Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Lo Máa Yááfì Kó O Lè Ní Ìyè Àìnípẹ̀kun?

Kí Lo Máa Yááfì Kó O Lè Ní Ìyè Àìnípẹ̀kun?

Kí Lo Máa Yááfì Kó O Lè Ní Ìyè Àìnípẹ̀kun?

“Kí ni ènìyàn kan yóò fi fúnni ní pàṣípààrọ̀ fún ọkàn rẹ̀?”—MÁT. 16:26.

1. Kí nìdí tí Jésù kò fi gba ìbáwí tí Pétérù fún un?

 ÀPỌ́SÍTÉLÌ PÉTÉRÙ kọ́kọ́ rò pé etí òun ń tan òun jẹ ni! Jésù Kristi, Aṣáájú rẹ̀, ẹni tó fẹ́ràn bí ojú ń fi “àìfọ̀rọ̀-bọpo-bọyọ̀” sọ pé òun máa tó jìyà tóun sì máa kú. Kò sí iyè méjì pé ire tí Pétérù ń fẹ́ fún Jésù ló mú kó bá a wí lọ́nà mímúná nígbà tó fèsì, pé: “Ṣàánú ara rẹ, Olúwa; ìwọ kì yóò ní ìpín yìí rárá.” Ni Jésù bá kọ ẹ̀yìn sí Pétérù, ó sì yíjú sáwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù. Ó ṣeé ṣe káwọn náà ní irú èrò tí kò tọ́ tí Pétérù ní lọ́kàn yìí. Ó wá sọ fún Pétérù pé: “Dẹ̀yìn lẹ́yìn mi, Sátánì, nítorí kì í ṣe àwọn ìrònú Ọlọ́run ni ìwọ ń rò, bí kò ṣe ti ènìyàn.”—Máàkù 8:32, 33; Mát. 16:21-23.

2. Kí ni Jésù sọ tó jẹ́ ká mọ ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tòótọ́?

2 Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ tẹ̀ lé e jẹ́ kí Pétérù rí ìdí tí Jésù fi fèsì lọ́nà tó le báyẹn nígbà tó fún un ní ìbáwí mímúná. Jésù “pe ogunlọ́gọ̀ náà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀,” ó sì sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀, kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo. Nítorí ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ gba ọkàn rẹ̀ là yóò pàdánù rẹ̀; ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá pàdánù ọkàn rẹ̀ nítorí èmi àti ìhìn rere yóò gbà á là.” (Máàkù 8:34, 35) “Ọkàn” tí Jésù sọ níbí yìí túmọ̀ sí “ẹ̀mí.” Ó ṣe kedere pé kì í ṣe pé kò ní pẹ́ fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ nìkan ni, àmọ́ ó tún retí pé káwọn tó ń tẹ̀ lé òun náà ṣe tán láti fi ẹ̀mí wọn rúbọ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á jèrè jìgbìnnì.—Ka Mátíù 16:27.

3. (a) Àwọn ìbéèrè wo ni Jésù bi àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀? (b) Kí lohun tó ṣeé ṣe kí ìbéèrè kejì tí Jésù béèrè mú káwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ rántí?

3 Níbẹ̀ yẹn náà, Jésù bi àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ìbéèrè méjì kan tó ń múni ronú jinlẹ̀, ó ní: “Àǹfààní wo ni ó jẹ́ fún ènìyàn kan láti jèrè gbogbo ayé, kí ó sì pàdánù ọkàn rẹ̀? Ní ti gidi, kí ni ènìyàn kan yóò fi fúnni ní pàṣípààrọ̀ fún ọkàn rẹ̀?” (Máàkù 8:36, 37) Kò sẹ́nì kankan tí kò ní mọ ìdáhùn sí ìbéèrè àkọ́kọ́ yẹn. Kò sí àǹfààní kankan tí ẹni tó jèrè gbogbo ayé àmọ́ tó wá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ jẹ. Ìgbà tí ẹ̀mí wa bá lè lo dúkìá ni dúkìá lè wúlò fún wa. Nígbà tí Jésù béèrè ìbéèrè kejì pé: “Ní ti gidi, kí ni ènìyàn kan yóò fi fúnni ní pàṣípààrọ̀ fún ọkàn rẹ̀?,” ó ṣeé ṣe kó mú káwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ rántí ohun tí Sátánì sọ nígbà ayé Jóòbù, pé: “Ohun gbogbo tí ènìyàn bá sì ní ni yóò fi fúnni nítorí ọkàn rẹ̀.” (Jóòbù 2:4) Ó ṣeé ṣe káwọn kan lára àwọn tí kò sin Jèhófà rò pé òótọ́ lohun tí Sátánì sọ yìí. Ọ̀pọ̀ lè ṣe ohunkóhun, wọ́n lè tẹ òfin èyíkéyìí lójú, torí kí ẹ̀mí wọn má ṣáà ti bọ́. Àmọ́ ojú tí àwa Kristẹni fi ń wo nǹkan yàtọ̀ síyẹn.

