Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Lè Jẹ́ Alágbára Láìfi Àìlera Wa Pè

A Lè Jẹ́ Alágbára Láìfi Àìlera Wa Pè

A Lè Jẹ́ Alágbára Láìfi Àìlera Wa Pè

ÀWỌN àìlera rẹ lè kà ọ́ láyà. O lè ti gbìyànjú títí kó o lè borí wọn, àmọ́ kí wọ́n má lọ. Ìyẹn sì lè mú kó o máa rò pé o ò ní lè borí wọn láéláé, tàbí pé wọ́n ti kọjá agbára rẹ, pé agbára rẹ ò lè gbé e bíi tàwọn èèyàn yòókù. Bóyá àìsàn tó le koko tó ń tánni lókun sì nìṣòro tìrẹ, tí kì í jẹ́ kí ara rẹ yá bó ṣe yẹ. Èyí tó wù kó jẹ́, ó lè dà bíi pé kò sọ́nà àbáyọ fún ọ. Ó lè máa ṣe ọ́ bíi ti Jóòbù tó sọ fún Ọlọ́run pé: “Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fi mí pa mọ́ sínú Ṣìọ́ọ̀lù, pé ìwọ yóò pa mí mọ́ ní ìkọ̀kọ̀ títí ìbínú rẹ yóò fi yí padà, pé ìwọ yóò yan àkókò kan kalẹ̀ fún mi, kí o sì rántí mi!”—Jóòbù 14:13.

Báwo lo ṣe máa borí irú ipò àìnírètí bẹ́ẹ̀? Bó ti wù kí ìṣòro rẹ le tó, má ṣe kó o lé ọkàn, kàkà bẹ́ẹ̀, mọ́kàn kúrò lórí ẹ̀ fúngbà díẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, o lè ronú lórí àwọn ìbéèrè tí Jèhófà bi Jóòbù ìránṣẹ́ rẹ̀. Ó ní: “Ibo ni ìwọ wà nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀? Sọ fún mi, bí o bá mòye. Ta ní fi ìwọ̀n rẹ̀ lélẹ̀, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ìwọ mọ̀, tàbí ta ní na okùn ìdiwọ̀n sórí rẹ̀?” (Jóòbù 38:4, 5) Bá a bá ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ìbéèrè yẹn, ó lè mú ká gbà pé a ò gbọ́n tó Jèhófà, àti pé agbára rẹ̀ ju ti wa lọ. Èyí fi hàn pé ìdí pàtàkì ní láti wà tí Ọlọ́run fi fàyè gba ipò nǹkan inú ayé yìí tó ń fa ìṣòro wa.

‘Ẹ̀gún Kan Nínú Ẹran Ara Mi’

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tóun náà jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà, bẹ Jèhófà pé kó bá òun mú ‘ẹ̀gún kan tó wà nínú ẹran ara’ òun kúrò, ìyẹn ìṣòro kan tó ń yọ ọ́ lẹ́nu nígbà gbogbo. Ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà pé kó mú ìṣòro náà kúrò. Ohun yòówù kí ìṣòro náà jẹ́, ńṣe ló ń yọ Pọ́ọ̀lù lẹ́nu ṣáá bí ìgbà tí ẹ̀gún há sí i lára, èyí tó jẹ́ pé ó lè paná ayọ̀ rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ó sọ pé ìṣòro náà dà bí ìgbà tí wọ́n ń gbáni lábàrá ṣáá. Kí wá ni Jèhófà sọ? Ó ní: “Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí mi ti tó fún ọ; nítorí agbára mi ni a ń sọ di pípé nínú àìlera.” Jèhófà kò mú ẹ̀gún tó wà nínú ẹran ara Pọ́ọ̀lù kúrò. Ó wá di dandan kó máa bá a yí. Síbẹ̀ Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nígbà tí èmi bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.” (2 Kọ́r. 12:7-10) Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣòro Pọ́ọ̀lù kò fò lọ lọ́nà àrà, ó ṣì gbé nǹkan ribiribi ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ńṣe ni Pọ́ọ̀lù gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, tó sì ń ké pè é fún ìrànlọ́wọ́ déédéé. (Fílí. 4:6, 7) Ìyẹn ló fi wá sọ lápá ìgbẹ̀yìn ayé rẹ̀ pé: “Mo ti ja ìjà àtàtà náà, mo ti sáré ní ipa ọ̀nà eré ìje náà dé ìparí, mo ti pa ìgbàgbọ́ mọ́.”—2 Tím. 4:7.

