Má Ṣe Jẹ́ Kí ‘Ìfẹ́ Tó O Ní Lákọ̀ọ́kọ́’ Jó Rẹ̀yìn
Má Ṣe Jẹ́ Kí ‘Ìfẹ́ Tó O Ní Lákọ̀ọ́kọ́’ Jó Rẹ̀yìn
“Máa bá a nìṣó ní dídi ohun tí ìwọ ní mú ṣinṣin.”—ÌṢÍ. 3:11.
1, 2. Báwo ló ṣe rí lọ́kàn rẹ nígbà tó dá ọ lójú pé òótọ́ lohun tó ò ń kọ́ nípa Jèhófà?
ǸJẸ́ o rántí ìgbà àkọ́kọ́ tó o gbọ́ nípa àwọn nǹkan àgbàyanu tí Jèhófà sọ pé òun máa ṣe fáwọn èèyàn tó bá jẹ́ onígbọràn? Tó bá jẹ́ pé o ti wà nínú ẹ̀sìn kan kó o tó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, báwo ló ṣe rí lọ́kàn rẹ nígbà tí wọ́n ṣàlàyé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ pé Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe, tàbí nígbà tí wọ́n ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ tó ti fìgbà kan rí ṣòro fún ọ láti lóye? Ó ṣeé ṣe kó o wá mọ̀ pé ẹ̀sìn rẹ ti ṣì ọ́ lọ́nà. Àmọ́, wo bí ayọ̀ rẹ ti kún tó nísinsìnyí tó o ti mọ òtítọ́! Tó bá jẹ́ pé Kristẹni làwọn òbí tó tọ́ ẹ dàgbà, ǹjẹ́ o rántí bí ayọ̀ rẹ ṣe kún tó nígbà tó wá dá ọ lójú pé òótọ́ lohun táwọn òbí rẹ ń kọ́ ẹ nípa Jèhófà, tó o sì pinnu láti máa gbé ìgbésí ayé rẹ ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó ò ń kọ́?—Róòmù 12:2.
2 Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ ló máa sọ fún ẹ pé inú àwọn dùn gan-an nígbà táwọn sún mọ́ Jèhófà, pé àwọn sì dúpẹ́ fún bó ṣe fa àwọn. (Jòh. 6:44) Ìdùnnú yìí ló mú kí wọ́n máa lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò ìjọ. Ayọ̀ yìí kúnnú ọkàn wọn débi pé wọ́n fẹ́ sọ ohun tó ń fún wọn láyọ̀ fún gbogbo èèyàn. Ṣé bọ́rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn?
3. Báwo ni nǹkan ṣe rí nínú ìjọ Éfésù nígbà tí Jésù ránṣẹ́ sí wọn?
3 Nínú iṣẹ́ tí Jésù rán sáwọn ará ìjọ tó wà nílùú Éfésù ní ọ̀rúndún kìíní, ó sọ̀rọ̀ nípa ‘ìfẹ́ tí wọ́n ní lákọ̀ọ́kọ́.’ Àwọn ará Éfésù láwọn ànímọ́ tó dára gan-an, àmọ́ ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà nígbà kan rí ti ń jó rẹ̀yìn. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ fún wọn pé: “Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ, àti òpò àti ìfaradà rẹ, àti pé ìwọ kò lè gba àwọn ènìyàn búburú mọ́ra, àti pé ìwọ ti dán àwọn tí wọ́n sọ pé àpọ́sítélì ni àwọn wò, ṣùgbọ́n tí wọn kì í ṣe bẹ́ẹ̀, o sì rí wọn ní òpùrọ́. Ìwọ ń fi ìfaradà hàn pẹ̀lú, o sì ti rọ́jú nítorí orúkọ mi, àárẹ̀ kò sì mú ọ. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, mo ní èyí lòdì sí ọ, pé ìwọ ti fi ìfẹ́ tí ìwọ ní ní àkọ́kọ́ sílẹ̀.”—Ìṣí. 2:2-4.