4. Kí nìdí tí àwọn ìbéèrè Jésù fi ní ìtúmọ̀ tó túbọ̀ jinlẹ̀ fún àwa Kristẹni?

4 A mọ̀ pé Jésù kò wá láti wá fún wa ní ìlera tó jí pépé, ọrọ̀ àti ẹ̀mí gígùn nínú ayé ìsinsìnyí. Àmọ́ ó wá kó lè ṣí àǹfààní sílẹ̀ láti gbé títí láé nínú ayé tuntun, ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun yẹn sì lohun tá a kà sí pàtàkì gan-an. (Jòh. 3:16) Kristẹni kan máa lóye pé ohun tí ìbéèrè àkọ́kọ́ tí Jésù béèrè túmọ̀ sí ni, “Àǹfààní wo ni ó jẹ́ fún ènìyàn kan láti jèrè gbogbo ayé, kí ó sì pàdánù ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun tó ní?” Ìdáhùn ni pé, Kò sí àǹfààní kankan níbẹ̀. (1 Jòh. 2:15-17) Ká lè dáhùn ìbéèrè kejì tí Jésù béèrè, a lè bi ara wa léèrè pé, ‘Kí ni mo lè yááfì nísinsìnyí tó máa jẹ́ kí n nírètí tó dájú pé màá wà nínú ayé tuntun?’ Ìdáhùn wa sí ìbéèrè yẹn yóò hàn nínú ọ̀nà tá a gbà ń gbé ìgbésí ayé wa, ìyẹn sì máa fi hàn bí ìrètí yẹn ṣe fìdí múlẹ̀ lọ́kàn wa tó.—Fi wé Jòhánù 12:25.

5. Báwo la ṣe lè rí ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun gbà?

5 Àmọ́ o, Jésù ò sọ pé iṣẹ́ ọwọ́ wa ló máa fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun. Ẹ̀bùn ni ìwàláàyè jẹ́, títí kan èyí tó jẹ́ ọlọ́jọ́ kúkúrú tá a ní nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí pàápàá. Owó kò lè rà á, bẹ́ẹ̀ ni kò sóhun tá a lè ṣe tó lè mú kó di ẹ̀tọ́ wa. Ọ̀nà kan ṣoṣo tá a lè gbà rí ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun gbà ni pé ká ní “ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jésù” àti nínú Jèhófà tó jẹ́ “olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” (Gál. 2:16; Héb. 11:6) Síbẹ̀síbẹ̀, a gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ tó ń fi ìgbàgbọ́ wa hàn, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé “ìgbàgbọ́ láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ òkú.” (Ják. 2:26) Nítorí náà, tá a bá túbọ̀ ń ṣàṣàrò lórí ìbéèrè Jésù yẹn, a máa ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ohun tá a múra tán láti yááfì nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí àtàwọn ohun tá a múra tán láti ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ká lè fi hàn lóòótọ́ pé ìgbàgbọ́ wa kì í ṣe òkú.

