Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ojú Jèhófà “Títàn Yanran” Ń Ṣàyẹ̀wò Gbogbo Èèyàn

Ojú Jèhófà “Títàn Yanran” Ń Ṣàyẹ̀wò Gbogbo Èèyàn

Ojú Jèhófà “Títàn Yanran” Ń Ṣàyẹ̀wò Gbogbo Èèyàn

“Ojú [Jèhófà] títàn yanran ń ṣàyẹ̀wò àwọn ọmọ ènìyàn.”—SM. 11:4.

1. Irú àwọn èèyàn wo la máa ń fẹ́ bá rìn?

 KÍ LÓ máa ń jẹ́ ìṣarasíhùwà rẹ nípa àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ? Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ fún ẹ tó o bá béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ wọn. Wọ́n máa ń fi tọkàntọkàn ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o bá nílò ìrànlọ́wọ́ wọn. Tìfẹ́tìfẹ́ sì ni wọ́n máa ń fún ẹ nímọ̀ràn nígbà tó o bá nílò ìmọ̀ràn. (Sm. 141:5; Gál. 6:1) Ǹjẹ́ kì í wù ẹ́ láti máa bá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ rìn? Irú ẹni tí Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ jẹ́ gan-an nìyẹn. Ká sòótọ́, ìfẹ́ tí wọ́n ní sí ẹ ju ti ẹ̀dá èèyàn èyíkéyìí lọ fíìfíì, ìfẹ́ wọn kì í sì í ṣe ìfẹ́ orí ahọ́n lásán. Ṣe ni wọ́n fẹ́ kó o “di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.”—1 Tím. 6:19; Ìṣí. 3:19.

2. Báwo ni Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó?

2 Dáfídì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Sáàmù sọ bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó, ó ní: “Ojú [Jèhófà] ń wò, ojú rẹ̀ títàn yanran ń ṣàyẹ̀wò àwọn ọmọ ènìyàn.” (Sm. 11:4) Bẹ́ẹ̀ ni o, kì í ṣe pé Ọlọ́run ń wá nìkan, ó tún ń ṣàyẹ̀wò wa pẹ̀lú. Dáfídì tiẹ̀ tún sọ pé: “O ti ṣàyẹ̀wò ọkàn-àyà mi, o ti ṣe àbẹ̀wò ní òru . . . Ìwọ yóò ṣàwárí pé èmi kò pète-pèrò ibi.” (Sm. 17:3) Ó ṣe kedere pé, Dáfídì mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun gan-an. Ó mọ̀ pé ó máa dun Jèhófà, ó sì máa bínú sóun tí òun bá ń ro èròkérò tàbí tóun bá pète-pèrò ibi lọ́kàn. Ṣé bí Dáfídì ṣe ka Jèhófà sí nìwọ náà ṣe kà á sí?

Jèhófà Ń Rí Ọkàn

3. Àwọn àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé Jèhófà máa ń wo ti jíjẹ́ tá a jẹ́ aláìpé mọ́ wa lára?

3 Ohun tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ sí jù ni irú ẹni tá a jẹ́ nínú ọkàn wa lọ́hùn-ún. (Sm. 19:14; 26:2) Àmọ́, ó dùn mọ́ni pé kì í ṣọ́ àwọn àṣìṣe wa pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Sárà aya Ábúráhámù kò fi gbogbo ara sòótọ́ fún áńgẹ́lì kan, tí áńgẹ́lì náà sì rí i pé ẹ̀rù ló bà á àti pé ojú tì í, ṣe ló kàn rọra bá a wí. (Jẹ́n. 18:12-15) Nígbà tí baba ńlá náà Jóòbù polongo “ọkàn ara rẹ̀ ní olódodo dípò Ọlọ́run,” Jèhófà kò torí ìyẹn fawọ́ ìbùkún rẹ̀ sẹ́yìn, torí ó mọ̀ pé Jóòbù ti jìyà gan-an lọ́wọ́ Sátánì. (Jóòbù 32:2; 42:12) Bákan náà, Jèhófà kò bínú sí opó Sáréfátì lórí ọ̀rọ̀ tó fìkanra sọ sí wòlíì Èlíjà. Ọlọ́run mọ̀ pé iná ọmọ tó jó o ló jẹ́ kó sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀.—1 Ọba 17:8-24.

4, 5. Kí ni Jèhófà wò mọ́ Ábímélékì lára?

