Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Bá A Nìṣó Láti Jẹ́ Adúróṣinṣin Pẹ̀lú Ọkàn Tó Ṣọ̀kan

Máa Bá A Nìṣó Láti Jẹ́ Adúróṣinṣin Pẹ̀lú Ọkàn Tó Ṣọ̀kan

Máa Bá A Nìṣó Láti Jẹ́ Adúróṣinṣin Pẹ̀lú Ọkàn Tó Ṣọ̀kan

“Èmi yóò máa rìn nínú òtítọ́ rẹ. Mú ọkàn-àyà mi ṣọ̀kan láti máa bẹ̀rù orúkọ rẹ.”—SM. 86:11.

1, 2. (a) Gẹ́gẹ́ bí Sáàmù 86:2, 11 ṣe sọ, kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ tá ó fi jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà nígbà tí àdánwò bá dé? (b) Ìgbà wo ló yẹ ká ti fi kọ́ra láti jẹ́ adúróṣinṣin pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa?

 ÀWỌN Kristẹni kan wà tí wọ́n ti fi ọ̀pọ̀ ọdún fara da ìfinisẹ́wọ̀n tàbí inúnibíni tí wọ́n sì dúró ṣinṣin, síbẹ̀ tí wọ́n ṣubú wẹ́rẹ́ sínú ìfẹ́ ọrọ̀. Kí ló máa ń fà á? Ìdáhùn náà dá lórí ipò ọkàn wa, ìyẹn irú ẹni tá a jẹ́ nínú lọ́hùn-ún. Sáàmù kẹrìndínláàádọ́rùn-ún fi hàn pé ìdúróṣinṣin ní í ṣe pẹ̀lú ọkàn tó ṣọ̀kan, ìyẹn ọkàn tó pé pérépéré, tí kò pínyà. Dáfídì tó kọ Sáàmù náà gbàdúrà pé: “Ṣọ́ ọkàn mi, nítorí pé adúróṣinṣin ni mí. Gba ìránṣẹ́ rẹ là-ìwọ ni Ọlọ́run mi-tí ó gbẹ́kẹ̀ lé ọ.” Ó tún gbà á ládùúrà pé: “Jèhófà, fún mi ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà rẹ. Èmi yóò máa rìn nínú òtítọ́ rẹ. Mú ọkàn-àyà mi ṣọ̀kan láti máa bẹ̀rù orúkọ rẹ.”—Sm. 86:2, 11.

2 Tá ò bá fi gbogbo ọkàn wa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, àwọn ọ̀ràn míì tó lè gbà wá lọ́kàn lè mú ká yẹsẹ̀ lórí ìdúróṣinṣin wa sí Ọlọ́run tòótọ́. Ìfẹ́ láti ní àwọn nǹkan tara lójú méjèèjì dà bí ohun abúgbàù tí wọ́n rì mọ́ ilẹ̀ ibi téèyàn ń gbà kọjá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè ti dúró ṣinṣin sí Jèhófà lábẹ́ àwọn ipò tó le koko, a ṣì lè ṣubú sínú ìdẹkùn Sátánì. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká fi gbogbo ọkàn wa dúró ṣinṣin ti Jèhófà nísinsìnyí kó tó di pé àdánwò dé bá wa! Bíbélì sọ pé: “Ju gbogbo ohun mìíràn tí a ní láti ṣọ́, fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ.” (Òwe 4:23) A lè rí ẹ̀kọ́ pàtàkì kọ́ lórí ọ̀ràn yìí tá a bá kíyè sí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wòlíì kan tí Jèhófà rán níṣẹ́ láti Júdà sí Jèróbóámù ọba Ísírẹ́lì.

