Wò ó! Ìránṣẹ́ Tí Jèhófà Tẹ́wọ́ Gbà
Wò ó! Ìránṣẹ́ Tí Jèhófà Tẹ́wọ́ Gbà
“Wò ó! Ìránṣẹ́ mi, . . . ẹni tí ọkàn mi tẹ́wọ́ gbà!”—AÍSÁ. 42:1.
1. Kí ló yẹ káwa èèyàn Jèhófà ṣe, pàápàá bí àkókò Ìrántí Ikú Kristi ṣe ń sún mọ́lé, kí sì nìdí rẹ̀?
BÍ ÀKÓKÒ tí a ó ṣe Ìrántí Ikú Kristi ti ń sún mọ́lé, ó yẹ kí àwa èèyàn Ọlọ́run tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé ká “tẹjú mọ́ Olórí Aṣojú àti Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa, Jésù.” Pọ́ọ̀lù fi kún un pé: “Ní tòótọ́, ẹ ronú jinlẹ̀-jinlẹ̀ nípa ẹni tí ó ti fara da irúfẹ́ òdì ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ láti ẹnu àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lòdì sí ire ara wọn, kí ó má bàa rẹ̀ yín, kí ẹ sì rẹ̀wẹ̀sì nínú ọkàn yín.” (Héb. 12:2, 3) Tí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn ẹlẹgbẹ́ wọn bá ń ronú jinlẹ̀ lórí ìgbé ayé olóòótọ́ tí Kristi gbé débi tó fi fẹ̀mí ara rẹ̀ rúbọ, wọn yóò lè máa sin Jèhófà nìṣó láìyẹsẹ̀, wọn ò sì ní ‘rẹ̀wẹ̀sì nínú ọkàn wọn.’—Fi wé Gálátíà 6:9.
2. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Aísáyà sọ nípa Ọmọ Ọlọ́run?
2 Jèhófà gbẹnu wòlíì Aísáyà sọ ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ọmọ rẹ̀. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí yóò jẹ́ ká lè “tẹjú mọ́ Olórí Aṣojú àti Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa,” Kristi Jésù. a Nítorí pé wọ́n ṣàlàyé irú ànímọ́ tó máa ní, ìyà tó máa jẹ àti bí Ọlọ́run ṣe máa gbé e ga táá fi di Ọba àti Olùtúnniràpadà wa. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí á tún mú kí òye wa túbọ̀ kún sí i nípa Ìrántí Ikú Kristi tá a máa ṣe lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀ lọ́jọ́ Thursday, April 9, ọdún tá a wà yìí.
Ẹni Tí Ìránṣẹ́ Náà Jẹ́
3, 4. (a) Báwo ni ìwé Aísáyà ṣe lo ọ̀rọ̀ náà, “ìránṣẹ́”? (b) Báwo ni Bíbélì fúnra rẹ̀ ṣe jẹ́ ká mọ ẹni tí ìwé Aísáyà orí 42, 49, 50, 52 àti 53 pè ní Ìránṣẹ́?
3 Ọ̀rọ̀ náà, “ìránṣẹ́,” pọ̀ nínú ìwé Aísáyà. Ìwé náà pe wòlíì Aísáyà fúnra rẹ̀ ní ìránṣẹ́ láwọn ibì kan. (Aísá. 20:3; 44:26) Láwọn ibòmíì ó pe gbogbo orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tàbí Jékọ́bù ní ìránṣẹ́. (Aísá. 41:8, 9; 44:1, 2, 21) Ṣùgbọ́n ta ni ìwé Aísáyà pè ní Ìránṣẹ́ nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì-pàtàkì tó wà ní Aísáyà orí 42, 49, 50, 52 àti 53? Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì jẹ́ ká mọ Ìránṣẹ́ Jèhófà tí ibẹ̀ yẹn ń sọ dájú. Ọ̀kan nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí ni ìwẹ̀fà ará Etiópíà tí ìwé Ìṣe sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ tiẹ̀ ń kà lọ́wọ́ nígbà tí ẹ̀mí darí Fílípì ajíhìnrere pé kó lọ bá a. Lẹ́yìn tí ìwẹ̀fà tó jẹ́ ìjòyè yìí ka àyọkà tó wà nínú Aísáyà 53:7, 8 báyìí, ó bi Fílípì pé: “Mo bẹ̀ ọ́, Ta ni wòlíì náà sọ èyí nípa rẹ̀? Nípa ara rẹ̀ ni tàbí nípa ẹlòmíràn?” Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Fílípì fi yé e pé ọ̀rọ̀ nípa Mèsáyà, ìyẹn Jésù ni Aísáyà ń sọ níbẹ̀.—Ìṣe 8:26-35.