‘Kristi Kò Ṣe Bó Ti Wù Ú’

6. Kí lohun tó ṣe pàtàkì jù lọ fún Jésù?

6 Kàkà kí Jésù máa fẹjú mọ́ àwọn ohun tí ọwọ́ rẹ̀ lè tẹ̀ nínú ayé ìgbà yẹn, àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù bẹ́ẹ̀ lọ ló gbájú mọ́, kò gbà kí ìfẹ́ láti gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ dẹ òun wò. Ó fi ọ̀pọ̀ nǹkan du ara rẹ̀, ó sì fi gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Dípò tí ì bá fi máa ṣe bó ti wù ú, ohun tó sọ ni pé: “Nígbà gbogbo ni mo ń ṣe ohun tí ó [wu Ọlọ́run].” (Jòh. 8:29) Àwọn nǹkan wo ni Jésù múra tán láti ṣe torí àtiwu Ọlọ́run?

7, 8. (a) Kí ni Jésù yááfì, báwo sì ni Ọlọ́run ṣe san án lẹ́san rere? (b) Ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa?

7 Nígbà kan, Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ọmọ ènìyàn . . . wá, kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, bí kò ṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́, kí ó sì fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mát. 20:28) Ṣáájú ìgbà yẹn, nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé láìpẹ́, òun máa ‘fi ọkàn òun fúnni,’ Pétérù sọ fún un pé kó ṣàánú ara rẹ̀. Síbẹ̀ Jésù ò yí ìpinnu rẹ̀ padà. Tinútinú ló fi fi ọkàn rẹ̀, ìyẹn ẹ̀mí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dà èèyàn pípé lélẹ̀ fún aráyé. Nítorí bí Jésù ṣe lo ìgbésí ayé rẹ̀ láìsí ìmọtara-ẹni-nìkan yìí, ọjọ́ ọ̀la tòun fúnra rẹ̀ náà dájú. Ọlọ́run jí i dìde, ó sì “gbé e ga sí ọwọ́ ọ̀tún” ara rẹ̀. (Ìṣe 2:32, 33) Ó wá tipa báyìí di àpẹẹrẹ àtàtà fún wa.

8 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni ní Róòmù nímọ̀ràn láti má “máa ṣe bí ó ti wù” wọ́n, ó sì rán wọn létí pé “Kristi pàápàá kò ṣe bí ó ti wu ara rẹ̀.” (Róòmù 15:1-3) Nígbà náà, ibo la lè fi ìmọ̀ràn àpọ́sítélì yìí sílò dé, àwọn nǹkan wo la sì lè yááfì láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi?

Jèhófà Ń Fẹ́ Ká Ṣe Gbogbo Ohun Tágbára Wa Gbé

9. Kí ni ìpinnu tí Kristẹni kan ṣe láti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí?

9 Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, Òfin Mósè sọ pé ẹni tó bá ní ẹrú kan tó jẹ́ Hébérù gbọ́dọ̀ dá a sílẹ̀ lómìnira lọ́dún keje ìsìnrú rẹ̀ tàbí lọ́dún Júbílì. Àmọ́ ṣá, ohun mìíràn wà tí ẹrú kan lè ṣe. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹrú kan wá nífẹ̀ẹ́ ọ̀gá rẹ̀, ó lè sọ pé òun fẹ́ máa jẹ́ ẹrú nílé ọ̀gá òun títí ayé. (Ka Diutarónómì 15:12, 16, 17.) Irú ìpinnu yẹn làwa náà ṣe nígbà tá a ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run. A fínnúfíndọ̀ gbà láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run dípò ohun tó wù wá. Ohun tá a ṣe yìí fi hàn pé a ní ìfẹ́ jíjinlẹ̀ fún Jèhófà, pé ó sì wù wá láti máa sìn ín títí ayé.

10. Ọ̀nà wo la gbà jẹ́ ohun ìní Ọlọ́run, báwo ló sì ṣe yẹ kí ìyẹn nípa lórí èrò àti ìṣe wa?

