Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bá A Ṣe Lè Borí Ìṣòro Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwáàsù Ilé-dé-Ilé

Bá A Ṣe Lè Borí Ìṣòro Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwáàsù Ilé-dé-Ilé

Bá A Ṣe Lè Borí Ìṣòro Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwáàsù Ilé-dé-Ilé

“Àwa . . . máyàle nípasẹ̀ Ọlọ́run wa láti sọ ìhìn rere Ọlọ́run fún yín pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìjàkadì.”—1 TẸS. 2:2.

1. Àwọn ìṣòro wo ni Jeremáyà dojú kọ, báwo ló sì ṣe borí wọn?

 È ÈYÀN ẹlẹ́ran ara bíi tiwa ni Jeremáyà. Nígbà tí Jèhófà sọ fún un pé òun ti yàn án láti jẹ́ “wòlíì fún àwọn orílẹ̀-èdè,” ó kígbe pé: “Págà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Kíyè sí i, èmi kò tilẹ̀ mọ ọ̀rọ̀ sọ, nítorí pé ọmọdé lásán ni mí.” Àmọ́, ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó sì gbà láti ṣe iṣẹ́ náà. (Jer. 1:4-10) Ó ju ogójì ọdún lọ táwọn èèyàn fi dágunlá sí ọ̀rọ̀ Jeremáyà, tí wọn ò fẹ́ gbọ́ iṣẹ́ tó fẹ́ jẹ́ fún wọn. Wọ́n fi ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n tiẹ̀ tún lù ú pàápàá. (Jer. 20:1, 2) Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó lóun ò ní sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà mọ́. Síbẹ̀, ó ń bá a nìṣó láti máa wàásù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù lára àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè náà ni kò fẹ́ gbọ́ ìwàásù rẹ̀. Ká ní Jeremáyà gbẹ́kẹ̀ lé agbára tara ẹ̀ ni, kò ní lè ṣàṣeyọrí, àmọ́ Ọlọ́run fún un lókun tó mú kó ṣàṣeyọrí.—Ka Jeremáyà 20:7-9.

2, 3. Àwọn ìṣòro wo làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní ń dojú kọ bíi ti Jeremáyà?

2 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jeremáyà yìí náà ń ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní. Nígbà tí àwọn kan lára wa kọ́kọ́ ronú nípa wíwàásù láti ilé dé ilé, ó ṣeé ṣe kí wọ́n sọ pé, ‘Mi ò rò pé mo lè ṣe é láé.’ Àmọ́ nígbà tá a wá mọ̀ pé ìfẹ́ Jèhófà ni pé ká wàásù ìhìn rere, ẹ̀rù tó ń bà wá tẹ́lẹ̀ fò lọ, a sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ní pẹrẹu. Pẹ̀lú gbogbo ìyẹn náà, ọ̀pọ̀ lára wa ló jẹ́ pé ó kéré tán, ìgbà kan wà tí ipò nǹkan ti mú kó ṣòro fún wa láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù nìṣó. Ká sòótọ́, ó gba ìsapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù láti ilé dé ilé, ká sì máa bá a nìṣó títí dé òpin.—Mát. 24:13.

3 Kí lo lè ṣe tó bá jẹ́ pé ó ti pẹ́ díẹ̀ tó o ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó o sì ti ń wá sípàdé ìjọ, àmọ́ tó ò ń lọ́ tìkọ̀ láti bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù láti ilé dé ilé? Tàbí kẹ̀, kí lo lè ṣe tó bá jẹ́ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ti ṣèrìbọmi ni ẹ́, àmọ́ tó máa ń ṣòro fún ẹ láti wàásù láti ilé dé ilé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé agbára rẹ gbé e láti ṣe é? Jẹ́ kó dá ọ lójú pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láti ibi gbogbo ló ń borí ìṣòro tí wọ́n ń dojú kọ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ìwọ náà lè borí àwọn ìṣòro wọ̀nyí.

