Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”

“Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”

“Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”

“Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀, kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”—LÚÙKÙ 9:23.

1, 2. (a) Kí ni Jésù ń pè wá pé ká wá ṣe? (b) Kí lo ṣe nígbà tó o gbọ́ ìpè Jésù?

 NÍGBÀ tó kù díẹ̀ kí Jésù parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó lọ wàásù ní àgbègbè Pèríà, èyí tó wà ní ìkọjá odò Jọ́dánì, lápá ìlà oòrùn àríwá Jùdíà. Bó ṣe ń wàásù, ọ̀dọ́kùnrin kan wá bá a, ó sì béèrè ohun tóun gbọ́dọ̀ ṣe láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun. Lẹ́yìn tí Jésù ti rí i pé ọ̀dọ́kùnrin yẹn máa ń pa Òfin Mósè mọ́ tọkàntọkàn, ó nawọ́ ìkésíni kan tó kọyọyọ sí i. Jésù sọ pé: “Lọ, ta àwọn ohun tí o ní, kí o sì fi fún àwọn òtòṣì, ìwọ yóò sì ní ìṣúra ní ọ̀run, sì wá di ọmọlẹ́yìn mi.” (Máàkù 10:21) Àbẹ́ ò rí àǹfààní ńlá yẹn, pé Jésù Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run, Ẹni Gíga Jù Lọ, pe ẹnì kan kó wá máa tọ òun lẹ́yìn!

2 Ọ̀dọ́kùnrin yẹn kọ̀, kò tẹ̀ lé Jésù, àmọ́ àwọn míì tẹ̀ lé e. Ṣáájú ìgbà yẹn, Jésù ti sọ fún Fílípì pé: “Di ọmọlẹ́yìn mi.” (Jòh. 1:43) Ni Fílípì bá tẹ̀ lé Jésù, ó sì di ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì nígbà tó yá. Bí Jésù ṣe pe Mátíù náà pé kó wá di ọmọ ẹ̀yìn òun nìyẹn, Mátíù sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé e. (Mát. 9:9; 10:2-4) Bákan náà ni Jésù ṣe ké sí gbogbo ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ òdodo, nígbà tó sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀, kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.” (Lúùkù 9:23) Èyí fi hàn pé ẹnikẹ́ni ló lè di ọmọlẹ́yìn Jésù tónítọ̀hún bá fẹ́ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn lóòótọ́. Ṣéwọ náà fẹ́ máa tọ Jésù lẹ́yìn? Ọ̀pọ̀ wa ló ti ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, a sì máa ń sọ fáwọn èèyàn lóde ẹ̀rí pé Jésù ń pe àwọn náà pé kí wọ́n máa tọ òun lẹ́yìn.

3. Kí la lè ṣe tá ò fi ní dẹni tó sú lọ kúrò lẹ́yìn Jésù?

3 Àmọ́ ṣá o, ó dùn wá pé àwọn kan tó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ Bíbélì nígbà kan kò tẹ̀ síwájú mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n dẹ̀rìn, tí wọ́n sì “sú lọ” kúrò lẹ́yìn Jésù nígbà tó yá. (Héb. 2:1) Kí la lè ṣe tírú ẹ̀ kò fi ní ṣẹlẹ̀ sí wa? Á dáa ká bi ara wa láwọn ìbéèrè bíi: ‘Kí tiẹ̀ nìdí tí mo fi pinnu láti máa tọ Jésù lẹ́yìn? Kí lẹni tó bá ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ní láti máa ṣe?’ Tá a bá ń fi ìdáhùn àwọn ìbéèrè méjèèjì yìí sọ́kàn, a ó lè dúró lórí ìpinnu wa pé a ó máa tọ Jésù lẹ́yìn. Èyí á sì jẹ́ ká lè máa rọ àwọn míì pé káwọn náà wá máa tọ Jésù lẹ́yìn.

