Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Ṣèrànwọ́ fún Wọn Kí Wọ́n Lè Tètè Pa Dà Láìjáfara!

Ẹ Ṣèrànwọ́ fún Wọn Kí Wọ́n Lè Tètè Pa Dà Láìjáfara!

Ẹ Ṣèrànwọ́ fún Wọn Kí Wọ́n Lè Tètè Pa Dà Láìjáfara!

“Ọ̀dọ̀ ta ni àwa yóò lọ? Ìwọ ni ó ní àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun.”—JÒH. 6:68.

1. Kí ni Pétérù sọ nígbà tí ọ̀pọ̀ ọmọ ẹ̀yìn kọ Jésù sílẹ̀?

 NÍGBÀ kan, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi kọ̀ ọ́ sílẹ̀ torí pé wọn kò fara mọ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀. Jésù wá bi àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin kò fẹ́ lọ pẹ̀lú, àbí?” Pétérù dá a lóhùn pé: “Olúwa, ọ̀dọ̀ ta ni àwa yóò lọ? Ìwọ ni ó ní àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòh. 6:51-69) Wọn ò ní ibòmíì tí wọ́n tún lè lọ. Kò sí “àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun” nínú ìsìn àwọn Júù ìgbà yẹn, ó sì dájú pé lóde òní náà, kò sóhun tó jọ bẹ́ẹ̀ nínú Bábílónì Ńlá, ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé. Nítorí náà, àkókò tàbí “wákàtí ti tó nísinsìnyí” fún gbogbo ẹni tó ṣáko lọ kúrò nínú agbo Ọlọ́run “láti jí” kí wọ́n sì pa dà sínú agbo rẹ̀ tí wọ́n bá ń fẹ́ kí inú Jèhófà dùn sáwọn.—Róòmù 13:11.

2. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn nípa ọ̀rọ̀ àṣírí tàbí ọ̀rọ̀ ìgbẹ́jọ́?

2 Jèhófà fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tó sọ nù jẹ òun lógún. (Ka Ìsíkíẹ́lì 34:15, 16.) Bákan náà, ó ń wu àwọn alàgbà, ó sì tún jẹ́ ojúṣe wọn láti ṣèrànwọ́ fún ẹni bí àgùntàn tó bá ṣáko lọ kúrò nínú agbo Ọlọ́run, kó lè pa dà wá. Tí wọ́n bá ní kí akéde kan máa ṣèkẹ́kọ̀ọ́ ẹni tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ tó fi hàn pé òun nílò ìrànlọ́wọ́, kí ló yẹ kí akéde náà ṣe tó bá gbọ́ pé ẹni náà ti dá ẹ̀ṣẹ̀ kan? Ńṣe ni kí akéde náà gbà á níyànjú pé kó sọ fáwọn alàgbà dípò kó máa fún un ní ìbáwí lórí ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìgbẹ́jọ́ tàbí ọ̀rọ̀ àṣírí. Tí aláìṣiṣẹ́mọ́ náà kò bá sọ fáwọn alàgbà, kí akéde náà lọ sọ fún wọn.—Léf. 5:1; Gál. 6:1.

3. Nígbà tí ọkùnrin tó ní ọgọ́rùn-ún àgùntàn rí èyí tó sọ nù, báwo ló ṣe rí lára rẹ̀?

3 Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, a sọ̀rọ̀ nípa àkàwé Jésù tó dá lórí ọkùnrin kan tó ní ọgọ́rùn-ún àgùntàn. Nígbà tí ọ̀kan sọ nù lára wọn, ńṣe ló fi mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún yòókù sílẹ̀, tó lọ wá èyí tó sọ nù. Inú ọkùnrin náà sì dùn gan-an nígbà tó rí i! (Lúùkù 15:4-7) Bí inú gbogbo wa ṣe máa ń dùn náà nìyẹn tí ọ̀kan nínú àwọn àgùntàn Ọlọ́run tó ṣáko lọ bá pa dà wá sínú agbo. Àwọn alàgbà tàbí àwọn ará ìjọ tiẹ̀ ti lè wá irú aláìṣiṣẹ́mọ́ bẹ́ẹ̀ lọ láti lè ràn án lọ́wọ́ nítorí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Àwọn náà fẹ́ rí i pé onítọ̀hún pa dà wá sínú ètò Ọlọ́run kó lè máa rí ìtìlẹyìn, ààbò àti ìbùkún Ọlọ́run gbà. (Diu. 33:27; Sm. 91:14; Òwe 10:22) Nítorí náà, bí wọ́n bá láǹfààní láti ṣèrànwọ́ fẹ́ni tó ti ṣáko lọ kó lè pa dà sínú ìjọ, kí ni wọ́n lè ṣe?

