Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Kún fún Ìmọ̀ Pípéye Nípa Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tọkàntọkàn

Máa Kún fún Ìmọ̀ Pípéye Nípa Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tọkàntọkàn

Máa Kún fún Ìmọ̀ Pípéye Nípa Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tọkàntọkàn

GBOGBO àwa ìránṣẹ́ Jèhófà la fẹ́ kí Jèhófà tẹ́wọ́ gbà wá. Nítorí èyí, ó ń wù wá tọkàntọkàn láti mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i ká sì máa fi ìtara ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ wa. Àmọ́ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká rí ìṣòro kan, èyí táwọn Júù kan nígbà ayé rẹ̀ ní, tó sì lè wu ìgbàgbọ́ wa léwu. Ó ní: “Wọ́n ní ìtara fún Ọlọ́run; ṣùgbọ́n kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye.” (Róòmù 10:2) Èyí fi hàn kedere pé ìgbàgbọ́ wa àti ìjọsìn wa sí Jèhófà kò gbọ́dọ̀ jẹ́ torí ìfẹ́ rẹ̀ tó lágbára lọ́kàn wa nìkan. A tún nílò ìmọ̀ pípéye nípa Ẹlẹ́dàá wa àti ohun tó fẹ́.

Nínú lẹ́tà míì tí Pọ́ọ̀lù kọ, ó sọ pé ohun tó máa mú ká lè máa hùwà tínú Ọlọ́run dùn sí ni pé ká máa fi tọkàntọkàn wá ìmọ̀. Ó gbà á ládùúrà pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi “kún fún ìmọ̀ pípéye nípa” ìfẹ́ Ọlọ́run kí wọ́n lè “máa rìn lọ́nà tí ó yẹ Jèhófà fún ète wíwù ú ní kíkún” bí wọ́n ti “ń bá a lọ ní síso èso nínú iṣẹ́ rere gbogbo,” tí wọ́n sì “ń pọ̀ sí i nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run.” (Kól. 1:9, 10) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì gan-an pé ká ní “ìmọ̀ pípéye”? Kí sì nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìmọ̀ wa máa pọ̀ sí i?

Ó Ń Mú Ká Ní Ìgbàgbọ́

Orí ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run àti ìfẹ́ inú rẹ̀ ni ìgbàgbọ́ wa dúró lé. Tá ò bá ní irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Jèhófà á kàn dà bí ilé tá a fi itọ́ mọ tó jẹ́ pé ìrì lásán ni yóò wó o. Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé ká máa ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ sí Ọlọ́run pẹ̀lú “agbára ìmọnúúrò” wa ká sì ‘yí èrò inú wa padà.’ (Róòmù 12:1, 2) Ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti ṣohun tí Pọ́ọ̀lù sọ yẹn dáadáa.

Arábìnrin Ewa tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé lórílẹ̀-èdè Poland sọ pé: “Tí mi ò bá máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, ìmọ̀ tí mo ní nípa Jèhófà kò ní máa pọ̀ sí i. Kò ní pẹ́ tí ìwà Kristẹni á bẹ̀rẹ̀ sí í sọ nù mọ́ mi lára ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ìgbàgbọ́ tí mo ní nínú Ọlọ́run á bẹ̀rẹ̀ sí í dín kù, ìyẹn sì lè ba àjọṣe èmi àti Ọlọ́run jẹ́.” A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìyẹn ṣẹlẹ̀ sí wa láé! Kíyè sí ọkùnrin kan tó fi kún ìmọ̀ tó ní nípa Jèhófà tó sì tipa bẹ́ẹ̀ dẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Rẹ̀.

“Mo Mà Nífẹ̀ẹ́ Òfin Rẹ O!”

Orin ewì tẹ́ ẹ máa rí nínú Sáàmù kọkàndínlọ́gọ́fà nínú Bíbélì sọ bí òfin, ìránnilétí, àṣẹ àti ìpinnu ìdájọ́ Jèhófà ṣe rí lára onísáàmù náà. Ó kọ̀wé pé: “Èmi yóò fi ìfẹ́ni hàn fún àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ rẹ. . . . Àwọn ìránnilétí rẹ ni mo ní ìfẹ́ni fún.” Ó tún sọ pé: “Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o! Òun ni mo fi ń ṣe ìdàníyàn mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.”—Sm. 119:16, 24, 47, 48, 77, 97.

Àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ, bí “ìfẹ́ni” àti “ìdàníyàn” fi hàn pé ó máa ń ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kódà ó máa ń ní inú dídùn sí irú àṣàrò bẹ́ẹ̀. Àwọn gbólóhùn yẹn jẹ́ ká rí i kedere bí ìfẹ́ tí onísáàmù yẹn ní sí kíkẹ́kọ̀ọ́ òfin Ọlọ́run ṣe pọ̀ tó. Ìfẹ́ tó ní yẹn kì í kàn-án ṣe torí pé ohun tó wà nínú òfin Ọlọ́run wú u lórí púpọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ‘fi òfin yẹn ṣe ìdàníyàn ọkàn rẹ̀’ kí òye ọ̀rọ̀ Jèhófà túbọ̀ lè yé e dáadáa. A lè rí i látinú ẹ̀mí tí onísáàmù yẹn ní, pé ó fẹ́ láti mọ Ọlọ́run àti ìfẹ́ rẹ̀ kó sì lè ní ìmọ̀ tá a pọ̀ débi tó bá lè pọ̀ dé.

Ó ṣe kedere pé ìfẹ́ tí onísáàmù yìí ní fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti ọkàn rẹ̀ wá. Àwa náà lè bi ara wa pé: ‘Ṣé bí ìfẹ́ témi náà ní fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe jinlẹ̀ tó nìyẹn? Ṣé inú mi máa ń dùn láti ka Bíbélì lójoojúmọ́ kí n sì máa ṣàṣàrò lórí ohun tí mo kà? Ṣé mo sì máa ń sa gbogbo ipá mi láti ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí mo sì ń gbàdúrà kí n tó kà á?’ Tá a bá lè fi gbogbo ẹnu dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni sáwọn ìbéèrè yìí, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ẹ̀rí pé a ti ń “pọ̀ sí i nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run.”

Arábìnrin Ewa sọ pé: “Gbogbo ìgbà ni mo máa ń sapá láti mú kí ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí mò ń ṣe sunwọ̀n sí i. Látìgbà tí mo ti gba ìwé pẹlẹbẹ Wo ‘Ilẹ̀ Dáradára Náà,’ ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìgbà tí mo bá ń kẹ́kọ̀ọ́ ni mò ń lò ó. Mo túbọ̀ ń gbìyànjú láti wá ọ̀pọ̀ àlàyé sí i lórí ọ̀pọ̀ nǹkan nínú ìwé Insight on the Scriptures àtàwọn ìwé ìwádìí míì.”

Tún wo àpẹẹrẹ àwọn tọkọtaya tó ń jẹ́ Wojciech àti Małgorzata tí wọ́n ní ọ̀pọ̀ bùkátà ìdílé. Báwo ni wọ́n ṣe ń ráyè ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú bí ọwọ́ wọn ṣe dí tó yìí? Wọ́n sọ pé: “Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa ń rí i pé òun wáyè kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bí ti í wù ó mọ. Nígbà tá a bá wá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tàbí nígbà tá a bá ń fọ̀rọ̀ wérọ̀ nínú ilé, a máa ń sọ ohun tá a ti kà tó fà wá lọ́kàn mọ́ra tàbí tó lè ràn wá lọ́wọ́.” Ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó jinlẹ̀ ń fún wọn ní ayọ̀ tó pọ̀ jọjọ ó sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ‘kún fún ìmọ̀ pípéye.’

Ṣí Ọkàn Rẹ Payá Nígbà Tó O Bá Ń Kẹ́kọ̀ọ́

Àwa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni gbà gbọ́ pé ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:3, 4) Èyí jẹ́ ká rí i bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa ka Bíbélì, ká sì máa sapá láti jẹ́ kí ‘òye rẹ̀ yé wa.’ (Mát. 15:10) Ohun kan tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ kí òye ohun tá a bá kọ́ yé wa ni pé ká ṣí ọkàn wa payá nígbà tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́. Irú ẹ̀mí táwọn ará Bèróà ìgbà àtijọ́ ní nìyẹn, nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń wàásù ìhìn rere fún wọn, “wọ́n gba ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ìháragàgà ńláǹlà nínú èrò inú, tí wọ́n ń fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ ní ti pé bóyá bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí rí.”—Ìṣe 17:11.

