Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé O Ń Mú Ipò Iwájú Nínú Bíbu Ọlá Fáwọn Èèyàn?

Ṣé O Ń Mú Ipò Iwájú Nínú Bíbu Ọlá Fáwọn Èèyàn?

Ṣé O Ń Mú Ipò Iwájú Nínú Bíbu Ọlá Fáwọn Èèyàn?

“Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.”—RÓÒMÙ 12:10.

1. Kí ni nǹkan tí ò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ mọ́ ní ọ̀pọ̀ ibi láyé?

 LÁWỌN ibì kan, àṣà wọn ni pé káwọn ọmọdé máa kúnlẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ nígbà tí wọ́n bá wà lọ́dọ̀ àwọn àgbàlagbà. Nípa báyìí, orí wọn ò ní yọ sókè ju tàwọn àgbàlagbà lọ. Láwọn ibi tá à ń sọ yìí, wọ́n tún kà á sí ìwà àrífín pé kí ọmọdé kọ ẹ̀yìn sí àgbàlagbà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni onírúurú èèyàn tí àṣà wọn yàtọ̀ síra gbà ń bọ̀wọ̀ fún ara wọn, bí wọ́n ṣe ń bọ̀wọ̀ fún ara wọn yìí rán wa létí Òfin Mósè. Ara àṣẹ tó wà nínú Òfin náà ni pé: “Kí o dìde dúró níwájú orí ewú [tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀], kí o sì fi ìgbatẹnirò hàn fún arúgbó.” (Léf. 19:32) Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé ní ọ̀pọ̀ ibi, àwọn èèyàn kì í sábàá bọlá fún ara wọn mọ́. Kódà, ìwà ọ̀yájú ló gbòde kan lónìí.

2. Àwọn wo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ká máa bọlá fún?

2 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ka bíbọlá fúnni sí nǹkan pàtàkì. Ó sọ fún wa pé ká máa bọlá fún Jèhófà àti Jésù. (Jòh. 5:23) Ó tún pa á láṣẹ fún wa láti máa bọlá fún ara wa nínú ìdílé, fún àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni àti fún àwọn kan tí wọn kì í ṣe Kristẹni. (Róòmù 12:10; Éfé. 6:1, 2; 1 Pét. 2:17) Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé a ń bọlá fún Jèhófà? Báwo la ṣe lè bu ọlá tàbí ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fáwọn arákùnrin àti arábìnrin wa? Ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn ìbéèrè yìí àtàwọn míì tó tan mọ́ ọn.

Máa Bọlá fún Jèhófà àti Orúkọ Rẹ̀

3. Ọ̀nà pàtàkì wo la lè gbà máa bọlá fún Jèhófà?

3 Ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà máa bọlá fún Jèhófà ni pé ká máa bọ̀wọ̀ tó yẹ fún orúkọ rẹ̀. Ó ṣe tán, “ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀” la jẹ́. (Ìṣe 15:14) Ká sòótọ́, àǹfààní ńlá la ní láti máa jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè. Wòlíì Míkà sọ pé: “Gbogbo àwọn ènìyàn, ní tiwọn, yóò máa rìn, olúkúlùkù ní orúkọ ọlọ́run tirẹ̀; ṣùgbọ́n àwa, ní tiwa, yóò máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.” (Míkà 4:5) Bá a ṣe ń “rìn ní orúkọ Jèhófà” ni pé à ń sapá láti máa ṣe ohun tá máa gbé Jèhófà àti orúkọ rẹ̀ ga lójoojúmọ́. Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe rán àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù létí, bá ò bá hùwà tó bá ìhìn rere tá a ń wàásù mu, orúkọ Ọlọ́run lè di èyí tí wọ́n “sọ̀rọ̀ òdì” sí, ìyẹn ni pé á di ohun tí wọ́n tàbùkù sí.—Róòmù 2:21-24.