10 Tó bá jẹ́ pé o ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, tó o ti ń wàásù ìhìn rere, tó o sì ti ń lọ sípàdé ìjọ, a kí ọ pé o káre láé. A nígbàgbọ́ pé láìpẹ́, a wù ọ́ láti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, ìwọ náà á sì lè béèrè irú ìbéèrè tí ará Etiópíà kan bi Fílípì pé: “Kí ni ó dí mi lọ́wọ́ dídi ẹni tí a batisí?” (Ìṣe 8:35, 36) Àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run á dà bíi tàwọn Kristẹni tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí, pé: “Ẹ kì í ṣe ti ara yín, nítorí a ti rà yín ní iye kan.” (1 Kọ́r. 6:19, 20) Yálà ọ̀run ni ìrètí wa tàbí orí ilẹ̀ ayé, tá a bá ti ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, òun ni Olówó wa. Ẹ ò wa rí i bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká mú ìfẹ́ tara wa kúrò lọ́kàn wa, ká sì “dẹ́kun dídi ẹrú ènìyàn”! (1 Kọ́r. 7:23) Àǹfààní ńlá mà ló jẹ́ o, pé a jẹ́ ìránṣẹ́ adúróṣinṣin tí Jèhófà lè lò bó ṣe wù ú!

11. Ẹbọ wo ni Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n máa rú, kí sì lèyí túmọ̀ sí tá a bá fi wé ẹbọ tí wọ́n ń rú lábẹ́ Òfin Mósè?

11 Pọ́ọ̀lù gba àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ nímọ̀ràn pé: “Ẹ fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ pẹ̀lú agbára ìmọnúúrò yín.” (Róòmù 12:1) Ó ṣeé ṣe kí gbólóhùn yìí mú káwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Júù rántí àwọn ẹbọ tí wọ́n máa ń rú tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó di ọmọlẹ́yìn Jésù. Wọ́n ti ní láti mọ̀ pé lábẹ́ Òfin Mósè, ẹran tí wọ́n bá máa fi rúbọ lórí pẹpẹ Jèhófà gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tó dáa jù lọ láàárín àwọn tó kù. Èyíkéyìí tára rẹ̀ kò bá dá ṣáṣá kò ṣètẹ́wọ́gbà. (Mál. 1:8, 13) Bọ́rọ̀ ṣe rí náà nìyẹn tá a bá fi ara wa fún Ọlọ́run ní “ẹbọ ààyè.” A ń fún Jèhófà ní ohun tó dára jù lọ nínú ayé wa, kì í ṣe èyí tó ṣẹ́ kù lẹ́yìn tá a ti tẹ́ ìfẹ́ ara wa lọ́rùn tán. Nígbà tá a ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run, a ò ṣẹ́ ohunkóhun kù sẹ́yìn. A fún un ní “ọkàn” wa, ìyẹn ẹ̀mí wa títí kan okun wa, àwọn ohun ìní wa àti gbogbo agbára wa. (Kól. 3:23) Báwo ló ṣe yẹ kí èyí máa hàn nígbèésí ayé wa?

Máa Fọgbọ́n Lo Àkókò Rẹ

12, 13. Ọ̀nà wo la lè gbà fún Jèhófà ní ohun tó dára jù lọ?

12 Ọ̀nà kan tá a lè gbà fún Jèhófà ní ohun tó dáa jù ni pé ká máa fọgbọ́n lo àkókò wa. (Ka Éfésù 5:15, 16.) Àmọ́, ó gba pé ká máa kó ara wa níjàánu. Ayé yìí, pa pọ̀ pẹ̀lú àìpé tá a jogún, máa ń mú kó wù wá láti lo àkókò wa lórí kìkì ìgbádùn tara wa àtohun tó máa ṣe àwa nìkan láǹfààní. Lóòótọ́, “ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún,” tó fi mọ́ ìgbà ìgbafẹ́ àti ìgbà iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ táá jẹ́ ká lè ṣàwọn ojúṣe wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. (Oníw. 3:1) Síbẹ̀ náà, Kristẹni kan tó bá ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ ní láti rí i pé òun ò fì sápá kan jù. Ńṣe ló yẹ kó máa fọgbọ́n lo àkókò rẹ̀.

