Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ànímọ́ Tá A Gbọ́dọ̀ Máa Lépa

Àwọn Ànímọ́ Tá A Gbọ́dọ̀ Máa Lépa

Àwọn Ànímọ́ Tá A Gbọ́dọ̀ Máa Lépa

“Ṣùgbọ́n máa lépa òdodo, fífọkànsin Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, ìfaradà, [àti] inú tútù.”—1 TÍM. 6:11.

1. Ṣàpèjúwe ohun tí ọ̀rọ̀ náà, “lépa” túmọ̀ sí.

 KÍ LÓ máa wá sí ọ lọ́kàn tó o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, “lépa”? Bóyá èyí lè mú kó o rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Mósè, nígbà táwọn ọmọ ogun Íjíbítì ‘ń lépa’ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, táwọn ọmọ ogun Íjíbítì sì ṣègbé sínú Òkun Pupa. (Ẹ́kís. 14:23) Tàbí kẹ̀, ó lè mú kó o rántí ewu tó dojú kọ ẹnì kan tó ṣèèṣì pààyàn nílẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́. Ẹni tó ṣèèṣì pààyàn náà gbọ́dọ̀ tètè sáré lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìlú ààbò mẹ́fà tí Ọlọ́run ti yàn fún wọn. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ‘olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀, nítorí pé ọkàn-àyà rẹ̀ gbóná, lè lépa apànìyàn náà, kí ó sì pa á.’—Diu. 19:6.

2. (a) Ẹ̀bùn wo ni Ọlọ́run pe àwọn Kristẹni kan sí láti máa lépa? (b) Kí ni Jèhófà fún ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Kristẹni lónìí láti máa lépa?

2 Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò èrò tó dára tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní nípa lílépa nǹkan, èyí tó yàtọ̀ sáwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ mẹ́nu kàn tán yẹn. Ó ní: “Mo ń lépa góńgó náà nìṣó fún ẹ̀bùn eré ìje ti ìpè Ọlọ́run sí òkè nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílí. 3:14) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé gbogbo àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tí wọ́n jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró, tí Pọ́ọ̀lù jẹ́ ọ̀kan lára wọn ló gba ẹ̀bùn ìyè ti ọ̀run yẹn. Àwọn pẹ̀lú Jésù Kristi yóò ṣàkóso aráyé nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba rẹ̀. Ẹ ò rí i pé ohun àgbàyanu ni Ọlọ́run pè wọ́n sí láti máa lépa yẹn! Àmọ́, ohun tó yàtọ̀ sí èyí ni ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Kristẹni tòótọ́ ń lépa lónìí. Tìfẹ́tìfẹ́ ni Jèhófà fún wọn láǹfààní láti gba ohun tí Ádámù àti Éfà sọ nù, ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun pẹ̀lú ìlera pípé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.—Ìṣí. 7:4, 9; 21:1-4.

3. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọrírì inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run?

3 Kò sí báwa èèyàn aláìpé ṣe lè tiraka tó láti máa ṣe rere, ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti jogún ò lè jẹ́ ká rí ìyè àìnípẹ̀kun. (Aísá. 64:6) Kìkì tá a bá nígbàgbọ́ nínú ìgbàlà tí Ọlọ́run fìfẹ́ pèsè nípasẹ̀ Jésù Kristi nìkan la fi lè rí ìyè àìnípẹ̀kun. Kí la lè ṣe láti fi hàn pé a mọrírì inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run yìí? Ohun kan tá a lè ṣe ni pé ká ṣègbọràn sí àṣẹ́ yìí pé: “Máa lépa òdodo, fífọkànsin Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, ìfaradà, [àti] inú tútù.” (1 Tím. 6:11) Tá a bá ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ànímọ́ yìí, yóò ran ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́ láti túbọ̀ máa bá a nìṣó ní lílépa wọn “lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́.”—1Tẹs. 4:1.

“Máa Lépa Òdodo”

4. Kí nìdí tó fi lè dá wa lójú pé lílépa “òdodo” ṣe pàtàkì, kí sì ni nǹkan àkọ́kọ́ tẹ́ni tó bá fẹ́ lépa òdodo gbọ́dọ̀ ṣe?