4. Kí ni Gálátíà 6:2, 5 jẹ́ ká mọ̀?

4 Láti lè gba aláìṣiṣẹ́mọ́ náà níyànjú láti pa dà wá sínú ìjọ, wọ́n lè jẹ́ kó yé e pé Jèhófà fẹ́ràn àwọn àgùntàn Rẹ̀ àti pé ohun tó ń fẹ́ kí olúkúlùkù wa máa ṣe kò ju ohun tá a lè ṣe lọ. Lára àwọn ohun tó sì ní ká máa ṣe ni pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́, ká máa lọ sípàdé, ká sì máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. A lè ka Gálátíà 6:2, 5, ká wá sọ pé, àwọn Kristẹni lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti bá a gbé ẹrù tó nira fún un o, àmọ́ tó bá dọ̀ràn àjọṣe ẹni àti Jèhófà, “olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ti ara rẹ̀.” Ìdí ni pé ìgbàgbọ́ ẹnì kan kò gba ẹnì kejì là.

Ṣé “Àwọn Àníyàn Ìgbésí Ayé” Ló Mú Un Ṣáko Lọ?

5, 6. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa bí ẹnì kan tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ bá ń ṣàlàyé ara rẹ̀? (b) Kí lo máa sọ tí aláìṣiṣẹ́mọ́ kan á fi rí i pé àìwá sípàdé mọ́ ti ṣàkóbá gan-an fóun?

5 Ńṣe ni káwọn alàgbà àtàwọn akéde onírìírí tó bá ń ṣèrànwọ́ fáwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa bí ẹni náà bá ń ṣàlàyé ara rẹ̀ kí wọ́n lè mọ bí wọ́n á ṣe ràn án lọ́wọ́. Jẹ́ ká sọ pé alàgbà ni ọ́, o sì lọ sọ́dọ̀ tọkọtaya kan tí “àwọn àníyàn ìgbésí ayé” kò jẹ́ kí wọ́n wá sípàdé mọ́. (Lúùkù 21:34) Ó lè jẹ́ ìṣòro àtijẹ-àtimu tàbí ojúṣe wọn nínú ìdílé tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i ló sọ wọ́n dẹni tí kì í lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò Kristẹni mọ́. Wọ́n lè sọ pé ńṣe làwọn fẹ́ fún ara nísinmi díẹ̀. Ṣùgbọ́n o lè jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé yíya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ará kọ́ loògùn ọ̀ràn náà. (Ka Òwe 18:1.) O lè fọgbọ́n bi wọ́n pé: “Ǹjẹ́ ayọ̀ yín pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ bẹ́ ò ṣe wá sípàdé mọ́? Ṣé nǹkan ti wá ń dáa ju ti tẹ́lẹ̀ lọ fún ìdílé yín báyìí? Ǹjẹ́ ẹ ṣì ń ní ìdùnnú téèyàn máa ń ní tó bá fi Jèhófà ṣe odi agbára rẹ̀?”—Neh. 8:10.

6 Táwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ bá ronú lórí irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀, ìyẹn lè jẹ́ kí wọ́n rí i pé àìwá sípàdé mọ́ ti jẹ́ kí ìgbàgbọ́ àwọn jó rẹ̀yìn, ìyẹn sì ti mú kí ayọ̀ àwọn dín kù. (Mát. 5:3; Héb. 10:24, 25) Ó tún lè ṣeé ṣe láti jẹ́ kí wọ́n rí i pé àwọn ń pàdánù ayọ̀ téèyàn ń rí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere. (Mát. 28:19, 20) Wàyí o, kí ló bọ́gbọ́n mu pé káwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ náà ṣe?