13 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ṣèbẹ̀wò sí ìlú Áténì, ó kíyè sí i pé, “gbogbo ará Áténì àti àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tí ń ṣàtìpó níbẹ̀ kì í lo àkókò tí ọwọ́ wọ́n dilẹ̀ fún nǹkan mìíràn bí kò ṣe fún sísọ ohun kan tàbí fífetísí ohun tí ó jẹ́ tuntun.” (Ìṣe 17:21) Lónìí náà pẹ̀lú, ọ̀pọ̀ máa ń fàkókò wọn ṣòfò. Lára ohun tó ń gbàkókò ẹni lónìí ni tẹlifíṣọ̀n, eré kọ̀ǹpútà àti Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ńṣe ni oríṣiríṣi nǹkan tó fẹ́ gba àkókò wa túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Tá a bá lọ gbà wọ́n láyè pẹ́nrẹ́n, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í pa ìmọ̀ Jèhófà tì. A tiẹ̀ lè wá máa wò ó pé ọwọ́ wa ti dí kọjá ká ráyè bójú tó “àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù,” ìyẹn àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ìjọsìn Jèhófà.—Fílí. 1:9, 10.

14. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká ronú jinlẹ̀ lé lórí?

14 Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́, bi ara rẹ pé, ‘Ṣé mo fi Bíbélì kíkà, ṣíṣàṣàrò àti gbígbàdúrà sínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ mi ojoojúmọ́?’ (Sm. 77:12; 119:97; 1 Tẹs. 5:17) ‘Ṣé mo ti wá àkókò tí màá fi máa múra sílẹ̀ fún àwọn ìpàdé ìjọ? Ṣé mo máa ń gbé àwọn èèyàn ró nípa dídáhùn nípàdé?’ (Sm. 122:1; Héb. 2:12) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé Pọ́ọ̀lù àtàwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀ “lo àkókò gígùn ní sísọ̀rọ̀ pẹ̀lú àìṣojo nípasẹ̀ ọlá àṣẹ Jèhófà.” (Ìṣe 14:3) Ǹjẹ́ o lè ṣe àwọn ìyípadà kan nígbèésí ayé rẹ kó o lè túbọ̀ lo àkókò díẹ̀ sí i, kódà “àkókò gígùn” pàápàá nínú iṣẹ́ ìwàásù, bóyá tó bá tiẹ̀ ṣeé ṣe kó o ṣe aṣáájú-ọ̀nà?—Ka Hébérù 13:15.

15. Báwo làwọn alàgbà ṣe ń fọgbọ́n lo àkókò wọn?

15 Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àtàwọn ọkùnrin olóòótọ́ míì ṣèbẹ̀wò sí ìjọ Kristẹni tó wà ní ìlú Áńtíókù, “wọ́n lo àkókò tí kì í ṣe kékeré pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn” kí wọ́n bàa lè gbé wọn ró. (Ìṣe 14:28) Lóde òní pẹ̀lú, àwọn alàgbà onífẹ̀ẹ́ máa ń lo ọ̀pọ̀ àkókò wọn láti gbé àwọn ará ró. Láfikún sí iṣẹ́ ìwàásù táwọn alàgbà máa ń ṣe, wọ́n tún máa ń ṣiṣẹ́ kára láti bójú tó agbo, wọ́n máa ń lọ wá àgùntàn tó sọ nù, wọ́n máa ń ran àwọn tó ń ṣàìsàn lọ́wọ́, wọ́n sì tún máa ń bójú tó ọ̀pọ̀ ojúṣe míì nínú ìjọ. Ìwọ arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi, ǹjẹ́ ipò rẹ máa fún ọ láàyè láti sapá kó o lè tóótun fún àwọn àfikún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn yìí?

16. Àwọn ọ̀nà díẹ̀ wo la lè gbà “ṣe ohun rere sí . . . àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́”?

16 Ọ̀pọ̀ ti láyọ̀ gan-an torí pé wọ́n ṣe ìrànlọ́wọ́ fáwọn tí wọ́n pàdánú èèyàn tàbí dúkìá wọn nígbà àjálù táwọn èèyàn fà tàbí èyí táwọn nǹkan àbáláyé fà. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan tó ti tẹ́ni ọdún márùndínláàádọ́rin tó ń sìn ní Bẹ́tẹ̀lì máa ń rìnrìn àjò lọ sọ́nà jínjìn lọ́pọ̀ ìgbà láti lọ ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù dé bá. Kí nìdí tó fi ń lo àkókò ìsinmi rẹ̀ fún irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀? Ó sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò mọ iṣẹ́ ọwọ́ pàtàkì kankan, àmọ́ àǹfààní ló jẹ́ láti ṣe ohunkóhun tó bá yẹ ní ṣíṣe. Ó máa ń fún mi níṣìírí gan-an bí mo ṣe ń rí bí ìgbàgbọ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin mi tí wọ́n ti pàdánù àwọn ohun ìní wọn ṣe lágbára tó.” Síwájú sí i, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn jákèjádò ayé ń ṣèrànwọ́ láti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àtàwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Bá a ṣe ń lọ́wọ́ nínú irú àwọn iṣẹ́ yìí, ńṣe là ń “ṣe ohun rere sí . . . àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́” láìsí ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan.—Gál. 6:10.