‘Jẹ́ Kí N Fún Ọ Ní Ẹ̀bùn’

3. Kí ni Jèróbóámù ṣe nígbà tí wòlíì Ọlọ́run jẹ́ iṣẹ́ fún un?

3 Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí. Èèyàn Ọlọ́run kan ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ iṣẹ́ tó lágbára fún Jèróbóámù Ọba ni. Ọba yìí ti gbé ìjọsìn ère ọmọ màlúù kalẹ̀ ní ìhà àríwá ìjọba Ísírẹ́lì tó ní ẹ̀yà mẹ́wàá. Orí ọba náà gbóná nígbà tí wòlíì yẹn jíṣẹ́ náà fún un. Ó pàṣẹ pé kí wọ́n gbá a mú. Àmọ́ Jèhófà kò fi ìránṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀. Lójú ẹsẹ̀, ńṣe ni ọwọ́ tí ọba yẹn nà síta pẹ̀lú ìbínú gbẹ háú, tí pẹpẹ tí wọ́n ti ń ṣe ìjọsìn èké yẹn sì là sọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Lójijì, Jèróbóámù pohùn dà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ èèyàn Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Jọ̀wọ́, tu Jèhófà Ọlọ́run rẹ lójú, kí o sì gbàdúrà nítorí mi kí a lè mú ọwọ́ mi padà bọ̀ sípò fún mi.” Wòlíì náà gbàdúrà, ọwọ́ ọba sì padà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀.—1 Ọba 13:1-6.

4. (a) Kí nìdí tí ẹ̀bùn ọba fi jẹ́ àdánwò gidi fún wòlíì yẹn lórí ọ̀ràn ìdúróṣinṣin? (b) Kí ni wòlíì náà fi dá ọba lóhùn?

4 Lẹ́yìn náà, Jèróbóámù wá sọ fún èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ pé: “Bá mi ká lọ sí ilé kí o sì jẹ ohun ìgbẹ́mìíró, kí èmi sì fún ọ ní ẹ̀bùn.” (1 Ọba 13:7) Kí ni kí wòlíì yìí wá ṣe báyìí o? Ṣé kí ó gbà kí ọba ṣe òun lálejò ni lẹ́yìn tó ti jíṣẹ́ fún un pé Ọlọ́run ò fọwọ́ sóun tó ń ṣe? (Sm. 119:113) Àbí kó kọ ìkésíni ọba, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dà bíi pé ọba yẹn ti ronú pìwà dà? Ó dájú pé Jèróbóámù lọ́rọ̀ dáadáa, kò sì sóhun tí kò lè fi tẹ́ àwọn àlejò rẹ̀ lọ́rùn tán. Ó ṣeé ṣe kí ohun tí ọba fẹ́ ṣe yìí jẹ́ àdánwò ńlá fún wòlíì Ọlọ́run yìí tó bá jẹ́ pé ìfẹ́ ọrọ̀ ti dọ́gbọ́n ń gbilẹ̀ lọ́kàn rẹ̀. Àmọ́ Jèhófà ti pàṣẹ fún wòlíì yẹn pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ oúnjẹ tàbí kí o mu omi, ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ gba ọ̀nà tí o gbà lọ padà.” Torí náà, wòlíì yẹn dá ọba lóhùn láìfọ̀rọ̀ bọpobọyọ̀ pé: “Bí o bá fún mi ní ìdajì ilé rẹ, èmi kì yóò bá ọ lọ kí n sì jẹ oúnjẹ tàbí kí n mu omi ní ibí yìí.” Wòlíì yẹn fi Bẹ́tẹ́lì sílẹ̀, ọ̀nà ibòmíì ló sì gbà padà. (1 Ọba 13:8-10) Ẹ̀kọ́ wo ni ìpinnu wòlíì yẹn kọ́ wa nípa ìdúróṣinṣin tó tọkàn wá?—Róòmù 15:4.

“Ní Ìtẹ́lọ́rùn”

5. Báwo ni ìfẹ́ ọrọ̀ ṣe kan ọ̀ràn ìdúróṣinṣin?

5 Ó lè dà bíi pé ìfẹ́ ọrọ̀ kò kan ọ̀ràn ìdúróṣinṣin, àmọ́ ó kàn án. Ṣé a gbẹ́kẹ̀ lé ìlérí tí Jèhófà ṣe, pé òun máa fún wa ní ohun tó jẹ́ kò-ṣeé-má-nìí? (Mát. 6:33; Héb. 13:5) Dípò ká máa forí ṣe fọrùn ṣe láìwo ohun tó lè ná wa, torí ká lè ní àwọn nǹkan amáyédẹrùn tọ́wọ́ wa ò lè tó nísinsìnyí, ṣé a lè mójú kúrò lára wọn? (Ka Fílípì 4:11-13.) Ṣé ó máa ń ṣe wá bíi pé ká pa àwọn àǹfààní láti ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn wa tì, torí ká lè ráyè lépa ohun tá a fẹ́ nísinsìnyí? Ǹjẹ́ iṣẹ́ ìsìn tá à ń fi ìdúróṣinṣin ṣe sí Jèhófà ló gbapò kìíní nínú ìgbésí ayé wa? Ìdáhùn ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa sinmi lórí bóyá à ń fi gbogbo ọkàn wa sin Ọlọ́run tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ó jẹ́ ọ̀nà èrè ńlá, àní fífọkànsin Ọlọ́run pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí ohun-moní-tómi. Nítorí a kò mú nǹkan kan wá sínú ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mú ohunkóhun jáde. Nítorí náà, bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.”—1 Tím. 6:6-8.