4 Nínú lẹ́tà méjèèjì tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì, ó sọ àwọn ànímọ́ tó yẹ kéèyàn máa lépa, “òdodo” ló sì fi ń ṣáájú àwọn ànímọ́ náà. (1 Tím. 6:11; 2 Tím. 2:22) Bákan náà, láwọn àpá ìbò míì nínú Bíbélì, léraléra la fún wa níṣìírí láti máa lépa òdodo. (Òwe 15:9; 21:21; Aísá. 51:1) Ọ̀nà kan tá a sì lè gbà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe èyí ni ‘gbígba ìmọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí [ó] rán jáde, Jésù Kristi.’ (Jòh. 17:3) Tẹ́nì kan bá ń lépa òdodo, èyí á mú kí ẹni náà ṣe nǹkan kan, ohun náà ni pé kó ronú pìwà dà gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá sẹ́yìn, kó sì “yí padà” kó bàa lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.—Ìṣe 3:19.

5. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe láti lè jẹ́ olódodo lójú Ọlọ́run ká sì máa bá a nìṣó?

5 Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn tí wọ́n ń lépa òdodo tọkàntọkàn ti ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, wọ́n sì ti fi ẹ̀rí èyí hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi. Tó bá jẹ́ pé Kristẹni tó ti ṣèrìbọmi ni ẹ́, ǹjẹ́ o tiẹ̀ mọ̀ pé bó o ṣe ń gbé ìgbé ayé rẹ nísinsìnyí gbọ́dọ̀ máa fi hàn pé ò ń lépa òdodo nìṣó? Ọ̀nà kan tó o lè gbà máa lépa òdodo ni pé kó o máa fòye mọ ohun tó wà nínú Bíbélì nípa ohun tó “tọ́ àti ohun tí kò tọ́” nígbà tó o bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu tó ṣe pàtàkì nígbèésí ayé ẹ. (Ka Hébérù 5:14) Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ pé Kristẹni tí kò tíì ṣègbéyàwó ni ẹ́, tó o sì ti dàgbà tó láti ṣègbéyàwó, ǹjẹ́ o ti pinnu pé ọ̀rọ̀ ìfẹ́ kò ní sí láàárín ìwọ àti Kristẹni kan tí kò tíì ṣèrìbọmi? Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ lò ń lépa òdodo, o ò ní ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀.—1 Kọ́r. 7:39.

6. Tẹ́nì kan bá fẹ́ máa lépa òdodo lóòótọ́, kí ló ní láti máa ṣe?

6 Ọ̀tọ̀ ni kéèyàn jẹ́ olódodo, ọ̀tọ̀ sì ni kéèyàn jẹ́ olódodo lójú ara ẹni tàbí “olódodo àṣelékè.” (Oníw. 7:16) Jésù sọ pé kò dáa kéèyàn jẹ́ olódodo àṣelékè, kéèyàn máa ṣe bíi pé òun sàn ju àwọn ẹlòmíì lọ. (Mát. 6:1) Téèyàn bá fẹ́ máa lépa òdodo lóòótọ́, ó ní í ṣe pẹ̀lú ọkàn ẹni, ìyẹn ṣíṣàtúnṣe àwọn èrò tí kò tọ́, ìwà tí kò dáa, àti ìfẹ́ ọkàn tí kò tọ́. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí, a ò ní dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá. (Ka Òwe 4:23; fi wé Ják. 1:14, 15.) Ìyẹn nìkan kọ́, inú Jèhófà á dùn sí wa, yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti máa lépa àwọn ànímọ́ pàtàkì míì tó yẹ kí Kristẹni ní.