Bó O Ṣe Lè Máyà Le

4. Kí ló mú kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lè wàásù ìhìn rere pẹ̀lú ìgboyà?

4 Láìsí àní-àní, o mọ̀ pé ẹ̀mí Ọlọ́run la fi ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé, kì í ṣe agbára tàbí ọgbọ́n èèyàn. (Sek. 4:6) Bọ́rọ̀ sì ṣe rí náà nìyẹn pẹ̀lú iṣẹ́ ìwàásù tí Kristẹni kọ̀ọ̀kan ń ṣe. (2 Kọ́r. 4:7) Jẹ́ ká gbé ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù yẹ̀ wò. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa igbà kan táwọn alátakò hùwà ìkà sóun àti ẹni tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì, ó sọ pé: ‘Ṣùgbọ́n àwa, lẹ́yìn tí a ti kọ́kọ́ jìyà, tí a sì hùwà sí wa lọ́nà àfojúdi ní ìlú Fílípì, ti máyàle nípasẹ̀ Ọlọ́run wa láti sọ ìhìn rere Ọlọ́run fún yín pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìjàkadì.’ (1 Tẹs. 2:2; Ìṣe 16:22-24) Ó lè ṣòro fún wa láti ronú pé Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ onítara lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù bá ara rẹ̀ jìjàkadì kó tó lè ṣiṣẹ́ ìwàásù láwọn ìgbà kan. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà kó bàa lè ṣeé ṣe fún un láti wàásù ìhìn rere pẹ̀lú ìgboyà, àwa náà sì gbọ́dọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀. (Ka Éfésù 6:18-20.) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù?

5. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti máyà le lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?

5 Àdúrà gbígbà jẹ́ ọ̀nà kan tá a fi lè máyà le lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Arábìnrin kan tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sọ pé: “Mo gbàdúrà pé kí n lè sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìdánilójú, kí n lè sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa wọ àwọn èèyàn lọ́kàn, mo sì tún gbàdúrà pé kí n lè láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ó ṣe tán, iṣẹ́ Jèhófà ni, kì í ṣe iṣẹ́ tara wa, nítorí náà, kò sóhun tá a lè ṣe láìjẹ pé ó ràn wá lọ́wọ́.” (1 Tẹs. 5:17) Ó yẹ kí gbogbo wa tẹra mọ́ gbígbàdúrà fún ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ká lè máa fìgboyà wàásù.—Lúùkù 11:9-13.

6, 7. (a) Ìran wo ni Jèhófà fi han Ìsíkíẹ́lì, kí ló sì túmọ̀ sí? (b) Ẹ̀kọ́ wo làwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní lè rí kọ́ látinú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí yìí?

6 Ìwé Ìsíkíẹ́lì jẹ́ ká mọ nǹkan míì tó tún lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa fìgboyà wàásù. Nínú ìran kan tí Ìsíkíẹ́lì rí, Jèhófà fún un ní àkájọ ìwé kan tí a kọ̀wé sí tojú-tẹ̀yìn rẹ̀ pẹ̀lú “orin arò àti ìkédàárò àti ìpohùnréré ẹkún.” Jèhófà wá ní kó jẹ ìwé náà, ó sọ pé: “Ọmọ ènìyàn, mú kí ikùn rẹ jẹ ẹ́, kí o lè fi àkájọ ìwé yìí tí mo ń fi fún ọ kún ìfun rẹ.” Kí ni ìran yìí túmọ̀ sí? Ohun tó túmọ̀ sí ni pé Ìsíkíẹ́lì gbọ́dọ̀ mọ iṣẹ́ tó fẹ́ lọ jẹ́ fáwọn èèyàn ní àmọ̀dunjú. Ọ̀rọ̀ yẹn sì gbọ́dọ̀ di ara rẹ̀, ìyẹn ni pé kó wà nínú ọkàn rẹ̀. Wòlíì náà ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ẹ́, ó sì wá dà bí oyin ní ẹnu mi ní dídùn.” Ohun ìdùnnú ni kíkéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní gbangba jẹ́ fún Ìsíkíẹ́lì, ńṣe ló dùn bí oyin lẹ́nu rẹ̀. Àǹfààní ńlá ni Ìsíkíẹ́lì kà á sí láti máa ṣojú fún Jèhófà àti láti máa ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn tí kò ní fẹ́ gbọ́rọ̀ rẹ̀ ló fẹ́ jẹ́ iṣẹ́ tó lágbára yìí fún.—Ka Ìsíkíẹ́lì 2:8-3:4, 7-9.