Ṣé ìwọ náà ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn ará Bèróà tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Ṣé o máa ń fi ìháragàgà kẹ́kọ̀ọ́, tó ò kì í sì í fàyè gba àwọn ohun tí kò ṣe pàtàkì láti pín ọkàn rẹ níyà? Ẹnì kan tó jẹ́ Kristẹni ṣì lè gbìyànjú láti ṣe bí àwọn ará Bèróà, kódà bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé kì í fi bẹ́ẹ̀ gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ tẹ́lẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn kan wà tí kì í lè kàwé púpọ̀ mọ́ bọ́jọ́ ogbó bá ti ń dé sí wọn, àmọ́ kò yẹ kẹ́nì kan tó jẹ́ Kristẹni tòótọ́ gbà kí ìyẹn ṣẹlẹ̀ sóun. Bó ti wù kéèyàn dàgbà tó, èèyàn ṣì lè sapá láti kàwé láìsí pé ọkàn rẹ̀ ń pínyà. Bó o bá ṣe ń kàwé, máa fojú sọ́nà láti rí ohun kan tí wàá lè jíròrò pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì. Bí àpẹẹrẹ, ṣó o lè sọ ọ́ di àṣà rẹ láti máa bá ọkọ rẹ, aya rẹ tàbí ọ̀rẹ́ rẹ kan tẹ́ ẹ jọ jẹ́ Kristẹni jíròrò ohun tó o kà tàbi tó o rí kọ́ nígbà tó ò ń kẹ́kọ̀ọ́? Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ kí gbogbo ọkàn rẹ wà nínú ohun tó ò ń kọ́, á sì tún jẹ́ kó o lè ṣe àwọn míì láǹfààní.

Nígbàkugbà tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́, tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ẹ́sírà, ìránṣẹ́ Ọlọ́run nígbà àtijọ́, tó “múra ọkàn-àyà rẹ̀ sílẹ̀ láti ṣe ìwádìí nínú òfin Jèhófà.” (Ẹ́sírà 7:10) Báwo lo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? O lè wá ibì kan tó lọ́wọ̀ tí wàá ti lè ráyè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wá jókòó síbẹ̀ kó o gbàdúrà pé kí Jèhófà dárí rẹ kó sì fún ọ lọ́gbọ́n. (Ják. 1:5) Lẹ́yìn náà bi ara rẹ pé, ‘Àwọn nǹkan wo ló yẹ kí n rí kọ́ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ tí mo fẹ́ ṣe yìí?’ Bó o ṣe ń kàwé lọ, máa fọkàn wá àwọn kókò pàtàkì tó wà nínú ibi tó ò ń kà. O lè ṣàkọsílẹ̀ àwọn kókó yìí tàbí kó o sàmì sí apá ibi tó wù ọ́ jù lọ láti rántí. Ronú nípa bó o ṣe lè lo ohun tó wà níbẹ̀ nígbà tó o bá ń wàásù, nígbà tó o bá ń ṣèpinnu àti nígbà tó o bá ń fún àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ Kristẹni níṣìírí. Lópin ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, ṣàtúnyẹ̀wò ráńpẹ́ lórí ohun tó o ti kà. Èyí á mú kóhun tó o kọ́ wà lọ́kàn rẹ digbí.

Arábìnrin Ewa tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ bó ṣe máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ tiẹ̀, ó ní: “Nígbà tí mo bá ń ka Bíbélì, mo máa ń lo atọ́ka etí ìwé tó wà nínú Bíbélì, ìwé atọ́ka Watch Tower Publications Index àti ‘Watchtower Library’ on CD-ROM [Àkójọ Ìwé Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tá A Ṣe Sínú Àwo Pẹlẹbẹ Tá À Ń Fi Kọ̀ǹpútà Lò]. Mo máa ń ṣàkọsílẹ̀ àwọn ohun tí mo rí pé mo lè lò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́.”

