Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Ṣe Ohun Tó Ń gbé Iyì Jèhófà Yọ

Máa Ṣe Ohun Tó Ń gbé Iyì Jèhófà Yọ

Máa Ṣe Ohun Tó Ń gbé Iyì Jèhófà Yọ

“Ìgbòkègbodò [Jèhófà] jẹ́ iyì àti ọlá ńlá pàápàá.”—SM. 111:3.

1, 2. (a) Ṣàlàyé ohun tí “iyì” túmọ̀ sí. (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

 BÍBÉLÌ sọ pé Ọlọ́run ‘fi iyì àti ọlá ńlá wọ ara rẹ̀ láṣọ.’ (Sm. 104:1) Lójú àwa èèyàn, ara ìwà tó buyì kúnni ni kéèyàn máa wọṣọ lọ́nà tó bójú mu. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé kí àwọn obìnrin Kristẹni “máa fi aṣọ tí ó wà létòletò ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú, kì í ṣe pẹ̀lú àwọn àrà irun dídì àti wúrà tàbí péálì tàbí aṣọ àrà olówó ńlá gan-an.” (1 Tím. 2:9) Àmọ́ ṣá o, ìwà ọmọlúwàbí tó ń gbé “iyì àti ọlá ńlá” Jèhófà yọ kò mọ sórí aṣọ wíwọ̀ nìkan.—Sm. 111:3.

2 Ọ̀rọ̀ èdè Hébérù tá a tú sí “iyì” nínú Bíbélì tún lè túmọ̀ sí “ọlá ńlá,” “ògo” àti “ọlá.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ èdè kan ṣe wí, iyì lè túmọ̀ sí “ìgbéniga, ìbọ̀wọ̀fúnni, ìkàsí tàbí àpọ́nlé.” Kò sẹ́ni tó yẹ ká gbé ga, ká sì tún bọ̀wọ̀ fún tó Jèhófà. Nítorí náà, ńṣe ló yẹ kí àwa ìránṣẹ́ Jèhófà máa yẹra fún ọ̀rọ̀ àti ìwà tó bá lè tàbùkù sí i. Ṣùgbọ́n kí ló ń mú káwa èèyàn lè hùwà tó ń buyì kúnni? Àwọn nǹkan wo ló ń fi iyì àti ọlá ńlá Jèhófà hàn? Ipa wo ló yẹ kí iyì Ọlọ́run ní lórí wa? Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lára Jésù Kristi nípa bá a ṣe lè máa buyì kúnni? Báwo la sì ṣe lè máa ṣe ohun tó ń gbé iyì Ọlọ́run yọ?

Ìdí Tá A Fi Lè Máa Hùwà Tó Ń Buyì Kúnni

3, 4. (a) Kí ni iyì tí Ọlọ́run gbé wọ̀ wá gba pé ká máa ṣe? (b) Ta ni Sáàmù 8:5-9 ń tọ́ka sí lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) (d) Àwọn wo ni Jèhófà buyì kún nígbà àtijọ́?

3 Gbogbo èèyàn ló lè hùwà tó buyì kúnni nítorí pé ńṣe ni Ọlọ́run dá wa ní àwòrán ara rẹ̀. Jèhófà buyì kún ọkùnrin àkọ́kọ́ nípa bó ṣe yàn án ṣe alábòójútó ilẹ̀ ayé. (Jẹ́n. 1:26, 27) Kódà, lẹ́yìn téèyàn tiẹ̀ di ẹlẹ́ṣẹ̀, Jèhófà ṣì tún ohun tó jẹ́ ojúṣe àwa èèyàn sí ilẹ̀ ayé sọ. Èyí tó fi hàn pé Ọlọ́rùn ṣì fi ògo àti ọlá ńlá ‘dé èèyàn ládé.’ (Ka Sáàmù 8:5-9.) a Iyì tí Ọlọ́run gbé wọ̀ wá yìí gba pé káwa náà máa ṣe ohun tó máa gbé iyì Ọlọ́run yọ, ìyẹn ni pé ká máa gbé orúkọ ọlọ́lá ńlá Jèhófà ga tiyì-tẹ̀yẹ.

