Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ẹ Kọ Ojú Ìjà sí Èṣù” bí Jésù Ti Ṣe

“Ẹ Kọ Ojú Ìjà sí Èṣù” bí Jésù Ti Ṣe

“Ẹ Kọ Ojú Ìjà sí Èṣù” bí Jésù Ti Ṣe

“Ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.”—JÁK. 4:7.

1. Ta ni Jésù mọ̀ pé ó máa dojú ìjà kọ òun lórí ilẹ̀ ayé, kí ló sì máa jẹ́ àbájáde rẹ̀?

 JÉSÙ KRISTI mọ̀ pé Èṣù máa dojú ìjà kọ òun. Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ sí ejò nígbà tó ń bá ẹ̀mí búburú tó lo ejò náà wí ló jẹ́ kí Jésù mọ̀ bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run sọ pé: “Èmi yóò sì fi ìṣọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà [ìyẹn apá ti ọ̀run lára ètò Jèhófà] àti sáàárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ rẹ̀. Òun [Jésù] yóò pa ọ́ ní orí, ìwọ yóò sì pa á ní gìgísẹ̀.” (Jẹ́n. 3:14, 15; Ìṣí. 12:9) Pípa Jésù ní gìgísẹ̀ túmọ̀ sí pé Èṣù á pa á lára fúngbà díẹ̀ ní ti pé wọ́n á ṣekú pa á nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé, àmọ́ Jèhófà yóò jí i dìde sí ògo tọ̀run. Ṣùgbọ́n pípa ejò náà ní orí túmọ̀ sí pé Jésù yóò pa Èṣù kú pátápátá.—Ka Ìṣe 2:31, 32; Hébérù 2:14.

2. Kí nìdí tí ọkàn Jèhófà fi balẹ̀ pé Jésù yóò kọjú ìjà sí Èṣù yóò sì borí?

2 Ọkàn Jèhófà balẹ̀ pé Jésù yóò ṣe iṣẹ́ tóun gbé fún un láṣeyọrí àti pé yóò kọjú ìjà sí Èṣù nígbà tó bá wà lórí ilẹ̀ ayé, yóò sì borí. Kí nìdí tó fi dá Jèhófà lójú? Ìdí ni pé, àìmọye ọdún sẹ́yìn ló ti dá Jésù sọ́run, tó ti ṣàkíyèsí rẹ̀, tó sì ti mọ̀ pé “àgbà òṣìṣẹ́” yìí, tó jẹ́ “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá,” jẹ́ onígbọràn àti olóòótọ́. (Òwe 8:22-31; Kól. 1:15) Nítorí náà, nígbà tí Ọlọ́run rán Jésù wá sáyé, tó sì gba Èṣù láyè láti dán an wò títí dójú ikú, ọkàn Ọlọ́run balẹ̀ pé Ọmọ bíbí kan ṣoṣo òun yóò borí.—Jòh. 3:16.

Jèhófà Ń Dáàbò Bo Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀

3. Kí ni Èṣù ń ṣe sáwọn ìránṣẹ́ Jèhófà?

3 Jésù pe Èṣù ní “olùṣàkóso ayé yìí,” ó sì sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé ayé á ṣe inúnibíni sí wọn bí wọ́n ti ṣe sóun. (Jòh. 12:31; 15:20) Ayé tó wà lábẹ́ agbára Sátánì Èṣù yìí kórìíra àwọn Kristẹni tòótọ́ nítorí pé wọ́n ń sin Jèhófà, wọ́n sì ń wàásù òdodo. (Mát. 24:9; 1 Jòh. 5:19) Èṣù dìídì dájú sọ àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró tí yóò bá Kristi jọba nínú Ìjọba rẹ̀ ọ̀run. Sátánì tún dájú sọ gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n nírètí àtigbé títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kìlọ̀ fún wa pé: “Elénìní yín, Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.”—1 Pét. 5:8.

