Ǹjẹ́ ‘Ìríjú Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run’ Ni Ọ́?
Ǹjẹ́ ‘Ìríjú Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run’ Ni Ọ́?
“Nínú ìfẹ́ ará, ẹ ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.”—RÓÒMÙ 12:10.
1. Kí ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń mú dá wa lójú?
Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ń mú un dá wa lójú léraléra pé Jèhófà yóò ràn wá lọ́wọ́ nígbà tí ìrẹ̀wẹ̀sì tàbí ìbànújẹ́ ọkàn bá bá wa. Bí àpẹẹrẹ, wo ọ̀rọ̀ ìtùnú tí Bíbélì sọ yìí, pé: “Jèhófà ń fún gbogbo àwọn tí ó ṣubú ní ìtìlẹyìn, ó sì ń gbé gbogbo àwọn tí a tẹ̀ lórí ba dìde.” Ó tún sọ pé: “Ó ń mú àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn lára dá, ó sì ń di àwọn ojú ibi tí ń ro wọ́n.” (Sm. 145:14; 147:3) Síwájú sí i, Baba wa ọ̀run fúnra rẹ̀ sọ pé: “Èmi, Jèhófà Ọlọ́run rẹ, yóò di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, Ẹni tí ń wí fún ọ pé, ‘Má fòyà. Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.’”—Aísá. 41:13.
2. Báwo ni Jèhófà ṣe ń pèsè ìrànlọ́wọ́ fáwa ìránṣẹ́ rẹ̀?
2 Báwo wá ni Jèhófà tó ń gbé nínú ọ̀run tá ò lè rí, ṣe ń ‘di ọwọ́ wa mú’? Báwo ló ṣe ń gbé wa dìde nígbà tí ìbànújẹ́ bá tẹ̀ wá lórí ba? Oríṣiríṣi ọ̀nà ni Jèhófà Ọlọ́run gbà ń pèsè ìrànlọ́wọ́ yìí. Bí àpẹẹrẹ, ó ń tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ fún àwa èèyàn rẹ̀ ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.” (2 Kọ́r. 4:7; Jòh. 14:16, 17) Ó tún ń fi ohun tó wà nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ń sa agbára, gbé àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ ró. (Héb. 4:12) Ǹjẹ́ ọ̀nà mìíràn tún wà tí Jèhófà gbà ń fún wa lágbára? Ìdáhùn ìbéèrè yìí wà nínú ìwé Pétérù Kìíní.
Ọlọ́run Ń Fi “Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí” Rẹ̀ Hàn “ní Onírúurú Ọ̀nà”
3. (a) Gbólóhùn wo ni àpọ́sítélì Pétérù sọ nípa àwọn àdánwò? (b) Kí ni Pétérù jíròrò nínú apá tó kẹ́yìn ìwé rẹ̀ àkọ́kọ́?
3 Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù ń kọ̀wé sáwọn onígbàgbọ́ tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró, ó sọ fún wọn pé ó yẹ kí wọ́n máa yọ̀ nítorí èrè ńlá tó ń dúró dè wọ́n. Ó fi kún un pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ fún ìgbà díẹ̀ nísinsìnyí, bí ó bá gbọ́dọ̀ rí bẹ́ẹ̀, a ti fi onírúurú àdánwò kó ẹ̀dùn-ọkàn bá yín.” (1 Pét. 1:1-6) Kíyè sí ọ̀rọ̀ náà, “onírúurú,” èyí tó fi hàn pé àwọn àdánwò náà máa ń wá ní oríṣiríṣi ọ̀nà. Àmọ́ Pétérù kò fi ọ̀rọ̀ náà mọ síbẹ̀, kí àwọn ará má lọ máa ṣiyèméjì pé bóyá làwọn á lè fara da àwọn onírúurú àdánwò náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, Pétérù mú un dá àwọn Kristẹni náà lójú pé Jèhófà yóò fún wọn lágbára láti fara da àdánwò èyíkéyìí tí wọn ì báà dojú kọ. Ó sọ ọ̀rọ̀ náà ní apá tó kẹ́yìn ìwé rẹ̀ àkọ́kọ́, níbi tó ti jíròrò ọ̀ràn tó jẹ mọ́ “òpin ohun gbogbo.”—1 Pét. 4:7.
4. Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ tó wà nínú 1 Pétérù 4:10 fi ń tuni nínú?