7 Àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní lè kẹ́kọ̀ọ́ ṣíṣeyebíye látinú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí yìí. Àwa pẹ̀lú ní iṣẹ́ tó lágbára kan láti jẹ́ fáwọn èèyàn, àwọn táwa náà sì ń jíṣẹ́ ọ̀hún fún kì í sábà mọyì àwọn ìsapá tá à ń ṣe. Tá a bá fẹ́ máa bá a nìṣó láti máa wo iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe gẹ́gẹ́ bí àǹfààní ńlá tí Ọlọ́run fún wa, a gbọ́dọ̀ máa gba ìmọ̀ Ọlọ́run sínú. Ṣíṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ lóréfèé tàbí ní ìdákúrekú kò tó rárá tá a bá fẹ́ kí ìmọ̀ wa jinlẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ǹjẹ́ ohun kan wà tó o lè ṣe láti mú kí Bíbélì kíkà rẹ àti ìdákẹ́kọ̀ọ́ rẹ túbọ̀ máa ṣe déédéé kó sì nítumọ̀? Ǹjẹ́ o lè túbọ̀ máa ṣàṣàrò sí i lórí àwọn ohun tó ò ń kà?—Sm. 1:2, 3.

Bó Ó Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò Bíbélì

8. Báwo làwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run kan ṣe gbé ọ̀rọ̀ wọn kalẹ̀ tí wọ́n fi lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò Bíbélì nígbà tí wọ́n ń wàásù láti ilé dé ilé?

8 Ohun tó ṣòro jù fún ọ̀pọ̀ àkéde nínú iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé ni bí wọ́n ṣe máa bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú àwọn èèyàn. Òótọ́ ni pé láwọn ìpínlẹ̀ kan kì í rọrùn rárá láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. Táwọn akéde kan bá ń wàásù láti ilé dé ilé, ó máa ń rọrùn fún wọn láti bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn pẹ̀lú ọ̀rọ̀ díẹ̀ tí wọ́n ti fara balẹ̀ ṣàkójọ rẹ̀, lẹ́yìn náà wọ́n á wá fún ẹni tí wọ́n ń wàásù fún ní ìwé àṣàrò kúkúrú kan, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àpótí tó wà lójú ìwé yìí. Ó ṣeé ṣe kí àkọlé ìwé àṣàrò kúkúrú náà tàbí àwòrán rẹ̀ fa ẹni náà mọ́ra, èyí sì lè ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún wa láti sọ ìdí tá a fi wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ṣókí, ká sì bi í ní ìbéèrè kan. Ọ̀nà míì tá a tún lè gbà ṣe é ni pé ká fi oríṣi ìwé àṣàrò kúkúrú bíi mẹ́ta tàbí mẹ́rin han ẹni náà, ká wá sọ fún un pé kó mú èyí tó bá fà á mọ́ra jù lọ. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe pé ká kàn máa fún àwọn èèyàn ní ìwé àṣàrò kúkúrú tàbí ká máa fi lọ àwọn èèyàn ní gbogbo ilé tá a bá ti ń dé o, ṣùgbọ́n ohun tá à ń fẹ́ ni pé ká lò ó láti fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò tó máa yọrí sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