“Máa Lépa . . . Fífọkànsin Ọlọ́run”

7. Kí ni “fífọkànsin Ọlọ́run?”

7 Ìfọkànsìn ní í ṣe pẹ̀lú yíya ara ẹni sí mímọ́ tọkàntọkàn kéèyàn sì jẹ́ olóòótọ́. Ìwé kan tó ń túmọ̀ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì sọ pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n túmọ̀ sí “fífọkànsin Ọlọ́run,” túmọ̀ sí pé “kéèyàn máa ṣọ́ra kí ohunkóhun má ṣe mú kí ìbẹ̀rù tó ní fún Ọlọ́run dín kù.” Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ọmọ Ísírẹ́lì kì í fi irú ìfọkànsìn yìí hàn, èyí sì hàn nínú bí wọ́n ṣe ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, kódà lẹ́yìn tó dá wọn sílẹ̀ ní Íjíbítì.

8. (a) Ìbéèrè wo ló ń jà ràn-ìn látìgbà tí Ádámù ti dẹ́ṣẹ̀? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe pèsè ìdáhùn sí “àṣírí mímọ́-ọlọ́wọ̀” yìí?

8 Lẹ́yìn ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún tí Ádámù tó jẹ́ ẹni pípé ti dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run, ìbéèrè náà ṣì ń jà ràn-ìn pé, “Ǹjẹ́ ẹ̀dá èèyàn èyíkéyìí lè fọkàn sin Ọlọ́run lọ́nà pípé?” Láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn, kò sí ẹ̀dá èèyàn aláìpé kankan tó lè gbé ìgbé ayé fífọkànsin Ọlọ́run lọ́nà pípé. Àmọ́, nígbà tí àkókò tó lójú Jèhófà, ó pèsè ìdáhùn sí “àṣírí mímọ́-ọlọ́wọ̀” yìí. Ó ṣe èyí nípa fífi ìwàláàyè Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo sínú ilé ọlẹ̀ Màríà, kí ó lè bí i ní ẹ̀dá èèyàn pípé. Ní gbogbo ìgbésí ayé Jésù, títí kan ikú ẹ̀gàn tó kú, ó fi ohun tó túmọ̀ sí láti yara ẹni sí mímọ́ tọkàntọkàn hàn, ó sì ṣe olóòótọ́ sí Ọlọ́run délẹ̀délẹ̀. Àwọn àdúrà tó gbà fi hàn pé ó fọkàn sin Bàbá rẹ̀ ọ̀run onífẹ̀ẹ́. (Mát. 11:25; Jòh. 12:27, 28) Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi mí sí Pọ́ọ̀lù láti fi “fífọkànsin Ọlọ́run” ṣàpèjúwe bí Jésù ṣe gbé ìgbé ayé rẹ̀, tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ fún wa.—Ka 1 Tím. 3:16.

9. Báwo la ṣe lè máa lépa fífọkànsin Ọlọ́run?

9 Jíjẹ́ tá a jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ kò lè jẹ́ ká fọkàn sin Ọlọ́run lọ́nà tó pé. Àmọ́ a lè máa lépa rẹ̀. Èyí sì gba pé ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi pẹ́kípẹ́kí bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. (1 Pét. 2:21) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní dà bí àwọn alágàbàgebè “tí wọ́n ní ìrísí fífọkànsin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀.” (2 Tím. 3:5) Èyí ò wá túmọ̀ sí pé fífọkànsin Ọlọ́run ní tòótọ́ kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ìrísí wa o. Bí àpẹẹrẹ, bóyá a fẹ́ yan irú aṣọ tá a máa wọ̀ lọ́jọ́ ìgbéyàwó wa ni o, tàbí èyí tá a máa wọ̀ tá a bá fẹ́ lọ ra nǹkan lọ́jà, ìrísí wa gbọ́dọ̀ fi hàn pé a ‘jẹ́wọ́ gbangba pé à ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run.’ (1 Tím. 2:9, 10) Bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn, bá a bá fẹ́ máa lépa fífọkànsin Ọlọ́run, ó gba pé ká máa ronú nípa ìlànà òdodo Ọlọ́run nínú ohunkóhun tá a bá fẹ́ ṣe nígbèésí ayé wa.

“Máa Lépa . . . Ìgbàgbọ́”

10. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe kí ìgbàgbọ́ wa lè máa lágbára sí i?

