Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Èyí Ni Ọ̀nà. Ẹ Máa Rìn Nínú Rẹ̀”

“Èyí Ni Ọ̀nà. Ẹ Máa Rìn Nínú Rẹ̀”

“Èyí Ni Ọ̀nà. Ẹ Máa Rìn Nínú Rẹ̀”

Ìtàn Ìgbésí Ayé Emilia Pederson

Gẹ́gẹ́ bí Ruth E. Pappas ṣe sọ ọ́

WỌ́N bí ìyá mi Emilia Pederson lọ́dún 1878. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ olùkọ́ ni màmá mi ṣe, àmọ́ ohun tó wù ú pé kó fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe ni ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí èyí, ó ra àpótí ńlá kan kó lè fi kó àwọn ẹrù rẹ̀ lọ sí orílẹ̀-èdè Ṣáínà níbi tó ti fẹ́ lọ ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Àpótí náà wà nílé wa nílùú Jasper ní ìpínlẹ̀ Minnesota, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Àmọ́ nígbà tí màmá rẹ̀ kú, ó ní láti pa iṣẹ́ míṣọ́nnárì tó fẹ́ lọ ṣe tì, ó sì jókòó sílé kó lè máa tọ́jú àwọn àbúrò rẹ̀. Lọ́dún 1907, ó fẹ́ Theodore Holien. Wọ́n bímọ méje, èmi àbíkẹ́yìn wọn ni wọ́n sì bí ní December 2, ọdún 1925.

Màmá mi láwọn ìbéèrè kan tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn nípa àwọn nǹkan kan nínú Bíbélì. Ọ̀kan lára ìbéèrè náà dá lórí ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ni pé ọ̀run àpáàdì jẹ́ ibi tí wọ́n ti ń dá àwọn ẹni ibi lóró. Ó bi alábòójútó tó wá bẹ Ṣọ́ọ̀ṣì Luther wò nípa ibi tí Bíbélì ti sọ bẹ́ẹ̀. Ohun tí alábòójútó náà sọ fi hàn pé ohun yòówù tí Bíbélì ì báà sọ, a gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn èèyàn pé ọ̀run àpáàdì jẹ́ ibi ìdálóró.

Ó Rí Òtítọ́ Tó Ti Ń Wá

Kété lẹ́yìn ọdún 1900, obìnrin kan tó ń jẹ́ Emma, àbúrò ìyá mi, lọ sílùú Northfield, ní ìpínlẹ̀ Minnesota láti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa orin. Ó ń gbé nílé Milius Christianson tó jẹ́ olùkọ́ rẹ̀. Ìyàwó olùkọ́ rẹ̀ yìí jẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń pe àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn. Àǹtí Emma sọ fún obìnrin náà pé òun ní àǹtí kan tó máa ń ka Bíbélì gan-an. Láìjáfara, Ìyáàfin Christianson kọ lẹ́tà kan sí màmá mi, èyí tó dáhùn àwọn ìbéèrè rẹ̀ nípa Bíbélì.

Lọ́jọ́ kan, obìnrin Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tó ń jẹ́ Lora Oathout wọ ọkọ̀ ojú irin láti ìlú Sioux Falls, ní ìpínlẹ̀ South Dakota, wá sí ìlú Jasper láti wàásù. Ni màmá mi bá gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì kà á. Lọ́dún 1915, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ òtítọ́ tó kẹ́kọ̀ọ́ nínú Bíbélì fáwọn èèyàn, ó sì ń pín ìwé tí Lora kó wá fún un.

Lọ́dún 1916, màmá mi gbọ́ pé Arákùnrin Charles Taze Russell ń bọ̀ wá ṣe àpéjọ kan nílùú Sioux City, ní ìpínlẹ̀ Iowa. Màmá mi sì fẹ́ lọ síbẹ̀. Lákòókò yìí, màmá mi ti bímọ márùn-ún, Marvin tó ń tọ́ lọ́wọ́ sì jẹ́ ọmọ oṣù márùn-un péré. Síbẹ̀, ó kó gbogbo àwọn ọmọ náà, ó wọkọ̀ ojú irin lọ sí ìlú Sioux City tó jìnnà tó nǹkan bí ọgọ́jọ [160] kìlómítà láti lọ ṣe àpéjọ náà. Ó gbọ́ àwọn àsọyé tí Arákùnrin Russell sọ, ó tún wo “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá,” ó sì ṣèrìbọmi. Nígbà tó pa dà délé, ó kọ àpilẹ̀kọ kan nípa àpéjọ náà, wọ́n sì gbé e jáde nínú ìwé ìròyìn Jasper Journal.