4. Ẹ̀rí wo ló wà pé àwa èèyàn Ọlọ́run lóde òní ti kọjú ìjà sí Èṣù, a sì ti borí?

4 Ètò Jèhófà tá a wà nínú rẹ̀ yìí ti kọjú ìjà sí Èṣù, ó sì ti borí nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run ń tì í lẹ́yìn. Ìwọ wo àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ yìí: Láti ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, làwọn kan lára àwọn aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ tó burú jù lọ ti gbìyànjú láti gbá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wọlẹ̀. Àmọ́ ńṣe làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún ń pọ̀ sí i, a sì ti tó nǹkan bíi mílíọ̀nù méje [7,000,000] nínú àwọn ìjọ tó ju ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] lọ kárí ayé. Àwọn òǹrorò aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sáwa èèyàn Jèhófà gan-an alára ló dàwátì!

5. Báwo ni Aísáyà 54:17 ṣe ṣẹ sára àwa ìránṣẹ́ Jèhófà?

5 Nígbà tí Ọlọ́run ń bá ìjọ àwọn èèyàn Ísírẹ́lì ìgbàanì tó pè ní obìnrin rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó ṣèlérí pé: “Ohun ìjà yòówù tí a bá ṣe sí ọ kì yóò ṣe àṣeyọrí sí rere, ahọ́n èyíkéyìí tí ó bá sì dìde sí ọ nínú ìdájọ́ ni ìwọ yóò dá lẹ́bi. Èyí ni ohun ìní àjogúnbá àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà, ọ̀dọ̀ mi sì ni òdodo wọn ti wá.” (Aísá. 54:11, 17) Ìlérí yẹn ti ṣẹ sára àwa èèyàn Jèhófà jákèjádò ayé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” wọ̀nyí. (2 Tím. 3:1-5, 13) À ń bá a lọ láti máa kọjú ìjà sí Èṣù, kò sì sóhun ìjà tí Èṣù lè lò táá lè pa àwa èèyàn Ọlọ́run rẹ́, nítorí Jèhófà dúró tì wá.—Sm. 118:6, 7.

6. Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì sọ fún wa pé yóò ṣẹlẹ̀ sí ìṣàkóso Èṣù lọ́jọ́ iwájú?

6 Òpin ètò nǹkan búburú ìsinsìnyí ti dé tán. Nígbà tó bá sì dé, gbogbo ẹ̀ka ìṣàkóso Sátánì ni yóò fọ́ túútúú. Ọlọ́run mí sí wòlíì Dáníẹ́lì láti sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn [ìyẹn àwọn tó wà lónìí], Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ [lọ́run] èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí [ìyẹn àwọn tó wà nísinsìnyí] túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Dán. 2:44) Nígbà tí ìyẹn bá ṣẹlẹ̀, ìṣàkóso Èṣù àti tàwọn èèyàn aláìpé yóò pòórá pátápátá. Gbogbo ẹ̀ka ìṣàkóso Èṣù yóò pa run ráúráú, Ìjọba Ọlọ́run yóò sì máa ṣàkóso gbogbo ayé láìsí alátakò kankan.—Ka 2 Pétérù 3:7, 13.

