Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Rí Ìdùnnú Nínú Iṣẹ́ Sísọni Dọmọ Ẹ̀yìn

Máa Rí Ìdùnnú Nínú Iṣẹ́ Sísọni Dọmọ Ẹ̀yìn

Máa Rí Ìdùnnú Nínú Iṣẹ́ Sísọni Dọmọ Ẹ̀yìn

‘Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn.’—MÁT. 28:19.

1-3. (a) Báwo ni kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe máa ń rí lára ọ̀pọ̀ akéde? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò?

 ARÁBÌNRIN kan tó wà ní ìjọ kan tí wọ́n ti ń sọ èdè Híńdì nílẹ̀ Amẹ́ríkà sọ pé: “Ó ti tó ọ̀sẹ̀ mọ́kànlá báyìí tí mo ti ń bá ìdílé kan láti orílẹ̀-èdè Pakistan ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. A sì ti wá mọwọ́ ara wa gan-an ni, ìrònú pé ìdílé yìí máa pa dà sí orílẹ̀-èdè Pakistan láìpẹ́ sì ń mú kí omijé dà lójú mi. Kì í ṣe tìtorí pé èmi àtàwọn ò ní máa ríra mọ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti lọ nìkan ló ń múmi domi lójú, àmọ́ mo tún ń ronú nípa ayọ̀ tí mo máa ń ní nígbà tí mo bá ń kọ́ wọn nípa Jèhófà.”

2 Ṣéwọ náà ti ní ayọ̀ téèyàn máa ń ní nídìí kíkọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bí irú èyí tí arábìnrin yìí ní? Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ọ̀rúndún kìíní rí ayọ̀ púpọ̀ nínú iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn. Nígbà táwọn àádọ́rin ọmọ ẹ̀yìn tí Jésù kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ tó sì rán jáde mú ìròyìn ayọ̀ pa dà wá fún un, òun náà kún fún “ayọ̀ púpọ̀ nínú ẹ̀mí mímọ́.” (Lúùkù 10:17-21) Bákan náà lónìí, ọ̀pọ̀ Kristẹni ló ń rí ayọ̀ púpọ̀ nínú iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn. Kódà, lọ́dún 2007, àwọn akéde fi tayọ̀tayọ̀ ṣiṣẹ́ yẹn kára débi pé iye ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ń ṣe lóṣooṣù lọ́dún yẹn tó mílíọ̀nù mẹ́fà àtààbọ̀!

3 Àmọ́ ṣá, àwọn akéde kan ò tíì máa bá èèyàn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n á fi lè rí adùn tó wà nínú ẹ̀. Àwọn míì sì wà tó jẹ́ pé ó tó ọdún mélòó kan tí wọ́n ti bá èèyàn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbẹ̀yìn. Àwọn ìṣòro wo la lè bá pàdé bá a ṣe ń gbìyànjú láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Báwo la ṣe lè borí àwọn ìṣòro yìí? Èrè wo la sì máa rí tá a bá ń sa gbogbo ipá wa láti ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn”?—Mát. 28:19.

Àwọn Ohun Tí Kì Í Jẹ́ Kéèyàn Rí Ìdùnnú Nínú Iṣẹ́ Náà

4, 5. (a) Báwo lọ̀pọ̀ èèyàn ṣe máa ń ṣe sí iṣẹ́ ìwàásù wa láwọn ibì kan láyé? (b) Àwọn ìṣòro wo làwọn akéde ń bá pàdé láwọn ibòmíì?

4 Láwọn ibì kan láyé, àwọn èèyàn máa ń gba ìwé wa dáadáa, ó sì máa ń wù wọ́n pé ká máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tọkọtaya kan tó ti ilẹ̀ Ọsirélíà lọ sí ilẹ̀ Sáńbíà láti lọ ṣiṣẹ́ ìsìn fúngbà díẹ̀ sọ pé: “Bí wọ́n ṣe sọ ọ́ la ṣe bá a. Iṣẹ́ ìwàásù dùn-ún ṣe gan-an lórílẹ̀-èdè Sáńbíà. Ìjẹ́rìí òpópónà tiẹ̀ kọjá àfẹnusọ! Àní àwọn èèyàn máa ń fúnra wọn wá bá wa, àwọn kan lára wọn tiẹ̀ máa ń béèrè ìwé ìròyìn wa tí wọ́n ń fẹ́.” Lọ́dún kan láìpẹ́ yìí, iye ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì táwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Sáńbíà ṣe ju ọ̀kẹ́ mẹ́wàá [200,000] lọ, ìyẹn ni pé tá a bá pín in dọ́gba, akéde kọ̀ọ̀kan ṣe ohun tó ju ìkẹ́kọ̀ọ́ kan lọ.

