Ìdí Tó Fi Yẹ Kó O Pa Ìwà Títọ́ Rẹ Mọ́
Ìdí Tó Fi Yẹ Kó O Pa Ìwà Títọ́ Rẹ Mọ́
“Ṣe ìdájọ́ mi, Jèhófà, . . . ní ìbámu pẹ̀lú ìwà títọ́ mi.”—SM. 7:8.
1, 2. Àwọn nǹkan wo ló lè máà jẹ́ kó rọrùn fáwa Kristẹni láti pa ìwà títọ́ wa mọ́?
FOJÚUNÚ yàwòrán àwọn nǹkan mẹ́ta wọ̀nyí: Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí àwọn ọmọléèwé ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ń fi ṣe yẹ̀yẹ́. Wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ fẹ́ pin ín lẹ́mìí, kó lè bínú sí wọn, kó ṣépè tàbí kó bá wọn jà. Ṣó máa gbẹ̀san, àbí ńṣe ló máa séra ró tó sì máa fibẹ̀ sílẹ̀? Ọkọ kan dá wà nílé, ó sì ń ṣèwádìí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ẹnu ìwádìí yìí ló wà tí àpótí ìsọfúnni kan, tí wọ́n fi ń polówó ìkànnì tó máa ń fàwọn àwòrán ìṣekúṣe hàn, fi yọ gannboro lórí kọ̀ǹpútà rẹ̀. Ṣó máa wo ìkànnì yẹn, àbí ńṣe ló máa pajú àpótí náà dé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀? Arábìnrin kan pẹ̀lú àwọn arábìnrin míì jọ ń sọ̀rọ̀, àmọ́ nígbà tó yá ló rí i pé ọ̀rọ̀ náà ti bẹ̀rẹ̀ sí í forí lé ibòmíì, ó wá di pé ọ̀rọ̀ arábìnrin kan nínú ìjọ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ láìdáa. Ṣóun náà á bá wọn dá sí i, àbí ńṣe ló máa fọgbọ́n yí ìjíròrò náà pa dà?
2 Àwọn nǹkan tá a fojúunú yàwòrán yìí yàtọ̀ síra lóòótọ́, àmọ́ ohun kan pa wọ́n pọ̀. Àwọn nǹkan mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ló gba pé kéèyàn sapá láti pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Ṣó o máa ń ronú nípa bó o ṣe lè pa ìwà títọ́ rẹ mọ́, bó o ṣe ń sapá láti bójú tó àwọn nǹkan tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn àtàwọn nǹkan tó o nílò, tó o sì ń fẹ́ láti lé àwọn àfojúsùn rẹ bá? Ojoojúmọ́ làwọn èèyàn máa ń ronú nípa ìrísí wọn, ìlera wọn, ìṣòro àtijẹ àtimu, àwọn ohun tó máa ń fa eré lónìí ìjà lọ́la láàárín àwọn ọ̀rẹ́, kódà láàárín àwọn olólùfẹ́ pàápàá. Àwọn nǹkan wọ̀nyẹn lè gbà wá lọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ. Àmọ́, kí ló jẹ Jèhófà lógún bó ṣe ń ṣàyẹ̀wò ọkàn wa? (Sm. 139:23, 24) Ìwà títọ́ wa ni.
3. Àǹfààní wo ni Jèhófà fún wa, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Jèhófà, Olùfúnni ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé” ti fún olúkúlùkù wa ní onírúurú ẹ̀bùn. (Ják. 1:17) A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fáwọn ẹ̀bùn tó fún wa, irú bí ara wa, agbára ìrònú wa, ìlera tó mọ níwọ̀n àtàwọn nǹkan míì tó ń fún wa lágbára láti ṣe. (1 Kọ́r. 4:7) Àmọ́, Jèhófà kì í fi dandan mú wa láti pa ìwà títọ́ mọ́. Ó fún wa láǹfààní láti pinnu bóyá a fẹ́ ní ànímọ́ yìí tàbí a ò fẹ́ ní in. (Diu. 30:19) Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká ṣàyẹ̀wò ohun tí ìwà títọ́ jẹ́ gan-an. Lẹ́yìn ìyẹn la máa wá jíròrò àwọn ìdí mẹ́ta tí ànímọ́ yìí fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀.
