Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Wàá Pa Ìwà Títọ́ Rẹ Mọ́?

Ṣé Wàá Pa Ìwà Títọ́ Rẹ Mọ́?

Ṣé Wàá Pa Ìwà Títọ́ Rẹ Mọ́?

“Títí èmi yóò fi gbẹ́mìí mì, èmi kì yóò mú ìwà títọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi!”—JÓÒBÙ 27:5.

1, 2. Kí ló yẹ ká sapá láti ṣe bí ìgbà téèyàn ń sapá láti kọ́lé, àwọn ìbéèrè wo la sì máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí?

 KÁ SỌ pé ò ń ṣàyẹ̀wò àwòrán bí wọ́n ṣe fẹ́ kọ́ ilé kan fún ẹ tí àwòrán yẹn sì jọ ẹ́ lójú gan-an. O wá jókòó láti ronú lórí bí ilé yẹn ṣe máa ṣe ìwọ, àwọn ọmọ àtìyàwó ẹ láǹfààní. Ó dájú pé o ò ní jiyàn pé kò sáǹfààní kankan tí àwòrán ilé yẹn àtohun tó o bá rò nípa ẹ̀ máa ṣe fún ẹ àyàfi tó o bá ti kọ́lé yẹn tán, tó o kó sínú ẹ̀, tó o sì ń bójú tó o dáadáa.

2 Bọ́rọ̀ ìwà títọ́ náà ṣe rí nìyẹn. A lè ronú pé ànímọ́ tó máa ṣe àwa àtàwọn tá a fẹ́ràn láǹfààní ni, àmọ́ kò sáǹfààní tí wíwulẹ̀ ronú lọ́nà yìí máa ṣe wá tá ò bá kọ́kọ́ ní ìwà títọ́ ká sì ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti pa ìwà títọ́ Kristẹni wa mọ́. Lásìkò tá a wà yìí, owó kékeré kọ́ lèèyàn máa ná tó bá fẹ́ kọ́lé. (Lúùkù 14:28, 29) Bákan náà, ó máa ń gba ọ̀pọ̀ àkókò àti ìsapá kéèyàn tó lè níwà títọ́, àmọ́ ó tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Torí náà, ẹ jẹ́ ká wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè mẹ́ta yìí: Kí la ní láti ṣe ká tó lè ní ìwà títọ́? Báwo la ò ṣe ní jẹ́ kí ìwà títọ́ Kristẹni bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́? Kí sì lọ̀nà àbáyọ, tẹ́nì kan ò bá pa ìwà títọ́ ẹ̀ mọ́ láwọn àkókò kan?

Kí La Ní Láti Ṣe Ká Tó Lè Ní Ìwà Títọ́?

3, 4. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń kọ́ wa láti máa hùwà títọ́? (b) Báwo la ṣe lè fara wé Jésù tó bá di pé ká hùwà títọ́?

3 Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, a kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà ti fún wa láǹfààní láti pinnu bóyá a ó máa hùwà títọ́. Àmọ́, a láyọ̀ pé kò dá wa dá ọ̀rọ̀ wa. Ó ń kọ́ wa láti máa fi ànímọ́ tó ṣeyebíye yìí ṣèwà hù, ó sì ń fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ lọ́pọ̀ yanturu, kó lè ràn wá lọ́wọ́ láti fàwọn ohun tá à ń kọ́ sílò. (Lúùkù 11:13) Yàtọ̀ síyẹn, tó bá dọ̀ràn ìjọsìn, Jèhófà ń dáàbò bo àwọn tó ń sapá láti máa hùwà títọ́.—Òwe 2:7.

4 Báwo ni Jèhófà ṣe ń kọ́ wa láti máa pa ìwà títọ́ mọ́? Olórí ọ̀nà tó gbà ń kọ́ wa ni rírán tó rán Jésù, Ọmọ rẹ̀ wá sáyé. Nígbà tí Jésù wà láyé, ó ṣègbọràn láìkù síbì kan. Ó “di onígbọràn títí dé ikú.” (Fílí. 2:8) Jésù ṣègbọràn sí Bàbá rẹ̀ ọ̀run nínú gbogbo ohun tó ṣe, kódà nígbà tí kò rọrùn fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sọ fún Jèhófà pé: “Kì í ṣe ìfẹ́ mi ni kí ó ṣẹ, bí kò ṣe tìrẹ.” (Lúùkù 22:42) Ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé bí èmi náà ṣe ń ṣègbọràn nìyẹn?’ Tá a bá ń ṣègbọràn látọkàn wá, ó máa ṣeé ṣe fún wa láti máa hùwà títọ́. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn apá díẹ̀ nígbèésí ayé wa tí ṣíṣègbọràn ti ṣe pàtàkì jù lọ.

