Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kẹ́kọ̀ọ́ Yege Àwọn Míṣọ́nnárì Dà Bí Eéṣú

Kẹ́kọ̀ọ́ Yege Àwọn Míṣọ́nnárì Dà Bí Eéṣú

Kíláàsì Kẹrìnlélọ́gọ́fà Ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì

Kẹ́kọ̀ọ́ Yege Àwọn Míṣọ́nnárì Dà Bí Eéṣú

OṢÙ mẹ́fà-mẹ́fà ni wọ́n máa ń ṣayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì, wọ́n sì máa ń pe ìdílé Bẹ́tẹ́lì ti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láti péjọ síbẹ̀. Ní ọjọ́ kẹjọ oṣù March ọdún 2008, àwọn àlejò wá láti orílẹ̀-èdè tó lé ní ọgbọ̀n láti dara pọ̀ mọ́ ìdílé Bẹ́tẹ́lì fún ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege kíláàsì kẹrìnlélọ́gọ́fà ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Gbogbo àwọn tí iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àti irínwó lé mọ́kànlá [6,411] tí wọ́n wá síbi ayẹyẹ náà bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà yọ̀ lọ́jọ́ àṣeyẹ wọn pàtàkì yìí.

Arákùnrin Stephen Lett tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ni alága ètò náà. Ó bẹ̀rẹ̀ ètò náà pẹ̀lú àkòrí ọ̀rọ̀ tó sọ pé, “Jáde Lọ Pẹ̀lú Àwọn Èèyàn Jèhófà Tí Wọ́n Dà Bí Eéṣú.” Ìwé Ìṣípayá 9:1-4 fi àwùjọ kékeré ti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n padà sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà lọ́dún 1919 wé ọ̀wọ́ àwọn eéṣú tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní pẹrẹu. Alága náà rán àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà létí pé jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ ara “àwọn àgùntàn mìíràn” ti mú kí wọ́n dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn tí wọ́n dà bí ọ̀wọ́ àwọn eéṣú yìí.—Jòh. 10:16.

Arákùnrin Lon Schilling tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ló sọ àsọyé tó kàn, tí àkòrí rẹ̀ sọ pé, “Ẹ Máa Fún Ara Yín Lókun.” Àsọyé yìí dá lórí àpẹẹrẹ Ákúílà àti Pírísílà (tàbí Pírísíkà) ti inú Bíbélì tí wọ́n jẹ́ tọkọtaya Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní. (Róòmù 16:3, 4) Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà jẹ́ tọkọtaya méjìdínlọ́gbọ̀n tí àròpọ̀ iye wọn sì jẹ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́ta. Alásọyé náà rán wọn létí pé tí wọ́n bá fẹ́ kẹ́sẹ járí lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì wọn, wọ́n ní láti mú kí ìdè ìgbéyàwó wọn lágbára gan-an. Kò sígbà tí Bíbélì dárúkọ Ákúílà tí kò ní dárúkọ Pírísílà ìyàwó rẹ̀. Èyí ló mú kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti gbogbo ìjọ lápapọ̀ mọ̀ wọ́n sí tọkọtaya tó ṣe ara wọn lọ́kan. Bákan náà, àwọn tọkọtaya míṣọ́nnárì tòde òní gbọ́dọ̀ mọwọ́ ara wọn dáadáa, kí wọ́n máa sin Ọlọ́run pa pọ̀, kí wọ́n jùmọ̀ kojú ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tí wọ́n máa bá pàdé nínú iṣẹ́ ìwàásù wọn nílẹ̀ òkèèrè, tí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á máa fún ara wọn lókun.—Jẹ́n. 2:18.

Arákùnrin Guy Pierce tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló sọ àsọyé tó tẹ̀ lé e, tí àkòrí rẹ̀ sọ pé, “Fi Hàn Pé O Mọyì Oore Jèhófà.” Arákùnrin Pierce ṣàlàyé pé kì í ṣe pé kéèyàn ṣáà ti má ṣe ibi nìkan ló túmọ̀ sí pé èèyàn jẹ́ ẹni rere. Ohun tó máa ṣàǹfààní fáwọn èèyàn lẹni rere máa ń ṣe. Jèhófà Ọlọ́run ló jẹ́ ẹni rere jù lọ láyé àtọ̀run. (Sek. 9:16, 17) Àwọn ohun rere tí Ọlọ́run ń ṣe fún wa àti ìfẹ́ tó ní sí wa lè mú káwa náà máa ṣoore fáwọn èèyàn. Arákùnrin Pierce parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ kan tó fi gbóríyìn fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà. Ó ní: “Ní báyìí, ẹ ti ń ṣe rere. Ó sì dá wa lójú pé ẹ óò máa báa nìṣó ní mímọyì oore Ọlọ́run nípa ṣíṣe rere nínú iṣẹ́ èyíkéyìí tí Jèhófà Ọlọ́run bá yàn fún yín.”