4. Kí nìdí tí ìmọ̀ràn tí Jésù fún àwọn ará Éfésù fi ṣe pàtàkì lóde òní?
4 Ìgbà kan wà tí ìmọ̀ràn Jésù tó wà nínú ìwé Ìṣípayá, èyí tó fún àwọn ará ìjọ Éfésù àtàwọn ìjọ tó kù, bá àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró mu, torí ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín wọn láwọn àkókò kan tó bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1914. (Ìṣí. 1:10) Síbẹ̀ náà, ó ṣì ṣeé ṣe fáwọn Kristẹni kan nísinsìnyí láti pàdánù “ìfẹ́ tí [wọ́n] ní ní àkọ́kọ́” fún Jèhófà àti fún òtítọ́. Bó o ṣe ń fìyẹn sọ́kàn, jẹ́ ká wá ṣàyẹ̀wò bí rírántí àwọn ìrírí ti ara rẹ àti ṣíṣàṣàrò lórí wọn ṣe lè jẹ́ kí ìfẹ́ àti ìtara tó o ní lákọ̀ọ́kọ́ fún Ọlọ́run àti fún òtítọ́ máa dọ̀tun, kó máa lágbára sí i, kó sì máa pọ̀ sí i.
Kí Ló Mú Kó Dá Ọ Lójú Pé Òtítọ́ Lohun Tó Ò Ń Kọ́?
5, 6. (a) Kí ló yẹ kí Kristẹni kọ̀ọ̀kan fi dá ara rẹ̀ lójú? (b) Kí ló mú kó dá ọ lójú pé òótọ́ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń kọ́ni? (d) Kí ló lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti sọ ìfẹ́ àkọ́kọ́ tó ní dọ̀tun?
5 Kó tó di pé ẹnì kan ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, òun fúnra rẹ̀ ní láti kọ́kọ́ “ṣàwárí” ohun tó jẹ́ “ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.” (Róòmù 12:1, 2) Ọ̀kan lára ọ̀nà téèyàn lè gbà ṣèyẹn ni pé kéèyàn kọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì. Ohun tó mú kó dá ẹnì kan lójú pé òótọ́ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń kọ́ni lè yàtọ̀ sóhun tó mú kó dá ẹlòmíì lójú. Àwọn míì rántí pé àwọn yí ìgbésí ayé àwọn padà nígbà táwọn ka orúkọ Ọlọ́run nínú Bíbélì tàbí nígbà táwọn mọ ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí èèyàn nígbà tó bá kú. (Sm. 83:18; Oníw. 9:5, 10) Ohun tó fa àwọn míì lọ́kàn mọ́ra ni ìfẹ́ táwọn èèyàn Jèhófà ní láàárín ara wọn. (Jòh. 13:34, 35) Àwọn míì sì yí padà nígbà tí wọ́n lóye ohun tó túmọ̀ sí láti má ṣe jẹ́ apá kan ayé. Wọ́n wá rí i pé àwọn Kristẹni tòótọ́ kò gbọ́dọ̀ bá wọn dá sí àríyànjiyan tó wà nínú òṣèlú tàbí ogun táwọn orílẹ̀-èdè èyíkéyìí bá ń jà.—Aísá. 2:4; Jòh. 6:15; 17:14-16.
