Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tí Iṣẹ́ Ìwàásù Ilé-dé-Ilé Fi Ṣe Pàtàkì Nísinsìnyí?

Kí Nìdí Tí Iṣẹ́ Ìwàásù Ilé-dé-Ilé Fi Ṣe Pàtàkì Nísinsìnyí?

Kí Nìdí Tí Iṣẹ́ Ìwàásù Ilé-dé-Ilé Fi Ṣe Pàtàkì Nísinsìnyí?

“Ní ojoojúmọ́ nínú tẹ́ńpìlì àti láti ilé dé ilé ni wọ́n sì ń bá a lọ láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere nípa Kristi náà.”—ÌṢE 5:42.

1, 2. (a) Ọ̀nà ìwàásù wo làwọn èèyàn fi ń dá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

 ÀWỌN èèyàn méjì tí wọ́n múra dáadáa wọnú ilé kan, wọ́n fẹ́ sọ̀rọ̀ ṣókí nípa Ìjọba Ọlọ́run látinú Bíbélì fún ẹni tí wọ́n bá bá nílé. Tẹ́ni ọ̀hún bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ tó gbọ́, wọ́n á fún un ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n á sì sọ fún un pé àwọn á wá máa kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílé rẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́. Lẹ́yìn náà, wọ́n á lọ sí ilé kejì. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ibi gbogbo láyé lo ti máa rí àwọn èèyàn tó ń ṣe iṣẹ́ yìí. Tó bá jẹ́ pé ìwọ náà máa ń kópa nínú iṣẹ́ yìí, wàá rí i pé lọ́pọ̀ ìgbà kó o tiẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ rárá làwọn èèyàn ti máa ń mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́. Ká sòótọ́, níbi gbogbo láyé ni wọ́n ti mọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé.

2 Oríṣiríṣi ọ̀nà là ń gbà ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé lé wa lọ́wọ́, ìyẹn iṣẹ́ wíwàásù àti sísọni dọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:19, 20) A máa ń wàásù ní ọjà, ní òpópónà, àtàwọn ibòmíràn táwọn èèyàn wà. (Ìṣe 17:17) A máa ń wàásù fún ọ̀pọ̀ èèyàn nípasẹ̀ tẹlifóònù àti lẹ́tà. A máa ń sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn tá a bá bá pàdé lẹ́nu ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́. A tiẹ̀ tún ní ìkànnì lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, níbi tí èèyàn ti lè rí ìsọfúnni nípa ẹ̀kọ́ Bíbélì ní èyí tó ju ọ̀ọ́dúnrún [300] èdè lọ. a Gbogbo ọ̀nà tá à ń gbà wàásù yìí ti so èso rere. Síbẹ̀, níbi tó pọ̀ jù lọ, ọ̀nà pàtàkì tá à ń gbà sọ ìhìn rere fáwọn èèyàn jẹ́ nípa wíwàásù láti ilé dé ilé. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé irú ọ̀nà yìí là ń lò láti wàásù? Báwo ló ṣe wá di pé àwọn èèyàn Ọlọ́run ń lo ọ̀nà yìí gan-an lóde òní? Kí nìdí tó sì fi ṣe pàtàkì nísinsìnyí?

Ọ̀nà Táwọn Àpọ́sítélì Gbà Ṣe É

3. Ìtọ́ni wo ni Jésù fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ nípa iṣẹ́ ìwàásù, kí sì ni èyí fi hàn nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa wàásù?