Jèhófà máa ń lo àwọn èèyàn aláìpé láti fi ṣàṣeparí ohun tó ní lọ́kàn láìfi kùdìẹ̀-kudiẹ wọn àti ìṣòro wọn pè. Nítorí náà, òun lọpẹ́ yẹ fáwọn àṣeyọrí tí wọ́n bá ṣe. Ó máa ń fún wọn ní ọgbọ́n àti ìtọ́sọ́nà tí wọ́n á fi lè máa bá ìṣòro wọn yí nìṣó, kí wọ́n má sì pàdánù ayọ̀ wọn nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni o, ó lè lo àwa èèyàn aláìpé láti fi gbé iṣẹ́ bàǹtà-banta ṣe láìfi àìlera wa pè.

Pọ́ọ̀lù sọ ìdí tí Ọlọ́run ò fi mú ẹ̀gún inú ẹran ara òun kúrò, ó ní: “Kí a má bàa gbé mi ga púpọ̀ jù.” (2 Kọ́r. 12:7) Ńṣe ni “ẹ̀gún” tó wà lára Pọ́ọ̀lù jẹ́ kó máa rántí pé ó níbi tágbára òun mọ, ìyẹn sì jẹ́ kó túbọ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Èyí bá ohun tí Jésù kọ́ wa mu, pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a ó rẹ̀ sílẹ̀, ẹnì yòówù tí ó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óò gbé ga.” (Mát. 23:12) Ìdánwò lè jẹ́ kí ìránṣẹ́ Ọlọ́run dẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, kó sì rí i pé òun ní láti gbára lé Jèhófà kóun tó lè fara dá a láìyẹsẹ̀. Èyí á jẹ́ kóun náà lè “máa ṣògo nínú Jèhófà” bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù.—1 Kọ́r. 1:31.

Àwọn Kùdìẹ̀-kudiẹ Tó Fara Sin

Àwọn kan lè ní àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ kan tí kò hàn sáwọn fúnra wọn tàbí tí wọn ò fẹ́ fi gbogbo ara gbà pé àwọn ní. Bí àpẹẹrẹ, èèyàn lè dá ara rẹ̀ lójú jù, kó gbára lé ara rẹ̀. (1 Kọ́r. 10:12) Àìpé ẹ̀dá míì tó wọ́pọ̀ lára àwa èèyàn ni pé a máa ń fẹ́ wà nípò ńlá.

Jóábù tó di olórí àwọn ọmọ ogun Dáfídì Ọba jẹ́ akíkanjú àti ògbójú jagunjagun. Síbẹ̀ ó hùwà ìkà tó fi hàn pé ó lẹ́mìí ìgbéraga àti pé ó ń fi ìwàǹwára wá ipò ńlá. Ọ̀gágun méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ṣìkà pa. Lákọ̀ọ́kọ́, ó fẹ̀mí ìgbẹ̀san pa Ábínérì dà nù. Nígbà tó yá, Jóábù tún ṣe bíi pé ó ń kí Ámásà tó jẹ́ ìbátan rẹ̀, ó fọwọ́ ọ̀tún di irùngbọ̀n Ámásà mú bíi pé ó fẹ́ fẹnu kò ó lẹ́nu, ó sì fi idà ọwọ́ òsì rẹ̀ gún un pa. (2 Sám. 17:25; 20:8-10) Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé, ṣáájú àkókò yìí Dáfídì ti fi Ámásà rọ́pò Jóábù gẹ́gẹ́ bí olórí àwọn ọmọ ogun. Ìyẹn ni Jóábù fi fọgbọ́n gbẹ̀mí Ámásà tó kà sẹ́ni tó ń bá òun dupò, bóyá kí Dáfídì bàa lè dá a padà sípò olórí àwọn ọmọ ogun. Èyí fi hàn pé Jóábù kò wá bó ṣe máa ṣẹ́pá ẹ̀mí burúkú tó ní, títí kan ẹ̀mí fífi ìwàǹwára wá ipò ńlá. Bó ṣe dẹni tó ṣìkà pa àwọn ẹni ẹlẹ́ni dà nù nìyẹn láìlẹ́mìí ìrònúpìwàdà. Nígbà tó kù díẹ̀ kí Dáfídì Ọba kú, ó sọ fún Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ pé kó rí i pé Jóábù jìyà ìwà ìkà rẹ̀.—1 Ọba 2:5, 6, 29-35.