Arákùnrin Michael Burnett ló sọ àsọyé tó tẹ̀ lé e. Míṣọ́nnárì ni arákùnrin yìí tẹ́lẹ̀, àmọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí ló di olùkọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Àkòrí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé, “Fi Ṣe Ọ̀já Ìgbàjú Láàárín Ojú Rẹ.” Jèhófà fẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa rántí ọ̀nà ìyanu tó gbà dá wọn sílẹ̀ ní Íjíbítì, ńṣe ni kó dà bíi pé wọ́n fi ṣe ‘ọ̀já ìgbàjú láàárín ojú wọn.’ (Ẹ́kís. 13:16) Olùbánisọ̀rọ̀ náà gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ níyànjú pé kí wọ́n fi ìtọ́ni rẹpẹtẹ tí wọ́n gbà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì yìí sọ́kàn, ńṣe ni kó dà bíi pé wọ́n fi ṣe ọ̀já ìgbàjú láàárín ojú wọn. Arákùnrin Burnett tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, kí wọ́n mọ̀wọ̀n ara wọn, kí wọ́n sì máa lo àwọn ìlànà Bíbélì láti yanjú èdèkòyédè láàárín àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ míṣọ́nnárì àtàwọn ẹlòmíràn.—Mát. 5:23, 24.

Arákùnrin Mark Noumair tó ti jẹ́ olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì tipẹ́tipẹ́ ló sọ àsọyé tí ọpọ́n sún kàn, tí àkòrí rẹ̀ sọ pé, “Orin Wo Làwọn Èèyàn Yóò Kọ Nípa Rẹ?” Láyé ọjọ́un, ó jẹ́ àṣà àwọn èèyàn láti máa fi orin ṣàjọyọ̀ ìṣẹ́gun. Ọ̀kan lára irú àwọn orin bẹ́ẹ̀ tú àṣírí àwọn ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Dánì àti Áṣérì pé wọ́n jẹ́ onímẹ̀ẹ́lẹ́ èèyàn tí kì í fara ṣiṣẹ́. Nígbà tó jẹ́ pé àwọn èèyàn kọrin láti yin ẹ̀yà Sébúlúnì pé wọ́n jẹ́ akíkanjú tó fẹ̀mí ara wọn wewu nítorí àwọn ẹlòmíràn. (Oníd. 5:16-18) Gẹ́gẹ́ bó ṣe jẹ́ pé èèyàn lè mọ ohun tí orin kan ń sọ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ orin náà, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé gbogbo ìwà àti ìṣe Kristẹni kọ̀ọ̀kan la máa fi mọ irú ẹni tó jẹ́ nígbà tó bá yá. Tẹ́nì kan bá ń fìtara ṣiṣẹ́ Ọlọ́run, tó sì ń fi ìṣòtítọ́ tẹ̀ lé ohun tí ètò Ọlọ́run bá sọ, inú Jèhófà á máa dùn sírú ẹni bẹ́ẹ̀, yóò sì jẹ́ àpẹẹrẹ rere fáwọn arákùnrin àti arábìnnrin rẹ̀. Táwọn ará nínú ìjọ bá ń rí ìwà àti ìṣe wa, tó jẹ́ orin nípa wa, ìyẹn á mú kí wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere wa.

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kíláàsì kẹrìnlélọ́gọ́fà náà lo àpapọ̀ nǹkan bíi ẹgbẹ̀rún mẹ́ta wákàtí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, èyí tó jẹ́ ara ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n gbà. Arákùnrin Sam Roberson, tó ń sìn ní Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Ẹ̀kọ́ Ètò Ọlọ́run ló sọ àsọyé tí àkòrí rẹ̀ jẹ́, “Bó O Ṣe Lè Jẹ́ Kí Ẹ̀mí Mímọ́ Máa Darí Rẹ.” Ó fọ̀rọ̀ wá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lẹ́nu wò, wọ́n sì sọ oríṣiríṣi ìrírí tí wọ́n ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n tún ṣàṣefihàn mélòó kan lára àwọn ìrírí náà. Lẹ́yìn táwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ti sọ àwọn ìrírí tó ń fúnni níṣìírí yìí, Arákùnrin Patrick LaFranca tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ yege nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì tí wọ́n sì ti ń sìn ní onírúurú orílẹ̀-èdè nísinsìnyí. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà mọyì àwọn ìmọ̀ràn tó wúlò táwọn arákùnrin náà fún wọn.