7. Báwo la ṣe mọ̀ pé àwa ìránṣẹ́ Jèhófà lẹ́nì kọ̀ọ̀kan lè kọjú ìjà sí Èṣù ká sì borí?

7 Kò sí àní-àní pé Jèhófà yóò máa dáàbò bo ètò rẹ̀, yóò sì máa bú kún ètò náà bó ti ń gbilẹ̀ sí i. (Ka Sáàmù 125:1, 2.) Àwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ńkọ́? Bíbélì sọ fún wa pé àwa náà lè kọjú ìjà sí Èṣù ká sì borí bíi ti Jésù. Kódà, àsọtẹ́lẹ̀ tí Kristi tipasẹ̀ Jòhánù sọ fi hàn pé láìfi àtakò Sátánì pè, “ogunlọ́gọ̀ ńlá,” ìyẹn àwọn tó nírètí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé, yóò la òpin ètò nǹkan yìí já. Ìwé Mímọ́ sọ pé, wọ́n ké jáde pé: “Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa, ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà [Jésù Kristi] ni ìgbàlà wa ti wá.” (Ìṣí. 7:9-14) Bíbélì sọ pé àwọn ẹni àmì òróró ṣẹ́gun Sátánì, àti pé àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn, ìyẹn “àwọn àgùntàn mìíràn” tún kọjú ìjà sí Sátánì, wọ́n sì borí. (Jòh. 10:16; Ìṣí. 12:10, 11) Àmọ́ èyí gba pé ká máa sapá gan-an ká sì máa gbàdúrà àtọkànwá pé kí Ọlọ́run “dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.”—Mát. 6:13.

Ẹni Tó Jẹ́ Àpẹẹrẹ Pípe Lórí Ọ̀rọ̀ Kíkọjú Ìjà sí Èṣù

8. Ìdẹwò wo ni Ìwé Mímọ́ sọ pé Èṣù kọ́kọ́ gbé ko Jésù lójú nínú aginjù, kí sì ni Jésù fi dá a lóhùn?

8 Èṣù sapá gidigidi láti ba ìwà títọ́ Jésù jẹ́. Ní aginjù, Èṣù gbìyànjú láti lo àwọn ìdẹwò láti mú kí Jésù ṣàìgbọràn sí Jèhófà. Àmọ́, Jésù fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ fún wa lórí ọ̀rọ̀ kíkọjú ìjà sí Sátánì. Lẹ́yìn tó ti gbààwẹ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, ebi wá ń pa á gan-an. Sátánì sọ fún un pé: “Bí ìwọ bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, sọ fún àwọn òkúta wọ̀nyí pé kí wọ́n di àwọn ìṣù búrẹ́dì.” Ṣùgbọ́n Jésù kọ̀ láti lo agbára tí Ọlọ́run fún un láti fi gbọ́ tara rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù sọ pé: “A kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.’”—Mát. 4:1-4; Diu. 8:3.

9. Kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ gbà kí Èṣù fi àwọn nǹkan tí ara máa ń fẹ́ mú wa?

9 Lóde òní, Èṣù máa ń wá ọ̀nà láti lo àwọn nǹkan tí ara máa ń fẹ́ láti fi mú àwa èèyàn Jèhófà. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ pinnu pé a ò ní gbà kí ohunkóhun mú wa lọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe, èyí tó wọ́pọ̀ nínú ayé oníwà ìbàjẹ́ yìí. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run là á mọ́lẹ̀ fún wa pé: “Kínla! Ẹ kò ha mọ̀ pé àwọn aláìṣòdodo kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run? Kí a má ṣì yín lọ́nà. Kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí a pa mọ́ fún àwọn ète tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin dà pọ̀ . . . ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 6:9, 10) Èyí fi hàn kedere pé, Ọlọ́run kì yóò gba àwọn oníṣekúṣe láyè nínú ayé tuntun rẹ̀.