4 Pétérù sọ pé: “Níwọ̀n yíyẹ gẹ́gẹ́ bí olúkúlùkù ti rí ẹ̀bùn kan gbà, ẹ lò ó fún ṣíṣe ìránṣẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì gẹ́gẹ́ bí ìríjú àtàtà fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tí a fi hàn ní onírúurú ọ̀nà.” (1 Pét. 4:10) Níbí yìí, Pétérù tún lo ọ̀rọ̀ náà “onírúurú.” Ohun tó ń fìyẹn sọ ni pé, ‘Àwọn àdánwò máa ń wá ní oríṣiríṣi ọ̀nà, àmọ́ bákan náà, Ọlọ́run máa ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ hàn ní oríṣiríṣi ọ̀nà.’ Kí nìdí tí gbólóhùn yẹn fi ń tuni nínú? Ìdí ni pé gbólóhùn yẹn jẹ́ ká mọ̀ pé kò sí irú àdánwò tí ì báà jẹ́, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run kan máa wà táá jẹ́ ká lè fara dà á. Àmọ́, ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ hàn sí wa nínú gbólóhùn Pétérù yẹn? Ó jẹ́ nípasẹ̀ àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́.
‘Ṣíṣe Ìránṣẹ́ fún Ara Wa Lẹnì Kìíní-Kejì’
5. (a) Kí ló yẹ kí olúkúlùkù àwa Kristẹni máa ṣe? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló jẹ yọ?
5 Gbogbo ará ìjọ ni Pétérù ń bá sọ̀rọ̀, nígbà tó sọ pé: “Lékè ohun gbogbo, ẹ ní ìfẹ́ gbígbóná janjan fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” Ó wá fi kún un pé: “Níwọ̀n yíyẹ gẹ́gẹ́ bí olúkúlùkù ti rí ẹ̀bùn kan gbà, ẹ lò ó fún ṣíṣe ìránṣẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” (1 Pét. 4:8, 10) Nítorí náà, olúkúlùkù àwa tá a wà nínú ìjọ ló yẹ ká jọ máa gbé ara wa ró. Jèhófà ti fi ohun kan tó ṣeyebíye sí ìkáwọ́ wa, ojúṣe wa sì ni láti máa pín in fáwọn ẹlòmíràn. Nítorí náà, kí làwọn ohun iyebíye tó wà níkàáwọ́ wa? Pétérù pe ohun náà ní “ẹ̀bùn.” Kí ni ẹ̀bùn náà? Báwo la ṣe ń “lò ó fún ṣíṣe ìránṣẹ́ fún ara [wa] lẹ́nì kìíní-kejì”?
6. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fi síkàáwọ́ àwa Kristẹni?
6 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé jẹ́ láti òkè.” (Ják. 1:17) Nì tòdodo, gbogbo ẹ̀bùn tí Jèhófà fi síkàáwọ́ àwa èèyàn rẹ̀ ló jẹ́ ọ̀nà tó gbà ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ hàn. Ẹ̀bùn kan tó ta yọ tí Jèhófà fún wa ni ẹ̀mí mímọ́. Ẹ̀bùn yìí ń jẹ́ ká ní àwọn ànímọ́ tí inú Ọlọ́run dùn sí, irú bí ìfẹ́, ìwà rere, àti ìwà tútù. Àwọn ànímọ́ yẹn sì ń mú ká fi ìfẹ́ àtọkànwá hàn sáwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ ká sì máa dìde ìrànlọ́wọ́ fún wọn. Ojúlówó ọgbọ́n àti ìmọ̀ tún wà lára àwọn ẹ̀bùn rere tá a ní nípasẹ̀ ìtìlẹyìn ẹ̀mí mímọ́. (1 Kọ́r. 2:10-16; Gál. 5:22, 23) Àní gbogbo agbára wa, òye wa àti gbogbo ohun tá a mọ̀-ọ́n ṣe la lè kà sí ẹ̀bùn tó yẹ ká máa lò fún ìyìn àti ògo Baba wa ọ̀run. Ojúṣe wa sí Ọlọ́run ni láti máa lo òye àti àwọn ànímọ́ wa láti mú kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run dé ọ̀dọ̀ àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́.
Báwo La Ṣe Lè Máa ‘Lò Ó fún Ṣíṣe Ìránṣẹ́ Fúnni’?
7. (a) Kí ni gbólóhùn náà, “níwọ̀n yíyẹ” fi hàn? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa, kí sì nìdí?