Lọ́dún 1922, màmá mi wà lára àwọn ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún [18,000] tó lọ sí àpéjọ tó wáyé nílùú Cedar Point, ní ìpínlẹ̀ Ohio. Lẹ́yìn àpéjọ náà, kò ṣíwọ́ kíkéde Ìjọba Ọlọ́run. Bá a ṣe ń wo àpẹẹrẹ rẹ̀, ṣe ló dà bí ìgbà tó ń sọ fún wa pé: “Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀.”—Aísá. 30:21.

Iṣẹ́ Ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run Sèso

Lẹ́yìn ọdún 1920, àwọn òbí mi ṣí lọ sí ilé kan tó wà lẹ́yìn ìlú Jasper. Okòwò bàbá mi búrẹ́kẹ́, ó sì ní bùkátà ìdílé ńlá tó ń gbọ́. Kò fi bẹ́ẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bíi ti ìyá mi, àmọ́ ó fi gbogbo ọkàn ti iṣẹ́ ìwàásù lẹ́yìn, ó sì yọ̀ǹda káwọn alábòójútó arìnrìn-àjò, tí wọ́n ń pè ní arìnrìn-àjò ìsìn nígbà yẹn, máa dé sílé wa. Lọ́pọ̀ ìgbà, tí alábòójútó arìnrìn-àjò bá wá sọ àsọyé nílé wa, iye èèyàn tó máa ń wá síbẹ̀ sábà máa ń tó ọgọ́rùn-ún. Gbogbo pálọ̀, ibi ìjẹun àti yàrá wa á sì wá kún fún èrò.

Nígbà tí mo wà ní bí ọmọ ọdún méje, Àǹtí Lettie, àbúrò ìyá mi, fi fóònù pè wá, ó ní Ọ̀gbẹ́ni Ed Larson àti ìyàwó rẹ̀ tó ń gbé ládùúgbò àwọn fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, wọ́n sì tún pe aládùúgbò wọn mìíràn tó ń jẹ́ Martha Van Daalen, tó jẹ́ ìyá ọlọ́mọ mẹ́jọ, láti dara pọ̀ mọ́ wọn nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Bí Martha àti gbogbo ìdílé rẹ̀ náà ṣe di Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn. a

Lákòókò yẹn, ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Gordon Kammerud, tó ń gbé ní ibùsọ̀ mélòó kan sọ́dọ̀ wa bẹ̀rẹ̀ sí í bá bàbá mi ṣiṣẹ́. Wọ́n ti kìlọ̀ fún Gordon tẹ́lẹ̀ pé: “Ṣọ́ra fún àwọn ọmọbìnrin ọ̀gá rẹ o, torí ẹ̀sìn wọn ò bá táyé mu.” Síbẹ̀ Gordon bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kò sì pẹ́ tó fi gbà pé òun ti rí òtítọ́. Oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà ló ṣèrìbọmi. Àwọn òbí rẹ̀ pẹ̀lú di onígbàgbọ́. Ìdílé mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ìyẹn ìdílé bàbá mi Holien, ti Kammerud, àti ti Van Daalen, sì wá di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́.

Àwọn Àpéjọ Fún Wa Lókun

Àpéjọ ti Cedar Point fún màmá mi níṣìírí gan-an tó fi jẹ́ pé kì í fẹ́ pa àpéjọ èyíkéyìí jẹ. Nítorí náà, ara àwọn ohun tí mo máa ń rántí jù nípa ìgbà ọmọdé mi ni bá a ṣe máa ń rìnrìn àjò gígún lọ sáwọn ìpàdé yẹn. Èyí tá a ṣe nílùú Columbus, ní ìpínlẹ̀ Ohio, lọ́dún 1931, jẹ́ mánigbàgbé, nítorí ìgbà yẹn la gba orúkọ náà Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Aísá. 43:10-12) Mo tún rántí àpéjọ tá a ṣe ní ìlú Washington, D.C. lọ́dún 1935, níbi tí wọ́n ti sọ àsọyé mánigbàgbé kan tó jẹ́ ká mọ àwọn tó jẹ́ “ogunlọ́gọ̀ ńlá,” tí ìwé Ìṣípayá sọ̀rọ̀ nípa wọn. (Ìṣí. 7:9) Àwọn ẹ̀gbọ́n mi obìnrin, ìyẹn Lilian àti Eunice wà lára àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [800] tó ṣèrìbọmi níbẹ̀.