Kí Ni Ìwà Títọ́?
4. Kí ni ìwà títọ́ túmọ̀ sí, kí la sì lè rí kọ́ lára òfin Jèhófà nípa fífi ẹran rúbọ?
4 Ọ̀pọ̀ èèyàn lohun tí ìwà títọ́ túmọ̀ sí ò dá lójú. Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn olóṣèlú bá ń fọ́nnu pé olóòótọ́ èèyàn làwọn, ohun tó sábà máa ń wà lọ́kàn wọn ni pé àwọn kì í figbá kan bọ̀kan nínú. Àìfigbá kan bọ̀kan nínú ṣe pàtàkì lóòótọ́, àmọ́ apá kan ìwà títọ́ ṣì ni. Tí Bíbélì bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìwà títọ́, ohun tó sábà máa ń túmọ̀ sí ni ìwà tó dáa látòkè délẹ̀, ìwà tó bọ́gbọ́n mu. Ohun táwọn ọ̀rọ̀ Hébérù tó ní í ṣe pẹ̀lú “ìwà títọ́” túmọ̀ sí ni ìwà ọmọlúwàbí, ìwà tí kò kù síbì kan tàbí ìwà tí kò lálèébù. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀rọ̀ yìí làwọn tó kọ Bíbélì fi ṣàpèjúwe irú ẹran táwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ máa fi rúbọ sí Jèhófà. Ohun tó lè mú kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ẹran tí wọ́n bá fi rúbọ ni pé kí ẹran náà máà ní àléébù, ìyẹn ni pé kára ẹ̀ pé. (Ka Léfítíkù 22:19, 20.) Jèhófà ò fojúure wo àwọn tó fàwọn ẹran tó ti yarọ, tó ń ṣàìsàn tàbí tójú ẹ̀ ti fọ́ rúbọ sí i.—Mál. 1:6-8.
5, 6. (a) Àwọn àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé àwa èèyàn sábà máa ń mọyì àwọn nǹkan tó pé pérépéré tàbí tí kò lálèébù? (b) Ṣé dandan ni káwa èèyàn aláìpé di ẹni pípé ká tó lè pa ìwà títọ́ mọ́? Ṣàlàyé.
5 Kì í ṣe nǹkan tuntun pé káwọn èèyàn máa wá nǹkan tó pé pérépéré, tàbí nǹkan tí kò lálèébù, kí wọ́n sì mọyì rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, fojúunú yàwòrán ọ̀mọ̀wé kan tó kúndùn kíkà àti ríra àwọn ojúlówó ìwé. Lọ́jọ́ kan, bó ṣe ń wá ojúlówó ìwé kiri, ó rí ọ̀kan tó fà á lójú mọ́ra, àmọ́ bó ti ń ṣí àwọn ojú ewé tó wà nínú ìwé ọ̀hún, ó rí i pé àwọn ojú ewé kan ti já dà nù àti pé ayédèrú ìwé ni, kí lo rò pó máa ṣe? Ó dájú pé kò ní ra ìwé náà. Tún fojúunú wo obìnrin kan tó lọ ra ẹyin lọ́jà. Bó ti ń ṣa àwọn ẹyin tó fẹ́ rà, ó rí i pé wọ́n ti da èyí tó ti fọ́ pọ̀ mọ́ èyí tí kò fọ́ tó sì mọ́ lóló. Irú ẹyin wo lo rò pó máa rà? Ó dájú pé èyí tí kò fọ́ tó sì mọ́ lóló ló máa rà lọọlé. Bí ti Ọlọ́run náà ṣe rí nìyẹn, àwọn tó máa ń ṣe nǹkan láìlálèébù tàbí lọ́nà tó pé pérépéré ló máa ń wá.—2 Kíró. 16:9.