Kí Nìdí Tá A Fi Ń Tọ Jésù Lẹ́yìn?

4, 5. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jésù ló tọ́ kó jẹ́ aṣáájú wa?

4 Wòlíì Jeremáyà sọ pé: “Mo mọ̀ dáadáa, Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jer. 10:23) Kò tíì sígbà kan rí nínú ìgbésí ayé àwa ẹ̀dá tí kò hàn pé òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ Jeremáyà yìí. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ ló túbọ̀ ń ṣe kedere pé àwa ẹ̀dá èèyàn aláìpé ò lè dá ṣàkóso ara wa. Àwa ń tẹ̀ lé Jésù bó ṣe pè wá, torí a ti mọ̀ pé òun lẹni tó tọ́ láti jẹ́ Aṣáájú wa, pé kò sí aṣáájú míì tó lè dà bíi tiẹ̀ láéláé láàárín àwọn ọmọ èèyàn. Jẹ́ ká gbé àwọn ẹ̀rí mélòó kan yẹ wò tó fi hàn pé Jésù ló yẹ ní aṣáájú.

5 Ẹ̀rí àkọ́kọ́ ni pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ló yan Jésù gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà Aṣáájú. Rò ó wò ná, lẹ́yìn Ẹlẹ́dàá wa, ta ló tún lè mọ Aṣáájú tó yẹ wá? Ẹ̀rí kejì ni pé Jésù ní àwọn ànímọ́ tó wuni téèyàn á fẹ́ ní. (Ka Aísáyà 11:2, 3.) Àpẹẹrẹ pípé ló jẹ́ fún wa. (1 Pét. 2:21) Ẹ̀rí kẹta ni pé tọkàntọkàn ni Jésù ń bójú tó àwọn tó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. Ó fi èyí hàn nípa bó ṣe fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wọn. (Ka Jòhánù 10:14, 15.) Ó sì fi hàn pé olùṣọ́ àgùntàn tó ń ṣètọ́jú àwọn àgùntàn rẹ̀ lòun bó ṣe ń ṣamọ̀nà wa lọ́nà tí ayé wa á fi láyọ̀ nísinsìnyí tá ó sì tún ní ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú ológo. (Jòh. 10:10, 11; Ìṣí. 7:16, 17) Fún àwọn ìdí yìí àtàwọn míì, ó bọ́gbọ́n mu bá a ṣe pinnu láti máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. Àmọ́ kí lẹni tó bá pinnu láti máa tọ Jésù lẹ́yìn ní láti máa ṣe?

6. Kí lẹni tó bá ń tọ Jésù lẹ́yìn ní láti máa ṣe?

6 Jíjẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi kì í ṣe ọ̀rọ̀ pé ká kàn máa pe ara wa ní Kristẹni. Nǹkan bíi bílíọ̀nù méjì èèyàn ṣáà ló ń pe ara wọn ní ọmọlẹ́yìn Kristi lónìí, ṣùgbọ́n tí ìwà wọn fi wọ́n hàn pé “oníṣẹ́ ìwà àìlófin” ni wọ́n. (Ka Mátíù 7:21-23.) Nígbà tẹ́nì kan bá fi hàn pé òun ti ṣe tán láti máa tọ Jésù lẹ́yìn, a máa ń ṣàlàyé fún un pé àwọn ẹ̀kọ́ Jésù àti àpẹẹrẹ rẹ̀ lẹni tó bá máa jẹ́ Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé nínú gbogbo ohun tó bá ń ṣe nígbèésí ayé. Kóhun tá à ń sọ lè ṣe kedere, wo díẹ̀ lára àwọn ohun tá a mọ̀ nípa Jésù.

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ọgbọ́n Jésù

7, 8. (a) Kí ni Jésù máa ń ṣe tó jẹ́ ká mọ ohun tí ọgbọ́n jẹ́, kí sì nìdí tí Jésù fi ní ọgbọ́n tó pọ̀ gan-an? (b) Báwo ni Jésù ṣe ṣohun tó bọ́gbọ́n mu, báwo la sì ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?