Ìdílé wa tún rìnrìn àjò lọ sí àwọn àpéjọ tá a ṣe nílùú Columbus ní ìpínlẹ̀ Ohio lọ́dún 1937, èyí tá a ṣe nílùú Seattle ní ìpínlẹ̀ Washington lọ́dún 1938, àtèyí tá a ṣe nílùú New York City lọ́dún 1939. Ìdílé wa àti ìdílé Van Daalen pẹ̀lú ti Kammerud àtàwọn míì lọ pa pọ̀ ni. A máa ń pabùdó tá ó sì sùn lójú ọ̀nà bá a ṣe ń lọ. Eunice ẹ̀gbọ́n mi fẹ́ Leo Van Daalen lọ́dún 1940, wọ́n sì di aṣáájú-ọ̀nà. Lọ́dún kan náà yẹn, Lilian fẹ́ Gordon Kammerud, àwọn náà sì di aṣáájú-ọ̀nà.

Àpéjọ ti ọdún 1941 tá a ṣe ní St. Louis, ní ìpínlẹ̀ Missouri ṣàrà ọ̀tọ̀. Àpéjọ yẹn ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún èwe ti gba ìwé Children tí wọ́n ṣe fáwa èwe. Àpéjọ yẹn yí ìgbésí ayé mi pa dà. Láìpẹ́ sígbà yẹn, ní September 1, ọdún 1941, èmi àti ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin, Marvin àti Joyce ìyàwó rẹ̀ di aṣáájú-ọ̀nà. Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni mí nígbà náà.

Ní àdúgbò tá à ń gbé, kì í ṣe gbogbo àwọn ará ló máa ń lè lọ sáwọn àpéjọ nítorí àgbẹ̀ ni wá, ìgbà ìkórè làwọn àpéjọ yẹn sì sábà máa ń bọ́ sí. Nítorí náà, lẹ́yìn àpéjọ, a máa ń ṣe àtúnyẹ̀wò àpéjọ lẹ́yìnkùlé wa fún àǹfààní àwọn tí kò lè lọ sí àpéjọ. Irú àwọn ìkórajọ bẹ́ẹ̀ máa ń lárinrin gan-an ni.

A Lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, Wọ́n sì Rán Wa Lọ sí Ilẹ̀ Òkèèrè

Ní February ọdún 1943, wọ́n dá Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì sílẹ̀ níbi tí wọ́n á ti máa kọ́ àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó máa di míṣọ́nnárì lẹ́kọ̀ọ́. Kíláàsì àkọ́kọ́ ni àwọn mẹ́fà lára ìdílé Van Daalen lọ, ìyẹn Emil, Arthur, Homer, Leo àti Donald ìbátan wọn, pa pọ̀ mọ́ ìyàwó Leo, ìyẹn Eunice ẹ̀gbọ́n mi. Inú wa dùn láti kí wọn pé ó dàbọ̀, àmọ́ ó ń dùn wá pé wọ́n ń fi wá sílẹ̀ nítorí a ò mọ̀gbà tá a tún máa rí wọn. Lẹ́yìn tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ yege, wọ́n rán gbogbo wọn lọ sí orílẹ̀-èdè Puerto Rico, níbi tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò ti tó méjìlá nígbà yẹn.

Ọdún kan lẹ́yìn náà, Lilian àti Gordon títí kan Marvin àti Joyce lọ sí kíláàsì kẹta ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Wọ́n tún rán àwọn náà lọ sí orílẹ̀-èdè Puerto Rico. Lẹ́yìn náà, ní September ọdún 1944, nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìdínlógún, èmi náà lọ sí kíláàsì kẹrin ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ yege lóṣù February ọdún 1945, wọ́n rán èmi náà lọ bá àwọn ẹ̀gbọ́n mi nílẹ̀ Puerto Rico. Àǹfààní ńláǹlà lọwọ́ mi tẹ̀ yìí o! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èdè Sípáníìṣì tí wọ́n ń sọ níbẹ̀ ṣòroó kọ́ fún wa, kò pẹ́ táwọn kan lára wa fi ń bá àwọn èèyàn tó ju ogún lọ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Jèhófà fi ìbùkún sí iṣẹ́ náà. Lónìí, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25,000] àwọn Ẹlẹ́rìí ló wà lórílẹ̀-èdè Puerto Rico!