6 O lè máa wá ronú pé ṣó dìgbà téèyàn bá pé kó tó lè pa ìwà títọ́ mọ́ ni? Torí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ àti aláìpé ni wá, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í fojú ìwé tí ò pé tàbí ẹyin tó ti fọ́ wo ara wa. Ṣé bọ́ràn yìí ṣe máa ń rí lára tìẹ náà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nìyẹn? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, mọ̀ dájú pé Jèhófà ò retí pé ká pé ní gbogbo ọ̀nà. Kò béèrè ohun tó ju agbára wa lọ lọ́wọ́ wa rí. a (Sm. 103:14; Ják. 3:2) Síbẹ̀, ó retí pé ká pa ìwà títọ́ mọ́. Ṣó wá túmọ̀ sí pé ìyàtọ̀ wà láàárín kéèyàn jẹ́ ẹni pípé àti kéèyàn pa ìwà títọ́ mọ́ ni? Bẹ́ẹ̀ ni, ìyàtọ̀ wà. Àpèjúwe kan rèé: Ọ̀dọ́mọkùnrin kan nífẹ̀ẹ́ ọ̀dọ́mọbìnrin kan, ó sì ní in lọ́kàn láti fẹ́ ẹ. Ó dájú pé kò ní bọ́gbọ́n mú kó máa retí pé kó má ṣàṣìṣe. Síbẹ̀, ó máa fẹ́ kó nífẹ̀ẹ́ òun látọkàn wá, kó sì jẹ́ pé ọ̀dọ̀ òun nìkan lọkàn ẹ̀ á máa fà sí ṣáá. Bí ti Jèhófà ṣe rí náà nìyẹn, Bíbélì pè é ní “Ọlọ́run tí ń béèrè ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe.” (Ẹ́kís. 20:5) Kò retí pé a ò ní í ṣàṣìṣe, àmọ́ ó fẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ òun látọkàn wá, kó sì jẹ́ pé òun nìkan la ó máa jọ́sìn.
7, 8. (a) Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ fún wa lórí ọ̀rọ̀ ìwà títọ́? (b) Kí ni ìwà títọ́ túmọ̀ sí lọ́nà tí Ìwé Mímọ́ gbà ṣàlàyé rẹ̀?
7 Ó ṣeé ṣe ká rántí ohun tí Jésù sọ nígbà tẹ́nì kan béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ pé èwo ló ṣe pàtàkì jù lọ nínú gbogbo òfin. (Ka Máàkù 12:28-30.) Jésù ò wulẹ̀ dáhùn ìbéèrè yẹn; àmọ́ ìwà tó ń hù bá ìdáhùn rẹ̀ mu. Ó fi àpẹẹrẹ tó tayọ lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa, gbogbo ẹ̀mí wa, gbogbo èrò-inú wa àti gbogbo okun wa. Ó jẹ́ kó yé wa pé pípa ìwà títọ́ mọ́ kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán, àmọ́ ó ní láti hàn nínú ìwà rere tá à ń hù látọkàn wá. Torí náà tá a bá fẹ́ máa pa ìwà títọ́ mọ́, a ní láti fara wé Jésù.—1 Pét. 2:21.
8 Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìwà títọ́ lọ́nà tí Ìwé Mímọ́ gbà ṣàlàyé rẹ̀, ohun tá a máa sọ ni pé: Ìwà títọ́ túmọ̀ sí fífi tọkàntara jọ́sìn Ẹni kan ṣoṣo tó ni ọ̀run, ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run, ká sì jọ́sìn rẹ̀ lọ́nà tó fẹ́ àti lọ́nà tó máa jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Tá a bá fẹ́ máa pa ìwà títọ́ mọ́, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kó máa hàn nínú ìwà tá à ń hù lójoojúmọ́ pé ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà Ọlọ́run ló jẹ wá lógún jù lọ. Àwọn nǹkan tí Jèhófà kà sí pàtàkì la gbọ́dọ̀ fi ṣohun àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò ìdí mẹ́ta tí ṣíṣe èyí fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀.