4 Jèhófà tún dìídì gbé iyì wọ àwọn tó jẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Ńṣe ni Ọlọ́run buyì kún Ébẹ́lì nígbà tó tẹ́wọ́ gba ẹbọ rẹ̀, àmọ́ ó kọ ẹbọ Kéènì ẹ̀gbọ́n rẹ̀. (Jẹ́n. 4:4, 5) Ọlọ́run sọ pé kí Mósè ‘mú lára iyì rẹ̀ sára’ Jóṣúà tó máa rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Núm. 27:20) Ohun tí Bíbélì sì sọ nípa Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì ni pé: “Jèhófà sì ń bá a lọ ní sísọ Sólómọ́nì di ńlá lọ́nà títa yọ ré kọjá lójú gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì fi iyì ọba sára rẹ̀, irúfẹ́ èyí tí kò tíì sí rí lára ọba èyíkéyìí ṣáájú rẹ̀ lórí Ísírẹ́lì.” (1 Kíró. 29:25) Iyì àrà ọ̀tọ̀ ni Ọlọ́run máa gbé wọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n ti fi ìṣòtítọ́ polongo “ògo ọlá ńlá ipò ọba rẹ̀.” (Sm. 145:11-13) Ojúṣe àtàtà tó sì buyì kúnni náà ni Ọlọ́run gbé lé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó ń pọ̀ sí i lọ́wọ́, ìyẹn “àwọn àgùntàn mìíràn,” bí wọ́n ṣe ń gbé Jèhófà ga.—Jòh. 10:16.

Iyì àti Ọlá Ńlá Jèhófà Hàn Kedere

5. Báwo ni iyì Jèhófà ṣe pọ̀ tó?

5 Nínú orin kan tí Dáfídì kọ láti fi hàn pé èèyàn rẹlẹ̀ gan-an sí Ọlọ́run tó ga fíofío, ó ní: “Ìwọ Jèhófà Olúwa wa, orúkọ rẹ mà kún fún ọlá ńlá ní gbogbo ilẹ̀ ayé o, ìwọ tí a ń ròyìn iyì rẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ lókè ọ̀run!” (Sm. 8:1) Àní sẹ́, Jèhófà Ọlọ́run ni Ọ̀gá Ògo tí iyì rẹ̀ borí ohun gbogbo láyé àtọ̀run. Láti ìgbà tó ti wà ṣáájú kí Ọlọ́run tó dá “ọ̀run àti ilẹ̀ ayé” ló sì ti rí bẹ́ẹ̀, yóò sì wà bẹ́ẹ̀ títí ré kọjá ìgbà tí yóò mú ìpinnu rẹ̀ ológo ṣẹ láti sọ ayé di Párádísè àti láti mú kí ìran èèyàn di pípé. Ìyẹn fi hàn pé láti ayérayé títí lọ dé ayérayé ni iyì rẹ̀ ti borí ohun gbogbo.—Jẹ́n. 1:1; 1 Kọ́r. 15:24-28; Ìṣí. 21:1-5.

6. Kí ni onísáàmù náà rò tó fi sọ pé Jèhófà fi iyì wọ ara rẹ̀ láṣọ?

6 Ẹ ò rí i pé onísáàmù tó bẹ̀rù Ọlọ́run yìí máa gbà pé Ọlọ́run tóbi lọ́ba gan-an ni, nígbà tó gbójú sókè tó ń wo ojú ọ̀run títòrò mini tó kún fọ́fọ́ fáwọn ìràwọ̀ tó ń tàn yinrin! Àgbàyanu iṣẹ́ àrà tí Ọlọ́run ṣe, pàápàá bó ṣe ‘na ọ̀run bí ẹní ta aṣọ àgọ́,’ jẹ́ ohun ìyanu tí onísáàmù náà rò tó fi yin Jèhófà lógo pé ó fi iyì wọ ara rẹ̀ láṣọ. (Ka Sáàmù 104:1, 2.) Iyì àti ọlá ńlá Olódùmarè Ẹlẹ́dàá wa tá ò lè fojú rí yìí hàn kedere nínú àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tá a lè rí.