10 Ka Róòmù 10:17. Kí Kristẹni kan tó lè ní ìgbàgbọ́ tó lágbára kí ìgbàgbọ́ náà má sì di ahẹrẹpẹ, ó gbọ́dọ̀ máa báa lọ láti máa ṣàṣàrò lórí àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó ṣeyebíye tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti pèsè àwọn ìwé àtàtà. Àwọn ìwé mẹ́ta kan tó ta yọ nínú wọn ni Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí, Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà, àti “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn.” A ṣe àwọn ìwé yìí kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ Kristi dáadáa, èyí á sì mú ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. (Mát. 24:45-47) Ẹrú olóòótọ́ àti olóye náà tún máa ń ṣètò àwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ, “ọ̀rọ̀ nípa Kristi” sì ni èyí tó pọ̀ jù nínú wọn máa ń dá lé lórí. Ǹjẹ́ ọ̀nà èyíkéyìí wà tó o lè gbà jàǹfààní nínú àwọn ìpèsè Ọlọ́run yìí nípa fífún wọn ní “àfiyèsí tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ”?—Héb. 2:1.

11. Ipa wo ni àdúrà àti ìgbọràn ń kó nínú bá a ṣe ń lépa ìgbàgbọ́?

11 Àdúrà tún ṣe pàtàkì tá a bá fẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára. Nígbà kan, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bẹ̀ ẹ́ pé: “Fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i.” Àwa náà lè fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ béèrè fún ìgbàgbọ́ tó pọ̀ sí i lọ́wọ́ Ọlọ́run. (Lúùkù 17:5) Tá a bá fẹ́ ní ìgbàgbọ́ tó pọ̀ sí i, a gbọ́dọ̀ gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run; ìgbàgbọ́ jẹ́ ara “èso ti ẹ̀mí.” (Gál. 5:22) Bákan náà, tá a bá ń ṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run, ìgbàgbọ́ wa yóò máa lágbára sí i. Bí àpẹẹrẹ, a lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù wa. Èyí á sì fún wa ní ayọ̀ púpọ̀. Bá a sì ṣe ń ronú lórí àwọn ìbùkún tó ń wá látinú “wíwá ìjọba náà àti òdodo [Ọlọ́run] lákọ̀ọ́kọ́,” ìgbàgbọ́ wa yóò túbọ̀ máa lágbára sí i.—Mát. 6:33.

“Máa Lépa . . . Ìfẹ́”

12, 13. (a) Kí ni àṣẹ tuntun tí Jésù pa? (b) Àwọn ọ̀nà pàtàkì wo la lè gbà máa lépa irú ìfẹ́ tí Kristi ní?

12 Ka 1 Tímótì 5:1, 2. Pọ́ọ̀lù fún àwa Kristẹni nímọ̀ràn tó wúlò gan-an nípa bá a ṣe lè máa fìfẹ́ hàn síra wa. Fífọkànsin Ọlọ́run gbọ́dọ̀ mú ká ṣègbọràn sí àṣẹ tuntun tí Jésù pa pé ká ‘nífẹ̀ẹ́ ara wa’ gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe nífẹ̀ẹ́ wa. (Jòh. 13:34) Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá ní àlùmọ́ọ́nì ayé yìí fún ìtìlẹyìn ìgbésí ayé, tí ó sì rí i tí arákùnrin rẹ̀ ṣe aláìní, síbẹ̀ tí ó sé ilẹ̀kùn ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ rẹ̀ mọ́ ọn, lọ́nà wo ni ìfẹ́ fún Ọlọ́run fi dúró nínú rẹ̀?” (1 Jòh. 3:17) Ǹjẹ́ ìfẹ́ ti mú kó o ran ẹnì kan lọ́wọ́ rí?

13 Ọ̀nà míì tá a tún lè gbà máa lépa ìfẹ́ ni pé ká máa dárí jini, ká má máa di àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa sínú. (Ka 1 Jòhánù 4:20.) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run mí sí yìí pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe.” (Kól. 3:13) Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni wà nínú ìjọ rẹ tó yẹ kó o dárí jì? Ṣé wàá dárí jì í?

“Máa Lépa . . . Ìfaradà”

14. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lára ìjọ tó wà ní Filadẹ́fíà?