6. Irú àwọn nǹkan wo ló lè dà bí ẹ̀bùn Jèróbóámù níwájú wa, kí ló sì máa ràn wá lọ́wọ́ láti pinnu bóyá ká gbà wọ́n àbí ká má gbà wọ́n?

6 Bí àpẹẹrẹ, ẹni tó gbà wá síṣẹ́ lè fún wa ní ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́, téyìí sì máa fi kún owó oṣù wa, tí a ó sì tún máa rí àwọn àǹfààní míì nídìí ẹ̀. A sì tún lè wò ó pé tá a bá wáṣẹ́ lọ sí orílẹ̀-èdè míì tàbí àgbègbè ibòmíì, ó ṣeé ṣe kówó tó ń wọlé fún wa gbé pẹ́ẹ́lí díẹ̀ sí i. Irú àwọn àǹfààní yẹn lè kọ́kọ́ dà bí ìbùkún látọ̀dọ̀ Jèhófà. Àmọ́ ká tó pinnu ohun tá a máa ṣe lórí àǹfààní tó yọjú yẹn, ṣé kò ní dáa ká wo ohun tó fẹ́ sún wa ṣerú ìpinnu yẹn? Ìbéèrè pàtàkì tó yẹ ká bi ara wa ni pé, “Báwo ni ìpinnu tí mo fẹ́ ṣe yóò ṣe nípa lórí àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà?”

7. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká fa ìfẹ́ ọrọ̀ tu kúrò lọ́kàn wa pátápátá?

7 Gbogbo ìgbà ni ayé Sátánì ń gbé ohun tó lè mú kéèyàn ní ìfẹ́ ọrọ̀ jáde. (Ka 1 Jòhánù 2:15, 16.) Ohun tí Èṣù ń fẹ́ ni pé kó sọ ọkàn wa dìbàjẹ́. Torí náà, a gbọ́dọ̀ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì. Tá a bá rí i pé ìfẹ́ ọrọ̀ ti ta gbòǹgbò lọ́kàn wa, ká tètè fà á tu pátápátá. (Ìṣí. 3:15-17) Kò ṣòro fún Jésù láti kọ gbogbo ìjọba ayé tí Sátánì fi lọ̀ ọ́. (Mát. 4:8-10) Ó kìlọ̀ fún wa pé: “Ẹ la ojú yín sílẹ̀, kí ẹ sì máa ṣọ́ra fún gbogbo onírúurú ojúkòkòrò, nítorí pé nígbà tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá, ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.” (Lúùkù 12:15) Ìdúróṣinṣin ló máa mú ká lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà dípò ara wa.

Àgbàlagbà Wòlíì “Tàn Án Jẹ”

8. Kí lohun tó dán ìdúróṣinṣin wòlíì Ọlọ́run wò?

8 Wòlíì Ọlọ́run yìí kò ní kó sí wàhálà kankan ká ní ó rọra ń bá ìrìn àjò rẹ̀ padà lọ sílé. Àmọ́, kò pẹ́ tó kúrò níbẹ̀ yẹn tó fi rí ìdánwò míì. Bíbélì sọ pé: “Àgbàlagbà wòlíì kan sì ń gbé ní Bẹ́tẹ́lì, àwọn ọmọ rẹ̀ sì wọlé wá wàyí, wọ́n sì ṣèròyìn gbogbo” ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn fún un. Bí bàbá yẹn ṣe gbọ́ ìròyìn yẹn báyìí, ó ní kí wọ́n bóun di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan ní gàárì kó bàa lè tètè bá wòlíì Ọlọ́run lọ́nà. Kò pẹ́ sígbà yẹn ló bá wòlíì yẹn tó ń sinmi lábẹ́ igi ńlá kan, ó bá sọ fún wòlíì náà pé: “Bá mi lọ sí ilé kí o sì jẹ oúnjẹ.” Wòlíì Ọlọ́run sọ fún un pé òun ò lè bá a lọ sílé, àgbàlagbà wòlíì yìí bá sọ fún un pé: “Èmi pẹ̀lú jẹ́ wòlíì bí tìrẹ, áńgẹ́lì kan sì bá mi sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Jèhófà pé, ‘Mú kí ó bá ọ padà wá sí ilé rẹ, kí ó lè jẹ oúnjẹ, kí ó sì mu omi.’” Àmọ́ Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ó tàn án jẹ.”—1 Ọba 13:11-18.