7, 8. Àwọn nǹkan tó ń fi iyì àti ọlá ńlá Jèhófà hàn kedere wo là ń rí lójú ọ̀run?

7 Bí àpẹẹrẹ, wo ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Onírìísí Wàrà (Milky Way). Tá a bá wo bí ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ àwọn ìràwọ̀ ṣe lọ salalu nínú ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ yìí, ńṣe ni ayé wa dà bí ẹyọ egunrín iyanrìn kan ṣoṣo láàárín iyanrìn etíkun tó lọ salalu. Àní àwọn ìràwọ̀ tó wà nínú ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ yìí ju ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù lọ! Téèyàn bá fẹ́ ka iye ìràwọ̀ tó jẹ́ ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù tán, báwo ló ṣe máa pẹ́ tó? Jẹ́ ká sọ pé ó ṣeé ṣe fún ọ láti máa ka ìràwọ̀ kan ní ìṣẹ́jú àáyá kọ̀ọ̀kan, kó o sì máa kà á lọ bẹ́ẹ̀ fún wákàtí mẹ́rìnlélógún láìdúró, yóò gbà ọ́ ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] ọdún lọ kó o tó ka ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù ìràwọ̀ tán!

8 Tí ìràwọ̀ tó wà nínú ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Onírìísí Wàrà yìí nìkan ṣoṣo bá ju ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù lọ, mélòó ni gbogbo ìràwọ̀ tó wà lójú ọ̀run máa wá jẹ́? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, àwọn onímọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀dá inú sánmà fojú díwọ̀n rẹ̀ pé, yàtọ̀ sí ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Onírìísí Wàrà, iye àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ míì tó wà tó nǹkan bí àádọ́ta bílíọ̀nù sí bílíọ̀nù márùnlélọ́gọ́fà [125]. Mélòó wá ni iye àwọn ìràwọ̀ inú gbogbo wọn? Iye wọn ta yọ ohun tí agbára òye àwa èèyàn lè gbé. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, Jèhófà ń “ka iye àwọn ìràwọ̀; gbogbo wọn ni ó ń fi orúkọ wọn pè.” (Sm. 147:4) Nígbà tó o ti wá rí bí Jèhófà ṣe fi iyì wọ ara rẹ̀ láṣọ wàyí, ǹjẹ́ kò yẹ kí ìyẹn mú ọ yin orúkọ rẹ̀ lógo?

9, 10. Báwo ni ọ̀nà àrà tí Ẹlẹ́dàá wa gbà ń pèsè irú oúnjẹ bíi búrẹ́dì ṣe gbé ọgbọ́n rẹ̀ yọ?

9 Ẹ jẹ́ ká gbé tàwọn nǹkan àgbàyanu tó wà lójú ọ̀run tì ná, ká tiẹ̀ wo búrẹ́dì lásánlàsàn. Yàtọ̀ sí pé Jèhófà jẹ́ “Olùṣẹ̀dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé,” òun tún ni “Ẹni tí ń fi oúnjẹ fún àwọn tí ebi ń pa.” (Sm. 146:6, 7) “Iyì àti ọlá ńlá” Ọlọ́run hàn kedere nínú àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ títóbi, títí kan bó ṣe pèsè àwọn irúgbìn tí wọ́n ń fi èso wọn ṣe ìyẹ̀fun tá a fi ń ṣe búrẹ́dì. (Ka Sáàmù 111:1-5.) Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n gbàdúrà pé: “Fún wa lónìí oúnjẹ wa fún ọjọ́ òní.” (Mát. 6:11) Búrẹ́dì jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára oúnjẹ àwọn èèyàn kan látijọ́, títí kan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Bí búrẹ́dì sì ṣe jẹ́ oúnjẹ tó wọ́ pọ̀ tó yìí, ohun kékeré kọ́ ló ń ṣẹlẹ̀ nínú àpòpọ̀ ìyẹ̀fun búrẹ́dì àtàwọn èròjà rẹ̀ mélòó kan kó tó di búrẹ́dì aládùn.

