Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Láti Lè Máa Láyọ̀, Ohun Tọ́wọ́ Rẹ Lè Tẹ̀ Ni Kó O Fi Ṣe Àfojúsùn Rẹ

Láti Lè Máa Láyọ̀, Ohun Tọ́wọ́ Rẹ Lè Tẹ̀ Ni Kó O Fi Ṣe Àfojúsùn Rẹ

Láti Lè Máa Láyọ̀, Ohun Tọ́wọ́ Rẹ Lè Tẹ̀ Ni Kó O Fi Ṣe Àfojúsùn Rẹ

“KÒ TÚN bọ́ sí i lọ́tẹ̀ yìí!” Ó ti tó ìgbà mélòó tó o ti sọ irú ọ̀rọ̀ báyìí torí pé kò ṣeé ṣe fún ọ láti ṣohun kan tó o ní lọ́kàn láti ṣe? Abiyamọ Kristẹni kan tó ṣì kéré lọ́jọ́ orí lè sọ irú gbólóhùn yìí torí wàhálà àtitọ́jú ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí tó mú kí gbogbo nǹkan tojú sú u. Ó lè jẹ́ pé ìtọ́jú ọmọ náà máa ń gba gbogbo àkókò rẹ̀ débi pé kì í ráyè tó fún ìjọsìn rẹ̀ àtàwọn ìgbòkègbodò Kristẹni. Arákùnrin míì lè máa rò pé torí bí wọ́n ṣe tọ́ òun dàgbà, òun ò lè débi tó yẹ kóun dé, kódà òun ò ṣe tó bó ṣe yẹ kóun máa ṣe nínú ìjọ. Ó lè máa dun arábìnrin kan tó ti dàgbà torí bí kò ṣe lè máa kópa tó bó ṣe fẹ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò ìjọ bíi tìgbà kan tó lágbára láti sá sókè sá sódò, tó sì máa ń gbádùn rẹ̀. Bí ipò nǹkan ṣe rí nínú ìdílé Arábìnrin Christiane kò jẹ́ kó lè ṣe tó bó ṣe fẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ó sọ pé: “Nígbà míì tí wọ́n bá kàn sọ àsọyé kan láti rọ àwọn ará pé kí wọ́n ṣe aṣáájú-ọ̀nà, ṣe ni omijé máa ń bọ́ lójú mi.”

Kí la lè ṣe bó bá ń ṣe àwa náà bẹ́ẹ̀? Kí làwọn Kristẹni kan ti ṣe tó fi ṣeé ṣe fún wọn láti ní èrò tó tọ́ nípa ipò wọn? Àwọn àǹfààní wo ló wà nínú kéèyàn fohun tó mọ̀ pé kò kọjá agbára òun ṣe àfojúsùn rẹ̀?

Ṣe Bó O Ti Mọ

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ohun kan tá a lè máa ṣe tí ayọ̀ wa ò fi ní bà jẹ́, ó sọ pé: “Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo nínú Olúwa. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ṣe ni èmi yóò wí pé, Ẹ máa yọ̀! Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.” (Fílí. 4:4, 5) Tá a bá fẹ́ láyọ̀, ká sì ní ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run, a ní láti máa lo òye ká bàa lè mọ ohun tó bọ́gbọ́n mu fún wa láti máa lépa níbàámu pẹ̀lú ipò tá a wà. Ńṣe la kàn máa ki ọrùn ara wa bọ wàhálà tá a bá lọ ń forí ṣe fọrùn ṣe, láìro ohun tó lè ná wa, nítorí kọ́wọ́ wa lè tẹ ohun tá a fi ṣe àfojúsùn tí kò yẹ ká máa lé nínú ipò tá a wà. Àmọ́ ṣá o, a gbọ́dọ̀ tún ṣọ́ra ká má lọ máa fọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú ọ̀ràn wa, ká wá máa fi ohun tá a rò pé ó jẹ́ ìṣòro wa kẹ́wọ́, ká wá máa dẹwọ́ ju bó ṣe yẹ lọ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni.