10. Gẹ́gẹ́ bí Mátíù 4:5, 6 ṣe wí, ìdẹwò wo ni Èṣù tún fẹ́ fi mú Jésù ṣohun tó lòdì sí ìfẹ́ Jèhófà?

10 Ìwé Mímọ́ sọ nípa ọ̀kan lára àwọn ìdẹwò tí Jésù dojú kọ ní aginjù, ó ní: “Èṣù mú un lọ sí ìlú ńlá mímọ́, ó sì mú un dúró lórí odi orí òrùlé tẹ́ńpìlì, ó sì wí fún un pé: ‘Bí ìwọ bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, fi ara rẹ sọ̀kò sílẹ̀; nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé, “Òun yóò pàṣẹ fún àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ nítorí rẹ, àti pé wọn yóò gbé ọ ní ọwọ́ wọn, kí ìwọ má bàa fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta nígbà kankan.”’” (Mát. 4:5, 6) Èṣù fẹ́ mú kí Jésù ronú pé tóun bá ṣe nǹkan ìyanu yìí, ayé á tètè gbà pé òun ni Mèsáyà. Àmọ́ tí Jésù bá ṣe bẹ́ẹ̀, yóò jẹ́ ìwà ìgbéraga tínú Ọlọ́run kò ní dùn sí, tí kò sì ní fọwọ́ sí. Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jésù kọ̀ láti ṣe ohun tó lòdì sí ìfẹ́ Jèhófà, ó sì fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan dá a lóhùn. Ó ní: “A tún kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ dán Jèhófà Ọlọ́run rẹ wò.’”—Mát. 4:7; Diu. 6:16.

11. Àwọn ọ̀nà wo ni Sátánì lè gbà dẹ wá wò, kí ló sì lè yọrí sí?

11 Sátánì lè fẹ́ gba onírúurú ọ̀nà dẹ wá wò láti mú ká máa wá ògo. Ó lè fẹ́ mú ká máa fara wé ayé yìí nínú àṣà ìwọṣọ àti ìmúra tó lóde tàbí ká lọ́wọ́ nínú eré ìnàjú kan téèyàn lè kọminú sí. Àmọ́ tá a bá pa àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì tì, tá a wá ń fara wé ayé, ṣé a lè máa retí pé káwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run gbà wá lọ́wọ́ ohun búburú tó máa tìdí rẹ̀ yọ? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì Ọba ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ tóun àti Bátí-ṣébà dá, kò bọ́ lọ́wọ́ ohun tó tẹ̀yìn rẹ̀ yọ. (2 Sám. 12:9-12) Ẹ má ṣe jẹ́ ká dán Jèhófà wò lọ́nà tí kò tọ́ nípa bíbá àwọn èèyàn ayé ṣọ̀rẹ́.—Ka Jákọ́bù 4:4; 1 Jòhánù 2:15-17.

12. Kí ni ìdẹwò tí Mátíù 4:8, 9 mẹ́nu kàn, kí sì ni Ọmọ Ọlọ́run fi dá adẹniwò náà lóhùn?

12 Ìdẹwò mìíràn tí Èṣù tún lò ní aginjù ni pé ó fi ipò ńlá nínú ìjọba ayé lọ Jésù. Sátánì fi gbogbo ìjọba ayé yìí àti ògo wọn han Jésù, ó sì sọ pé: “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò fi fún ọ dájúdájú bí ìwọ bá wólẹ̀, tí o sì jọ́sìn mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.” (Mát. 4:8, 9) Ẹ ò rí i pé ìwà ọ̀yájú gbáà ni Èṣù hù yìí bó ṣe fẹ́ gba ìjọsìn tó jẹ́ ti Jèhófà, tó sì ń wá ọ̀nà láti sọ Jésù di aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run! Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tó mú kó fẹ́ dẹni tí wọ́n á máa jọ́sìn yìí, tó jẹ́ kó ta gbòǹgbò lọ́kàn òun nígbà tó ṣì jẹ́ áńgẹ́lì adúróṣinṣin, ló sọ ọ́ di Sátánì Èṣù, ẹlẹ́ṣẹ̀, olójúkòkòrò àti olubi adẹniwò. (Ják. 1:14, 15) Àmọ́, Jésù yàtọ̀ gan-an ní tiẹ̀. Ó pinnu láti jẹ́ olóòótọ́ sí Baba rẹ̀ ọ̀run, èyí tó mú kó sọ pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì! Nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.’” Bí Jésù tún ṣe kọjú ìjà sí Èṣù nípa dídá a lóhùn láìfọ̀rọ̀ bọpobọyọ̀ nìyẹn. Ọmọ Ọlọ́run kò fẹ́ bá ayé Sátánì da nǹkan kan pọ̀ rárá, kò sì gbà kí ohunkóhun mú òun jọ́sìn olubi yẹn!—Mát. 4:10; Diu. 6:13; 10:20.