1. Ìwà Títọ́ Wa àti Ọ̀ràn Ipò Jèhófà Gẹ́gẹ́ Bí Ọba Aláṣẹ
9. Báwo ni ìwà títọ́ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ṣe kan ọ̀ràn ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ?
9 Kò dìgbà tá a bá pa ìwà títọ́ mọ́ káwọn èèyàn tó mọ̀ pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ láyé àtọ̀run. Ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ bá ìdájọ́ òdodo mu, kò lópin, ó sì ba lórí ohun gbogbo. Bó sì ṣe máa rí nìyẹn, láìka ohunkóhun tí ẹ̀dá èyíkéyìí lè sọ tàbí tí wọ́n bá ṣe sí. Àmọ́, àwọn ẹ̀dá kan láyé àti lọ́run ti gbéjà ko ẹ̀tọ́ Ọlọ́run láti jẹ́ ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run. Torí náà, a ní láti dá ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ láre, ìyẹn ni pé ká jẹ́ kí gbogbo ẹ̀dá olórí pípé mọ̀ pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso láyé àtọ̀run, pé ìṣàkóso rẹ̀ bá ìdájọ́ òdodo mu, àti pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn tó wà lábẹ́ àkóso rẹ̀. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fẹ́ láti ṣàlàyé ohun tí ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ túmọ̀ sí fún gbogbo àwọn tó bá fẹ́ gbọ́. Àmọ́, báwo làwa fúnra wa ṣe lè jólóòótọ́ lórí ọ̀rọ̀ tó wà ńlẹ̀ yìí? Báwo la ṣe lè fi hàn pé a fara mọ́ ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń pa ìwà títọ́ mọ́.
10. Ẹ̀sùn wo ni Sátánì fi kan àwa èèyàn lórí ọ̀ràn ìwà títọ́, kí lo sì máa ṣe nípa rẹ̀?
10 Jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò bí ìwà títọ́ rẹ ṣe kan ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí. Sátánì ti lérí pé kò séèyàn kankan tó máa fara mọ́ ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, kò sì sẹ́ni tó máa sin Jèhófà láìjẹ́ pé wọ́n rí nǹkan kan gbà ńbẹ̀. Iwájú ògìdìgbó àwọn áńgẹ́lì ni Èṣù ti sọ fún Jèhófà pé: “Awọ fún awọ, ohun gbogbo tí ènìyàn bá sì ní ni yóò fi fúnni nítorí ọkàn rẹ̀.” (Jóòbù 2:4) Ṣó o rí i pé kì í ṣe Jóòbù ọkùnrin olóòótọ́ yẹn nìkan ni Sátánì kàn lábùkù, ṣùgbọ́n gbogbo ẹ̀dá èèyàn lápapọ̀. Abájọ tí Bíbélì fi pe Sátánì ní “olùfisùn àwọn arákùnrin wa.” (Ìṣí. 12:10) Ó fẹ̀sùn kan Jèhófà pé gbogbo Kristẹni, títí kan ìwọ alára, ò lè jólóòótọ́ sí i délẹ̀délẹ̀. Sátánì ń lérí pé o máa sẹ́ Jèhófà kó o lè tẹ́ ara ẹ lọ́rùn. Báwo làwọn ẹ̀sùn tí Sátánì fi kàn ẹ́ yìí ṣe rí lára ẹ? Ṣó ò ní wá ọ̀nà láti fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì? Ohun tó o máa ṣe gan-an nìyẹn tó o bá pa ìwà títọ́ rẹ mọ́.
11, 12. (a) Àwọn àpẹẹrẹ wo ló jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ìpinnu tá à ń ṣe lójoojúmọ́ kan ìwà títọ́ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan? (b) Kí nìdí tí pípa ìwà títọ́ mọ́ fi jẹ́ àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́?