Ọjọ́ pẹ́ táwọn kan ti ń gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó jinlẹ̀, wọ́n sì ti wá dẹni tó ti mọ́ lára láti máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. (Òwe 2:1-5) Síbẹ̀ wọ́n ní ọ̀pọ̀ bùkátà láti gbọ́, ó sì máa ń ṣòro fún wọn láti wá àyè tí wọ́n á fi máa ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́. Tó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn, àwọn àyípadà wo lo lè ṣe sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ?

Báwo Ni Màá Ṣe Máa Ráyè?

Ó ṣeé ṣe kó o gbà pé tó o bá ń gbádùn ohun kan, kò ní ṣòro rárá fún ẹ láti máa wáyè fún un. Ọ̀pọ̀ ti rí i pé ohun tó lè ran àwọn lọ́wọ́ táwọn á fi túbọ̀ máa gbádùn ìdákẹ́kọ̀ọ́ ni pé káwọn ní àfojúsùn kan táwọn á lé bá, bíi kíka Bíbélì látòkèdélẹ̀. Lóòótọ́, ó lè dà bí iṣẹ́ ńlá láti ka àwọn apá ibi tó jẹ́ ìtàn ìlà ìran tó máa ń gùn yẹn, tàbí àpèjúwe bí tẹ́ńpìlì àtijọ́ ṣe rí, tàbí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ta kókó tí kò sì jẹ mọ́ àwọn ohun tá a sábà máa ń rí. Àmọ́, gbìyànjú láti ṣe àwọn ohun tó máa jẹ́ kọ́wọ́ rẹ tẹ ohun tó ò ń lé yẹn. Bí àpẹẹrẹ, kó o tó ka ibì kan tó dà bíi pé ó ṣòroó lóye nínú Bíbélì, o lè kà nípa ìtàn tó so mọ́ àkọsílẹ̀ yẹn tàbí kó o kà nípa bá a ṣe lè lo ẹ̀kọ́ tó wà nínú rẹ̀. Irú àlàyé bẹ́ẹ̀ wà nínú ìwé “All Scripture Is Inspired of God and Beneficial.” Ìwé yìí wà ní àádọ́ta èdè báyìí.

Ó máa ń dùn mọ́ni téèyàn bá ń fojú inú wo nǹkan tó ń kà nínú Bíbélì. Èyí á jẹ́ kó dà bíi pé èèyàn ń rí àwọn ẹni tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn yìí nínú ọkàn ẹni, téèyàn sì ń rí báwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn ṣe ń ṣẹlẹ̀. Tó o bá tẹ̀ lé àwọn àbá mélòó kan tá a sọ yìí, ó ṣeé ṣe kó mú kó o túbọ̀ máa gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ kó o sì jèrè nínú rẹ̀. Èyí á sì mú kó túbọ̀ máa wù ẹ́ láti wáyè fún un. Á wá rọrùn láti jẹ́ kí Bíbélì kíkà ojoojúmọ́ mọ́ ẹ lára.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àbá tá a ti dá yìí lè ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, síbẹ̀ kí làwọn ìdílé tọ́wọ́ wọn máa ń dí lè ṣe? Ẹ ò ṣe kúkú wáyè gẹ́gẹ́ bí ìdílé láti jíròrò àwọn àǹfààní tẹ́ ẹ lè jẹ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé? Nínú ìjíròrò yẹn, ẹ lè rí àwọn àbá tó lè ràn yín lọ́wọ́. Ó lè jẹ́ pé ṣe ló yẹ kẹ́ ẹ máa jí nídàájì láti ka Bíbélì, ó sì lè jẹ́ pé àwọn ọjọ́ kan nìyẹn máa ṣeé ṣe. Ìjíròrò yẹn tún lè jẹ́ kẹ́ ẹ rí apá ibi tó yẹ kẹ́ ẹ ti ṣàtúnṣe nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìdílé yín. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìdílé kan ti rí i pé ohun tó máa ṣàǹfààní fáwọn ni pé káwọn máa jíròrò ẹsẹ ojoojúmọ́ tàbí káwọn ka Bíbélì pa pọ̀ lẹ́yìn oúnjẹ. Kó tó di pé ẹnikẹ́ni ń palẹ̀ mọ́ tàbí kó lọ ṣe nǹkan míì, gbogbo ìdílé á lo bí ìṣẹ́jú mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún láti jíròrò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọjọ́ yẹn tàbí kí wọ́n ka Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. Ó lè má rọrùn lákọ̀ọ́kọ́, àmọ́ kò ní pẹ́ tó fi máa mọ́ gbogbo ìdílé lára tí wọ́n á sì wá rí i pé ó ń dùn mọ́ àwọn.