9. Kí nìdí tó fi dáa kéèyàn máa múra sílẹ̀ dáadáa kó tó lọ sóde ẹ̀rí?

9 Ọ̀nà yòówù kó o gbà gbé ọ̀rọ̀ rẹ kalẹ̀, tó o bá ti múra sílẹ̀ dáadáa, ọkàn rẹ yóò balẹ̀, wàá sì lè fìtara sọ̀rọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé. Arákùnrin kan tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sọ pé: “Mo máa ń láyọ̀ gan-an tí mo bá múra ọ̀rọ̀ ti mo fẹ́ sọ sílẹ̀ dáadáa. Ó ń jẹ́ kí n lè lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tí mo ti múra sílẹ̀.” Arákùnrin míì tóun náà jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sọ pé: “Tí mo bá mọ àwọn ohun tó wà nínú ìwé tí mo fẹ́ fi lọ àwọn èèyàn, ó máa ń jẹ́ kí n lè fìtara sọ̀rọ̀ nípa wọn.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àǹfààní kan wà nínú kéèyàn fi ọkàn ṣàtúnyẹ̀wò ohun tó fẹ́ sọ lóde ìwàásù, àmọ́ ọ̀pọ̀ akéde ti rí i pé ó ṣàǹfààní gan-an kéèyàn sọ̀rọ̀ sókè ketekete nígbà tó bá ń fi ohun tó fẹ́ sọ lóde ìwàásù dánra wò. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ń mú kí iṣẹ́ ìsìn wọn sí Jèhófà túbọ̀ dára sí i.—Kól. 3:23; 2 Tím. 2:15.

10. Kí lẹni tó ń darí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá lè ṣe láti mú kí ìpàdé náà gbéṣẹ́ kó sì ṣàǹfààní?

10 Tá a bá darí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá lọ́nà tá a jẹ́ káwọn ara mọ onírúurú ọ̀nà tí wọ́n a máa gbà wàásù fáwọn èèyàn, yóò mú ká túbọ̀ já fáfá sí i, yóò sì mú ká láyọ̀ bá a ti ń wàásù láti ilé dé ilé. Tó bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ìwàásù ni ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́ ọjọ́ náà dá lé, ẹ lè kà á kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀ ní ṣókí. Bákan náà, kí arákùnrin tó ń dárí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá fara balẹ̀ jíròrò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan tàbí kó ṣàṣefihàn èyí tó rọrùn tó sì bá ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn mu, tàbí kó sọ ọ̀rọ̀ míì tó wúlò táwọn ará lè lò lóde ẹ̀rí. Èyí á mú káwọn ará gbára dì láti wàásù lọ́nà tó máa wọ àwọn èèyàn lọ́kàn. Bóyá àwọn alàgbà tàbí àwọn míì ló ń dárí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá, tí wọ́n bá múra sílẹ̀ dáadáa, wọ́n á lè ṣe àwọn nǹkan tá a sọ yìí, láìjẹ́ pé wọ́n lo kọjá àkókò tó yẹ kí wọ́n lò.—Róòmù 12:8.

Àǹfààní Tó Wà Nínú Fífetísílẹ̀

11, 12. Báwo ni títẹ́tí sáwọn èèyàn tàánútàánú ṣe lè mú kí wọ́n fẹ́ gbọ́ ìhìn rere? Sọ àwọn àpẹẹrẹ kan.

11 Kì í ṣe mímúra ohun tá a máa báwọn èèyàn sọ sílẹ̀ nìkan ló máa mú ká lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò Bíbélì pẹ̀lú wọn kí ọ̀rọ̀ wa sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn, a tún ní láti fẹ́ràn àwọn tá à ń wàásù fún dénúdénú. Ọ̀nà kan tá a lè gbà fi hàn pé a fẹ́ràn àwọn tá à ń wàásù fún ni pé ká máa fetí sílẹ̀ tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀. Alábòójútó arìnrìn-àjò kan sọ pé: “Bó o bá ń fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn èèyàn, ìyẹn á mú kí wọ́n túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ tó ò ń sọ, ó sì tún jẹ́ ọ̀nà pàtàkì kan tó o fi lè jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o fẹ́ràn wọn dénúdénú.” Tá a bá ń tẹ́tí sáwọn èèyàn tàánútàánú, ó lè mú kí wọ́n fẹ́ láti máa gbọ́ ọ̀rọ̀ wa, gẹ́gẹ́ bí ìrírí tá a fẹ́ sọ yìí ṣe fi hàn.