Láìka ipò èyíkéyìí tá a lè wà sí, Jèhófà retí pé ká máa fún òun ní gbogbo ohun tágbára wa gbé, ìyẹn sì ni iṣẹ́ ìsìn tá à ń ṣe tọkàntọkàn. (Kól. 3:23, 24) Ṣùgbọ́n bí agbára wa bá gbé ju ohun tá à ń fún Jèhófà, a kò mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa ṣẹ nìyẹn. (Róòmù 12:1) Yàtọ̀ síyẹn, ọkàn wa ò ní balẹ̀, a ò sì ní láyọ̀ tòótọ́ àtàwọn ìbùkún jìngbìnnì míì tó ń wá látinú sísin Ọlọ́run tọkàntọkàn.—Òwe 10:22.

Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ tá a túmọ̀ sí “fòye báni lò” ní èrò pé kéèyàn máa gba tẹlòmíràn àti tara rẹ̀ rò. Ìtumọ̀ rẹ̀ ní tààràtà ni “jíjuwọ́sílẹ̀.” Ọ̀rọ̀ yẹn tún túmọ̀ sí pé kéèyàn má le koko jù. Nítorí náà, tá a bá jẹ́ afòyebánilò, a ó máa fojú tó tọ́ wo ipò wa. Àbí ìyẹn ṣòro láti ṣe? Ó ṣòro fáwọn kan láti máa fojú tó tọ́ wo ipò wọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè jẹ́ ẹni tó ń fòye bá àwọn èèyàn lò. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé à ń rí àmì pé iṣẹ́ àṣekúdórógbó tí ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́ kan ń ṣe lè dá àárẹ̀ sí i lára lọ́jọ́ kan, ǹjẹ́ a ò ní fẹ́ láti ràn án lọ́wọ́ kó lè mọ̀ pé ó máa ṣe é láǹfààní tó bá fètò sí bó ṣe ń gbé ìgbésí ayé rẹ̀? Lọ́nà kan náà, tá a bá ń rí àmì tó ń sọ fún wa pé a ti ń ṣe ju agbára wa lọ, ó yẹ káwa náà mọ̀ ọ́n.—Òwe 11:17.

Tó bá jẹ́ pé àwọn òbí tó ṣòroó tẹ́ lọ́rùn ló tọ́ wa dàgbà, ó lè ṣòro láti mọ ohun tó bọ́gbọ́n mu fún wa láti máa lé tí kò ní kọjá agbára wa. Nígbà táwọn kan wà lọ́mọdé, wọ́n gbà pé kò sóhun táwọn ṣe kò sì sí ìwà táwọn hù tó lè mú kínú òbí àwọn dùn sáwọn. Tó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ táwa náà ṣe jẹ́ nìyẹn, a lè ní èrò tí kò tọ́ nípa irú ojú tí Jèhófà fi ń wò wá. Inú Jèhófà dùn sí bá a ṣe ń fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú un dá wa lójú pé Jèhófà “mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé ekuru ni wá.” (Sm. 103:14) Ó mọ ibi tágbára wa mọ, inú rẹ̀ sì máa ń dùn sí wa tá a bá ń fi ìtara sìn ín láìka ohun tó ń dí wa lọ́wọ́ sí. Tá a bá ń rántí pé Ọlọ́run wa kì í ṣe ọ̀gá iṣẹ́ tó ṣòroó tẹ́ lọ́rùn, yóò ràn wá lọ́wọ́ láti má máa ṣe ju agbára wa lọ.—Míkà 6:8.