6 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé àwọn ohun tá a mẹ́nu bà yìí àtàwọn ẹ̀kọ́ míì tí wọ́n kọ́ ló mú kí wọ́n ní ìfẹ́ Ọlọ́run fúngbà àkọ́kọ́. Sinmẹ̀dọ̀, kó o ronú lórí ohun tó mú kí ìwọ náà gbà pé o ti rí òtítọ́. Ipò olúkúlùkù wa àti irú ẹni tá a jẹ́ yàtọ̀ síra, torí náà, ohun tó mú kó o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tó o sì fi gba àwọn ìlérí rẹ̀ gbọ́ lè yàtọ̀ sí tàwọn ẹlòmíì, ó sì ṣeé ṣe kóhun náà ṣì wà lọ́kàn rẹ digbí títí dòní, gẹ́gẹ́ bó ṣe rí nígbà tó o kọ́kọ́ mọ̀ ọ́n. Òtítọ́ ò tíì yí padà. Nítorí náà, tó o bá tún ń gbé àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ náà yẹ̀ wò, tó o sì ń rántí bó ṣe dùn mọ́ ọ tó nígbà tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ wọn, yóò máa sọ ìfẹ́ àkọ́kọ́ tó o ní fún òtítọ́ dọ̀tun.—Ka Sáàmù 119:151, 152; 143:5.
Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Tó O Ní Lákọ̀ọ́kọ́ Túbọ̀ Máa Lágbára
7. Kí nìdí tó fi yẹ ká túbọ̀ fi kún ìfẹ́ àkọ́kọ́ tá a ní fún òtítọ́, ọ̀nà wo la sì lè gbà ṣe èyí?
7 Ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ ìyípadà ti wáyé nínú ìgbésí ayé rẹ látìgbà tó o ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. Ìfẹ́ tó o ní fún òtítọ́ nígbà yẹn pọ̀ gan-an, ṣùgbọ́n bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, o wá rí i pé o nílò ìfẹ́ tó jinlẹ̀ sí i kó o bàa lè dojú kọ àwọn ohun tó ń dán ìgbàgbọ́ rẹ wò. Àmọ́ Jèhófà kò fi ọ́ sílẹ̀. (1 Kọ́r. 10:13) Ìyẹn ló fà á táwọn ìrírí tó o ti ní láwọn ọdún yìí wá fi ṣeyebíye lójú rẹ. Àwọn ìrírí wọ̀nyí ti jẹ́ kó o lè túbọ̀ fi kún ìfẹ́ tó o ní lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n sì tún wà lára àwọn ọ̀nà tó o fi lè fúnra rẹ ṣàwárí ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà.—Jóṣ. 23:14; Sm. 34:8.
8. Kí ni Jèhófà sọ fún Mósè nípa irú ẹni tóun jẹ́, báwo sì làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe wá túbọ̀ mọ Ọlọ́run dáadáa?
8 Bí àpẹẹrẹ, wo ipò táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ara wọn nígbà tí Jèhófà sọ ohun tó ní lọ́kàn fún wọn, pé òun máa dá wọn nídè lóko ẹrú tí wọ́n wà ní Íjíbítì. Ọlọ́run sọ irú ẹni tí òun jẹ́ fún Mósè, ó sọ pé: “Èmi yóò jẹ́ ohun tí èmi yóò jẹ́.” (Ẹ́kís. 3:7, 8, 13, 14) Ohun tí Jèhófà ń fi èyí sọ ni pé ohun tó bá yẹ kóun ṣe lòun á ṣe láti lè gba àwọn èèyàn òun sílẹ̀. Nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lẹ́yìn náà, pẹ̀lú ipò táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ara wọn, wọ́n rí bí Jèhófà ṣe ń fi ara rẹ̀ hàn lóríṣiríṣi ọ̀nà, irú bí ìgbà tó fi ara rẹ̀ hàn ní Olódùmarè, Adájọ́, Amọ̀nà, Olùdáǹdè, Jagunjagun àti Olùpèsè.—Ẹ́kís. 12:12; 13:21; 14:24-31; 16:4; Neh. 9:9-15.
9, 10. Irú nǹkan wo ló ti ṣẹlẹ̀ tó lè mú kẹ́nì kan túbọ̀ mọ Ọlọ́run, kí sì nìdí tó fi dáa kéèyàn máa rántí irú àwọn ìrírí bẹ́ẹ̀?
