Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ohun Tá A Gbọ́dọ̀ Máa Sá Fún

Àwọn Ohun Tá A Gbọ́dọ̀ Máa Sá Fún

Àwọn Ohun Tá A Gbọ́dọ̀ Máa Sá Fún

“Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀, ta ní fi tó yín létí láti sá kúrò nínú ìrunú tí ń bọ̀?”—MÁT. 3:7.

1. Àwọn àpẹẹrẹ wo ló wà nínú Bíbélì nípa àwọn tó sá?

 KÍ LÓ máa wá sí ọ lọ́kàn tó o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, “sá fún”? Ọ̀rọ̀ yìí lè mú káwọn kan rántí bí ọ̀dọ́kùnrin arẹwà kan tó ń jẹ́ Jósẹ́fù ṣe sá fún aya Pọ́tífárì tó fi ìṣekúṣe lọ̀ ọ́. (Jẹ́n. 39:7-12) Ó sì lè mú káwọn míì rántí àwọn Kristẹni tó sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù lọ́dún 66 Sànmánì Kristẹni, nígbà tí wọ́n ṣègbọràn sí ìkìlọ̀ Jésù pé: “Nígbà tí ẹ bá rí tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun adótini bá yí Jerúsálẹ́mù ká, nígbà náà ni kí . . . àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá, kí àwọn tí wọ́n sì wà ní àárín rẹ̀ fi ibẹ̀ sílẹ̀.”—Lúùkù 21:20, 21.

2, 3. (a) Kí ni ọ̀rọ̀ tí Jòhánù Olùbatisí sọ sáwọn olórí ìsìn túmọ̀ sí? (b) Báwo ni Jésù ṣe túbọ̀ mú kí ìkìlọ̀ tí Jòhánù ṣe lágbára sí i?

2 Àwọn àpẹẹrẹ tá a mẹ́nu kàn lókè yẹn jẹ́ sísá láti ibì kan sí ibòmíràn. Lónìí, ó jẹ́ kánjúkánjú fáwa Kristẹni níbi gbogbo láyé láti sá lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Jòhánù Olùbatisí lo ọ̀rọ̀ náà “sá” ní irú ọ̀nà ìṣàpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀. Lára àwọn tó wá sọ́dọ̀ Jòhánù ni àwọn olórí ìsìn Júù tí wọ́n jẹ́ olódodo lójú ara wọn, tí wọ́n sọ pé kò sídìí fún àwọn láti ronú pìwà dà. Ojú ẹ̀gàn ni wọ́n máa fi ń wo àwọn gbáàtúù èèyàn tí wọ́n ń ṣèrìbọmi láti fẹ̀rí hàn pé àwọn ti ronú pìwà dà. Jòhánù kò bẹ̀rù rárá, ó tú àṣírí àwọn olórí ìsìn yẹn pé wọ́n jẹ́ alágàbàgebè, ó ní: “Ọmọ paramọ́lẹ̀, ta ní fi tó yín létí láti sá kúrò nínú ìrunú tí ń bọ̀? Nítorí bẹ́ẹ̀, ẹ mú èso tí ó yẹ ìrònúpìwàdà jáde.”—Mát. 3:7, 8.

3 Kì í ṣe sísá láti ibì kan sí ibòmíràn ni Jòhánù ń sọ o. Ńṣe ló ń kìlọ̀ nípa ìdájọ́ tó ń bọ̀, ìyẹn ọjọ́ ìbínú Jèhófà; ó sì fi tó àwọn olórí ìsìn létí pé tí wọn ò bá fẹ́ pa run lọ́jọ́ yẹn, wọ́n ní láti ṣe ohun tó máa fi hàn pé àwọ́n ti ronú pìwà dà. Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù bá àwọn olórí ìsìn wọ̀nyẹn wí, ó là á mọ́lẹ̀ fún wọn pé ìwà apààyàn tí wọ́n ń hù yẹn fi hàn pé Èṣù ni baba wọn lóòótọ́. (John 8:44) Jésù wá mú kí ìkìlọ̀ tí Jòhánù ṣe yẹn lágbára sí i nígbà tó pè wọ́n ní “ọmọ paramọ́lẹ̀,” tó sì bi wọ́n pé: “Báwo ni ẹ ó ṣe sá kúrò nínú ìdájọ́ Gẹ̀hẹ́nà?” (Mát. 23:33) Kí ni ìtúmọ̀ “Gẹ̀hẹ́nà” tí Jésù sọ níbí yìí?