4. Ojú wo lo fi ń wo àǹfààní tó o ní láti máa jẹ́rìí nípa Jèhófà?

4 A tún ń bọlá fún Jèhófà nípa iṣẹ́ ìjẹ́rìí tá à ń ṣe. Jèhófà ké sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé àtijọ́ pé kí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́rìí òun, àmọ́ wọ́n kọ̀. (Aísá. 43:1-12) Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń kẹ̀yìn sí Jèhófà, tí wọ́n sì máa ń “ṣe ohun tí ó dun Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.” (Sm. 78:40, 41) Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, orílẹ̀-èdè náà pàdánù ojú rere Jèhófà pátápátá. Ṣùgbọ́n àwa lónìí mọrírì àǹfààní tá a ní láti máa jẹ́rìí nípa Jèhófà àti láti sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ̀. Ìdí tá a fi ń ṣe èyí ni pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì wù wá kí orúkọ rẹ̀ di mímọ́. Kí ló lè mú kí iṣẹ́ ìwàásù má wù wá, níwọ̀n bá a ti mọ òtítọ́ nípa Baba wa ọ̀run àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe? Bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ló ṣe rí lára tiwa náà lónìí. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àìgbọ́dọ̀máṣe wà lórí mi. Ní ti gidi, mo gbé bí èmi kò bá polongo ìhìn rere!”—1 Kọ́r. 9:16.

5. Báwo ni níní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà àti bíbọ̀wọ̀ fún un ṣe wọnú ara wọn?

5 Dáfídì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Sáàmù sọ pé: “Àwọn tí ó mọ orúkọ rẹ yóò sì gbẹ́kẹ̀ lé ọ, nítorí tí ìwọ, Jèhófà, kì yóò fi àwọn tí ń wá ọ sílẹ̀ dájúdájú.” (Sm. 9:10) Bá a bá mọ Jèhófà lóòótọ́, tá a sì bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ̀ nítorí ohun tí orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí, a óò gbẹ́kẹ̀ lé e báwọn adúróṣinṣin ìránṣẹ́ rẹ̀ àtijọ́ náà ti ṣe. Ìgbẹ́kẹ̀lé àti ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Jèhófà yìí tún jẹ́ ọ̀nà míì tá a lè máa gbà bọlá fún un. Wo bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe fi hàn pé gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà àti bíbọ̀wọ̀ fún un wọnú ara wọn. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé àtijọ́ kọ̀ láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó bi Mósè léèrè pé: “Yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ènìyàn yìí yóò máa hùwà àìlọ́wọ̀ sí mi, yóò sì ti pẹ́ tó tí wọn kì yóò ní ìgbàgbọ́ nínú mi fún gbogbo iṣẹ́ àmì tí mo mú ṣe láàárín wọn?” (Núm. 14:11) Níní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà jẹ́ àmì ọ̀wọ̀ fún un. Ńṣe là ń fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún Jèhófà bá a ṣe ń gbẹ́kẹ̀ lé e pé ó máa ṣọ́ wa, ó sì máa ràn wá lọ́wọ́ kódà nígbà àdánwò.

6. Kí ló ń mú ká ní ọ̀wọ̀ àtọkànwá fún Jèhófà?

6 Jésù fi hàn pé ọ̀wọ̀ fún Jèhófà gbọ́dọ̀ wá láti inú ọkàn. Nígbà tí Jésù ń bá àwọn kan tí kò fi gbogbo ọkàn wọn jọ́sìn Jèhófà sọ̀rọ̀, ó sọ ohun tí Jèhófà sọ, pé: “Àwọn ènìyàn yìí ń fi ètè wọn bọlá fún mi, síbẹ̀ ọkàn-àyà wọn jìnnà réré sí mi.” (Mát. 15:8) Ìfẹ́ àtọkànwá tá a ní fún Jèhófà ló ń mú ká bọ̀wọ̀ fún un tọkàntọkàn. (1 Jòh. 5:3) A ò sì gbàgbé ọ̀rọ̀ ìdánilójú tí Jèhófà sọ, pé: “Àwọn tí ń bọlá fún mi ni èmi yóò bọlá fún.”—1 Sám. 2:30.