3 Wíwàásù ìhìn rere láti ilé dé ilé jẹ́ ọ̀nà tí Ìwé Mímọ́ là kalẹ̀. Nígbà tí Jésù rán àwọn àpọ́sítélì láti lọ wàásù, ó fún wọn ní ìtọ́ni pé: “Ìlú ńlá tàbí abúlé èyíkéyìí tí ẹ bá wọ̀, ẹ wá ẹni yíyẹ inú rẹ̀ kàn.” Báwo ni wọ́n ṣe máa wá ẹni yíyẹ kàn? Jésù sọ fún wọn pé kí wọ́n lọ sí ilé àwọn èèyàn, ó ní: “Nígbà tí ẹ bá ń wọ ilé, ẹ kí agbo ilé náà; bí ilé náà bá sì yẹ, kí àlàáfíà tí ẹ fẹ́ fún un wá sórí rẹ̀.” Ṣé wọ́n á dúró dìgbà táwọn èèyàn bá pè wọ́n kí wọ́n tó lọ ni? Kíyè sí ohun tí Jésù sọ síwájú sí i, ó ní: “Ibi yòówù tí ẹnikẹ́ni kò bá ti gbà yín wọlé tàbí fetí sí ọ̀rọ̀ yín, nígbà tí ẹ bá ń jáde kúrò ní ilé yẹn tàbí ìlú ńlá yẹn, ẹ gbọn ekuru ẹsẹ̀ yín dànù.” (Mát. 10:11-14) Ìtọ́ni yìí mú kó ṣe kedere pé báwọn àpọ́sítélì ṣe ń “la ìpínlẹ̀ náà já láti abúlé dé abúlé, ní pípolongo ìhìn rere,” wọ́n ní láti máa lọ bá àwọn èèyàn nílé wọn.—Lúùkù 9:6.

4. Ibo ni Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé ní tààràtà?

4 Bíbélì sọ ní pàtó pé àwọn àpọ́sítélì wàásù láti ilé dé ilé. Bí àpẹẹrẹ, kété lẹ́yìn tí wọ́n dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀ ní ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Ìṣe 5:42 sọ nípa wọn pé: “Ní ojoojúmọ́ nínú tẹ́ńpìlì àti láti ilé dé ilé ni wọ́n sì ń bá a lọ láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere nípa Kristi náà, Jésù.” Ní nǹkan bí ogún ọdún lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán àwọn alàgbà ìjọ Éfésù létí pé: “Èmi kò . . . fà sẹ́yìn kúrò nínú sísọ èyíkéyìí lára àwọn ohun tí ó lérè nínú fún yín tàbí kúrò nínú kíkọ́ yín ní gbangba àti láti ilé dé ilé.” Ǹjẹ́ Pọ́ọ̀lù bẹ àwọn alàgbà yẹn wò kí wọ́n tó di onígbàgbọ́? Dájúdájú, ó ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé lára ohun tó kọ́ wọn ni “ìrònúpìwàdà sí Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ nínú Olúwa wa Jésù.” (Ìṣe 20:20, 21) Nígbà tí ìwé kan tó ń jẹ́ Word Pictures in the New Testament ti Robertson ń ṣàlàyé nípa Ìṣe 20:20, ó sọ pé: “Ohun kan tó gbàfiyèsí ni pé àgbà oníwàásù yìí wàásù láti ilé dé ilé.”

Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Eéṣú Ti Òde Òní

5. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì ṣe ṣàpèjúwe iṣẹ́ ìwàásù?

5 Iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n ṣe ní ọ̀rúndún kìíní jẹ́ àpẹẹrẹ iṣẹ́ ìwàásù tá a máa ṣe lóde òní lọ́nà tó gbòòrò ju tìgbà yẹn lọ. Wòlíì Jóẹ́lì fi iṣẹ́ ìwàásù táwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ń ṣe wé báwọn kòkòrò bí eéṣú ṣe máa ń jẹ nǹkan run. (Jóẹ́lì 1:4) Bí àwọn ọmọ ogun làwọn eéṣú ṣe máa ń tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́, wọ́n máa ń borí ìdènà, wọ́n máa ń wọnú ilé, wọ́n sì máa ń jẹ ohunkóhun tí wọ́n bá rí. (Ka Jóẹ́lì 2:2, 7-9.) Ẹ wo bí àpèjúwe yẹn ṣe bá ìfaradà àti ọ̀nà táwọn èèyàn Ọlọ́run gbà ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù lóde òní mu tó! Iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé ni ọ̀nà tó ṣe pàtàkì jù lọ táwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn tó jẹ́ “àgùntàn mìíràn” gbà ń mú àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ. (Jòh. 10:16) Báwo ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń lo ọ̀nà táwọn àpọ́sítélì gbà wàásù?

