Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Máa Lépa Àwọn Ohun Tí Ń Yọrí sí Àlàáfíà”

“Máa Lépa Àwọn Ohun Tí Ń Yọrí sí Àlàáfíà”

“Máa Lépa Àwọn Ohun Tí Ń Yọrí sí Àlàáfíà”

TÍ WỌ́N bá ṣẹ̀ṣẹ̀ da ọ̀dà ọ̀nà kan, ó máa ń dà bíi pé kò lè bà jẹ́ láéláé. Àmọ́ tó bá yá, àwọn ibì kan lè bẹ̀rẹ̀ sí í bà jẹ́ díẹ̀díẹ̀ kó sì máa ní kòtò. Yóò wá pọn dandan pé ká tún àwọn ibi tó bà jẹ́ yẹn ṣe kó má bàa fa jàǹbá, kí ọ̀nà yẹn sì lè wà pẹ́.

Lọ́nà kan náà, ìṣòro máa ń wáyé láàárín àwa àtàwọn ẹlòmíì nígbà míì, ó tiẹ̀ lè fẹ́ ba àjọṣe àárín wa jẹ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn pé èrò àwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Róòmù kò ṣọ̀kan. Ó wá gbà wọ́n nímọ̀ràn pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa lépa àwọn ohun tí ń yọrí sí àlàáfíà àti àwọn ohun tí ń gbéni ró fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.” (Róòmù 14:13, 19) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká “máa lépa àwọn ohun tí ń yọrí sí àlàáfíà”? Báwo la ṣe lè sa gbogbo ipá wa láti rí i dájú pé àlàáfíà wà láàárín àwa àtàwọn ará wa?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Lépa Àlááfíà?

A mọ̀ pé ó léwu tá ò bá wá nǹkan ṣe sáwọn ibi tó ń bà jẹ́ díẹ̀díẹ̀ lójú títì, torí pé ó lè di kòtò ńlá. Bó ṣe léwu náà nìyẹn bá ò bá wá nǹkan ṣe sí aáwọ̀ tó bá wáyé láàárín àwa Kristẹni. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá sọ gbólóhùn náà pé: ‘Mo nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run,’ síbẹ̀ tí ó kórìíra arákùnrin rẹ̀, òpùrọ́ ni. Nítorí ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀, tí òun rí, kò lè máa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tí kò rí.” (1 Jòh. 4:20) Tẹ́nì kan ò bá yanjú aáwọ̀ tó wà láàárín òun àtẹni tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni, ó lè dẹni tó kórìíra arákùnrin rẹ̀ yẹn.

Jésù Kristi fi yé wa pé Jèhófà ò ní tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa bá ò bá jẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín àwa àtàwọn èèyàn. Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Nígbà náà, bí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ bọ̀ níbi pẹpẹ, tí o sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ ní ohun kan lòdì sí ọ, fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ, kí o sì lọ; kọ́kọ́ wá àlàáfíà, ìwọ pẹ̀lú arákùnrin rẹ, àti lẹ́yìn náà, nígbà tí o bá ti padà wá, fi ẹ̀bùn rẹ rúbọ.” (Mát. 5:23, 24) Dájúdájú, ìdí pàtàkì kan tá a fi ní láti máa lépa àlááfíà ni pé a fẹ́ múnú Jèhófà Ọlọ́run dùn. a

Ohun kan ṣẹlẹ̀ ní ìjọ tó wà nílùú Fílípì tó jẹ́ ká rí ìdí míì tó fi yẹ ká máa lépa àlááfíà. Ìṣòro kan wáyé láàárín arábìnrin méjì kan tí orúkọ wọn ń jẹ́ Yúódíà àti Síńtíkè. Bó tílẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò sọ bó ṣe jẹ́, ẹ̀rí fi hàn pé ìṣòro náà ti fẹ́ máa da ìjọ rú. (Fílí. 4:2, 3) Bákan náà, tẹ́ni méjì tí aáwọ̀ wà láàárín wọn ò bá tètè yanjú ẹ̀, kò ní pẹ́ di ohun táwọn míì á máa gbọ́ sí. Níwọ̀n bí a ò ti ní fẹ́ kí ọ̀ràn wa bomi paná ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ, ó yẹ ká máa wá àlááfíà láàárín àwa àti àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́.

Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà.” (Mát. 5:9) Wíwá àlááfíà máa ń jẹ́ kéèyàn láyọ̀, ó sì máa ń jẹ́ kí ọkàn ẹni balẹ̀. Síwájú sí i, tá a bá jẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín àwa àtàwọn ẹlòmíì, ó máa ń ṣàlékún ìlera wa, nítorí “ọkàn-àyà píparọ́rọ́ ni ìwàláàyè ẹ̀dá alààyè ẹlẹ́ran ara.” (Òwe 14:30) Ṣùgbọ́n, tá a bá ń di kùnrùngbùn, ó lè ṣàkóbá fún ìlera wa.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwa Kristẹni ló gbà pé wíwá àlááfíà ṣe pàtàkì, síbẹ̀, o lè máa ṣàníyàn nípa bí wàá ṣe yanjú aáwọ̀ láàárín ìwọ àti ẹnì kan. Jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ tá a lè lò.

Fífi Sùúrù Yanjú Ọ̀rọ̀ Máa Ń Mú Kí Àlàáfíà Wà

Lọ́pọ̀ ìgbà, tá a bá fẹ́ tún ibi tó ti ń bà jẹ́ díẹ̀díẹ̀ lójú ọ̀nà kan ṣe, ńṣe la máa da ọ̀dà míì lé e lórí. Bákan náà, ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe fún wa láti dárí ji àwọn ará tó ṣẹ̀ wá, ká sì bo ẹ̀ṣẹ̀ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tí wọ́n ṣẹ̀ wá mọ́lẹ̀? Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kó yanjú ọ̀pọ̀ aáwọ̀, torí àpọ́sítélì Pétérù sọ pé “ìfẹ́ a máa bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.”—1 Pét. 4:8.

Àmọ́, nígbà míì, ìṣòro kan lè dà bíi pé ó lágbára kọjá ohun tá a kàn lè gbójú fò. Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láìpẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n gba Ilẹ̀ Ìlérí. Bíbélì ròyìn pé, kí “àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè” tó sọdá Odò Jọ́dánì lọ sí ilẹ̀ wọn, wọ́n mọ “pẹpẹ kan tí ó tóbi lọ́nà tí ó fara hàn gbangba-gbàǹgbà.” Àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì tó kù ti gbà pé pẹpẹ ìbọ̀rìṣà ni, wọn ò sì lè gbójú fo ọ̀ràn náà. Ni wọ́n bá fẹ́ lọ ṣígun bá wọn.—Jóṣ. 22:9-12.

Àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè ti rò pé àwọn ti ní ẹ̀rí tó pọ̀ tó pé àwọn ẹ̀yà tí wọ́n fẹ̀sùn kàn yẹn ti dẹ́ṣẹ̀ àti pé táwọn bá yọ sí wọn lójijì, iye ẹ̀mí tó máa ṣòfò kò ní pọ̀ jù. Àmọ́, dípò táwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì tó wà ní ìwọ̀ oòrùn Jọ́dánì yìí á fi fi ìwàǹwára ṣe é, wọ́n gbé oníṣẹ́ dìde láti lọ bá àwọn ẹ̀yà tí wọ́n fẹ̀sùn kàn náà sọ̀rọ̀ lórí ohun tí wọ́n gbọ́ náà. Wọ́n bi wọ́n pé: “Ìwà àìṣòótọ́ wo ni ẹ hù sí Ọlọ́run Ísírẹ́lì yìí, ní yíyípadà lónìí kúrò nínú títọ Jèhófà lẹ́yìn?” Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn ẹ̀yà tó mọ pẹpẹ yìí kò hùwà àìṣòótọ́. Ṣùgbọ́n kí ni wọ́n máa ṣe nípa ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n yẹn? Ṣé wọ́n máa fìbínú dá wọn lóhùn ni, àbí wọ́n máa yarí pé àwọn ò tiẹ̀ lọ́rọ̀ bá wọn sọ? Ńṣe làwọn ẹ̀yà tí wọ́n fẹ̀sùn kan náà dáhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́, wọ́n sì ṣàlàyé kedere pé ìfẹ́ táwọn ní láti sin Jèhófà ló mú káwọn ṣe ohun táwọn ṣe. Ọ̀nà pẹ̀lẹ́ tí wọ́n gbà dáhùn yẹn kò jẹ́ kí wọ́n ba àjọṣe àwọn àti Ọlọ́run jẹ́, kò sì jẹ́ kí ẹ̀mí ẹnikẹ́ni ṣòfò. Bí wọ́n ṣe fi sùúrù yanjú ọ̀ràn náà jẹ́ kó tán nílẹ̀, ó sì jẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín wọn.—Jóṣ. 22:13-34.