4 Nígbà tí Jésù ṣì wà lọ́mọ ọwọ́, ẹ̀mí mímọ́ mú kí ọkùnrin olódodo kan tó ń jẹ́ Síméónì kéde pé “ọmọ kékeré náà Jésù” yóò di “ìmọ́lẹ̀ fún mímú ìbòjú kúrò lójú àwọn orílẹ̀-èdè,” gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Aísáyà 42:6 àti 49:6 ṣe fi hàn. (Lúùkù 2:25-32) Bákan náà, ìwọ̀sí tí wọ́n fi lọ Jésù lóru ọjọ́ tí wọ́n gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ wà lára ohun tí Aísáyà 50:6-9 ti sọ tẹ́lẹ̀. (Mát. 26:67; Lúùkù 22:63) Lẹ́yìn àjọ̀dún Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àpọ́sítélì Pétérù fi hàn kedere pé Jésù ni “Ìránṣẹ́” Jèhófà yẹn. (Aísá. 52:13; 53:11; ka Ìṣe 3:13, 26.) Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà yìí?
Jèhófà Dá Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Lẹ́kọ̀ọ́
5. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wo ni Ìránṣẹ́ náà gbà?
5 Ọ̀kan nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà nípa Ìránṣẹ́ Ọlọ́run jẹ́ ká mọ irú àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ àkọ́bí yìí ṣáájú kí wọ́n tó bí i sáyé. (Ka Aísáyà 50:4-9.) Ìránṣẹ́ náà fúnra rẹ̀ jẹ́ ká mọ̀ pé ojoojúmọ́ ni Jèhófà ń dá òun lẹ́kọ̀ọ́, ó ní: “Ó ń jí etí mi láti gbọ́, bí àwọn tí a kọ́.” (Aísá. 50:4) Ní gbogbo àkókò yẹn, ńṣe ni Ìránṣẹ́ Jèhófà yìí tẹ́tí sílẹ̀ tó ń fi ìtẹríba kẹ́kọ̀ọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn lọ́dọ̀ Baba rẹ̀. Àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ gbáà ni o, láti jẹ́ ẹni tí Ẹlẹ́dàá ayé àtọ̀run kọ́ lẹ́kọ̀ọ́!
6. Báwo ni Ìránṣẹ́ yìí ṣe fi hàn pé òun tẹrí ba pátápátá fún Baba òun?
6 Nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí, Ìránṣẹ́ náà pe Baba rẹ̀ ní “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.” Èyí fi hàn pé Ìránṣẹ́ yìí mọ̀ dájú pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run. Láti fi hàn pé òun tẹrí ba pátápátá fún Baba òun, ó ní: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ tìkára rẹ̀ ti ṣí etí mi, èmi, ní tèmi, kò sì ya ọlọ̀tẹ̀. Èmi kò yí padà sí òdì-kejì.” (Aísá. 50:5) Ó “wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ [Jèhófà] gẹ́gẹ́ bí àgbà òṣìṣẹ́” nígbà tí Jèhófà ń dá ọ̀run, ayé àtàwa èèyàn. Ńṣe ni “àgbà òṣìṣẹ́” yìí “ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ níwájú [Jèhófà] ní gbogbo ìgbà, [ó] ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ sí ilẹ̀ eléso ilẹ̀ ayé rẹ̀, àwọn ohun tí [Ọmọ Ọlọ́run yìí] sì ní ìfẹ́ni sí jẹ́ sípa àwọn ọmọ ènìyàn.”—Òwe 8:22-31.