5 Àmọ́ láwọn ibòmíì, ó máa ń ṣòro fáwọn akéde láti fi ìwé síta, ó sì máa ń ṣòro fún wọn láti máa rẹ́ni bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Kí ló fà á? Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó máa ń fà á ni pé àwọn èèyàn kì í sí nílé nígbà táwọn akéde bá délé wọn, àwọn tí wọ́n bá sì wà nílé lè jẹ́ àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ ẹ̀sìn. Ó lè jẹ́ pé ilé tí wọn ò ti nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ ẹ̀sìn ni wọ́n ti tọ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ dàgbà tàbí kó jẹ́ pé àgàbàgebè inú ìsìn èké ti mú kí wọ́n kórìíra ẹ̀sìn. Ọ̀pọ̀ làwọn èké olùṣọ́ àgùntàn ti fojú wọn rí màbo, tí wọ́n dà bí àgùntàn tí wọ́n bó láwọ tí wọ́n sì wá fọ́n káàkiri. (Mát. 9:36) Nítorí náà, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè máa lọ́ tìkọ̀ láti bá ẹnikẹ́ni jíròrò ọ̀rọ̀ Bíbélì.

6. Àwọn ìṣòro wo ló lè máa dí àwọn akéde kan lọ́wọ́?

6 Àwọn kan lára àwọn akéde olóòótọ́ ń dojú kọ ìṣòro míì tó yàtọ̀ síyẹn, èyí tí kì í jẹ́ kí wọ́n gbádùn iṣẹ́ náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé tẹ́lẹ̀ wọn ò kẹ̀rẹ̀ nídìí iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn, àmọ́ ní báyìí, àìlera àti ọjọ́ ogbó ń ṣèdíwọ́ fún wọn tí wọn ò fi lè ṣe tó bẹ́ẹ̀ mọ́. Tún wo àwọn ìdíwọ́ míì tó ṣeé ṣe ká máa fà fún ara wa. Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ o máa ń rò pé o ò mọ bá a ṣe ń kọ́ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Ọ̀rọ̀ rẹ lè dà bíi ti Mósè tó ro ara rẹ̀ pin nígbà tí Jèhófà rán an pé kó lọ bá Fáráò sọ̀rọ̀. Mósè sọ pé: “Dákun, Jèhófà, ṣùgbọ́n èmi kì í ṣe ẹni tí ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tí ó já geere, kì í ṣe láti àná, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ṣáájú ìgbà yẹn.” (Ẹ́kís. 4: 10) Ohun míì tó tún jọ èyí ni ìbẹ̀rù pé ẹni téèyàn ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lè má dọmọ ẹ̀yìn. A lè máa rò pé nítorí pé a ò mọ̀ọ̀yàn kọ́ tó bó ṣe yẹ, ẹni tá à ń kọ́ ò ní lè dọmọ ẹ̀yìn. Nítorí náà, kó má bàa wá di pé a bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ tí kò ní yọrí sí rere, a lè wá pinnu pé a ò wulẹ̀ ní máa bá ẹnì kankan ṣèkẹ́kọ̀ọ́. Kí la lè ṣe lórí àwọn ìṣòro tá a mẹ́nu kàn yìí?

Múra Sílẹ̀ Látọkànwá

7. Kí ló ń mú kí Jésù máa ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀?

7 Ohun àkọ́kọ́ tá a ní láti ṣe ni pé ká múra sílẹ̀ látinú ọkàn wa wá. Jésù sọ pé: “Lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu ń sọ.” (Lúùkù 6:45) Ohun kan tó ń mú kí Jésù máa ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ni ire àwọn èèyàn tó jẹ ẹ́ lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó rí báwọn Júù bíi tiẹ̀ ṣe jìnnà sí Ọlọ́run tó, “àánú wọn ṣe é.” Ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ìkórè pọ̀ . . . Ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè láti rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.”—Mát. 9:36-38.