12 Nínú lẹ́tà kan tó jáde nínú ìwé ìròyìn kan tó ń jẹ́ Le Progrès, tí wọ́n tẹ̀ nílùú Saint-Étienne nílẹ̀ Faransé, obìnrin kan sọ̀rọ̀ nípa ìbẹ̀wò táwọn obìnrin méjì kan ṣe sílé rẹ̀ kété lẹ́yìn tí ọmọbìnrin rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ oṣù mẹ́ta kú. Ó sọ pé: “Kíá ni mọ mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n. Ńṣe ni mo fẹ́ fọgbọ́n lé wọn dà nù, àmọ́ mo wá rí ìwé pẹlẹbẹ kan lọ́wọ́ wọn. Ọ̀rọ̀ nípa ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà ló wà níbẹ̀. Mo ní kí wọ́n wọlé pẹ̀lú èrò pé màá já wọn nírọ́ . . . Ó lé ní wákàtí kan táwọn Ẹlẹ́rìí náà lò lọ́dọ̀ mi. Tàánútàánú ni wọ́n fi tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo sọ, nígbà tí wọ́n sì ń lọ, mo rí i pé ara mi yá gan-an ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, débi pé mo ní kí wọ́n tún padà wá lọ́jọ́ mìíràn.” (Róòmù 12:15) Nígbà tó yá, obìnrin yìí gbà kí wọ́n máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹ̀kọ́ lohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn jẹ́ fún wa o. Kì í ṣohun táwọn arábìnrin yẹn sọ ni obìnrin yẹn rántí, àmọ́ bí wọ́n ṣe tẹ́tí sílẹ̀ ló gbàfiyèsí rẹ̀ jù lọ.

13. Báwo la ṣe lè sọ ìhìn rere náà lọ́nà tó máa bá ipò ẹni tá à ń wàásù fún mu?

13 Tá a bá ń tẹ́tí sáwọn èèyàn tàánútàánú, ńṣe là ń tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí wọ́n sọ ìdí tí wọ́n fi nílò Ìjọba Ọlọ́run. Èyí á sì mú kó rọrùn dáadáa fún wa láti wàásù ìhìn rere fún wọn. Ó ṣeé ṣe kó o ti ṣàkíyèsí pé àwọn oníwàásù tó máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn èèyàn ló sábà máa ń sọ̀rọ̀ lọ́nà táá fi wọ àwọn èèyàn lọ́kàn dáadáa. (Òwe 20:5) Wọ́n máa ń fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn táwọn ń wàásù fún jẹ àwọn lógún gan-an. Yàtọ̀ sí pé wọ́n máa ń ṣàkọsílẹ̀ orúkọ àti àdírẹ́sì àwọn tí wọ́n wàásù fún, wọ́n tún máa ń ṣàkọsílẹ̀ ohun tó ń jẹ àwọn tí wọ́n wàásù fún lọ́kàn àti ibi tí wọ́n ti nílò ìrànlọ́wọ́. Bí ẹni tí wọ́n wàásù fún bá sọ ìṣòro kan tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn, wọ́n máa ń ṣèwádìí nípa ìṣòro náà, wọn kì í sì í jẹ́ kó pẹ́ kí wọ́n tó lọ fún un lésì. Bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, wọ́n máa ń mú ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run bá ipò ẹni tí wọ́n ń wàásù fún mu. (Ka 1 Kọ́ríńtì 9:19-23.) Tá a bá ń fi hàn lọ́nà bẹ́ẹ̀ pé ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ wá lógún, èyí á mú káwọn èèyàn fẹ́ gbọ́ ìhìn rere, èyí á sì mú ká máa fi “ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti Ọlọ́run wa” hàn lọ́nà tó ga lọ́lá.—Lúùkù 1:78.