10 Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ìyẹ̀fun àlìkámà tàbí ti ọkà báálì àti omi làwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ń ṣe búrẹ́dì. Nígbà míì, wọ́n máa ń fi ìwúkàrà tó máa ń mú ìyẹ̀fun wú sí búrẹ́dì náà tí wọ́n bá ń ṣe é. Àpòpọ̀ ìyẹ̀fun, ìwúkàrà àti omi lásán yìí ló ń yí padà lọ́nà àrà tí yóò sì di búrẹ́dì. Di báyìí, àwọn èèyàn ò tíì ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye nípa gbogbo bí àyípadà yẹn ṣe ń wáyé gan-an. Yàtọ̀ síyẹn, bí òòlọ̀ inú wa ṣe ń lọ búrẹ́dì ọ̀hún pàápàá tún jẹ́ ohun àgbàyanu kan. Abájọ tí onísáàmù náà fi tẹnu bọ orin pé: “Àwọn iṣẹ́ rẹ mà pọ̀ o, Jèhófà! Gbogbo wọn ni o fi ọgbọ́n ṣe”! (Sm. 104:24) Ṣé nǹkan wọ̀nyí ń mú kí ìwọ náà yin Jèhófà lógo?

Báwo Ni Iyì àti Ọlá Ńlá Ọlọ́run Ṣe Kàn Ọ́?

11, 12. Ipa wo ni ṣíṣàṣàrò lórí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run máa ní lórí wa?

11 Kò dìgbà tá a bá jẹ́ onímọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀dá inú sánmà káwọn iṣẹ́ àrà tá à ń rí lójú ọ̀run lálẹ́ tó lè jọ wá lójú, kò sì dìgbà tá a bá mọ gbogbo bí wọ́n ṣe ń ṣe búrẹ́dì ká tó lè máa jẹ búrẹ́dì ní àjẹgbádùn. Ṣùgbọ́n ká tó lè mọyì bí Ẹlẹ́dàá wa ṣe tóbi lọ́ba, a ní láti fara balẹ̀ ronú nípa àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Ipa wo ni ṣíṣe irú àṣàrò bẹ́ẹ̀ máa ní lórí wa? Ipa kan náà tí ṣíṣàṣàrò lórí àwọn iṣẹ́ àrà míì tí Jèhófà ṣe ló máa ní.

12 Dáfídì kọrin nípa àwọn iṣẹ́ àrà tí Jèhófà ṣe nítorí àwọn èèyàn Rẹ̀, ó ní: “Ọlá ńlá ológo ti iyì rẹ àti ọ̀ràn nípa àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ ni èmi yóò fi ṣe ìdàníyàn mi.” (Sm. 145:5) Ọ̀nà tá a lè gbà fi àwọn iṣẹ́ àrà yìí ṣe ìdàníyàn wa ni pé ká máa ka Bíbélì, ká sì máa wá àyè láti ṣàṣàrò lórí ohun tá a kà nínú rẹ̀. Àǹfààní wo ni ṣíṣe àṣàrò yìí máa ṣe fún wa? Ńṣe ló máa mú ká túbọ̀ mọrírì iyì àti ọlá ńlá Ọlọ́run. Èyí tó fi hàn pé àwa náà máa pohùn pọ̀ pẹ̀lú Dáfídì láti gbé Jèhófà ga, tí a ó sọ pé: “Ní ti títóbi rẹ, ṣe ni èmi yóò máa polongo rẹ̀.” (Sm. 145:6) Tá a bá ń ṣàṣàrò lórí àwọn iṣẹ́ àrà Ọlọ́run, ó yẹ kó mú kí àjọṣe àwa àti Jèhófà dára sí i, kó sì tún mú ká pinnu láti máa fi ìtara sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà fáwọn èèyàn. Ǹjẹ́ ò ń fi ìtara kéde ìhìn rere láti lè mú káwọn èèyàn mọrírì iyì, ọlá ńlá àti ògo Jèhófà Ọlọ́run wa?