5, 6. (a) Báwo ni Dáfídì ṣe jẹ́ ká rí bí pípa ìwà títọ́ mọ́ ṣe ṣe pàtàkì tó kódà nígbà tá a bá dá wà? (b) Àwọn ìṣòro wo ló ń dojú kọ àwa Kristẹni lónìí tó bá kan ọ̀ràn ká pa ìwà títọ́ mọ́ nígbà tá a bá dá wà?

5 A ní láti ṣègbọràn sáwọn àṣẹ Jèhófà, kódà nígbà tó bá dà bíi pé kò sẹ́nì kankan tó ń rí wa. Dáfídì tó kọ lára ìwé Sáàmù rí i pó ṣe pàtàkì láti máa hùwà títọ́ nígbà tóun bá dá wà. (Ka Sáàmù 101:2.) Torí pé ọba ni Dáfídì, kì í sábà dá wà. Kò sí àníàní pé lọ́pọ̀ ìgbà, ọgọ́rọ̀ọ̀rún kódà ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló máa ń wà lọ́dọ̀ rẹ̀. (Fi wé Sáàmù 26:12.) Pípa ìwà títọ́ mọ́ nírú àwọn àkókò wọ̀nyí ṣe pàtàkì gan-an fún Dáfídì, torí ọba gbọ́dọ̀ fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn èèyàn rẹ̀. (Diu. 17:18, 19) Àmọ́, Dáfídì kẹ́kọ̀ọ́ pé òun ṣì ní láti máa pa ìwà títọ́ òun mọ́ nígbà tí kò bá sáwọn èèyàn lọ́dọ̀ òun, ìyẹn nígbà tó bá wà ‘nínú ilé rẹ̀.’ Àwa ńkọ́?

6 Dáfídì ló sọ ohun tó wà nínú Sáàmù 101:3, ó ní: “Èmi kì yóò gbé ohun tí kò dára fún ohunkóhun ka iwájú mi.” Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan wà tá a lè ṣe lónìí tó máa dà bí ìgbà tá à ń gbé ohun tí ò dáa síwájú ara wa, àgàgà nígbà tí kò bá sẹ́nì kankan lọ́dọ̀ wa. Lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì ti di ìṣòro sáwọn èèyàn lọ́rùn lórí ọ̀rọ̀ yìí. Ó rọrùn láti wo àwọn àwòrán ìṣekúṣe. Àmọ́ ṣé a lè sọ pé ẹni tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ ń ṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run tó mí sí Dáfídì láti kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sílẹ̀? Àwòrán ìṣekúṣe léwu gan-an torí ńṣe ló máa ń jẹ́ kí èròkerò àti ìmọtara-ẹni-nìkan wọni lọ́kàn, ó máa ń ba ẹ̀rí ọkàn jẹ́, ó máa ń tú ìgbéyàwó ká, ó sì máa ń sọ àwọn tó ń wò ó dìdàkudà.—Òwe 4:23; 2 Kọ́r. 7:1; 1 Tẹs. 4:3-5.

7. Ìlànà wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa pa ìwà títọ́ mọ́ nígbà tá a bá dá wà?

7 Ká sòótọ́, kò sí ìránṣẹ́ Jèhófà tó lè sọ pé òun dá wà. Gbogbo ohun tá à ń ṣe ni Bàbá wa ọ̀run ń wò tìfẹ́tìfẹ́. (Ka Sáàmù 11:4.) O ò rí i bínú Jèhófà ṣe máa dùn tó, tó bá rí i pó ò gbà kí ìdẹwò èyíkéyìí ba ìwà títọ́ ẹ jẹ́! Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe lò ń ṣègbọràn sí ìkìlọ̀ tó ṣe kedere tí Jésù fún wa nínú Mátíù 5:28. Torí náà, pinnu pé o ò ní wo àwòrán tó lè mú kó o ṣìwà hù. Má ṣe sọ ìwà títọ́ ẹ nù nítorí wíwo àwòrán ìṣekúṣe tàbí kíka ohunkóhun tó lè mú ọkàn rẹ fà sí ìṣekúṣe!

