Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mo Ti Rí Báwọn Èèyàn Ọlọ́run Ṣe Ń pọ̀ Sí I Lórílẹ̀-èdè Kòríà

Mo Ti Rí Báwọn Èèyàn Ọlọ́run Ṣe Ń pọ̀ Sí I Lórílẹ̀-èdè Kòríà

Mo Ti Rí Báwọn Èèyàn Ọlọ́run Ṣe Ń pọ̀ Sí I Lórílẹ̀-èdè Kòríà

Gẹ́gẹ́ bí Milton Hamilton ṣe sọ ọ́

“Ó dùn wá láti sọ fún yín pé ìjọba orílẹ̀-èdè Kòríà ti gbẹ́sẹ̀ lé gbogbo ìwé ìrìnnà ẹ̀yin míṣọ́nnárì, wọ́n sì sọ pé àwọn ò fẹ́ yín lórílẹ̀-èdè àwọn. . . . Nítorí náà, a ti ṣètò pé kẹ́ ẹ ṣì máa lọ sìn lórílẹ̀-èdè Japan fúngbà díẹ̀ ná.”

BÍ ỌDÚN 1954 ṣe ń parí lọ lèmi àti ìyàwó mi gba lẹ́tà yìí láti Brooklyn, ní ìpínlẹ̀ New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yẹn làwa méjèèjì kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kẹtàlélógún [23] Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì tó wà ní àríwá ìpínlẹ̀ náà. Indianapolis ní ìpínlẹ̀ Indiana la ti ń sìn nígbà tá a gba lẹ́tà yìí.

Kíláàsì kan náà lèmi àti Liz ìyàwó mi wà nígbà tá a wà níléèwé girama. (Liz Semock ló ń jẹ́ tẹ́lẹ̀) Nígbà tó di ọdún 1948, a ṣègbéyàwó. Ó fẹ́ràn iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún gan-an, àmọ́ kò wù ú kó kúrò lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láti lọ sìn lórílẹ̀-èdè míì. Kí ló wá yí èrò rẹ̀ pa dà?

Liz gbà láti tẹ̀ lé mi lọ sípàdé kan tó wà fáwọn tó bá fẹ́ lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Àpéjọ àgbáyé tá a ṣe ní pápá ìṣeré Yankee, ní ìpínlẹ̀ New York nígbà ẹ̀rùn ọdún 1953 la ti ṣe ìpàdé yìí. Lẹ́yìn ìpàdé tó fúnni níṣìírí yẹn, a gba fọ́ọ̀mù Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, a sì dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà níbẹ̀. Ó yà wá lẹ́nu nígbà tí wọ́n pè wá pé ká wá sí kíláàsì tó tẹ̀ lé e, èyí tó bẹ̀rẹ̀ lóṣù February, ọdún 1954.

Wọ́n ní ká lọ sìn lórílẹ̀-èdè Kòríà bó tilẹ̀ jẹ́ pé ogun tí wọ́n jà fún ọdún mẹ́ta lórílẹ̀-èdè náà ṣẹ̀ṣẹ̀ parí nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1953 ni, ó sì ti ba orílẹ̀-èdè yẹn jẹ́ gan-an. Àmọ́, bó ṣe wà nínú lẹ́tà tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lókè yìí, orílẹ̀-èdè Japan la kọ́kọ́ lọ. Lẹ́yìn tá a rìnrìn àjò ogúnjọ́ [20] lórí òkun, àwa àtàwọn míṣọ́nnárì mẹ́fà míì tí wọ́n yàn sí orílẹ̀-èdè Kòríà dé sí Japan lóṣù January, ọdún 1955. Lloyd Barry tó jẹ́ alábòójútó ẹ̀ka lórílẹ̀-èdè Japan nígbà yẹn wá pàdé wa bá a ṣe fẹ́ sọ kalẹ̀ lórí omi ní aago mẹ́fà òwúrọ̀. Láìpẹ́, a gbéra ó dilé àwọn míṣọ́nnárì nílùú Yokohama. Lọ́jọ́ yẹn kan náà, a lọ sóde ẹ̀rí.