Ní Ẹ̀mí Tó Dára

14. Báwo la ṣe lè máa fi àwọn ànímọ́ Jèhófà hàn bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?

14 Jèhófà ka ẹnì kọ̀ọ̀kan wa sí, ìdí nìyẹn tó fi fún wa ní òmìnira láti yan ohun tó bá wù wá. Lóòótọ́, Ọlọ́run Olódùmarè ni Jèhófà, àmọ́ kò fipá mú ẹnikẹ́ni láti máa sin òun, ńṣe ló ń rọ àwọn èèyàn tìfẹ́tìfẹ́ láti wá sọ́dọ̀ òun. Ó sì ń bù kún àwọn tó bá mọyì àwọn ìpèsè àgbàyanu rẹ̀. (Róòmù 2:4) Nítorí pé òjíṣẹ́ Ọlọ́run la jẹ́, a gbọ́dọ̀ múra tán láti máa wàásù ìhìn rere náà lọ́nà tó máa buyì kún Ọlọ́run wa aláàánú ní gbogbo ìgbà tá a bá ń wàásù. (2 Kọ́r. 5:20, 21; 6:3-6) Láti lè ṣe èyí, a gbọ́dọ̀ ní èrò tó dára nípa gbogbo àwọn tó bá wà ní ìpínlẹ̀ tá a ti ń wàásù. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe èyí?

15. (a) Kí ni Jésù sọ pé káwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ṣe táwọn kan ò bá gbọ́ ìwàásù wọn? (b) Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti wá àwọn ẹni yíyẹ kàn?

15 Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé wọn ò gbọ́dọ̀ dààmú ju bó ṣe yẹ lọ táwọn kan ò bá gbọ́ ìwàásù wọn, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ni kí wọ́n gbájú mọ́ wíwa àwọn ẹni yíyẹ kàn. (Ka Mátíù 10:11-15.) Ohun tó máa jẹ́ káwa náà lè ṣe èyí ni pé ká fi àwọn ohun kan tọ́wọ́ wa lè tẹ̀ ṣe àfojúsùn wa. Arákùnrin kan fi ara rẹ̀ wé ẹni tó ń wa kùsà. Ọ̀rọ̀ tó fi ṣe atọ́nà rẹ̀ ni: “Mo mọ̀ pé màá walẹ̀ kan wúrà lónìí yìí.” Arákùnrin mìíràn sọ ohun tó fi ṣe àfojúsùn tiẹ̀, ó ní: “Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, mo fẹ́ máa wàásù fẹ́ni kan tó máa nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere nígbà àkọ́kọ́ tí mo bá wàásù fún un, kí n sì padà lọ bẹ onítọ̀hún wò láàárín ọjọ́ díẹ̀ láti mú kí ìfẹ́ tó ní sí òtítọ́ jinlẹ̀ sí i.” Ohun táwọn akéde kan ń lépa ni pé, ó kéré tán, àwọn á ka ẹsẹ Bíbélì kan fún ẹni tí wọ́n bá wàásù fún, tó bá ṣeé ṣe. Ǹjẹ́ ohun kan wà tí ìwọ̀ náà lè fi ṣe àfojúsùn rẹ?

16. Àwọn ìdí wo la ní tá a fi gbọ́dọ̀ máa bá a iṣẹ́ ìwàásù nìṣó?

16 Bá a ṣe ń wàásù fáwọn èèyàn láti ilé dé ilé ni ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, yálà wọn fetí sí wa tàbí wọn ò fetí sí wa, ìyẹn nìkan kọ́ lohun tó máa pinnu bóyá a ṣàṣeyọrí nídìí iṣẹ́ náà tàbí a ò ṣàṣeyọrí. Lóòótọ́, ipa pàtàkì ni iṣẹ́ ìwàásù ń kó nínú báwọn tó fẹ́ mọ òtítọ́ ṣe máa rí ìgbàlà, àmọ́ ó tún ń ṣiṣẹ́ fún àwọn ohun pàtàkì mìíràn. Iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni tá à ń ṣe ń fún wa láǹfààní láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (1 Jòh. 5:3) Ó ń mú ká bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. (Ìṣe 20:26, 27) À ń tipasẹ̀ ìwàásù ìhìn rere kìlọ̀ fáwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run pé “wákàtí ìdájọ́ láti ọwọ́ [Ọlọ́run] ti dé.” (Ìṣí. 14:6, 7) Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé, à ń tipasẹ̀ ìwàásù ìhìn rere yin orúkọ Jèhófà lógo kárí ayé. (Sm. 113:3) Nítorí náà, yálà àwọn èèyàn fetí sí wa tàbí wọn ò fetí sí wa, a gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti máa kéde Ìjọba Ọlọ́run. Ní tòótọ́, gbogbo ìsapá tá à ń ṣe láti máa kéde ìhìn rere ló lẹ́wà lójú Jèhófà.—Róòmù 10:13-15.