8, 9. (a) Ìṣòro wo ni Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ dojú kọ nípa ìwà títọ́ wọn? (b) Báwo làwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni lónìí ṣe lè múnú Jèhófà àtàwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni dùn?

8 A tún lè pa ìwà títọ́ wa mọ́ nípa ṣíṣègbọràn sáwọn àṣẹ Jèhófà nígbà tá a bá wà lọ́dọ̀ àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Ọ̀dọ́ ni wọ́n nígbà táwọn ará Bábílónì kó wọn lẹ́rú. Ìṣòro tí wọ́n dojú kọ ò kéré rárá, torí àárín àwọn tí kì í ṣe olùjọ́sìn Jèhófà ni wọ́n wà, ó sì lè máa wù wọ́n láti jẹ àwọn oúnjẹ tó dọ́ṣọ̀ tí ọba ní kí wọ́n fún wọn jẹ, àmọ́ tí Òfin Ọlọ́run kà léèwọ̀. Ó rọrùn fáwọn ọmọdékùnrin wọ̀nyẹn láti ronú pé jíjẹ oúnjẹ àdídùn ò ba ìgbàgbọ́ jẹ́. Ó ṣe tán, àwọn òbí wọn ò sí níbẹ̀, kò sí alàgbà, kò sì sáwọn àlùfáà nítòsí tó lè mọ ohun tí wọ́n ń ṣe. Àmọ́ ta ló máa mọ̀? Jèhófà fúnra rẹ̀ ni. Torí náà, wọ́n dúró lórí ìpinnu wọn, wọ́n sì ṣègbọràn sí Jèhófà láìka báwọn èèyàn ṣe ń rọ̀ wọ́n àti ewu tó rọ̀ mọ́ ọn sí.—Dán. 1:3-9.

9 Kárí ayé làwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń fara wé àwọn ọ̀dọ́ Hébérù wọ̀nyí, wọ́n ń ṣègbọràn sáwọn àṣẹ tí Ọlọ́run fáwọn Kristẹni, wọ́n sì ń kọ̀ láti jẹ́ kí ẹ̀mí dà-bí-mo-ṣe-dà tó wà nínú ayé máa darí wọn. Gbogbo ìgbà tẹ́yin ọ̀dọ́ bá ti kọ̀ láti lo oògùn olóró, tẹ́ ẹ kọ̀ láti hùwà ipá, tẹ́ ò jẹ́ kọ́rọ̀ rírùn jáde lẹ́nu yín, tẹ́ ẹ kọ̀ láti ṣèṣekúṣe, tẹ́ ò sì lọ́wọ́ sáwọn ìwàkiwà míì, Jèhófà lẹ̀ ń ṣègbọràn sí. Tẹ́ ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe lẹ̀ ń pa ìwà títọ́ yín mọ́. Ẹ máa tipa bẹ́ẹ̀ ṣera yín láǹfààní, ẹ sì máa múnú Jèhófà àtàwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ Kristẹni dùn!—Sm. 110:3.

10. (a) Èròkerò wo làwọn ọ̀dọ́ kan ti ní nípa àgbèrè, tó sì ti jẹ́ kí wọ́n sọ ìwà títọ́ wọn nù? (b) Kí ni ìwà títọ́ máa jẹ́ ká ṣe tó bá dọ̀rọ̀ ewu tó wà nínú àgbèrè?