Jésù Gbé Iyì Ọlọ́run Yọ Lọ́nà Pípé

13. (a) Gẹ́gẹ́ bí ìwé Dáníẹ́lì 7:13, 14 ṣe sọ, kí ni Jèhófà gbé lé Ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́? (b) Gẹ́gẹ́ bí Ọba, báwo ni Jésù ṣe hùwà sí àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀?

13 Jésù Kristi Ọmọ Ọlọ́run fìtara kéde ìhìn rere, ó sì gbé Baba rẹ̀ ọ̀run tó jẹ́ Ọ̀gá Ògo, Ọlọ́lá-ńlá ga. Jèhófà wá gbé iyì àrà ọ̀tọ̀ wọ Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo yìí nípa fífún un ní ‘agbára ìṣàkóso àti ìjọba.’ (Ka Dáníẹ́lì 7:13, 14.) Síbẹ̀, Jésù ò torí ìyẹn di agbéraga tàbí ẹni tí kò ṣeé sún mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló jẹ́ Ọba aláàánú, tó mọ àwọn ohun tó jẹ́ ìṣòro àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀, tó sì tún ń fọ̀wọ̀ wọ̀ wọ́n. Ìwọ wo àpẹẹrẹ kan nípa ọ̀nà tí Jésù gbà hùwà sáwọn èèyàn tó ń bá pàdé nígbà tó ṣì jẹ́ Ọba-lọ́la, pàápàá àwọn táráyé pa tì, tí wọ́n kì í fẹ́ rí sójú.

14. Ojú wo ni wọ́n fi ń wo àwọn adẹ́tẹ̀ nílẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́?

14 Láyé àtijọ́, tí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá kọ lu èèyàn ńṣe ló máa ń hàn án léèmọ̀ wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́, tá máa jẹ ara rẹ̀ títí onítọ̀hún á fi kú. Nígbà yẹn, ẹní bá wo alárùn ẹ̀tẹ̀ sàn, bíi pé ó jí ẹni tó ti kú dìde ni. (Núm. 12:12; 2 Ọba 5:7, 14) Aláìmọ́ èèyàn àti ẹni ìríra ni wọ́n ń ka adẹ́tẹ̀ sí, wọ́n sì máa ń lé wọn kúrò láàárín ìlú ni. Tí adẹ́tẹ̀ bá ń sún mọ́ ibi téèyàn wà ó gbọ́dọ̀ máa kígbe pé, “aláìmọ́, aláìmọ́!” káwọn èèyàn lè yàgò fún un. (Léf. 13:43-46) Adẹ́tẹ̀ ò yàtọ̀ sí òkú lójú àwọn èèyàn ìgbà yẹn. Ohun tó tiẹ̀ wà nínú àkọsílẹ̀ àwọn rábì ni pé, adẹ́tẹ̀ ò gbọ́dọ̀ sún mọ́ ẹnikẹ́ni ju nǹkan bíi mítà méjì ó dín díẹ̀ lọ. Ìròyìn kan sọ pé nígbà tí aṣáájú ẹ̀sìn kan tiẹ̀ rí adẹ́tẹ̀ kan lọ́ọ̀ọ́kán, ńṣe ló ń ju òkò sí i láti fi lé e jìnnà.

15. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà hùwà sí adẹ́tẹ̀ kan?

15 Ṣùgbọ́n, ìwọ wo ohun tí Jésù ṣe nígbà tí adẹ́tẹ̀ kan wá bẹ̀ ẹ́ pé kó mú òun lára dá. (Ka Máàkù 1:40-42.) Dípò tí Jésù á fi lé adẹ́tẹ̀ táwọn èèyàn ta nù yẹn, ṣe ló ṣàánú rẹ̀ tó sì fi ọ̀wọ̀ wọ̀ ọ́. Ojú ẹni tó nílò ìwòsàn, tó yẹ kéèyàn ṣàánú, ni Jésù fi wò ó. Àánú rẹ̀ tó ṣe Jésù mú kó wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Jésù wá fọwọ́ rẹ̀ kan adẹ́tẹ̀ náà, ó sì mú un lára dá.

16. Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ látinú ọ̀nà tí Jésù gbà hùwà sáwọn èèyàn?