4 Torí pé Jèhófà máa ń ṣàyẹ̀wò ọkàn, ó máa ń gba táwọn aláìgbàgbọ́ pàápàá rò. Wo ohun tó ṣe fún Ábímélékì ọba ìlú Gérárì nílẹ̀ àwọn Filísínì. Ábímélékì kò mọ̀ pé tọkọtaya ni Ábúráhámù àti Sárà, ló bá mú Sárà láti fi ṣe aya. Àmọ́, kí Ábímélékì tó gbìyànjú láti ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú Sárà, Jèhófà sọ fún un lójú àlá pé: “Èmi pẹ̀lú mọ̀ pé nínú àìlábòsí ọkàn-àyà rẹ ni o ti ṣe èyí, èmi pẹ̀lú sì ń dá ọ dúró láti má ṣe ṣẹ̀ sí mi. Ìdí nìyẹn tí èmi kò fi jẹ́ kí o fọwọ́ kàn án. Ṣùgbọ́n, nísinsìnyí dá aya ọkùnrin náà padà, nítorí tí ó jẹ́ wòlíì, òun yóò sì rawọ́ ẹ̀bẹ̀ nítorí rẹ. Nítorí náà, máa wà láàyè nìṣó.”—Jẹ́n. 20:1-7.

5 Ó dájú pé, Jèhófà ì bá fi dẹndẹ ìyà jẹ Ábímélékì tó jẹ́ abọ̀rìṣà. Àmọ́ Ọlọ́run rí i pé kì í ṣe pé ó fi ṣèkà. Jèhófà wo ìyẹn mọ́ ọba náà lára, ó wá sọ ohun tí ọba náà máa ṣe kó lè rí ìdáríjì, kó sì “máa wà láàyè nìṣó.” Ǹjẹ́ kì í ṣe irú Ọlọ́run tó o fẹ́ máa sìn nìyẹn?

6. Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Baba rẹ̀?

6 Jésù tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Baba rẹ̀ lọ́nà pípé, torí pé ibi táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dára sí ló máa ń wò, ó sì máa ń tètè dárí jì wọ́n. (Máàkù 10:35-45; 14:66-72; Lúùkù 22:31, 32; Jòh. 15:15) Ìwà Jésù bá ohun tó sọ nínú Jòhánù 3:17 mu, pé: “Ọlọ́run rán Ọmọ rẹ̀ jáde sí ayé, kì í ṣe kí ó lè ṣèdájọ́ ayé, bí kò ṣe kí a lè gba ayé là nípasẹ̀ rẹ̀.” Ó dájú pé, ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó sì jinlẹ̀ ni Jèhófà àti Jésù ní sí wa. Èyí sì hàn nínú bí wọ́n ṣe ń fẹ́ ká jèrè ìyè. (Jóòbù 14:15) Ìfẹ́ yẹn ló mú kí Jèhófà máa ṣàyẹ̀wò wa, òun ló mú kó máa wo ibi tá a dára sí, òun ló sì ń jẹ́ kó máa tọ́ wa sọ́nà níbàámu pẹ̀lú ohun tó rí.—Ka 1 Jòhánù 4:8, 19.

Jèhófà Ń Ṣàyẹ̀wò Wa Tìfẹ́tìfẹ́

7. Kí ni Jèhófà kì í ṣe tó bá ń ṣàyẹ̀wò wa?

7 Kò ní bọ́gbọ́n mú pé, ká máa wo Jèhófà bí ẹni pé ó jẹ́ ọlọ́pàá kan tó ń ṣọ́ wa lọ́wọ́-lẹ́sẹ̀ látọ̀run bóyá yóò lè ká ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ wa lọ́wọ́. Sátánì ló ń fẹ̀sùn kàn wá pé a jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan. (Ìṣí. 12:10) Ó tiẹ̀ máa ń parọ́ ohun tá ò ní lọ́kàn mọ́ wa lọ́dọ̀ Ọlọ́run! (Jóòbù 1:9-11; 2:4, 5) Àmọ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Sáàmù sọ nípa Ọlọ́run pé: “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ìṣìnà ni ìwọ ń ṣọ́, Jáà, Jèhófà, ta ni ì bá dúró?” (Sm. 130:3) Ìdáhùn ìbéèrè yẹn ni pé, Kò sí! (Oníw. 7:20) Kàkà bẹ́ẹ̀, ojú àánú ni Jèhófà fi ń wò wá, bí òbí tó láájò ọmọ ṣe ń ṣọ́ ọmọ rẹ̀ kó má bàa fara pa. Ó máa ń kìlọ̀ fún wa nípa àìpé wa àti ìkùdíẹ̀-káàtó wa, ká má bàa kó ara wa sínú ewu.—Sm. 103:10-14; Mát. 26:41.

