Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Gbogbo Wọn Ń Fi “Ọkàn Kan” Sin Ọlọ́run

Gbogbo Wọn Ń Fi “Ọkàn Kan” Sin Ọlọ́run

Gbogbo Wọn Ń Fi “Ọkàn Kan” Sin Ọlọ́run

ÀWỌN Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe pé jọ yí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi ká lọ́jọ́ Àjọ̀dún Pẹ́ńtíkọ́sì ní Jerúsálẹ́mù. Àwọn èèyàn yìí wá sí Jerúsálẹ́mù fún ayẹyẹ yìí láti onírúurú ibi tó jìnnà, bí ìlú Róòmù, tó wà lápá ìwọ̀ oòrùn àti ilẹ̀ Pátíà, tó wà lápá ìlà oòrùn. Onírúurú èdè làwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn náà ń gbọ́ látẹnu àwọn ọmọ ẹ̀yìn. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ará Gálílì ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó ń bá wọn sọ̀rọ̀. Ẹnu ya àwọn àlejò yìí, àwọn kan lára wọn wá ń béèrè pé: “Báwo ni ó ṣe jẹ́ tí olúkúlùkù wa ń gbọ́ èdè tirẹ̀ nínú èyí tí a bí wa sí?”—Ìṣe 2:8.

Àpọ́sítélì Pétérù wá dìde dúró láti ṣàlàyé ohun tó fa iṣẹ́ ìyanu tí wọ́n ń rí yẹn. Ojú ẹsẹ̀ ni ogunlọ́gọ̀ yẹn gba ìhìn rere. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ni wọ́n batisí! (Ìṣe 2:41) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọ yẹn ń yára bí sí i, síbẹ̀ wọ́n wà níṣọ̀kan. Lúùkù tó wà lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ pé: “Ògìdìgbó àwọn tí wọ́n ti gbà gbọ́, ní ọkàn-àyà àti ọkàn kan.”—Ìṣe 4:32.

Àwọn ogunlọ́gọ̀ tó ṣèrìbọmi lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni fẹ́ láti dúró díẹ̀ sí i ní Jerúsálẹ́mù kí wọ́n lè túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀sìn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà yìí. Àmọ́ wọn ò múra pé àwọn máa pẹ́ tó bẹ́ẹ̀ nígbà tí wọ́n kúrò nílé. Èyí ló mú kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò ọrẹ tó la owó lọ tí wọ́n lè fi tọ́jú wọn. Àwọn kan lára àwọn onígbàgbọ́ fínnúfíndọ̀ ta àwọn ohun ìní wọn, wọ́n sì kó owó tí wọ́n rí níbẹ̀ wá fáwọn àpọ́sítélì kí wọ́n lè pín in fáwọn tí kò ní. (Ìṣe 2:42-47) Àbí ẹ ò rí ẹ̀mí ìfẹ́ àti ọ̀làwọ́ tí wọ́n lò yẹn!

Ó ti pẹ́ tí irú ẹ̀mí ìfẹ́ àti ọ̀làwọ́ bẹ́ẹ̀ ti wà láàárín àwọn Kristẹni tòótọ́. Títí dòní olónìí làwa Kristẹni ṣì ń fi “ọkàn kan” sin Jèhófà. Ẹ̀mí ìfẹ́ àti ọ̀làwọ́ ló ń mú kí olúkúlùkù Kristẹni máa lo àkókò rẹ̀, okun rẹ̀, àti owó rẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere àti láti fi máa gbé gbogbo ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run lárugẹ.—Wo àpótí náà,  “Àwọn Ọ̀nà Táwọn Kan Ń Gbà Ṣètọrẹ.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6, 7]

 ÀWỌN Ọ̀NÀ TÁWỌN KAN Ń GBÀ ṢÈTỌRẸ

ỌRẸ FÚN IṢẸ́ KÁRÍ AYÉ

Ọ̀pọ̀ máa ń ya iye kan sọ́tọ̀ tí wọ́n á máa fi sínú àpótí ọrẹ tá a kọ “Ọrẹ fún Iṣẹ́ Kárí Ayé” sí lára.