9 Ipò tìrẹ yàtọ̀ sí tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì. Síbẹ̀, o lè ti ní àwọn ìrírí tó jẹ́ kó o mọ̀ dájú pé Ọlọ́run dìídì nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an, tíyẹn sì ti mú kí ìgbàgbọ́ rẹ lágbára. Ó ṣeé ṣe kí Jèhófà ti fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí Olùpèsè, Olùtùnú àti Olùkọ́ fún ọ láwọn ọ̀nà kan. (Ka Aísáyà 30:20b, 21.) Tàbí kó jẹ́ pé o ti rí i kedere bí àdúrà rẹ kan ṣe gbà. Ó lè jẹ́ pé ṣe lo wà nínú ìṣòro kan tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan sì wá ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tàbí kó jẹ́ pé nígbà tó ò ń ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ lo ráwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó wúlò fún ọ gan-an.
10 Irú àwọn ìrírí wọ̀nyí lè máà wú àwọn èèyàn kan lórí tó o bá sọ ọ́ fún wọn. Ó ṣe tán àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ náà kì í ṣe iṣẹ́ ìyanu. Àmọ́ nǹkan pàtàkì ni wọ́n jẹ́ lójú tìẹ. Kókó ibẹ̀ nìyẹn, Jèhófà jẹ́ ohun tó yẹ kó jẹ́ gan-an fún ọ. Ronú nípa àwọn ọdún tó o ti lò nínú òtítọ́. Ǹjẹ́ o lè rántí ìgbà tó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ tí ìwọ alára gan-an mọ̀ pé Jèhófà dìídì dá sí ọ̀ràn rẹ? Tó o bá lè rántí àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn tó o sì rántí bí wọ́n ṣe mú ọ láyọ̀ tó, ìfẹ́ Jèhófà yóò túbọ̀ jinlẹ̀ lọ́kàn rẹ gẹ́gẹ́ bó ṣe rí nígbà táwọn nǹkan wọ̀nyẹn ṣẹlẹ̀. Máa fi hàn pé o mọyì àwọn ìrírí yẹn. Máa ṣàṣàrò lórí wọn. Ẹ̀rí tó fi hàn nìyẹn pé Jèhófà dìídì nífẹ̀ẹ́ rẹ, kò sì sẹ́ni tó lè sọ pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ rẹ mọ́.
Gbé Ipò Rẹ Yẹ̀ Wò
11, 12. Kí ló lè mú kí ìfẹ́ tí Kristẹni kan ní sí òtítọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í jó rẹ̀yìn, ìmọ̀ràn Jésù wo sì ni irú ẹni bẹ́ẹ̀ ní láti fi sọ́kàn?
11 Bó bá ṣẹlẹ̀ pé irú ìfẹ́ tó o kọ́kọ́ ní sí Ọlọ́run àti sí òtítọ́ ò fi bẹ́ẹ̀ sí mọ́, èyí kì í ṣe nítorí pé Ọlọ́run ti yàtọ̀ sí irú ẹni tó jẹ́ tẹ́lẹ̀. Jèhófà kì í yí padà. (Mál. 3:6; Ják. 1:17) Bí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe jẹ Ọlọ́run lógún nígbà tó o kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ló ṣe jẹ ẹ́ lógún títí di ìsinsìnyí. Ó dára, ká sọ pé ohun kan ti ṣẹlẹ̀ tó mú kó dà bíi pé àjọṣe àárín ìwọ àti Jèhófà kò rí bó ṣe rí tẹ́lẹ̀ mọ́, kí lo rò pé ó fà á? Ṣé kì í ṣe pé ò ń rò ó pé wàhálà àti àníyàn ìgbésí ayé yìí ti pọ̀ jù fún ọ? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé tẹ́lẹ̀ o máa ń gbàdúrà tọkàntọkàn, o ò kóyán ìdákẹ́kọ̀ọ́ kéré rárá, o ò sí fi àṣàrò ṣeré. Ṣé kò lè jẹ́ pé ìtara tó o fi ń wàásù tẹ́lẹ̀ ti dín kù, tí ìpàdé lílọ rẹ kò sì dà bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́?—2 Kọ́r. 13:5.