6. Lọ́dún 1922, ìṣírí wo la fún àwọn Kristẹni nípa iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé, kí làwọn kan sì ṣe?

6 Láti ọdún 1919 la ti ń tẹnu mọ́ bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé kí Kristẹni kọ̀ọ̀kan máa fúnra rẹ̀ wàásù. Bí àpẹẹrẹ, àpilẹ̀kọ kan tó sọ̀rọ̀ nípa bí iṣẹ́ ìsìn ṣe ṣe pàtàkì tó, èyí tó jáde nínú Ilé Ìṣọ́ ti August 15, 1922 lédè Gẹ̀ẹ́sì, rán àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró létí pé “mímú ìròyìn tá a tẹ̀ sórí ìwé lọ fáwọn èèyàn, bíbá wọn sọ̀rọ̀ nílé wọn, àti wíwàásù fún wọn pé ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé” ṣe pàtàkì gan-an. Ìtẹ̀jáde tó ń jẹ́ Bulletin (tá à ń pè ní Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa nísinsìnyí) ṣàlàyé lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ nípa ọ̀nà tá a lè gbà bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Síbẹ̀ náà, iye àwọn tó ń wàásù láti ilé dé ilé kéré nígbà yẹn. Àwọn kan ò fẹ́ láti wàásù. Oríṣiríṣi àwáwí ni wọ́n ń ṣe, àmọ́ ohun tó fa ìṣòro náà gan-an ni pé àwọn kan sọ pé ó bu àwọn kù láti máa wàásù láti ilé dé ilé. Bá a ṣe túbọ̀ ń tẹnu mọ́ ọn pé iṣẹ́ ìwàásù ṣe pàtàkì gan-an, ni ọ̀pọ̀ lára irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ń kúrò nínú ètò Jèhófà ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀.

7. Lọ́dún mélòó kan lẹ́yìn ọdún 1950, kí ló hàn gbangba pé a nílò?

7 Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àwọn èèyàn púpọ̀ sí i túbọ̀ ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù náà. Àmọ́, ó wá hàn gbangba pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn nílò ìdálẹ́kọ̀ọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún mélòó kan lẹ́yìn ọdún 1950 lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà yẹ̀ wò. Nígbà yẹn, nǹkan bí ọ̀kẹ́ méje ààbọ̀ [150,000] ni àwọn akéde tó wà lórílẹ̀-èdè náà, àmọ́ nǹkan bí ẹgbàá mọ́kànlélógún [42,000] lára wọn kò ṣe ju kí wọ́n pín ìwé ìléwọ́ tàbí kí wọ́n dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà láti máa fún àwọn èèyàn ní ìwé ìròyìn. Àwọn akéde tó lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́ta [60,000] ni kò ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà déédéé, tí ọ̀pọ̀ oṣù kọjá tí wọn ò wàásù rárá. Kí la lè ṣe láti ṣèrànwọ́ fún gbogbo Kristẹni tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ kí wọ́n bàa lè máa wàásù láti ilé dé ilé?

8, 9. Ètò ìdálẹ́kọ̀ọ́ wo la bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1953, kí ló sì yọrí sí?

8 A tẹnu mọ́ iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé gan-an nígbà àpéjọ àgbáyé tó wáyé ní ìlú New York lọ́dún 1953. Arákùnrin Nathan H. Knorr tó ń bójú tó iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé nígbà yẹn sọ pé, olórí iṣẹ́ àwọn alábòójútó inú ìjọ ni pé kí wọ́n ran Kristẹni kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ láti máa wàásù déédéé láti ilé dé ilé. Ó sọ pé: “Kristẹni kọ̀ọ̀kan ní láti máa wàásù ìhìn rere láti ilé dé ilé.” Kí èyí lè ṣeé ṣe, a bẹ̀rẹ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé. A dá àwọn tí kò tíì máa wàásù láti ilé dé ilé lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè mọ bí wọ́n ṣe máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, kí wọ́n lè máa báwọn èèyàn fèrò-wérò látinú Bíbélì kí wọ́n sì máa dáhùn àwọn ìbéèrè wọn.