11 Ọ̀ràn nípa ìwà títọ́ ẹ ti wá jẹ́ kí ìwà tó ò ń hù àtàwọn ìpinnu tó ò ń ṣe lójoojúmọ́ ṣe pàtàkì gan-an. Tún ronú lórí àwọn nǹkan mẹ́ta tá a fojúunú yàwòrán wọn nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò yìí. Kí làwọn èèyàn wọ̀nyẹn máa ṣe tó máa fi hàn pé wọ́n pa ìwà títọ́ wọn mọ́? Ó ń ṣe ọmọ táwọn ọmọ iléèwé ẹ̀ fi ń ṣe yẹ̀yẹ́ yẹn bíi pé kó bá wọn fà á, àmọ́ ó rántí ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì pé: “Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ yàgò fún ìrunú; nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Tèmi ni ẹ̀san; dájúdájú, èmi yóò san ẹ̀san, ni Jèhófà wí.’” (Róòmù 12:19) Torí náà, ńṣe ló bá ẹsẹ̀ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Ọkọ kan tó ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì lè ti máa wo àwòrán ìṣekúṣe, àmọ́ kó wá rántí ìlànà tó wà nínú ọ̀rọ̀ Jóòbù nígbà tó sọ pé: “Èmi ti bá ojú mi dá májẹ̀mú. Nítorí náà, èmi yóò ha ṣe tẹjú mọ́ wúńdíá?” (Jóòbù 31:1) Lọ́nà kan náà, ọkùnrin yẹn pinnu pé òun ò ní wo ìwòkuwò yẹn, ó sì wá kórìíra ẹ̀ torí ó mọ̀ pé ó lè da ilé òun rú. Obìnrin tó ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn obìnrin ẹgbẹ́ rẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ́tí sí òfófó táwọn wọ̀nyẹn ń ṣe nípa àwọn ẹlòmíì, àmọ́ ó rántí ìtọ́sọ́nà tó wà nínú Bíbélì pé: “Kí olúkúlùkù wa máa ṣe bí ó ti wu aládùúgbò rẹ̀ nínú ohun rere fún gbígbé e ró.” (Róòmù 15:2) Òfófó tó ṣeé ṣe kóun náà bẹ̀rẹ̀ sí í tàn kiri yẹn ò lè gbé àwọn ẹlòmíì ró. Ó máa ba arábìnrin rẹ̀ lórúkọ jẹ́, kò sì ní dùn mọ́ Bàbá rẹ̀ ọ̀run nínú. Torí náà, ó kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu, ó sì wá nǹkan míì sọ.
12 Nínú ọ̀ràn kọ̀ọ̀kan tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé yẹ̀ wò yìí, àwọn Kristẹni wọ̀nyẹn ṣèpinnu tó dà bí ìgbà tí wọ́n ń sọ pé: ‘Jèhófà ni Olùṣàkóso mi. Mo sì máa gbìyànjú láti ṣohun tó máa múnú rẹ̀ dùn.’ Ṣéwọ náà máa ń ronú lórí bó o ṣe lè múnú Jèhófà dùn nígbà tó o bá fẹ́ ṣèpinnu? Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé lóòótọ́ lò ń ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ tó ń múni ronú jinlẹ̀ tó wà nínú Òwe 27:11, ó ní: “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì.” Ẹ ò rí i pé àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ la ní láti mú ọkàn Ọlọ́run yọ̀! Ṣé kò wá yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti máa pa ìwà títọ́ wa mọ́?
2. Ìwà Títọ́ Wa Ni Jèhófà Máa Fi Ṣèdájọ́ Wa
13. Báwo lohun tí Jóòbù àti Dáfídì sọ ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ìwà títọ́ wa ni Jèhófà máa fi ṣèdájọ́ wa?