12 O lè má ṣàkíyèsí pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti ń sẹlẹ̀, àmọ́ tó o bá kíyè sí i, kí lo rò pó fà á? Ṣó lè jẹ́ pé àníyàn nípa àwọn ohun tó yẹ ní ṣíṣe, irú bíi pípèsè ohun tó tó fáwọn ìdílé rẹ, bíbójútó ìlera rẹ àtàwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ ti ń jẹ́ kó o gbàgbé pé ọjọ́ Jèhófà ti dé tán? Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Ẹ kíyè sí ara yín, kí ọkàn-àyà yín má bàa di èyí tí a dẹrù pa pẹ̀lú àjẹjù àti ìmutíyó kẹ́ri àti àwọn àníyàn ìgbésí ayé, lójijì tí ọjọ́ yẹn yóò sì dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn. Nítorí yóò dé bá gbogbo àwọn tí ń gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀ ayé. Ẹ máa wà lójúfò, nígbà náà, ní rírawọ́ ẹ̀bẹ̀ ní gbogbo ìgbà, kí ẹ lè kẹ́sẹ járí ní yíyèbọ́ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti ṣẹlẹ̀.”—Lúùkù 21:34-36.
13. Kí ni Jákọ́bù fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wé?
13 Ọlọ́run mí sí Jákọ́bù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì láti rọ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ pé kí wọ́n máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbé ara wọn yẹ̀ wò láìṣẹ̀tàn. Ó kọ̀wé pé: “Ẹ di olùṣe ọ̀rọ̀ náà, kì í sì í ṣe olùgbọ́ nìkan, ní fífi èrò èké tan ara yín jẹ. Nítorí bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí kò sì jẹ́ olùṣe, ẹni yìí dà bí ènìyàn tí ń wo ojú àdánidá rẹ̀ nínú dígí. Nítorí ó wo ara rẹ̀, ó sì lọ, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó gbàgbé irú ènìyàn tí òun jẹ́. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń wo inú òfin pípé tí í ṣe ti òmìnira ní àwòfín, tí ó sì tẹpẹlẹ mọ́ ọn, ẹni yìí, nítorí tí kò di olùgbọ́ tí ń gbàgbé, bí kò ṣe olùṣe iṣẹ́ náà, yóò láyọ̀ nínú ṣíṣe é.”—Ják. 1:22-25.
14, 15. (a) Báwo ni Bíbélì ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ mú kó o sunwọ̀n sí i gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni? (b) Àwọn ìbéèrè wo lo lè fara balẹ̀ ronú lé lórí?
14 Ẹnì kan lè wo dígí láti fi mọ̀ bóyá òun múra dáadáa. Bí àpẹẹrẹ, tọ́kùnrin kan bá rí i pé táì òun wọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, yóò tún un ṣe. Tí obìnrin kan bá sì rí i pé irun òun dà rú, yóò tún un ṣe. Lọ́nà kan náà, Ìwé Mímọ́ máa ń jẹ́ ká lè ṣàyẹ̀wò irú ẹni tá a jẹ́. Tá a bá ń fi Bíbélì yẹ ara wa wò láti mọ̀ bóyá irú ẹni tó yẹ ká jẹ́ la jẹ́, a jẹ́ pé à ń lò ó bíi dígí nìyẹn. Ṣùgbọ́n kí làǹfààní pé a wo ara wa nínú dígí tí a kò bá ṣàtúnṣe ibì kan tó kù díẹ̀ káàtó? A jẹ́ ọlọ́gbọ́n bá a bá ń ṣe ohun tá a rí nínú “òfin pípé” tó jẹ́ ti Ọlọ́run, ìyẹn ni pé ká di “olùṣe” ohun tó wà nínú rẹ̀. Nítorí náà, bí ẹnikẹ́ni bá fura pé ìfẹ́ àkọ́kọ́ tóun ní fún Jèhófà àti òtítọ́ ti dín kù, kó fara balẹ̀ ronú lórí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí: ‘Àwọn ìṣòro wo ni mò ń rí nígbèésí ayé, kí sì ni mo máa ń ṣe sí wọn? Kí ni mo ti ń ṣe sí wọn tẹ́lẹ̀? Kí ló wá fa ìyàtọ̀?’ Lẹ́yìn tó o bá ti yẹ ara rẹ wò báyìí, tó o bá wá rí i pé ó kù dìẹ̀ káàtó láwọn ibì kan, wá nǹkan ṣe sí i. Rí i dájú pé o ṣe àtúnṣe èyíkéyìí tó bá yẹ, kó o sì ṣe é láìfi falẹ̀.—Héb. 12:12, 13.