“Ẹ Kọ Ojú Ìjà sí Èṣù, Yóò sì Sá Kúrò Lọ́dọ̀ Yín”

13, 14. (a) Kí ni Èṣù fi ń lọ Jésù nígbà tó fi gbogbo ìjọba ayé yìí hàn án? (b) Báwo ni Sátánì ṣe máa ń fẹ́ gbin ìwà ìbàjẹ́ sí wa lọ́kàn?

13 Bí Èṣù ṣe fi gbogbo ìjọba ayé yìí han Jésù, agbára ìjọba tí ẹnikẹ́ni kò tíì ní rí ló fi ń lọ̀ ọ́. Sátánì rò pé ohun tí Jésù rí máa fà á mọ́ra táá sì mú kó gbà pé òun yóò di alákòóso tó lágbára jù lọ láyé. Lóde òní, Sátánì kì í fi àwọn ìjọba ayé yìí lọ̀ wá, àmọ́ ó máa ń fẹ́ fi ohun tá à ń fojú wa rí, ohun tá à ń fetí wa gbọ́ àtohun tá à ń finú wa rò gbin ìwà ìbàjẹ́ sí wa lọ́kàn.

14 Èṣù ló ń ṣàkóso ayé yìí, nítorí náà, òun ló ń darí ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde. Abájọ tí ohun táwọn èèyàn ń kà, ohun tí wọ́n ń gbọ́ àti ohun tí wọ́n ń wò fi kún fọ́fọ́ fún ìṣekúṣe àti ìwà ipá. Ìpolówó ọjà inú ayé máa ń fẹ́ mú kí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ nǹkan tá ò nílò wù wá rà. Èṣù máa ń tipasẹ̀ ìpolówó ọjà yìí fi onírúurú nǹkan tó lè wọ̀ wá lójú, tó dùn-ún gbọ́ létí, tó sì lè fani mọ́ra dẹ wá wò lemọ́lemọ́. Ṣùgbọ́n tá a bá ń kọ̀ láti ka àwọn ìwé, wo àwọn àwòrán tàbí gbọ́ àwọn ohun tó lòdì sí ìlànà Ìwé Mímọ́, ńṣe là ń sọ pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì!” Bá a ṣe dúró lórí ìpinnu wa yìí tá a kọ ayé Sátánì tó jẹ́ aláìmọ́ yìí sílẹ̀ lákọ̀tán, àpẹẹrẹ Jésù là ń tẹ̀ lé. Bá a sì ṣe ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ wá sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ọmọlẹ́yìn Kristi láìtijú, níbi iṣẹ́ wa, nílé ìwé, ládùúgbò àti láàárín àwọn mọ̀lẹ́bí wa tún ń fi hàn pé a kì í ṣe ara ayé Sátánì.—Ka Máàkù 8:38.

15. Kí nìdí tí kíkọ ojú ìjà sí Sátánì fi gba pé ká máa wà lójúfò nígbà gbogbo?

15 Lẹ́yìn tí Èṣù ti gbìyànjú lẹ́ẹ̀mẹ́ta láti mú kí Jésù ṣe ohun tó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run, “Èṣù fi í sílẹ̀.” (Mát. 4:11) Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe pé Sátánì fẹ́ jáwọ́ nínú dídẹ Jésù wò, torí Bíbélì sọ fún wa pé: “Nítorí náà, lẹ́yìn tí ó ti mú gbogbo ìdẹwò náà wá sí ìparí [ní aginjù], Èṣù fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ títí di àkókò mìíràn tí ó wọ̀.” (Lúùkù 4:13) Bí àwa náà bá kọjú ìjà sí Èṣù tá a sì borí rẹ̀ lórí ohun kan, ó yẹ ká dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. Àmọ́, ó yẹ ká ṣì máa gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ Jèhófà nígbà gbogbo, nítorí pé Èṣù ṣì ń pa dà bọ̀ wá dẹ wá wò lákòókò mìíràn tó wọ̀ fún un, ó sì lè jẹ́ ìgbà tá ò tiẹ̀ retí ìdẹwò rárá. Nítorí ìdí yìí, a gbọ́dọ̀ máa wà lójúfò nígbà gbogbo, ká máa tẹra mọ́ ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Jèhófà láìfi ìdẹwò èyíkéyìí tá a máa bá pàdé pè.