Arákùnrin Anthony Morris, tó wà lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló sọ àsọyé tó kẹ́yìn tí àkòrí rẹ̀ sọ pé, “Má Gbàgbé Pé Àwọn Ohun Tí A Ń Rí Jẹ́ Fún Ìgbà Díẹ̀.” Ìwé Mímọ́ rọ̀ wá láti máa fọkàn sí àwọn ìbùkún tí Jèhófà máa fún wa lọ́jọ́ iwájú, dípò ká máa ro ti àwọn ìpọ́njú tó wà fúngbà díẹ̀ tá à ń rí báyìí. (2 Kọ́r. 4:16-18) Lára àwọn ìpọ́njú tá à ń rí lónìí ni, ipò òṣì tó burú jáì, ìrẹ́nijẹ, ìnilára, àìsàn àti ikú. Ó sì ṣeé ṣe káwọn míṣọ́nnárì dojú kọ irú àwọn ipò tó ń bani nínú jẹ́ yìí. Àmọ́ tá a bá ń rántí pé ìgbà díẹ̀ làwọn nǹkan wọ̀nyí máa fi wà, èyí á mú ká máa fi Jèhófà sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa, a ó sì máa retí ìbùkún ọjọ́ iwájú.

Gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà wá sórí pèpéle láti gbọ́ ọ̀rọ̀ àsọkágbá tí Arákùnrin Lett fi gbà wọ́n níyànjú. Ó fún wọ́n níṣìírí pé kí wọ́n má ṣe rẹ̀wẹ̀sì. Ó ní: “Ìṣòro yòówù kó dé bá wa, ká jẹ́ adúróṣinṣin, a ò ní juwọ́ sílẹ̀ bí Jèhófà bá ń tì wá lẹ́yìn.” Ó rọ àwọn míṣọ́nnárì tuntun náà pé kí wọ́n dà bí eéṣú, kí wọ́n tẹra mọ́ sísin Jèhófà, kí wọ́n jẹ́ onítara, kí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin, kí wọ́n sì jẹ́ onígbọràn títí láé.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 30]

ÌSỌFÚNNI NÍPA KÍLÁÀSÌ

Iye orílẹ̀-èdè táwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti wá: 7

Iye orílẹ̀-èdè tá a yàn wọ́n sí: 16

Iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́: 56

Ìpíndọ́gba ọjọ́ orí wọn: 33.8

Ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti lò nínú òtítọ́: 18.2

Ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti lò nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún: 13.8

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Kíláàsì Kẹrìnlélọ́gọ́fà Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì

Nínú ìlà àwọn orúkọ tí ń bẹ́ nísàlẹ̀ yìí, ńṣe la to nọ́ńbà ìlà kọ̀ọ̀kan láti iwájú lọ sẹ́yìn, a sì to orúkọ láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún lórí ìlà kọ̀ọ̀kan.

(1) Nicholson, T.; Main, H.; Senge, Y.; Snape, L.; Vanegas, C.; Pou, L. (2) Santana, S.; Oh, K.; Lemaitre, C.; Williams, N.; Alexander, L. (3) Woods, B.; Stainton, L.; Huntley, E.; Alvarez, G.; Cruz, J.; Bennett, J. (4) Williamson, A.; González, N.; Zuroski, J.; Degandt, I.; May, J.; Diemmi, C.; Tavener, L. (5) Lemaitre, W.; Harris, A.; Wells, C.; Rodgers, S.; Durrant, M.; Senge, J. (6) Huntley, T.; Vanegas, A.; Pou, A.; Santana, M.; Bennett, V.; Tavener, D.; Oh, M. (7) Zuroski, M.; Rodgers, G.; Diemmi, D.; Nicholson, L.; Alvarez, C.; Snape, J. (8) Harris, M.; González, P.; Main, S.; Woods, S.; Stainton, B.; Williamson, D.; Durrant, J. (9) Cruz, P.; Degandt, B.; Williams, D.; Wells, S.; Alexander, D.; May, M.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì wà ní Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower