Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
September 15, 2008
Ẹ̀dà Tó Wà Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ TÁ A MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍ Ọ̀SẸ̀:
November 3-9
Jèhófà Jẹ́ “Olùpèsè Àsálà” Láyé Ìgbà Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì
OJÚ ÌWÉ 3
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 74, 44
November 10-16
Jèhófà Jẹ́ “Olùpèsè Àsálà” fún Wa
OJÚ ÌWÉ 7
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 153, 3
November 17-23
Máa Jẹ́ Kí Ìgbéyàwó Rẹ Jẹ́ “Okùn Onífọ́nrán Mẹ́ta”
OJÚ ÌWÉ 16
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 117, 173
November 24-30
OJÚ ÌWÉ 20
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 10, 191
Ohun Táwọn Àpilẹ̀kọ Tá a Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Dá Lé
Àpilẹ̀kọ fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ 1 àti 2 OJÚ ÌWÉ 3 sí 11
Àpilẹ̀kọ méjèèjì yìí dá lórí Sáàmù àádọ́rin, èyí tó sọ pé Jèhófà jẹ́ “Olùpèsè àsálà.” Àwọn àpilẹ̀kọ náà ṣàgbéyẹ̀wò bí Jèhófà ṣe pèsè àsálà fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì àti bó ṣe ń pèsè àsálà fún wa lóde òní.
Àpilẹ̀kọ fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ 3 OJÚ ÌWÉ 16 sí 20
Ó lè ṣòro fáwọn lọ́kọláya láti máa wà níṣọ̀kan lóde òní, kódà káwọn méjèèjì jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà. Àwọn àbá nípa báwọn tọkọtaya ṣe lè jẹ́ kí Jèhófà wà nínú ìgbéyàwó wọn wà nínú àpilẹ̀kọ yìí, ó sì tún sọ àwọn ohun tí wọ́n lè ṣe nígbà tí ìṣòro bá ń yọjú.
Àpilẹ̀kọ fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ 4 OJÚ ÌWÉ 20 sí 24
A ní láti yan èyí tá a fẹ́ níbẹ̀: Ṣé a máa fẹ́ gba ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ká sì jẹ́ kó máa darí wa, àbí ẹ̀mí ayé la óò jẹ́ kó máa darí wa? Àpilẹ̀kọ yìí sọ bá a ṣe lè rí ẹ̀mí Ọlọ́run gbà àti bá a ṣe lè dènà ẹ̀mí ayé, ó sì tún ṣàlàyé èyí tá a lè yàn nínú méjèèjì tó máa mú ká láyọ̀.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ:
Máa Kún fún Ìmọ̀ Pípéye Nípa Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tọkàntọkàn
OJÚ ÌWÉ 12
OJÚ ÌWÉ 25
Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù—Sin Ọlọ́run bí Ọlọ́run Ṣe Fẹ́
OJÚ ÌWÉ 26
OJÚ ÌWÉ 29
OJÚ ÌWÉ 32