14 Ohun kan ni pé kéèyàn sapá gidigidi láti máa lé nǹkan tó mọ̀ pé kò ní pẹ́ kọ́wọ́ òun tó tẹ̀ ẹ́, ohun míì ni pé kéèyàn máa lé nǹkan tọ́wọ́ ò lè tètè tẹ̀, tí nǹkan ọ̀hún tún wá ń pẹ́ ju bó ṣe rò lọ. Ká sòótọ́, lílépa ìyè àìnípẹ̀kun gba pé kéèyàn ní ìfaradà. Jésù Olúwa sọ fún ìjọ tó wà ní Filadẹ́fíà pé: “Nítorí pé ìwọ pa ọ̀rọ̀ nípa ìfaradà mi mọ́, ṣe ni èmi pẹ̀lú yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú wákàtí ìdánwò.” (Ìṣí. 3:10) Bẹ́ẹ̀ ni, Jésù kọ́ wa ní ìdí tá a fi nílò ìfaradà, ìyẹn ànímọ́ tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe juwọ́ sílẹ̀ nígbà tá a bá dojú kọ ìṣòro tàbí ìdẹwò. Ó ti ní láti jẹ́ pé àwọn ará tó wà ní ìjọ Filadẹ́fíà lọ́rùn-ún-dún kìíní fi ìfaradà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ hàn nígbà tí wọ́n dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro tó dán ìgbàgbọ́ wọn wò. Èyí ló mú kí Jésù fi dá wọn lójú pé òun á dúró tì wọ́n nígbà àdánwò ńlá tó ń bọ̀.—Lúùkù 16:10.

15. Ẹ̀kọ́ wo ni Jésù kọ́ wa nípa ìfaradà?

15 Jésù mọ̀ pé àwọn ìbátan tí kì í ṣe Kristẹni àti gbogbo ayé lápapọ̀ máa kórìíra àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun, ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé, ó kéré tán, ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló fún wọn níṣìírí pé: “Ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là” (Mát. 10:22; 24:13) Jésù tún sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà yẹn bí wọ́n ṣe máa gba okun tí wọ́n á fi lè fara dà á. Nínú àkàwé kan tí Jésù sọ, ó fi erùpẹ̀ orí àpáta wé àwọn tí “wọ́n fi ìdùnnú gba ọ̀rọ̀ [Ọlọ́run],” àmọ́ nígbà tí ìṣòro tó ń dán ìgbàgbọ́ wò dé, wọ́n yẹsẹ̀. Àmọ́, ó fi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ olóòótọ́ wé erùpẹ̀ àtàtà, torí pé wọ́n “di” ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “mú ṣinṣin” “wọ́n sì so èso pẹ̀lú ìfaradà.”—Lúùkù 8:13, 15.

16. Ìpèsè onífẹ̀ẹ́ wo ló ti mú kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ní ìfaradà?

16 Ṣó o ti rí àṣírí béèyàn ṣe lè ní ìfaradà? A gbọ́dọ̀ ‘di ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú ṣinṣin,’ ká jẹ́ kó máa wà ní ọkàn wa nígbà gbogbo. A ní ohun kan tó lè mú kí èyí rọrùn fún wa láti ṣe, ìyẹn Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, nítorí Bíbélì yìí péye, ọ̀nà tí wọ́n gbà túmọ̀ rẹ̀ mú kó rọrùn láti kà, ó sì wà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè. Ṣíṣàṣàrò lórí apá kan nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ á mú ká rí okun tá a nílò gbà, èyí tá a mú ká lé máa bá a nìṣó ní síso èso “pẹ̀lú ìfaradà.”—Sm. 1:1, 2.

“Máa Lépa . . . Inú Tútù” àti Àlááfíà

17. (a) Kí nìdí tí “inú tútù” fi ṣe pàtàkì gan-an? (b) Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun jẹ́ onínú tútù?