7. Kí la lè rọ àwọn tó ti ṣáko lọ kúrò nínú agbo Ọlọ́run pé kí wọ́n ṣe?

7 Jésù sọ pé: “Ẹ kíyè sí ara yín, kí ọkàn-àyà yín má bàa di èyí tí a dẹrù pa pẹ̀lú àjẹjù àti ìmutíyó kẹ́ri àti àwọn àníyàn ìgbésí ayé . . . Ẹ máa wà lójúfò, nígbà náà, ní rírawọ́ ẹ̀bẹ̀ ní gbogbo ìgbà, kí ẹ lè kẹ́sẹ járí ní yíyèbọ́ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti ṣẹlẹ̀.” (Lúùkù 21:34-36) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká rọ àwọn tó ti ṣáko lọ kúrò nínú agbo Ọlọ́run, tí wọ́n ṣì ń fẹ́ máa ní ayọ̀ tí wọ́n ń ní tẹ́lẹ̀, pé kí wọ́n máa gbàdúrà fún ẹ̀mí mímọ́ àti ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, kí wọ́n sì máa ṣe ohun tó bá àdúrà wọn mu.—Lúùkù 11:13.

Ṣé Nǹkan Kan Mú Wọn Kọsẹ̀ Ni?

8, 9. Irú ọ̀rọ̀ wo ni alàgbà kan lè bá ẹni tó kọsẹ̀ sọ tónítọ̀hún á fi lè tún inú rò?

8 Nítorí àìpé ẹ̀dá, àwa èèyàn máa ń forí gbárí nígbà míì, ìyẹn sì lè mú ẹlòmíì kọsẹ̀. Ohun tó fa ìkọ̀sẹ̀ fáwọn kan ni pé ẹnì kan tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún nínú ìjọ ṣe ohun tó lòdì sí ìlànà Bíbélì. Tó bá jẹ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ló mú aláìṣiṣẹ́mọ́ kan kọsẹ̀, alàgbà tó wá a lọ lè jẹ́ kó yé e pé Jèhófà kì í mú ẹnikẹ́ni kọsẹ̀. Torí náà, ǹjẹ́ ó wá yẹ kéèyàn torí ẹnì kan kẹ̀yìn sí Ọlọ́run àtàwọn èèyàn rẹ̀? Kàkà bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ kì í ṣe pé ó yẹ kéèyàn máa sin Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ lọ, kó sì fi ọ̀ràn náà sọ́wọ́ Jèhófà “Onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé,” kó gbà pé Jèhófà mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ náà, àti pé ó máa ṣe ohun tó tọ́ nípa rẹ̀? (Jẹ́n. 18:25; Kól. 3:23-25) Téèyàn bá fẹsẹ̀ kọ tó sì ṣubú, kò sáà ní jókòó pa síbẹ̀, pé òun ò ní dìde mọ́. Àbí á jókòó síbẹ̀?

9 Tí alàgbà kan bá ń ṣèrànwọ́ fún aláìṣiṣẹ́mọ́ kó lè pa dà sínú ètò Ọlọ́run, alàgbà náà lè jẹ́ kó mọ̀ pé àwọn kan ti wá rí i nígbà tó yá pé ohun tó mú àwọn kọsẹ̀ náà kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì mọ́. Kódà, ohun tó mú wọn kọsẹ̀ yẹn tiẹ̀ lè ti kúrò nílẹ̀ pátápátá. Tó bá sì jẹ́ pé ṣe ni wọ́n bá onítọ̀hún wí tó wá tìtorí ìyẹn kọsẹ̀, tó bá ronú jinlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà, tó sì gbàdúrà lé e, ó lè rí ibì kan tóun alára ti ṣe ohun tí kò dáa tó nínú ọ̀ràn náà. Ìyẹn sì lè jẹ́ kó rí i pé òun ì bá má ti jẹ́ kí ìbáwí yẹn mú òun kọsẹ̀.—Sm. 119:165; Héb. 12:5-13.