9 Ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí méso rere jáde. Láàárín ọdún mẹ́wàá, iye àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run pọ̀ sí i ní ìlọ́po méjì, iye àwọn tí wọ́n padà lọ bẹ̀ wò lé ní ìlọ́po méjì, iye àwọn tó sì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jẹ́ ìlọ́po méjì àtààbọ̀. Ní báyìí, iye àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run tó ń wàásù ìhìn rere náà kárí ayé ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù méje. Ìdàgbàsókè tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń bù kún àwa èèyàn rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé.—Aísá. 60:22.

Fífi Àmì Sórí Àwọn Èèyàn fún Ìgbàlà

10, 11. (a) Ìran wo ni Ìsíkíẹ́lì rí gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú Ìsíkíẹ́lì orí kẹsàn-án? (b) Báwo ni ìran yẹn ṣe ń ní ìmúṣẹ lóde òní?

10 Ìran tí wòlíì Ìsíkíẹ́lì rí jẹ́ ká mọ bí iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé ti ṣe pàtàkì tó. Nínú ìran náà, Ìsíkíẹ́lì rí ọkùnrin mẹ́fà tí wọ́n mú ohun ìjà dání, ó tún rí ọkùnrin keje tó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ tó sì ní ìwo yíǹkì akọ̀wé ní ìgbáròkó rẹ̀. Ọlọ́run sọ fún ọkùnrin keje yẹn pé kó “la àárín ìlú ńlá náà já” kó sì “sàmì sí iwájú orí àwọn ènìyàn tí ń mí ìmí ẹ̀dùn, tí wọ́n sì ń kérora nítorí gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí tí a ń ṣe ní àárín rẹ̀.” Lẹ́yìn tí iṣẹ́ ìsàmì náà ti parí, Ọlọ́run sọ fún àwọn ọkùnrin mẹ́fà tí wọ́n ní ohun ìjà lọ́wọ́ pé kí wọ́n pa àwọn tí kò ní àmì níwájú orí wọn run.—Ka Ìsíkíẹ́lì 9:1-6.

11 A lóye pé nínú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn, ọkùnrin tó “wọ aṣọ ọ̀gbọ̀” yẹn dúró fún ìyókù àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. Ẹgbẹ́ àwọn ẹni àmì òróró náà ń tipasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù fi àmì ìṣàpẹẹrẹ síwájú orí àwọn tó di ara “àgùntàn mìíràn” ti Kristi. (Jòh. 10:16) Kí ni àmì náà? Ẹ̀rí ni àmì náà jẹ́, bíi pé a kọ ọ́ síwájú orí wọn, pé irú àwọn ẹni bí àgùntàn bẹ́ẹ̀ ti ṣe ìyàsímímọ́, wọ́n sì ti ṣèrìbọmi láti fi hàn pé ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi ni àwọn, àti pé wọ́n ti gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, wọ́n sì ti fìwà jọ Kristi. (Éfé. 4:20-24) Àwọn ẹni bí àgùntàn wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró di agbo kan, wọ́n sì ń ran àwọn ẹni àmì òróró lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ pàtàkì ti sísàmì sórí àwọn èèyàn púpọ̀ sí i.—Ìṣí. 22:17.

12. Báwo ni ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí nípa sísàmì síwájú orí àwọn èèyàn ṣe jẹ́ ká mọ bí iṣẹ́ wíwá àwọn ẹni bí àgùntàn rí ti ṣe pàtàkì tó?