A kò gbọ́dọ̀ gba èrò burúkú láyé rárá, torí pé a lè kápá àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa. Àmọ́ ká tó lè kápá wọn a ní láti kọ́kọ́ gbà pé a ní àwọn ìṣòro yẹn. Lẹ́yìn náà ká wá sapá gidigidi láti ṣẹ́pá wọn. Ká máa gbàdúrà sí Jèhófà déédéé pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ náà, ká sì tẹra mọ́ kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti lè mọ bá a ṣe lè gbógun ti èròkerò wọ̀nyẹn. (Héb. 4:12) Ó lè gbà pé ká máa báwọn jìjàkadì nìṣó, láìjẹ́ kó sú wa. A tiẹ̀ lè má bọ́ nínú ìjàkadì lórí àìlera míì, níwọ̀n ìgbà tá a bá ṣì jẹ́ aláìpé. Pọ́ọ̀lù gbà pé bọ̀rọ̀ òun ṣe rí nìyẹn, nígbà tó sọ pé: “Ohun tí mo ń fẹ́, èyí ni èmi kò fi ṣe ìwà hù; ṣùgbọ́n ohun tí mo kórìíra ni èmi ń ṣe.” Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ṣe mọ̀, Pọ́ọ̀lù ò juwọ́ sílẹ̀ fáwọn ìwà wọ̀nyẹn bí ẹni pé ó ti ju ohun tó lè ṣèkáwọ́ lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń bá wọn jìjàkadì nìṣó, tó sì gbẹ́kẹ̀ lé ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi. (Róòmù 7:15-25) Nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ míì, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo ń lu ara mi kíkankíkan, mo sì ń darí rẹ̀ bí ẹrú, pé, lẹ́yìn tí mo bá ti wàásù fún àwọn ẹlòmíràn, kí èmi fúnra mi má bàa di ẹni tí a kò tẹ́wọ́ gbà lọ́nà kan ṣáá.”—1 Kọ́r. 9:27.

Lóòótọ́ o, ẹ̀dá èèyàn sábà máa ń wá àwíjàre fáwọn àṣìṣe wọn. Àmọ́ a lè dènà ìyẹn tá a bá fi kọ́ra láti máa wo àwọn nǹkan bí Jèhófà ṣe ń wò ó, ká sì máa ṣe ohun tí Pọ́ọ̀lù gba àwa Kristẹni níyànjú pé ká máa ṣe. Ó ní: “Ẹ fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ohun burúkú, ẹ rọ̀ mọ́ ohun rere.” (Róòmù 12:9) Bá a ṣe ń sapá láti borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa, a gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́, ká tẹra mọ́ ìsapá wa, ká sì rí i pé à ń ṣèkáwọ́ ara wa. Dáfídì bẹ Jèhófà pé: “Yọ́ kíndìnrín mi àti ọkàn-àyà mi mọ́.” (Sm. 26:2) Ó mọ̀ pé Ọlọ́run lè mọ ohun tó wà ní ìsàlẹ̀ ikùn wa pátápátá, kó sì ràn wá lọ́wọ́ bó bá ṣe yẹ. Tá a bá ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tí Jèhófà ń tipasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ fún wa, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, a lè dẹni tó borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa.