Ṣé Torí Àlàyé Kan Tí Ètò Ọlọ́run Ṣe Ló Ṣe Kọsẹ̀?

10, 11. Àlàyé wo la lè ṣe láti fi mú kí ẹnì kan tó lérò tó yàtọ̀ nípa ẹ̀kọ́ Bíbélì kan tún inú rò?

10 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àìfaramọ́ àlàyé kan tí ètò Ọlọ́run ṣe látinú Ìwé Mímọ́ ló mú káwọn kan kúrò nínú ètò Ọlọ́run. Bó ṣe rí nígbà kan nìyẹn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí Ọlọ́run dá nídè kúrò lóko ẹrú Íjíbítì “gbàgbé àwọn iṣẹ́” tí Ọlọ́run ṣe nítorí wọn, tí “wọn kò [sì] dúró de ìmọ̀ràn rẹ̀.” (Sm. 106:13) Á dáa láti rán irú aláìṣiṣẹ́mọ́ bẹ́ẹ̀ létí pé oúnjẹ tẹ̀mí tí kò lẹ́gbẹ́ ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè. (Mát. 24:45) Ìpèsè yẹn ló sáà jẹ́ kí onítọ̀hún mọ ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó mọ̀. Nítorí náà, kí ló dé tí kò pinnu láti tún bẹ̀rẹ̀ sí í rìn nínú òtítọ́?—2 Jòh. 4.

11 Alàgbà tó ń gbìyànjú láti ran irú aláìṣiṣẹ́mọ́ bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ lè tọ́ka sí àpẹẹrẹ àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kọ Jésù sílẹ̀ torí pé wọn ò fara mọ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀. (Jòh. 6:53, 66) Ńṣe làwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn jó rẹ̀yìn nípa tẹ̀mí tí wọ́n sì pàdánù ayọ̀ wọn nígbà tí wọ́n kọ Kristi àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù tó dúró tì í sílẹ̀. Ǹjẹ́ àwọn tó fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀ wá ń rí ibòmíì tí wọ́n ti lè rí irú oúnjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀ bíi tinú ètò Ọlọ́run jẹ? Rárá o, torí kò síbòmíì tó dà bí ètò Jèhófà!

Ṣé Ó Dá Ẹ̀ṣẹ̀ Kan Ni?

12, 13. Tí aláìṣiṣẹ́mọ́ kan bá sọ pé òun ti dá ẹ̀ṣẹ̀ kan, báwo la ṣe lè ràn án lọ́wọ́?

12 Ẹ̀ṣẹ̀ táwọn kan dá ló fà á tí wọ́n fi ṣíwọ́ iṣẹ́ ìwàásù àti wíwá sípàdé. Wọ́n lè rò pé táwọn bá jẹ́wọ́ fáwọn alàgbà, wọ́n á yọ àwọn lẹ́gbẹ́. Ṣùgbọ́n wọn kò ní yọ wọ́n lẹ́gbẹ́ tí wọ́n bá ti jáwọ́ nínú ìwà tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu yẹn tí wọ́n sì ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn. (2 Kọ́r. 7:10, 11) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni inú àwọn ará ìjọ máa dùn pé wọ́n pa dà wá, àwọn alàgbà á sì ṣèrànwọ́ fún wọn kí àjọṣe àwọn àti Jèhófà tún lè pa dà dán mọ́rán.