4. Kí ni ìtúmọ̀ “Gẹ̀hẹ́nà” tí Jésù sọ?

4 Gẹ̀hẹ́nà jẹ́ àfonífojì kan tó wà lẹ́yìn ògiri tó yí Jerúsálẹ́mù ká, ibẹ̀ ni wọ́n ti máa ń sun ìdọ̀tí àti òkú ẹran. Jésù lo Gẹ̀hẹ́nà láti fi ṣàpẹẹrẹ ikú àkúrun. (Wo ojú ìwé 27.) Ìbéèrè tó béèrè nípa sísá kúrò ní Gẹ̀hẹ́nà fi hàn pé àwùjọ àwọn olórí ìsìn yìí yẹ fún ìparun ayérayé.—Mát. 5:22, 29.

5. Báwo ni ìtàn ṣe fi hàn pé ohun tí Jòhánù àti Jésù kìlọ̀ nípa rẹ̀ ṣẹ lóòótọ́?

5 Inúnibíni táwọn aṣáájú àwọn Júù ṣe sí Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mú kí ẹ̀ṣẹ̀ wọn túbọ̀ pọ̀ sí i. Nígbà tó yá, ọjọ́ ìbínú Ọlọ́run dé, gẹ́gẹ́ bí Jòhánù àti Jésù ṣe kìlọ̀. Nígbà yẹn, ibì kan pàtó ni “ìrunú tí ń bọ̀” yẹn dé sí, ìyẹn Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà, nítorí náà, á ṣeé ṣe láti sá kúrò níbẹ̀ lọ sí ibòmíràn. Ìrunú náà dé nígbà táwọn ọmọ ogun Róòmù pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni. “Ìpọ́njú” yẹn ju gbogbo ohun táwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù tíì rí rí. Wọ́n pa ọ̀pọ̀ èèyàn, wọ́n sì kó ọ̀pọ̀ lọ sígbèkùn. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ń sọ nípa ìparun kan tó máa le ju ti Jerúsálẹ́mù lọ, tó ń bọ̀ wá sórí àwọn aláfẹnujẹ́ Kristẹni àtàwọn ẹlẹ́sìn mìíràn.—Mát. 24:21.

Ìrunú Kan Ń Bọ̀ Tá A Ní Láti Sá Fún

6. Kí ló bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní?

6 Àwọn kan lára àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní di apẹ̀yìndà, wọ́n sì fa àwọn èèyàn sẹ́yìn ara wọn. (Ìṣe 20:29, 30) Nígbà táwọn àpọ́sítélì Jésù ṣì wà láàyè, wọ́n jẹ́ “aṣèdíwọ́” fún ìpẹ̀yìndà yẹn, àmọ́ lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n kú, ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn èké Kristẹni dìde. Lónìí, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ẹ̀sìn Kristẹni tó ta kora wọn ló wà. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì yóò dìde, ó sì pè wọ́n lápapọ̀ ní “ọkùnrin oníwà àìlófin” àti “ọmọ ìparun . . . ẹni tí Jésù Olúwa yóò . . . pa, tí yóò sì sọ di asán nípasẹ̀ ìfarahàn wíwàníhìn-ín rẹ̀.”—2 Tẹs. 2:3, 6-8.

7. Kí nìdí tó fi bá a mu pé Bíbélì pe àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ní “ọkùnrin oníwà àìlófin”?

7 Àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì jẹ́ aláìlófin ní ti pé wọ́n ti kó ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ṣìnà nípa kíkọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ tí kò bá Bíbélì mu tí wọ́n sì ń gbé àwọn ọlidé àtàwọn ìwà tó ta ko Bíbélì lárugẹ. Bíi tàwọn olórí ìsìn tí Jésù dá lẹ́bi, àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì tòde òní tí wọ́n jẹ́ “ọmọ ìparun” yìí máa pa run, wọn ò sì ní ní àjíǹde. (2 Tẹs. 1:6-9) Àmọ́ kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tí àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì àtàwọn olórí ẹ̀sìn èké yòókù ti kó ṣìnà? Láti lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni.