A Dé Orílẹ̀-Èdè Kòríà Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín

Kò pẹ́ tá a dé orílẹ̀-èdè Japan la rí ìwé ìrìnnà tó máa jẹ́ ká lè wọ orílẹ̀-èdè Kòríà gbà. Ní March 7, ọdún 1955, ọkọ̀ òfuurufú wa gbéra ní pápákọ̀ òfúrufú Haneda tó wà nílùú Tọ́kíyò lọ sí pápákọ̀ òfúrufú Yoido tó wà nílùú Seoul, wákàtí mẹ́ta la sì fi rìnrìn-àjò ọ̀hún. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà lórílẹ̀-èdè Kòríà tó wá pàdé wa ju igba [200] lọ, orí wa wú gan-an ni, omijé ayọ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí í dà lójú àwa àtàwọn tó wá pàdé wa. Nígbà yẹn, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà lórílẹ̀-èdè Kòríà ò ju ẹgbẹ̀rún kan [1,000] lọ. Ńṣe làwa tá à ń gbé ní Ìlà Oòrùn ayé máa ń rò pé gbogbo àwọn tó ń gbé ní ìwọ̀ oòrùn ló fojú jọra wọn, tí wọ́n sì máa ń hùwà bákan náà bí orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti wá tiẹ̀ yàtọ̀ síra. Àmọ́, kò pẹ́ tá a fi mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ò rí bá a ṣe rò. Yàtọ̀ sí pé àwọn ará Kòríà ní èdè àti ááfábẹ́ẹ̀tì tiwọn, bí wọ́n ṣe ń se oúnjẹ wọn, ìrísí wọn, ìmúra wọn, bí wọ́n ṣe máa ń kọ́lé àti bí wọ́n ṣe máa ń ṣàwọn nǹkan míì yàtọ̀ pátápátá sí tàwọn orílẹ̀-èdè míì.

Bá a ṣe máa kọ́ èdè wọn ni ìṣòro wa àkọ́kọ́. A ò ní ìwé kankan tá a lè fi kọ́ èdè àwọn ará Kòríà. Kò pẹ́ tó fi yé wa pé kò sí béèyàn ṣe lè fi ohùn èdè Gẹ̀ẹ́sì pe àwọn ọ̀rọ̀ wọn kó sì bá a mu gẹ́lẹ́. Kéèyàn tó lè mọ báwọn ará Kòríà ṣe ń pe ọ̀rọ̀, àfi kéèyàn kọ́kọ́ kọ́ ááfábẹ́ẹ̀tì wọn.

A máa ń gbé e gbági lọ́pọ̀ ìgbà. Ọ̀kan lèyí tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kan nígbà tí Liz, ìyàwó mi fẹ́ béèrè lọ́wọ́ onílé bóyá ó ní Bíbélì. Ohun tíyàwó mi béèrè ya onílé yẹn lẹ́nu, àmọ́ ó wọlé lọ nígbà tó sì máa jáde, páálí ìṣáná kan ló mú wá. Sungnyang, ìyẹn ìṣáná, ni Liz béèrè fún dípò sungkyung, ìyẹn Bíbélì.

Lẹ́yìn oṣù díẹ̀, wọ́n gbé wa lọ sílùú Pusan, ìlú kan tó wà ní etíkun gúúsù orílẹ̀-èdè Kòríà, àwa sì ni míṣọ́nnárì àkọ́kọ́ tó máa lọ sílùú yẹn. A gba yàrá mẹ́ta fún èmi àti ìyàwó mi àtàwọn arábìnrin méjì tí wọ́n yàn pẹ̀lú wa. Kò sí omi ẹ̀rọ nínú àwọn yàrá wọ̀nyẹn, kò sì sí ṣáláńgá aláwo. Òru nìkan ni omi máa ń yọ ní àjà kejì ilé náà. Torí náà, ńṣe la máa ń pín omi pọn, ẹni tó bá sì kàn máa ní láti tètè jí láàárọ̀ kó lè lọ gbọ́n omi nínú àwọn àgbá tó wà nílé náà. A máa ń se omi yẹn tàbí ká fi kẹ́míkà tí wọ́n ń pè ní chlorine sí i kó lè dáa fún mímu.

A tún láwọn ìṣòro míì. Iná mànàmáná ò gbé ẹ̀rọ tá a fi ń fọṣọ àtèyí tá a fi ń lọṣọ. Àárín ọ̀ọ̀dẹ̀ la ti máa ń dáná, sítóòfù tó ń lo epo kẹrosíìnì nìkan la sì lè lò níbẹ̀. Nígbà tó yá, a bẹ̀rẹ̀ sí í pín oúnjẹ sè. Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn tá a dé ìlú yẹn, èmi àti Liz ni àrùn mẹ́dọ̀wú, ìyẹn hepatitis. Èyí tó pọ̀ jù nínú àwa míṣọ́nnárì ló ní àrùn yẹn láwọn ọdún tá à ń wí yìí. Ó tó oṣù bíi mélòó kan kára wa tó yá, yàtọ̀ síyẹn a tún láwọn àìsàn míì pẹ̀lú.