Àwọn kan lè máa dààmú nípa àwọn ìṣòro kan tí wọ́n rò pé àwọn ò lè dá yanjú. Ṣùgbọ́n ó dájú pé àwọn alàgbà ìjọ lè ràn wá lọ́wọ́ tìfẹ́tìfẹ́ kí wọ́n sì fún wa níṣìírí. (Aísá. 32:1, 2) Àmọ́ ṣá o, kò yẹ ká máa retí ohun tí kò lè ṣeé ṣe. Nítorí àwọn ìṣòro kan wà tí kò lè yanjú nínú ètò àwọn nǹkan yìí. Síbẹ̀ náà, àwọn èèyàn míì ti mọgbọ́n tí wọ́n ń ta sí ìṣòro wọn tó jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wọn láti máa bá ìgbésí ayé wọn lọ.

Ìtìlẹ́yìn Jèhófà Dájú

Ohun yòówù kó jẹ́ ìṣòro wa ní ìgbà líle koko tá à ń gbé yìí, ó dájú pé Jèhófà yóò máa gbé wa ró yóò sì máa tọ́ wa sọ́nà ká lè mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe. Bíbélì rọ̀ wá pé: “Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọ́run, kí ó lè gbé yín ga ní àkókò yíyẹ; bí ẹ ti ń kó gbogbo àníyàn yín lé e, nítorí ó bìkítà fún yín.”—1 Pét. 5:6, 7.

Nígbà tí arábìnrin Kathy tó ti ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì fún ọ̀pọ̀ ọdún rí i pé ọkọ òun ní àìsàn tó ń mú kí arúgbó máa ṣarán, kò rò pé ẹ̀mí òun á lè gbé gbogbo wàhálà tí àìsàn yẹn máa dá sílẹ̀. Ńṣe ló wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà lójoojúmọ́ pé kó fóun ní ọgbọ́n àti ẹ̀mí tóun á fi lè máa bójú tó o. Nígbà tó wá di pé àìsàn ọkọ rẹ̀ burú sí i, ẹ̀mí ìfẹ́ mú kí àwọn arákùnrin kan lọ ṣèwádìí nípa ọ̀nà téèyàn lè gbà ṣètọ́jú irú aláìsàn bẹ́ẹ̀. Àwọn arábìnrin sì fi tìfẹ́tìfẹ́ dúró ti àwọn méjèèjì gbágbáágbá. Jèhófà lo àwọn ará wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan tó gbà pèsè ìtìlẹyìn fún arábìnrin Kathy tó fi lè tọ́jú ọkọ rẹ̀ fún nǹkan bí ọdún mọ́kànlá kí ọkọ rẹ̀ tó kú. Arábìnrin Kathy wá sọ pé: “Tomijé-tomijé ni mo ń dúpẹ́ tọkàntọkàn lọ́wọ́ Jèhófà fún gbogbo ìrànlọ́wọ́ rẹ̀; ìyẹn ló jẹ́ kí n lè rọ́kàn gbé e. Mi ò rò pé màá lè ṣe gbogbo wàhálà yẹn pẹ́ tó bẹ́ẹ̀ kí ẹ̀mí mi má sì bọ́!”