Síbẹ̀, ó ṣì ṣòro fáwọn kan láti ní irú èrò tó tọ́ bẹ́ẹ̀. Tó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ tiẹ̀ náà ṣe rí nìyẹn, ńṣe ni kó o lọ sọ́dọ̀ Kristẹni kan tó nírìírí tó sì mọ̀ ẹ́ dáadáa pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Òwe 27:9) Bí àpẹẹrẹ, ṣó wù ọ́ láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé ni? Ìyẹn mà dára gan-an o! Àbí ó ṣòro fún ẹ láti lé e bá? Bóyá o sì nílò ìrànlọ́wọ́ láti lè mú kí ìgbésí ayé rẹ wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. O lè fọ̀rọ̀ ẹ lọ ọ̀rẹ́ rẹ kan tó jẹ́ Kristẹni, kẹ́ ẹ jọ jíròrò rẹ̀ bóyá ó bọ́gbọ́n mu fún ẹ kó o máa lépa àtidi aṣáájú-ọ̀nà déédéé nísinsìnyí pẹ̀lú ọ̀pọ̀ bùkátà tó ò ń gbé nínú ìdílé. Ìjíròrò pẹ̀lú arákùnrin tàbí arábìnrin náà lè jẹ́ kó o mọ̀ bóyá apá rẹ á ká àfikún iṣẹ́ tó rọ̀ mọ́ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tàbí bóyá ńṣe ni wàá ṣe àwọn ìyípadà kan tó máa jẹ́ kó o lè ṣe púpọ̀ sí i. Ọkọ sì tún lè ran aya rẹ̀ lọ́wọ́ láti jẹ́ kó mọ bá a ṣe máa ṣohun tágbára rẹ̀ ká. Bí àpẹẹrẹ, ọkọ lè dá a lábàá fún ìyàwó rẹ̀ pé kó sinmi dáadáa kó tó di ìbẹ̀rẹ̀ oṣù tó máa fi kún iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Èyí lè jẹ́ kó túbọ̀ ní agbára tá a fi ṣe é, kó sì jẹ́ kó máa láyọ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀.

Wàá Rí Àwọn Ohun Tọ́wọ́ Rẹ Lè Tẹ̀

Ọjọ́ ogbó tàbí ara tí kò jí pépé lè má jẹ́ ká lè ṣe ohun tó pọ̀ mọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Tó o bá jẹ́ òbí, ó lè máa ṣe ọ́ bíi pé o kì í fi bẹ́ẹ̀ gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ ara ẹni tàbí ìpàdé ìjọ nítorí pé èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò rẹ àti agbára rẹ ló ń lò lórí àwọn ọmọ rẹ kéékèèké. Àmọ́, ṣé kì í ṣe pé ọ̀rọ̀ ohun tọ́wọ́ rẹ ò lè tẹ̀ tó gbà ọ́ lọ́kàn yìí ti ń ṣàkóbá fún ọ nígbà míì, débi pé o kì í rí àwọn ohun tọ́wọ́ rẹ lè tẹ̀?

Ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn, ọmọ Léfì kan sọ pé nǹkan kan wu òun, àmọ́ ọwọ́ rẹ̀ kó tẹ nǹkan ọ̀hún. Ó láǹfààní àrà ọ̀tọ̀ láti máa sìn nínú tẹ́ńpìlì fún ọ̀sẹ̀ méjì méjì lọ́dọọdún. Àmọ́, ó sọ bó ṣe wu òun tó láti máa sìn títí láé lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ, ohun tó wù ú yẹn sì dára gan-an ni. (Sm. 84:1-3) Kí ló jẹ́ kí ọkunrin adúróṣinṣin yìí lè nítẹ̀lọ́rùn? Ó mọ̀ pé àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ ni pé kéèyàn lo kódà ọjọ́ kan péré nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì. (Sm. 84:4, 5, 10) Bákan náà, dípò tá a ó fi wá máa ronú ṣáá lórí àwọn ohun tọ́wọ́ wa ò lè tẹ̀, ẹ jẹ́ ká gbìyànjú láti fòye mọ àwọn ohun tọ́wọ́ wa lè tẹ̀, ká sì mọrírì rẹ̀.

Wo àpẹẹrẹ arábìnrin kan tó ń jẹ́ Nerlande lórílẹ̀-èdè Kánádà. Orí àga àwọn aláàbọ̀ ara ló ń jókòó sí báyìí, èyí sì jẹ́ kó máa rò pé òun ò lè ṣe púpọ̀ mọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù. Ṣùgbọ́n ó tún èrò yẹn ṣe nígbà tó rí i pé òun lè sọ ilé ìtajà ńlá kan tó wà nítòsí di ìpínlẹ̀ ìwàásù tòun. Arábìnrin náà sọ pé: “Mo máa ń jókòó sórí àga mi lẹ́gbẹ̀ẹ́ bẹ́ǹṣì kan tí wọ́n gbé sínú ilé ìtajà náà. Mò ń láyọ̀ bí mo ṣe ń wàásù fáwọn èèyàn tí wọ́n bá wá jókòó tí wọ́n ń sinmi.” Bí Nerlande ṣe ń wàásù lọ́nà pàtàkì yìí mú kó nítẹ̀ẹ́lọ́rùn púpọ̀.