13 Tó o bá jẹ́ akéde tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ táwọn alàgbà sì ní kó o ṣèrànwọ́ fún aláìṣiṣẹ́mọ́ kan, kí ló yẹ kó o ṣe tí onítọ̀hún bá wá sọ fún ọ pé òun ti dá ẹ̀ṣẹ̀ kan? Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, dípò tí wàá fi bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí wàá ṣe bójú tó irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, sọ fún un pé kó lọ sọ fáwọn alàgbà. Bí kò bá wá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, lọ fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn alàgbà létí gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe ní ká ṣe lórí irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Wàá tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé orúkọ Jèhófà àti bí ìjọ ṣe máa wà ní mímọ́ ló jẹ ọ́ lógún. (Ka Léfítíkù 5:1.) Àwọn alàgbà mọ bí wọ́n ṣe ń ṣèrànwọ́ fáwọn tó bá fẹ́ pa dà sínú ètò Ọlọ́run láti lè máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ó lè gba pé kí wọ́n bá onítọ̀hún wí tìfẹ́tìfẹ́. (Héb. 12:7-11) Tónítọ̀hún bá gbà pé òun ṣẹ̀ sí Ọlọ́run, tó sì ti jáwọ́ nínú ìwà náà, tó sì ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn, àwọn alàgbà yóò ràn án lọ́wọ́ kí Jèhófà lè dárí jì í.—Aísá. 1:18; 55:7; Ják. 5:13-16.

Bí Ọmọ Kan Ṣe Pa Dà Wálé Mú Inú Bàbá Rẹ̀ Dùn

14. Ṣàlàyé àkàwé ọmọ onínàákúnàá tí Jésù sọ, lọ́rọ̀ ara rẹ.

14 Ẹni táwọn alàgbà yàn pé kó ṣèrànwọ́ fún ẹni bí àgùntàn tó ṣáko lọ lè lo àkàwé tí Jésù sọ nínú Lúùkù 15:11-24 láti fi ran onítọ̀hún lọ́wọ́. Nínú àkàwé yẹn, ọmọkùnrin kan hùwà àpà, ó ná ìnákúnàá, ó sì run ogún rẹ̀. Nígbà tó yá, ó wá kábàámọ̀ ayé ìjẹkújẹ tó ti jẹ. Ọwọ́ ebi tẹ̀ ẹ́, àárò ilé sọ ọ́, ló bá sọ pé ó tó gẹ́ẹ́, ilé yá! Òkèèrè ló ṣì wà tí bàbá rẹ̀ ti rí i, tó sáré lọ pàdé rẹ̀, tó gbá a mọ́ra, tó sì fẹnu kò ó lẹ́nu. Inú bàbá rẹ̀ mà dùn o! Tẹ́ni tó ṣáko lọ náà bá ronú lórí àkàwé yìí, ó lè fẹ́ láti pa dà sínú agbo Ọlọ́run. Níwọ̀n bí òpin ètò nǹkan ìsinsìnyí ti dé tán, ńṣe ni kí onítọ̀hún tètè pa dà wá sínú ètò Jèhófà láìjáfara.

15. Kí nìdí táwọn kan fi sú lọ kúrò nínú ìjọ?

15 Ọ̀rọ̀ ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó sú lọ kúrò nínú ìjọ kò rí bíi ti ọmọ onínàákúnàá yẹn. Díẹ̀díẹ̀ làwọn míì lára wọn ń lọ títí wọ́n fi sú lọ pátápátá, gẹ́gẹ́ bí ọkọ̀ ojú omi kan tí wọn ò so mọ́lẹ̀ ṣe máa ń sún díẹ̀díẹ̀ kúrò létí bèbè odò títí táá fi bọ́ sáàárín agbami. Àníyàn ìgbésí ayé ló wọ ẹlòmíì lọ́rùn tó fi dẹni tí ò fọwọ́ pàtàkì mú àjọṣe òun àti Jèhófà mọ́. Ńṣe làwọn míì jẹ́ kí ohun tẹ́nì kan ṣe nínú ìjọ mú àwọn kọsẹ̀. Ohun tó mú àwọn míì fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀ ni pé wọn ò fara mọ́ àlàyé tí ètò Ọlọ́run ṣe nípa ẹ̀kọ́ Bíbélì kan. Nǹkan tó sì mú àwọn ẹlòmíì kọsẹ̀ ni ìwà tí ò bá ìlànà Bíbélì mu táwọn fúnra wọn hù. Àmọ́ ṣá, àwọn ohun tá a ti sọ nípa ipò kọ̀ọ̀kan lè jẹ́ kó o mọ bí wàá ṣe ṣèrànwọ́ fáwọn tó tìtorí ìdí wọ̀nyẹn tàbí òmíràn fi agbo Ọlọ́run sílẹ̀, kí wọ́n lè tètè pa dà wá kó tó pẹ́ jù.