Ọ̀fọ̀ Ṣẹ̀ Wá Lẹ́ẹ̀mejì

Leo àti Eunice ò kúrò ní orílẹ̀-èdè Puerto Rico lẹ́yìn tí wọ́n bí Mark ọmọkùnrin wọn lọ́dún 1950. Lọ́dún 1952 wọ́n ṣètò láti lọ lo ìsinmi lọ́dọ̀ àwọn ará ilé. Ni wọ́n bá wọ ọkọ̀ òfúrufú ní April 11. Ṣùgbọ́n ó bani nínú jẹ́ pé, kò pẹ́ lẹ́yìn tí ọkọ̀ náà gbéra ló já sínú òkun. Leo àti Eunice sì kú. Àmọ́ wọ́n rí Mark ọmọ wọn tó jẹ́ ọmọ ọdún méjì tó léfòó lórí òkun. Ọkùnrin kan tó la jàǹbá náà já ló ti ọmọ náà sórí ohun kan tó lè gbéèyàn léfòó. Ọmọ náà sì sọ jí lẹ́yìn tí wọ́n ti fẹ́ afẹ́fẹ́ sí i nímú. b

Ọdún márùn-ún lẹ́yìn náà, ní March 7, ọdún 1957, nígbà tí ìyá àti bàbá mi ń gbé ọkọ̀ wọn lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, táyà ọkọ̀ náà jò. Nígbà tí bàbá mi ń gbé táyà míì sí ẹsẹ̀ ọkọ̀ náà lẹ́bàá ọ̀nà, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan tó ń kọjá lọ gbá a ó sì kú lójú ẹsẹ̀. Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600] èèyàn ló wá gbọ́ àsọyé ìsìnkú rẹ̀. Èyí tún jẹ́ káwọn ará ìlú náà lè mọ púpọ̀ sí i nípa òtítọ́, nítorí wọ́n mọ bàbá mi sí ẹni iyì tẹ́lẹ̀.

Àwọn Iṣẹ́ Ìsìn Mìíràn Tí Mo Ṣe

Nígbà díẹ̀ ṣáájú kí bàbá mi tó kú, wọ́n gbé mi kúrò níbi tí mo wà tẹ́lẹ̀ pé kí n lọ sí ilẹ̀ Ajẹntínà. Ní August ọdún 1957, mo dé sí ìlú Mendoza tó wà ní ẹsẹ̀ àwọn Òkè Ńlá Andes. Lọ́dún 1958, wọ́n ní kí George Pappas, tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì ọgbọ̀n ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, wá máa sìn nílẹ̀ Ajẹntínà. Èmi àti George di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, a sì fẹ́ ara wa lóṣù April ọdún 1960. Lọ́dún 1961, màmá mi kú lẹ́ni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin. Ó ti fi gbogbo ọkàn rẹ̀ rìn ní ọ̀nà ìjọsìn tòótọ́, ó sì ti ran àìmọye èèyàn lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.

Ọdún mẹ́wàá ni èmi àti George fi sìn pẹ̀lú àwọn míṣọ́nnárì míì ní ọ̀pọ̀ ilé àwọn míṣọ́nnárì. Lẹ́yìn náà, a lo ọdún méje lẹ́nu iṣẹ́ alábòójútó àyíká. Lọ́dún 1975, a pa dà sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láti ṣèrànwọ́ fáwọn kan tára wọn ò yá ní ìdílé wa. Lọ́dún 1980, wọ́n ní kí ọkọ mi wá máa ṣe alábòójútó àyíká àwọn ìjọ tí wọ́n ń sọ èdè Sípáníìṣì. Nígbà yẹn, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600] ìjọ ló wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tí wọ́n ń sọ èdè Sípáníìṣì. Ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n la fi bẹ púpọ̀ lára wọn wò, ìṣojú wa ni iye ìjọ náà fi ń pọ̀ sí i, títí tó fi ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] lọ.