17 Kò sẹ́ni tínú ẹ̀ máa dùn tí wọ́n bá fẹ̀sùn kàn án lórí ohun tí kò sọ tàbí tí kò ṣe. Ìbínú làwa èèyàn sábà fi máa ń dáhùn padà tí wọ́n bá firú ẹ̀sùn bẹ́ẹ̀ kàn wá. Ẹ wo bó ṣe dára tó kéèyàn máa fi “inú tútù” hàn! (Ka Òwe 15:1.) Kì í ṣohun tó rọrùn rárá kéèyàn jẹ́ onínú tútù tí wọ́n bá fẹ̀sùn ohun tí kò ṣe kàn án. Àpẹẹrẹ pípé ni Jésù Kristi fi lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ kéèyàn jẹ́ onínú tútù. “Nígbà tí a ń kẹ́gàn rẹ̀, kò bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́gàn padà. Nígbà tí ó ń jìyà, kò bẹ̀rẹ̀ sí halẹ̀ mọ́ni, ṣùgbọ́n ó ń bá a nìṣó ní fífi ara rẹ̀ lé ọwọ́ ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ lọ́nà òdodo.” (1 Pét. 2:23) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè dà bíi Jésù pátápátá tó bá dọ̀rọ̀ jíjẹ́ onínú tútù, àmọ́ ṣé a lè sapá láti túbọ̀ máa fi inú tútù hàn?

18. (a) Àwọn ohun wo ni inú tútù lè jẹ́ ká ṣe? (b) Ànímọ́ mìíràn wo ni Bíbélì rọ̀ wá pé ká máa lépa?

18 Ẹ jẹ́ ká máa fara wé Jésù, ká “wà ní ìmúratán nígbà gbogbo láti ṣe ìgbèjà” àwọn ohun tá a gbà gbọ́, “kí [á] máa ṣe bẹ́ẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” (1 Pét. 3:15) Ọ̀rọ̀ rèé o, tá a bá jẹ́ onínú tútù, a ò ní tètè máa bínú ká sì máa pariwo mọ́ àwọn èèyàn tó bá ṣẹlẹ̀ pé èrò wọn yàtọ̀ sí tiwa, bóyá tá a bá wà lóde ẹ̀rí tàbí tá a bá wà pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni. (2 Tím. 2:24, 25) Inú tútù máa ń jẹ́ kéèyàn ní àlááfíà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi to “àlááfíà” mọ́ ara àwọn ànímọ́ tó yẹ kéèyàn máa lépa, nígbà tó kọ lẹ́tà kejì sí Tímótì. (2 Tím. 2:22; fi wé 1 Tímótì 6:11.) Bẹ́ẹ̀ ni, “àlááfíà” jẹ́ ànímọ́ mìíràn tí Ìwé Mimọ gbà wá níyànjú láti máa lépa.—Sm. 34:14; Héb. 12:14.

19. Lẹ́yìn tá a ti ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ànímọ́ Kristẹni méje yìí, kí lo pinnu pé wàá máa ṣe, kí sì nìdí?

19 A ti ṣàgbéyẹ̀wò ṣókí nípa àwọn ànímọ́ méje tí Bíbélì rọ àwa Kristẹni láti máa lépa, àwọn ànímọ́ náà ni: òdodo, fífọkànsin Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, ìfaradà, inú tútù àti àlááfíà. Ẹ wo bí yóò ti dára tó táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ní gbogbo ìjọ bá ń sapá gidigidi láti túbọ̀ máa fi àwọn ànímọ́ tó ṣeyebíye yìí hàn! Èyí yóò máa bọlá fún Jèhófà, á sì mú kó sọ gbogbo wa dẹni tí yóò máa fìyìn fún un.

Ohun Tó Yẹ Ká Ronú Lé Lórí

• Kí lèèyàn lè ṣe láti máa lépa òdodo àti fífọkànsin Ọlọ́run?

• Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti máa lépa ìgbàgbọ́ àti ìfaradà?

• Báwo la ṣe lè lo ìfẹ́ nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn èèyàn?

• Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa lépa inú tútù àti àlàáfíà?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Jésù sọ pé kò dáa kéèyàn máa ṣe òdodo àṣelékè

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ká máa lépa ìgbàgbọ́ nípa ṣíṣàṣàrò lórí ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ká máa lépa ìfẹ́ àti inú tútù