8. (a) Kí ló yẹ ká máa ronú nípa rẹ̀? (b) Kí la lè rí kọ́ látinú ọ̀rọ̀ tí obìnrin kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sọ?

8 Bá a ṣe ń bá iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn lọ, ẹ jẹ́ ká máa ronú jinlẹ̀ lórí àǹfààní púpọ̀ táwa náà ti jẹ torí pé ẹnì kan fara balẹ̀ kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹ jẹ́ ká tún máa ronú nípa àwọn tá a máa bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ká sì máa ronú lórí àǹfààní tí wọ́n máa jẹ bí wọ́n bá gbọ́ ohun tá a fẹ́ bá wọn sọ. Obìnrin kan kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè tó ń gbé, ó sọ pé: “Mò ń fi àǹfààní yìí sọ fún yín pé mo mọyì àwọn Ẹlẹ́rìí tó máa ń wá kọ́ mi nílé mi. Mo mọ̀ pé ọ̀rọ̀ mi á máa sú wọn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nítorí bí mo ṣe máa ń da ìbéèrè bò wọ́n tí mo sì máa ń jẹ́ kí wọ́n pẹ́ kọjá àkókò tá a fàdéhùn sí. Àmọ́ wọ́n máa ń ṣe sùúrù fún mi, wọ́n sì máa ń fẹ́ kọ́ mi lóhun tí wọ́n mọ̀. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà àti Jésù pé mo bá irú àwọn èèyàn báyìí pàdé.”

9. Kí ni Jésù gbájú mọ́, báwo la sì ṣe lè fara wé e?

9 Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo èèyàn ló gba ẹ̀kọ́ tí Jésù ń kọ́ wọn. (Mát. 23:37) Àwọn kan fìgbà díẹ̀ tọ̀ ọ́ lẹ́yìn àmọ́ nígbà tó yá, wọn kò “bá a rìn mọ́,” nítorí pé wọn ò fara mọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀. (Jòh. 6:66) Àmọ́ Jésù ò torí pé àwọn kan ò gba ẹ̀kọ́ òun kó wá rò pé kò sí àǹfààní kankan nínú iṣẹ́ ìwàásù tóun ń ṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ irúgbìn tí Jésù fún kò sèso, síbẹ̀ iṣẹ́ rere tó ń ṣe ló gbájú mọ́. Ohun tó ń wò ni àwọn pápá tó ti funfun fún kíkórè, ó sì ń rí ìdùnnú kíkọyọyọ bó ṣe ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìkórè náà. (Ka Jòhánù 4:35, 36.) Ǹjẹ́ kò yẹ káwa náà máa ronú lórí ìkórè tá a lè rí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, dípò ká kàn máa ronú pé aṣálẹ̀ lásán ni? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó lè mú ká máa nírú èrò rere yẹn lọ́kàn.

Máa Wá Bó O Ṣe Máa Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

10, 11. Kí lo lè ṣe kí ìdùnnú tí iṣẹ́ yìí ń fún ọ lè máa bá a lọ?

10 Àgbẹ̀ tó ń fúnrúgbìn máa ń retí pé òun máa kórè. Bákan náà, bá a ṣe ń wàásù, ó yẹ ká máa fi sọ́kàn pé ẹni tá a máa bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì là ń wá. Àmọ́ tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé, pẹ̀lú bó o ṣe máa ń jáde òde ẹ̀rí tó, ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ lò ń bá nílé tàbí tó jọ pé o kì í rí àwọn ìpadàbẹ̀wò rẹ mọ́ ńkọ́? Lóòótọ́, ìyẹn lè fiṣẹ́ ọ̀hún súni. Àmọ́ ǹjẹ́ ó yẹ kó o pa iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé tì? Àgbẹdọ̀! Ọ̀nà tí ìhìn rere kọ́kọ́ ń gbà dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn ṣì ni nípa iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé tá a ti ń lò bọ̀ tipẹ́tipẹ́ tá a sì rí i pé ó dáa gan-an ni.