15 Irú àṣàrò bẹ́ẹ̀ tún lè jẹ́ kó o ronú kan ohun kan tọ́wọ́ rẹ lè tẹ̀, tó máa mú kó o tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún Tímótì alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀ ní ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run mí sí kó bàa lè túbọ̀ mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ sunwọ̀n sí i. Ó rọ ọ̀dọ́kùnrin yẹn pé: “Máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá, kí ìlọsíwájú rẹ lè fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.” Báwa náà ṣe ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó máa dáa tá a bá ń fẹ̀sọ̀ ronú lórí ibi tá a ti lè tẹ̀ síwájú.—1 Tím. 4:15.
16. Nígbà tó o bá ń fi Ìwé Mímọ́ yẹ ara rẹ wò, ewu wo ló yẹ kó o ṣọ́ra fún?
16 Tó o bá fi òótọ́ inú yẹ ara rẹ wò, wàá rí i pé o láwọn kùdìẹ̀-kudiẹ kan. Ìyẹn sì lè fẹ́ mú kó o rẹ̀wẹ̀sì, àmọ́ má ṣe jẹ́ kíyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ. Ó ṣe tán, ìdí tó o fi yẹ ara rẹ wò ni pé o fẹ́ mọ ibi tó ti yẹ kó o ṣe dáadáa sí i. Sátánì ń fẹ́ kí Kristẹni kan rò pé òun ò já mọ́ nǹkan kan torí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ òun. Kódà, ó sọ pé Ọlọ́run ò ka gbogbo ìsapá àwọn èèyàn láti jọ́sìn rẹ̀ sí nǹkan kan. (Jóòbù 15:15, 16; 22:3) Irọ́ pátápátá nìyẹn, Jésù sì já a ní koro. Ọlọ́run ka ẹnì kọ̀ọ̀kan wa sẹ́ni tó ṣeyebíye. (Ka Mátíù 10:29-31.) Nítorí náà, ṣe ló yẹ kí mímọ̀ tó o mọ̀ pé aláìpé ni ọ́ mú kó o fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ pinnu láti ṣàtúnṣe, Jèhófà yóò sì ràn ọ́ lọ́wọ́. (2 Kọ́r. 12:7-10) Tí àìsàn tàbí ọjọ́ ogbó kò bá jẹ́ kó o lè ṣe tó bó o ṣe fẹ́, má ṣe jẹ́ kó sú ọ tàbí kí ìfẹ́ rẹ jó rẹ̀yìn, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o máa lépa àwọn ohun tó o mọ̀ pé apá rẹ á lè ká.
Ọ̀pọ̀ Ìdí Tó Fi Yẹ Kó O Máa Dúpẹ́
17, 18. Àwọn àǹfààní wo lo máa jẹ tó o bá jẹ́ kí ìfẹ́ àkọ́kọ́ tó o ní máa lágbára sí i?