7. Kí ló fi hàn pé ó dá Ìránṣẹ́ yìí lójú pé Baba òun ń bẹ lẹ́yìn òun nígbà tó ń fojú winá àdánwò láyé?
7 Ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí Ìránṣẹ́ yìí gbà àti ìfẹ́ tó ní sọ́mọ aráyé ló jẹ́ kó lè fara da inúnibíni tí wọ́n ṣe sí i nígbà tó wá sáyé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣe inúnibíni sí i lọ́nà rírorò, inú rẹ̀ ṣì ń dùn láti máa ṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀. (Sm. 40:8; Mát. 26:42; Jòh. 6:38) Ní gbogbo ìgbà tí Jésù ń fojú winá àdánwò láyé, ó dá a lójú pé Baba òun ń bẹ lẹ́yìn òun àti pé inú rẹ̀ ń dùn sóun. Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà fi hàn pé, ó ṣeé ṣe fún Jésù láti sọ pé: “Ẹni tí ń polongo mi ní olódodo ń bẹ nítòsí. Ta ni ó lè bá mi fà á? . . . Wò ó! Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ tìkára rẹ̀ yóò ràn mí lọ́wọ́.” (Aísá. 50:8, 9) Láìsí àní-àní, Jèhófà ran Ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ yìí lọ́wọ́ jálẹ̀ gbogbo ìgbà tó ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé. Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà míì sì fi èyí hàn.
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìránṣẹ́ Náà Lórí Ilẹ̀ Ayé
8. Kí ló fi hàn pé Jésù ni “àyànfẹ́” Jèhófà tí àsọtẹ́lẹ̀ inú Aísáyà 42:1 ń sọ?
8 Bíbélì sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi lọ́dún 29 Sànmánì Kristẹni, ó ní: “Ẹ̀mí mímọ́ . . . bà lé e, ohùn kan sì jáde wá láti inú ọ̀run pé: ‘Ìwọ ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n; mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.’” (Lúùkù 3:21, 22) Bí Jèhófà ṣe jẹ́ ká mọ “àyànfẹ́” rẹ̀ tí àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ń sọ nìyẹn. (Ka Aísáyà 42:1-7.) Nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé, ó mú àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ lọ́nà tó pabanbarì. Nígbà tí Mátíù ń kọ ìwé Ìhìn Rere rẹ̀, ó ṣàyọlò ọ̀rọ̀ tó wà nínú Aísáyà 42:1-4, ó ní ó ṣẹ sí Jésù lára.—Mát. 12:15-21.
9, 10. (a) Báwo ni Jésù ṣe mú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà 42:3 ṣẹ nígbà tó ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀? (b) Báwo ni Kristi ṣe “mú ìdájọ́ òdodo wá” nígbà tó wà ní ayé, ìgbà wo ló sì máa “gbé ìdájọ́ òdodo kalẹ̀ ní ilẹ̀ ayé”?
9 Ṣe làwọn aṣáájú ẹ̀sìn àwọn Júù máa ń fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn aráàlú. (Jòh. 7:47-49) Bí wọ́n ṣe ń ṣe àwọn èèyàn náà ṣúkaṣùka mú káwọn èèyàn dà bí “esùsú fífọ́” tàbí “òwú àtùpà tí a fi ọ̀gbọ̀ ṣe” tó ń jó lọ́úlọ́ú, tí ẹ̀ṣẹ́ná ìkẹyìn tó kù lára rẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú. Àmọ́ ní ti Jésù, ńṣe ló ń ṣàánú àwọn aláìní àtàwọn tó wà nínú ìpọ́njú. (Mát. ) Ó pè wọ́n sọ́dọ̀, ó ní: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára.” ( 9:35, 36Mát. 11:28) Yàtọ̀ síyẹn, Jésù “mú ìdájọ́ òdodo wá” ní ti pé ó kọ́ àwọn èèyàn ní ìlànà Jèhófà nípa ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́. (Aísá. 42:3) Ó tún fi hàn pé tipátipá kọ́ ló yẹ ká máa múni tẹ̀ lé Òfin Ọlọ́run bí kò ṣe pé ká máa lo òye àti àánú. (Mát. 23:23) Bákan náà, Jésù mú ìdájọ́ òdodo wá ní ti pé àtolówó àti tálákà ló ń wàásù fún láìsí ojúsàájú.—Mát. 11:5; Lúùkù 18:18-23.