7 Ọ̀pọ̀ ànímọ́ tó ta yọ ni Jésù ní, ṣùgbọ́n mẹ́rin péré tá a óò gbé yẹ̀ wò ni ọgbọ́n rẹ̀, ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀, ìtara rẹ̀ àti ìfẹ́ rẹ̀. Jẹ́ ká kọ́kọ́ jíròrò ọgbọ́n Jésù, ìyẹn bó ṣe máa ń fi ìmọ̀ àti òye ṣe gbogbo ohun tó bá ń ṣe. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Inú [Jésù] ni a rọra fi gbogbo ìṣúra ọgbọ́n àti ti ìmọ̀ pa mọ́ sí.” (Kól. 2:3) Ibo ni Jésù ti rí irú ọgbọ́n yìí? Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba ti kọ́ mi ni mo ń sọ nǹkan wọ̀nyí.” (Jòh. 8:28) Ọ̀dọ́ Jèhófà ló ti rí ọgbọ́n rẹ̀, torí náà, kò yà wá lẹ́nu bí àwọn ìṣe rẹ̀ ṣe fi làákàyè tó kàmàmà hàn.

8 Bí àpẹẹrẹ, làákàyè tó ga ni Jésù fi yan ohun tó fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe. Ńṣe ni Jésù dìídì jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ òun lọ́rùn, tó sì gbájú mọ́ ohun kan ṣoṣo, ìyẹn ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ó lo àkókò àti agbára rẹ̀ lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu, ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ló fi tàn kálẹ̀. Táwa náà bá jẹ́ kí ‘ojú wa mú ọ̀nà kan,’ a jẹ́ pé à ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Èyí ni kò ní jẹ́ ká fi àwọn nǹkan tí kò pọn dandan tó ń gba èyí tó pọ̀ jù lára okun àti àkókò èèyàn dí ara wa lọ́wọ́. (Mát. 6:22) Ọ̀pọ̀ Kristẹni ló ti ṣe ohun tó fi hàn pé wọ́n jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ wọn lọ́rùn, kí wọ́n lè rí àkókò tó pọ̀ sí i lò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́. A ti rí àwọn kan tí wọ́n di aṣáájú-ọ̀nà. Tó o bá wà lára wọn, a kí ọ pé o káre láé. ‘Wíwá Ìjọba Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́’ máa ń fúnni nífọ̀kànbalẹ̀ àti ayọ̀ tó pọ̀.—Mát. 6:33.

Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ bíi Ti Jésù

9, 10. Báwo ni Jésù ṣe fi ìrẹ̀lẹ̀ hàn?

9 Ohun kejì tá óò jíròrò nípa Jésù ni ìrẹ̀lẹ̀ tó ní. Bí agbára bá dọ́wọ́ àwọn èèyàn aláìpé, ńṣe ló máa ń gùn wọ́n. Àmọ́ ọ̀rọ̀ Jésù mà yàtọ̀ síyẹn o! Pẹ̀lú ipò pàtàkì tí Jésù dì mú nínú mímú ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ, Jésù kò ní ìgbéraga olóókan. Bíbélì gbà wá níyànjú pé káwa náà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ nínú ìyẹn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ pa ẹ̀mí ìrònú yìí mọ́ nínú yín, èyí tí ó wà nínú Kristi Jésù pẹ̀lú, ẹni tí ó jẹ́ pé, bí ó tilẹ̀ wà ní ìrísí Ọlọ́run, kò ronú rárá nípa ìjá-nǹkan-gbà, èyíinì ni, pé kí òun bá Ọlọ́run dọ́gba. Ó tì o, ṣùgbọ́n ó sọ ara rẹ̀ di òfìfo, ó sì gbé ìrísí ẹrú wọ̀, ó sì wá wà ní ìrí ènìyàn.” (Fílí. 2:5-7) Kí nìyẹn túmọ̀ sí?