11 Ṣùgbọ́n, kó o lè máa ní ìdùnnú lẹ́nu iṣẹ́ yìí, ǹjẹ́ o lè wá ọ̀nà míì tó o lè gbà máa kàn sáwọn èèyàn láfikún sí ọ̀nà tó o gbà ń wàásù tẹ́lẹ̀? Bí àpẹẹrẹ, ṣó o ti gbìyànjú láti máa wàásù fáwọn èèyàn ní òpópónà tàbí níbi iṣẹ́ wọn? Ǹjẹ́ o lè máa kàn sáwọn èèyàn lórí tẹlifóònù tàbí kó o gba nọ́ńbà tẹlifóònù àwọn tó o ti sọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run fún kó o bàa lè máa pè wọ́n? Tó o bá lẹ́mìí ìfaradà, tó o sì ń yíwọ́ pa dà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù rẹ, wàá máa láyọ̀ torí pé wàá máa ráwọn táá máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run.

Ohun Tá A Lè Ṣe Táwọn Èèyàn Ò Bá Nífẹ̀ẹ́ Sọ́rọ̀ Ẹ̀sìn

12. Kí la lè ṣe tó bá dà bíi pé ọ̀pọ̀ àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa kò nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ ẹ̀sìn?

12 Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín kò nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ ẹ̀sìn ńkọ́? Ǹjẹ́ o lè máa fi àwọn kókó ọ̀rọ̀ tírú wọn máa nífẹ̀ẹ́ sí bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn Kristẹni tó wà nílùú Kọ́ríńtì pé: “Fún àwọn Júù mo dà bí Júù . . . Fún àwọn tí wọ́n wà láìní òfin mo dà bí aláìní òfin, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò wà láìní òfin sí Ọlọ́run.” Kí ló ń sún Pọ́ọ̀lù ṣe gbogbo ìyẹn? Ó sọ pé: “Mo ti di ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo, kí n lè rí i dájú pé mo gba àwọn kan là.” (1 Kọ́r. 9:20-22) Ṣé àwa náà lè wá kókó ọ̀rọ̀ tó máa fa àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa lọ́kàn mọ́ra? Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ ẹ̀sìn ló ń fẹ́ kí àlàáfíà máa wà nínú ilé àwọn. Wọ́n tiẹ̀ tún lè fẹ́ mọ ìdí tí Ọlọ́run fi dá àwọn. Ǹjẹ́ a lè bá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run lọ́nà tó máa wọ̀ wọ́n lọ́kàn?

13, 14. Báwo la ṣe lè fi kún ayọ̀ tá à ń rí lẹ́nu iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn?

13 Àwọn akéde tó ń pọ̀ sí i ló ti wá ọ̀nà láti fi kún ayọ̀ tí wọ́n ń rí lẹ́nu iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn, àní láwọn àgbègbè tó dà bíi pé àwọn tí kò fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa pọ̀ sí. Báwo ni wọ́n ṣe ṣe é? Ńṣe ni wọ́n kọ́ èdè ilẹ̀ òkèèrè. Bàbá àti ìyá kan tí wọ́n jẹ́ tọkọtaya tọ́jọ́ orí wọn lé lọ́gọ́ta ọdún rí i pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará ilẹ̀ Ṣáìnà tó jẹ́ ọmọ iléèwé àti ìdílé wọn ń gbé ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn. Bàbá yẹn sọ pé: “Èyí ló mú wa kọ́ èdè Ṣáínà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kíkọ́ èdè yẹn ń gba ọ̀pọ̀ àkókò lọ́wọ́ wa lójoojúmọ́, ó yọrí sí rere, nítorí pé ó jẹ́ ká lè bá ọ̀pọ̀ àwọn ará Ṣáínà tó wà ládùúgbò wa yẹn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì mú wa láyọ̀.”

14 Ká tiẹ̀ ní o ò lè kọ́ èdè ilẹ̀ òkèèrè, o ṣì lè máa lo ìwé kékeré náà, Good News for People of All Nations, nígbà tó o bá pàdé àwọn tó ń sọ èdè tí o kò gbọ́. O sì tún lè máa gba ìwé tó wà ní èdè táwọn èèyàn tó ò ń bá pàdé ń sọ. Lóòótọ́, ó lè gba ọ̀pọ̀ àkókò àti ìsapá láti lè wàásù fún àwọn tó ń sọ èdè míì tí àṣà wọn sì yàtọ̀, àmọ́ má gbàgbé ìlànà kan tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ìlànà náà ni: “Ẹni tí ó bá . . . ń fúnrúgbìn yanturu yóò ká yanturu pẹ̀lú.”—2 Kọ́r. 9:6.