Ìrànlọ́wọ́ Tó Jẹ́ Káwọn Ará Kòríà Lè Borí Inúnibíni

Láti nǹkan bí ọdún márùnléláàádọ́ta [55] sẹ́yìn, orílẹ̀-èdè Kòríà wà lára àwọn orílẹ̀-èdè tọ́ràn ìṣèlú wọn ò dúró sójú kan ní Éṣíà. Àgbègbè táwọn ológun ò gbọ́dọ̀ dé ti pín orílẹ̀-èdè Kòríà sí méjì. Àgbègbè náà wà ní kìlómítà márùnléláàádọ́ta [55] sí àríwá ìlú Seoul, tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè Kòríà. Lọ́dún 1971, Arákùnrin Frederick Franz wá bẹ̀ wá wò láti oríléeṣẹ́ wa tó wà ní Brooklyn. Mo mú wọn lọ sí àgbègbè tó ti wá di ààlà tó lágbára jù lọ lágbàáyé náà. Ọjọ́ pẹ́ táwọn aláṣẹ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti máa ń pàdé níbẹ̀ pẹ̀lú àwọn aṣojú ìjọba àgbègbè méjèèjì tí orílẹ̀-èdè Kòríà pín sí.

Àmọ́ ní tiwa, a ò dá sí ọ̀ràn ìṣèlú ayé yìí, èyí sì kan èyí tó ń wáyé lórílẹ̀-èdè Kòríà. (Jòh. 17:14) Torí pé àwa Ẹlẹ́rìí tó wà lórílẹ̀-èdè Kòríà kọ̀ láti jagun, èyí tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá [13,000] lọ lára àwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Kòríà ló lo àròpọ̀ ohun tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [26,000] ọdún lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. (2 Kọ́r. 10:3, 4) Gbogbo àwọn arákùnrin tó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́ lórílẹ̀-èdè náà mọ̀ pé ọ̀ràn náà ṣì ń bọ̀ wá kan àwọn, àmọ́ wọn ò jẹ́ kíyẹn kó wọn láyà jẹ. Ó bani nínú jẹ́ pé ẹ̀sùn ọ̀daràn ni ìjọba fi ń kan àwọn Kristẹni tó bá kọ̀ láti bá wọn lọ sójú ogun.

Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì lọ́dún 1944, torí pé èmi náà kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun, mo lo ọdún méjì àtààbọ̀ lẹ́wọ̀n ní Lewisburg, ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú àwọn arákùnrin wa tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Kòríà ti rí màbo lẹ́wọ̀n, èmi náà ti fara gbá irú ìyà táwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí jẹ rí. Nígbà tọ́pọ̀ nínú wọn gbọ́ pé àwa míṣọ́nnárì tá a wà lórílẹ̀-èdè náà ti jẹ irú ìyà tí wọ́n ń jẹ rí, ó fún wọn níṣìírí gan-an ni.—Aísá. 2:4.

A Níṣòro Kan

Kíkọ̀ tá a kọ̀ láti jagun wà lára ohun tó fa ọ̀ràn kan tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1977. Àwọn aláṣẹ ìjọba rò pé àwa la kó sáwọn ọ̀dọ́ tó wà lórílẹ̀-èdè Kòríà lórí tí wọ́n fi kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun. Torí náà, ìjọba pinnu pé àwọn ò ní fún míṣọ́nnárì èyíkéyìí tó bá jáde lórílẹ̀-èdè náà níwèé ìrìnnà láti pa dà wọlé. Ọdún 1977 sí 1987 lohun tí mò ń sọ yìí ṣẹlẹ̀. Tó bá jẹ́ pé a kúrò lórílẹ̀-èdè Kòríà láàárín àwọn ọdún yẹn ni, wọn ò ní jẹ́ ká pa dà wọlé mọ́. Nítorí náà, a ò lọ sí orílẹ̀-èdè wa láti lọ kí àwọn èèyàn wa ní gbogbo àwọn ọdún wọ̀nyẹn.

Ọ̀pọ̀ ìgbà la lọ ṣàlàyé fáwọn aláṣẹ ìjọba pé a ò ní lè lọ sógun torí ọmọlẹ́yìn Kristi ni wá. Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá, wọ́n rí i pé àwọn ò lè dẹ́rù bà wá, wọ́n sì wá gbà wá láyè láti máa wọlé ká sì máa jáde lórílẹ̀-èdè náà. Láàárín àwọn ọdún yẹn, díẹ̀ lára àwa míṣọ́nnárì kúrò lórílẹ̀-èdè yẹn torí ọ̀ràn ìlera, àmọ́ àwa tó kù dúró, ìyẹn sì múnú wa dùn gan-an.