10 A tún gbọ́dọ̀ ṣègbọràn tó bá kan bá a ṣe ń ṣe sáwọn tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiwa. A mọ̀ dájú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé a ò gbọ́dọ̀ ṣàgbèrè. Àmọ́, ó rọrùn fẹ́ni tó ti ń ṣègbọràn tẹ́lẹ̀ láti wá dẹni tí ò ka nǹkan sí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọ̀dọ́ kan máa ń fi ahọ́n lá ẹ̀yà ìbímọ ara wọn, wọ́n máa ń ti ihò ìdí bára wọn ṣèṣekúṣe tàbí kí wọ́n máa fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ara wọn kára wọn lè gbóná sódì, wọ́n á wá máa ronú pé ohun táwọn ń ṣe ò tíì burú tó bẹ́ẹ̀ torí àwọn ò ṣáà tíì bá onítọ̀hún sùn ní tààràtà. Irú àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ lè ti gbàgbé, tàbí kí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ fojú kéré ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Bíbélì tá a tú sí àgbèrè, ìtumọ̀ yẹn kan àwọn ìwà pálapàla wọ̀nyí, wọ́n sì lè torí ẹ̀ yọ ẹnì kan lẹ́gbẹ́. a Ohun tó wá burú jù ni pé àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyẹn ò rídìí tó fi yẹ káwọn máa hùwà títọ́. Torí pé gbogbo wa là ń sapá láti pa ìwà títọ́ wa mọ́, kò sídìí fún wa láti máa wá àwíjàre. Kò yẹ ká máa fẹ́ sún mọ́ bèbè ẹ̀ṣẹ̀ ká má sì fẹ́ jìyà ẹ̀ṣẹ̀. Bẹ́ẹ̀ la ò sì ní máa ronú lórí ìyà tí ìjọ Ọlọ́run máa fi jẹ wá nìkan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó máa múnú Jèhófà dùn la fẹ́ máa ṣe, ká máa yẹra fóhun tó máa dùn ún. Dípò ká máa ronú lórí ibi tá a lè sún mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mọ, ńṣe la fẹ́ jìnnà sí i, ká bàa lè “sá fún àgbèrè.” (1 Kọ́r. 6:18) Ìyẹn á fi hàn pé lóòótọ́ là ń hùwà títọ́.

Báwo La Ṣe Lè Máa Pa Ìwà Títọ́ Wa Mọ́?

11. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti máa ṣègbọràn nígbà gbogbo? Ṣàpèjúwe.

11 Ìgbọràn ló ń jẹ́ ká máa hùwà títọ́, torí náà tá a bá fẹ́ máa pa ìwà títọ́ wa mọ́ a gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti máa ṣègbọràn. Àìgbọràn lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo lè dà bí ohun tí ò já mọ́ nǹkan kan, àmọ́ bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, èèyàn lè sọ ọ́ dàṣà. Àpèjúwe kan rèé: Búlọ́ọ̀kù ìkọ́lé kan ṣoṣo lè dà bí ohun tí ò tó nǹkan, àmọ́ béèyàn bá fara balẹ̀ to ọ̀pọ̀lọpọ̀ búlọ́ọ̀kù pa pọ̀, èèyàn lè kọ́ ilé tó rẹwà. Torí náà tá a bá fẹ́ pa ìwà títọ́ mọ́, àfi ká máa bá a nìṣó láti máa ṣègbọràn.—Lúùkù 16:10.

12. Báwo ni Dáfídì ṣe fàpẹẹrẹ rere lélẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ pípa ìwà títọ́ mọ́ nígbà táwọn èèyàn bá fọwọ́ ọlá gbá wa lójú tàbí tí wọ́n bá rẹ́ wa jẹ?

12 Ìgbà tá a bá fara da àwọn nǹkan tí kò rọgbọ, táwọn èèyàn bá fọwọ́ ọlá gbá wa lójú tàbí tí wọ́n rẹ́ wa jẹ ló máa ń hàn sáwọn èèyàn pé lóòótọ́ là ń pa ìwà títọ́ wa mọ́. Àpẹẹrẹ Dáfídì tó wà nínú Bíbélì máa ràn wá lọ́wọ́. Nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, ó fara da inúnibíni látọwọ́ ọba tó yẹ kó ṣojú fún ọlá àṣẹ Jèhófà. Àmọ́ nígbà tí Jèhófà ò fojú rere wo Sọ́ọ̀lù Ọba mọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí í jowú Dáfídì tí Ọlọ́run yàn. Síbẹ̀, Sọ́ọ̀lù ṣì wà lórí àlééfà fún àkókò díẹ̀, ó sì lo àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì láti gbógun ti Dáfídì. Jèhófà fàyè gba ìwà ìrẹ́nijẹ yìí fún ọdún mélòó kan. Ṣé Dáfídì bínú sí Ọlọ́run torí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí? Àbí ńṣe ló ronú pé kò tiẹ̀ sídìí tó fi yẹ kóun máa fara dà á mọ́? Rárá kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ó bọ̀wọ̀ fún ojúṣe tí Jèhófà fún Sọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ bí ẹni àmì òróró Ọlọ́run, ó sì kọ̀ láti ṣeé ní jàǹbá nígbà tó láǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀.—1 Sám. 24:2-7.