12 Ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí jẹ́ ká mọ ìdí pàtàkì kan tí wíwá tá à ń wá “àwọn ènìyàn tí ń mí ìmí ẹ̀dùn, tí wọ́n sì ń kérora” kiri fi jẹ́ ọ̀ràn kánjúkánjú tó bẹ́ẹ̀. Ìdí náà ni pé ẹ̀mí àwọn èèyàn wà nínú ewu. Láìpẹ́, àwọn ọmọ ogun ọ̀run tí Jèhófà yóò lò láti mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ, ìyẹn àwọn ọkùnrin mẹ́fà tó ní ohun ìjà lọ́wọ́, yóò pa àwọn tí kò ní àmì ìṣàpẹẹrẹ náà níwájú orí wọn run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ìdájọ́ tó ń bọ̀ yẹn, ó sọ pé Jésù Olúwa àti “àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára” yóò “mú ẹ̀san wá sórí àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa.” (2 Tẹs. 1:7, 8) Kíyè sí i pé ohun tí Jésù máa fi ṣèdájọ́ àwọn èèyàn ni bí wọ́n ṣe tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà sí. Nítorí náà, kíkéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn gbọ́dọ̀ máa bá a lọ láìdáwọ́ dúró títí dé òpin. (Ìṣí. 14:6, 7) Èyí sì fi hàn pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ ní ojúṣe pàtàkì kan láti ṣe.—Ka Ìsíkíẹ́lì 3:17-19.

13. (a) Ojúṣe pàtàkì wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní, kí sì nìdí? (b) Kí lo gbọ́dọ̀ ṣe láti ran àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ rẹ lọ́wọ́?

13 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ojúṣe pàtàkì ni iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn jẹ́ fóun. Ó sọ pé: “Èmi jẹ́ ajigbèsè sí àwọn Gíríìkì àti àwọn Aláìgbédè, sí àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn òpònú: nítorí náà, ìháragàgà wà ní ìhà ọ̀dọ̀ mi láti polongo ìhìn rere pẹ̀lú fún ẹ̀yin tí ẹ wà ní Róòmù.” (Róòmù 1:14, 15) Nítorí Pọ́ọ̀lù mọyì àánú tí Ọlọ́run fi hàn sí i, ó rí i pé ó di dandan kóun ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè jàǹfààní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tóun náà ti jàǹfààní rẹ̀. (1 Tím. 1:12-16) Ńṣe ló dà bíi pé ó jẹ ẹnikẹ́ni tó bá ti bá pàdé ní gbèsè, tó jẹ́ pé kìkì sísọ ìhìn rere fún wọn ló fi lè san gbèsè náà. Ǹjẹ́ ó máa ń ṣe ìwọ náà bíi pé o jẹ́ àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ rẹ ní irú gbèsè yẹn?— Ìṣe 20:26, 27.

14. Kí nìdí tó ṣe pàtàkì jù lọ tá a fi ń wàásù ní gbangba àti láti ilé dé ilé?

14 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbígba ẹ̀mí àwọn èèyàn là ṣe pàtàkì, ohun kan wà tó ṣe pàtàkì gan-an jùyẹn lọ, èyí tá à ń torí ẹ̀ wàásù láti ilé dé ilé. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Málákì 1:11, Jèhófà sọ pé: “Nítorí láti yíyọ oòrùn àní dé wíwọ̀ rẹ̀, orúkọ mi yóò tóbi láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, . . . a óò mú ọrẹ wá fún orúkọ mi, àní ẹ̀bùn tí ó mọ́; nítorí pé orúkọ mi yóò tóbi láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.” Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ ń mú àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ nípa yíyin orúkọ rẹ̀ ní gbogbo ayé bí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ìwàásù náà tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀. (Sm. 109:30; Mát. 24:14) Rírú “ẹbọ ìyìn” sí Jèhófà ni ìdí tó ṣe pàtàkì jù lọ tá a fi ń wàásù ní gbangba àti láti ilé dé ilé.—Héb. 13:15.

Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Gbankọgbì Ń Bọ̀ Lọ́nà

15. (a) Báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe túbọ̀ mú iṣẹ́ wọn pọ̀ sí i lọ́jọ́ keje tí wọ́n yan yí ìlú Jẹ́ríkò ká? (b) Kí lèyí fi hàn nípa bí iṣẹ́ ìwàásù wa ṣe máa rí?

