Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Jẹ́ “Olùpèsè Àsálà” Láyé Ìgbà Tí Wọ́n Ń kọ Bíbélì

Jèhófà Jẹ́ “Olùpèsè Àsálà” Láyé Ìgbà Tí Wọ́n Ń kọ Bíbélì

Jèhófà Jẹ́ “Olùpèsè Àsálà” Láyé Ìgbà Tí Wọ́n Ń kọ Bíbélì

“Ọlọ́run, tètè gbé ìgbésẹ̀ nítorí mi. Ìwọ ni ìrànlọ́wọ́ mi àti Olùpèsè àsálà fún mi.”— SM. 70:5.

1, 2. (a) Nínú irú àwọn ipò wo làwọn olùjọsìn Jèhófà ti máa ń bẹ̀ ẹ́ pé kó ran àwọn lọ́wọ́? (b) Ìbéèrè wo ló jẹ yọ, ibo la sì ti lè rí ìdáhùn?

 BÀBÁ àti ìyá kan rìnrìn àjò lọ síbì kan láti lo àkókò ìsinmi wọn. Ṣàdédé ni wọ́n gbọ́ pé ọmọ wọn, ẹni ọdún mẹ́tàlélógún tó wà nílé ọkọ ti dàwátì, bọ́rọ̀ náà sì ṣe ṣẹlẹ̀ kò yé wọn rárá. Wọ́n fura pé àwọn oníṣẹ́ ibi kan ló wà nídìí ọ̀rọ̀ yìí. Bí wọ́n ṣe kó ẹrù wọn nìyẹn tí wọ́n mú ọ̀nà ilé pọ̀n. Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́. Àyẹ̀wò tí dókítà ṣe fi hàn pé arákùnrin kan tó jẹ́ ẹni ogún ọdún ní àrùn kan tó máa mú kó yarọ látòkèdélẹ̀. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ló gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́. Obìnrin kan tó ń dá tọ́mọ ń wá iṣẹ́ lójú méjèèjì, owó tó sì wà lọ́wọ́ rẹ̀ kò tó láti fi ra oúnjẹ tí òun àti ọmọbìnrin rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá máa jẹ. Obìnrin náà gbàdúrà sí Jèhófà tọkàntọkàn pé kó ran òun lọ́wọ́. Gbogbo èyí fi hàn pé táwọn olùjọsìn Jèhófà bá dojú kọ ìṣòro tó lágbára tàbí tí wọ́n bá wà nínú ìpọ́njú, ojú Jèhófà ni wọ́n máa ń wò fún ìrànlọ́wọ́. Ǹjẹ́ o ti bẹ Jèhófà rí pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ lásìkò tó o nílò nǹkan kan lójú méjèèjì?

2 Ṣùgbọ́n ìbéèrè pàtàkì kan rèé: Ṣé lóòótọ́ la lè retí pé kí Jèhófà dáhùn àdúrà tá a gbà pé kó ràn wá lọ́wọ́? Ìdáhùn tó ń fún ìgbàgbọ́ ẹni lókun wà ní Sáàmù àádọ́rin. Dáfídì ló kọ sáàmù tó ń mórí ẹni wú yìí. Olùjọ́sìn Jèhófà tó dúró ṣinṣin ni, ó sì dojú kọ ìṣòro àti àdánwò nígbà ayé rẹ̀. Kódà, a mí sí Dáfídì láti sọ nípa Jèhófà pé: “Ọlọ́run, . . . ìwọ ni ìrànlọ́wọ́ mi àti Olùpèsè àsálà fún mi.” (Sm. 70:5) Tá a bá ṣàgbéyẹ̀wò Sáàmù àádọ́rin dáadáa, a máa rí ìdí tó fi yẹ ká máa bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro, a ó sì gbẹ́kẹ̀ lé e pé yóò jẹ́ “Olùpèsè àsálà” fún wa.

‘Ìwọ Ni Olùpèsè Àsálà’

3. (a) Ní Sáàmù àádọ́rin, àdúrà ìrànwọ́ wo ni Dáfídì gbà ní kánjúkánjú? (b) Ọ̀rọ̀ wo ni Dáfídì sọ ni Sáàmù àádọ́rin tó fi hàn pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run?