9. Kí ni Ìwé Mímọ́ sọ nípa àwọn ẹlẹ̀tàn èèyàn, ta ni wọ́n sì máa ń kó bá?

9 A ò mọ ohun tó mú kí àgbàlagbà wòlíì yẹn ṣohun tó ṣe o, àmọ́ irọ́ ló pa. Ó ṣeé ṣe kí bàbá yẹn ti fìgbà kan rí jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Àmọ́ lákòókò tá à ń sọ yìí, ńṣe ló ń ṣẹ̀tàn. Ìwé Mímọ́ bẹnu àtẹ́ lu irú ìwà bẹ́ẹ̀. (Ka Òwe 3:32.) Yàtọ̀ sí pé àwọn ẹlẹ̀tàn èèyàn máa ń ba àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà jẹ́, wọ́n tún máa ń fi tiwọn kó bá àwọn ẹlòmíì.

‘Ó Padà Bá Bàbá Àgbàlagbà Yẹn Lọ’

10. Kí ni wòlíì Ọlọ́run ṣe nígbà tí bàbá àgbàlagbà yẹn ní kó bá òun lọ sílé, kí ló sì tẹ̀yìn ẹ̀ yọ?

10 Ó yẹ kí wòlíì tó wá láti Júdà yẹn ti rí ọgbọ́n békebèke tí àgbàlagbà wòlíì yẹn ń ta. Ó yẹ kó bi ara rẹ̀ pé, ‘Kí nìdí tí Jèhófà á fi rán áńgẹ́lì sí ẹlòmíì táá sì wá sọ ohun tó yàtọ̀ sóhun tó sọ fún mi?’ Wòlíì yẹn ì bá ti sọ fún Jèhófà pé kó ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà kó yé òun dáadáa, àmọ́ Ìwé Mímọ́ ò sọ pé ó ṣohun tó jọ bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni “ó bá [bàbá àgbàlagbà yẹn] padà lọ kí ó lè jẹ oúnjẹ ní ilé rẹ̀ kí ó sì mu omi.” Ohun tó ṣe yẹn ò dùn mọ́ Jèhófà nínú. Lẹ́yìn tí wòlíì yẹn sì fẹ́ máa padà sí Júdà, kìnnìún kan rí i lójú ọ̀nà ó sì pa á. Àbí ẹ ò ríbi tó parí iṣẹ́ wòlíì tó ń ṣe sí!—1 Ọba 13:19-25. a

11. Àpẹẹrẹ rere wo ni Áhíjà fi lélẹ̀?

11 Áhíjà kò dà bíi wòlíì tó kú yẹn ní tirẹ̀. Òun ni Jèhófà ní kó lọ ta òróró oyè lé Jèróbóámù lórí. Ńṣe ni Áhíjà jẹ́ adúróṣinṣin títí tó fi darúgbó. Nígbà tí Áhíjà darúgbó débi tí kò fi ríran mọ́, Jèróbóámù rán ìyàwó rẹ̀ sí i láti lọ béèrè ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ọmọ wọn tó ń ṣàìsàn. Áhíjà ò bẹ̀rù láti sọ tẹ́lẹ̀ pé ọmọ Jèróbóámù máa kú. (1 Ọba 14:1-18) Ara ọ̀pọ̀ ìbùkún tí Áhíjà rí gbà ni pé ó láǹfààní láti lọ́wọ́ sí ohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní ìmísí. Bíi báwo? Ìwé tí Áhíjà kọ wà lára ibi tí Ẹ́sírà àlùfáà ti rí ìsọfúnni tó kọ sílẹ̀.—2 Kíró. 9:29.