17 Ọ̀pọ̀ àǹfààní ńlá lo máa jẹ tó o bá ń jẹ́ kí ìfẹ́ àkọ́kọ́ tó o ní túbọ̀ máa lágbára. Á jẹ́ kí ìmọ̀ tó o ní nípa Ọlọ́run túbọ̀ máa jinlẹ̀, wàá sì lè máa mọrírì bó ṣe ń fi ìfẹ́ tọ́ ẹ sọ́nà. (Ka Òwe 2:1-9; 3:5, 6.) Onísáàmù kan sọ pé, “èrè ńlá wà nínú pípa [àwọn ìpinnu ìdájọ́ Jèhófà] mọ́.” “Ìránnilétí Jèhófà ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, ó ń sọ aláìní ìrírí di ọlọ́gbọ́n.” Bákan náà, ó sọ pé “aláyọ̀ ni àwọn aláìní-àléébù ní ọ̀nà wọn, àwọn tí ń rìn nínú òfin Jèhófà.”—Sm. 19:7, 11; 119:1.
18 Láìsí àní-àní, o ti wá rí ọ̀pọ̀ ohun rere tó o lè tìtorí rẹ̀ máa dúpẹ́. O mọ ohun tó fa gbogbo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé lónìí. Ò ń jàǹfààní àbójútó tẹ̀mí àti onírúurú ohun tí Ọlọ́run ń pèsè fáwọn èèyàn rẹ̀ lónìí. Ó dájú pé wàá tún mọrírì bí Jèhófà ṣe fà ọ́ wá sínú ìjọ rẹ̀ tó wà kárí ayé tó sì fún ọ láǹfààní láti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀. Téèyàn bá mọnú rò, ó yẹ kó mọ ọpẹ́ dá! Tó o bá ní kó o máa kọ gbogbo ìbùkún tó o ti rí gbà sínú ìwé kan, ó dájú pé ilẹ̀ á kún. Tó o bá ń ronú lóòrèkóòrè nípa àwọn ìbùkún tó o ti ní, á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fi ìmọ̀ràn yìí sílò, pé: “Máa bá a nìṣó ní dídi ohun tí ìwọ ní mú ṣinṣin.”—Ìṣí. 3:11.
19. Yàtọ̀ sí ṣíṣàṣàrò lórí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run, kí ló tún ṣe pàtàkì téèyàn bá fẹ́ máa lókun nípa tẹ̀mí?
19 Ńṣe ni ṣíṣàṣàrò lórí bí ìgbàgbọ́ rẹ ṣe ń di èyí tó lágbára sí i láti àwọn ọdún yìí wá kàn wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tó o lè ṣe tó máa jẹ́ kó o lè di ohun tó o ní mú ṣinṣin. Ìwé ìròyìn yìí ti máa ń ṣàlàyé lemọ́lemọ́ lórí àwọn ohun pàtàkì tó lè jẹ́ kí èèyàn máa lókun nípa tẹ̀mí. Ara wọn ni àdúrà, lílọ sípàdé àti kíkópa níbẹ̀, àti fífi ìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù. Àwọn nǹkan wọ̀nyí á jẹ́ kí ìfẹ́ tó o ní lákọ̀ọ́kọ́ túbọ̀ máa dọ̀tun, kó máa jinlẹ̀ sí i kó sì máa lágbára sí i.—Éfé. 5:10; 1 Pét. 3:15; Júúdà 20, 21.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Báwo làwọn nǹkan tó mú kó o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ṣe lè máa fún ọ níṣìírí nísinsìnyí?
• Kí ni ríronú lórí àwọn ohun tójú ẹ ti rí látìgbà tó o ti ń sin Jèhófà bọ̀ lè fi dá ọ lójú?
• Kí nìdí tó fi yẹ kó o ronú dáadáa nípa ìfẹ́ tó o ní fún Ọlọ́run?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Kí lohun náà tó fà ọ́ mọ́ra tó sì mú kó dá ọ lójú pé òtítọ́ lohun tó ò ń kọ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ǹjẹ́ o kíyè sí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ kan tó yẹ kó o ṣàtúnṣe rẹ̀?