10 Inú ògo ni Jésù wà nígbà tó wà lọ́dọ̀ Bàbá rẹ̀ lọ́run lọ́hùn-ún, àmọ́ tinútinú ló fi “sọ ara rẹ̀ di òfìfo.” Jèhófà mú ìwàláàyè Jésù ó sì fi sínú wúńdíá Júù kan tó lóyún rẹ̀ fún oṣù mẹ́sàn-án kó tó wá bí i gẹ́gẹ́ bí ọmọ tuntun jòjòló. Ilé Jósẹ́fù, káfíńtà kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́ ni wọ́n bí i sí. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, Jésù dọmọ àfànítẹ̀tẹ́, ó ṣe bẹ́ẹ̀ di ọmọdékùnrin, nígbà tó sì yá, ó dẹni tó tójúúbọ́. Jésù kì í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀, síbẹ̀ ní gbogbo ìgbà èwe rẹ̀, ó jẹ́ kí àwọn òbí rẹ̀ ẹlẹ́ṣẹ̀ àti aláìpé máa darí òun. (Lúùkù 2:51, 52) Àbẹ́ ò rí i pé ìrẹ̀lẹ̀ yẹn pọ̀!

11. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìrẹ̀lẹ̀ Jésù?

11 Àpẹẹrẹ ìrẹ̀lẹ̀ Jésù là ń tẹ̀ lé báwa náà bá ń fi tinútinú gba àwọn iṣẹ́ kan tó dà bí ẹní bù wá kù. Bí àpẹẹrẹ, wo iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere tí Jésù gbé lé wa lọ́wọ́. Ó lè dà bí iṣẹ́ tí ò gbayì, àgàgà báwọn èèyàn ò bá fẹ́ gbọ́ wa, tí wọ́n ń kẹ́gàn wa tàbí tí wọ́n ń ṣe ẹ̀tanú sí wa. Àmọ́, bá ò ṣe jáwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà, ó ń ṣeé ṣe fún wa láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa tọ Jésù lẹ́yìn. Èyí ń jẹ́ ká lè máa gbẹ̀mí là. (Ka 2 Tímótì 4:1-5.) Àpẹẹrẹ mìíràn ni iṣẹ́ títún Gbọ̀ngàn Ìjọba wa ṣe. Lára irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ni gbígbálẹ̀, kíkó ìdọ̀tí dà nù, fífọ ilé ìtura tàbí ṣíṣe àwọn iṣẹ́ míì bẹ́ẹ̀, téèyàn lè máa rò pé kò pọ́nni lé. Ṣùgbọ́n, a mọ̀ pé ara iṣẹ́ ìsìn mímọ́ wa ló jẹ́ láti rí i pé à ń bójú tó Gbọ̀ngàn Ìjọba wa, nítorí pé ibẹ̀ ni ibùjọsìn tòótọ́ ládùúgbò. Bí a bá ń fi tọkàntọkàn ṣe àwọn iṣẹ́ tá a lè máa wò bí èyí tí ò fi bẹ́ẹ̀ gbayì, ńṣe là ń fi hàn pé a jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, a sì ń tipa bẹ́ẹ̀ tẹ̀ lé ipasẹ̀ Kristi.

Jẹ́ Onítara bíi Ti Jésù

12, 13. (a) Báwo ni Jésù ṣe lo ìtara, kí ló sì mú kó lo ìtara náà? (b) Kí ló máa mú káwa náà máa fìtara ṣiṣẹ́ ìwàásù?