3 Àdúrà pé kí Ọlọ́run má ṣe pẹ́ jù kó tó ran òun lọ́wọ́ ni Dáfídì fi bẹ̀rẹ̀ Sáàmù àádọ́rin, òun tó sì fi parí rẹ̀ náà nìyẹn. (Ka Sáàmù 70:1-5.) Dáfídì bẹ Jèhófà pé kó “ṣe kánkán,” kó sì “tètè gbé ìgbésẹ̀” láti ran òun lọ́wọ́. Ní ẹsẹ ìkejì sí ìkẹrin, Dáfídì tọrọ nǹkan márùn-ún lọ́wọ́ Jèhófà. Ọrọ̀ tó sì fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan ni, “kí.” Ọ̀rọ̀ yìí sì máa ń wà nínú gbólóhùn téèyàn máa ń sọ tó bá ń tọrọ nǹkan. Ẹ̀yìn náà ló wá sọ ohun tó fẹ́ kí Ọlọ́run ṣe fóun. Nǹkan mẹ́ta àkọ́kọ́ tí Dáfídì tọrọ ní í ṣe pẹ̀lú àwọn tó fẹ́ gbẹ̀mí ẹ̀. Dáfídì bẹ Jèhófà pé kó bá òun ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá òun kó sì jẹ́ kí ojú tì wọ́n nítorí ìwà burúkú wọn. Àdúrà ẹ̀bẹ̀ méjì tó tẹ̀ lé e ní í ṣe pẹ̀lú àwọn èèyàn Ọlọ́run. Dáfídì gbàdúrà pé kí ọ̀rọ̀ ayọ̀ máa bá gbogbo àwọn tó ń wá Jèhófà, kí wọ́n bàa lè máa gbé e ga. Níparí sáàmù yẹn, ohun tí Dáfídì sọ fún Jèhófà rèé: “Ìwọ ni ìrànlọ́wọ́ mi àti Olùpèsè àsálà fún mi.” Kíyè sí i pé Dáfídì kò sọ pé “Kí o jẹ́,” bí ìgbà tó ń tọrọ nǹkan míì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé “Ìwọ ni,” èyí tó fi hàn pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run. Dáfídì gbà gbọ́ pé Ọlọ́run á ran òun lọ́wọ́.

4, 5. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ lára Dáfídì ní Sáàmù àádọ́rin, kí ló sì yẹ kó dá àwa náà lójú?

4 Kí ni Sáàmù àádọ́rin jẹ́ ká mọ̀ nípa Dáfídì? Nígbà táwọn ọ̀tá Dáfídì ń lépa ẹ̀mí rẹ̀ lójú méjèèjì, kò fẹ́ láti gbèjà ara rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé yóò fìyà tó tọ́ jẹ àwọn ọ̀tá òun lásìkò tó tọ́. (1 Sám. 26:10) Ó dá Dáfídì lójú gan-an pé Jèhófà máa ń ran àwọn tó bá ń wá a lọ́wọ́, ó sì máa ń dá wọn nídè. (Héb. 11:6) Dáfídì gbà gbọ́ pé irú àwọn olùjọsìn Jèhófà tòótọ́ bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ máa yọ̀, kí wọ́n sì máa gbé Jèhófà ga, nípa sísọ fún àwọn èèyàn nípa ọlá ńlá Jèhófà.—Sm. 5:11; 35:27.

5 Bíi ti Dáfídì, ó yẹ kó dá wa lójú pé Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ àti “Olùpèsè àsálà” fún wa. Nítorí náà, tá a bá rí àdánwò lílekoko tàbí a nílò ìrànlọ́wọ́ Jèhófà lójú méjèèjì, a lè gbàdúrà pé kó tètè ràn wá lọ́wọ́. (Sm. 71:12) Ọ̀nà wo ni Jèhófà lè gbà dáhùn àdúrà wa pé kó ràn wá lọ́wọ́? Ká tó jíròrò ọ̀nà tí Jèhófà lè gbà dáhùn, ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà mẹ́ta tó gbà dá Dáfídì nídè, tó sì ràn án lọ́wọ́ nígbà tó nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ ní kíákíá.