12-14. (a) Ẹ̀kọ́ wo la lè kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wòlíì tó wá láti Júdà yẹn? (b) Sọ àpẹẹrẹ ìdí tó fi yẹ ká máa ronú dáadáa ká sì máa gbàdúrà lórí ìmọ̀ràn tí àwọn alàgbà bá fún wa látinú Bíbélì.

12 Bíbélì ò sọ ìdí tí wòlíì tó wá láti Júdà kò fi béèrè lọ́wọ́ Jèhófà kó tó padà bá bàbá àgbàlagbà yẹn lọ láti jẹ àti láti mu lọ́dọ̀ rẹ̀. Ṣé kò lè jẹ́ pé ohun tó wu wòlíì yẹn láti gbọ́ gan-an ni bàbá yẹn sọ fún un? Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ìyẹn? Ó yẹ ká máa gbà láìṣiyèméjì pé ohun tí Jèhófà bá ní ká ṣe ló tọ́. Ó sì yẹ ká pinnu pé ọ̀rọ̀ Jèhófà la máa tẹ̀ lé láìro ohun yòówù tó lè tìdí ẹ̀ yọ.

13 Àwọn kan wà tó jẹ́ pé ohun tó wù wọ́n láti gbọ́ ni wọ́n máa ń fetí sí tá a bá ń fún wọn nímọ̀ràn. Bí àpẹẹrẹ, akéde kan lè rí iṣẹ́ kan tó máa gbà lára àkókò tó yẹ kó lò pẹ̀lú ìdílé rẹ̀ àtèyí tó yẹ kó lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ìjọba Ọlọ́run. Ó lè lọ bá alàgbà kan pé kó fóun nímọ̀ràn. Alàgbà náà lè sọ fún arákùnrin náà níbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé òun ò lẹ́tọ̀ọ́ láti bá a pinnu bó ṣe yẹ kó bójú tó ìdílé rẹ̀. Lẹ́yìn náà kó wá jẹ́ kó rí ewu tẹ̀mí tó wà nínú gbígba iṣẹ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ rí yẹn. Ṣóhun tí alàgbà yẹn fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nìkan ló máa rántí àbí ó máa ronú dáadáa lórí ohun tó sọ tẹ̀ lé e? Ó dájú pé ó yẹ kí arákùnrin náà pinnu ohun tó dáa fún òun jù lọ nípa tẹ̀mí.

14 Jẹ́ ká tún wo ipò míì tó lè jẹ yọ. Arábìnrin kan lè lọ bi alàgbà kan pé ṣé kí òun kó kúrò nílé ọkọ òun tó jẹ́ aláìgbàgbọ́. Ó dájú pé alàgbà náà á ṣàlàyé fún un pé òun fúnra rẹ̀ ló máa pinnu bóyá kó kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀ tàbí kó má ṣe kúrò. Alàgbà náà lè wá ṣàlàyé ìmọ̀ràn Bíbélì lórí ọ̀ràn ìpínyà fún un. (1 Kọ́r. 7:10-16) Ṣé arábìnrin náà yóò ronú jinlẹ̀ lórí ohun tí alàgbà náà sọ? Tàbí ó tiẹ̀ ti pinnu lọ́kàn ara rẹ̀ pé òun máa kó kúrò nílé ọkọ òun? Arábìnrin náà máa fi hàn pé ọlọgbọ́n lòun tó bá ronú tàdúràtàdúrà lórí ìmọ̀ràn Bíbélì kó tó ṣèpinnu.

Mọ̀wọ̀n Ara Rẹ

15. Kí la rí kọ́ látara àṣìṣe wòlíì Ọlọ́run?

15 Nǹkan míì wo la tún rí kọ́ látara àṣìṣe wòlíì tó wá láti Júdà? Òwe 3:5 sọ pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ.” Dípò kí wòlíì yẹn máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nìṣó bó ti ṣe ń ṣe bọ̀, ńṣe ló gbára lé òye tirẹ̀ lọ́tẹ̀ yìí. Àṣìṣe tó ṣe yẹn mú kó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ àti orúkọ rere tó ní pẹ̀lú Ọlọ́run. Ẹ ò rí i bí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i ṣe jẹ́ kó hàn kedere pé ó ṣe pàtàkì pé ká mọ̀wọ̀n ara wa, ká sì máa fi ìdúróṣinṣin sin Jèhófà!