7 Pétérù tún sọ nípa àwọn ẹ̀bùn tá a gbà, ó ní: “Níwọ̀n yíyẹ gẹ́gẹ́ bí olúkúlùkù ti rí ẹ̀bùn kan gbà, ẹ lò ó.” Gbólóhùn náà, “níwọ̀n yíyẹ” fi hàn pé kì í ṣe pé àwọn ànímọ́ àti òye náà yàtọ̀ síra nìkan ni, àmọ́ ìwọ̀n tí olúkúlùkù wa ní tún yàtọ̀ síra. Irú ẹ̀bùn tí ì báà jẹ́, ó rọ ẹnì kọ̀ọ̀kan láti ‘lo ẹ̀bùn náà fún ṣíṣe ìránṣẹ́ fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.’ Bákàn náà, gbólóhùn náà, “lò ó . . . gẹ́gẹ́ bí ìríjú àtàtà” jẹ́ àṣẹ tá a gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé. Nítorí náà, a ní láti bi ara wa pé: ‘Ǹjẹ́ mo máa ń lo àwọn ẹ̀bùn tá a fi síkàáwọ́ mi láti fi gbé àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ ró?’ (Fi wé 1 Tímótì 5:9, 10.) ‘Àbí ńṣe ni mo máa ń lo òye tí Jèhófà fún mi fún àǹfààní ara mi nìkan, bóyá láti wá ọrọ̀ tàbí ipò?’ (1 Kọ́r. 4:7) Tá a bá ń lo àwọn ẹ̀bùn wa ‘fún ṣíṣe ìránṣẹ́ fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì,’ inú Jèhófà á máa dùn sí wa.—Òwe 19:17; ka Hébérù 13:16.
8, 9. (a) Àwọn ọ̀nà wo làwọn ará kárí ayé gbà ń ran ara wọn lọ́wọ́? (b) Ọ̀nà wo làwọn arákùnrin àti arábìnrin nínú ìjọ yín gbà ń ran ara wọn lọ́wọ́?
8 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mẹ́nu kan onírúurú ọ̀nà táwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní gbà ń ṣe ìránṣẹ́ fún ara wọn. (Ka Róòmù 15:25, 26; 2 Tímótì 1:16-18.) Bákan náà lónìí, àwa Kristẹni tòótọ́ ń fi gbogbo ọkàn wa tẹ̀ lé àṣẹ náà pé ká máa ṣe ìránṣẹ́ fáwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́. Jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀nà kan tá a gbà ń ṣe é.
9 Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin ló ń lo ọ̀pọ̀ wákàtí lóṣooṣù láti múra iṣẹ́ tí wọ́n ní nípàdé sílẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá dé ìpàdé, tí wọ́n wá ń sọ àwọn kókó pàtàkì-pàtàkì tí wọ́n ti rí kó jọ nígbà ìdákẹ́kọ̀ọ́ wọn, ọ̀rọ̀ wọn tó kún fún ẹ̀kọ́ máa ń mú kí gbogbo àwọn ará ìjọ ní ìfaradà. (1 Tím. 5:17) Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin jẹ́ ọlọ́yàyà wọ́n sì ń fi ìyọ́nú hàn sáwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́. (Róòmù 12:15) Àwọn kan sábà máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ní ìdààmú ọkàn, wọ́n sì máa ń gbàdúrà fún wọn. (1 Tẹs. 5:14) Àwọn mìíràn máa ń kọ ọ̀rọ̀ ìtùnú tó ń gbéni ró ránṣẹ́ sáwọn ará tó bá wà nínú àdánwò. Àwọn mìíràn sì tún máa ń ṣèrànwọ́ fáwọn tára wọn ò le kí wọ́n lè wá sípàdé. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kópa nínú ètò ìrànwọ́ tá a máa ń ṣe fún àwọn ará tí àjálù ba ilé wọn jẹ́. Gbogbo ìfẹ́ àti ìrànwọ́ táwọn arákùnrin àti arábìnrin aláàánú yìí ń ṣe jẹ́ “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tí a fi hàn ní onírúurú ọ̀nà.”—Ka 1 Pétérù 4:11.
Èwo Ló Ṣe Pàtàkì Jù?
10. (a) Apá méjì wo ni Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ó jẹ́ ara iṣẹ́ ìsìn òun sí Ọlọrun? (b) Báwo la ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù lóde òní?