10 Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà tún sọ pé “àyànfẹ́” Jèhófà yóò “gbé ìdájọ́ òdodo kalẹ̀ ní ilẹ̀ ayé.” (Aísá. 42:4) Ó máa tó ṣe èyí, nígbà tí òun Mèsáyà, ọba Ìjọba Ọlọ́run, bá pa gbogbo àwọn ìjọba ayé yìí run tó sì fi ìṣàkóso òdodo tirẹ̀ rọ́pò wọn. Yóò wá mú ayé tuntun kan wá, níbi tí “òdodo yóò sì máa gbé.”—2 Pét. 3:13; Dán. 2:44.
Ó Jẹ́ “Ìmọ́lẹ̀” àti “Májẹ̀mú”
11. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè” ní ọ̀rúndún kìíní, ọ̀nà wo ló sì gbà jẹ́ bẹ́ẹ̀ títí dòní?
11 Àsọtẹ́lẹ̀ inú Aísáyà 42:6 ṣẹ sí Jésù lára ní ti pé ó jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè” lóòótọ́. Nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé, ọ̀dọ̀ àwọn Júù ló mú ìmọ́lẹ̀ ìhìn rere wá ní pàtàkì. (Mát. 15:24; Ìṣe 3:26) Ṣùgbọ́n Jésù tún sọ pé: “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.” (Jòh. 8:12) Yàtọ̀ sí pé ó jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fáwọn Júù àtàwọn orílẹ̀-èdè ní ti pé ó là wọ́n lóye nípa tẹ̀mí, ó tún jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún wọn ní ti pé ó fi ẹ̀mí rẹ̀ pípé rúbọ kó lè ra gbogbo aráyé pátá pa dà. (Mát. 20:28) Lẹ́yìn tó jíǹde, ó ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa ṣe ẹlẹ́rìí òun “títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ń wàásù, wọ́n ṣàyọlò ọ̀rọ̀ náà, “ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,” látinú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, wọ́n ní àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ló ń ní ìmúṣẹ báwọn ṣe ń wàásù fáwọn tí kì í ṣe Júù. (Ìṣe 13:46-48; fi wé Aísáyà 49:6.) Iṣẹ́ ìwàásù yìí ṣì ń bá a lọ títí dòní, bí àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ arákùnrin Jésù lórí ilẹ̀ ayé àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn ṣe ń tan ìhìn rere káàkiri, tí wọ́n sì ń mú káwọn èèyàn nígbàgbọ́ nínú Jésù, tó jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè.”