Àwọn Tó Ń Múpò Iwájú Máa Ń Bọ̀wọ̀ Fáwọn Èèyàn

7. (a) Kí nìdí táwọn arákùnrin tó wà nípò àbójútó nínú ìjọ fi ní láti máa bu ọlá fáwọn tó wà lábẹ́ àbójútó wọn? (b) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe bọ̀wọ̀ fáwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́?

7 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ níyànjú pé: “Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.” (Róòmù 12:10) Ó yẹ káwọn arákùnrin tó wà nípò àbójútó nínú ìjọ máa fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ nípa ‘mímú ipò iwájú’ nínú bíbu ọlá fáwọn tó wà lábẹ́ àbójútó wọn. Ó yẹ káwọn tó wà nípò àbójútó máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù lórí ọ̀ràn yìí. (Ka 1 Tẹsalóníkà 2:7, 8.) Àwọn ará tó wà láwọn ìjọ tí Pọ́ọ̀lù bẹ̀ wò mọ̀ pé kò ní sọ pé káwọn ṣe àwọn nǹkan tóun alára ò ní fẹ́ ṣe. Pọ́ọ̀lù bọ̀wọ̀ fáwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́, ìdí nìyẹn táwọn náà fi bọ̀wọ̀ fún un. Ó dá wa lójú pé nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ pé, “Mo pàrọwà fún yín, ẹ di aláfarawé mi,” ọ̀pọ̀ fara wé e tinútinú nítorí àpẹẹrẹ àtàtà tó fi lélẹ̀.—1 Kọ́r. 4:16.

8. (a) Ọ̀nà pàtàkì wo ni Jésù gbà bọ̀wọ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀? (b) Báwo làwọn alábòójútó òde òní ṣe lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù?

8 Ọ̀nà míì tí alábòójútó kan lè gbà máa bọ̀wọ̀ fáwọn tó wà lábẹ́ àbójútó rẹ̀ ni pé kó máa jẹ́ kí wọ́n mọ ìdí tó fi ń fún wọn láwọn ìtọ́ni tó ń fún wọn. Tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jésù ló ń fara wé yẹn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n gbàdúrà kí Jèhófà rán ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ wá sínú ìkórè, ó sọ ìdí rẹ̀ fún wọn. Ó sọ pé: “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́. Nítorí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè láti rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.” (Mát. 9:37, 38) Bákan náà, nígbà tó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n ‘máa ṣọ́nà,’ ó sọ ìdí rẹ̀ fún wọn. Ó ní: “Nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín ń bọ̀.” (Mát. 24:42) Lọ́pọ̀ ìgbà tí Jésù bá ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe nǹkan kan, ó tún máa ń sọ ìdí tó fi yẹ kí wọ́n ṣe nǹkan ọ̀hún fún wọn. Ó tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òun fi ọ̀wọ̀ tiwọn wọ̀ wọ́n. Àpẹẹrẹ àtàtà mà léyìí fáwọn alábòójútó nínú ìjọ o!

