Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wíwàásù ní Ọjà

Wíwàásù ní Ọjà

Wíwàásù ní Ọjà

NÍGBÀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà nílùú Áténì, ojoojúmọ́ ló máa ń lọ wàásù ìhìn rere nípa Jésù ní ọjà. (Ìṣe 17:17) Ìdí tí Pọ́ọ̀lù fi máa ń lọ wàásù ní ọjà Áténì ni pé, ibẹ̀ làwọn èèyàn ìlú Áténì sábà máa ń wà jù.

Ní nǹkan bí ẹgbàá [2,000] ọdún lẹ́yìn náà, àwa èèyàn Jèhófà lónìí ṣì máa ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní ọjà, nítorí pé a máa ń rí ọ̀pọ̀ èèyàn wàásù fún níbẹ̀. Irú ọjà bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ ọ̀wọ́ àwọn ilé ìtajà tàbí ṣọ́ọ̀bù ẹnì kan. Báwọn Ẹlẹ́rìí kan ṣe ń ṣe é ni pé, wọ́n á tọrọ àyè lọ́wọ́ ẹni tó ni ilé ìtajà tàbí ẹni tó jẹ́ ọ̀gá níbẹ̀, wọ́n á wá kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sórí tábìlì tàbí sínú ìsọ̀ kékeré tí wọ́n ṣe káwọn tó ń kọjá lè máa rí àwọn ìwé náà.

Ìrírí kan nìyí. Àwọn ará pàtẹ àwọn ìwé wa lọ́nà tó fani mọ́ra síbi ilé ìtajà ńlá kan ní ìpínlẹ̀ New Jersey lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, wọ́n sì kọ àkọlé kan síbẹ̀ pé, “Ohun Tó Lè Mú Ìdílé Ẹni Tòrò.” Lọ́jọ́ kan ṣoṣo, ìwé mẹ́tàléláàádọ́jọ [153] ní oríṣi èdè mẹ́fà làwọn èèyàn gbà.

Obìnrin kan tó wá síbi ìsọ̀ náà fetí sílẹ̀ dáadáa sí àlàyé tí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí náà ṣe fún un. Obìnrin náà gbà pé, ó ṣe pàtàkì pé káwa àti ìdílé wa máa fi ti Ọlọ́run ṣáájú. Ó wá gba àwọn ìwé yìí: Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà, Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé àti Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́.

Nígbà tó dọwọ́ ọ̀sán, ọkùnrin kan gba ẹ̀gbẹ́ ibi tí wọ́n pàtẹ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà sí bó ṣe fẹ́ wọ ṣọ́ọ̀bù kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibẹ̀. Ó wá ń wo ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé. Arábìnrin tó wà nínú ìsọ̀ náà kíyè sí i pé ọkùnrin náà nífẹ̀ẹ́ sí ìwé yẹn. Ó wá bi í pé: “Ṣé ẹ rí èyí tó wù yín nínú àwọn ìwé yìí ni?” Ọkùnrin náà sì forí dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni, ó wá tọ́ka sí ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé. Bó ṣe fẹ́ mú un, arábìnrin yẹn fi lé e lọ́wọ́. Ó sọ pé ọmọ mẹ́ta lòun ní. Bí wọ́n sì ṣe ń bá ìjíròrò yẹn lọ, ó sọ pé òun máa ń ní ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ náà lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀. Àwọn méjì tó dàgbà jù nínú àwọn ọmọ náà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ogun ọdún. Ó wo ìwé náà gààràgà, ó sì ní ó máa rọrùn gan-an fóun láti lo ìwé náà gẹ́gẹ́ bí atọ́nà nínú àwọn ìjíròrò ìdílé àwọn. Arábìnrin náà tún fi ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé hàn án, ó sì fi dá a lójú pé òun àti ìyàwó rẹ̀ á rí ìmọ̀ràn tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú ìwé yẹn nígbà tí wọ́n bá láwọn ìpinnu láti ṣe nínú ìdílé wọn. Ọkùnrin náà dúpẹ́ lọ́wọ́ arábìnrin yẹn fún àwọn ohun tó sọ fún un, ó sì fi ọrẹ ṣètìlẹ́yìn, ó sì tún gbà pé kí Ẹlẹ́rìí kan máa wá kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́.

Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù táwọn Ẹlẹ́rìí náà ṣe ní ilé ìtajà yẹn ṣe rí lára wọn? Arábìnrin kan sọ pé: “Mo gbádùn ọ̀nà tá a gbà wàásù yìí gan-an ni. Ó ti lọ wà jù!” Arábìnrin mìíràn ní: “Jèhófà sọ pé a óò wàásù ìhìn rere náà dé apá ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé. Lónìí, tá a wàásù ní ilé ìtajà tó wà ládùúgbò Paramus, ní New Jersey yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn látinú onírúurú èdè ló gbọ́ ìhìn rere náà. Inú mi dùn gan-an pé mo wà lára àwọn tó wàásù ní ilé ìtajà yìí. Gbogbo àwọn tó sì kópa nínú rẹ̀ ló láyọ̀, àfi bíi pé ká má padà sílé.”

Ǹjẹ́ ìwọ náà lè ronú onírúurú ọ̀nà míì tó o tún lè gbà wàásù ìhìn rere? Lóòótọ́, ìwàásù ilé-dé-ilé ni olórí ọ̀nà tá à ń gbà mú ìhìn rere dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn. (Ìṣe 20:20) Àmọ́, ṣé o tún lè ronú nípa wíwàásù ní ọjà tàbí àwọn ilé ìtajà ńlá?