“Ẹ Fẹsẹ̀ Fẹ Kúrò ní Àárín Bábílónì”

8, 9. (a) Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Jeremáyà sọ fún àwọn Júù tó wà nígbèkùn ní Bábílónì? (b) Lẹ́yìn tí àwọn ara Mídíà àti Páṣíà ṣẹ́gun Bábílónì, lọ́nà wo ni àwọn Júù gbà sá?

8 Wòlíì Jeremáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìparun Jerúsálẹ́mù tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ó sọ pé wọ́n á mú àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ sí ìgbèkùn, àmọ́ wọ́n á tún dá wọn padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn lẹ́yìn “àádọ́rin ọdún.” (Jer. 29:4, 10) Jeremáyà ní iṣẹ́ pàtàkì tó fẹ́ jẹ́ fáwọn Júù tó wà nígbèkùn ní Bábílónì. Iṣẹ́ náà ni pé wọn kò gbọ́dọ̀ fi ìsìn èké Bábílónì sọ ara wọn dẹlẹ́gbin. Wọ́n á tipa bẹ́ẹ̀ múra sílẹ̀ láti padà sí Jerúsálẹ́mù kí wọ́n sì mú ìjọsìn mímọ́ padà bọ̀ sípò lákòókò tí Jèhófà yàn. Èyí ṣẹlẹ̀ kété lẹ́yìn tí àwọn ará Mídíà àti Páṣíà ṣẹ́gun Bábílónì lọ́dún 539 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ọba Páṣíà tó ń jẹ́ Kírúsì Kejì pàṣẹ fún àwọn Júù láti padà lọ sí Jerúsálẹ́mù, kí wọ́n sì tún tẹ́ńpìlì Jèhófà kọ́.—Ẹ́sírà 1:1-4.

9 Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Júù lo àǹfààní yìí láti padà sí ìlú wọn. (Ẹ́sírà 2:64-67) Ohun tí wọ́n ṣe yìí mú àsọtẹ́lẹ̀ Jeremáyà ṣẹ, èyí tó pàṣẹ pé kí wọ́n sá lọ, ìyẹn pé kí wọ́n ṣí lọ sí ibòmíràn. (Ka Jeremáyà 51:6, 45, 50.) Nítorí àwọn ìdí kan, kò ṣeé ṣe fún gbogbo àwọn Júù láti rin ìrìn-àjò gígùn yẹn padà sí Jerúsálẹ́mù àti Júdà. Àwọn tí wọ́n ṣì wà ní Bábílónì, irú bíi Dáníẹ́lì tó jẹ́ wòlíì tó ti darúgbó ṣì lè ní ìbùkún Ọlọ́run tí wọ́n bá ń fi gbogbo ọkàn wọn ṣètìlẹ́yìn fún ìjọsìn mímọ́ tó fìdí kalẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù tí wọn ò sì lọ́wọ́ sí ìjọsìn èké táwọn èèyàn ń ṣe ní Bábílónì.

10. “Àwọn ohun ìríra” wo ni “Bábílónì Ńlá” ti ṣe?

10 Lónìí, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ń ṣe onírúurú ìjọsìn èké tó pilẹ̀ṣẹ̀ láti Bábílónì ìgbàanì. (Jẹ́n. 11:6-9) Gbogbo àwọn ẹ̀sìn yẹn lápapọ̀ ló ń jẹ́ “Bábílónì Ńlá, ìyá àwọn aṣẹ́wó àti ti àwọn ohun ìríra ilẹ̀ ayé.” (Ìṣí. 17:5) Ó ti pẹ́ tí ìsìn èké ti ń ṣètìlẹ́yìn fún àwọn olóṣèlú tó ń ṣàkóso ayé yìí. Lára “àwọn ohun ìríra” tó ti ṣe ni àwọn ogun tó ti gbẹ̀mí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn, ìyẹn “àwọn tí a ti fi ikú pa lórí ilẹ̀ ayé.” (Ìṣí. 18:24) “Àwọn ohun ìríra” mìíràn ni bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe àti àwọn oríṣi ìṣekúṣe mìíràn táwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ń ṣe táwọn aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì sì fàyè gbà. Kò yẹ kó yani lẹ́nu nígbà náà pé láìpẹ́, Jèhófà Ọlọ́run yóò mú ìsìn èké kúrò láyé!—Ìṣí. 18:8.