10 Kì í ṣe ẹ̀bùn tá ó máa lò fáwọn ará wa nìkan ni Ọlọ́run fi síkàáwọ́ àwa ìránṣẹ́ rẹ̀, ó tún fi ìhìn rere síkàáwọ́ wa láti máa sọ fún aráyé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé apá méjèèjì yìí ló jẹ́ ara iṣẹ́ ìsìn tóun gbọ́dọ̀ máa ṣe sí Jèhófà. Ó kọ̀wé sí ìjọ tó wà ní Éfésù nípa “iṣẹ́ ìríjú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run” tó rí gbà fún àǹfààní wọn. (Éfé. 3:2) Síbẹ̀, ó tún sọ pé: “Ọlọ́run ti fi wá hàn ní ẹni tí ó yẹ kí a fi ìhìn rere sí ní ìkáwọ́.” (1 Tẹs. 2:4) Bíi ti Pọ́ọ̀lù, àwa pẹ̀lú mọ̀ pé Ọlọ́run ti fi iṣẹ́ wíwàásù Ìjọba Ọlọ́run sí ìkáwọ́ wa. Bá a ti ń fi ìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà, ńṣe là ń sapá láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ oníwàásù ìhìn rere tí kì í ṣàárẹ̀. (Ìṣe 20:20, 21; 1 Kọ́r. 11:1) A mọ̀ pé wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run máa ń gba ẹ̀mí là, àmọ́ lẹ́sẹ̀ kan náà, a tún máa ń rí i pé à ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù nípa wíwá àǹfààní láti “fi ẹ̀bùn ẹ̀mí díẹ̀” fún àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́.—Ka Róòmù 1:11, 12; 10:13-15.
11. Ojú wo ló yẹ ká fi máa wo iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ gbígbé àwọn ará wa ró?
11 Èwo ló ṣe pàtàkì jù nínú apá iṣẹ́ ìsìn Kristẹni méjèèjì yìí? Ìbéèrè yìí fẹ́ dá bí ìgbà téèyàn ń béèrè pé èwo ló ṣe pàtàkì jù nínú apá méjì tí ẹyẹ kan ní? Gbogbo wa la mọ̀ pé méjèèjì ló ṣe pàtàkì nítorí ẹyẹ kì í fi apá kan fò. Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀ràn tiwa rí, a ní láti máa lọ́wọ́ nínú apá iṣẹ́ ìsìn méjèèjì yìí ká tó lè ṣe iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run láṣepé. Nítorí èyí, dípò ká máa rò pé wíwàásù ìhìn rere àti gbígbé àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ ró kò bá ara wọn tan, ojú tí àpọ́sítélì Pétérù àti Pọ́ọ̀lù fi wo àwọn iṣẹ́ náà ló yẹ káwa náà fi máa wò wọ́n. Ńṣe ni apá méjèèjì wọ́nú ara wọn. Lọ́nà wo?
12. Báwo la ṣe jẹ́ ohun èlò ní ọwọ́ Jèhófà?
12 Gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere, a máa ń lo gbogbo ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tá a bá mọ̀ láti fi mú kí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run wọ ọkàn àwọn èèyàn. Lọ́nà yẹn, a retí pé ìyẹn á mú kí wọ́n di ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Àmọ́, a tún máa ń lo òye èyíkéyìí àti àwọn ẹ̀bùn mìíràn tá a bá ní láti fún àwọn ará wa níṣìírí. À ń ṣe èyí nípa sísọ ọ̀rọ̀ tó ń gbé wọn ró àti nípa ṣíṣèrànwọ́ fún wọn. Gbogbo ìwọ̀nyí sì jẹ́ ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ hàn sí wọn. (Òwe 3:27; 12:25) Lọ́nà yẹn, a retí pé ìyẹn á mú kí wọ́n máa jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi nìṣó. Iṣẹ́ méjèèjì yìí, ìyẹn wíwàásù fáwọn èèyàn àti ‘ṣíṣe ìránṣẹ́ fún ara wa,’ ń fún wa láǹfààní àgbàyanu láti jẹ́ ohun èlò ní ọwọ́ Jèhófà.—Gál. 6:10.
“Ẹ Ní Ìfẹ́ni Oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún Ara Yín Lẹ́nì Kìíní-Kejì”
13. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ tá a bá ṣíwọ́ ‘ṣíṣe ìránṣẹ́ fún ara wa’?
13 Pọ́ọ̀lù rọ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ pé: “Nínú ìfẹ́ ará, ẹ ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.” (Róòmù 12:10) Ká sòótọ́, tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará dénúdénú, yóò jẹ́ ká lè máa fi gbogbo ọkàn wa sìn gẹ́gẹ́ bí ìríjú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run. A mọ̀ pé tó bá lè ṣeé ṣe fún Sátánì láti mú ká ṣíwọ́ ‘ṣíṣe ìránṣẹ́ fún ara wa,’ yóò já ìdè ìrẹ́pọ̀ wa. (Kól. 3:14) Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ńṣe ni àìsí ìṣọ̀kan yóò bomi paná ìtara wa nínú iṣẹ́ ìwàásù. Sátánì mọ̀ pé tóun bá fi lè mú ká pa ọ̀kan nínú ojúṣe wa méjèèjì yìí tì, ńṣe la máa dà bí ẹyẹ tí wọ́n dá apá rẹ̀ kan, tí ò ní lè fò mọ́.