8. Báwo ni Jèhófà ṣe ń tọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ́nà tó sì ń bá wọn wí?

8 Ọlọ́run ń fi ìfẹ́ tó ní sí wa hàn nípasẹ̀ ìtọ́ni àti ìbáwí tá à ń rí gbà látinú Ìwé Mímọ́ àti nípa oúnjẹ tẹ̀mí tó ń tipasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” pèsè fún wa. (Mát. 24:45; Héb. 12:5, 6) Jèhófà tún ń ràn wá lọ́wọ́ nípasẹ̀ ìjọ Kristẹni àtàwọn “ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn.” (Éfé. 4:8) Síwájú sí i, nítorí pé ó jẹ́ Baba onífẹ̀ẹ́ ó tún ń wò wá kó lè rí bá a ṣe ń fi ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ wa sílò sí, kó lè túbọ̀ ràn wá lọ́wọ́. Sáàmù 32:8 sọ pé: “Èmi yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀. Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.” Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa fetí sí Jèhófà nígbà gbogbo! Ó yẹ ká máa rẹ ara wa sílẹ̀ níwájú rẹ̀, ká sì gbà pé Baba àti Olùkọ́ tó nífẹ̀ẹ́ wa ló jẹ́.—Ka Mátíù 18:4.

9. Àwọn ìwà wo ló yẹ ká máa sá fún, kí sì nìdí?

9 Àmọ́ ṣá, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìgbéraga, àìnígbàgbọ́ tàbí “agbára ìtannijẹ ẹ̀ṣẹ̀” sọ wá dẹni tí ọkàn rẹ̀ yigbì. (Héb. 3:13; Ják. 4:6) Lọ́pọ̀ ìgbà, ibi kéèyàn ní èròkérò tàbí kó máa nífẹ̀ẹ́ sáwọn ohun tí kò tọ́ ni ìwà yìí ti ń bẹ̀rẹ̀. Ó tiẹ̀ lè burú débi pé ẹni náà yóò kọ etí ikún sí ìmọ̀ràn tí wọ́n bá fún un látinú Ìwé Mímọ́. Èyí tó wá burú jù ni pé, ẹni náà lè wá jingíri sínú ìwà burúkú débi pé á wá sọ ara rẹ̀ di ọ̀tá Ọlọ́run. Ìyẹn mà kúkú burú o! (Òwe 1:22-31) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Kéènì, àkọ́bí Ádámù àti Éfà.

Jèhófà Ń Rí Gbogbo Wa Ó sì Ń Tọ́ Wa Sọ́nà

10. Kí nìdí tí Jèhófà kò fi gba ẹbọ Kéènì, kí sì ni Kéènì ṣe?

10 Nígbà tí Kéènì àti Ébẹ́lì mú ọrẹ ẹbọ wá síwájú Jèhófà, kì í ṣe ọrẹ ẹbọ wọn nìkan ló jẹ Jèhófà lógún, èrò ọkàn wọn náà jẹ ẹ́ lógún. Nítorí ohun tí Jèhófà rí lọ́kàn wọn, ó gba ẹbọ tí Ébẹ́lì fi ìgbàgbọ́ rú, ó sì kọ ẹbọ Kéènì nítorí kò ní ìgbàgbọ́. (Jẹ́n. 4:4, 5; Héb. 11:4) Àmọ́, dípò tí Kéènì ì bá fi kọ́gbọ́n nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí kó sì yíwà pa dà, ńṣe ni ìbínú rẹ̀ túbọ̀ gbóná sí àbúrò rẹ̀.—Jẹ́n. 4:6.