Jèhófà Gba Dáfídì Lọ́wọ́ Àwọn Alátakò

6. Kí ló mú kí Dáfídì mọ̀ pé Jèhófà máa ń dá àwọn olódodo nídè?

6 Dáfídì kẹ́kọ̀ọ́ látinú àkọsílẹ̀ Bíbélì tí Jèhófà mí sí, tó wà nígbà ayé rẹ̀ pé àwọn olódodo lè gbọ́kàn lé Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́. Nígbà tí Jèhófà fi Àkúnya omi pa àwọn èèyàn tí kò ṣe ìfẹ́ rẹ̀ run, ó pa Nóà àti ìdílé rẹ̀ mọ́, nítorí pé wọ́n ṣèfẹ́ Ọlọ́run. (Jẹ́n. 7:23) Nígbà tí Jèhófà rọ̀jò iná àti imí ọjọ́ sórí àwọn olùgbé Sódómù àti Gòmórà tí wọ́n jẹ́ èèyàn burúkú, ó ran Lọ́ọ̀tì àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjì lọ́wọ́ láti sá àsálà. (Jẹ́n. 19:12-26) Nígbà tí Jèhófà pa Fáráò agbéraga àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ run nínú Òkun Pupa, ó dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀. (Ẹ́kís. 14:19-28) Abájọ tí Dáfídì fi sọ nínú sáàmù mìíràn tó kọ láti fi yin Jèhófà pé, ó jẹ́ “Ọlọ́run oníṣẹ́ ìgbàlà.”—Sm. 68:20.

7-9. (a) Kí ló mú kí Dáfídì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó lè gba òun? (b) Ta ni Dáfídì sọ pé ó gba òun lọ́wọ́ ikú?

7 Dáfídì tún ní ìdí pàtàkì kan tó fi gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá pé ó lè gba òun. Dáfídì ti fojú ara rẹ̀ rí i pé Jèhófà lè fi apá rẹ̀ tó jẹ́ “apá ayeraye” gba àwọn tó ń sìn ín. (Deu. 33:27, Bibeli Yoruba Atọ́ka) Ó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ tí Jèhófà gba Dáfídì lọ́wọ́ àwọn ‘ọ̀tá tí inú ń bí.’ (Sm. 18:17-19, 48) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan.

8 Nígbà táwọn obìnrin ilẹ̀ Ísírẹ́lì forin ṣàyẹ́sí Dáfídì fún jíjẹ́ tó jẹ́ akọni lójú ogun, Sọ́ọ̀lù Ọba bẹ̀rẹ̀ sí í jowú débi pé ẹ̀ẹ̀mejì ló sọ ọ̀kọ̀ láti fi gún Dáfídì. (1 Sám. 18:6-9) Àmọ́, Dáfídì yẹ ọ̀kọ̀ náà nígbà méjèèjì yẹn. Ṣé torí pé Dáfídì gbọ́n tó sì jẹ́ jagunjagun tó já fáfá tó mọ bí wọ́n ṣe ń yẹ nǹkan ni ọ̀kọ̀ yẹn kò ṣe bà á? Rárá o. Ohun tí Bíbélì sọ ni pé, “Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ̀.” (Ka 1 Sámúẹ́lì 18:11-14.) Nígbà tó yá, táwọn Filísínì kò rí Dáfídì pa bí Sọ́ọ̀lù ṣe rò, “Sọ́ọ̀lù sì wá rí i, ó sì mọ̀ pé Jèhófà wà pẹ̀lú Dáfídì.”—1 Sám. 18:17-30.

9 Ta ni Dáfídì sọ pé ó gba òun lọ́wọ́ ikú? Àkọlé Sáàmù kejìdínlógún sọ pé Dáfídì “sọ àwọn ọ̀rọ̀ orin yìí fún Jèhófà ní ọjọ́ tí Jèhófà dá a nídè . . . kúrò ní ọwọ́ Sọ́ọ̀lù.” Dáfídì fi bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀ kọ orin kan pé: “Jèhófà ni àpáta gàǹgà mi àti odi agbára mi àti Olùpèsè àsálà fún mi. Ọlọ́run mi ni àpáta mi. Èmi yóò sá di í.” (Sm. 18:2) Ǹjẹ́ mímọ̀ tá a mọ̀ pé Jèhófà lágbára láti dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè kò fún ìgbàgbọ́ wa lókun?—Sm. 35:10.

Jèhófà Gbé Dáfídì Ró Nígbà Tó Dùbúlẹ̀ Àìsàn

10, 11. Báwo la ṣe mọ ìgbà tó ṣeé ṣe kí Dáfídì ṣàìsàn tí Sáàmù kọkànlélógójì sọ nípa rẹ̀?