13. Báwo la ṣe lè pa ìwà títọ́ wa mọ́ nígbà tẹ́nì kan bá já wa kulẹ̀ tàbí tó ṣohun tó dùn wá?

13 Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà tí Dáfídì fi lélẹ̀ yìí wúlò gan-an fún wa lónìí! A wà lára ẹgbẹ́ ará kárí ayé, aláìpé sì ni gbogbo wa, ẹnikẹ́ni nínú àwọn ará ló lè ṣohun tó máa dùn wá tàbí tó tiẹ̀ lè di aláìṣòótọ́. Àmọ́ a láyọ̀ pé lákòókò tá à ń gbé yìí kò ṣeé ṣe pé kí gbogbo àwọn èèyàn Jèhófà lápapọ̀ di aláìṣòótọ́. (Aísá. 54:17) Síbẹ̀, kí la máa ṣe tẹ́nì kan nínú ìjọ bá já wa kulẹ̀ tàbí tó ṣohun tó dùn wa gan-an? Tá a bá jẹ́ kínú tó ń bí wa sẹ́nì kan tá a jọ jẹ́ Kristẹni gbà wá lọ́kàn jù, ìyẹn lè ṣàkóbá fún ìwà títọ́ wa. Ìwà táwọn èèyàn ń hù sí wa kò ní ká máa bínú sí Ọlọ́run tàbí ká torí ẹ̀ pa ìwà títọ́ tì. (Sm. 119:165) Tá a bá ń fara da àdánwò, ìyẹn á ràn wá lọ́wọ́ láti máa pa ìwà títọ́ wa mọ́.

14. Kí làwọn tó ń pa ìwà títọ́ mọ́ máa ń ṣe nígbà táwọn ìyípadà kan bá wáyé nínú ètò Ọlọ́run tàbí táwọn àlàyé tó dá lórí àwọn ẹsẹ Bíbélì kan bá yí pa dà?

14 A tún lè máa pa ìwà títọ́ mọ́ tá ò bá kí í ṣàríwísí àwọn ẹlòmíì, tá a kì í sì í wá àṣìṣe wọn lójú méjèèjì. Ìyẹn á fi hàn pé a jólóòótọ́ sí Jèhófà. Ó ń bù kún àwọn èèyàn rẹ̀ báyìí ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Kò tí ì sígbà kankan nínú ìtàn táwọn èèyàn fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn mímọ́ báyìí rí. (Aísá. 2:2-4) Nígbà táwọn ìyípadà kan bá wáyé nípa àlàyé tó dá lórí àwọn ẹsẹ Bíbélì kan tàbí nípa bó ṣe yẹ ká máa ṣe nǹkan, ó yẹ ká gbà wọ́n tọwọ́ tẹsẹ̀. Inú wa dùn gan-an bá a ṣe ń rí àwọn ẹ̀rí tó jẹ́ ká mọ̀ pé ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí ṣì ń mọ́lẹ̀ nìṣó. (Òwe 4:18) Tí kò bá rọrùn fún wa láti lóye ìdí táwọn ìyípadà kan fi wáyé, ẹ jẹ́ ká gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè lóye rẹ̀. Àmọ́, a ó ṣì máa bá a nìṣó láti ṣègbọràn, ìyẹn á sì fi hàn pé lóòótọ́ là ń pa ìwà títọ́ wa mọ́.

Tẹ́nì Kan Ò Bá Pa Ìwà Títọ́ Ẹ̀ Mọ́ Ńkọ́?