13 A ti wá rí i báyìí pé ìwà títọ́ ló máa jẹ́ ká lè fara mọ́ ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ. Torí náà, òun ni Ọlọ́run máa fi ṣèdájọ́ wa. Jóòbù mọ òtítọ́ yìí dájú. (Ka Jóòbù 31:6.) Jóòbù mọ̀ pé Ọlọ́run ń wọn gbogbo ẹ̀dá èèyàn lórí “òṣùwọ̀n pípéye” nípa lílo ìlànà òdodo Rẹ̀ tó pé láti mọ̀ bóyá à ń pa ìwà títọ́ wa mọ́. Dáfídì náà sọ pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn. Ṣe ìdájọ́ mi, Jèhófà, ní ìbámu pẹ̀lú òdodo mi àti ní ìbámu pẹ̀lú ìwà títọ́ mi tí ó wà nínú mi. . . . Ọlọ́run, tí ó jẹ́ olódodo, sì ń dán ọkàn-àyà àti àwọn kíndìnrín wò.” (Sm. 7:8, 9) A mọ̀ pé Ọlọ́run lè mọ irú ẹni tá a jẹ́ nínú lọ́hùn-ún, bí ìgbà tá a bá sọ pé ó ń wo “ọkàn-àyà àti àwọn kíndìnrín” wa. Àmọ́, a ò tún gbọ́dọ̀ gbàgbé ohun tó ń wá níbẹ̀. Bí Dáfídì ṣe sọ, ìwà títọ́ wa ni Jèhófà máa fi ṣèdájọ́ wa.
14. Kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ parí èrò sí pé a ò lè pa ìwà títọ́ wa mọ́ torí pé a jẹ́ aláìpé?
14 Rò ó wò ná, Jèhófà Ọlọ́run ń ṣàyẹ̀wò ọkàn àìmọye àwọn ẹ̀dá èèyàn tó wà láyé lónìí. (1 Kíró. 28:9) Báwo ló ṣe máa ń ráwọn tó ń pa ìwà títọ́ Kristẹni mọ́ tó? Ká sòótọ́, kò wọ́pọ̀! Àmọ́, kò yẹ ká wá parí èrò sí pé àìpé wa ò lè jẹ́ ká pa ìwà títọ́ mọ́ láé. Kàkà bẹ́ẹ̀, bíi ti Dáfídì àti Jóòbù àwa náà nídìí láti gbà lọ́kàn wa pé Jèhófà máa rí i pé à ń pa ìwà títọ́ wa mọ́, bá a tiẹ̀ jẹ́ aláìpé jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣó ò gbàgbé pé bá a tiẹ̀ jẹ́ ẹni pípé, ìyẹn ò ní ká pa ìwà títọ́ mọ́? Àwọn ẹni pípé mẹ́ta péré ló ti gbé ayé rí, àmọ́ méjì nínú wọn, ìyẹn Ádámù àti Éfà, ni ò pa ìwà títọ́ mọ́. Síbẹ̀, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn tó jẹ́ aláìpé ti pa ìwà títọ́ wọn mọ́. Ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀.
3. Ìwà Títọ́ Ṣe Pàtàkì Sóhun Tá À Ń Retí
15. Báwo ni Dáfídì ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ìwà títọ́ ṣe pàtàkì tá a bá fẹ́ kóhun tá à ń retí lọ́jọ́ iwájú tẹ̀ wá lọ́wọ́?
15 Torí pé ìwà títọ́ wa gan-an ni Jèhófà máa fi ṣèdájọ́ wa, ó ṣe pàtàkì kọ́wọ́ wa tó lè tẹ ohun tá à ń retí lọ́jọ́ iwájú. Dáfídì mọ òótọ́ ọ̀rọ̀ yìí dájú. (Ka Sáàmù 41:12.) Ó mọyì ìrètí tó ní pé lọ́jọ́ kan Ọlọ́run á bẹ̀rẹ̀ sí í fojú rere wo òun títí láé. Bíi tàwọn Kristẹni tòótọ́ lónìí, Dáfídì retí pé òun ṣì máa wà láàyè títí láé, tóun á sì túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run bóun ti ń sìn ín. Dáfídì mọ̀ pé òun gbọ́dọ̀ pa ìwà títọ́ mọ́ tóun bá fẹ́ kí nǹkan tóun ń retí tẹ òun lọ́wọ́. Lọ́nà kan náà, Jèhófà ń tì wá lẹ́yìn, ó ń kọ́ wa, ó ń tọ́ wa sọ́nà, ó sì ń bù kún wa bá a ṣe ń pa ìwà títọ́ wa mọ́.