12. Báwo ni Jèhófà ṣe fi Ìránṣẹ́ rẹ̀ fúnni “gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú àwọn ènìyàn”?
12 Nínú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn, Jèhófà sọ fún Ìránṣẹ́ rẹ̀ tó yàn pé: “Èmi yóò sì máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ, èmi yóò sì fi ọ́ fúnni gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú àwọn ènìyàn.” (Aísá. 42:6) Sátánì sa gbogbo ipá rẹ̀ láti ṣekú pa Jésù, kí Jésù má bàa lè parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó wá ṣe láyé, àmọ́ Jèhófà dáàbò bò ó títí di ìgbà tó yẹ kó kú. (Mát. 2:13; Jòh. 7:30) Lẹ́yìn náà, Jèhófà jí Jésù dìde, ó sì fi í fún àwa ọmọ aráyé gẹ́gẹ́ bí “májẹ̀mú” tàbí ẹ̀jẹ́. Ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ yìí mú kó dájú pé Ìránṣẹ́ Ọlọ́run olóòótọ́ yìí yóò jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,” yóò sì máa mú àwọn èèyàn kúrò nínú òkùnkùn tẹ̀mí.—Ka Aísáyà 49:8, 9. b
13. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà mú “àwọn tí ó jókòó sínú òkùnkùn” jáde nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní ayé, báwo ló sì ṣe ń bá iṣẹ́ dídá àwọn èèyàn nídè nìṣó?
13 Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀jẹ́ yìí ṣe fi hàn, Ìránṣẹ́ tí Jèhófà yàn yìí yóò “la àwọn ojú tí ó fọ́,” yóò “mú ẹlẹ́wọ̀n jáde kúrò nínú àjà ilẹ̀,” yóò sì mú “àwọn tí ó jókòó sínú òkùnkùn” jáde kúrò níbẹ̀. (Aísá. 42:7) Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni Jésù ṣe nígbà tó ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé, ní ti pé ó táṣìírí àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́sìn èké, ó sì tún wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Mát. 15:3; Lúùkù 8:1) Ó wá tipa bẹ́ẹ̀ dá àwọn Júù tó di ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nídè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀sìn èké. (Jòh. 8:31, 32) Bákan náà ló ṣe dá ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn míì tí kì í ṣe Júù nídè nípa jíjẹ́ kó ṣeé ṣe fún wọn láti kọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́. Ó tún rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n “lọ . . . máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn,” ó sì ṣèlérí pé òun máa wà pẹ̀lú wọn “títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 28:19, 20) Kristi Jésù sì ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé yìí láti ibi tó wà lọ́run lóòótọ́.
Jèhófà Gbé “Ìránṣẹ́” Rẹ̀ Ga
14, 15. Kí nìdí tí Jèhófà fi gbé Ìránṣẹ́ rẹ̀ ga, báwo ló sì ṣe gbé e ga?
14 Ohun tí Jèhófà tún sọ nínú àsọtẹ́lẹ̀ míì nípa Mèsáyà Ìránṣẹ́ rẹ̀ yìí ni pé: “Wò ó! Ìránṣẹ́ mi yóò fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà. Yóò wà ní ipò gíga, a ó sì gbé e lékè dájúdájú, a ó sì gbé e ga gidigidi.” (Aísá. 52:13) Bí Ọmọ Ọlọ́run yìí ṣe tẹrí ba pátápátá fún Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ, tó sì jẹ́ olóòótọ́ lábẹ́ ìdánwò tó le koko jù lọ ló mú kí Jèhófà gbé e ga.
15 Àpọ́sítélì Pétérù sọ nípa Jésù pé: “Ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, nítorí tí ó bá ọ̀nà rẹ̀ lọ sí ọ̀run; a sì fi àwọn áńgẹ́lì àti àwọn aláṣẹ àti àwọn agbára sábẹ́ rẹ̀.” (1 Pét. 3:22) Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà sì sọ ni pé: “Ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di onígbọràn títí dé ikú, bẹ́ẹ̀ ni, ikú lórí òpó igi oró. Fún ìdí yìí gan-an pẹ̀lú ni Ọlọ́run fi gbé e sí ipò gíga, tí ó sì fi inú rere fún un ní orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn, kí ó lè jẹ́ pé ní orúkọ Jésù ni kí gbogbo eékún máa tẹ̀ ba ti àwọn tí ń bẹ ní ọ̀run àti àwọn tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé àti àwọn tí ń bẹ lábẹ́ ilẹ̀, kí gbogbo ahọ́n sì máa jẹ́wọ́ ní gbangba pé Jésù Kristi ni Olúwa fún ògo Ọlọ́run Baba.”—Fílí. 2:8-11.