12 Ẹ jẹ́ ká wá jíròrò bí Jésù ṣe fi ìtara ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jésù ṣe nígbà tó wà láyé. Níbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé Jésù, ó ṣeé ṣe kó bá Jósẹ́fù, bàbá tó jẹ́ alágbàtọ́ rẹ̀, ṣiṣẹ́ káfíńtà. Nígbà tó wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó ń ṣiṣẹ́ ìyanu. Ara iṣẹ́ ìyanu ọ̀hún ni wíwo aláìsàn sàn àti jíjí òkú dìde. Ṣùgbọ́n olórí iṣẹ́ rẹ̀ ni wíwàásù ìhìn rere àti kíkọ́ àwọn tó létí ìgbọ́. (Mát. 4:23) Iṣẹ́ yẹn kan náà làwa tá a jẹ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní láti ṣe. Ọ̀nà wo la lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀? Ọ̀nà kan ni pé ká jẹ́ kí ohun tó mú kí Jésù ṣiṣẹ́ yẹn mú káwa náà máa ṣe é.

13 Ìfẹ́ tí Jésù ní sí Ọlọ́run ni olórí ohun tó ń mú kó máa wàásù kó sì máa kọ́ni. Àmọ́ Jésù tún ní ìfẹ́ sí ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó fi ń kọ́ àwọn èèyàn. Lójú Jésù, ìṣúra iyebíye ni òtítọ́ tó ń kọ́ni, ó sì máa ń wù ú láti fi kọ́ àwọn ẹlòmíì. Ojú táwa tá a jẹ́ “olùkọ́ni ní gbangba” fi ń wo òtítọ́ náà nìyẹn. Àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tá a ti kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mà ṣeyebíye gan-an o! Bí àpẹẹrẹ, a ti kọ́ nípa ọ̀ràn ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ láyé àtọ̀run àti bí ọ̀ràn náà ṣe máa yanjú. Bákan náà, a ti lóye ohun tí Ìwé Mímọ́ fi kọ́ni nípa ipò táwọn tó ti kú wà àtàwọn ìbùkún tá a máa rí nínú ayé tuntun Ọlọ́run. Ì báà ti pẹ́ tá a ti mọ àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ yìí tàbí kó jẹ́ pé a ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀ wọ́n ni, òtítọ́ ṣíṣeyebíye náà ni wọ́n á ṣì máa jẹ́, ìyẹn ìṣúra tí kò ṣeé díye lé. (Ka Mátíù 13:52.) Bá a ṣe ń wàásù tìtaratìtara, ńṣe là ń jẹ́ káwọn èèyàn rí bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn ohun tí Jèhófà ti kọ́ wa.

14. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́?

14 Jẹ́ ká tún ṣàyẹ̀wò ọ̀nà tí Jésù gbà kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́. Gbogbo ìgbà ló máa ń darí àwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ sínú Ìwé Mímọ́. Tó bá fẹ́ sọ ọ̀rọ̀ pàtàkì kan, ó sábàá máa ń sọ pé: “A kọ̀wé rẹ̀.” (Mát. 4:4; 21:13) Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó sọ sínú Bíbélì, ó ju ìdajì lọ lára àwọn Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí Jésù ṣàyọlò ní tààràtà tàbí tó kàn tọ́ka sí. Bíi ti Jésù, Bíbélì làwa náà gbára lé lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, a sì máa ń gbìyànjú láti ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ní gbogbo ìgbà tó bá ṣeé ṣe. À ń tipa báyìí mú káwọn ọlọ́kàn rere fúnra wọn rí i pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run la fi ń kọ́ wọn, kì í ṣe èrò tiwa. Ẹ ò rí bínú wa ṣe máa ń dùn tó bá a bá rẹ́ni tó nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì, tó sì fẹ́ ká jọ wo ìtumọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ọ̀nà tó gbà wúlò! Bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá sì wá gbà láti máa tọ Jésù lẹ́yìn, ńṣe layọ̀ wa máa ń kún àkúnwọ́sílẹ̀.