11. Iṣẹ́ tó pọn dandan wo làwọn Kristẹni tòótọ́ ní láti ṣe kí Bábílónì Ńlá tó pa run?

11 Àwọn Kristẹni tòótọ́ tí wọ́n mọ̀ nípa ọ̀ràn yìí, rí iṣẹ́ tó já lé wọn léjìká pé àwọn ní láti kìlọ̀ fáwọn tó wà nínú Bábílónì Ńlá. Ọ̀nà kan tí wọ́n ń gbà ṣe é ni pé wọ́n máa ń fáwọn èèyàn ní Bíbélì àtàwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì, èyí tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” tẹ̀ jáde. Ẹrú yìí ni Jésù yàn láti máa pèsè “oúnjẹ ní àkókò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” (Mát. 24:45) Táwọn kan bá nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ Bíbélì, a máa ń ṣètò láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì. A nírètí pé wọ́n á rí ìdí tó fi yẹ káwọn “fẹsẹ̀ fẹ kúrò ní àárín Bábílónì” kó tó pẹ́ jù.—Ìṣí. 18:4.

Ẹ Sá fún Ìbọ̀rìṣà

12. Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo jíjọ́sìn ère àti òrìṣà?

12 Ohun ìríra mìíràn tí Bábílónì Ńlá máa ń ṣe ni jíjọ́sìn ère àti òrìṣà. Ọlọ́run pe àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ní “àwọn ohun ìríra” àti “àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ.” (Diu. 29:17) Gbogbo àwọn tó bá fẹ́ máa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ gbọ́dọ̀ sá fún ìbọ̀rìṣà, nítorí Ọlọ́run sọ pé: “Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi; èmi kì yóò sì fi ògo mi fún ẹlòmíràn, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi ìyìn mi fún àwọn ère fífín.”—Aísá. 42:8.

13. Irú àwọn ìbọ̀rìṣà téèyàn ò lè tètè fura sí wo la ní láti sá fún?

13 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún jẹ́ ká mọ àwọn oríṣi ìbọ̀rìṣà mìíràn téèyàn ò lè tètè fura sí. Bí àpẹẹrẹ, ó pe ojúkòkòrò ní “ìbọ̀rìṣà.” (Kól. 3:5) Ojúkòkòrò ni pé kójú èèyàn máa wọ ohun tí kò lẹ́tọ̀ọ́ sí, irú bí ohun ìní ẹlòmíràn. (Ẹ́kís. 20:17) Áńgẹ́lì tó di Sátánì Èṣù ṣojúkòkòrò, ó fẹ́ dà bí Ọlọ́run, Ẹni Gíga Jù Lọ, káwọn èèyàn sì máa sìn ín. (Lúùkù 4:5-7) Èyí ló mú kí Sátánì ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà tó sì mú kí ojú Éfà wọ ohun tí Ọlọ́run kà léèwọ̀. A lè sọ pé Ádámù pẹ̀lú jẹ̀bi ìbọ̀rìṣà nípa bó ṣe jẹ́ kí àjọṣe tó wà láàárín òun àti ìyàwó rẹ̀ ṣe pàtàkì lójú rẹ̀ ju ìgbọ́ràn sí Bàbá rẹ̀ ọ̀run onífẹ̀ẹ́ lọ. Àmọ́, ní ti gbogbo àwọn tó bá fẹ́ sá fún ọjọ́ ìrunú Ọlọ́run, wọ́n gbọ́dọ̀ jọ́sìn òun nìkan ṣoṣo kí wọ́n sì sá fún ojúkòkòrò.

“Ẹ Máa Sá fún Àgbèrè”

14-16. (a) Kí nìdí tí Jósẹ́fù fi jẹ́ àpẹẹrẹ ìwà rere? (b) Kí ló yẹ ká ṣe nígbà tí ọkàn wa bá ń fà sí ìṣekúṣe? (d) Ọ̀nà wo la lè gbà sá fún àgbèrè?