“Káàbọ̀ Ọmọ Mi!”

16-18. (a) Báwo ni alàgbà kan ṣe ṣèrànwọ́ fún arákùnrin kan tó di aláìṣiṣẹ́mọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún? (b) Kí nìdí tí arákùnrin yẹn fi di aláìṣiṣẹ́mọ́, ìrànlọ́wọ́ wo la ṣe fún un, báwo làwọn ará ṣe ṣe sí i nígbà tó pa dà dé?

16 Alàgbà kan sọ pé: “Ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ìjọ wa máa ń ṣètò pé ká wá àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ. Mo wá ronú kan arákùnrin kan tí mo bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ tó sì dẹni tó wá sínú òtítọ́. Ṣùgbọ́n ó ti wá di aláìṣiṣẹ́mọ́ láti nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, nǹkan ò sì fara rọ fún un. Mo ṣàlàyé bí àwọn ìlànà Bíbélì ṣe lè ràn án lọ́wọ́ tó bá tẹ̀ lé e. Láìpẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, ó sì gbà pé ká tún bá òun ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí ìpinnu òun láti pa dà sínú òtítọ́ má bàa yẹ̀.”

17 Kí ló tiẹ̀ sọ arákùnrin yìí di aláìṣiṣẹ́mọ́? Ohun tó sọ ni pé: “Ńṣe ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í lé nǹkan tayé dípò nǹkan tẹ̀mí. Mo bá dẹni tí ò kẹ́kọ̀ọ́ mọ́, mi ò lọ sóde ẹ̀rí mọ́, mi ò sì lọ sípàdé mọ́. Kí n tó mọ̀, mo ti fi ètò Jèhófà sílẹ̀. Àmọ́ ohun tó jẹ́ kí n lè pa dà sínú ètò ni bí alàgbà kan ṣe fà mí mọ́ra tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèrànlọ́wọ́ fún mi.” Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ìṣòro arákùnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí í dín kù bó ṣe jẹ́ kí wọ́n bá òun ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó ní: “Mo rí i pé ohun tí mo pàdánù ni ìfẹ́ àti ìtọ́sọ́nà Jèhófà àti ti ètò rẹ̀.”

18 Báwo làwọn ará ṣe ṣe sí arákùnrin yìí nígbà tó pa dà sínú ìjọ? Arákùnrin náà ní: “Ọ̀rọ̀ mi dà bíi ti ọmọ onínàákúnàá tí Jésù Kristi sọ̀rọ̀ rẹ̀. Ohun tí ìyá àgbàlagbà kan tá a jọ wà nínú ìjọ yẹn ní ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn, tó ṣì wà níbẹ̀ di ìsinsìnyí, tiẹ̀ sọ fún mi ni pé, ‘Káàbọ̀ ọmọ mi, mo bá ọ yọ̀!’ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ yẹn tù mí nínú gan-an. Ọkàn mi balẹ̀ pé ilé ni mo pa dà sí. Mo dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ alàgbà yẹn àti gbogbo ìjọ lápapọ̀ fún sùúrù, ìfẹ́ àti ọ̀yàyà tí wọ́n fi hàn sí mi. Ìfẹ́ Jèhófà àti ti ọmọnìkejì tí wọ́n ní lohun pàtàkì tó jẹ́ kí n lè pa dà sínú agbo Ọlọ́run.”

Ẹ Gbà Wọ́n Níyànjú Kí Wọ́n Tètè Pa Dà Láìjáfara!

19, 20. Kí lo máa sọ láti fi gba àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ níyànjú kí wọ́n lè tètè pa dà sínú agbo Ọlọ́run láìjáfara, báwo lo sì ṣe máa jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ohun tí Ọlọ́run ní ká ṣe kò kọjá agbára wa?