“Mo Wà Pẹ̀lú Yín ní Gbogbo Àwọn Ọjọ́”

17. Kí ni ìwọ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan lè yááfì torí kó o lè ní ìyè àìnípẹ̀kun?

17 Ayé yìí tó ti kẹ̀yìn sí Ọlọ́run kò ní pẹ́ kọjá lọ. A kò mọ àkókò náà gan-an tí èyí máa ṣẹlẹ̀. Ṣùgbọ́n a mọ̀ pé “àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti dín kù” àti pé “ìrísí ìran ayé yìí ń yí padà.” (Ka 1 Kọ́ríńtì 7:29-31.) Èyí wá jẹ́ ká túbọ̀ rí bí ìbéèrè Jésù yẹn ti ṣe pàtàkì tó, pé: “Kí ni ènìyàn kan yóò fi fúnni ní pàṣípààrọ̀ fún ọkàn rẹ̀?” A óò yááfì ohunkóhun tí Jèhófà bá ní ká yááfì ká bàa lè jèrè “ìyè tòótọ́.” (1 Tím. 6:19) Àní sẹ́, ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká gba ìmọ̀ràn Jésù, pé ‘ká máa tẹ̀ lé òun nígbà gbogbo,’ ká sì máa ‘wá ìjọba Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́.’—Mát. 6:31-33; 24:13.

18. Ìgbẹ́kẹ̀lé wo la ní, kí sì nìdí?

18 Lóòótọ́, títẹ̀lé Jésù kì í fi ìgbà gbogbo rọrùn. Kódà gẹ́gẹ́ bí ìkìlọ̀ Jésù, ẹ̀mí àwọn míì ti bọ́ nínú ètò nǹkan ìsinsìnyí nítorí pé wọ́n fẹ́ tẹ̀ lé e. Síbẹ̀, bíi ti Jésù, a kò ní fàyè gba ohunkóhun tó bá lè máa sọ fún wa pé “ṣàánú ara rẹ.” A nígbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ ìdánilójú tí Jésù sọ fáwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ọ̀rúndún kìíní, pé: “Mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 28:20) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa lo àkókò àti agbára wa débi tá a bá lè lò ó dé lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn mímọ́. Bá a ṣe ń ṣe èyí, ńṣe là ń fi hàn pé a ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Jèhófà máa pa wá mọ́ la ìpọ́njú ńlá já tàbí kó jí wa dìde sínú ayé tuntun. (Héb. 6:10) A ó sì tún máa tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé a mọyì ẹ̀bùn ìwàláàyè gan-an ni.

Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?

• Báwo ni Jésù ṣe fi hàn lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ pé òun múra tán láti sin Ọlọ́run kó sì tún ṣiṣẹ́ sin èèyàn?

• Kí nìdí tó fi yẹ kéèyàn sẹ́ ara rẹ̀, báwo sì la ṣe lè ṣe èyí?

• Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, irú ẹbọ wo ló ṣètẹ́wọ́gbà lójú Jèhófà, kí sì la lè rí kọ́ nínú ìyẹn lónìí?

• Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà máa fọgbọ́n lo àkókò wa?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ìgbà gbogbo ni Jésù máa ń ṣe ohun tó wu Ọlọ́run

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó moore máa ń fi ohun tó dáa jù lọ ti ìjọsìn tòótọ́ lẹ́yìn

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

À ń ṣe ohun tó múnú Ọlọ́run dùn tá a bá ń fọgbọ́n lo àkókò wa