16 Báwo ni àwa tá a jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù ní ti bó ṣe gbé iyì Baba rẹ̀ yọ? Ọ̀nà kan ni pé ká gbà tinútinú pé gbogbo èèyàn ni ọ̀wọ̀ àti ọlá tọ́ sí láìfi ipò wọn láwùjọ, ìlera wọn tàbí ọjọ́ orí wọn pè. Ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí àwọn tó wà nípò àbójútó, irú bí àwọn òbí, ọkọ àtàwọn alàgbà, máa fi ọ̀wọ̀ wọ àwọn tó wà lábẹ́ àbójútó wọn káwọn wọ̀nyẹn lè tipa bẹ́ẹ̀ máa fojú iyì wo ara wọn. Bíbélì sì mú kó ṣe kedere pé gbogbo Kristẹni ni kókó yìí kàn. Ó ní: “Nínú ìfẹ́ ará, ẹ ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.”—Róòmù 12:10.

Máa Ṣe Ohun Tí Kò Ní Tàbùkù sí Ọlọ́run Nínú Ìjọsìn Rẹ

17. Ẹ̀kọ́ wo ni Ìwé Mímọ́ kọ́ wa nípa ṣíṣe ohun tí kò ní tàbùkù sí Jèhófà nígbà ìjọsìn?

17 A gbọ́dọ̀ rí i pé a kì í ṣe ohun tó lè tàbùkù sí Jèhófà nígbà ìjọsìn. Oníwàásù 5:1 sọ pé: “Ṣọ́ ẹsẹ̀ rẹ nígbàkigbà tí o bá ń lọ sí ilé Ọlọ́run tòótọ́.” Bí Ọlọ́run ṣe pàṣẹ fún Mósè nígbà kan ló ṣe pàṣẹ fún Jóṣúà náà pé kó bọ́ sálúbàtà rẹ̀ nígbà tó wà ní ibi mímọ́. (Ẹ́kís. 3:5; Jóṣ. 5:15) Àwọn méjèèjì ní láti ṣe bẹ́ẹ̀ láti fi hàn pé wọ́n bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run. Ọlọ́run pa á láṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ àlùfáà pé kí wọ́n máa wọ ṣòkòtò tá a fi aṣọ ọ̀gbọ̀ ṣe “láti [fi] bo ara tí ó wà ní ìhòòhò.” (Ẹ́kís. 28:42, 43) Èyí kò ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni rí ìhòòhò wọn nígbà tí wọ́n bá wà lẹ́nu iṣẹ́ wọn nídìí pẹpẹ. Gbogbo ìdílé àlùfáà pẹ̀lú ló gbọ́dọ̀ máa hùwà tí kò ní tàbùkù sí Ọlọ́run.

18. Kí la ní láti máa ṣe kí ìjọsìn wa lè máa gbé iyì Jèhófà yọ?

18 Èyí fi hàn pé ìjọsìn tó bá máa gbé iyì Ọlọ́run yọ ní láti jẹ́ èyí tá a ṣe tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, láìṣe ohunkóhun tó lè tàbùkù sí Ọlọ́run. Ká tó lè jẹ́ ẹni táwọn èèyàn ń buyì kún tí wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún, a ní láti yẹra fún ìwà àbùkù. Kò yẹ ká máa fi ẹnu lásán sọ pé a ń hùwà tó buyì kúnni tàbí ká máa ṣe ojú ayé. Ó ní láti wá látinú ọkàn wa lọ́hùn-ún, níbi téèyàn ò lè rí àfi Ọlọ́run. (1 Sám. 16:7; Òwe 21:2) Ó yẹ kí híhùwà tó buyì kúnni mọ́ wa lára, kó máa hàn nínú ìṣe wa àti àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn èèyàn, àní títí kan èrò tá à ń ní nípa ara wa àti irú ojú tá a fi ń wo ara wa pàápàá. Láìsí àní-àní, gbogbo ìgbà ló yẹ ká máa yàgò fún ohun àbùkù, yálà nínú ìṣe wa tàbí ọ̀rọ̀ ẹnu wa. Ní ti ìwà, ìṣe àti ìmúra wa, ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù yìí ló yẹ kó máa ró lọ́kàn wa, ó ní: “Kò sí ọ̀nà kankan tí àwa gbà jẹ́ okùnfà èyíkéyìí fún ìkọ̀sẹ̀, kí a má bàa rí àléébù sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa; ṣùgbọ́n lọ́nà gbogbo, a ń dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run.” (2 Kọ́r. 6:3, 4) Ńṣe ni ká máa “ṣe ẹ̀kọ́ Olùgbàlà wa, Ọlọ́run, lọ́ṣọ̀ọ́ nínú ohun gbogbo.”—Títù 2:10.

