Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ o gbádùn kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí:

• Ìṣòro wo ló dojú kọ àwọn Kristẹni kan lẹ́yìn tí wọ́n ṣègbéyàwó, kí ló sì yẹ kí wọ́n ṣe?

Àwọn Kristẹni kan lè wá rí i pé ìwà ẹni táwọn fẹ́ kò bá tàwọn mu. Àmọ́, àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ pé ìkọ̀sílẹ̀ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu kò dára láti fi yanjú ìṣòro yìí, nítorí náà wọ́n ní láti ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí ìdílé wọn lè wà níṣọ̀kan.—4/15, ojú ìwé 17.

• Àwọn ìṣòro wo ni Kristẹni àgbàlagbà kan tó wà nílé ìtọ́jú àwọn arúgbó lè dojú kọ?

Ó lè jẹ́ pé ìpínlẹ̀ ìjọ tí wọn ò ti mọ ẹni náà ni ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó náà wà. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn yàtọ̀ sí tirẹ̀ ni wọ́n jọ ń gbé ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó, wọ́n sì lè fẹ́ mú un pé kó bá àwọn lọ́wọ́ sí ìgbòkègbodò ìsìn wọn. Àwọn tó jẹ́ ẹbí àgbàlagbà tó ń gbé ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó àti ìjọ tó wà ládùúgbò náà ní láti mọ àwọn ìṣòro tó ń dojú kọ àgbàlagbà náà kí wọ́n sì ràn án lọ́wọ́.—4/15, ojú ìwé 25 sí 27.

• Àwọn ohun mẹ́rin wo ló lè ran tọkọtaya lọ́wọ́ láti yanjú àwọn ìṣòro wọn?

Ẹ ṣètò àkókò tẹ́ ẹ jọ máa jíròrò ọ̀rọ̀ náà. (Oníw. 3:1, 7) Fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ. (Éfé. 4:25) Fetí sí ọkọ tàbí aya rẹ, kó o sì fi hàn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé o lóye ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. (Mát. 7:12) Ẹ fohùn ṣọ̀kan lórí ohun tó máa yanjú ìṣòro náà, kẹ́ ẹ sì jọ ṣiṣẹ́ lé e lórí. (Oníw. 4:9, 10)—5/1, ojú ìwé 10 sí 12.

• Nígbà tí Jésù rọ̀ wá láti gbàdúrà fún ìdáríjì àwọn gbèsè wa, àwọn gbèsè wo ló ní lọ́kàn?

Tá a bá fi ohun tó wà ní Mátíù 6:12Lúùkù 11:4, ó ṣe kedere pé kì í ṣe gbèsè owó ni Jésù ní lọ́kàn. Ẹ̀ṣẹ̀ ni ohun tí Jésù ń sọ nípa rẹ̀. Ó yẹ ká máa fara wé Ọlọ́run nípa mímúra tán láti dárí jini.—5/15, ojú ìwé 9.

• Àwọn ìgbìmọ̀ kéékèèké wo la pín àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí sí?

Ìgbìmọ̀ Olùṣekòkáárí; Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Òṣìṣẹ́; Ìgbìmọ̀ Ìṣèwéjáde; Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn; Ìgbìmọ̀ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́; Ìgbìmọ̀ Ìkọ̀wé.—5/15, ojú ìwé 29.

• Báwo ló ṣe dá wa lójú pé Ìkún-omi ọjọ́ Nóà kárí ayé?

Jésù gbà pé Ìkún-omi náà wáyé, ó sì kárí ayé. Àwọn ìkìlọ̀ tó wà nínú Bíbélì mú ká gbà pé Ìkún-omi tó kárí ayé ṣẹlẹ̀ lóòótọ́.—6/1, ojú ìwé 8.

• Ní Róòmù 1:24-32, Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ìwà kan, ṣé àwọn Júù ló ń bá wí ni àbí àwọn Kèfèrí?

Àlàyé yẹn lè bá àwọn méjèèjì mu. Àmọ́ ní pàtàkì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì tí wọ́n ti fi ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún ṣàìgbọràn sí Òfin Ọlọ́run ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń bá wí. Wọ́n mọ àṣẹ òdodo Ọlọ́run, àmọ́ wọn kò tẹ̀ lé àwọn àṣẹ náà.—6/15, ojú ìwé 29.

• Ibo ni Teli Árádì wà, kí sì nìdí tí ìlú náà fi ṣe pàtàkì?

Ìwọ̀ oòrùn Òkun Òkú ló wà, ní ìlú Ísírẹ́lì. Jíjẹ́ tí ìlú Árádì yìí jẹ́ ìlú olókè sì mú kó dá yàtọ̀. Àwọn walẹ̀walẹ̀ rí àkójọ àwọn àpáàdì tí wọ́n kọ nǹkan sí lára níbi òkè yìí. Àwọn orúkọ tó wà nínú Bíbélì wà lára àwọn kan nínú wọn. Àwọn àpáàdì náà sì fi hàn pé àwọn èèyàn ń lo orúkọ Ọlọ́run nínú àwọn àkọsílẹ̀ tí kì í ṣe ti ìsìn.—7/1, ojú ìwé 23 àti 24.

• Kí nìdí tí lílépa ohun tọ́wọ́ ẹni lè tẹ̀ fi ń jẹ́ kí ayọ̀ ẹni máa pọ̀ sí i?

Tó bá jẹ́ pé àwọn ohun tọ́wọ́ wa kò lè tẹ̀ là ń lé lójú méjèèjì, ńṣe la máa tọrùn bọ wàhálà. Àmọ́ ṣá o, a gbọ́dọ̀ tún ṣọ́ra ká má lọ máa fọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú ọ̀ràn wa, ká wá máa fi ohun tá a rò pé ó jẹ́ ìṣòro wa kẹ́wọ́, ká wá máa dẹwọ́ ju bó ṣe yẹ lọ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni.—7/15, ojú ìwé 29.

• Kí ló lè mú kó ṣòro fáwọn òbí láti bá àwọn ọ̀dọ́ sọ̀rọ̀?

Ìtìjú lè mú kí ọ̀dọ́ kan má máa bá òbí rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó sì lè jẹ́ pé ńṣe ni náà kò fẹ́ kẹ́nì kankan máa darí òun, tàbí pé ó fẹ́ kóun dá wà láìsí ìdíwọ́. Ohun tó lè ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti bá àwọn ọ̀dọ́ sọ̀rọ̀ ni pé kí wọ́n jọ máa fọ̀rọ̀-jomi-toro ọ̀rọ̀ kí wọ́n sì fòye mọ àwọn ohun tó wà lọ́kàn àwọn ọ̀dọ́ látinú ọ̀rọ̀ táwọn ọ̀dọ̀ náà bá ń sọ.—8/1, ojú ìwé 10 àti 11.