Ṣe Àtúnṣe Tó Bá Yẹ

Ọkọ̀ ojú omi kan lè máa bá eré tó ń sá lọ lórí omi, bí ẹ̀fúùfù ṣe ń fẹ́ lu ìgbòkun rẹ̀. Àmọ́, tí atukọ̀ náà bá débi tí ìjì líle ti ń jà lórí omi, ó di dandan fún un láti tún ìgbòkun ọkọ̀ yẹn ṣe. Atukọ̀ náà ò lágbára lórí ìjì, àmọ́ bó ṣe ń ṣàtúnṣe sáwọn ìgbòkun ọkọ̀ náà yóò jẹ́ kó lè máa darí ọkọ̀ rẹ̀ nìṣó. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwa náà kì í lágbára lórí àwọn ìṣòro ìgbésí ayé tó dà bí ìjì líle tó ń bá wa fínra. Àmọ́ a lè darí ìgbésí ayé wa dé ìwọ̀n tó bá ṣeé ṣe tá a bá ṣàtúnṣe sí bá a ṣe ń lo okun wa, tá ò kó ohun tó kọjá agbára wa lé ọkàn, tá ò jẹ́ kí inú wa bà jẹ́ torí ohun tọ́wọ́ wa ò lè tẹ̀. Tá a bá ń fi ipò tá a wà nísinsìnyí sọ́kàn nínú gbogbo ohun tá à ń ṣe, a óò máa ní ìbàlẹ̀ ọkàn, ayọ̀ tá à ń rí nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run kò sì ní bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́.—Òwe 11:2.

Jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀. Bá ò bá fi bẹ́ẹ̀ lágbára mọ́, á dáa tá a bá ń ṣọ́ra láti má ṣe àwọn ohun tó máa tán wa lókun kó tó di àkókò ìpàdé, ká lè lágbára láti lọ sípàdé lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́. Èyí á jẹ́ ká lè gbádùn ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Tí abiyamọ kan kò bá sì lè kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé torí ara ọmọ rẹ̀ tí kò yá, ó lè ké sí arábìnrin kan pé kó wá darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀ kan nílé òun nígbà tọ́mọ náà bá ń sùn lọ́wọ́.

Ká wá sọ pé ipò rẹ ò jẹ́ kó o lè múra gbogbo ohun tá a máa jíròrò nípàdé sílẹ̀ ńkọ́? O lè pinnu ìwọ̀n tó o lè múra sílẹ̀ nínú rẹ̀, kó o sì rí i dájú pé o múra rẹ̀ sílẹ̀. A óò máa tẹ̀ síwájú, a ó sì máa láyọ̀, bá a bá ń tún èrò wa pa lórí àwọn ohun tá a fi ṣe àfojúsùn wa ní lọ́wọ́lọ́wọ́.

Ó lè gba ìsapá ká tó lè yí àfojúsùn wa padà, ó sì lè gba pé ká ṣe ìpinnu kan gbòógì. Wo àpẹẹrẹ tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Serge àti Agnès, orílẹ̀-èdè Faransé ni wọ́n ń gbé. Ohun kan ṣẹlẹ̀ tó mú kó di dandan fún wọn láti ṣe ìyípadà ńlá kan lórí ohun tí wọ́n ti ní lọ́kàn tẹ́lẹ̀. Arákùnrin Serge sọ pé: “Gbàrà tá a mọ̀ pé Agnès ìyàwó mi ti lóyún la ti mọ̀ pé kò ní lè ṣeé ṣe fún wa mọ́ láti di míṣọ́nnárì.” Ní báyìí, aya Serge ti bí ọmọbìnrin méjì tó ń ta pọ́n-ún pọ́n-ún. Serge wá sọ bóun àti ìyàwó rẹ̀ ṣe gbé àfojúsùn míì kalẹ̀, ó ní: “Bá a ṣe rí i pé a ò lè lọ sìn ní orílẹ̀-èdè míì gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì mọ́, a pinnu láti máa ṣiṣẹ́ tó jọ iṣẹ́ míṣọ́nnárì lórílẹ̀-èdè wa. A dara pọ̀ mọ́ ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè.” Ǹjẹ́ wọ́n jàǹfààní látinú ohun tí wọ́n fi ṣe àfojúsùn wọn tuntun yìí? Serge sọ pé: “A rí i pé a wúlò gan-an nínú ìjọ yẹn.”