11. Báwo ni Kéènì ṣe dẹni tí ọkàn rẹ̀ ṣe àdàkàdekè, ẹ̀kọ́ wo sì nìyẹn kọ́ wa?

11 Jèhófà kíyè sí i pé inú burúkú ló ń bí Kéènì yìí, ó sì bá Kéènì sọ̀rọ̀. Ó sọ fún un pé bó bá ṣe rere, ara rẹ̀ yóò yá gágá. Ó bani nínú jẹ́ pé Kéènì kọ ìmọ̀ràn tí Ẹlẹ́dàá rẹ̀ fún un yìí, ó sì pa àbúrò rẹ̀. Ọkàn burúkú tí Kéènì ní hàn nínú bó ṣe fi ọ̀yájú dáhùn ìbéèrè tí Ọlọ́run bi í pé: “Ibo ni Ébẹ́lì arákùnrin rẹ wà?” Ńṣe ni Kéènì fìbínú dáhùn pé: “Èmi kò mọ̀. Èmi ha ni olùtọ́jú arákùnrin mi bí?” (Jẹ́n. 4:7-9) Ẹ ò rí i pé ọkàn máa ń ṣe àdàkàdekè gan-an ni, débi pé ó lè ṣàìka ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún un ní tààràtà sí! (Jer. 17:9) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ látinú irú àwọn ìtàn báwọ̀nyí, ká sì tètè máa kọ àwọn èròkérò àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tó bá wá sí wa lọ́kàn ní kíá. (Ka Jákọ́bù 1:14, 15.) Tí wọ́n bá fún wa ní ìtọ́ni látinú Ìwé Mímọ́, ẹ jẹ́ ká máa mọrírì rẹ̀, ká sì máa wò ó pé ó jẹ́ ẹ̀rí ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa.

Kò Sí Ẹ̀ṣẹ̀ Tó Fara Sin fún Jèhófà

12. Kí ni Jèhófà máa ń ṣe nípa ìwà àìtọ́?

12 Àwọn kan lè rò pé tí kò bá ti sẹ́ni tó ráwọn nígbà táwọn ṣe ohun tó burú, àwọn ti ṣe é gbé nìyẹn. (Sm. 19:12) Àmọ́ ṣá o, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ tó fara sin fún Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé: “Ohun gbogbo wà ní ìhòòhò àti ní ṣíṣísílẹ̀ gbayawu fún ojú ẹni tí a óò jíhìn fún.” (Héb. 4:13) Jèhófà ni Onídàájọ́ tó ń ṣàyẹ̀wò ìsàlẹ̀ ikùn wa láti mọ ohun tó ń mú wa ṣe nǹkan, ó sì máa ń gbégbèésẹ̀ lórí ìwà àìtọ́ lọ́nà tó fi han pé pípé ni ìdájọ́ rẹ̀. Òun ni “Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, [tí] ó ń lọ́ra láti bínú, [tí] ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́.” Àmọ́ ní ti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà, tí wọ́n “mọ̀ọ́mọ̀ sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà” tàbí tí wọ́n jẹ́ elétekéte, Ọlọ́run kò ní ‘dá wọn sí láìjẹ wọ́n níyà.’ (Ẹ́kís. 34:6, 7; Héb. 10:26) Ohun tí Jèhófà ṣe nínú ọ̀ràn Ákáánì, Ananíà àti Sáfírà gan-an nìyẹn.

13. Báwo ni ọkàn burúkú ṣe mú kí Ákáánì hùwà àìtọ́?

13 Ákáánì mọ̀ọ́mọ̀ tẹ àṣẹ Ọlọ́run lójú, ó mú nínú ohun tí wọ́n kó nílùú Jẹ́ríkò nígbà tí wọ́n ṣẹ́gun ìlú yẹn, ó sì fi pa mọ́ sínú àgọ́ rẹ̀. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe káwọn ìdílé rẹ̀ mọ̀ sí i. Nígbà tí àṣírí tú, Ákáánì fi hàn pé òun mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ tóun dá ti burú tó, nítorí ó sọ pé: “Èmi ti ṣẹ̀ sí Jèhófà.” (Jóṣ. 7:20) Ńṣe ni Ákáánì dẹni tó lọ́kàn burúkú bíi ti Kéènì. Ìwọra ni olórí ohun tó mú kí Ákáánì di ẹlẹ̀tàn. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé Jèhófà ló ni àwọn ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó bọ̀ láti ìlú Jẹ́ríkò, ohun tó jẹ́ ti Ọlọ́run ni Ákáánì jí, ẹ̀mí rẹ̀ àti ti ìdílé rẹ̀ sì lọ sí i.—Jóṣ. 7:25.

14, 15. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi bínú sí Ananíà àti Sáfírà, ẹ̀kọ́ wo nìyẹn sì kọ́ wa?