Wojciech àti Małgorzata ṣàlàyé ohun tó ran ìdílé wọn lọ́wọ́, wọ́n ní: “Nígbà kan, àwọn nǹkan tí kò ṣe pàtàkì là ń fi gbogbo àkókò wa ṣe. La bá pinnu pé a óò dín kù lára àkókò tá à ń lò nídì fífi lẹ́tà ránṣẹ́ sáwọn èèyàn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. A tún dín àkókò tá a fi ń ṣe eré ìnàjú kù a sì wá pinnu iye àkókò tí a ó fi máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ tó jinlẹ̀.” Ó dájú pé ìdílé yìí ò kábàámọ̀ ohun tí wọ́n ṣe. Tí ìdílé tiyín náà bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó rí i pé ẹ ò ní kábàámọ̀ rẹ̀.

Èrè Wà Nínú Kíkún fún Ìmọ̀ Pípéye!

Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jinlẹ̀ lè so “èso nínú iṣẹ́ rere gbogbo.” (Kól. 1:10) Nígbà tó bá ń so irú èso yẹn nínú ìgbésí ayé rẹ, ìtẹ̀síwájú rẹ á fara hàn kedere sí gbogbo èèyàn. Wàá jẹ́ ẹni tẹ̀mí tó máa ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ òye òtítọ́. Àwọn ìpinnu rẹ á bọ́gbọ́n mu, wàá sì lè máa fáwọn èèyàn ní ìmọ̀ràn tó yẹ. Àṣejù ò ní wọ ọ̀ràn rẹ bíi tàwọn tóye ò yé. Lékè gbogbo rẹ̀, wàá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Wàá túbọ̀ mọrírì àwọn ìlànà rẹ̀, èyí á sì hàn nínú bó o ṣe ń sọ fáwọn ẹlòmíì nípa rẹ̀.—1 Tím. 4:15; Ják. 4:8.

Láìwo ti ọjọ́ orí rẹ tàbí ìrírí rẹ, sa gbogbo ipá rẹ láti máa rí ìdùnnú nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kó o sì máa ṣí ọkàn rẹ payá nígbà tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀. Ní ìdánílójú pé Jèhófà kò ní gbàgbé ìsapá rẹ. (Héb. 6:10) Ó sì máa rọ̀jò ìbùkún rẹ̀ lé ọ lórí.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]

TÁ A BÁ ‘KÚN FÚN ÌMỌ̀ PÍPÉYE’. . .

A óò fún ìgbàgbọ́ wa nínú Ọlọ́run lágbára, a ó sì máa rìn lọ́nà tó yẹ Jèhófà.—Kól. 1:9, 10

A óò ní ìjìnlẹ̀ òye, a ó sì lè máa lo ìfòyemọ̀, a óò tún máa ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání.—Sm. 119:99

Inú wa yóò túbọ̀ máa dùn bá a ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jèhófà.—Mát. 28:19, 20

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Ó lè má rọrùn láti rí ibi tó lọ́wọ̀ tí wàá ti lè ráyè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ téèyàn bá ṣe nírú ibi bẹ́ẹ̀ máa ń gbádùn mọ́ni

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Báwọn ìdílé kan ṣe máa ń ṣe rèé, gbàrà tí wọ́n bá ti jẹun tán ni wọ́n máa ń ka Bíbélì pa pọ̀