17. Kí làwọn èèyàn máa gbà tipátipá láìpẹ́?

17 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò fojú pàtàkì wo iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe lónìí, láìpẹ́ wọn yóò mọ ìdí tá a fi ń wàásù. (Mát. 24:37-39) Jèhófà fi dá Ìsíkíẹ́lì lójú pé nígbà táwọn ìdájọ́ tí Ìsíkíẹ́lì ń kéde bá ní ìmúṣẹ, ilé Ísírẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ yóò mọ̀ “dájú pé . . . wòlíì kan wà ní àárín wọn.” (Ìsík. 2:5) Bákan náà, nígbà tí Ọlọ́run bá mú ìdájọ́ rẹ̀ wá sórí ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí, àwọn èèyàn máa gbà tipátipá pé ọ̀dọ̀ Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́, ni ohun tá à ń wàásù rẹ̀ ní gbàǹgbà àti láti ilé dé ilé ti wá, wọ́n á sì gbà pé Ọlọ́run làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣojú fún lóòótọ́. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá la ní láti máa jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà tá a sì ń kéde ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní àkókò tó ṣe pàtàkì yìí! Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà fún wa lókun tá a fi lè máa borí ìṣòro lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Báwo la ṣe lè máyà le ká sì máa wàásù?

• Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò Bíbélì bá a ṣe ń wàásù láti ilé dé ilé?

• Báwo la ṣe lè fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ wá lógún?

• Kí ló lè mú ká ní ẹ̀mí tó dára nípa àwọn èèyàn ní ìpínlẹ̀ tá a ti ń wàásù?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ọ̀nà Tá A Lè Gbà Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò Bíbélì

O lè bẹ̀rẹ̀ báyìí:

◼ Lẹ́yìn tó o bá ti kí ẹni tó o fẹ́ wàásù fún, o lè fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú kan, kó o wá sọ pé: “Ìdí tí mo fi wá sọ́dọ̀ rẹ ni pé mo fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀ ìṣírí kan lórí kókó pàtàkì yìí.”

◼ Tàbí kẹ̀, o lè fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú kan, kó o wá sọ̀ pé: “Mo wá ṣèbẹ̀wò ráńpẹ́ sọ́dọ̀ rẹ, nítorí pé mo fẹ́ mọ èrò rẹ̀ lórí kókó yìí.”

Tẹ́ni náà bá gba ìwé àṣàrò kúkúrú náà:

◼ Láìjáfara, béèrè ìbéèrè kan látinú ìwé àṣàrò kúkúrú náà láti fi mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀.

◼ Fetí sílẹ̀ dáadáa bí ẹni náà ṣe ń sọ̀rọ̀, kó o rí i pé o lóye ohun tó jẹ́ èrò rẹ̀. Dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún ìdáhùn rẹ̀, kó o sì lo ohun tó bá sọ nínú ìjíròrò yín.

Tẹ́ ẹ bá fẹ́ máa bá ìjíròrò yín lọ:

◼ Ka ẹsẹ Bíbélì kan kó o sì ṣàlàyé rẹ̀, kó o jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ dá lórí ohun tó ń jẹ ẹni tó ò ń wàásù fún lọ́kàn, kó sì bá ipò rẹ̀ mu.

◼ Tí ẹni náà bá fi ìfẹ́ hàn sí ohun tó gbọ́, fi ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ ọ́, kó o sì fi bá a ṣe ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́ hàn án. Kẹ́ ẹ ṣàdéhùn ìgbà tó o máa padà wá.