15 Àwọn nǹkan wo la ṣì máa ṣe nínú iṣẹ́ ìwàásù lọ́jọ́ iwájú? Ohun tó wà nínú ìwé Jóṣúà nípa bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe sàga ti ìlú Jẹ́ríkò yóò jẹ́ ká mọ èyí. Rántí pé nígbà tó kù díẹ̀ kí Ọlọ́run pa ìlú Jẹ́ríkò run, ó sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n yan yí ìlú náà ká lẹ́ẹ̀kan lóòjọ́ fún ọjọ́ mẹ́fà. Àmọ́ ní ọjọ́ keje, iṣẹ́ wọ́n túbọ̀ pọ̀ gidigidi. Jèhófà sọ fún Jóṣúà pé: “Kí ẹ yan yí ìlú ńlá náà ká ní ìgbà méje, kí àwọn àlùfáà sì fun àwọn ìwo náà. Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí wọ́n bá fun ìwo àgbò náà, . . . kí gbogbo ènìyàn kígbe ogun ńlá; ògiri ìlú ńlá náà yóò sì wó lulẹ̀ bẹẹrẹbẹ.” (Jóṣ. 6:2-5) Ó ṣeé ṣé kó jẹ́ pé a óò túbọ̀ ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù wa nírú ọ̀nà tó jọ ìyẹn. Ó dájú pé nígbà tó bá máa fi dìgbà ìparun ètò àwọn nǹkan yìí, a óò ti wàásù lọ́nà tó kàmàmà nípa orúkọ Ọlọ́run àti Ìjọba rẹ̀ lọ́nà tá ò rírú rẹ̀ rí láyé yìí.

16, 17. (a) Àwọn nǹkan wo ló máa ṣẹlẹ̀ kí “ìpọ́njú ńlá” tó parí? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí?

16 Àkókò kan ń bọ̀ tí iṣẹ́ tá à ń jẹ́ yóò dà bí ‘igbe ogun ńlá.’ Nínú ìwé Ìṣípayá, a fi àwọn ìhìn ìdájọ́ náà wé “yìnyín ńláǹlà, tí òkúta rẹ̀ kọ̀ọ̀kan fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìwọ̀n tálẹ́ńtì.” b Ìdí nìyẹn tí Ìṣípayá 16:21 fi sọ pé: “Ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀ pọ̀ lọ́nà kíkàmàmà.” A ò tíì mọ ipa tí iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé máa kó nínú kíkéde apá tó kẹ́yìn nínú ìdájọ́ Ọlọ́run. Àmọ́, ó dájú pé kí “ìpọ́njú ńlá” tó parí, a óò ti sọ orúkọ Jèhófà di mímọ̀ lọ́nà tá ò rírú rẹ̀ rí.—Ìṣí. 7:14; Ìsík. 38:23.

17 Bá a ti ń dúró de àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì tó ń bọ̀ lọ́nà, kí gbogbo wa máa bá a lọ láti máa sọ ìhìn rere Ìjọba náà fáwọn èèyàn. Àwọn ìṣòro wo là ń rí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé tá à ń ṣe, báwo la sì ṣe lè borí àwọn ìṣòro náà? A óò dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ni www.watchtower.org.

b Tó bá jẹ́ pé ìwọ̀n tálẹ́ńtì kan ti ilẹ̀ Gíríìsì là ń sọ nípa rẹ̀, tálẹ́ńtì kan á fẹ́rẹ̀ẹ́ wúwo tó ìdajì àpò sìmẹ́ǹtì.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Ẹ̀rí wo ló wà nínú Ìwé Mímọ́ tó fi hàn pé a ní láti máa wàásù láti ilé dé ilé?

• Báwo la ṣe tẹnu mọ́ iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé lóde òní?

• Kí nìdí tí iṣẹ́ wíwàásù fi jẹ́ ojúṣe pàtàkì fún àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti ya ara wọn sí mímọ́?

• Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì wo ló ń bọ̀ lọ́nà?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Ṣéwọ náà gbà pé ojúṣe pàtàkì ni iṣẹ́ wíwàásù fáwọn èèyàn jẹ́ fún ọ bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Arákùnrin Knorr rèé, lọ́dún 1953