Iṣẹ́ Gbogbo Ará Ìjọ Ni

15, 16. (a) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé iṣẹ́ gbogbo ará ìjọ ni iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn? (b) Ipa wo làwọn àgbàlagbà ń kó?

15 Àmọ́, iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn kì í ṣe iṣẹ́ tẹ́nì kan máa ń dá ṣe o. Kàkà bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ gbogbo ará ìjọ ni. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Jésù sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòh. 13:35) Lóòótọ́ sì ni, báwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá wá sípàdé, ìfẹ́ tí wọ́n ń rí láàárín wa máa ń wú wọn lórí. Obìnrin kan tó ń kọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì kọ̀wé sí wa pé: “Mo máa ń gbádùn ìpàdé tí mò ń lọ gan-an ni. Wọ́n máa ń gba èèyàn tọwọ́tẹsẹ̀ níbẹ̀!” Jésù sọ pé àwọn tó bá di ọmọlẹ́yìn òun lè rí àtakò lọ́dọ̀ àwọn ìbátan wọn. (Ka Mátíù 10:35-37.) Àmọ́ ó ṣèlérí pé wọ́n á rí ọ̀pọ̀ “àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin àti àwọn ìyá àti àwọn ọmọ” nínú ìjọ Ọlọ́run.—Máàkù 10:30.

16 Àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tó ti dàgbà ń kó ipa pàtàkì nínú ríran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú. Lọ́nà wo? Ká tiẹ̀ ní àwọn kan lára àwọn àgbàlagbà yìí ò lè bá èèyàn ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìdáhùn wọn tó máa ń gbéni ró nínú ìpàdé máa ń mú kí ìgbàgbọ́ gbogbo ẹni tó ń gbọ́ wọn lágbára sí i. Ìrírí wọn lójú “ọ̀nà òdodo” tí wọ́n ti ń rìn látọjọ́ pípẹ́ máa ń mú kí ìjọ túbọ̀ lárinrin ó sì ń jẹ́ kó wu àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ láti wá sínú ètò Ọlọ́run.—Òwe 16:31.

Bá A Ṣe Lè Borí Ìbẹ̀rù Wa

17. Kí la lè ṣe láti borí èrò pé a ò mọ bá a ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

17 Tó o bá ń rò pé o ò mọ bá a ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí lo lè ṣe? Rántí pé Jèhófà ran Mósè lọ́wọ́ nípa fífún un ní ẹ̀mí mímọ́ àti ẹni tí wọ́n jọ máa ṣiṣẹ́, ìyẹn Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ̀. (Ẹ́kís. 4:10-17) Jésù ṣèlérí pé ẹ̀mí Ọlọ́run á máa ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (Ìṣe 1:8) Yàtọ̀ síyẹn, méjìméjì ni Jésù rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jáde lọ wàásù. (Lúùkù 10:1) Torí náà, tó bá ń ṣòro fún ọ láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún ọ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ kó o lè ní ọgbọ́n. Lẹ́yìn náà, bá ẹni tó lè jẹ́ kó o nígboyà tó o sì lè jàǹfààní látinú ìrírí rẹ̀ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Téèyàn bá ń rántí pé àwọn táráyé ò kà sí, ìyẹn àwọn tí Ìwé Mímọ́ pè ní “àwọn ohun aláìlera ayé,” ni Jèhófà yàn láti máa lò láti gbé iṣẹ́ bàǹtà banta yìí ṣe, ó máa ń mú kí ìgbàgbọ́ ẹni túbọ̀ lágbára.—1 Kọ́r. 1:26-29.