Bọ̀wọ̀ fún Ìjọ Jèhófà àti Ìtọ́ni Tá À Ń Gbà Níbẹ̀

9. Ta là ń bọlá fún bá a ṣe ń bọ̀wọ̀ fún ìjọ Kristẹni tó kárí ayé àtàwọn aṣojú rẹ̀? Ṣàlàyé.

9 Tá a bá fẹ́ bọlá fún Jèhófà, a tún gbọ́dọ̀ máa bọlá fún ìjọ Kristẹni tó karí ayé àtàwọn aṣojú rẹ̀. Títẹ̀lé ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ tí ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ náà ń fún wa máa ń fi hàn pé à ń bọ̀wọ̀ fún ètò tí Jèhófà ṣe láti máa darí wa. Nínú ìjọ Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní, àpọ́sítélì Jòhánù ṣàkíyèsí pé ó yẹ kóun bá àwọn kan wí lórí bí wọn kò ṣe bọ̀wọ̀ fáwọn tí ẹ̀mí mímọ́ yàn sípò. (Ka 3 Jòhánù 9-11.) Ọ̀rọ̀ tí Jòhánù sọ fi hàn pé àwọn kan wà nígbà yẹn tí kò bọ̀wọ̀ fún àwọn alábòójútó, tí wọn ò sì ka ẹ̀kọ́ àti ìtọ́ni wọn sí. A dúpẹ́ pé ọ̀pọ̀ Kristẹni nígbà yẹn kì í ṣe irú èèyàn bẹ́ẹ̀. Ẹ̀rí fi hàn pé ẹgbẹ́ àwọn ará lódindi ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún àwọn tó ń mú ipò iwájú nígbà táwọn àpọ́sítélì ṣì wà láyé.—Fílí. 2:12.

10, 11. Fi Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé ìdí tó fi bójú mu pé káwọn kan wà nípò àṣẹ nínú ìjọ Kristẹni.

10 Àwọn kan ronú pé níwọ̀n bí Jésù ti sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé “arákùnrin ni gbogbo yín jẹ́,” kò yẹ káwọn kan wà nípò àṣẹ nínú ìjọ Kristẹni. (Mát. 23:8) Àmọ́, Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì sọ̀rọ̀ nípa ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin tí Ọlọ́run gbé àṣẹ lé lọ́wọ́. Ìtàn àwọn baba ńlá àwọn Hébérù, àwọn onídàájọ́ àtàwọn ọba àwọn Hébérù nígbà àtijọ́ fún wa ní ọ̀pọ̀ ẹ̀rí tó fi hàn pé Jèhófà máa ń lo àwọn èèyàn láti fúnni ní ìtọ́ni. Jèhófà máa ń fìyà jẹ àwọn èèyàn náà nígbà tí wọn ò bá bọlá tó yẹ fáwọn tó yàn.—2 Ọba 1:2-17; 2:19, 23, 24.

11 Lọ́nà kan náà, àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní gbà pé Ọlọ́run gbé àṣẹ lé àwọn àpọ́sítélì lọ́wọ́. (Ìṣe 2:42) Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni ní ìtọ́ni. (1 Kọ́r. 16:1; 1 Tẹs. 4:2) Síbẹ̀, òun náà fínnúfíndọ̀ tẹrí ba fáwọn tó ní àṣẹ lórí rẹ̀. (Ìṣe 15:22; Gál. 2:9, 10) Èyí fi hàn pé Pọ́ọ̀lù fojú tó tọ́ wo àwọn tó wà nípò àṣẹ nínú ìjọ Kristẹni.

12. Ẹ̀kọ́ méjì wo la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ tí Bíbélì fún wa nípa àwọn tó wà nípò àṣẹ?

12 Ọ̀nà méjì ni ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ pín sí. Àkọ́kọ́, ó bá Ìwé Mímọ́ mu bí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” nípasẹ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí tó ń ṣojú fún un, ṣe yan àwọn ọkùnrin kan sípò àbójútó, tí wọ́n sì tún wá yan àwọn kan lára àwọn alábòójútó yìí láti máa bójú tó àwọn alábòójútó bíi tiwọn. (Mát. 24:45-47; 1 Pét. 5:1-3) Èkejì ni pé, gbogbo wa, títí kan àwọn alábòójútó, ní láti máa bọlá fáwọn tí wọ́n ní àṣẹ lórí wa. Àwọn ọ̀nà díẹ̀ wo la wá lè máa gbà bọlá fáwọn tó wà nípò àbójútó nínú ìjọ Kristẹni tó kárí ayé?

