Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìwé Nehemáyà 8:10 sọ pé káwọn Júù “jẹ àwọn ohun ọlọ́ràá,” àmọ́ Òfin tó wà nínú Léfítíkù 3:17 sọ pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ ọ̀rá èyíkéyìí.” Ṣáwọn ẹsẹ Bíbélì méjèèjì yìí ò ta kora báyìí?
Nínú èdè tí wọ́n fi kọ àwọn ẹsẹ Bíbélì méjèèjì yìí, àwọn ọ̀rọ̀ tá a tú sí “àwọn ohun ọlọ́ràá” nínú Nehemáyà 8:10 àti “ọ̀rá” nínu Léfítíkù 3:17 yàtọ̀ síra. Cheʹlev tó jẹ́ ọ̀rọ̀ Hébérù tá a tú sí “ọ̀rá” nínú Léfítíkù 3:17 túmọ̀ sí ọ̀rá ẹran tàbí ti èèyàn. (Léf. 3:3; Oníd. 3:22) Àwọn ọ̀rọ̀ tó yí ẹsẹ 17 ká jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò gbọ́dọ̀ jẹ àwọn ọ̀rá tó wà lára ìfun, kídìnrín àti èyí tó wà ní abẹ́nú ẹran tí wọ́n bá fi rúbọ, ìdí sì ni pé “gbogbo ọ̀rá jẹ́ ti Jèhófà.” (Léf. 3:14-16) Torí náà, wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ ọ̀rá tó bá wà lára ẹran tí wọ́n bá fẹ́ fi rúbọ sí Jèhófà.
Àmọ́, mash·man·nimʹ ni ọ̀rọ̀ tá a tú sí “àwọn ohun ọlọ́ràá” nínú Nehemáyà 8:10, ẹsẹ yìí nìkan ṣoṣo lọ̀rọ̀ náà sì wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Inú ọ̀rọ̀ ìṣe kan tí wọ́n ń pè ní sha·menʹ ni wọ́n ti mú ọ̀rọ̀ náà, ohun tó sì túmọ̀ sí ni “kéèyàn tóbi” tàbí “kéèyàn sanra.” Àwọn ọ̀rọ̀ míì tí ìtumọ̀ wọn jọra pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìṣe tá a mẹ́nu kàn lókè yìí lè túmọ̀ sí kí ọkàn ẹnì kan balẹ̀ tàbí kónítọ̀hún máa gbé ìgbé ayé yọ̀tọ̀mì. (Fi wé Aísáyà 25:6.) Ọ̀kan lára àwọn ọ̀rọ̀ orúkọ tí wọ́n sábà máa ń mú jáde látinú ọ̀rọ̀ ìṣe yẹn ni sheʹmen, wọ́n sì sábà máa ń tú u sí “òróró,” bí àpẹẹrẹ “òróró ólífì.” (Diu. 8:8; Léf. 24:2) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tí Mash·man·nimʹ tó wà nínú Nehemáyà 8:10 túmọ̀ sí ni oúnjẹ tí wọ́n fi òróró tó pọ̀ gan-an sè, ó sì tún lè túmọ̀ sí ara ẹran tó ní ọ̀rá díẹ̀, àmọ́ kò túmọ̀ sí ògidì ọ̀rá ẹran.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ka jíjẹ ọ̀rá ẹran léèwọ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n lè jẹ oúnjẹ aládùn, oúnjẹ tó dọ́ṣọ̀. Òróró ni wọ́n máa fi ń dín àwọn oúnjẹ bí àkàrà tí wọ́n fi ọkà ṣe. (Léf. 2:7) Nítorí náà, ìwé Insight on the Scriptures ṣàlàyé pé “àwọn ohun ọlọ́ràá” tí ẹsẹ yìí ń sọ ni “àwọn oúnjẹ aládùn tí wọ́n fi òróró sè, kì í ṣe àwọn oúnjẹ gbẹrẹfu.”
Àwọn Kristẹni ti mọ̀ dáadáa pé Òfin Mósè ló ka jíjẹ ọ̀rá ẹran léèwọ̀. Àmọ́, wọn ò sí lábẹ́ Òfin Mósè, ìyẹn sì kan àwọn ohun tí Òfin náà sọ nípa fífi ẹran rúbọ—Róòmù 3:20; 7:4, 6; 10:4; Kól. 2:16, 17.