14 Ka 1 Kọ́ríńtì 6:18. Nígbà tí aya Pọ́tífárì gbìyànjú láti tan Jósẹ́fù dẹ́ṣẹ̀, ńṣe ni Jósẹ́fù sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Ẹ wo àpẹẹrẹ rere tó fi lélẹ̀ fáwa Kristẹni tó ti ṣègbéyàwó àtàwa tí kò tíì ṣègbéyàwó! Ó ṣe kedere pé Jósẹ́fù ti fi èrò Ọlọ́run kọ́ ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Bá a bá fẹ́ tẹ̀ lé àṣẹ Ọlọ́run pé ká “sá fún àgbèrè,” a ní láti yẹra fún ohunkóhun tó lè mú kí ọkàn wa máa fà sí níní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe aya tàbí ọkọ wa. Bíbélì sọ fún wa pé: “Ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín . . . di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò, tí í ṣe ìbọ̀rìṣà. Ní tìtorí nǹkan wọnnì ni ìrunú Ọlọ́run fi ń bọ̀.”—Kól. 3:5, 6.

15 Ṣàkíyèsí pé Ìwé Mímọ́ sọ pé ‘ìrunú Ọlọ́run ń bọ̀.’ Ọ̀pọ̀ nínú ayé ni ọkàn wọn ń fà sí ìbálópọ̀ tí kò tọ́, wọn ò sì lè kó ara wọn níjàánu. Nítorí náà, àwa Kristẹni ní láti gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run àti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ kí ìfẹ́ ìṣekúṣe má bàa borí wa. Yàtọ̀ síyẹn, kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, lílọ sáwọn ìpàdé àti sísọ ìhìn rere fáwọn èèyàn lè ràn wá lọ́wọ́ láti “máa rìn nípa ẹ̀mí.” Nípa bẹ́ẹ̀, a kò ní ‘ṣe ìfẹ́ ti ara rárá.’—Gál. 5:16.

16 Ó dájú pé, bá a bá ń wo ohun tó ń mu ọkàn ẹni fà sí ìṣekúṣe, a ò ní “máa rìn nípa ẹ̀mí.” Bákan náà, gbogbo Kristẹni ní láti yẹra fún kíka ohun tó lè mú kí ọkàn wọn máa fà sí ìbálòpọ̀, kí wọ́n yẹra fún wíwò ó, tàbí fífetí sí àwọn ọ̀rọ̀ tó lè ru ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ sókè. Bákan náà, ó lòdì fún “àwọn èèyàn mímọ́” ti Ọlọ́run láti máa fi ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ dápàárá tàbí kí wọ́n máa fi ìṣekúṣe tàkúrọ̀sọ láàárín ara wọn. (Éfé. 5:3, 4) A óò máa tipa báyìí fi han Bàbá wa ọ̀run pé lóòótọ́ la fẹ́ sá fún ìrunú rẹ̀ tó ń bọ̀ ká sì gbé nínú ayé tuntun tí òdodo yóò wà.

Ẹ Sá fún “Ìfẹ́ Owó”

17, 18. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ sá fún “ìfẹ́ owó”?

17 Nínú lẹ́tà àkọ́kọ́ tí Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì, ó sọ àwọn ìlànà pàtàkì tó yẹ káwọn Kristẹni tó jẹ́ ẹrú máa tẹ̀ lé. Àwọn kan lára wọn ti lè máa retí àwọn àǹfààní nǹkan tara nítorí pé ọ̀gá wọn jẹ́ Kristẹni. Àwọn míì lè fẹ́ láti lo ohun mímọ́, ìyẹn àjọṣe tó wà láàárín ẹgbẹ́ àwọn ará, fún èrè ti ara wọn. Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé kí wọ́n má ṣe máa “ronú pé fífọkànsin Ọlọ́run jẹ́ ọ̀nà èrè [ohun ti ara].” Ohun tó fa irú ìrònú bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ “ìfẹ́ owó” tó lè ṣàkóbá fún ẹnikẹ́ni, ì báà ṣe ọlọ́rọ̀ tàbí tálákà.—1 Tím. 6:1, 2, 5, 9, 10.

18 Ǹjẹ́ o mọ ẹnì kan nínú Bíbélì tí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run bà jẹ́ nítorí “ìfẹ́ owó” tàbí nítorí ìfẹ́ ohun tí kò níláárí tí owó lè rà? (Jóṣ. 7:11, 21; 2 Ọba 5:20, 25-27) Pọ́ọ̀lù rọ Tímótì pé: “Ìwọ, ènìyàn Ọlọ́run, sá fún nǹkan wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n máa lépa òdodo, fífọkànsin Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, ìfaradà, [àti] inú tútù.” (1 Tím. 6:11) Títẹ̀lé ìmọ̀ràn yẹn ṣe pàtàkì gan-an fún gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ yè bọ́ lọ́jọ́ ìrunú tó ń bọ̀.