16, 17. (a) Kí nìdí tó o fi pinnu láti máa pa ìwà títọ́ ẹ mọ́ ní gbogbo ìgbà? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
16 Tá a bá fẹ́ kínú wa máa dùn lónìí, ohun tá à ń retí gbọ́dọ̀ máa wà lọ́kàn wa. Ìrètí yìí lá máa fún wa láyọ̀ tá a nílò ká lè la àkókò lílekoko yìí já. Ìrètí tún lè dáàbò bo ìrònú wa. Ṣó o rántí pé Bíbélì fi ìrètí wé àṣíborí? (1 Tẹs. 5:8) Bí àṣíborí tàbí akoto ṣe máa ń dáàbò bo orí ọmọ ogun kan lójú ogun, bẹ́ẹ̀ náà ni ìrètí tá a ní ò ní jẹ́ ká máa ní ìrònú òdì tí Sátánì ti tàn kálẹ̀ nínú ayé ògbólógbòó yìí. Ká sòótọ́, ìgbésí ayé ò ní nítumọ̀ tá ò bá nírètí. Ó yẹ ká fòótọ́ inú yẹ ara wa wò, ká sì fara balẹ̀ kíyè sí ipò tí ìwà títọ́ wa àti ìrètí tá a ní wà. Má gbàgbé pé tó o bá ń pa ìwà títọ́ mọ́, ńṣe lò ń fi hàn pé o fara mọ́ ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, o sì ń dáàbò bo ìrètí tó ṣeyebíye tó o ní nípa ọjọ́ ọ̀la. A rọ̀ ẹ́ pé kó o máa bá a nìṣó láti ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti máa pa ìwà títọ́ rẹ mọ́!
17 Nígbà tá a ti wá rí bí ìwà títọ́ ṣe ṣe pàtàkì tó, ó yẹ ká gbé àwọn ìbéèrè mélòó kan yẹ̀ wò. Kí la lè ṣe láti ní ìwà títọ́? Báwo la ò ṣe ní jẹ́ kí ìwà títọ́ wa bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́? Kí sì lọ̀nà àbáyọ, tẹ́nì kan ò bá pa ìwà títọ́ ẹ̀ mọ́ láwọn àkókò kan? Àpilẹ̀kọ tó kàn máa dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Jésù sọ pé: “Kí ẹ jẹ́ pípé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, bí Baba yín ọ̀run ti jẹ́ pípé.” (Mát. 5:48) Ó dájú pé Jésù mọ̀ pé àwa èèyàn aláìpé náà lè ṣe nǹkan tó máa pé pérépéré, tàbí ká jẹ́ ẹni pípé, dé ìwọ̀n àyè kan. A lè ṣègbọràn sí àṣẹ náà pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn látọkàn wá, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ múnú Ọlọ́run dùn. Àmọ́ ní ti Jèhófà, gbogbo ọ̀nà ló fi jẹ́ pípé. Nígbà tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà, ọ̀rọ̀ náà “ìwà títọ́” wé mọ́ ìjẹ́pípé.—Sm. 18:30.
Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
• Kí ni ìwà títọ́?
• Báwo ni ìwà títọ́ ṣe kan ọ̀ràn ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ?
• Báwo ni ìwà títọ́ ṣe lè jẹ́ kọ́wọ́ wa tẹ ohun tá à ń retí?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́ máa ń jẹ́ kó ṣòro láti pa ìwà títọ́ mọ́