Oṣooṣù làwọn ìjọ máa ń fi owó yìí ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè wọn. O sì lè fi ọrẹ owó tó o fínnúfíndọ̀ ṣe ránṣẹ́ ní tààràtà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ. Tó o bá fẹ́ fi sọ̀wédowó ránṣẹ́ sí wa, “Watch Tower” ni kó o kọ sórí rẹ̀ pé kí wọ́n san án fún. O tún lè fi ohun ọ̀ṣọ́ tó ṣeyebíye tàbí dúkìá mìíràn ṣètọrẹ. Kí o sì kọ lẹ́tà ṣókí mọ́ ohun tó o fẹ́ fi ránṣẹ́ láti fi hàn pé ẹ̀bùn ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ jẹ́.

ỌRẸ TÉÈYÀN WÉWÈÉ

Yàtọ̀ sí pé ká dìídì fowó ṣètọrẹ, àwọn ọ̀nà mìíràn tún wà tá a lè gbà ṣètọrẹ tó máa ṣàǹfààní fún iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé. Lára àwọn ọ̀nà náà rèé:

Owó Ìbánigbófò: A lè kọ orúkọ Watch Tower gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò gba owó ìbánigbófò ẹ̀mí tàbí owó ìfẹ̀yìntì ẹni lẹ́nu iṣẹ́.

Àkáǹtì Owó ní Báńkì: A lè fi àkáǹtì owó tá a ní sí báńkì, tàbí owó tá a fi pa mọ́ sí báńkì fún àkókò pàtó kan (fixed deposit), tàbí àkáǹtì owó ìfẹ̀yìntì ẹni lẹ́nu iṣẹ́, síkàáwọ́ Watch Tower láti máa lò ó tàbí ká ṣètò pé kí wọ́n san owó náà fún Watch Tower lẹ́yìn ikú ẹni, níbàámu pẹ̀lú ìlànà báńkì náà.

Ìpín Ìdókòwò (Shares), Ẹ̀tọ́ Orí Owó Ìdókòwò (Debentures Stocks) àti Ti Ètò Ẹ̀yáwó (Bonds): A lè fi ẹ̀tọ́ ìpín ìdókòwò, ẹ̀tọ́ orí owó ìdókòwò àti ti ẹ̀yáwó ta Watch Tower lọ́rẹ.

Ilẹ̀ àti Ilé: A lè fi ilẹ̀ tó ṣeé tà tọrẹ fún Watch Tower, yálà nípa fífi ṣe ẹ̀bùn, tàbí tó bá jẹ́ ilẹ̀ tí ilé wà lórí rẹ̀ téèyàn ṣì ń gbénú rẹ̀, olùtọrẹ náà lè fi tọrẹ àmọ́ kó sọ pé òun á ṣì máa gbénú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà tóun bá ṣì wà láàyè. Kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè rẹ kó o tó fi ìwé àṣẹ sọ ilẹ̀ tàbí ilé èyíkéyìí di èyí tó o fi ta wá lọ́rẹ.

Ìwé Ìhágún àti Ohun Ìní Téèyàn Fi Síkàáwọ́ Onígbọ̀wọ́: A lè fi dúkìá tàbí owó sílẹ̀ bí ogún fún Watch Tower nípasẹ̀ ìwé ìhágún tá a ṣe lábẹ́ òfin, tàbí ká ṣe ìwé pé Watch Tower ni ẹni tí yóò ni ohun ìní tá a fi síkàáwọ́ onígbọ̀wọ́.

Àwọn ọrẹ tá a mẹ́nu bà wọ̀nyí lábẹ́ àkòrí tá a pè ní “ọrẹ téèyàn wéwèé” gba pé kí ẹni tó fẹ́ ṣètọrẹ náà fara balẹ̀ wéwèé wọn kó tó ṣe irú ìtọrẹ bẹ́ẹ̀.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ọ̀rọ̀ yìí, o lè kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Nàìjíríà, yálà nípa kíkọ̀wé sí àdírẹ́sì tá a kọ sísàlẹ̀ yìí tàbí kó o fi nọ́ńbà tẹlifóònù tó wà níbi àdírẹ́sì náà pè wá, tàbí kó o kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ.

Jehovah’s Witnesses

P.M.B. 1090,

Benin City 300001,

Edo State, Nigeria.

Tẹlifóònù wa ni: (052) 202020