Wọ́n Ti Rìn ní “Ọ̀nà” Náà

Ìdùnnú ló tún jẹ́ fún màmá mi láti rí bí àwọn ọmọ àti ọmọ ọmọ rẹ̀ ṣe ń wọnú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Bí àpẹẹrẹ, Carol tó jẹ́ ọmọ Ester, àǹtí mi àgbà, bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ́dún 1953. Ó fẹ́ Dennis Trumbore, wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún láti ìgbà yẹn. Ọmọ Ester míì tó ń jẹ́ Lois fẹ́ Arákùnrin Wendell Jensen. Wọ́n lọ sí kíláàsì kọkànlélógójì ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, wọ́n sì ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní Nàìjíríà fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Ọmọ ìyá Leo kan tó ń jẹ́ Ruth La Londe, àti Curtiss ọkọ rẹ̀ gba Mark táwọn òbí rẹ̀ kú nínú jàǹbá ọkọ̀ òfúrufú ṣọmọ, wọ́n sì tọ́ ọ dàgbà. Mark àti ìyàwó rẹ̀, Lavonne sì wá ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fún ọ̀pọ̀ ọdún, wọ́n sì tọ́ àwọn ọmọ wọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní “ọ̀nà” náà.—Aísá. 30:21.

Ẹ̀gbọ́n mi kan ṣoṣo tó ṣì wà láàyè, ìyẹn Orlen, ti tó nǹkan bí ẹni ọdún márùnléláàádọ́rùn-ún báyìí. Ó ṣì ń sin Jèhófà tọkàntọkàn títí di ìsinsìnyí. Èmi àti George ọkọ mi ṣì ń bá iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún wa lọ tayọ̀tayọ̀.

Ohun Tí Màmá Mi Fi Sílẹ̀

Èmi ni mo wá jogún ọ̀kan lára ohun ìní tí màmá mi kà sí iyebíye, ìyẹn tábìlì ìkọ̀wé rẹ̀. Bàbá mi ló fi ṣe ẹ̀bùn ìgbéyàwó fún un. Ìwé kan tó dà bí ìwé tí wọ́n ń kó fọ́tò pa mọ́ sí wà nínú ọ̀kan lára dúrọ́ọ̀ tábìlì náà. Ohun tí màmá mi ń kó sínú rẹ̀ ni àwọn lẹ́tà rẹ̀ àtàwọn àpilẹ̀kọ́ rẹ̀ tó jẹ́ ọ̀rọ̀ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, èyí tí wọ́n gbé jáde nínú ìwé ìròyìn. Àwọn kan lára wọn ti wà láti nǹkan bí ọdún 1900. Àwọn lẹ́tà ṣíṣeyebíye táwọn ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ míṣọ́nnárì kọ sí i náà wà nínú dúrọ́ọ̀ tábìlì yìí. Àkàtúnkà ni mo máa ń ka àwọn lẹ́tà yẹn, mo sì ń gbádùn wọn gan-an ni. Àwọn lẹ́tà tí màmá mi ń kọ sí wa nígbà yẹn ń fúnni níṣìírí gan-an, wọ́n kún fún ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró. Màmá mi kò lè ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì tó wù ú gan-an láti ṣe, àmọ́ ó ní ìtara fún iṣẹ́ míṣọ́nnárì débi pé ìtara náà mú kí àwọn ọmọ rẹ̀ àti ọmọ-ọmọ lẹ́yìn rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ náà. Ọjọ́ lọjọ́ náà tí gbogbo ìdílé wa yóò tún wà pa pọ̀ pẹ̀lú màmá àti bàbá mi nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé!—Ìṣí. 21:3, 4.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Ile-iṣọ Naa December 15, 1983, ojú ìwé 24 sí 27, láti mọ̀ nípa ìtàn ìgbésí ayé Emil H. Van Daalen, tó jẹ́ ọmọ Arábìnrin Martha Van Daalen.

b Wo Jí! ti June 22, 1952, ojú ìwé 3 àti 4, lédè Gẹ̀ẹ́sì.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Emilia Pederson

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Lọ́dún 1916: Màmá mi, bàbá mi (ó gbé Marvin dání); nísàlẹ̀, láti apá òsì sí apá ọ̀tún: Orlen, Ester, Lilian àti Mildred

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Leo àti Eunice rèé, wọ́n kú láìpẹ́ sígbà yẹn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Lọ́dún 1950: Láti apá òsì sí apá ọ̀tún, lókè: Ester, Mildred, Lilian, Eunice, Ruth; nísàlẹ̀: Orlen, màmá mi, bàbá mi, àti Marvin

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

George àti Ruth Pappas lẹ́nu iṣẹ́ alábòójútó àyíká, lọ́dún 2001