16. Agbára ńlá wo ni Jèhófà ń fún wa, kí sì nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fi í fún wa?

16 Ká lè rí ìrànwọ́ tá a nílò láti fi kọjú ìjà sí Èṣù, a ní láti máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún wa ní agbára tó ju gbogbo agbára lọ, ìyẹn ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, yóò sì fún wa. Ẹ̀mí yìí á mú kó ṣeé ṣe fún wa láti ṣe àwọn ohun tá ò lè dá ṣe ní agbára wa nìkan. Jésù mú un dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú pé Ọlọ́run máa fún wọn ní ẹ̀mí mímọ́. Ó sọ pé: “Nígbà náà, bí ẹ̀yin, tí ẹ tilẹ̀ jẹ́ [aláìpé tí èyí sì mú kẹ́ ẹ dà bí] ẹni burúkú, bá mọ bí ẹ ṣe ń fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” (Lúùkù 11:13) Ẹ jẹ́ ká máa bá a nìṣó ní gbígbàdúrà pé kí Jèhófà fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Bí ẹ̀mí mímọ́ tó ju gbogbo agbára lọ yìí ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa kọjú ìjà sí Èṣù, ó dájú pé a óò ṣẹ́gun rẹ̀. Yàtọ̀ sí gbígba àdúrà àtọkànwá déédéé, a ní láti gbé gbogbo ìhámọ́ra tẹ̀mí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀ ká bàa lè ‘dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí àwọn ètekéte Èṣù.’—Éfé. 6:11-18.

17. Ìdùnnú wo ló jẹ́ kí Jésù lè kọjú ìjà sí Èṣù?

17 Ohun mìíràn tún jẹ́ kí Jésù lè kọjú ìjà sí Èṣù, ó sì lè ran àwa náà lọ́wọ́. Bíbélì sọ fún wa pé: “Nítorí ìdùnnú tí a gbé ka iwájú [Jésù], ó fara da òpó igi oró, ó tẹ́ńbẹ́lú ìtìjú, ó sì ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.” (Héb. 12:2) A lè ní irú ìdùnnú kan náà tá a bá ń fi hàn pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ, nípa bíbọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ̀ mímọ́, tá a sì tẹjú mọ́ èrè ìyè àìnípẹ̀kun tó wà níwájú wa. Ẹ wo bí ìdùnnú wa yóò ṣe pọ̀ tó nígbà tí Ọlọ́run bá pa Sátánì àti gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ run pátápátá, tí ‘àwọn ọlọ́kàn tútù yóò ni ilẹ̀ ayé tí wọ́n á sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà’! (Sm. 37:11) Nítorí náà, ẹ máa bá a nìṣó ní kíkọjú ìjà sí Èṣù bí Jésù ti ṣe.—Ka Jákọ́bù 4:7, 8.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Ẹ̀rí wo ló wà pé Jèhófà ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀?

• Báwo ni Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa lórí ọ̀rọ̀ kíkọjú ìjà sí Sátánì?

• Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà kọjú ìjà sí Èṣù?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Bíbá ayé ṣọ̀rẹ́ yóò sọ wá di ọ̀tá Ọlọ́run

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Jésù kọ gbogbo ìjọba ayé tí Èṣù fi lọ̀ ọ́