“Sá fún Àwọn Ìfẹ́-ỌKàn Tí Ó Máa Ń Bá Ìgbà Èwe Rìn”

19. Kí ló yẹ káwọn ọ̀dọ́ máa ṣe?

19 Ka Òwe 22:15. Ìwà òmùgọ̀ tó wà lọ́kàn ọ̀dọ́ kan lè mú kó ṣìnà láìfura. Ohun tó lè mú èyí kúrò lọ́kàn rẹ̀ ni ìbáwí tó wá látinú Bíbélì. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tí òbí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń wá àwọn ìlànà inú Bíbélì, wọ́n sì máa ń lò ó. Àwọn kan lára wọn máa ń jàǹfààní nínú ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tí wọ́n ń gbà látọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó dàgbà nípa tẹ̀mí nínú ìjọ. Ẹni yòówù kó fúnni nímọ̀ràn látinú Bíbélì, títẹ̀lé ìmọ̀ràn náà lè mú kéèyàn láyọ̀ nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú.—Héb. 12:8-11.

20. Kí ló lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti sá fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́?

20 Ka 2 Tímótì 2:20-22. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tí kò gba ẹ̀kọ́ ti kira bọ ìwà òmùgọ̀, irú bí ẹ̀mí ìdíje, ojúkòkòrò, àgbèrè, ìfẹ́ owó, àti lílépa fàájì. Àwọn nǹkan wọ̀nyí máa ń gbé “ìfẹ́-ọkàn tí ó máa ń bá ìgbà èwe rìn” lárugẹ, èyí tí Bíbélì ní ká sá fún. Sísá fún àwọn nǹkan wọ̀nyẹn túmọ̀ sí pé Kristẹni kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ ní láti yẹra fún ẹnikẹ́ni tó lè ṣàkóbá fún ìwà rere wọn. Ìmọ̀ràn àtọ̀runwá kan tún ṣèrànwọ́ gan-an, èyí tó sọ pé ká máa lépa àwọn ànímọ́ Ọlọ́run “pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí ń ké pe Olúwa láti inú ọkàn-àyà tí ó mọ́.”

21. Ìlérí àgbàyanu wo ni Jésù Kristi ṣe nípa àwọn ẹni bí àgùntàn tí wọ́n jẹ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀?

21 Yálà ọ̀dọ́ ni wá tàbí àgbàlagbà, tá ò bá fetí sí àwọn èèyàn tó fẹ́ ṣì wá lọ́nà, ńṣe là ń fi hàn pé a fẹ́ jẹ́ ara àwọn ẹni bí àgùntàn tí wọ́n jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù tí wọ́n ‘ń sá fún ohùn àwọn àjèjì.’ (Jòhánù 10:5) Àmọ́, tá a bá fẹ́ yè bọ́ lọ́jọ́ ìrunú Ọlọ́run, ohun tó ń béèrè lọ́wọ́ wa ju pé ká kàn sá fún àwọn ohun tó lè ṣàkóbá fún wa. A tún gbọ́dọ̀ máa lépa àwọn ànímọ́ tó dára. Nínú àpilẹ̀kọ́ tó kàn, a máa gbé méje yẹ̀ wò lára àwọn ànímọ́ náà. Ó dára gan-an ká túbọ̀ yẹ ọ̀rọ̀ náà wò dáadáa, nítorí Jésù ṣèlérí àgbàyanu yìí pé: “Èmi sì fún [àwọn àgùntàn mi] ní ìyè àìnípẹ̀kun, a kì yóò sì pa wọ́n run lọ́nàkọnà láé, kò sì sí ẹnì kankan tí yóò já wọn gbà kúrò ní ọwọ́ mi.”—John 10:28.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Ìkìlọ̀ wo ni Jésù fún àwọn olórí ìsìn?

• Ipò eléwu wo ni ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn dojú kọ lónìí?

• Àwọn ìbọ̀rìṣà téèyàn ò lè tètè fura sí wo la gbọ́dọ̀ sá fún?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Kí ló máa wá sí ọ lọ́kàn tó o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, “sá fún”?