10 Dáfídì Ọba ṣàìsàn gidigidi nígbà kan, èyí tó wà lákọsílẹ̀ ní Sáàmù kọkànlélógójì. Àìsàn náà le débi pé, àwọn ọ̀tá rẹ̀ rò pé “kì yóò dìde mọ́.” (Sm. 41:7, 8) Ìgbà wo ni Dáfídì ṣàìsàn tó le tó bẹ́ẹ̀? Àwọn ipò tá a mẹ́nu kàn nínú sáàmù yìí lè jẹ́ ìgbà tí ìdààmú ọkàn bá Dáfídì nítorí pé ọmọ rẹ̀ Ábúsálómù fẹ́ fipá gbàjọba lọ́wọ́ rẹ̀.—2 Sám. 15:6, 13, 14.

11 Bí àpẹẹrẹ, Dáfídì sọ pé ọ̀rẹ́ òun kan tóun fọkàn tán, táwọn jọ máa ń jẹun da òun. (Sm. 41:9) Èyí lè rán wa létí ohun kan tó ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì. Nígbà tí Ábúsálómù ṣọ̀tẹ̀, Áhítófẹ́lì, agbaninímọ̀ràn tí Dáfídì fọkàn tán di ọ̀dàlẹ̀, ó sì dara pọ̀ mọ́ Ábúsálómù láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọba. (2 Sám. 15:31; 16:15) Tiẹ̀ fojú inú wo ọba tó dùbúlẹ̀ àìsàn, tí kò lókun láti dìde, tó mọ̀ pé àwọn ọlọ̀tẹ̀ èèyàn ló yí òun ká, tó sì mọ̀ pé wọ́n ń gbèrò ikú sóun kí wọ́n lè ráyè máa bá iṣẹ́ ibi wọn lọ.—Sm. 41:5.

12, 13. (a) Kí ló dá Dáfídì lójú? (b) Ọ̀nà wo ló ṣeé ṣe kí Ọlọ́run gbà fún Dáfídì lókun?

12 Ìgbẹ́kẹ̀lé tí Dáfídì ní nínú Olùpèsè àsálà kò yingin rárá. Nígbà tí Dáfídì ń sọ̀rọ̀ nípa ẹnì kan tó ń fòdodo sin Jèhófà, tẹ́ni náà sì wá ń ṣàìsàn, ó ní: “Ní ọjọ́ ìyọnu àjálù, Jèhófà yóò pèsè àsálà fún un. Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò gbé e ró lórí àga ìnàyìn ti àmódi; gbogbo ibùsùn rẹ̀ ni ìwọ yóò yí padà dájúdájú nígbà àìsàn rẹ̀.” (Sm. 41:1, 3) Dáfídì tún fi hàn níbí yìí pé òun gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. A lè rí èyí nínú ọ̀rọ̀ tó sọ, ó ní, “Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò.” Ó dá Dáfídì lójú pé Jèhófà yóò gba òun. Lọ́nà wo?

13 Dáfídì kò retí pé kí Jèhófà fi iṣẹ́ ìyanu wo òun sàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó dá Dáfídì lójú pé Jèhófà yóò ‘gbé òun ró,’ ìyẹn ni pé Jèhófà yóò dúró ti òun, yóò sì fún òun lókun nígbà tóun dùbúlẹ̀ àìsàn. Dájúdájú, Dáfídì nílò irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀. Láfikún sí àìsàn tó tán Dáfídì lókun, àwọn ọ̀tá tí wọ́n ń sọ ohun búburú nípa rẹ̀ ló yí i ká. (Sm. 41:5, 6) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Jèhófà fún Dáfídì lókun nípa mímú kó rántí àwọn ọ̀rọ̀ tó ń tuni nínú. Ó gbàfiyèsí pé, Dáfídì sọ pé: “Ìwọ ti gbèjà mi nítorí ìwà títọ́ mi.” (Sm. 41:12) Ohun míì tó tún ṣeé ṣe kó fún Dáfídì lókun ni, mímọ̀ tó mọ̀ pé Jèhófà ṣì ka òun sí olóòótọ́ láìwo ti ipò àárẹ̀ tóun wà àti ohun burúkú táwọn ọ̀tá rẹ̀ ń sọ. Níkẹyìn ara Dáfídì yá. Ǹjẹ́ kò fini lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà lè gbé àwọn tó ń ṣàìsàn ró?—2 Kọ́r. 1:3.

Jèhófà Pèsè Jíjẹ àti Mímu fún Dáfídì

14, 15. Ìgbà wo ni Dáfídì àtàwọn èèyàn rẹ̀ ṣaláìní oúnjẹ àti ohun mímu, ìrànwọ́ wo sì ni wọ́n rí gbà?