14 Ananíà àti ìyàwó rẹ̀ Sáfírà jẹ́ ara ìjọ Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù. Lẹ́yìn ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àwọn ará ìjọ tó wà ní Jerúsálẹ́mù ya owó kan sọ́tọ̀ láti máa fi bójú tó àìní àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di onígbàgbọ́ tó wá láti ọ̀nà jíjìn sí Jerúsálẹ́mù. Ipasẹ̀ ọrẹ àtinúwá sì ni wọ́n fi ń kó owó yìí jọ. Ananíà wá ta ilẹ̀ kan ó sì fi apá kan lára owó ilẹ̀ yẹn ṣètọrẹ kí wọ́n lè fi kún owó tí wọ́n ń kó jọ náà. Ṣùgbọ́n òun àti ìyàwó rẹ̀ ṣe bí ẹni pé gbogbo owó ilẹ̀ náà làwọn kó sílẹ̀. Ó dájú pé ṣe ni tọkọtaya yìí ń wá bí wọ́n á ṣe gbayì lójú àwọn ará ìjọ. Àmọ́ ìwà ẹ̀tàn gbáà ni wọ́n hù. Jèhófà wá tú àṣírí wọn fún àpọ́sítélì Pétérù lọ́nà ìyanu, ló bá bi Ananíà léèrè ìdí tó fi hùwà ẹ̀tàn yìí. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Ananíà ṣubú lulẹ̀ tó sì kú. Láìpẹ́ sígbà yẹn, Sáfírà aya rẹ̀ náà kú.—Ìṣe 5:1-11.

15 Kì í ṣe pé Ananíà àti Sáfírà ṣàdédé ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ láìmọ̀ o. Ńṣe ni wọ́n dìídì gbìmọ̀ pọ̀ tí wọ́n sì parọ́ fáwọn àpọ́sítélì. Èyí tó wá burú jù ni pé wọ́n ‘ṣèké sí ẹ̀mí mímọ́ àti sí Ọlọ́run.’ Ohun tí Jèhófà wá ṣe fi hàn kedere pé ó ṣe tán láti dáàbò bo ìjọ lọ́wọ́ àwọn alágàbàgebè. Dájúdájú, “ó jẹ́ ohun akúnfẹ́rù láti ṣubú sí ọwọ́ Ọlọ́run alààyè”!—Héb. 10:31.

Máa Pa Ìwà Títọ́ Mọ́ Nígbà Gbogbo

16. (a) Báwo ni Sátánì ṣe ń sapá láti mú àwọn èèyàn Ọlọ́run dẹ́ṣẹ̀? (b) Kí ni Èṣù ń lò ládùúgbò yín láti fi mú àwọn èèyàn dẹ́ṣẹ̀?

16 Sátánì ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti rí i pé òun mú wa dẹ́ṣẹ̀, ká lè pàdánù ojú rere Jèhófà. (Ìṣí. 12:12, 17) Èrò ibi tó wà nínú Èṣù yìí là ń rí nínú ayé tí wọ́n ti ń fi ìṣekúṣe àti ìwà ipá ṣomi mu yìí. Àwọn ohun tó ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe ti wá gbòde kan lórí ẹ̀rọ̀ kọ̀ǹpútà àtàwọn ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́ míì. Ẹ má ṣe jẹ́ ká juwọ́ sílẹ̀ fún Sátánì láé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kí ìpinnu wa dà bíi ti onísáàmù náà, Dáfídì, ẹni tó sọ pé: “Ṣe ni èmi yóò máa fi ọgbọ́n inú hùwà lọ́nà àìlálèébù. . . . Èmi yóò máa rìn káàkiri nínú ìwà títọ́ ọkàn-àyà mi nínú ilé mi.”—Sm. 101:2.

17. (a) Kí nìdí tí Jèhófà fi máa ń jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ táwọn kan dá níkọ̀kọ̀ hàn sóde lẹ́yìn-ọ̀-rẹ̀yìn? (b) Kí ló yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa?