15. Ta lẹnì kan ṣoṣo tó lè gba ìwà títọ́ ẹ mọ́ ẹ lọ́wọ́?

15 Ìbéèrè tó ń múni ronú jinlẹ̀ lèyí, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Bá a ṣe kẹ́kọ̀ọ́ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, ìwà títọ́ ṣe pàtàkì gan-an. Tá ò bá ní ìwà títọ́, kò sí bá a ṣe lè ní àjọṣe kankan pẹ̀lú Jèhófà, a ò sì ní nírètí tó dájú. Má gbàgbé pé ẹnì kan péré ní gbogbo ayé, ló lè gba ìwà títọ́ ẹ mọ́ ẹ lọ́wọ́. Ìwọ alára sì lẹni náà. Jóòbù mọ òtítọ́ yìí dájú. Ó sọ pé: “Títí èmi yóò fi gbẹ́mìí mì, èmi kì yóò mú ìwà títọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi!” (Jóòbù 27:5) Tó bá jẹ́ pé ìpinnu tìẹ náà nìyẹn, tó ò sì jìnnà sí Jèhófà, kò sóhun tó máa gba ìwà títọ́ ẹ mọ́ ẹ lọ́wọ́.—Ják. 4:8.

16, 17. (a) Tẹ́nì kan bá ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì, kí ni kò yẹ kó ṣe? (b) Kí ló yẹ kó ṣe?

16 Àmọ́ ṣá o, àwọn kan ti sọ ìwà títọ́ wọn nù. Bó ṣe ṣẹlẹ̀ nígbà ayé àwọn àpọ́sítélì, àwọn kan lónìí náà ti dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì. Tíyẹn bá ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ, ṣó wá túmọ̀ sí pé kò sọ́nà àbáyọ ni? Kò fi dandan rí bẹ́ẹ̀. Kí lo lè ṣe sí i? Jẹ́ ká kọ́kọ́ jíròrò ohun tí kò yẹ kó o ṣe. Ohun tó máa ń wá sọ́kàn ẹ̀dá èèyàn ni pé kó ṣe ọ̀rọ̀ náà láṣìírí, káwọn òbí, àwọn ará àtàwọn alàgbà má bàa mọ̀ nípa ẹ̀. Àmọ́, Bíbélì rán wa létí pé: “Ẹni tí ó bá ń bo àwọn ìrélànàkọjá rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì yóò kẹ́sẹ járí, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ tí ó sì fi wọ́n sílẹ̀ ni a ó fi àánú hàn sí.” (Òwe 28:13) Àṣìṣe ńlá làwọn tó ń bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn ń ṣe, torí kò sóhun tó pa mọ́ lójú Ọlọ́run. (Ka Hébérù 4:13.) Àwọn kan tiẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbésí ayé méjì, wọ́n á máa ṣe bíi pé àwọn ń sin Jèhófà síbẹ̀ wọ́n ń yọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì dá lábẹ́lẹ̀. Irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀ ò fi hàn pé èèyàn ń hùwà títọ́, kódà òdìkejì ìwà títọ́ lẹni yẹn ń hù níwà. Inú Jèhófà kì í sì í dùn sí iṣẹ́ ìsìn ẹnikẹ́ni tó bá ń bo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ìwà àgàbàgebè yìí máa ń bí i nínú.—Òwe 21:27; Aísá. 1:11-16.

17 Nígbà tí Kristẹni kan bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì, ohun tó yẹ kó ṣe wà nínú Bíbélì. Ìgbà yẹn gan-an ló yẹ kó lọ bá àwọn alàgbà pé kí wọ́n ran òun lọ́wọ́. Jèhófà ti ṣètò bí ẹni tó bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì ṣe máa rí ìrànlọ́wọ́ gbà nípa tẹ̀mí. (Ka Jákọ́bù 5:14.) Má ṣe jẹ́ kí ìjìyà tàbí ìbáwí tí wọ́n máa fún ẹ bà ẹ́ lẹ́rù débi tó ò fi ní lè gba ìwòsàn nípa tẹ̀mí. Ó ṣe tán, ọlọ́gbọ́n èèyàn ò ní ro ti pé abẹ́rẹ́ máa dun òun tàbí pé iṣẹ́ abẹ máa ro òun lára, kó wá pa àìsàn ńlá mọ́ra.—Héb. 12:11.

18, 19. (a) Báwo ni àpẹẹrẹ Dáfídì ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ẹni tó ti dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì tún lè pa dà máa hùwà títọ́? (b) Kí lo pinnu láti ṣe nípa ìwà títọ́ rẹ?

