Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Rọ Àwọn Míṣọ́nnárì Pé Kí Wọ́n Dà Bíi Jeremáyà

A Rọ Àwọn Míṣọ́nnárì Pé Kí Wọ́n Dà Bíi Jeremáyà

Ayẹyẹ Ìkẹ́kọ̀ọ́yege Kíláàsì Karùnlélọ́gọ́fà Nílé Ẹ̀kọ́ Gílíádì

A Rọ Àwọn Míṣọ́nnárì Pé Kí Wọ́n Dà Bíi Jeremáyà

AYẸYẸ ìkẹ́kọ̀ọ́yege kíláàsì karùnlélọ́gọ́fà nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì wáyé ní September 13, ọdún 2008. Iye àwọn tó pésẹ̀ síbi ayẹyẹ náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ó lé mẹ́rìndínlọ́gọ́jọ [6,156]. Nígbà tí alága ètò náà, Arákùnrin Geoffrey Jackson tó jẹ́ ọ̀kan nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí dẹ́nu lé ọ̀rọ̀, ó sọ pé: “Ọ̀kan pàtàkì ni kíláàsì yìí jẹ́ nínú ìtàn Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì.” Ìdí ni pé pẹ̀lú àwọn mẹ́rìndínlọ́gọ́ta tó kẹ́kọ̀ọ́ yege lọ́jọ́ yẹn, iye àwọn míṣọ́nnárì tí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ti rán jáde lọ sí “apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé” ti lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ.—Ìṣe 1:8.

Arákùnrin Jackson béèrè ìbéèrè kan lọ́wọ́ àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege náà, ó ní, “Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ rẹ á ṣeé gbà gbọ́ lóde ẹ̀rí?” Ó wá sọ ohun mẹ́rin tó máa ń jẹ́ káwọn èèyàn gbani gbọ́. Àwọn ohun náà ni ìṣarasíhùwà tó dáa, àpẹẹrẹ rere, gbígbé ọ̀rọ̀ ẹni karí Bíbélì àti sísapá láti máa pòkìkí orúkọ Jèhófà.

Arákùnrin David Schafer, tó ń bá Ìgbìmọ̀ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ṣiṣẹ́ pọ̀, jíròrò ọ̀rọ̀ tí àkòrí rẹ̀ jẹ́: “Ṣé O Máa Mọ Gbogbo Nǹkan?” Ó fi dá àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì lójú pé bí wọn ò bá tiẹ̀ mọ gbogbo nǹkan nípa ibi tí wọ́n ti fẹ́ lọ ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì, wọ́n ṣì lè “mọ gbogbo nǹkan” tí wọ́n nílò láti ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì láṣeyọrí bí wọ́n bá ń wá Jehófà tí wọ́n sì ń fìrẹ̀lẹ̀ tẹ̀ lé “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.”—Òwe 28:5; Mát. 24:45.

Ẹni tó sọ̀rọ̀ tẹ̀ lé e ni Arákùnrin John E. Barr tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni, “Ẹ Má Ṣe Jẹ́ Kí Ohunkóhun Yà Yín Kúrò Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run.” Ìmọ̀ràn baba sí ọmọ ni ọ̀rọ̀ Arákùnrin Barr jẹ́ sáwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege àtàwọn òbí wọn. Ìmọ̀ràn yẹn fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ lórí ohunkóhun tó lè máa bà wọ́n lẹ́rù nípa ibi táwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ yege yìí ti fẹ́ lọ ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì wọn. Ó ṣàlàyé fún wọn pé: “Inú ibì kan ṣoṣo téèyàn lè wà láyé yìí tọ́kàn ẹni á ti balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ láìsí ewu ni inú ìfẹ́ Ọlọ́run.” Kò sóhun tó lè ya àwọn míṣọ́nnárì kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run àfi tí àwọn fúnra wọn bá kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run.

Arákùnrin Sam Roberson tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Ẹ̀kọ́ Ètò Ọlọ́run rọ àwọn tó wà níkàlẹ̀ pé kí wọ́n gbé “ẹ̀wù tó ju gbogbo ẹ̀wù lọ,” ìyẹn Jésù Kristi wọ̀. Bí àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ṣe lè “gbé Olúwa Jésù Kristi wọ̀” ni pé kí wọ́n máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Jésù ṣe kí wọ́n sì máa fi sílò. (Róòmù 13:14) Lẹ́yìn ìyẹn ni Arákùnrin William Samuelson, tó jẹ́ alábòójútó Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Ẹ̀kọ́ Ètò Ọlọ́run ṣàlàyé ohun tó ń mú kéèyàn dẹni iyì. Ó ní kì í ṣe bí aráyé ṣe ń wo èèyàn ló ń sọni dẹni iyì bí kò ṣe ojú tí Ọlọ́run fi ń wo èèyàn.