16. Báwo ni Jèhófà ṣe “gbé” Jésù “ga gidigidi” lọ́dún 1914, kí sì ni Jésù ti gbé ṣe látìgbà náà?
16 Lọ́dún 1914, Jèhófà tún gbé Jésù ga ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Jèhófà “gbé e ga gidigidi” nígbà tó gbé e gorí ìtẹ́, tó wá fi jẹ ọba Ìjọba Ọlọ́run. (Sm. 2:6; Dán. 7:13, 14) Látìgbà yẹn ni Kristi ti jáde lọ tó sì wá ń “ṣẹ́gun lọ láàárín àwọn ọ̀tá” rẹ̀. (Sm. 110:2) Ó kọ́kọ́ ṣẹ́gun Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù, ó sì lé wọn jù sí sàkáání ayé. (Ìṣí. 12:7-12) Lẹ́yìn náà, Kristi tó jẹ́ Kírúsì Ńlá wá gbéra, ó dá àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ arákùnrin rẹ̀ nídè kúrò lọ́wọ́ “Bábílónì Ńlá.” (Ìṣí. 18:2; Aísá. 44:28) Ó ń darí iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé láti fi kó “àwọn tí ó ṣẹ́ kù” lára àwọn arákùnrin rẹ̀ nípa tẹ̀mí jọ pọ̀ àti láti fi kó àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn “àgùntàn mìíràn” olóòótọ́ tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ àwọn “agbo kékeré” náà jọ.—Ìṣí. 12:17; Jòh. 10:16; Lúùkù 12:32.
17. Ẹ̀kọ́ wo la ti rí kọ́ látinú àgbéyẹ̀wò àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Aísáyà nípa “ìránṣẹ́” Ọlọ́run náà?
17 Bá a ṣe gbé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì-pàtàkì inú ìwé Aísáyà yẹ̀ wò yìí ti jẹ́ ká túbọ̀ mọyì Jésù Kristi Ọba wa àti Olùtúnniràpadà wa. Ọ̀nà tí Jésù Ọmọ Ọlọ́run gbà tẹrí ba fún Baba rẹ̀ nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé fi hàn pé ó ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ dáadáa lọ́dọ̀ Baba rẹ̀ kó tó wá sáyé. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé àti iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tó ń bójú tó títí dòní yìí ti fi hàn pé “ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè” ló jẹ́ lóòótọ́. Bí a ó ṣe tún rí i nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, àsọtẹ́lẹ̀ míì nípa Ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí í ṣe Mèsáyà yìí fi hàn pé yóò jìyà, yóò sì fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa. Èyí jẹ́ àwọn nǹkan tó yẹ ká “ronú jinlẹ̀-jinlẹ̀” lé lórí bí àkókó Ìrántí Ikú Kristi ṣe dé tán yìí.—Héb. 12:2, 3.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a O lè rí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí nínú Aísáyà 42:1-7; 49:1-12; 50:4-9 àti 52:13–53:12.
b Tó o bá fẹ́ ka àlàyé nípa àsọtẹ́lẹ̀ inú Aísáyà 49:1-12, wo ìwé Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì, ojú ìwé 136 sí 145.
Àtúnyẹ̀wò
• Ta ni “ìránṣẹ́” náà táwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Aísáyà sọ̀rọ̀ rẹ̀, báwo la sì ṣe mọ̀?
• Ìdálẹ́kọ̀ọ́ wo ni Ìránṣẹ́ náà gbà lọ́dọ̀ Jèhófà?
• Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè”?
• Báwo ni Jèhófà ṣe gbé Ìránṣẹ́ náà ga?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Fílípì fi hàn kedere pé Jésù tí í ṣe Mèsáyà ni “ìránṣẹ́” tí Aísáyà ń sọ̀rọ̀ rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Jésù, Ìránṣẹ́ tí Jèhófà yàn, ṣàánú àwọn aláìní àtàwọn tó wà nínú ìpọ́njú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Baba Jésù gbé e ga, ó sì gbé e gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọba Ìjọba Ọlọ́run