Láàárín ọdún 1984 àti ọdún 1985, àwọn alátakò fẹ̀sùn èké kan àwọn olùdarí àjọ tá a gbé kalẹ̀ lábẹ́ òfin, wọ́n ní àwọn olùdarí yìí ń kọ́ àwọn ọ̀dọ́ pé wọn ò gbọ́dọ̀ wọṣẹ́ ológun. Torí náà, ìjọba bẹ̀rẹ̀ sí í pe àwa olùdarí níkọ̀ọ̀kan láti fọ̀rọ̀ wá wa lẹ́nu wò. Ní January 22, ọdún 1987, àwọn agbẹjọ́rò ìjọba rí i pé ẹ̀sùn náà ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. Orúkọ rere tá a ní yìí ló ń jẹ́ ká borí àwọn irọ́ míì tí wọ́n pa mọ́ wa lẹ́yìn ìgbà náà.

Ọlọ́run Bù Kún Iṣẹ́ Wa

Nítorí pé a kọ̀ láti jagun, ńṣe ni àtakò tí wọ́n ń ṣe sí wa nígbà tá a bá ń wàásù túbọ̀ ń le koko sí i lórílẹ̀-èdè Kòríà. Nítorí náà, kò rọrùn rárá láti ríbi tá a ti máa ṣàwọn àpéjọ wa. Ìdí nìyẹn táwa Ẹlẹ́rìí fi ronú lórí ohun tá a lè ṣe láti yanjú ìṣòro náà, a wá kọ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ kan sílùú Pusan, ìyẹn sì làkọ́kọ́ irú ẹ̀ ní Ìlà Oòrùn Ayé. Mo láǹfààní láti sọ àsọyé ìyàsímímọ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ náà ní April 5, ọdún 1976, àwọn ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [1,300] èèyàn ló sì pésẹ̀ síbẹ̀ lọ́jọ́ náà.

Láti ọdún 1950 wá, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ológun láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n ti ní kó wá ṣiṣẹ́ lórílẹ̀-èdè Kòríà fúngbà díẹ̀. Lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ nínú wọn sì pa dà sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, wọ́n di Ẹlẹ́rìí tó ń fìtara wàásù. Wọ́n sábà máa ń kọ lẹ́tà sí wa, inú wa sì máa ń dùn pé Jèhófà bù kún iṣẹ́ wa débi tá a fi lè ràn wọ́n lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí.

Ó bà mí nínú jẹ́ pé Liz, olólùfẹ́ mi kú ní September 26, ọdún 2006. Àárò rẹ̀ ń sọ mí gan-an. Ní gbogbo ọdún mọ́kànléláàádọ́ta [51] tó fi wà lórílẹ̀-èdè Kòríà, tayọ̀tayọ̀ ló fi máa ń gba iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá ní ká ṣe, kì í sì í ṣàwáwí. Kò fìgbà kan rí dábàá pé ká pa dà sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, kì í tiẹ̀ jẹ ẹ́ lẹ́nu rárá, bẹ́ẹ̀ ó ti lóun ò fẹ́ kúrò lórílẹ̀-èdè yẹn tẹ́lẹ̀!

Mo ṣì ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà lórílẹ̀-èdè Kòríà títí di báyìí. Àwọn tó para pọ̀ jẹ́ ìdílé Bẹ́tẹ́lì ò ju kéréje lọ nígbà kan, àmọ́ ní báyìí a ti tó àádọ́talénígba [250]. Àǹfààní ló jẹ́ fún mi láti wà lára àwọn arákùnrin méje tó para pọ̀ jẹ́ Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka tó ń bójú tó iṣẹ́ lórílẹ̀-èdè náà.

Nígbà tá a kọ́kọ́ dé, orílẹ̀-èdè Kòríà ò rí tajé ṣe, àmọ́ ní báyìí ó ti di ọ̀kan lára orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà lágbàáyé. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní orílẹ̀-èdè Kòríà ti ju ẹgbẹ̀rún márùnléláàádọ́rùn-ún [95,000] lọ, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ẹni mẹ́rin nínú mẹ́wàá ló ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà déédéé tàbí aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Gbogbo èyí wà lára ìdí tí mo fi mọyì àǹfààní tí mo ní láti sin Ọlọ́run lórílẹ̀-èdè yìí, tí mo sì ń rí báwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe ń pọ̀ sí i.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Ìgbà táwa àtàwọn tá a jọ jẹ́ míṣọ́nnárì dé sí orílẹ̀-èdè Kòríà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]

Ìgbà tá à ń sìn nílùú Pusan

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Èmi àti Arákùnrin Franz rèé lọ́dún 1971 ní àgbègbè táwọn ológun ò gbọ́dọ̀ dé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Kò pẹ́ témi àti Liz ya fọ́tò yìí ló kú

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà lórílẹ̀-èdè Kòríà rèé, ibẹ̀ ni mo ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ìdílé Bẹ́tẹ́lì