Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ṣó o gbádùn kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí:

• Báwo la ṣe lè sọ “èdè mímọ́,” tó jẹ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run àtàwọn ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe lọ́nà tó já geere? (Sef. 3:9)

Ká tó lè sọ “èdè mímọ́” lọ́nà tó já geere, bó ṣe máa ń rí téèyàn bá fẹ́ kọ́ èdè kan, a ní láti tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́, ká máa fara wé àwọn tó mọ èdè náà sọ dáadáa, ká há orúkọ àwọn ìwé inú Bíbélì àtàwọn ẹsẹ Bíbélì kọ̀ọ̀kan sórí, ká máa tún àwọn ẹ̀kọ́ tá a ti kọ́ sọ ní àsọtúnsọ, ká máa kàwé sókè, ká mọ gírámà èdè tàbí ẹ̀kọ́ òtítọ́ dáadáa, ká sapá láti máa tẹ̀ síwájú, ká ṣètò àkókò tá a ó fi máa kẹ́kọ̀ọ́, ká sì máa fi “sísọ” èdè mímọ́ náà kọ́ra.—8/15, ojú ìwé 21 sí 25.

• Kí ló túmọ̀ sí láti mọ Ọlọ́run?

“Jèhófà ni orúkọ rẹ̀,” ó sì fẹ́ ká fi orúkọ yẹn mọ òun. (Ẹ́kís. 15:3) “Ọlọ́run ìfẹ́ àti àlàáfíà” ni. (2 Kọ́r. 13:11) “Ọlọ́run ìmọ̀” àti “Ọlọ́run ìgbàlà” ni. (1 Sám. 2:3; Sm. 25:5) Torí náà, Ọlọ́run máa sún mọ́ àwọn tó bá fẹ́ mọ̀ ọ́n.—9/1, ojú ìwé 4 sí 7.

• Báwo ni àpèjúwe “okùn onífọ́nrán mẹ́ta” ṣe bá ìgbéyàwó mu?

Àpèjúwe ni gbólóhùn náà, “okùn onífọ́nrán mẹ́ta.” (Oníw. 4:12) Tá a bá fi àpèjúwe yìí ṣàlàyé bí tọkọtaya ṣe jẹ́ síra wọn, ohun tó túmọ̀ sí ni pé ọkọ àti aya jẹ́ okùn méjì, okùn kẹta tí wọ́n jọ lọ́ mọ́ra ni Ọlọ́run. Bí tọkọtaya bá wà níṣọ̀kan pẹ̀lú Ọlọ́run, wọ́n á ní okun tẹ̀mí tí wọ́n á fi lè máa borí àwọn ìṣòro tó bá ń yọjú, wọ́n á sì máa láyọ̀.—9/15, ojú ìwé 16.

• Kí ni “gbígbé ọwọ́ léni” tó wà nínú Hébérù 6:2 túmọ̀ sí?

Dípò tá a fi máa gbà pé ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ nípa yíyan àwọn alàgbà, ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí gbígbé ọwọ́ lé àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di onígbàgbọ́ láti fún wọn ní ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́. (Ìṣe 8:14-17; 19:6)—9/15, ojú ìwé 32.

• Àwọn nǹkan wo ni bàbá rere máa ń mọ̀ pé àwọn ọmọ òun nílò?

Lára àwọn ohun táwọn ọmọ nílò látọ̀dọ̀ bàbá wọn ni pé (1) kó fẹ́ràn wọn, (2) kó jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún wọn, (3) kó jẹ́ kínú wọn máa dùn, (4) kó máa kọ́ wọn nípa Ọlọ́run, (5) kó máa bá wọn wí, (6) kó sì máa dáàbò bò wọ́n.—10/1, ojú ìwé 18 sí 21.

• Báwo làwọn tó ń múpò iwájú ṣe lè máa bọlá fáwọn èèyàn?

Ọ̀nà kan tí alàgbà kan lè gbà ṣe èyí ni pé kò má máa sọ pé káwọn ará ṣàwọn nǹkan tóun alára ò ní fẹ́ láti ṣe. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún lè máa ṣe bẹ́ẹ̀ nípa jíjẹ́ káwọn èèyàn mọ ìdí tó fi ní kí wọ́n ṣàwọn nǹkan kan tàbí ìdí tó fi fún wọn láwọn ìtọ́ni kan.—10/15, ojú ìwé 22.

• Àwọn nǹkan wo làwọn tọkọtaya lè ṣe kí wọ́n lè túbọ̀ ṣera wọn lọ́kan?

Méjì lára àwọn ohun tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ ni pé, kí wọ́n (1) jẹ́ kọ́rọ̀ ọkọ tàbí ìyàwó wọn máa jẹ wọ́n lógún. (2) má ṣe dalẹ̀ ara wọn. Bóyá àárín wọn gún tàbí wọ́n láwọn ìṣòro kan, ọkọ tàbí ìyàwó ní láti jẹ́ kẹ́nì kejì òun mọ̀ pé lóòótọ́ ló wu òun pé káwọn máa ṣera àwọn lọ́kan, kí ìgbéyàwó wọn bàa lè kẹ́sẹ járí.—11/1, ojú ìwé 18 sí 21.

• Kí làwọn alàgbà lè rí kọ́ látinú báwọn olùṣọ́ àgùntàn tó wà ní Ísírẹ́lì ṣe máa ń fi ọ̀pá gígùn tórí ẹ̀ tẹ̀ kọdọrọ da agbo ẹran?

Ọ̀pá gígùn tórí ẹ̀ tẹ̀ kọdọrọ làwọn olùṣọ́ àgùntàn máa ń lo láti da agbo ẹran wọn. Báwọn àgùntàn bá ṣe ń wọlé tàbí tí wọ́n ń jáde nínú ọgbà tí wọ́n ń kó wọn sí, wọ́n máa “kọjá lábẹ́ ọ̀pá ìdaran” náà, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn olùṣọ́ àgùntàn láti ka iye àgùntàn wọn. (Léf. 27:32) Àwọn Kristẹni tó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn náà ní láti mọ agbo Ọlọ́run tó wà lábẹ́ àbójútó wọn lámọ̀dunjú.—11/15, ojú ìwé 9.

• Báwo làwọn ìyá ṣe lè fi hàn pé àwọ́n fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ ìmọ́tótó?

Oríṣiríṣi ọ̀nà ni kòkòrò lè gbà wọnú oúnjẹ, ìdí nìyẹn tó fi yẹ káwọn ìyá máa fọwọ́ wọn dáadáa kí wọ́n tó fọwọ́ kan oúnjẹ, kí wọ́n sì tún máa bo oúnjẹ. Kí wọ́n máa rí i pé ilé wà ní mímọ́ tónítóní káwọn eku àti aáyán má bàa ríbi sá pa mọ́ sí. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n gbọ́dọ̀ máa rí i dájú pé gbogbo aṣọ ló wà ní mímọ́ tónítóní, kí wọ́n máa túnlé ṣe ní gbogbo ìgbà kí wọ́n sì máa rí i dájú pé gbogbo ará ilé ló ń wẹ̀ déédéé. Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí bá ìlànà ìmọ́tótó tó wà nínú Bíbélì mu.—12/1, ojú ìwé 9 sí 11.