18 Ṣẹ́ni tó ti sọ ìwà títọ́ nù tún lè pa dà bọ̀ sípò nípa tẹ̀mí pátápátá? Ṣẹ́ni náà tún lè ní ìwà títọ́ pa dà? Tún gbé àpẹẹrẹ Dáfídì yẹ̀ wò. Ó dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì. Ojúkòkòrò tó ní mú kí ọkàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí ìyàwó oníyàwó, ó ṣàgbèrè, ó sì ṣètò pé kí wọ́n pa ọkọ obìnrin yẹn. Ó dájú pé kò sẹ́ni tó máa sọ pé Dáfídì hùwà títọ́ nígbà yẹn, àbí? Àmọ́, ṣé kò sọ́nà àbáyọ ni? Dáfídì nílò ìbáwí ó sì gba ìbáwí tó múná. Síbẹ̀, Jèhófà ṣàánú ẹ̀ torí pé ó ronú pìwà dà látọkàn wá. Dáfídì kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìbáwí tó gbà, ó sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà títọ́ nípa bíbá a nìṣó láti máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Ìgbésí ayé Dáfídì jẹ́ ká mọ̀ pé òótọ́ lọ̀rọ̀ inú ìwé Òwe 24:16 tó sọ pé: “Olódodo lè ṣubú ní ìgbà méje pàápàá, yóò sì dìde dájúdájú.” Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Ka ohun tí Jèhófà sọ fún Sólómọ́nì nípa Dáfídì lẹ́yìn tí Dáfídì kú. (Ka 1 Ọba 9:4.) Ọlọ́run rántí Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń pa ìwà títọ́ mọ́. Kò sí àníàní pé Jèhófà lè mú àbàwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ kúrò lára ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà, kódà àbàwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì pàápàá.—Aísá. 1:18.

19 Ó dájú pé tó o bá ń ṣègbọràn sí Jèhófà nítorí pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, wàá lè máa hùwà títọ́. Máa bá a nìṣó láti fara dà á láìyẹsẹ̀, tó o bá sì dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, ṣe ni kó o ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Ó dájú pé ìwà títọ́ wa ṣeyebíye gan-an ni! Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ṣerú ìpinnu tí Dáfídì ṣe nígbà tó sọ pé: “Ní tèmi, èmi yóò máa rìn nínú ìwà títọ́ mi.”—Sm. 26:11.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Ilé Ìṣọ́ February 15, 2004, ojú ìwé 13, ìpínrọ̀ 15.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Báwo lo ṣe lè máa pa ìwà títọ́ mọ́?

• Kí lo lè ṣe tó ò fi ní jẹ́ kí ìwà títọ́ rẹ bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́?

• Báwo lẹni tó ti dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì ṣe lè pa dà máa hùwà títọ́?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]

“Èyí Mà Dáa Gan-an O”

Obìnrin kan tó lóyún oṣù márùn-ún ló sọ bẹ́ẹ̀ nípa inú rere àti ìwà títọ́ tẹ́nì kan hù sí i. Wákàtí mélòó kan lẹ́yìn tó kúrò nínú ṣọ́ọ̀bù kan tí wọ́n ti ń ta kọfí ló rántí pé òun ti gbàgbé pọ́ọ̀sì òun síbẹ̀. Ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] owó dọ́là ló wà nínú pọ́ọ̀sì náà, kì í sì í sábà gbé owó tó tóyẹn dání. Ó sọ fún àwọn akọ̀ròyìn kan pé: “Nǹkan tojú sú mi.” Àmọ́, obìnrin kan rí pọ́ọ̀sì yẹn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá ẹni tó ni ín kiri lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Nígbà tí kò rẹ́ni tó ni ín, ó mú pọ́ọ̀sì náà lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá, àwọn ọlọ́pàá sì wá aláboyún náà kàn. Obìnrin tó ni owó yẹn fi ìmọrírì hàn, ó ní: “Èyí mà dáa gan-an o.” Kí nìdí tí obìnrin yẹn fi ṣe wàhálà tó pọ̀ tóyẹn láti dá owó náà pa dà? Ìwé ìròyìn yẹn sọ pé gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà “ẹ̀sìn tí wọ́n ti tọ́ obìnrin náà dàgbà ló jẹ́ kó máa hùwà títọ́.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Àwọn ọ̀dọ́ lè pa ìwà títọ́ mọ́ nígbà tí wọ́n bá dojú kọ àdánwò

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Dáfídì kùnà láti pa ìwà títọ́ mọ́ nígbà kan, àmọ́ ó borí ẹ̀