Máa Bá A Lọ Ní Ṣíṣe Ohun Tó Ń Gbé Iyì Ọlọ́run Yọ

19, 20. (a) Ọ̀nà tó dára wo la lè gbà buyì kún àwọn èèyàn? (b) Ní ti ṣíṣe ohun tó ń gbé iyì Ọlọ́run yọ, kí ló yẹ ká fi ṣe ìpinnu wa?

19 Ohun tó ń gbé iyì Ọlọ́run yọ làwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ “ikọ̀ tí ń dípò fún Kristi” máa ń ṣe. (2 Kọ́r. 5:20) “Àwọn àgùntàn mìíràn,” tó ń tì wọ́n lẹ́yìn gbágbáágbá náà tún jẹ́ aṣojú Ìjọba Mèsáyà tó ń ṣe ohun tó ń gbé iyì Ọlọ́run yọ. Ńṣe ni ikọ̀ tàbí aṣojú ìjọba kan máa ń fi ìgboyà sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa gbé iyì ìjọba tó ń ṣojú fún yọ. Nítorí náà, ṣe ló yẹ ká máa fìgboyà sọ ọ̀rọ̀ tí yóò máa gbé iyì Ìjọba Ọlọ́run yọ. (Éfé. 6:19, 20) Nígbà tá a bá sì “mú ìhìn rere ohun tí ó dára jù” tọ àwọn èèyàn lọ, ǹjẹ́ kì í ṣe pé a buyì kún wọn nìyẹn?—Aísá. 52:7.

20 Ó yẹ ká fi ṣe ìpinnu wa pé a óò máa gbé Ọlọ́run ga nípa yíyẹra fún gbogbo ohun tó bá lè tàbùkù sí i. (1 Pét. 2:12) Ẹ jẹ́ ká rí i dájú pé à ń bọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Ọlọ́run, fún ìjọsìn rẹ̀ àti fún àwọn ará wa. Ǹjẹ́ kí Jèhófà, ẹni tó fi iyì àti ọlá ńlá wọ ara rẹ̀ láṣọ, máa fi ìdùnnú tẹ́wọ́ gbà ìjọsìn wa tá à ń ṣe lọ́nà tó ń gbé iyì rẹ̀ yọ.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ nínú Sáàmù kẹjọ yìí tún jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jésù Kristi ẹni pípé.—Héb. 2:5-9.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Tá a bá mọrírì iyì àti ọlá ńlá Jèhófà, ipa wo ló yẹ kí ìyẹn ní lórí wa?

• Ní ti ká fi ọ̀wọ̀ wọni, ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú ọ̀nà tí Jésù gbà hùwà sí adẹ́tẹ̀ kan?

• Kí làwọn ohun tó yẹ ká máa ṣe láti lè máa gbé iyì Jèhófà yọ?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Báwo ni Jèhófà ṣe buyì kún Ébẹ́lì?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Iṣẹ́ àrà Jèhófà hàn àní nínú bó ṣe ń pèsè irú oúnjẹ bíi búrẹ́dì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Tó bá dọ̀rọ̀ fífi ọ̀wọ̀ wọ àwọn èèyàn, ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ látinú ọ̀nà tí Jésù gbà hùwà sí adẹ́tẹ̀ kan?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ìjọsìn tó ń gbé iyì Jèhófà yọ kò gbọ́dọ̀ ní ohunkóhun tó bá lè tàbùkù sí Ọlọ́run