16, 17. Kí ni yóò jẹ́ ká lè máa bá a nìṣó ní jíjẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà?

16 Ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan tó wà nínú ọkàn èèyàn lè mú kí ọkàn wa darí wa síbi tí kò tọ́. Bíbélì sọ pé: “Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà.” (Jer. 17:9) Ká bàa lè máa jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà nìṣó, a gbọ́dọ̀ máa bá a lọ ní títiraka ká lè bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀, ká sì sá fún ìwà ọ̀yájú àti ìdára-ẹni-lójú jù. A sì gbọ́dọ̀ gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, “èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.”—Ka Éfésù 4:22-24.

17 Ìwé Òwe 11:2 sọ pé: “Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.” Tá a bá mọ̀wọ̀n ara wa, tá a sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, a ò ní máa ṣe àṣìṣe tó lè kó bá wa. Bí àpẹẹrẹ, ìrẹ̀wẹ̀sì lè mú ká ṣi inú rò. (Òwe 24:10) Apá kan nínú iṣẹ́ ìsìn mímọ́ lè sú wa, ká wá máa rò pé a ti gbìyànjú tó láti ọdún yìí wá, pé ó yẹ káwọn míì náà máa bá a lọ níbi tá a ṣe é dé yìí. Tàbí a lè túbọ̀ fẹ́ gbádùn ìgbésí ayé táwọn èèyàn kà sí ìgbésí ayé gidi. Àmọ́, tá a bá ń ‘tiraka tokuntokun’ tá a sì ń ‘ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa,’ yóò máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn wa.—Lúùkù 13:24; 1 Kọ́r. 15:58.

18. Kí la lè ṣe tá ò bá mọ ìpinnu tó yẹ ká ṣe?

18 Nígbà míì, ó lè di dandan pé ká ṣèpinnu kan tó ṣòroó ṣe, ohun tó sì yẹ ká ṣe lè má tètè yé wa. Ṣé kò wá ní máa ṣe wá bíi pé ká tìtorí ìyẹn ṣe nǹkan tá a rò pé ó máa yanjú ìṣòro yẹn lójú ara wa? Nígbàkigbà tá a bá bá ara wa nírú ipò bẹ́ẹ̀, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́. Jákọ́bù 1:5 sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣaláìní ọgbọ́n, kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí òun a máa fi fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú ìwà ọ̀làwọ́.” Baba wa ọ̀run yóò fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ tá a nílò ká bàa lè máa ṣe ìpinnu tó dára.—Ka Lúùkù 11:9, 13.

Pinnu Pé Wàá Máa Jẹ́ Adúróṣinṣin Nìṣó

19, 20. Kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe?

19 Nǹkan ò rọrùn rárá fáwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lẹ́yìn tí Sólómọ́nì pa ìjọsìn tòótọ́ tì, ìyẹn sì dán ìdúróṣinṣin wọn wò gan-an ni. Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ juwọ́ sílẹ̀ lọ́nà kan tàbí òmíràn. Síbẹ̀, àwọn kan dúró ṣinṣin ti Jèhófà.

20 Ojoojúmọ́ là ń dojú kọ àwọn ìpinnu tó ń dán ìdúróṣinṣin wa wò. Àwa náà lè fi hàn pé a jẹ́ olóòótọ́. Ẹ jẹ́ ká máa jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà nígbà gbogbo bá a ṣe ń mú ọkàn wa ṣọ̀kan, ká sì jẹ́ kó dá wa lójú pé yóò máa bá a nìṣó ní bíbùkún àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀.—2 Sám. 22:26.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bíbélì ò sọ bóyá Jèhófà fa ikú àgbàlagbà wòlíì yẹn tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká fa ìfẹ́ ọrọ̀ tu kúrò lọ́kàn wa?

• Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà?

• Báwo ni ìmọ̀wọ̀n ara ẹni ṣe lè mú ká máa jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run nìṣó?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ǹjẹ́ ó nira fún ọ láti dúró ṣinṣin lójú àdánwò?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ṣé wàá ronú tàdúràtàdúrà lórí ìmọ̀ràn tí wọ́n bá fún ẹ látinú Bíbélì?