Ìwà ọgbọ́n làwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì tó kù hù bí wọ́n ṣe pinnu pé àwọn á kọ́kọ́ lọ bá àwọn ẹ̀yà Rúbẹ́nì àti Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè sọ̀rọ̀ lórí ohun táwọn gbọ́ káwọn tó gbé ìgbésẹ̀ tó lágbára lórí ọ̀ràn náà. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Má ṣe kánjú nínú ẹ̀mí rẹ láti fara ya, nítorí pé fífara ya sinmi ní oókan àyà àwọn arìndìn.” (Oníw. 7:9) Ọ̀nà tó bá Ìwé Mímọ́ mu láti yanjú aáwọ̀ ni pé kí ìwọ àti ẹni náà fi sùúrù sọ ọ̀rọ̀ náà láìfi ohunkóhun sínú. Ǹjẹ́ a lè retí pé kí inú Jèhófà dùn sí wa tá a bá di ẹnì kan tá a rò pé ó ṣẹ̀ wá sínú, tá a sì kọ̀ láti lọ bá onítọ̀hún?

Ẹ tún wò ó báyìí ná, kí la máa ṣe ká sọ pé ẹnì kan tá a jọ jẹ́ Kristẹni wá bá wa pé a ṣẹ òun, bóyá ẹ̀sùn èké ló tiẹ̀ fi kàn wá? Bíbélì sọ pé: “Ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà.” (Òwe 15:1) Àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjì àtààbọ̀ tí wọ́n fẹ̀sùn kàn fi sùúrù ṣàlàyé yékéyéké nípa ìdí tí wọ́n fi ṣe ohun tí wọ́n ṣe, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ bomi paná ohun tí ì bá di iṣu ata-yán-an-yàn-an láàárín àwọn àtàwọn arákùnrin wọn. Bóyá àwa la gbé ìgbésẹ̀ láti lọ bá ará wa kan tó ṣẹ̀ wá ni o àbí òun ló wá bá wa pé a ṣẹ òun, ó yẹ ká bi ara wa pé, ‘Kí ni mo lè sọ, ọ̀nà wo ni mo lè gbà sọ ọ́, kí ló sì lè jẹ́ ìṣarasíhùwà mi tí àlàáfíà á fi wà láàárín àwa méjèèjì?’

Máa Ṣọ́ Irú Ọ̀rọ̀ Tí Wàá Máa Sọ

Jèhófà mọ̀ pé a máa ń fẹ́ sọ ohun tó ń dùn wá jáde. Àmọ́ o, tá a bá kọ̀ tá ò yanjú aáwọ̀ tó wà láàárín àwa àtẹnì kan, ńṣe lọ̀rọ̀ yẹn á máa gbé wa níkùn débi tá a ó fi fẹ́ sọ ọ́ fáwọn ẹlòmíì. Aáwọ̀ tá ò sì yanjú lè mú ká máa sọ̀rọ̀ ẹni tó ṣẹ̀ wá láìdáa. Owe 11:11 sọ àkóbá tí lílo ahọ́n wa lọ́nà tí kò tọ́ lè ṣe, ó ní: “Nítorí ẹnu àwọn ẹni burúkú, [ìlú] di èyí tí a ya lulẹ̀.” Bákan náà, tá ò bá máa ṣọ́ irú ọ̀rọ̀ tá a ó máa sọ nípa ẹnì kan tá a jọ jẹ́ Kristẹni, ó lè ṣàkóbá fún àlááfíà ìjọ tá a lè fi wé ìlú.