14. Ta ló máa ń jàǹfààní ‘ṣíṣe ìránṣẹ́ fún ara wa’? Sọ àpẹẹrẹ kan.
14 Kì í ṣe kìkì àwọn tó gba inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run ló ń jàǹfààní tá a bá ń ‘ṣe ìránṣẹ́ fún ara wa,’ àwọn tó ń jẹ́ káwọn èèyàn rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí náà gbà tún ń jàǹfààní pẹ̀lú. (Òwe 11:25) Wo àpẹẹrẹ tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Ryan àti Roni ní ìpínlẹ̀ Illinois, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ìjì líle kan tí wọ́n ń pè ní Katrina ba ọgọ́rọ̀ọ̀rún ilé àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́, ìfẹ́ ará mú kí wọ́n fi iṣẹ́ wọn sílẹ̀, kí wọ́n fi ilé wọn sílẹ̀, kí wọ́n sì ra ilé alágbèérìn kan, èyí tí wọ́n tún ṣe, tí wọ́n sì fọkọ̀ gbé lọ sí ìpínlẹ̀ Louisiana tó tó nǹkan bí egbèje [1,400] kìlómítà síbi tí wọ́n wà. Wọ́n lò ju ọdún kan lọ níbẹ̀, wọ́n ń lo àkókò wọn, agbára wọn àti gbogbo ohun tí wọ́n ní láti fi ran àwọn ará lọ́wọ́. Ryan tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n sọ pé: “Lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìrànwọ́ ti mú kí n túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run, mo sì rí bí Jèhófà ṣe ń bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀.” Ryan fi kún un pé: “Bíbá àwọn àgbà tó jù mí lọ ṣiṣẹ́ ti jẹ́ kí n mọ bá a ṣe ń bójú tó àwọn ará. Mo tún wá mọ̀ pé iṣẹ́ púpọ̀ wà fáwa ọ̀dọ́ láti ṣe nínú ètò Jèhófà.” Roni ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sọ pé: “Inú mi dùn pé mo lè lọ́wọ́ nínú ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Inú mi kò tíì dùn tó báyìí rí láyé mi. Mo mọ̀ pé títí ayé ni màá máa jàǹfààní ìrírí alárinrin yìí.”
15. Àwọn ìdí pàtàkì wo la ní tá a fi ní láti jẹ́ kí Ọlọ́run máa lò wá gẹ́gẹ́ bí ìríjú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀?
15 Ká sòótọ́, ṣíṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run pé ká máa wàásù ìhìn rere, ká sì máa gbé àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ ró máa ń mú ìbùkún wá fún gbogbo wa. Àwọn tá a ràn lọ́wọ́ yóò máa bá a nìṣó ní sísin Jèhófà, bí àwa náà ti ń ní ayọ̀ ọkàn tó máa ń wá látinú fífúnni. (Ìṣe 20:35) Ìjọ yóò túbọ̀ máa lárinrin, bí àwọn ará ìjọ bá ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn ará jẹ wọ́n lógún. Síwájú sí i, ìfẹ́ àti ọ̀yàyà tá a fi ń bá ara wa lò ń fi wá hàn kedere pé Kristẹni tòótọ́ ni wá. Jésù sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòh. 13:35) Lékè gbogbo rẹ̀, Jèhófà Baba wa onífẹ̀ẹ́ ni ògo yẹ, bí àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé ṣe ń mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ nípa ṣíṣèrànwọ́ fáwọn tó nílò rẹ̀. Ẹ ò rí i pé gbogbo wa la ní àwọn ìdí pàtàkì láti máa lo ẹ̀bùn wa ‘nínú ṣíṣe ìránṣẹ́ fún ara wa gẹ́gẹ́ ìríjú àtàtà fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run’! Ṣé wàá máa lo ẹ̀bùn tìrẹ?—Ka Hébérù 6:10.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lókun?
• Kí ni Ọlọ́run fi síkàáwọ́ wa?
• Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà máa ran àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ lọ́wọ́?
• Kí ló máa mú ká máa bá a lọ láti lo ẹ̀bùn wa ‘nínú ṣíṣe ìránṣẹ́ fún ara wa’?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ṣé ò ń fi “ẹ̀bùn” rẹ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ ni àbí o fi ń gbọ́ tara rẹ?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
À ń wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn, a sì ń ran àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni lọ́wọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ó yẹ ká máa gbóríyìn fáwọn tó ń wá ṣèrànwọ́ nígbà àjálù nítorí wọ́n ń lo ara wọn fáwọn ẹlòmíì