14 Nígbà tí Dáfídì di ọba Ísírẹ́lì, oúnjẹ tó dára jù àti ohun mímu tó dára jù ló ń jẹ. Ó tiẹ̀ máa ń pe àwọn èèyàn láti wá bá a jẹun. (2 Sám. 9:10) Àmọ́, ìgbà kan wà tí Dáfídì kò rí oúnjẹ àti ohun mímu. Nígbà tí Ábúsálómù gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú àwọn kan láti fipá gba ìjọba lọ́wọ́ Dáfídì, Dáfídì àtàwọn kan tí wọ́n dúró tì í gbágbáágbá fi Jerúsálẹ́mù sílẹ̀. Wọ́n sì sá lọ sí ilẹ̀ Gílíádì ní ìlà oòrùn Odò Jọ́dánì. (2 Sám. 17:22, 24) Nítorí pé àwọn ọ̀tá ń lé wọn, ṣe ni wọ́n ń sá láti ibì kan sí ibòmíràn. Nígbà tó yá, ebi àti òùngbẹ han Dáfídì àtàwọn èèyàn rẹ̀ léèmọ̀, ó sì rẹ̀ wọ́n tẹnutẹnu. Ibo ni wọ́n ti wá máa rí omi àti oúnjẹ nínú aginjù yẹn?

15 Nígbà tó yá, Dáfídì àtàwọn èèyàn rẹ̀ dé ìlú Máhánáímù. Níbẹ̀ ni wọ́n ti pàdé àwọn ọkùnrin mẹ́ta kan tí wọ́n jẹ́ onígboyà. Àwọn ni, Ṣóbì, Mákírù àti Básíláì. Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ṣe tán láti fẹ̀mí ara wọn wewu nípa gbígbárùkù ti Dáfídì, ẹni tí Jèhófà fi jẹ ọba. Nítorí tí Ábúsálómù bá dépò ọba pẹ́nrẹ́n, ó dájú pé yóò fi palaba ìyà jẹ gbogbo àwọn tó gbárùkù ti Dáfídì. Nígbà táwọn ọkùnrin adúróṣinṣin yìí mọ ohun tí Dáfídì àtàwọn èèyàn rẹ̀ nílò, wọ́n pèsè gbogbo rẹ̀ fún wọn pátá. Ara àwọn nǹkan tí wọ́n pèsè ni ibùsùn, àlìkámà, ọkà báálì, àyangbẹ ọkà, ẹ̀wà pàkálà, ẹ̀wà lẹ́ńtìlì, oyin, bọ́tà àti àgùntàn. (Ka 2 Sámúẹ́lì 17:27-29.) Láìsí àní-àní, Dáfídì á mọrírì ìdúróṣinṣin àrà ọ̀tọ̀ táwọn ọkùnrin yìí fi hàn àti bí wọ́n ṣe pèsè àwọn nǹkan tóun àtàwọn èèyàn rẹ̀ nílò. Ó dájú pé Dáfídì ò jẹ́ gbàgbé ohun tí wọ́n ṣe fún un yìí.

16. Ta lẹni náà gan-an tó pèsè oúnjẹ àti ohun mímu fún Dáfídì àtàwọn èèyàn rẹ̀?

16 Ta lẹni náà gan-an tó pèsè oúnjẹ àti ohun mímu fún Dáfídì àtàwọn èèyàn rẹ̀? Ó dá Dáfídì lójú pé Jèhófà máa ń bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀. Ó dájú pé Jèhófà lè fọwọ́ tọ́ ọkàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kan, kó sì mú kí wọ́n pèsè ìrànwọ́ fún ẹlòmíràn tí wọ́n jọ ń sìn-ín. Tí Dáfídì bá ronú jinlẹ̀ lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ nílẹ̀ Gílíádì, láìsí àní-àní, yóò rí inú rere àwọn ọkùnrin mẹ́ta yẹn gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tí Jèhófà gbà tọ́jú òun tìfẹ́tìfẹ́. Nígbà tí Dáfídì darúgbó, ó kọ̀wé pé: “Èmi ti jẹ́ ọ̀dọ́ rí, mo sì ti darúgbó, síbẹ̀síbẹ̀, èmi kò tíì rí i kí a fi olódodo [àti Dáfídì pàápàá] sílẹ̀ pátápátá, tàbí kí ọmọ rẹ̀ máa wá oúnjẹ kiri.” (Sm. 37:25) Ǹjẹ́ kò tuni nínú láti mọ̀ pé Jèhófà ti ṣe tán nígbà gbogbo láti pèsè ohun táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nílò fún wọn?—Òwe 10:3.