Àpẹẹrẹ mìíràn ni ti Arábìnrin Odile, tó ń gbé nílẹ̀ Faransé, ó ti lé ní àádọ́rin ọdún. Làkúrègbé tó ń sọ egungun di hẹ́gẹhẹ̀gẹ mú un ní orúnkún, èyí ló sì fà á tí kò fi lè wà lórí ìdúró fún àkókò gígùn. Ó máa ń dùn ún pé àìlera rẹ̀ yìí kò jẹ́ kó lè máa lọ ṣe iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé. Síbẹ̀ kò juwọ́ sílẹ̀. Àtúnṣe tó ṣe ni pé ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi tẹlifóònù wàásù. Ó sọ pé: “Ó rọrùn, mo sì gbádùn rẹ̀ gan-an ni. Mi ò mọ̀ pé bó ṣe máa rí nìyẹn!” Ọ̀nà tó gbà ń wàásù yìí mú kí iṣẹ́ ìwàásù tún padà máa wù ú láti ṣe.

Àǹfààní Wà Nínú Ṣíṣe Ohun Tágbára Wa Ká

Níní èrò tó tọ́ nípa ohun tá a lè ṣe kò ní jẹ́ kí ọkàn wa máa dà rú. Ọkàn wa máa balẹ̀ pé a ṣe àṣeyọrí láìka àwọn ìṣòro wa sí tá a bá ń lépa ohun tí kò kọjá agbára wa. Èyí á sì mú kí inú wa máa dùn lórí ohun tá a lè ṣe, kódà kó jẹ́ pé ohun kékeré ni.—Gál. 6:4.

A óò túbọ̀ dẹni tó ń gba táwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni rò, tá ò bá lérò àtiṣe kọjá agbára wa. A ó máa mọrírì ohun tí wọ́n bá ṣe fún wa torí pé a mọ ibi tí agbára wọn mọ. Bá a ṣe ń fi ìmọrírì hàn fún ìrànlọ́wọ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá ṣe fún wa, ńṣe là ń fi kún ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti ìgbọ́-ara-ẹni-yé. (1 Pét. 3:8) Má sì gbàgbé pé gẹ́gẹ́ bíi Baba onífẹ̀ẹ́, Jèhófà ò fìgbà kan rí béèrè ohun tó ju agbára wa lọ. Tá a bá sì ní èrò tó tọ́ nípa ohun tá a lè ṣe, tá ò sì lépa ohun tó kọjá agbára wa, ìgbòkègbodò wa lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà á túbọ̀ fi wá lọ́kàn balẹ̀, yóò sì máa fún wa láyọ̀.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 29]

Tá a bá fẹ́ láyọ̀, ká sì ní ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run, a ní láti máa lo òye ká bàa lè mọ ohun tó bọ́gbọ́n mu fún wa láti máa lépa níbàámu pẹ̀lú ipò tá a wà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Arábìnrin Nerlande ń láyọ̀ bó ṣe ń ṣe ohun tágbara rẹ̀ gbé nínú iṣẹ́ ìwàásù

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Gẹ́gẹ́ bí atukọ̀ yìí, kọ́ bó o ṣe máa ṣàtúnṣe ìgbésí ayé rẹ

[Credit Line]

© Wave Royalty Free/age fotostock

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

Arákùnrin Serge àti Arábìnrin Agnès jàǹfààní nínú bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í lépa àwọn ohun míì tọ́wọ́ wọn lè tẹ̀