19 Ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí, òpin ètò nǹkan yìí sì ti dé tán. Nítorí náà, ẹ gba àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ níyànjú pé kí wọ́n máa wá sípàdé. Ẹ rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n tètè bẹ̀rẹ̀ báyìí. Ẹ jẹ́ kí wọ́n rí i pé ńṣe ni Sátánì ń gbìyànjú láti ba àjọṣe àwọn àti Ọlọ́run jẹ́ nípa mímú kí wọ́n rò pé téèyàn bá pa ìjọsìn tòótọ́ tì, èèyàn lè rí ìtura kúrò nínú wàhálà ìgbésí ayé. Ẹ lè fi yé wọn pé ìgbà tí wọ́n bá jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù tó dúró gbọin-gbọin nìkan ni wọ́n lè rí ojúlówó ìtura.—Ka Mátíù 11:28-30.

20 Ẹ rán àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ létí pé ohun tí Ọlọ́run ń retí pé ká ṣe kò ju ohun tá a lè ṣe. Àti pé nígbà táwọn kan ń bínú sí Màríà ẹ̀gbọ́n Lásárù nítorí pé ó da òróró olówó iyebíye sórí Jésù láìpẹ́ sígbà tí Jésù máa kú, Jésù sọ pé: “Ẹ jọ̀wọ́ rẹ̀ jẹ́ẹ́. . . . Ó ṣe ohun tí ó lè ṣe.” (Máàkù 14:6-8) Jésù tún yin opó aláìní kan tó fi owó tó kéré níye sínú àpótí ìṣúra ní tẹ́ńpìlì, nítorí pé òun náà ṣe ìwọ̀n tó lè ṣe. (Lúùkù 21:1-4) Kò sí àní-àní pé èyí tó pọ̀ jù lara wa ló lè máa wá sípàdé, tó sì lè máa kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, àwọn tó jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí á lè ṣe nǹkan wọ̀nyí.

21, 22. Ìdánilójú wo lo lè fún àwọn tó bá pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà?

21 Tí ẹni bí àgùntàn tó ṣáko lọ bá ń lọ́ tìkọ̀ láti yọjú sáwọn ará, o lè rán an létí irú ayọ̀ tó wáyé nígbà tí ọmọ onínàákúnàá pa dà wálé. Bákan náà làwọn ará ṣe máa ń yọ̀ bí wọ́n bá rí àwọn tó pa dà sínú ètò Ọlọ́run. Gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n tara ṣàṣà kọjú ìjà sí Èṣù nísinsìnyí, kí wọ́n sì sún mọ́ Ọlọ́run.—Ják. 4:7, 8.

22 Tìdùnnú-tìdùnnú làwọn ará máa tẹ́wọ́ gba àwọn tó bá pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. (Ìdárò 3:40) Ó dájú pé wọ́n ń rí ayọ̀ gan-an nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run kí wọ́n tó di aláìṣiṣẹ́mọ́. Ìbùkún tó kọjá àfẹnusọ ló ń bẹ níwájú fáwọn tó bá pa dà sínú agbo Ọlọ́run láìjáfara!

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Báwo lo ṣe máa ṣèrànwọ́ fún Kristẹni tó kọsẹ̀ tó sì wá di aláìṣiṣẹ́mọ́?

• Tẹ́nì kan bá kúrò nínú ètò Ọlọ́run torí pé ó lérò tó yàtọ̀ nípa ẹ̀kọ́ Bíbélì kan, àlàyé wo lo lè ṣe fún un táá fi tún inú rò?

• Báwo lèèyàn ṣe lè ran ẹni tó ń lọ́ tìkọ̀ láti pa dà sínú ètò Ọlọ́run lọ́wọ́?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa bí ará wa kan tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ bá ń ṣàlàyé ara rẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Táwọn tó ṣáko lọ bá ronú lórí àkàwé ọmọ onínàákúnàá tí Jésù sọ, wọ́n lè fẹ́ láti pa dà sínú ètò Ọlọ́run