Arákùnrin Michael Burnett, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege náà nípa ìrírí tí wọ́n ní lóde ẹ̀rí lákòókò tí wọ́n fi wà nílé ẹ̀kọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìpínlẹ̀ ìwàásù táwọn ará máa ń ṣe wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ ni wọ́n pín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sí nígbà tí wọ́n wà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì nílùú Patterson, ní ìpínlẹ̀ New York, síbẹ̀ wọ́n pàpà rí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ìwàásù wọn. Arákùnrin Gerald Grizzle tó ń ṣiṣẹ́ ní Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Àpéjọ fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn arákùnrin mẹ́ta tí wọ́n wá sí Ilé Ẹ̀kọ́ fún Àwọn Tó Wà Nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka. Ohun tí wọ́n sọ mú àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì gbara dì fún ohun tí wọ́n máa bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ wọn nílẹ̀ òkèèrè.

Arákùnrin David Splane tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí, tóun náà kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kejìlélógójì ilé ẹ̀kọ́ yìí, ló sọ àsọyé tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Ẹ Dà Bíi Jeremáyà.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rù ba Jeremáyà nípa iṣẹ́ tí Jèhófà fẹ́ gbé fún un, àmọ́ Jèhófà fún un lókun. (Jer. 1:7, 8) Bẹ́ẹ̀ náà ni Ọlọ́run ṣe máa fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di míṣọ́nnárì yìí lókun. Arákùnrin Splane sọ pé: “Tí àárín ìwọ àtẹnì kan ò bá gún, fara balẹ̀ kọ ohun mẹ́wàá tó o rí pé ó dára nínú ìwà onítọ̀hún sílẹ̀. Tó ò bá lè rí mẹ́wàá kọ sílẹ̀, a jẹ́ pé o ò tíì mọ onítọ̀hún dáadáa.”

Jeremáyà jẹ́ ẹni tó fi gbogbo ara jin iṣẹ́ Ọlọ́run. Nígbà tó sì ń ṣe é bíi pé kó pa iṣẹ́ tí Jèhófà yàn fún un tì, ó gbàdúrà, Jèhófà sì dúró tì í. (Jer. 20:11) Arákùnrin Splane sọ pé: “Tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá fẹ́ bá yín, ẹ bá Jèhófà sọ ọ́. Ẹnu á yà yín bí Jèhófà ṣe máa ràn yín lọ́wọ́.”

Níparí ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege náà, alága ayẹyẹ náà rán àwọn tó wà níbẹ̀ létí pé àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege yìí ti kọ́ onírúurú ọ̀nà tí wọ́n fi lè dẹni tó ṣeé gbà gbọ́. Bí wọ́n ṣe ń bá iṣẹ́ ìjẹ́rìí wọn lọ níbi tá a yàn wọ́n sí, táwọn èèyàn bá mọ̀ wọ́n sẹ́ni tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣeé gbà gbọ́, ìwàásù wọn á túbọ̀ máa nípa tó dára lórí àwọn èèyàn.—Aísá. 43:8-12.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]

ÌSỌFÚNNI NÍPA KÍLÁÀSÌ

Iye orílẹ̀-èdè táwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti wá: 6

Iye orílẹ̀-èdè tá a yàn wọ́n sí: 21

Iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́: 56

Ìpíndọ́gba ọjọ́ orí wọn: 32.9

Ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti lò nínú òtítọ́: 17.4

Ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti lò nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún: 13

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Kíláàsì Karùnlélọ́gọ́fà Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì

Nínú ìlà àwọn orúkọ tí ń bẹ nísàlẹ̀ yìí, ńṣe la to nọ́ńbà ìlà kọ̀ọ̀kan láti iwájú lọ sẹ́yìn, a sì to orúkọ láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún lórí ìlà kọ̀ọ̀kan.

(1) Hodgson, A.; Wall, A.; Beerens, K.; Hortelano, M.; Newman, L.; De Caso, A. (2) Jenkins, J.; Jarzemski, T.; Méndez, N.; Corona, V.; Canalita, L. (3) Fryer, H.; Savage, M.; Tidwell, K.; Erickson, N.; Dyck, E.; McBeath, R. (4) Perez, L.; Puse, L.; Skidmore, A.; Young, B.; McBride, N.; Rondón, P.; Goodman, E. (5) Beerens, M.; Ferguson, J.; Pearson, N.; Chapman, L.; Wardle, J.; Canalita, M. (6) Perez, P.; De Caso, D.; Young, T.; Rondón, D.; Goodman, G.; Jenkins, M.; Dyck, G. (7) Corona, M.; Wall, R.; Puse, S.; Méndez, F.; Jarzemski, S.; Savage, T. (8) Newman, C.; Ferguson, D.; Skidmore, D.; Erickson, T.; McBride, J.; Pearson, M.; Chapman, M. (9) Hodgson, K.; Wardle, A.; McBeath, A.; Tidwell, T.; Fryer, J.; Hortelano, J.