Ìrànlọ́wọ́ Tó Máa Jẹ́ Ká Borí Ẹ̀ṣẹ̀ Tó Fara Sin

Nígbà táwọn èèyàn bá ń wò ó pé ọwọ́ àwọn ò mọ́, wọ́n lè máa rò pé Jèhófà ò ní gbọ́ àdúrà wọn tí wọ́n bá ké pè é nígbà ìpọ́njú. Ṣùgbọ́n, á dáa ká ronú lórí ohun tí Dáfídì sọ nígbà tó ń kábàámọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tó dá nínú ọ̀ràn Bátí-ṣébà. Ó ní: “Ọkàn-àyà tí ó ní ìròbìnújẹ́ tí ó sì wó palẹ̀ ni ìwọ, Ọlọ́run, kì yóò tẹ́ńbẹ́lú.” (Sm. 51:17) Níwọ̀n bí Dáfídì ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn, ó mọ̀ pé òun lè gbàdúrà sí Ọlọ́run nítorí aláàánú ni. Ìgbé ayé Jésù jẹ́ ká rí bí Jèhófà ṣe jẹ́ aláàánú tó. Mátíù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Ìwé Ìhìn Rere lo ọ̀rọ̀ kan tó wà nínú ìwé Aísáyà fún Jésù, ó ní: “Kò sí esùsú kankan tí a ti pa lára tí yóò tẹ̀ fọ́, kò sì sí òwú àtùpà kankan tí a fi ọ̀gbọ̀ ṣe tí ń jó lọ́úlọ́ú tí yóò fẹ́ pa.” (Mát. 12:20; Aísá. 42:3) Nígbà tí Jésù wà láyé, ó ṣàánú àwọn ẹni rírẹlẹ̀ àtàwọn tí wọ́n ń tẹ̀ lórí ba. A lè sọ ọ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ pé kò filé ayé sú àwọn tí ẹ̀mí wọn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́ bí ìgbà tèèyàn fẹ́ iná àtùpà tó ń jó lọ́úlọ́ú pa. Kàkà bẹ́ẹ̀, bí ẹní bu epo sí àtùpà kó lè máa jó dáadáa ló ṣe rọra ń kọ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ nípa Ọlọ́run kí ẹ̀mí wọn lè sọjí. Irú ọwọ́ tí Jésù fi mú àwọn èèyàn nìyẹn nígbà tó wà láyé. Ǹjẹ́ o gbà pé bí Jésù ṣe jẹ́ nìyẹn títí di báyìí àti pé ó lè bá ọ kẹ́dùn nínú gbogbo àìlera rẹ? Ṣàkíyèsí pé ohun tí Hébérù 4:15 sọ nípa Jésù ni pé ó lè “báni kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa.”

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ‘ẹ̀gún tó wà nínú ẹran ara’ rẹ̀, ó ní ńṣe ni agbára Kristi bo òun lórí “bí àgọ́.” (2 Kọ́r. 12:7-9) Ó mọ̀ ọ́n lára pé Ọlọ́run ń tipasẹ̀ Kristi dàábò bo òun bí àgọ́ ṣe ń gbani lọ́wọ́ òjò àti oòrùn. Irú ẹ̀mí tí Pọ́ọ̀lù ní ló yẹ káwa náà ní. Ká má fàyè gba àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ àti ìṣòro wa. Ńṣe ni ká máa lo àwọn ohun tí Jèhófà ń tipasẹ̀ ètò rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé pèsè fún wa dáadáa kí àjọṣe tó dán mọ́rán lè wà láàárín àwa àti Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká rí i pé a sa gbogbo ipá wa lórí àwọn ìṣòro wa, ká wá fèyí tó kù sílẹ̀ sọ́wọ́ Jèhófà, ká sì ní ìdánilójú pé yóò tọ́ wa sọ́nà. Tá a bá ń rí bí agbára Ọlọ́run ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ nípa àwọn àìlera wa, àwa náà á lè sọ gẹ́gẹ́ bíi ti Pọ́ọ̀lù pé: “Nígbà tí èmi bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.”—2 Kọ́r. 12:10.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Ìgbà gbogbo ni Pọ́ọ̀lù ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó tọ́ òun sọ́nà kóun lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun láṣeparí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Dáfídì Ọba fa àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lé Jóábù lọ́wọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Jóábù ṣìkà pa Ámásà tó kà sẹ́ni tó ń bá òun dupò

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Àwọn alàgbà máa ń fìfẹ́ sọ ohun tí Bíbélì wí fún wa ká lè mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe nípa àwọn ìṣòro wa