Títẹ̀lé Jésù Gba Pé Ká Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn

15. Kí ni ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ Jésù tó ta yọ, bá a bá sì ń ronú lórí rẹ̀, ipa wo ló máa ń ní lórí wa?

15 Èyí tó kẹ́yìn lára àwọn ànímọ́ Jésù tá a máa gbé yẹ̀ wò ni èyí tó ń mọ́kàn yọ̀ jù, ìyẹn ìfẹ́ tó ní sọ́mọ aráyé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ìfẹ́ tí Kristi ní sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wa.” (2 Kọ́r. 5:14) Bá a bá ń ronú síwá sẹ́yìn lórí bí Jésù ṣe nífẹ̀ẹ́ aráyé lápapọ̀ àti bó ṣe nífẹ̀ẹ́ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, ayọ̀ máa ń kún ọkàn wa, ó sì máa ń jẹ́ kó di ọ̀ranyàn fún wa láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.

16, 17. Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn?

16 Ọ̀nà wo ni Jésù gbà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ aráyé? Bó ṣe fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ tinútinú nítorí aráyé ni ọ̀nà tó ga jù lọ tó gbà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa. (Jòh. 15:13) Ṣùgbọ́n o, lákòókò iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó tún fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn láwọn ọ̀nà míì. Bí àpẹẹrẹ, ó bá àwọn tó wà nínú ìbànújẹ́ kẹ́dùn. Nígbà tó rí Màríà àtàwọn tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé wọ́n ń sunkún nítorí Lásárù tó kú, ipò ìbànújẹ́ wọn dùn ún wọra. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù máa jí Lásárù dìde láìpẹ́ sígbà yẹn, ipò náà ká a lára débi pé ó “bẹ̀rẹ̀ sí da omijé.”—Jòh. 11:32-35.

17 Nígbà tí Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, adẹ́tẹ̀ kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí fún un pé: “Bí ìwọ bá sáà ti fẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ lè mú kí èmi mọ́.” Kí ni Jésù wá ṣe? Àkọsílẹ̀ yẹn sọ pé, “àánú ṣe” Jésù. Ló bá ṣe ohun kan tó jọni lójú. Bíbélì sọ pé: “Ó sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fọwọ́ kàn án, ó sì wí fún un pé: ‘Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀. Kí ìwọ mọ́.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹ̀tẹ̀ náà sì pòórá kúrò lára rẹ̀, ó sì mọ́.” Gẹ́gẹ́ bẹ́ ẹ ṣe mọ̀, Òfin Mósè ka àwọn adẹ́tẹ̀ sí aláìmọ́, ó sì dájú pé kò dìgbà tí Jésù bá fọwọ́ kan ọkùnrin náà kó tó lè wò ó sàn. Síbẹ̀, bí Jésù ṣe fọwọ́ kan adẹ́tẹ̀ yẹn nígbà tó ń wò ó sàn, ńṣe ló jẹ́ kó láǹfààní láti fara kan èèyàn, bóyá sì ni adẹ́tẹ̀ yẹn lè rántí ìgbà téèyàn ti fọwọ́ kan òun gbẹ̀yìn. Ìyọ́nú tí Jésù lò yìí mà ga o!—Máàkù 1:40-42.

18. Ọ̀nà wo la lè gbà máa fi hàn pé a ní “ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì”?