17 Lóde òní, Jèhófà kì í tú àṣírí ẹ̀ṣẹ̀ àti ìwà ẹ̀tàn àwọn èèyàn lọ́nà ìyanu, bó ṣe ṣe láwọn ìgbà kan láyé àtijọ́. Àmọ́, ó ń rí gbogbo wa, tó bá sì tó àkókò lójú rẹ̀ yóò jẹ́ káwọn ohun ìkọ̀kọ̀ hàn sóde bó ṣe fẹ́. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ àwọn kan a máa fara hàn gbangba, ní ṣíṣamọ̀nà sí ìdájọ́ ní tààràtà, ṣùgbọ́n ní ti àwọn ẹlòmíràn, ẹ̀ṣẹ̀ wọn pẹ̀lú a máa fara hàn kedere lẹ́yìn-ọ̀-rẹ̀yìn.” (1 Tím. 5:24) Ní pàtàkì, ìfẹ́ ló máa ń mú kí Jèhófà tú àṣírí ìwà burúkú. Ó fẹ́ràn ìjọ, ó sì ń fẹ́ kó máa bá a lọ ní wíwà ní mímọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń fàánú hàn sáwọn tó bá dẹ́ṣẹ̀, àmọ́ tí wọ́n wá ronú pìwà dà. (Òwe 28:13) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa bá a lọ ní fífi ọkàn pípé sin Ọlọ́run, ká sì máa sá fún ohunkóhun tó bá lè mú wa dẹ́ṣẹ̀.

Máa Fi Ọkàn Pípé Sin Ọlọ́run

18. Kí ni Dáfídì Ọba fẹ́ kí ọmọ rẹ̀ mọ̀ nípa Ọlọ́run?

18 Dáfídì Ọba sọ fún Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ pé: “Mọ Ọlọ́run baba rẹ kí o sì fi ọkàn-àyà pípé pérépéré àti ọkàn tí ó kún fún inú dídùn sìn ín; nítorí gbogbo ọkàn-àyà ni Jèhófà ń wá, gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú sì ni ó ń fi òye mọ̀.” (1 Kíró. 28:9) Dáfídì kò fẹ́ kí Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ kàn gba Ọlọ́run gbọ́ nìkan. Ó fẹ́ kó mọ bí ìfẹ́ tí Jèhófà ní sáwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó. Ǹjẹ́ ìwọ náà mọ bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó?

19, 20. Bí Sáàmù 19:7-11 ṣe fi hàn, kí ló jẹ́ kí Dáfídì lè sún mọ́ Ọlọ́run, báwo làwa náà ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?

19 Jèhófà mọ̀ pé àwọn èèyàn tó fẹ́ràn òtítọ́ máa sún mọ́ òun àti pé wọ́n á túbọ̀ fà mọ́ òun tí wọ́n bá mọ àwọn ànímọ́ rere òun. Èyí fi hàn pé Jèhófà fẹ́ ká mọ òun, ká sì tún mọ àwọn ànímọ́ àgbàyanu tóun ní dáadáa. Báwo la ṣe máa mọ̀ ọ́n? Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a sì rí ìbùkún rẹ̀ gbà a óò mọ̀ ọ́n.—Òwe 10:22; Jòh. 14:9.

20 Ǹjẹ́ ò ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, tó o sì ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa fi ohun tó ò ń kọ́ sílò? Ǹjẹ́ ò ń rí bí títẹ̀lé àwọn ìlànà Bíbélì ṣe ṣàǹfààní tó? (Ka Sáàmù 19:7-11.) Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ rẹ àti ìfẹ́ rẹ fún Jèhófà yóò túbọ̀ máa jinlẹ̀ sí i. Òun fúnra rẹ̀ yóò túbọ̀ máa sún mọ́ ọ, wàá sì máa bá a rìn lọ. (Aísá. 42:6; Ják. 4:8) Jèhófà yóò fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ dájúdájú ní ti pé yóò bù kún ọ, yóò sì máa dáàbò bò ọ́ nípa tẹ̀mí, bó o ti ń rìn lójú ọ̀nà híhá tó lọ sí ìyè.—Sm. 91:1, 2; Mát. 7:13, 14.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí nìdí tí Jèhófà fi ń ṣàyẹ̀wò wa?

• Kí ló sọ àwọn èèyàn kan di ọ̀tá Ọlọ́run?

• Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ka Jèhófà sí?

• Báwo la ṣe lè máa fi ọkàn pípé sin Ọlọ́run?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Báwo ni Jèhófà ṣe ń ṣọ́ wa bí òbí tó láájò ọmọ?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ananíà?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Kí ló máa jẹ́ ká máa sin Jèhófà nìṣó pẹ̀lú ọkàn tó pé pérépéré?