Bá A Ṣe Lè Máa Bọ̀wọ̀ Fáwọn Alábòójútó Arìnrìn-Àjò

13. Báwo la ṣe lè bọ̀wọ̀ fáwọn alábòójútó arìnrìn-àjò tó ń ṣojú fún ìjọ Kristẹni?

13 Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àwa béèrè lọ́wọ́ yín, ẹ̀yin ará, pé kí ẹ ní ẹ̀mí ìkanisí fún àwọn tí ń ṣiṣẹ́ kára láàárín yín, tí wọ́n ń ṣe àbójútó yín nínú Olúwa, tí wọ́n sì ń ṣí yín létí; kí ẹ sì máa fún wọn ní ìkàsí tí ó ju àrà ọ̀tọ̀ lọ nínú ìfẹ́ nítorí iṣẹ́ wọn. Ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” (1 Tẹs. 5:12, 13) Dájúdájú, àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò wà lára àwọn tó yẹ ká kà sí “àwọn tí ń ṣiṣẹ́ kára.” Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa fún wọn ní “ìkàsí tí ó ju àrà ọ̀tọ̀ lọ.” Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe èyí ni pé ká máa fi tọkàntọkàn tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àti ọ̀rọ̀ ìyànjú wọn. Tírú àwọn alábòójútó bẹ́ẹ̀ bá fún wa ní ìtọ́ni látọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye, “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè” máa jẹ́ ká “múra tán láti ṣègbọràn.”—Ják. 3:17.

14. Báwo làwọn ìjọ ṣe máa ń fi hàn pé àwọn ní ọ̀wọ̀ àtọkànwá fáwọn alábòójútó arìnrìn-àjò, kí sì ló máa ń yọrí sí?

14 Tí wọ́n bá wá ní ká ṣe nǹkan lọ́nà tó yàtọ̀ sí bá a ṣe máa ń ṣe é tẹ́lẹ̀ ńkọ́? Láwọn ìgbà míì, tá a bá fẹ́ fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún wọn, ó lè gba pé ká fara mọ́ ohun tí wọ́n sọ, dípò sísọ nǹkan bí “Àwa kì í ṣe báyẹn níbí” tàbí, “Ìyẹn lè ṣiṣẹ́ láwọn ibòmíì o, àmọ́ kò lè ṣiṣẹ́ nínú ìjọ wa níbí.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ká máa sapá láti tẹ̀ lé ìtọ́ni náà. Tá a bá ń rántí nígbà gbogbo pé Jèhófà ló ni ìjọ àti pé Jésù Kristi ni Orí ìjọ, a ó máa tẹ̀ lé ìtọ́ni wọn. Tá a bá fi ayọ̀ gba ìtọ́ni tí alábòójútó arìnrìn-àjò kan fún wa, tá a sì fi í sílò nínú ìjọ wa, èyí jẹ́ ẹ̀rí pé a ní ọ̀wọ̀ àtọkànwá. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù yin àwọn ará tó wà ní Kọ́ríńtì fún bí wọ́n ṣe fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ṣègbọràn sí ìtọ́ni tí Títù, alàgbà tó wá bẹ̀ wọ́n wò, fún wọn. (2 Kọ́r. 7:13-16) Ó dá àwa náà lójú lónìí pé mímúra tán láti tẹ̀ lé ìtọ́ni táwọn alábòójútó arìnrìn-àjò fún wa ń ṣàlékún ayọ̀ tá à ń ní nínú iṣẹ́ ìwàásù wa.—Ka 2 Kọ́ríńtì 13:11.

“Bọlá fún Onírúurú Ènìyàn Gbogbo”

15. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tá a gbà ń bọ̀wọ̀ fún àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́?