18 Bíbélì sọ fún àwa tá a jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi pé ká máa fìfẹ́ bá àwọn èèyàn lò nípa níní “ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì.” (1 Pét. 3:8) Òótọ́ ni pé, ó lè má rọrùn láti mọ bó ṣe ń ṣe arákùnrin tàbí arábìnrin kan tí àìsàn líle koko ń bá fínra tàbí tí ìdààmú ọkàn bá, àgàgà bá ò bá tíì nírú ìṣòro bẹ́ẹ̀ rí. Ṣùgbọ́n, ká rántí pé Jésù ò ṣàìsàn rí, síbẹ̀ ó báwọn aláìsàn kẹ́dùn. Báwo la ṣe lè ní ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn bíi tirẹ̀? A lè fi hàn pé a ní ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn nípa fífetí sílẹ̀ nígbà táwọn tó níṣòro bá ń sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn fún wa. A lè bi ara wa pé, ‘Bó bá jémi ni mo nírú ìṣòro tí wọ́n ní yìí ńkọ́, báwo lá ṣe rí lára mi?’ Bá a bá ń tètè fòye mọ ohun tó ń ṣe àwọn ẹlòmíì, á túbọ̀ rọrùn fún wa láti “máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́.” (1 Tẹs. 5:14) A ó máa tipa báyìí tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù.

19. Àwọn ọ̀nà wo ló yẹ kí àpẹẹrẹ Jésù gbà nípa lórí wa?

19 Ẹ ò rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan tó lárinrin la lè rí kọ́ látinú àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù Kristi sọ àtàwọn ohun tó ṣe! Bá a bá ṣe ń kọ́ nípa rẹ̀ tó la ó ṣe máa fẹ́ láti dà bíi rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì ṣe máa wù wá tó láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ káwọn náà lè fìwà jọ ọ́. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa rí ìdùnnú nínú títẹ̀lé Mèsáyà Ọba wa nísinsìnyí àti títí láé!

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

• Báwo la ṣe lè jẹ́ ọlọgbọ́n bíi ti Jésù?

• Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé a jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?

• Báwo la ṣe lè jẹ́ onítara lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?

• Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù lórí ọ̀rọ̀ nínífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

ÌWÉ KAN TÓ Ń RANNI LỌ́WỌ́ LÁTI MÁA TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ KRISTI

Nígbà àpéjọ àgbègbè ọdún 2007, a kéde pé a ti gbé ìwé tuntun kan jáde tó ń jẹ́ “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn.” Ojú ewé igba ó dín mẹ́jọ [192] ni ìwé náà ní. A ṣe ìwé yìí láti mú káwọn Kristẹni tó bá kà á lè túbọ̀ máa ronú jinlẹ̀ nípa Jésù, pàápàá nípa àwọn ànímọ́ àti ìṣe rẹ̀. Lẹ́yìn orí méjì àkọ́kọ́ tá a fi nasẹ̀ ìwé yìí, ẹ óò rí ìsọ̀rí àkọ́kọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ànímọ́ Jésù tó ta yọ, ìyẹn ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀, ìgboyà rẹ̀, ọgbọ́n rẹ̀, ìgbọràn rẹ̀ àti ìfaradà rẹ̀.

Ẹ̀yìn ìyẹn ni ìwé náà wá jíròrò àwọn ohun tí Jésù gbé ṣe gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ àti oníwàásù ìhìn rere, ó sì tún sọ àwọn ọ̀nà kan tó gbà fi ìfẹ́ ńlá rẹ̀ hàn. Látìbẹ̀rẹ̀ ìwé náà dópin rẹ̀ lẹ ó ti máa rí àwọn ohun tó máa ran àwa Kristẹni lọ́wọ́ láti fara wé Jésù.

Ó dá wa lójú pé ìwé yìí á jẹ́ ká lè ṣàyẹ̀wò ara wa ká sì bi ara wa pé: ‘Ṣé mò ń tọ Jésù lẹ́yìn lóòótọ́? Báwo ni mo ṣe lè túbọ̀ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn pẹ́kípẹ́kí?’ Yóò tún ran ‘gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun’ lọ́wọ́ láti di ọmọlẹ́yìn Kristi.—Ìṣe 13:48.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Jésù fínnúfíndọ̀ gbà kí wọ́n bí òun gẹ́gẹ́ bí ọmọ tuntun jòjòló sínú ayé. Ànímọ́ wo ló ní kó tó lè ṣèyẹn?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Kí ló máa mú ká jẹ́ onítara lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?