18. Báwo la ṣe lè borí ìbẹ̀rù pé ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lè má di ọmọ ẹ̀yìn?

18 Báwo la ṣe lè borí ìbẹ̀rù pé ẹni téèyàn ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lè má dọmọ ẹ̀yìn? Ó yẹ ká máa fi sọ́kàn pé iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn kò dà bí iṣẹ́ oúnjẹ gbígbọ́, tó jẹ́ pé bí oúnjẹ dùn tàbí kò dùn, ọwọ́ ẹnì kan ṣoṣo ló wà, ìyẹn ẹni tó gbọ́únjẹ náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó kéré tán oríṣi àwọn mẹ́ta ló máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nínú iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn. Jèhófà ló ń ṣe ipa tó ṣe pàtàkì jù, nípa fífa onítọ̀hún sọ́dọ̀ ara rẹ̀. (Jòh. 6:44) Àwa àtàwọn tó kù nínú ìjọ náà á sa gbogbo ipa wa nípa lílo ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ láti fi kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà kó lè tẹ̀ síwájú. (Ka 2 Tímótì 2:15.) Yóò sì wá kù sọ́wọ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí láti tẹ̀ lé ohun tó ń kọ́. (Mát. 7:24-27) Ó lè dùn wá tẹ́ni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kò bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ mọ́. Ohun tó wù wá ni pé káwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pinnu láti sin Jèhófà, ṣùgbọ́n olúkúlùkù “ni yóò ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.”—Róòmù 14:12.

Èrè Wo Ló Wà Níbẹ̀?

19-21. (a) Àwọn àǹfààní wo la ń rí nínú kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? (b) Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo gbogbo àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù?

19 Kíkọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń jẹ́ ká lè pọkàn pọ̀ sórí wíwá Ìjọba Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́. Ó tún máa ń jẹ́ kí òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run túbọ̀ jinlẹ̀ nínú ọkàn wa. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Aṣáájú-ọ̀nà kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Barak ṣàlàyé pé: “Tó o bá ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn á mú kó di dandan fún ọ láti tẹra mọ́ ìdákẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Mo rí i pé, kí n tó lè fi ohun tí mo gbà gbọ́ kọ́ ẹlòmíì dáadáa, mo ní láti rí i dájú pé ó dá èmi fúnra mi lójú.”

20 Tó ò bá ní ẹnì kankan tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ṣó wá túmọ̀ sí pé iṣẹ́ ìsìn rẹ ò já mọ́ nǹkan kan lójú Ọlọ́run ni? Rárá o! Jèhófà mọrírì gbogbo akitiyan wa láti máa yin òun. Gbogbo àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù ló jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.” Síbẹ̀, iṣẹ́ kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń mú kí ayọ̀ wa pọ̀ sí i, bá a ṣe ń rí i tí Ọlọ́run ń mú kí irúgbìn tá à ń fún sèso. (1 Kọ́r. 3:6, 9) Aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Amy sọ pé: “Bó o bá ṣe ń rí i tí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ ń tẹ̀ síwájú, ọ̀nà ọpẹ́ rẹ lọ́dọ̀ Jèhófà á túbọ̀ máa pọ̀ sí i torí bó ṣe jẹ́ pé ìwọ ni Jèhófà lò láti fún ẹni náà ní ẹ̀bùn àgbàyanu kan, ìyẹn àǹfààní láti mọ Jèhófà àti láti rí ìyè àìnípẹ̀kun.”

21 Tá a bá ń sa gbogbo ipá wa láti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó máa mú ká lè pọkàn pọ̀ sórí sísin Ọlọ́run nísinsìnyí, ó sì máa mú kí ìrètí wa láti wọnú ayé tuntun túbọ̀ dájú. Pẹ̀lú àtìlẹ́yìn Jèhófà, àwa náà lè láǹfààní láti gba àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wa là. (Ka 1 Tímótì 4:16.) Ẹ ò rí i pé ìdùnnú yẹn á kọyọyọ!

Ǹjẹ́ O Rántí?

Àwọn ìṣòro wo ló ṣeé ṣe kó máa dí àwọn kan lọ́wọ́ tí wọn ò fi lè kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

• Kí la lè ṣe tó bá dà bíi pé ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa kò nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ ẹ̀sìn?

• Èrè wo la máa ń rí nínú kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ǹjẹ́ ò ń wá ọ̀nà míì tó o lè gbà máa kàn sáwọn èèyàn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù láti lè wá àwọn olóòótọ́ ọkàn rí?