‘Jèhófà Mọ Bí A Ti Ń Dá Àwọn Ènìyàn Nídè’

17. Kí ni Jèhófà ti ṣe láìmọye ìgbà?

17 Kì í ṣe Dáfídì nìkan ni Jèhófà pèsè ọ̀nà àbáyọ fún láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn tún wà tí Jèhófà ṣe bẹ́ẹ̀ fún. Látìgbà ayé Dáfídì, àìmọye ìgbà ni Ọlọ́run ti ṣe ohun tó fi hàn pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pétérù sọ, pé: “Jèhófà mọ bí a ti ń dá àwọn ènìyàn tí ń fọkàn sin Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò.” (2 Pét. 2:9) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ méjì sí i.

18. Báwo ni Jèhófà ṣe gba àwọn èèyàn rẹ̀ là nígbà ayé Hesekáyà?

18 Ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni, nígbà táwọn ọmọ ogun Ásíríà sàga ti ìlú Júdà tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í halẹ̀ pé àwọn máa pa Jerúsálẹ́mù run. Hesekáyà Ọba gbàdúrà pé: “Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run wa, gbà wá là lọ́wọ́ rẹ̀, kí gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé lè mọ̀ pé ìwọ, Jèhófà, nìkan ṣoṣo ni Ọlọ́run.” (Aísá. 37:20) Ohun tó jẹ Hesekáyà lógún ni báwọn èèyàn á ṣe máa yin orúkọ Ọlọ́run. Jèhófà dáhùn àdúrà àtọkànwá yẹn. Lóru ọjọ́ kan péré, áńgẹ́lì kan ṣoṣo pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [185,000] àwọn ọmọ ogun àwọn ará Ásíríà. Bí Jèhófà ṣe gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ là nìyẹn.—Aísá. 37:32, 36.

19. Ìkìlọ̀ wo làwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ṣègbọràn sí tí wọn ò fi kú sínú àjálù tó ṣẹlẹ̀?

19 Nígbà tó ku ọjọ́ bíi mélòó kan kí wọ́n pa Jésù, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan tó fi ṣèkìlọ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọ́n wà ní Jùdíà. (Ka Lúùkù 21:20-22.) Ọ̀pọ̀ ọdún kọjá, kò sóhun tó ṣẹlẹ̀. Àmọ́ nígbà tó di ọdún 66 Sànmánì Kristẹni, ọ̀tẹ̀ kan táwọn Júù dì mú káwọn ọmọ ogun Róòmù kógun ja ìlú Jerúsálẹ́mù. Ọ̀gágun Cestius Gallus kó ọmọ ogun wá sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì gbẹ́ ìdí ògiri tẹ́ńpìlì. Àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n kàn dédé kúrò níbẹ̀. Àwọn Kristẹni olóòótọ́ lo àǹfààní yẹn láti sá lọ sórí àwọn òkè ńlá, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ fún wọn, kí wọ́n má bàa pa run. Nígbà tó di ọdún 70 Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọ ogun Róòmù padà wá sí Jerúsálẹ́mù. Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, wọn ò kúrò níbẹ̀ àfìgbà tí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run pátápátá. Àwọn Kristẹni tí wọ́n ṣègbọràn sí ìkìlọ̀ Jésù kò kú sínú àjálù yẹn.—Lúùkù 19:41-44.

20. Kí nìdí tá a fi lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé òun ni “Olùpèsè àsálà” fún wa?

20 Tá a bá ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Jèhófà máa ń ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́, yóò fún ìgbàgbọ́ wa lókun gan-an. Àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe sẹ́yìn mú ká gbẹ́kẹ̀ lé e. Ìṣòro yòówù kó máa bá wa fínra, bóyá lọ́wọ́lọ́wọ́ ni o tàbí èyí tó lè dojú kọ wá lọ́jọ́ iwájú, àwa náà lè fi gbogbo ọkàn wa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé òun ni “Olùpèsè àsálà” fún wa. Ọ̀nà wo ni Jèhófà lè gbà pèsè ọ̀nà àbáyọ fún wa? Báwo ni nǹkan ṣe wá rí fáwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí? A óò rí ìdáhùn nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Ìdánilójú wo ni Sáàmù àádọ́rin fún wa?

• Báwo ni Jèhófà ṣe gbé Dáfídì ró nígbà tó dùbúlẹ̀ àìsàn?

• Àwọn àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé Jèhófà lè gba àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn alátakò?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Jèhófà dáhùn àdúrà Hesekáyà