15 Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Má ṣe fi àṣìṣe àgbà ọkùnrin hàn lọ́nà mímúná janjan. Kàkà bẹ́ẹ̀, pàrọwà fún un gẹ́gẹ́ bí baba, àwọn ọ̀dọ́kùnrin gẹ́gẹ́ bí arákùnrin, àwọn àgbà obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìyá, àwọn ọ̀dọ́bìnrin gẹ́gẹ́ bí arábìnrin pẹ̀lú gbogbo ìwà mímọ́. Bọlá fún àwọn opó tí wọ́n jẹ́ opó ní ti gidi.” (1 Tím. 5:1-3) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tipa báyìí rọ̀ wá pé ká máa bọlá fún gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ. Tí aáwọ̀ bá wáyé láàárín ìwọ àti arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ ńkọ́? Ṣé èyí wá ní kó o má bọ̀wọ̀ fún ẹni yẹn mọ́ ni? Àbí o lè tún èrò rẹ ṣe nípa wíwo àwọn ànímọ́ tẹ̀mí tí ìránṣẹ́ Ọlọ́run yẹn ní? Ní pàtàkì jù lọ, àwọn tó wà nípò àṣẹ gbọ́dọ̀ máa fi ọ̀wọ̀ àwọn ará wọ̀ wọ́n, kí wọ́n má ṣe máa “jẹ olúwa lé . . . agbo” lórí. (1 Pét. 5:3) Nínú ìjọ Kristẹni, tó jẹ́ pé ìfẹ́ àtọkànwá tó wà láàárín wa làwọn èèyàn fi ń dá wa mọ̀, onírúurú ọ̀nà ló wà tá a lè gbà máa bọlá fún ara wa.—Ka Jòhánù 13:34, 35.

16, 17. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa bọ̀wọ̀ fún àwọn tá à ń wàásù fún, àti àwọn alátakò pàápàá? (b) Báwo la ṣe lè máa “bọlá fún onírúurú ènìyàn gbogbo”?

16 Àmọ́, kì í ṣàwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni nìkan la máa ń bọ̀wọ̀ fún. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn Kristẹni nígbà ayé rẹ̀ pé: “Níwọ̀n ìgbà tí a bá ní àkókò tí ó wọ̀ fún un, ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn.” (Gál. 6:10) Lóòótọ́, ó lè ṣòro fún wa láti tẹ̀ lé ìlànà yẹn tí ẹnì kan tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí ọmọ iléèwé wa kan bá hùwà tí kò dáa sí wa. Nírú àkókò bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká rántí gbólóhùn yìí: “Má ṣe gbaná jẹ nítorí àwọn aṣebi.” (Sm. 37:1) Tá a bá fi ìmọ̀ràn yẹn sílò, a ó lè máa hùwà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sáwọn èèyàn, títí kan àwọn alátakò pàápàá. Bákàn náà, tá a bá ń rẹ ara wa sílẹ̀ nígbà tá a bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ó máa ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá gbogbo èèyàn lò pẹ̀lú “inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” (1 Pét. 3:15) Kódà ìrísí wa àti ìmúra wa lè fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fáwọn tá à ń wàásù fún.

17 Lákòótán, bóyá àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni ni nǹkan jọ dà wá pọ̀ ni o tàbí àwọn tí kì í ṣe Kristẹni, ẹ jẹ́ ká máa gbìyànjú láti fi ìmọ̀ràn yìí sílò, èyí tó sọ pé: “Ẹ máa bọlá fún onírúurú ènìyàn gbogbo, ẹ máa ní ìfẹ́ fún gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará, ẹ máa bẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ máa fi ọlá fún ọba.”—1 Pét. 2:17.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

Báwo la ṣe lè máa fi hàn pé à ń bọ̀wọ̀ tó tọ́ fún:

• Jèhófà?

• Àwọn alàgbà ìjọ àtàwọn alábòójútó arìnrìn-àjò?

• Ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ?

• Àwọn tó ò ń wàásù fún?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní bọ̀wọ̀ fún ìgbìmọ̀ olùdarí tó ń bójú tó wọn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Àwọn alàgbà tó wà jákèjádò ayé máa ń bọlá fáwọn alábòójútó arìnrìn-àjò tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí yàn