Ṣùgbọ́n o, pé à ń wá àlááfíà kò wá sọ pé a ò ní máa sọ ohunkóhun nípa àwọn arákùnrin tàbí arábìnrin wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni níyanjú pé: “Ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ kan kan kò gbọ́dọ̀ ti ẹnu yín jáde.” Àmọ́, ó wá fi kún un pé: “Ọ̀rọ̀ rere ni kí ẹ máa sọ jáde lẹ́nu tí ó lè jẹ́ ìrànlọ́wọ́ ní ìgbàkúgbà. Èyí yóo ṣe àwọn tí ó bá gbọ́ ní anfani. . . . Ẹ máa ṣoore fún ara yín; ẹ ní ojú àánú. Kí ẹ sì máa dariji ara yín.” (Éfé. 4:29-32, Ìròhìn Ayọ̀) Tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá wá bá ọ pé ọ̀rọ̀ kan tó o sọ tàbí ìwà kan tó o hù dun òun, ṣé kò ní rọrùn fún ọ láti bẹ ẹni náà tó bá jẹ́ ẹni tí kì í sọ̀rọ̀ rẹ láìdáa fáwọn èèyàn tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀? Bákan náà, táwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni bá ti mọ̀ wá sẹ́ni tó máa ń sọ ohun tó ń gbéni ró nípa àwọn èèyàn, ó máa rọrùn fún wa láti wá àlááfíà nígbà tí aáwọ̀ bá wà láàárín àwa àti ẹlòmíì.—Lúùkù 6:31.

Ẹ Máa Sin Ọlọ́run “ní Ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́”

Ìwà àwa èèyàn tá a ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ ni pé ká fẹ́ máa yẹra fún àwọn tó bá ṣẹ̀ wá, débi pé ká máa ya ara wa sọ́tọ̀. Ṣùgbọ́n irú ìwà bẹ́ẹ̀ kò bọ́gbọ́n mu. (Òwe 18:1) Ìdí ni pé àwa èèyàn tó ń fi ìṣọ̀kan ké pe orúkọ Jèhófà ti pinnu pé a ó “máa sìn ín ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.”—Sef. 3:9.

Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ táwọn kan sọ sí wa tàbí ìwà tí wọ́n hù sí wa mú kí ìtara tá a ní fún ìjọsìn tòótọ́ dín kù. Nígbà tó ku bí ọjọ́ mélòó kan péré tí Jésù máa rú ẹbọ tó máa rọ́pò gbogbo ẹbọ tí wọ́n máa ń rú ní tẹ́ńpìlì, tí kò sì pẹ́ sígbà tó bẹnu àtẹ́ lu gbogbo nǹkan táwọn akọ̀wé òfin ń ṣe, ó rí tálákà opó kan tó ń “sọ gbogbo àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé tí ó ní” sínú àpótí ìṣúra. Ṣé Jésù gbìyànjú láti dá a lẹ́kun? Rárá o, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni Jésù yìn ín fún bó ṣe kọ́wọ́ ti ìjọ tí Jèhófà ń lò lákòókò yẹn. (Lúùkù 21:1-4) Ìwà àìṣòótọ́ táwọn míì ń hù kò sọ pé kí opó yẹn má ṣètìlẹyìn fún ìjọsìn Jèhófà mọ́.

Lóde òní, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa náà lè rò pé arákùnrin tàbí arábìnrin kan ti ṣe ohun tí kò bójú mu, kódà kó ṣàìtọ́, kí ló yẹ ká ṣe? Ṣé a máa jẹ́ kí èyí ṣàkóbá fún ìjọsìn tá à ń ṣe tọkàntọkàn sí Jèhófà ni? Àbí a máa sa gbogbo ipá wa láti wá bí aáwọ̀ náà ṣe máa yanjú kí àlàáfíà lè jọba nínú ìjọ Ọlọ́run?

Ìwé Mímọ́ gbà wá níyànjú pé: “Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.” (Róòmù 12:18) Ǹjẹ́ ká pinnu pé a máa jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà, kí ẹsẹ̀ wa lè múlẹ̀ lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ìmọ̀ràn Jésù tó wà nínú Mátíù 18:15-17, wo Ilé Ìṣọ́ October 15 1999, ojú ìwé 17 sí 22.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Ó yẹ kí Yúódíà àti Síńtíkè gba àlàáfíà láyè

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Kí ni mo lè sọ, ọ̀nà wo ni mo lè gbà sọ ọ́, kí ló sì lè jẹ́ ìṣarasíhùwà mi tí àlàáfíà á fi wà láàárín àwa méjèèjì?