹ́ wọn. Ní òpin ìwé tó kọ sáwọn ará Róòmù, ó kí àwọn èèyàn tó ju ogún lọ, tó tiẹ̀ tún dárúkọ wọn pàápàá. Ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ló jẹ́ pé kò síbòmíì tá a tún ti dárúkọ wọn nínú Ìwé Mímọ́, ìwọ̀nba díẹ̀ ló sì ní ẹrú iṣẹ́ pàtàkì lára wọn. Àmọ́ olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ni wọ́n, Pọ́ọ̀lù sì fẹ́ràn wọn gan-an.—Róòmù 16:1-16.

18 Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ Pọ́ọ̀lù àti kíkó tó kó àwọn ará mọ́ra gbé àwọn ìjọ ró gan-an ni. Lẹ́yìn ìpàdé tó ṣe kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn alàgbà tó wá láti ìlú Éfésù, ńṣe ni wọ́n “rọ̀ mọ́ ọrùn Pọ́ọ̀lù, wọ́n sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́, nítorí pé ọ̀rọ̀ tí ó sọ, pé wọn kì yóò tún rí ojú òun mọ́, dùn wọ́n ní pàtàkì.” Tó bá jẹ́ni tí kì í kóni mọ́ra tàbí agbéraga ẹ̀dá ni, bóyá ni lílọ rẹ̀ á fi dùn wọ́n bẹ́ẹ̀.—Ìṣe 20:37, 38.

19. Báwo la ṣe lè máa fi “ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú” bá àwọn ará wa lò nínú ìjọ?

19 Gbogbo ẹni tó bá fẹ́ ní ìtẹ̀síwájú nínú òtítọ́ gbọ́dọ̀ ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ bíi ti Pọ́ọ̀lù. Ó rọ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni pé kí wọ́n má ṣe “ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí [wọ́n] máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù [wọ́n] lọ.” (Fílí. 2:3) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yẹn? Ọ̀nà kan ni pé ká jẹ́ni tó ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà ìjọ, ká máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà wọn, ká sì máa fara mọ́ ìpinnu tí ìgbìmọ̀ onídàájọ́ lára wọn bá ṣe. (Ka Hébérù 13:17.) Ọ̀nà míì ni pé ká máa ka àwọn ará wa nínú òtítọ́, lọ́kùnrin lóbìnrin, sí ẹni iyì. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tó máa ń para pọ̀ wà nínú ìjọ àwọn èèyàn Jèhófà sábà máa ń jẹ́ àwọn èèyàn láti onírúurú orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà àti ìran. Nígbà náà, ǹjẹ́ kò wá yẹ kí àwa náà dẹni tó ń kó gbogbo wọn mọ́ra láìṣe ojúṣàájú ká sì nífẹ̀ẹ́ gbogbo wọn jinlẹ̀-jinlẹ̀ bíi ti Pọ́ọ̀lù? (Ìṣe 17:26; Róòmù 12:10a) Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká máa “fi inú dídùn tẹ́wọ́ gba ara [wa] lẹ́nì kìíní-kejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà wá, pẹ̀lú ògo fún Ọlọ́run ní iwájú.”—Róòmù 15:7.

Ẹ “Fi Ìfaradà” Sá Eré Ìje Ìyè

20, 21. Kí ni yóò jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti sá eré ìje ìyè dé ìparí?

20 Ìgbésí ayé wa gẹ́gẹ́ bí Kristẹni dà bí ẹni tó ń sá eré ìje ọlọ́nà jíjìn. Pọ́ọ̀lù ní: “Mo ti ja ìjà àtàtà náà, mo ti sáré ní ipa ọ̀nà eré ìje náà dé ìparí, mo ti pa ìgbàgbọ́ mọ́. Láti àkókò yìí lọ, a ti fi adé òdodo pa mọ́ dè mí, èyí tí Olúwa, onídàájọ́ òdodo, yóò fi san mí lẹ́san ní ọjọ́ yẹn, síbẹ̀ kì í ṣe fún èmi nìkan, ṣùgbọ́n fún gbogbo àwọn tí ó ti nífẹ̀ẹ́ ìfarahàn rẹ̀ pẹ̀lú.”—2 Tím. 4:7, 8.

21 Tá a bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù, yóò ṣeé ṣe fún wa láti sá eré ìje ìyè dé ìparí. (Héb. 12:1) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká rí i dájú pé à ń tẹ̀ síwájú nínú òtítọ́ nípa níní ìṣètò tó ṣe gúnmọ́ fún ìdákẹ́kọ̀ọ́, nípa dídẹni tó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn jinlẹ̀-jinlẹ̀, àti nípa jíjẹ́ ẹlẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Báwo ni ṣíṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ nínú Ìwé Mímọ́ déédéé ṣe ṣe Pọ́ọ̀lù láǹfààní?

• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí Kristẹni tòótọ́ nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn jinlẹ̀-jinlẹ̀?

• Ànímọ́ wo ni wàá ní tá jẹ́ kó o lè máa bá àwọn èèyàn lò láìṣe ojúsàájú?

• Báwo ni títẹ̀lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù yóò ṣe mú kó o dẹni tó ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà ìjọ rẹ?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Máa fi ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ gbé ara rẹ ró bíi ti Pọ́ọ̀lù

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn nípa wíwàásù ìhìn rere fún wọn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Ǹjẹ́ o mọ ohun tó mú káwọn ará fẹ́ràn Pọ́ọ̀lù gan-an?